AKAYE OLORO GEERE

OSE KEJE

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: AKAYE OLORO GEERE.

Akaye ni kika ayoka kan ti o ni itumo ni ona ti o le gba yeni yekeyeke

Igbese ayoka kika

a.kika ati mimo ohun ti ayoka naa dale lori

  1. sise itupale ayoka ni finifinni
  2. fifi imo ede, laakaye ati iforabale ka ayoka naa sinu
  3. dida awon koko oro, owe ati akanlo ede inu ayoka naa mo
  4. mimo orisirisi ibeere ti o wa labe ayoka naa
  5. didahun awon ibeere pelu laakaye

apeere ibeere ti owa labe akaye

i.ibeere ewo-ni-idahun

  1. ibeere ajemo itumo-ede

iii.Ibeere agboroko

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE OMO BIBI ( ORO IDILE BABA OLOMO)

Oniruru esin abalaye ni o wa ni ile Yoruba. Eya  kookan ni o si ni esin ti won sin kaari ile kaaro-oo-jiire. Esin bii,

Sango-pipe

Oya-pipe

Obatala

Esu

Ifa

Egngun abbl.

 

Asa isomoloruko ati oro ti won n se yato lati ile kansi ekeji, lati ebi kan si ekeji tabi lati iran kan si ekeji.

Okan laar oro ti a maa nse fun omo tuntun ni ile Yoruba ni gbigbe omo si igbasoro ni ita, won yoo si da omi si orule, won yoo wa je ki omi naa ro si omo naa lara. Leyin eyi ni baba omo yoo fun omo ni oruko ati oriki, gbogbo ebi yoo si so fun omo naa pe “ki olorun je ki a mo on mo oruko re o, iwo naa yoo so omo loruko”

Awon obi omo yoo to awon babalawo lo lati lo da ifa, won yoo fi ese omo naa te opon ifa bee ni won yoo si beere ohun ti omo naa yoo da laye lowo ifa. Gbogbo akunleyan omo yii lati orun ni ifa yoo so. Eyi ti o ba si nilo etutu ki aye re le tuba-tuse ni won yoo se.

 

EKA ISE LITIRESO 

AKOLE ISE: KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.

Igbelewon: 

  • Fun akaye loriki
  • Ko awon igbese ti a ni lati tele bi a ba n ka akaye
  • Salaye apeere ibeere ti o wa labe akaye
  • Bawo ni oro idile se ye o si?

Ise asetilewa: salaye lekun un rere bi oro idile baba olomo se ye o si. Lo apeere oro idile re lati gbe idahun re lese

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share