AKOLE ISE EYA GBOLOHUN NIPA ISE WON

Table of Contents

OSE KEJI

EKA ISE – EDE

AKOLE ISE  EYA GBOLOHUN NIPA ISE WON

Gbolohun ni afo ti o kun, to si ni ise to n se nibikibi ti won ba ti je jade.

Gbolohun ni olori iso.

Eya gbolohun nipa ise won

  1. Gbolohun alalaye
  2. Gbolohun Ibeere
  3. Gbolohun ase
  4. Gbolohun ebe
  5. Gbolohun ayisodi

   

Gbolohun alalaye:Eyi ni a fi n se iroyin bi isele tabi nnkan se ri fun elomiran lati gbo. Apeere;

  1. Ebi n pa mi
  2. Tisa lo gba iwe e mi
  1. A ti ri gbogbo won abbl.

 

Gbolohun Ibeere:Eyi ni ona ti a n gba se ibeere nipa lilo atoka asebeere bii, ta ni, ki ni, ba wo, me loo, igba wo, nibo, sebi, abi abbl.

  1. Nje won gba?
  2. Se Ade wa?
  1. Eran meloo lo je?
  2. Ta ni o jale?

 

Gbolohun Ase:    Eyi ni gbolohun ti a fi n pase fun eni ti a n ba soro. Apeere.

  1. Dide duro
  2. E dake jeje
  1. Wa ri mi 

 

Gbolohun Ebe: A n lo gbolohun ebe lati fi bebe fun ohun kan. Apeere

  1. Fun mi ni omi mu
  2. Jowo maa bu mi mo
  1. Bami toju re daa daa

Gbolohun Ayi sodi:Gbolohun yii maa n fihan pe isele kan ko waye. Itunmo re ni beeko. Awon oro atoka gbolohun ayisodi ni; ko, kii, ko i, le

Apeere;

  1. Olu ko le lo
  2. Jide kii se ako igba
  1. Oluko koi ti lo le
  2. Bola ko wa ni ana

 

EKA ISE    ASA

AKOLE ISE    ASA IGBEYAWO NI ILE YORUBA.

Asa Yoruba je okan lara awon asa to se Pataki ni awujo Yoruba. Igbeyawo je asa ti Eledumare pa fun eniyan lati maa bi sii ki a si maa re sii.

Gege bi owe Yoruba ti o wi pe “bi omode ba to loko ni a n fun loko” Omokunrin ni o maa n gbe iyawo, ti a si n fomo obinrin foko ni ile Yoruba.

 

Ilana asa Igbeyawo Ibile.

  1. Eto Ifo jusode:    Eyi ni ohun akoko ti awon obi omokunrin ti o ti to laya yoo se lati ba omo won okunrinwa omo binrin ti o lewa ti o si niwa.’
  2. Alarina:    Eyi ni eni ti yoo maa sotun-sosin laarin awon omokunrin ati omobinrin leyin ti a ba ti se iwadiink,.idile ati iru ebi ti omobinrin naa ti wa.
  3. Ijohen/Isihun:    Ni gba ti omobinrin ba ti gba lati fe odomokunrin ni a n pe ni Ijohen. Leyin eyi ni omokunrin yoo fun omobinrin ni owo akoko ti a n pe ni “Owo Ijohen”
  4. Itoro:    Awon obi ati ebi omokunrin ni yoo lo si ile awon omobinrin lati lo toro re gege bii iyawo afesona fun omo won.
  5. Idana:    Oniruuru ohun ti enu nje bii igo oyin, ogoji isu, obi, orogbo, apo iyo kan, igo oti, aadun, eso lorisirisi aso iro meji, owo idana, ni ebi omo kunrin naa yoo ko lo ile obi omobinrin ti won fe fi se aya fun omo won leyin naa, won a mu ojo igbeyawo.
  6. Ipalemo:    Eyi ni sise eto lori bi ojo igbeyawo yoo se yori si ayo.
  7. Igbeyawo:    Ojo yii gan-an ni eto igbeyawo lekun-un rere. Sise –siso yoo wa nile iyawo ati oko, iyawo yoo maa gba ebun lorisirisi ati owo. Ojo yii gan-an ni iyawo yoo fi a yo, orin ati ekun gba adura lodo awon obi re.

 

ASA IBAALE

Ibaale je asa ti o se Pataki ninu igbeyawo ibile. O je apeere pe iyawo ko tii ni ibasepo kan-kan ri pelu okunrin.

Ti oko ba ba iyawo re nile, yoo gbe paali isana ti o kun fofo, ekun akeegbe emu ati owo ibale ranse si awon obi iyawo re lati fihan pe won to omo won daadaa ati lati fi dupe.

 

PATAKI IBAALE

  1. O je ami iyi ati eye fun iyawo, obi iyawo ati gbogbo ebi iyawo
  2. Ko si ifoya pe iyawo ti ko aarun ibalopo.
  3. O n so ife laarin lokolaya ati ebi po.

 

EKA ISE:    LITIRESO

AKOLE ISE    kika iwe apileko alohun to je mo aseye ti ijoba yan.

 

Igbelewon: 

  • Fun gbolohun loriki
  • Salaye eya gbolohun ede Yoruba
  • Salaye ilana igbeyawo ibile lekun-un-rere

Ise asetilewa: bawo ni asa ibale se ye o si? Ko Pataki ibale meta pere