ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE.

Table of Contents

OSE KESA-AN

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE.

Aroko je ohun ti a ro ti a si se akosile re lori pepa

ILANA FUN KIKO AROKO

  1. yiyan Ori-oro: A ni lati fa ila teere si abe ori-oro ti a n ko aroko le lori
  2. sise ilapa ero: A ni lati ronu jinle ki a si to ero okan wa ni okookan ninu ipinro kookan ki o le ye onkawe
  3. Kiko Aroko:-
  4. Alaroko gbodo ronu ohun ti o ye ki o je ifaara, ko gbodo gun ju
  5. Aarin aroko ni a o ti lo awon ojulowo koko oro bi a se lo won ninu ilapa ero. sipeli akoto ode-oni ni ki a fi ko aroko yii
  6. Ikadii:- eyi ni ipari aroko
  7. Ojulowo ede se pataki ninu aroko bii, Afiwe, akanlo ede abbl , ni akekoo gbodo se amulo.

ORISI AROKO

  1. Aroko atonisona alepejuwe
  2. Aroko asariyanjiyan
  3. Aroko atonisona oniroyin
  4. Aroko onileta
  5. Aroko ajemo – isipaya abbl

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: ISOMOLORUKO II – AWON ORISIRISI ORUKO ABISO AMUTORUNWA ABBL.

Gege bi owe Yoruba ti o wipe “ile la n wo, ki a to so omo loruko” A kii dede fun omo ni oruko ni ile Yoruba, ki won to fun omo loruko, won a se akiyesi iru ipo ti omo wa ni gba ti iya re bii tabi ipo ti ebi wa tabi ojo ati asiko ti a bi omo naa.

A pin oruko jije ni ile Yoruba si isori isori. Awon ni wonyi

  1. Oruko Abiso
  2. Oruko Amutorunwa
  3. Oruko Oriki
  4. Oruko Abiku
  5. Oruko Inagije
  6. Oruko Idile

Oruko Abiso: Eyi ni oruko ti a fun omo ni ibamu pelu iru ipo ti ebi baba tabi iya omo naa wa nigba ti abi

Apeere ati itumo

  1. Fijabi- omo ti a bi ni asiko ti ija wa ninu ebi
  2. Kuponiyi – omo ti a bi leyin iku alafokantan tabi akikanju
  3. Abosede – omo ti a bi lojo ose
  4. Odunjo – omo ti a bi lasiko odun ifa tabi odun miiran abbl

Oruko amutorunwa:- Eyi ni oruko ti a fun omo gege bi ipo ti omo wa ni gba ti iya re bi. Apeere,

  1. Taiwo: Omo ti o koko jade nigba ti a bi ibeji
  2. Kehinde: omo ti o keyin de nigba ti a bi ibeji
  3. Idowu: omo ti a bi tele ibeji
  4. Alaba: omo ti a bi tele idowu
  5. Idogbe: omo ti a bi tele alaba
  6. idoha: omo ti a bi tele idogbe
  7. Olugbodi: omo ti a bi ti oni ika owo tabi ika ese mefa
  8. Ilori: omo ti a bi nigba ti iya re ko se nnkan osun
  9. Omope: omo ti o lo ju osu mesan-an lo ninu iya re ki a to bi.

Oruko oriki: Eyi ni oruko iwuri ti awon Yoruba n fun omo tuntun. Won n lo o lati fi ki ni tabi gbori yin fun eniyan. Apeere,

Adeola, Abefe, Aduke, Adufe, Amoke, Asake, Ayinde, Ariike, Akanni abbl

Oruko Abiku: Eyi ni oruko ti a fun omo ti o je pe bi a se n bi ni o n ku, nigba ti a ba tun bi won pada ti won a tun pada ku. Apeere

Kosoko, kukoyi, durojaye, oruko tan duroriike, bamijokoo, abii na, omotunde, aja, durosimi, kokumo malomo abbl.

Oruko inajije: eyi ni oruko apeje ti ore tabi ebi fi n pe eniyan. O je oruko gbajumo. Apeere,

Ibadiaran, Idileke, Owonifaari, olowojebutu, epolanta, Aponbepore, Awelewa, Ekufunjowo, Eyinmenugun, Dudummadan abbl.

oruko idile: Opo idile ni o maa n fun awon omo ni oruko ni ibamu pelu ipo idile tabi ibamu pelu orisa, ise abinibi ti idile naa n se. apeere,

Idile oloye: Oyebele, Oyediran, Oyewole, Oyekanmi

Idile Oba: Adeooti, Adekanmibi, Adeniyi, Adesola

Idile ola: Oladoye, Oladapo, Olayeni, Olajide

Idile Olorisa: Orisatele, Orisaseye, Orisagbemi, Aborisade

Idile Alawo/Onifa: Faleti, Fabunmi, Fafuke, Fagbohun.

Idile Eleeyin: Olojede, Ojewole, Eeyinjobi

Idile Ede: Oderinde, Odewole, Odeyemi abbl.

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ERE-ONITAN

Litireso apileko ere-onitan ni iwe ere atinude ti onkowe ko lati so ohun ti o sele ninu itan tabi ti o sele loju aye.

Apeere iwe ere-onitan ni “Efusetan Aniwura ti Akinwumi Isola ko

Onkawe ere-onitan gbode mo awon koko wonyi,

  1. O gbodo mo nipa igbesi-aye onkowe
  2. O gbodo mo itan inu iwe naa
  3. O gbodo mo awon eda itan inu iwe naa
  4. O gbodo mo ibudo itan – adugbo tabi ilu ti ere naa ti waye
  5. Onkawe gbodo maa fi oye ba awon isele inu ere-onitan naa lo ni sise-n-tele.
  6. Koko oro-onkawe gbodo mo ohun ti itan naa dale lori , ki o si le toko si ete ti won ri ko.
  7. O gbo mo asa Yoruba ti o suyo
  8. O gbodo mo nipa ihuwasi eda itan
  9. Akekoo gbedo sakiyesi ohun ti o gbadun ninu ere-onitan naa.

Igbelewon:

  • Kin ni aroko?
  • Ko ilana kiko aroko
  • Daruko orisi aroko marunun
  • Fun asa isomoloruko ni oriki
  • Ko orisi oruko jije ni ile Yoruba marun un ki o si salaye pelu apeere
  • Kini litireso apileko ere onitan?
  • Ko awon ohun ti onkawelitireso ere onitan gbodo fi sokan

Ise asetilewa: Ise sise inu Yoruba Akayege JSSone