AWON IRO TI A FI N SE AARO ARA WON
First Term SSS 2 Yoruba |
ILANA ISE SAA KIN-IN-NI
ISE: EDE YORUBA
KLASSI: SS 2
Ose Kinni:
Ede Ankoo ati Ijeyopo Faweli ninu Ede Yoruba.
Asa Eko ile; Imototo, Itoju ara, Ikini, Oro siso.
litireso Itupale Asayan Iwe litireso ati Ajo Waeki yan.
Ose Keji:
Ede- Oro Ayalo
Asa- Igbagbo ati Ero awon Yoruba nipa Oso ati Aje.
litireso- Itupale Asayan Iwe ti Ijoba yan.
Ose Keta:
Ede- Apola ninu Gbolohun Ede Yoruba. Apola Oruko.
Asa- Ipa ti agbara Aje ko ninu Ise ati Iwosan; Ipagidina Iwosan ati Alaafia.
litireso- Kika Iwe Adakedajo.
Ose Kerin:
Ede- Isori Gbolohun Olopo Oro-Ise.
Asa- Egbe Awo.
litireso- Kika Iwe Adakedajo.
Ose Karun-un:
Ede- Awe Gbolohun Ede Yoruba.
Asa Eto Eni si Ogun jije.
litireso- Kika Iwe litireso.
Ose Kefa:
Ede- Oro Aponle
Asa- Ojuse eni ni Awujo: Ire ati Ibi ti o wa ninu Ojuse eni sise.
litireso- Kika Iwe litireso.
Ose Keje:
Ede- Oro Agbaso.
Asa- Eto Iselu Abinibi.
litireso- Kika Iwe Adakejo
Ose Kejo:
Ede- Oro ti Iparoje ti waye; Itupale Oro ti Iparoje ati Aranmo ti waye.
Asa- Igbagbo Elesin Ibile nipa Orisa gege bi Alarina, Alagbawi laarin Eledaa.
litireso- Kika Iwe Adakedajo.
Ose Kesan-an:
Ede Awon Isori Gbolohun Yoruba gege bi Ise won.
Asa- Awon Orisa Ile Yoruba.
litireso- Kika Iwe litireso.
Ose Kewaa:
Ede- Leta Kiko: Orisii Leta, Fifi iyato Leta mejeeji han.
Asa- Awon Orisa Ile Yoruba.
Litireso- Kika Iwe litireso
IWE ITOKASI
- Imo, Ede, Asa Ati litireso. S.Y Adewoyin
- Eto Iro ati Girama fun Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.
- Akojopo Alo Apagbe: Amoo A. (WAEC).
- Oriki Orile Metadinlogbon: Babalola, A (WAEC).
- Iremoje Ere Isipa Ode: Ajuwon B. (WAEC).
- Igbeyin Lalayonta: Ajewole O. (WAEC).
- Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
- Oremi Mi: Aderibigbe, M. (WAEC).
- Egun Ori Ikunle: Lasunkanmi Tela. (NECO)
- Omo Ti A Fise Wo: Ojukorola Oluwadamilare. (NECO).
- Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).
OSE KINNI
ANKOO ATI IJEYOPO FAWELI
AKOONU
Ankoo faweli ni ibasepo ti o n waye laarin awon iro faweli. Oun naa ni a mo si ijeyopo faweli.
Faweli airanmupe le ba faweli airanmupe ko ankoo bee ni faweli airanmupe le ba faweli aranmupe ko ankoo.
Ninu oro onisilebu meji ni a ti maa n toka si ankoo faweli.
F1 – KF2
Ti fi ba je, | F2 gbodo je |
A | a, e, e, i, o o, u, an, in, on, un |
E | e, i, o, u, in |
E | a, e, i, o, u, an, in, on, un, |
I | a, e, e, i, o, o, u, an, in, en, on, un |
O | e, i, o, u, in, un |
O | a, e, i, o, u, an, in, on, un |
Apeere awon oro to fi ankoo faweli han ni:
a: afi, aye, ale, ata, awo, aso, adu, awin, awon, adun
e: eti, ede, ejo, ewu, erin, egun,\
e: ebi, eje, epa, efo, eru, eyin, ewon, ekun
i: igi, ile, ite, iya, iwo, ito, iku,isin, iyen, ibon, itan, ihun
o: odi, ole, owo, oju, ofin, okun
o: oti, ole, oja, oko, ogbin, gbon, orun, odan, omu
Ninu Yoruba ajumolo, faweli “u” kii bere oro afi ninu eka- ede Ijesa, Ekiti abbl. Fun apeere: Usu – Isu.
Ninu Yoruba ajumolo, faweli aranmupe kii bere oro. Bi faweli e/o baje faweli akoko faweli aranmupe en/on ko le wa ni ipo faweli keji, nitori naa awon mejeeji ko le jeyo po ninu oro.
IGBELEWON
Ko oro onisilebu meji mewaa sile, ki o si se ayewo awon faweli to ba ara won kegbe po.
EKO- ILE
AKOONU
EKO ILE: Je ilana eko abinibi ti awon obi fi n ko awon omo won lati kekere. Yoruba ni kekere ni musulumi ti n ko omo re laso. Awon Yoruba ka eko-ile si pupo, won a si maa du u ni gbogbo ona lati ko omo won, ki won si ri i pe omo naa gbeko, nitori won gbagbo pe omo ti a o ba ko ni yoo gbe ile ti a ko ta.
Omo ti a ko ti ko gba ni a n pe ni akoogba. Won gba pe ajoto ni omo ki i se ajoke nikan. Ki i se ojuse obi nikan, ojuse gbogbo ebi ni lati ko omo. Ni ile Yoruba, ni kete ti a ba ti bi omo si aye ni eko ti n bere titi yoo fi dagba bee ni eko ile ko ni opin, eko omobinrin bere lati kekere titi ti yoo fi wo ile-oko.
IMOTOTO : Lati kekere ni awon Yoruba ti n ko omo won ni imototo, won a ti we fun won laaaro, won a fo enu fun won, iwa yii naa ni awon omo maa tele ti a si mo won lara dagba. Yoruba bo won ni imototo bori arun mole bi oye t n bori oru.
IKINI: Je asa ti o se pataki laarin awon Yoruba. Ojuse gbogbo obi si ni lati fi ko omo. Won a ti ko won lati kekere pe bi a ba ti ji laaro kutukutu omode gbodo koko ki awon obi re pe obinrin a kunle, okunrin a si dobale. Ko si igba ti eniyan o ki n ki eniyan. Igba gbogbo ni a maa n ki eniyan koda ti eniyan ba n sun, a maa n ki eniyan wi pe asunji.
‘E ku ikale’ ni a n ki eni to wa ni ijoko.
‘E ku ewu’omo ni a n ki eni to bimo .
‘Mo kota, mo kope’ ni a n ki awon ti n ta ayo.
Gbogbo ikini wonyi ni awon Yoruba fi n ko omo won lati kekere.
ORO SISO: Lati kekere ni awon Yoruba ti maa n to awon omo won sona nipa oro siso, pe kii se gbogbo oro tabi ohun ti a ri ni a n so. Bakan naa, won a to won sona nipa bi a se le ba agbalagba soro lai ni fi enu ko tabi ri agba fin nitori pe eko ile ni atona fun iwa rere. Ti agbalagba ba n soro, omode ki i da si afi ti won ba pe si oro.
Lati kekere naa ni awon Yoruba paapaa julo awon iya yoo ti maa ko awon omobinrin bi a ti n toju ounje ati bi a se n se itoju ile laaaro, ile gbigba ati abo fifo.
LITIRESO
ORIKI ORILE METADINLOGBON
IGBELEWON
- Kin ni eko ile?
- Awon wo ni o n ko omo ni eko ile?
LITIRESO
Kika iran keta ati ikerin Adakedajo.
APAPO IGBELEWON
- Bi faweli keji ninu oro onisilebu meji ti fi ba je i,e,u,o, in ati un
Kin ni F2 yoo je?
- Salaye lekun-un rere iwulo eko ile.
IWE AKATILEWA
Adeboye Babalola et. Iwe Imodotun Yoruba SS2. o.i. 3
Adewoyin S.Y Imo Ede Asa ati LITIRESO SS2 o.i. 156 – 158.
ISE ASETILEWA
- Faweli _____ ni o le ba gbogbo faweli to ku sise papo (a) i (b) e (d) u
- Faweli ____ kii bere oro ninu ede Yoruba (a) I (b) e (d) u
- ___ ni oluko eko ile fun omo (a) Tisa (b) Ore (d) Awon obi ati ebi
- Igba wo ni awon Yoruba ti maa n ko omo ni eko ile? (a) Lati kekere (b) Bi won ba ti to omo odun mewaa (d) Ti won ba dagba
- Omo ti a ko ti o gbeko ni _____ (a) abiiko (b) akoogba (d) alaileko
APA KEJI
- Kin ni eko ile?
- Salaye lekun-un rere bi awon Yoruba se n ko omo ni eko ile.
- Kin ni ankoo faweli?
- Awon faweli wo ni ko le ba ara won kegbe po?
- Se agekuru ohun ti o sele ni iran keta ati ikerin ti. Iwe o ka (Adakedajo).
OSE KEJI
ORO – AYALO
AKOONU
Oro – Ayalo: ni awon oro ajeji ti a maa n ya wonu ede Yoruba lati inu ede miiran tabi ki a so wipe Oro ayalo ni mimu oro lati inu ede kan wo inu ede miiran lona ti pipe ati lilo re yoo fi wa ni ibamu pelu ede ti a mu-un wo. Oro – ayalo maa n mu ki ede dagba. Bakan naa, o maa n je ki oruko wa fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba n sese n wo awujo wa
Yoruba ni ilana meji ti won n gba ya oro wo inu ede Yoruba, awon naa ni
– Ilana afetiya
– Ilana afojuya
ILANA AFETIYA: Eyi ni pipe oro ayalo ni ona to sunmo bi awon elede se n pe oro gan-an:
Bible – Baibu
Peter – Pita
Table – Tebu
Esther – Esita
Deacon – Dikini
Council – Kansu
Al- basal – Alubosa
ILANA AFOJUYA: Eyi ni kiko oro ni ilana eyi to sunmo bi awon elede se n ko.
Soldier – Soja
Table – Tabili
Peter – Peteru
Esther – Esiteri
Bible – Bibeli
Deacon – Diakoni
Paradise – Paradise
Hebrew – Heberu
Inu awon ede wonyii ni a ti n ya oro wo inu ede Yoruba
Ede Geesi
Ede Larubawa
Ede Faranse
BI ORO AYALO SE WONU EDE YORUBA
Eyi ni orisiirisii ona ti oro ayalo gba wonu ede Yoruba.
- Esin:- nipase esin musulumi ati esin Kristi ti won mu wa fun wa ni a se ni awon oro wonyi Mosalasi, Soosi, Alijanna, Angeli Bibeli, Pasito, Kurani abbl
- Ajose Owo:- eyi ni ajose owo laarin Yoruba ati awon eya miiran apeere: senji, korensi, wisiki, buluu
- Eto Oselu:- Nipase ijoba ajeji ti awon larubawa ati Geesi mu wa ni a ti ya opolopo oro bii seria, kootu, sinato, Gomina.
- Asa ati Olaju:- ajumose nipa asa ati olaju mu ki a ya opolopo oro lo apeere: yigi, marede
- Eto Eko:- eyi ni oro ti a ya nipa eto eko apeere: tisa, boodu,
AWON IRO TI A FI N SE AARO ARA WON
- Ki oro ede Geesi ti a ya lo to le di ara oro inu ede Yoruba, o gbodo tele ofin ede Yoruba:
Konsonanti ki i gbeyin oro ninu ede Yoruba. Bi oro ayalo ba ni, a o fi faweli ti o ye seyin re, o le je: i, u, a tabi o, apeere:
Bread – Buredi
Gum – Goomu
Bed – Beedi
Shirt – seeti
fail – Feeli
Glass – Gilaasi
Gold – Goolu
Class – Kilaasi.
- Yiyo konsonanti ipari oro ayalo kuro ap
Mobil – Mobi
Moses – Mose
Jesus – Jesu
Lazarus – Lasaru
iii. Yiya isupo konsonanti oro- ayalo. Fifi faweli ya isupo konsonanti oro ayalo. ap
Bread – Buredi
Milk – Miliiki
Tray – Tiree
Station – Tesan
Belt – Beliiti
- Ifiropo konsonanti ninu oro ayalo nigba miirran konsonanti oro Geesi maa n yato si ti Yoruba ap
Lazarus – Lasaru
Church – Soosi
Queen – Kunyin
Valve – Faafu
Stamp – Sitanbu/Sitanbu
Cup – Koobu/Koopu
- Ami gbodo wa lori oro- ayalo
- Oro ayalo lo maa n bere pelu ami ohun oke
- Faweli aranmupe maa n bere oro ayalo
IWULO ORO AYALO
- Oro ayalo lo maa n mu ki ede dagba.
- Nipa yiya oro lo, a maa n ri oruko fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba sese n wo awujo wa.
IGBELEWON
- a. Kin ni oro ayalo?
- Daruko ona ti a n gba ya oro o.
ASA
IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA OSO ATI AJE
AKOONU
Awon Yoruba gba pe oso ati aje wa, won tile ni igbagbo yii to bee ti o fi je pe o soro lati ri eni ti o ku, yagan tabi ti wahala sele si ti won ko ni so o mo oso ati aje.
Bakan naa awon Yoruba gbagbo pe oso ati aje ni agbara oogun ti won le fi pa eni ti won ba fe. Ewe won gbagbo pe inu ipade aje ni won ti maa n duna- an- dura bi won yoo se pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe ona meji ni okunrin fi n gba oso
– ajogunba
– wiwo egbe oso
bee naa ni ti aje o le je nipa ajogunba
Iyato laarin oso ati aye. Iyato to wa laarin oso ati aje ni pe awon okunrin lo maa n je oso ni gba ti awon aje je obinrin.
LITIRESO
ORIKI ORILE METADINLOGBON
IGBELEWON
- Kin ni igbagbo ati ero awon orile-ede Naijiria ati orile-ede miiran nipa oso ati aje?
- Se agekuru iran karun-un ati ikefa iwe Adakedajo.
APAPO IGBELEWON
- Kin ni igbagbo ati ero awon orile-ede Naijiria ati orile-ede miiran nipa oso ati aje?
- Se agekuru iran karun-un ati ikefa iwe Adakedajo.
IWE AKATILEWA
Adeboye Babalola et al Iwe Imodotun Yoruba SS2. o.i. 3.
Folarin Olatubosun Eto iro ati Girama Yoruba fun Sekondiri Agba. o.i 41
ISE ASETILEWA
- Ona _____________ ni a le gba ya oro wonu ede Yoruba (a) meji (b) meta (d) merin
- A ya faini wonu ede Yoruba nipase (a) eko (b) eto ilera (d) idajo
- A ya Bibeli nipase ilana (a) afetiya (b) afojuya (d) a kosofun wa
- Nje oso ati aje wa bi? (a) beeni (b) beeko (d) a kosofun wa
- Ta ni Kanmi ati Alade fi owo ran? (a) Alaaji (b) Adigun (d) Omo ise re
APA KEJI
- Kin ni oro- ayalo?
- Daruko ede meta ti a ti le ya oro lo
- Daruko ona ti a le gba lati ya oro lo.
- a. Salaye igbagbo ati ero awon Yoruba nipa oso ati aje
- Kin ni ofin yiya oro wonu ede Yoruba.
OSE KETA
APOLA – ORUKO
AKOONU
APOLA ORUKO:- Ni oro tabi akojopo oro to le duro gege bi Oluwa, abo pelu eyan tabi laisi eyan ninu gbolohun. Apeere:
Ile wo
O wa
Awa naa je eba metameta.
IHUN APOLA ORUKO
Apola – oruko le je eyikeyii ninu awon wonyi
Oro-oruko kan soso pere
Oro aropo-oruko
Oro aropo-afarajoruko
Oro – oruko pelu eyan
Oro- oruko pelu awe gbolohun
- Apola-oruko to je oro-oruko kansoso pere. Ap:
Bade se wahala.
Aja pa okete.
Mama fo aso.
- Apola-oruko to je oro aropo-oruko. Ap:
Won sun
Mo ko leta
E gbin in
- Apola-oruko to je oro aropo afarajoruko. Ap:
Oun ni ore mi
Emi yoo lo si Eko.
Awon naa je epa.
4 Apola-oruko to je oro-oruko pelu eyan. Ap:
Iri die wo ile
Baba arugbo ti ku
Abebi egbon Oye we gele.
5 Apola – Oruko to je oro – oruko pelu awe gbolohun. Ap.
Iri wo ile ti a fi ito mo
Oro ti oga so dun
Omo ti o bi gbon.
Iwe ti mo ra po
IGBELEWON
- Kin ni apola-oruko?
- Daruko awon isori oro ti a maa n ba pade ninu apola-oruko.
- Lo meji ninu apeere ninu won.
ASA
IPA TI AGBARA AJE N KO NINU ISE ISEGUN ATI IWOSAN
Ipa ti aje n ko lati mu iwosan ba eniyan ati be won se n pagidina iwosan ti alaafia.
Ipa kekere ko ni awon aje n ko ninu ise isegun ati iwosan ,a o si le fi owo ro won seyin.Bi ara alaisan ko baya,won a gbe lo si odo babalawo fun itoju,ohun to maa koko se nipe yoo se ayewo lati mo boya aisan ara lasan ni tabi o ni owo aye ninu.
Leyin ti o ba ti se ayewo tan,ohun ti o kan ni itoju alaisan sugbon ti apa re ko ba ka a. Boya o ti lo gbogbo oogun ti o mo,ti aisan naa si ko ti ko lo,a lo be awon aje ti o je alatileyin re lowe pe ki won ran oun lowo.
Bi won ba gba, won yoo so ohun ti yoo fi se etutu ti ara re yoo fi ya bakan naa o ni lati san eje fun won bi ara alaisan naa ba ti ya,eyi ni ona ti won n gba ran ise isegun ati iwosan lowo.
BI AWON AJE SE N PAGIDINA IWOSAN
Bi onisegun ba ti mo pe owo aje lo wa lara alaisan, a lo si ajo won tabi ki won paroko ranse sii pe ki o ma toju alaisan naa pe eran agba ni alaisan naa i se
Eyi fihan pe agbara awon aje si wa sibe lori ise iwosan ,won si le pagidina
Iwosan ti o ba wu won
LITIRESO
Kika iran keje ati ikejo ninu iwe Adakedajo
IGBELEWON
- Se agekuru ohun ti o ka ni iran keje ati ikejo.
- Salaye ona ti awon aje n gba pagidina ati ran ise isegun lowo.
IWE AKATILEWA
- Folarin Olatubosun Eto Iro ati Girama Yoruba fun Sekondiri Agba o.i 61-62
- Oyebamiji Mustapha Eko Ede Yoruba Titun S.S2 University Press Oju Iwe 107 -113
- Adakedajo
APAPO IGBELEWON
- Se agekuru ohun ti o ka ni iran keje ati ikejo.
- Salaye ona ti awon aje n gba pagidina ati ran ise isegun lowo.
- a. Kin ni apola-oruko?
- Daruko awon isori oro ti a maa n ba pade ninu apola-oruko.
- Lo meji ni apeere ninu won
ISE ASETILEWA
- E lo si ibi inawo. Apola- oruko inu gbolohun yii ni _____(a) e (b) lo (d) inawo
- Eja ti mo ra ti ro. Apola-oruko inu gbolohun yii ni (a) eja (b) ro (d) eja ti mo ra
- Bola je eba. Bola je (a) apola-ise (b) apola-oruko (d) oro-oruko
- Nje awon aje maa n pagidina iwosan bi? (a) bee ni (b) bee ko (d) ko kan mi.
- Ise ____ ni Kanmi n se (a) agbaleko (b) Kafinta (d) aso riran.
APA KEJI
- a. Kin ni apola-oruko?
- Salaye isori oro ti a le ba pade ninu apola –oruko pelu apeere kookan
- Salaye awon ona ti aje n gba ran ise isegun lowo.
OSE KERIN
ISORI GBOLOHUN OLOPO ORO-ISE
Ko si bi eniyan se le wa ti ko ni se amulo gbohun bi ti wule ki o ri, eeyan gbodo se amulo gbolohun ayafi ti eniyan ba je odi loku. Ki ni gbolohun (sentence)? Gbolohun ni ipede ti o kun, ti o ni itumo, ti o si ni ise ti o n je. Gbolohun ni a fi maa n se agbekale ero okan wa kale. Ara orisii gbolohun ni gbolohn olopo oro ise wa. Gbolohun olopo oro ni gbolohun ti o maa n ni ju eyo oro ise kan lo. Gbolohun yii maa n ni oro ise bi meji, meta, merin tabi ju bee lo. Apeere:
Kunle tete lo pon omi wa.
Ade sare gbe igi wa.
Mo wo o mo si ri.
IGBELEWON
Ki ni gbolohun Olopo Oro Ise?
IWE AKATILEWA
Ayo Bamgbose (1990) Fonoloji ati Girama Yoruba University Press Ibadan Oju iwe 178 & 192
ASA
EGBE AWO
AKOONU
Egbe Awo je ohun ti a se ti a ko fi asiri re han ni. So pe Egbe awo ni egbe ti a da sile ti won n se ipade ti enikeni ko si mo ohun ti won n se nibi ipade naa. Iru egbe bee ti di egbe awo, ti awon omo egbe si fi ibura de ara won pe enikeni ko gbodo tu asiri ohun ti won n se.
ORISII EGBE AWO TI O WA NILE YORUBA
Orisiirisii egbe awo lo wa, opolopo nnkan ni won fi jora iyato diedie lo wa ni aarin won.
- Ogboni Ibile.
- Egbe Ogboni ti a se atunse re si (R. O. F)
- Awo Opa
- Awo to je mo Esin Ibile
- Awo Oso ati Aje
- Egbe Emere ati Abiku
IPA TI AWON EGBE WONYI N KO NINU ETO ISELU.
- Ipa pataki ni awon ogboni n ko ninu eto oselu, awon lo maa n je oludamoran fun awon oba.
- Awon ni alase ilu, owo won ni eto ifobaje wa. Oba gbodo je okan ninu omo egbe.
- Bi Oba ba se, awon ogboni ni ase lati da seria fun-un, bi ese re baju ijiya lo, won le yo/ro kuro loye.
- Owo won ni eto idajo wa nitori pe awon lo n se idajo fun awon arufin ati odaran.
- Awon lo n fi oro gbe awon odaran ti ijiya ese won ba je mo iku.
- Awon lo n se eto isinku oba, olola ati ijoye laarin ilu.
ETO ORO AJE
- Awon ogboni tun ni agbara nipa eto oro aje nitori pe awon ni parakoyi (onisowo pataki). Awon parakoyi yi lo maa n mojuto awon oja to wa laarin ilu.
- Awon lo n ri si idagbasoke owo sise laye atijo.
- Won maa n ran eni ti a je lowo lati ba a gba gbese pada.
ETUTU ILU
- Awon ogboni lo maa n se etutu to le mu ilu tuba-tuse ni pataki julo ti ajakale arun ba wa.
- Awon oye inu egbe awo bi eeyan ba koo darapo mo egbe awon ni pataki ogboni ipeyin tabi omode ni o maa koko wa, sugbon bi o ti n dagba si ninu egbe ni yoo ma ni igbega.
- Iledi tabi ile ogboni ni a n pe ibi ti won maa n se ipade.
- Oye mefa ni o ga ju ninu egbe ogboni, awon ni a mo si “iwarefa” awon naa ni:
Oluwo – ni olori patapata.
Lisa
Asalu
Aro
Apeena
Losi
Lemo
Nlado
Odofin abbl.
IMURA WON
Ona ti awon ogboni n gba mura ni a fi maa n da won mo. Won maa n san aso mo idi, won yoo da bora, won yoo so saki tabi itagbe si ejika otun, leyin naa won yoo de akete fenfe, won yoo maa fi opa tele, won a si wa ileke sorun ati owo.
Awon omo egbe ogboni ka ara won si omo iya, won a si maa huwa omo iya meji si ara won. Idi niyi ti won fi maa n ran ara won lowo.
LITIRESO
IRAN KESAN-AN ATI IKEWAA.
IGBELEWON
- a. Kin ni egbe awo?
- Daruko orisii egbe awo ti o wa.
- Salaye ipa ti won n ko ninu eto iselu, eto oro aje & etutu ilu.
IWE AKATILEWA
Folarin Olatubosun Eto Iro ati Girama Yoruba fun Sekondiri Agba o.i. 75 – 80
Iwe Adakedajo
APAPO IGBELEWON
- Ki ni gbolohun Olopo Oro Ise?
- Kin ni egbe awo?
- Daruko orisii egbe awo ti o wa.
- Salaye ipa ti won n ko ninu eto iselu, eto oro aje & etutu ilu.
- Se alaye perete lori iwe litireso ti o ka.
ISE ASETILEWA
- ____ ni ibi ti awon ogboni ti maa n se ipade (a) Ile egbe (b) Ile ipade (d) iledi.
- ____ ni olori patapata ninu egbe ogboni (a) Apeena (b) Oluwo (d) Lemo
- Awon oye mefa to ga ju ninu ogboni ni a mo si (a) Oloye agba (b) Iwarefa (d)
Oga
- ‘Bola jeun o si yo’ je apeere gbolohun (a) Olopo oro ise (b) alakanpo (d) aijowa 5. O sanra ona ko gba je apeere Gbolohun alakanpo oloro-ise (a) Apaaro (b) onilodisi (d) alaijowa
APA KEJI
- a. Kin ni egbe awo?
- Daruko orisii egbe awo ti o wa
- Salaye ipa/isemeta ti awon egbe Ogboni n ko ni ilu
- a. Kin ni gbolohun olopo oro-ise?
- Daruko awon isori gbolohun olopo oro-ise
- Salaye meji ninu won pelu apeere meji fun ikookan.
OSE KERIN
ISORI GBOLOHUN OLOPO ORO-ISE
AKOONU
Gbolohun Olopo Oro- ise ni gbolohun ti o maa n ni ju oro-ise kan lo, o le je meji meta tabi ju bee lo. Gbolohun olopo oro-ise naa ni a mo si gbolohun onibo. Apeere:
Mo jeun mo si yo.
Won wo aso, won si wo bata.
Won n rin, won n yan, won si n se oge.
ORISIIRISII GBOLOHUN OLOPO ORO-ISE
Gbolohun olopo oro-ise alakanpo
Gbolohun olopo oro-ise afibo
Gbolohun olopo oro-ise afipase
Gbolohun olopo oro-ise asinpo
GBOLOHUN OLOPO ORO-ISE/ ALAKANPO: a ma n lo awon oro-asopo kan lati so gbolohun eleyo oro-ise po di gbolohun olopo oro-ise akanpo. Awon oro-asopo naa ni sugbon, si bee. Apeere:
Ade jeun o si yo
Mo wa sugbon n ko farahan
Emi ati iwo ni a lo gba ile
GBOLOHUN OLOPO ORO-ISE AFIBO:– eyi ni fifi gbolohun kan bo inu gbolohun miiran. Apeere:
Awon akekoo a sunraki ti oluko ba de.
Ayinde a ko petesi ti owo ba de
Ti owo ba de Ayinde a ko petesi
Ewu ti e wo dara (asapejuwe)
Gbolohun olopo oro-ise afibo asodoruko ‘pe’ ni atoka gbolohun yii ap
Mo gba pe olowo lo laye
Pe mo je tete dara
GBOLOHUN OLOPO ORO-ISE AFIPASE: a maa n fi gbolohun yii pase ni Oro-ise yii le je meji, meta tabi ju bee lo. Ap.
Sare lo jeun.
Gbenu wa sibi.
GBOLOHUN OLOPO ORO-ISE ASINPO : ni a ti ma n sin oro-ise meji tabi ju
bee lo. Ap.
Atanda gbe aso wa ka mi mo ile.
Mo lo ra eran ogunfe lati se.
IWE AKATILEWA
Ayo Bamgbose (1990) Fonoloji ati Girama Yoruba University Press Ibadan Oju iwe 178 & 192
ASA
IGBELEWON
- Kin ni gbolohun olopo oro-ise?
- Ko Isori gbolohun olopo oro-ise merin sile.
- Salaye meji ninu won pelu apeere.
OSE KARUN-UN
AWE GBOLOHUN EDE YORUBA.
Oriki
Olori Awe Gbolohun (Isori Awe Gbolohun)
Awe Gbolohun Afarahe
Orisii Awe Gbolohun Afarahe.
AKOONU
Awe gbolohun je ipede to ni oluwa ati ohun ti oluwa se (oro-ise). O je ipede ti ko ni ju apola-oruko ati apola-ise kookan lo. Apeere:
Femi wa
Sola sun.
Isori Awe Gbolohun
Awe Gbolohun pin si orisii meji: Olori awe gbolohun ati Awe gbolohun Afarahe. Olori awe gbolohun awe gbolohun ti o le da duro ti o si ni itumo kikun.
Olori Awe Gbolohun: Olori awe gbolohun ni awe gbolohun ti o le da duro ti o si ni itumo kikun. Apeere:
Tolu n kawe
Maa foso
Aburo mi wa
Awe Gbolohun Afarahe: ni awe ti ko le da duro funra re ki o si fun wa ni itumo kikun ayafi ti a ba fi kun olori awe gbolohun. Apeere:
Bi ile basu maa wa
Won ti sun ki n to de
Ki n to wa maa gbadura
Awe gbolohun sii le wa ni ibere tabi ipari gbolohun.
ORISII AWE GBOLOHUN AFARAHE
Orisii awe gbolohun afarahe meta ni o wa:
- Awe Gbolohun (afibo afarahe) Asodoruko: ni odidi gbolohun ti a so di oro-oruko. Atoka re ni ‘pe’ ap.
Pe a ba won nile ya mi lenu.
Mo ranti pe n ko til jeun.
- Awe Gbolohun Afarahe Asaponle: ni o maa n pon oro-ise tabi odidi gbolohun. Atoka re ni nigba ti, leyin ti, nitori ti. Apeere:
Mo sun nigba ti ile de.
Tola ke nitori owo re to sonu
Ki n to de won ti pari ise.
iii. Awe Gbolohun Afarahe Asapejuwe: Inu apola-oruko ni awe gbolohun asapejuwe maa n wa. Atoka re ni ‘ti’ap:
Iwe ti mo sese ra ti faya
Ore mi ti mo soro re ti de
Iyawo aare ti a soro re ti de
IGBELEWON
1 a. Kin ni awe gbolohun?
- Salaye lori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe pelu apeere metameta fun ikookan.
IWE AKATILEWA
S.Y Adewoyin (2006) Imo, Ede, Asa ati litireso Yoruba fun Ile-Eko Sekondiri Agba S.S.S. 3 Copromutt (Publishers) Nigeria Limited Oju Iwe 200.
ETO ENI SI OGUN JIJE
- Oriki
- Ohun ti a n je logun
- Ona ti a n gba pin Ogun
- Opo Sisu ati Omo Ajemogun
- Ire ati Ibi to ro mo Ogun Pipin
- Iyato laarin Ogun Iya ati Baba
AKOONU
Ogun ni gbogbo dukia ti oloogbe fi sile fun omo ati awon ebi. Adura gbogbo obi ni pe ki won ri omo rere gbeyin won.
Oro ogun pipin yii gbelege pupo ni pataki julo, ogun baba lo gbelege julo nitori opolopo iyawo ti won maa n ni laye atijo. Baba – n – sinku ni o ni ase lori isinku ati ogun pipin
Awon ohun ti won maa n pin logun. Gbogbo ohun ti oku ni ni dukia. Bii
- Ile
- Ile
- Oko
- Iso
- Iyawo
Gbogbo awon nnkan wonyi ni won maa n pin logun. Obinrin (Iyawo) ti oku fi sile naa ni a le su lopo fun aburo tabi molebi oku ti o ba kan-an gbongbon.
ONA TI A N GBA PIN OGUN
Ona meji ni won n gba pin ogun ni aye atijo. i. ori –o- jori ati ii.idi igi.
ORI- O-JORI -: eyi tumo si pe ogun ti oloogbe ba fi sile ni won yoo pin ni deede fun gbogbo omo ti o bi.
IDI IGI-: bi oku ba ku laye atijo, ti o si ni iyawo pupo. Idi igi ni won fi maa n pin ogun bee. Iyawo to bi omo kan ati olomo mejo ogun kan naa ni won yoo pin fun awon mejeeji. Ireje maa n wa ninu ogun pipun. idi niyi ti ogun baba si fi lewu pupo nitori pe inu olomo mejo ko le dun si ogun ti won pin fun-un, koda won maa n se orogun si ara won lori ogun.
Iyato laarin ogun iya ati baba. Ogun iya lo fi okan bale julo nitori pe ko si orogun ninu ogun iya. idi niyi ti won fi n paa lowe pe – “Gbede bi ogun iya, anini lara ba ogun baba”.
IGBELEWON
1a Kin ni ogun pinpin
- Daruko awon ohun ti a n je logun.
APAPO IGBELEWON
- Kin ni awe gbolohun
- Salaye lori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe pelu apeere metameta fun ikookan.
- Kin ni ogun pinpin
- Daruko awon ohun ti a n je logun.
IWE AKATILEWA
Imo Ede Asa ati litireso SS3 o.i 200-203
Adakedajo
ISE ASETILEWA
- Atoka awe gbolohun asodoruko ni (a) pe (b) iba (d) si
- Ninu bi emi ba wa, ireti n be. Ireti n be je (a) awe-gbolohun afarahe (b) Olori awe gbolohun (d) awe-gbolohun asaponle
- ____ maa n duro bi gbolohun (a) awe-gbolohun afarahe (b) Olori awe gbolohun (d) awe-gbolohun asodoruko
- Ogun ______ lo maa n rorun ju (a) Iya (b) baba (d) baba ati iya
- Ona _____ ni a maa n gba pin ogun (a) kan (b) meji (d) meta
APA KEJI
- a. Kin ni awe-gbolohun?
- Salaye orisii awe-gbolohun ti o wa pelu apeere mejimeji fun ikookan.
- a. Kin ni ogun pipin
- Daruko awon ohun ti a n pin gege bi ogun.
- Kin ni ire ati ibi ti o wa ninu ogun pinpin?
OSE KEFA
ORO – APONLE
AKOONU
Oro-Aponle je oro ti o maa n pon oro-ise ninu gbolohun. O maa n se afikun itumo fun apola-ise, ti yoo si je ki itumo re si tubo ye ni yekeyeke.
Tobi jeun die
Bolu n rin kanmokanmo bo.
Irufe oro-aponle inu ede Yoruba pin si orisii meji. Awon naa ni:-
Awon oro-aponle aiseda.
Awon oro-aponle aseda.
1 ORO APONLE AISEDA ni oro-aponle ti a ko seda. Iru oro yii kii ni ju silebu kan tabi meji lo. Awon ni fio, kia, gan-an logan.
O lo logan.
Ile naa ga fio.
- ORO-APONLE ASEDA:- ni oro-aponle ti a seda lati ara oro-aponle nipa sise apetunpe oro-aponle ponbele. Apeere:
Kia + Kia = Kiakia
Wadu + Wadu = waduwadu
Pele + pele = pelepele
Jan + jan = Janjan
Kele + kele = kelekele
Tobi n laagun yoboyobo
Kunle n lo ile kiakia.
Ajumorin Oro-Ise ati oro aponle. Awon oro-ise kan wa to je pe won ni oro-aponle ti won maa n ba rin.
Oro – Ise Oro – Aponle
Pon rakorako, foo, wee
Re dodo
Yo kelekele
Ga fiofio, gelemo, gelete
Rin gbendeke, janjan, diedie
Mole rokoso, kedere
Laagun yobo, sinkin
Funfun gboo, pin-in , balau, sese
Mo n laagun yobo
Aso naa funfun gboo
Obe naa ti tan yanyan
Osupa mole rokoso
IGBELEWON
- a. Kin ni oro-aponle?
- Ibo ni o maa n wa ninu ihun gbolohun gbolohun.
- Pelu apeere merin salaye ise ti oro-aponle n se ninu.
IWE AKATILEWA
S.Y Adewoyin (2006) Imo, Ede, Asa ati litireso Yoruba fun Ile-Eko Sekondiri Agba S.S.S. 3 Copromutt (Publishers) Nigeria Limited Oju Iwe 163.
ASA
OJUSE ENI NI AWUJO
OJUSE: ni ohun ti a n reti ki enikookan se fun ilosiwaju awujo re. Gege bi ara ilu, a ni ojuse ti a ni lati se fun awujo wa.
- Akoko ni pe gege bi omo ilu, ti o ni ife ilu re, a gbodo pa ofin ilu wa tabi awujo wa mo fun alaafia ati ilosiwaju awujo wa.
- Ojuse wa ni lati san owo ori wa. Eyi a le je ki awon ijoba ri owo lati le pese iwosan, omi, eko ofe, ina, oju ona to dara fun wa. Bi a ba ko lati se ojuse wa, awon ijoba naa yoo ko lati se ohun to to fun wa.
- Ojuse wa ni lati lowo ninu ise ajumose ilu bii yiye ona, tite afara, abbl. Fun idagbasoke ilu tabi awujo wa.
- Bakan naa, ojuse wa ni lati je olooto nibikibi ti a ba wa, ki won si le gba eri wa je.
- Ojuse wa ni lati je asoju rere fun ilu awujo ati orile ede.
lapapo, ki a mase ba oruko ilu wa je. Ibi ti a ti le se ojuse wa ni ni ibikibi ti a ba ti ba ara wa. O bere lati inu ile wa, laarin ebi, egbe, lodo ara adugbo, alabaagbe, ilu, ati ni awujo lapapo.
Ire inu Ojuse
Opolopo anfaani ni o wa ninu ki eeyan maa se ojuse re.
Ti eeyan ba n se ojuse re, eyi a fi han pe eni naa je eni ti o wulo
– Ti anfaani tabi aaye kan ba si sile, awon eeyan a ranti iru eni be .
– Iru eni bee a je eni iyi ati eye, awon eeyan a maa pon-on le.
Ibi ti o wa ninu ki Eeyan ma se Ojuse re.
Oju eni ti ko wulo ni awon eeyan a fi maa woo
– Eni ete ni iru eni bee maa je
– A maa na eeyan ni owo
IWE AKATILEWA
S.Y Adewoyin (2006) Imo, Ede, Asa ati litireso Yoruba fun Ile-Eko Sekondiri Agba S.S.S. 3 Copromutt (Publishers) Nigeria Limited Oju Iwe 271.
IGBELEWON
- a. Kin ni ojuse eni ni awujo?
- Daruko ojuse merin ti a le se ni awujo
- Kin ni iwulo ti o wa ninu ojuse sise?
APAPO IGBELEWON
- Kin ni oro-aponle?
- Ibo ni o maa n wa ninu ihun gbolohun?
- Pelu apeere merin salaye ise ti oro-aponle n se ninu.
- Kin ni ojuse eni ni awujo?
- Daruko ojuse merin ti a le se ni awujo
- Kin ni iwulo ti o wa ninu ojuse sise?
IWE AKATILEWA
- Adakedajo – Oladele Sangotoye
- Imo Ede Asa ati LITIRESO Adewoyin S.Y. o.i 163 -168
- Eko Ede Yoruba Titun Oyebamji Mustapha et al. Iwe Keji o.i
ISE ASETILEWA
- _______ ni oro-aponle maa n pon ninu gbolohun (a) Oro-ise (b) Atokun (d) Oro-oruko
- Ninu apola ____ ni a ti maa n ri oro-atokun (a) oruko (b) ise (d) atokun
- Igi agbalumo naa ga fiofio. Oro-aponle inu gbolohun yii ni (a) igi (b) ga (d) fiofio
- ____ ni a ti le se ojuse wa.(a) ni ile (b) ni ile ijosin (d) ni ibi gbogbo
- Okan lara ojuse wa ni awujo ni (a) dida ilu ru (b) sisan owo ori (d) dida ija sile
APA KEJI
- a. Kin ni oro-aponle?
- Lo oro-aponle marun-un ni gbolohun
- a. Kin ni ojuse eni ni awujo?
- Daruko ohun merin ti o je ojuse wa ni awujo.
OSE KEJE
ORO-AGBASO
AKOONU
Oro agbaso:- je siso oro ti a gbo lenu oloro fun elomiran. Iru oro tabi iroyin bee gbodo je eyi to ti koja. Oro agbaso le je ohun ti enikan so nipa wa tabi elomiran. O si le je iroyin ohun to sele nibikan. Oro agbaso naa ni a mo si afo agbaran. Awon wunren atoka oro agbaso ni: so, wi, ni, ki, pase, wi pe, salaye, so fun abbl
Tunde ni oun ko ni wa si ipade.
Sola beere boya a ti jeun
Bi a ba n se agbaso, ayipada maa n de ba oro aropo oruko tabi oro aropo afarajoruko, ti eni to n soro ba lo oro aropo-oruko tabi oro aropo-afarajoruko enikinni ninu oro re – oro aropo –oruko tabi afarajoruko eniketa ni eni to n se agbaso yoo lo. Ap
Mo ri owo he.
Agbaso- O ni oun ri owo he
A ko mo won ri.
Agbaso- Won ni awon ko mo won ri.
Mo fo aso.
Agbaso- O ni oun fo aso.
Atunse maa n sele si oro-oruko. ap
Afo asafo: Eyi ni ki o ra
O pase pe iyen ni ki o ra.
IGBELEWON
Se agbaso ayolo isale yii ni ilana agbaso.
Titi: Emi ni ore baba banile ni aaro yii nigba ti won wa ke si won fun ipade egbe.
Kemi: Nigba wo ni won wa?
Titi: Ni nnkan bi aago mejo aabo ni.
Kemi: Nibo ni mo wa nigba naa ti n ko fi mo igba ti won wole?
Titi: Igba naa ni o lo ra akara fun mama alate.
Kemi: Abajo, ko daju pe won rose, de baba rara nitori n ko pe rara nibi ti won ran mi.
IWE AKATILEWA
S.Y Adewoyin (2006) Imo, Ede, Asa ati litireso Yoruba fun Ile-Eko Sekondiri Agba S.S.S. 3 Copromutt (Publishers) Nigeria Limited Oju Iwe 231.
ASA
ETO ISELU ABINIBI
AKOONU
Eto iselu ni ile Yoruba bere lati inu ile. Gege bi asa, baba ni Olori ile, iya ni atele bee ni awon omo naa ni ojuse bi ojo ori won ba se telera.
Eto agbo-ile ni ipile eto ijoba ni ile Yoruba. Olori agbo-ile ni Baale.
Baale: ni eni ti o ba dagba ju lo ni o n je oye yii. Kii se oye ti a maa n du, ti bale kan ba ku ni eni ti o ba tun dagba ju miiran yoo je.
Baale ni alase ati alakoso agbo ile, ohun ti o ba so ni abe ge. Ko si eni ti o gbodo fi owo pa ida re loju.
Ile maa n to beere ninu agbo ile nla ni won a wa mo ogiri yii gbogbo ile bee ka, ilekun kan yoo wa ni enu ona abawole tabi abajade kuro ninu agbo ile.
Baale kii gbe eyin odi, aarin agbo – ile ni o maa n gbe lati mojuto gbogbo ohun ti o ba n lo.
Igbejo maa n wa ti won maa n jokoo si lati gbo ejo pelu awon agbaagba bii merin. Omo kekere kan yoo maa fe abebe si baba ni ara.
ISE Baale
Ija Pipari ni Agbo-Ile: Ti ede aiyede ba waye, ise baale ni lati yanju re. Totun-tosi yoo ro ejo, ki o to da ejo. Baale lo maa kadii ohun to ba si so ni abe ge.
Fifi Omo Foko: bi omobinrin ile ba fe loko, odede bale ni won yoo ti wure fun-un. Bi iyawo tuntun ba si wole o gbodo de odede baale fun adura.
Imojuto omo ile lokunrin ati lobinrin:O gbodo mo ijade ati iwole awon odo agbo ile.
Ogun Pipin: Odede Baale ni won ti n saato bi won yoo se pin ogun fun awon omo oku ni idi igi kookan.
IYAALE: ni Obinrin ti o dagba ju ni iye odun ti won wo ile oko. Oun ni igbakeji bale ninu eto iselu agbo ile. O je asoju ati alamojuto awon iyawo ile ati omobinrin ile.
Ise re ni lati mo igba ati akoko ti a bi omo lati yanju aawo ti o waye nipa ojo ori.
Oun ni yoo toju iyawo asesegbe oyun inu, omo ikoko ati eto ila kiko fun omo tuntun.
Iyaale gbodo ni imo kikun nipa itan idile, oriki ile oko, ti yoo si maa ko awon atele re gbogbo.
OMOKUNRIN ILE: ni awon gende okunrin ti won ti laya tabi ki won je odo.
Awon ni bale maa n ran ni ise bi ile oku gbigbe, oko ile riro, ona yiye, oju ogun lilo, sisin ibi omo si baluwe abbl. Awon ni won n pa eran nibi inawo. Apa eran ni won maa n fun won. Won maa n wa nibi ti bale ti n pari ija.
OBINRIN ILE: Awon ni iyawo agbo-ile, ojuse won ni lati rogba yi iyaale ka, ki won sa pa ofin re mo.
Awon ni won maa n dana ounje ni akoko odun tabi ayeye. Awon ni won maa n sun rara nibi inawo idile oko won.
Awon lo maa n se itoju iyawo titun ati iyawo ile to ba bimo. Awon lo maa n jora fun iya omo. Awon lo maa n gba eyin eran.
OMO OSU ILE: ni awon agba obinrin ti won ti lo si ile oko, ti won wa pada wa maa gbe ni ile baba won. Won maa n ni enu ninu oro ebi, awon lo maa n gba aya eran ti won ba pa.
OMOBINRIN ILE: ni awon omobinrin ti ko tii lo si ile oko. Won maa n kopa ninu oro ile. Ojuse won ni lati lo ki iyawo ile to ba bimo.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S. Y. Imo Ede, Asa Ati LITIRESO. SS 2 Copromutt (Puplishers) Nigeria Limited Oju Iwe 161 – 164.
IGBELEWON
Salaye ipa ti Iyaale ile ati obinrin ile n ko ninu eto isakoso agbo ile.
LITIRESO
Kika Iwe Adakedajo
Adakedajo – Oladele Sangotoye
APAPO IGBELEWON
- Salaye ipa ti Iyaale ile ati obinrin ile n ko ninu eto isakoso agbo ile.
- Ki ni oro agbaso?
ISE ASETILEWA
- Yi afo asafo yii si oro agbaso, Tope: A ti gba ominira. (a) Tope ni awon ti gba
ominira. (b) Tope ni “A ti gba ominira’’ (d) Tope ni a ti gba ominira
- ——- ni olori patapata ni aye atijo ninu eto iselu abinibi
(a) Oba (b) Bale (d) Iyaale ile,
- ——- lo maa n yanju aawo lori ojo ori awon omo ile
(a) bale (b) Iya (d) Iyaale ile
- Eewo ni Bale ko gbodo gbe?
(a) Inu ile (b) rin irin-ajo (d) eyin odi
- Awon ——– lo maa n gba aya eran.
(a) iyawo ile (b) okunrin ile (d) omo osu ile
APA KEJI
- Salaye ipa ti omokunrin ile ati iyaale ile n ko ninu eto ti o ba waye nipa isakoso agbo ile.
- Yi afo asafo yii si afo agbaran (agbaso) Oro
Ebora buburu naa ni, “Mo mo pe eyin ode alaigboran wonyi ti ko aso mi ni abe igi obi ti mo ko o si. E tun pa ewure kansoso ti mo gbekele. Dajudaju, e ti gbe ebo yin koja orita, bee ni e si ti gun igi rekoja ewe. N o wo ibi ti e o gba koja lonii laije pe e da aso ati ewure mi pada fun mi.
OSE KEJO
IPAROJE/IPAROJE
AKOONU
Iparoje: ni fifo awon iro tabi siso awon iro nu nigba ti a ba n yara soro. Ti a ba n yara soro, a maa n pa awon iro kan je, awon iro ti a maa n paje ni:
- Iro konsonanti
- Faweli ati ohun
- Apapo konsonanti, fawli ati ohun ninu oro
Nibi ti a ba ti pa iro je, alafo yoo wa nibe, a o wa pa iro mejeeji po di eyokan. Pipapo apa oro eyo kan ni a mo si isunki.
IPAROJE/ISUNKI
Se ise = S ( ‘ ) ise = sise (faweli ‘e’ ni a paje)
Adiye = adi ( ) e adie (kons y ni a paje)
IPAJE KONSONANTI
Opolopo iro Konsonanti ede Yoruba ni a le paje ninu afo. Eyi ni awon eyo oro ti a ti pa konsonanti je ni ikookan ati ayorisi ipaje
Oro | Iro ti a paye | Abajade ipaje (isunki) |
Ebibi Daradara Olorun Kehinde Gbolohun Olele Ajayi Adiye Jowo | (eibi) b r r ‘h’ ‘h’ l y y w | Eebi Daadaa Oloun Keinde Gboloun Oole Ajai Adie Joo |
Omoluabi Adura Ekuro Akara Dara Akitan | w r r r r r | Omoluabi Adua Ekuo Akaa Daa Aatan |
Itupale oro ti iparoje ati aranmo ti waye
Eyi ni awon oro ti iparoje ati aranmo ti waye laaarin faweli.
Eyo oro konsonanti ti a paje Aranmo laarin faweli Isunki
Bawo bao (w) “a” ati “o” boo
Egbewa egbaa (w) “e” ati “a” egbaa
siwaju siaju (w) “i” ati “a” saaju
otito Oito (t) “o” ati “i” ooto
akike aike (k) “a” ati “i” aake
orirun oirun “o” ati “i” oorun
alila aila “a” ati “i” aala
oyiya oiya “o” ati “i” ooya
edidu eidu “e” ati “i” eedu
otutu outu “o” ati “u” ootu
okankan oankan “o” ati an ookan
efinfin eifin “e” ati in eefin
egungun eungun “e” ati un eegun
Apejuwe bi isunki se waye
- A koko pa konsonanti je ninu oro: ‘bawo’ _ bao (w)
- Aranmo waye laarin faweli meji to saaju ‘a ati o” = bao
- Abajade ni boo.
IGBELEWON
Se apejuwe bi ipaje ati aranmo se waye ninu awon oro yii:
Edidu, owuro, akike.
ASA
Igbagbo Elesin Ibile Nipa Orisa Gege Bi Alarina Alagbawi Laarin Eledaa
AKOONU
Ni aye atijo lati ibere pepe awon baba-nla wa gbago pe Olorun wa, won gbagbo pe oun ni o da awon ati ohun gbogbo ti o wa ninu aye. Won gbagbo pe oun ni o ga ju, ti o si ju gbogbo eda lo. Igbagbo yii maa n han ninu awon oro won ati orisiirisii oruko won fun Olorun. Apeere:
Eledaa
Asedaa
Oyigiyigi
Alapa-n-la-to-so – ile-aye – ro
Awimayehun
Adigun Aro, baba mehaya
Kabiesi
Olodumare
Esin ibile ni awon baba-nla wa n sin ni aye atijo. Esin ibile bii Sango , Ogun, Oya, Oro, Egungun abbl. Awon orisa ti won n sin yii ni won ri gege bi alarina tabi alagbawi laarin won ati Olorun. Awon baba-nla wa gbagbo pe awon o le ba Olorun soro taara, afi ti won ba lo ba awon orisa wonyi ti won si ran –an si Olorun gege bi alarina ti yoo ba won gbe edun okan won lo si iwaju Olorun.
Gege bi apeere bi ojo ko ba ro, won yoo rubo si ogun tabi orisa oko, ebo yii ni won gbagbo pe awon orisa yii yoo gbe lo si iwaju Olodumare ti ojo yoo sir o.
Nitori naa, awon baba-nla wa ni esin, won kii sii se abogibope, ona ti won n gba sin Olorun won lo yato.
IGBELEWON
- Ko orissii orisa ile Yoruba marun-un sile.
- Ko idi meji awon Yoruba fin sin awon orisa wonyi.
IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun oju iwe 198-204 University Press.
LITIRESO
ITUPALE IWE ADAKEDAJO
- Awon Eda Itan
- Asa Yoruba ti o je yo.
- Eko ti a ri ko.
- Isowolo-Ede Onkowe.
IGBELEWON
- Ko eda itan marun-un sile ninu iwe ‘ADAKEDAJO’
- Ko asa Yoruba marun-un ti o jeyo ninu iwe naa.
- Eko wo ni a ri ko ninu iwe naa? Ko meji sile.
- Ko ona ede meji ti o jeyo ninu iwe naa sile.
IWE AKATILEWA
S.Y dewoyin (2006) Imo, Ede, Asa ati litireso Yoruba fun Ile Eko Sekondiri Agba S.S.S 3 Copromutt Publishers Nigeria Limited Oju Iwe 334
APAPO IGBELEWON
- Kin ni iparoje? b. Nibo ni iparoje ti n waye?
- Ko orissii orisa ile Yoruba marun-un sile.
- Ko idi meji ti awon Yoruba fin sin awon orisa wonyi.
- Ko eda itan marun-un sile ninu iwe ‘ADAKEDAJO’ ki o si salaye ipa ti eni kookan ko
ninu iwe naa.
IWE AKATILEWA
Eto iro ati Girama Yoruba fun Sekondari Agba. Folarin Olatubosun o.i 37 – 39
Adakedajo
ISE ASETILEWA
- ____ ni pipa iro je nigba ti a ba n sare soro (a) Isunki (b) Aranmo (d) Ipaje
- Ebibi di eibi nipa pipa iro ____ je (a) i (b) b (d) e
- Abogibope ni awon Yoruba? (a) Bee ni (b) bee ko (d) A ko mo
- Awon Yoruba ni awon orisa gege bi _____ (a) Olorun (b) alagbawi (d) alagbara
- Meloo ni awon omo oga olopaa ti Bobu ati awon egbe re fi majele sinu bisikiiti fun? (a) meji
(b) meta (d) merin
APA KEJI
- ‘Abogibope ni awon Yoruba’ Pelu alaye lekun-un-rere so si gbolohun oke yii.
- Se apejuwe bi isunki se waye ninu awon oro wonyi.
otutu, egungun, siwaju, epipo oyiya.
OSE KESAN-AN
AWON ISORI GBOLOHUN YORUBA GEGE BI ISE WON.
Gbólóhùn ni ìpèdè tí ó kún, tí o sí ní ìse tí ó ń jé. Gbólóhùn jé ìsọ tí ó ní ìtumo kíkún. A fún àwon gbólóhùn Yorùbá ní orúkọ gégé bí íse tí won ń se. Àpẹẹrẹ:
Bólú je èbà
Bàbá kọ ebè
Èyà gbólóhùn. Orisiirisii ni awon eya gbolohun ti o wa ninu ede Yoruba.
Gbólóhùn Eleyo oro-ise
Gbólóhùn Olopo oro-ise
Gbólóhùn Ibeere
Gbólóhùn Ase
Gbólóhùn Alaye
Gbólóhùn Akiyesi alatenumo
Gbólóhùn Kan
Gbólóhùn lyisodi
Gbólóhùn Asodoruko
Gbólóhùn Eleyo Oro-Ise-: ni gbolohun ti o maa n ni eyo oro ise kan
Apola oro oruko ati apola oro ise ni o maa n wa ninu gbolohun eleyo oro-lse. Apeere:
Baba te eba
Apola oro-oruko Apola oro-ise
Olu sun
Mo ra eran
Tisa na Titi
Gbólóhùn Olopo Oro-Ise-: eyi ni gbolohun ti o maa n ni ju oro-ise kan lo. Oro ise inu gbolohun yii le je meji, meta tabi ju bee lo. Iye oro ise ti o ba wa ninu gbólóhùn yii ni iye gbolohun ti a le ri fayo ninu re. Apeere:
– Omo naa gba ile baba mo tonitoni.
– Omo naa gba ile baba
– Ile baba mo tonitoni.
– Bolu sare lo ra aso.
– Mama lo ra eran wa.
Gbólóhùn –Ase:- ni a maa n lo lati pase. Apeere
Wa
Jade
Dake
Lo pon omi wa.
Gbólóhùn lbeere-: ni a maa n lo lati se lbeere tabi wadii nnkan ni orisiirisii ona nipa lilo wunren lbeere bii: ki ni, ni elo, nibo, tani, meloo, nigba wo. A si maa n lo ami ibeere (?) fun irufe gbolohun yii.
Kin ni oruko re?
Nibo ni o n lo?
Elo ni o ra iwe yii?
Tola da ?
Se Olu ti wa?
Gbólóhùn Kani-: ni a fi maa n so wulewule bi nnkan se ri ati idi ti o fi ri bee. Apeere:
Bi mo ba lowo, maa kole.
Kaka ki n jale, maa seru.
Bi Bolu ba ro bee yoo jeko.
Gbólóhùn Akiyesi/Alatenumo-: ni a fi n pe akiyesi si apa kan koko inu odidi gbólóhùn. ‘Ni’ ni atoka gbolohun yii . A le se atenumo fun oluwa ,abo tabi oro-ise. Apeere:
Mo ra iwe
Iwe ni mo ra (abo)
Rira ni mo ra iwe (oro-ise)
Emi ni mo ra iwe (oluwa).
Gbolohun Iyisodi-: ni a fi n ko isele. ‘ko, kii’ ni atoka/wuren gbolohun yii. Apeere
Bolu ko jeun
Baba ko yo.
Se o maa lo?
N ko lo.
Bolu ti de?
Ko tii de
IGBELEWON
Kin ni gbolohun?
Salaye eya gbolohun marun-un pelu apeere kookan.
IWE AKATILEWA
S.Y dewoyin (2006) Imo, Ede, Asa ati litireso Yoruba fun Ile Eko Sekondiri Agba S.S.S 3 Copromutt Publishers Nigeria Limited Oju Iwe 211.
AWON ORISA ILE YORUBA
Ogun: Orisiirisii itan ni a gbo nipa ogun. Itan kan so fun wa pe ogun je okan ninu awon orisa to fi okun tabi ewon ro wa sile lati orun. A gbo pe iranse Olodumare ni awon orisa to fi ewon ro wa. Awon orisa naa ni Obatala, Orunmila, Esu ati ogun.
Itan naa fi ye wa pe ogun nikan lo ni ada irin lowo, ada ide lo wa lowo obatala, ogun wa ni bi won ba ti gba ki oun se olori, pe oun yoo fi ada irin oun la ona fun won won si gba pe ki o je olori tabi asiwaju. O si fi ada re la ona, idi niyi ti won fi n pe ogun ni ‘Osin imole’ eyi ni pe oun ni olori awon imole.
Okookan awon orisa to fi ewon ro wa si ile aye yii lo ni ise ti won wa se ni ile aye.
Itan miiran so pe eniyan ni ogun tele pe nigba ti o ku tan ni won so o di orisa akunlebo nitori agbara-oto ti o ni nigba ti o wa ni ile aye.
A gbo pe ile-ife ni o koko gbe sugbon o si lo si ire, a gbo pe ode ni ogun, oloogun ati akoni ni, o si je oninufufu. Ogun feran emu nigba aye re, kii gbe aarin awon eniyan, inu igbo lori oke kan lebaa ire lo n gbe, nitori naa ni won se n pe e ni ‘Ogun Onire’. O feran esunsun isu ati ewa agan. Mariwo ni aso re. Ninu oriki re, eeyan lile ati akoni eniyan ni. Awon to n fi irin – ode, alagbede, Onimoto, oloola abbl sise ni olusin ogun won si gbagbo pe bi won ba n bo o, ti won si n se aponle re yoo maa daabobo won, yoo si maa je ki won ri eran pa.
Awon ohun ti won fi n bo o gun ni Ibon, ada, obe, ida, epo pupa, eje aja abbl. Won maa n ni ojubo ogun ni ita gbangba ni agboole awon ologun-un. Awon olusin ogun a maa je oruko mo ogun bii-Oguntade, Ogunleke, Ogunsola, Oderinde, Odedele abbl.
Ni asiko odun ogun awon olusin re maa n toro omo, owo, alaafia abbl
Ibi gbogbo ni won ti n bo ogun ni ile Yoruba. Ohun ti a fi n bo ogun ni-aja, ewa, isu sisun, emu, obi ati gbogbo ohun ti enu n je.
Ni akoko ojo ti ounje po ni won maa n bo ogun. Ilu agere ati dundun ni ilu ogun. Awon eewo ogun ni pe:
Ode ko gbodo bura eke
Ode ko gbodo jale
Won ko gbodo se agbere pelu iyawo ode egbe re.
Ode ko gbodo ji eran ode egbe re.
Won gbagbo pe eni to ba se okan ninu awon eewo naa yoo ri ija ogun.
IMURA WON
Eha (gberi ode) ni ewu ti awon ode maa n wo, apo maa n wa ninu ewu yii ninu eyi ni won ma gbe eran ti won ba pa si, ti ko si tobi pupo. Won maa n fi ajura le ejika otun won, ajura yii ni won fi n le kokoro tin-in-tin-in to maa n je won ninu igbo ode.
Awon ewi atenudenu ti a n lo fun ogun ni – Ijala, iremoje.
Won maa n sun ijala nigba ti won ba n sipa fun ode elegbe won to ti papoda. O si maa n kun fun oriki ogun.
Ogun lakaaye, osin mole
Olomi nile feje we
Olaso nile fimokimo bora
Ojo ogun n ti ori oke bo
Aso ina lo mu bora
Ewu eje lo wo
Orisa ti yoo se bi ogun ko si mo
Bi ko soni re, a o roko
Bi ko sonire, a ko yena.
ESU TABI ELEGBARA
Okan pataki lara awon orisa abalaye ni Esu je, a gbo pe o wa lara awon iranse Olodumare to fi ewon ro wale aye lati orun. Alase pataki ni Esu laarin awon orisa iyoku.
O dabi oga olopaa patapata ti o maa n mu awon to ba ru ofin Olodumare ati awon to n te awon orisa iyoku loju nipa aisooto ati airubo deede.
Gege bi oga Olopaa, ise re ni lati rii pe omo araye gba oro Olorun ti orunmila so. Eni ti ko ba si mu ase Olodumare se. Esu ni yoo je iru eni bee niya fun aigboran re.
Orunmila ati Esu jo je alajosise po nitori pe oun lo n wa ounje fun Esu. O ni agbara lati da ise Orunmila ru. Orunmila ati awon orisa miiran lo n da ebo eniyan. Esu ni yoo rii pe oluware ru u, oun ni yoo si gbe ebo naa lo sorun. Ninu gbogbo ebo, Esu gbodo gba ipin tire nibe.
Ni gbogbo ile Yoruba naa ni won ti n bo Esu, igba ti o ba wu won ni won maa n boo ni ilu kookan.
Aarin gbungbun ilu tabi ileto ni won maa n ko ile Esu si gege bi ojubo, ki oju re le maa to gbogbo ohun ti o n lo. Okuta yangi ni ami ojubo Esu ti epo a si maa rin gbindin ni ori re tabi ere Esu ti ipako re a gun sobolo seyin, amo dudu ni won fi n kun-un nitori pe o burewa. O si feran epo pupo, adi ati omi gbigbona ni eewo re. Esu je ika, o ni ife lati maa ba ohun ti o dara je. Inu re kii dun si ibi ti alaafia ba wa. A maa fa idarudapo, o maa n da aarin ore meji, oko ati aya ru.
Esu korira iwa ole ati omugo. Esu Yoruba yato si Satani tabi Aseetani ti inu Bibeli ati Kurani. Esu ti Yoruba maa n se buburu, se rere. O maa n fun awon eniyan ni omo. Awon to n sin Esu gbagbo pe o ni agbara lati fun obinrin to ba yagan ni omo. Iru omo bee ni Esubiyii, Esubunmi, Esufunke abbl.
Ohun ti won fi n bo Esu ni adiye, obuko, obi ati awon ohun miiran ti enu n je. Ilu dundun ni won maa n lo fun-un. Ewi atenudenu ti won n lo fun un ni rara ati esu pipe.
IGBELEWON
- Salaye ajosepo to wa laarin Ifa ati Esu.
- Ni soki salaye ohun ti o mo ni pa orisa Ogun.
IWE AKATILEWA
Ijinle Ede at litireso Yoruba, Iwe keta Olu Owolabi et al. o-I 35-43
Adakedajo.
APAPO IGBELEWON
- Kin ni gbolohun?
- Salaye eya gbolohun marun-un pelu apeere kookan.
- Salaye ajosepo to wa laarin Ifa ati Esu.
- Ni soki salaye ohun ti o mo ni pa orisa Ogun.
ISE ASETILEWA
- ‘ni’ je atoka fun gbolohun _____ (a) ibeere (b) akiyesi alatenumo (d) iyisodi
- Kin je wunren ti a n lo fun gbolohun ___ (a) ase (b) alaye (d) ibeere
- ____ ni aso ogun (a) Koriko (b) Imo ope (d) Mariwo
- Ewi atenudenu ti a n lo fun orisa Ogun ni _____ (a) ijala (b) rara (d) orin arungbe
- Eewo Esu ni ____ (a) adi gbigbona (b) adi (d) epo
APA KEJI
- a. Kin ni gbolohun?
- Daruko isori gbolohun marun-un. Salaye meta ninu won pelu apeere.
- Ni soki salaye itan Ogun ati Esu.
- Kin ni a fi n bo won?
- Kin ni eewo won?
OSE KEWAA
LETA KIKO
AKOONU
Orisii leta meji lo wa ninu ede Yoruba, awon naa ni; –
Leta gbefe ati
Leta aigbagbefe.
Leta mejeeji ni o ni eto ati ilana ti a n gba ko won.
LETA GBEFE: ni leta ti a ko si obi, ara, ore, ebi, egbon, aburo tabi si eni ti a mo ri. Ilana leta gbefe ni:
- kiko adiresi eni ti o ko leta eyi le je olooro tabi elebe. Ni owo otun oke leta ni o maa n wa.
- Deeti
- Ibere leta pelu ikini ibere. Apeere: Tunji mi tooto, Aunti mi, Baba mi owon, Mama mi owon. Ikini ni o maa n bere leta. A le wi pe ‘Se alaafia ni o wa ati gbogbo ara ile.
- Inu Leta.
- Ni ipari leta gbefe, a o dagbere fun eni ti a n ko leta si pelu apeere: ‘Ire o’, ‘O digba’, ‘ Tire ni tooto’.
- Oruko eni ti o ko leta ni o maa n gbeyin. Apeere: Kola, Bolu, Tope, Seun.
Ninu leta gbefe aaye wa fun ikini, apara ati awada.
LETA AIGBAGBEFE: Eyi ni leta ti a n ko si ile-ise ijoba bii ile-ise amohun-maworan, ile-ise itewe, Yunifasiti abbl. Ninu leta aigbagbefe eni ti o di ipo kan mu ni a maa n ko leta si ki i se enikan ni pato.
- Ko si pe a n ki ni, sere tabi se awada ninu leta aigbefe. Ibi koko leta ni a maa n lo taara.
- Adiresi meji ni o maa n wa ninu leta aigbagbefe. (adiresi eni ti o ko leta ati eni ti a n ko leta si). A maa n mo ipo eni ti a n ko si. Apeere: Alaga, Akowe, Oga Agba.
- Ori-oro tabi akole maa n wa ninu leta aigbagbefe.
- Inu leta/koko ti a fe bo gan-an ni a gbodo lo taara.
- Ipari leta. ‘Emi ni tiyin’ ni a gbodo fi pari.
- Oruko eni ti o ko leta. Apeere:
LETA AIGBAGBEFE.
12, Adeoti Street,
Oyo state,
23rd May,1996.
The Director,
Iwe Iroyin Yoruba Press,
77,Kadara Street,
Lagos.
Olootu,
IBEERE FUN IPO AKOWE ATEWE.
Koko inu leta.
Emi ni tiyin
Adebisi Raheem.
IGBELEWON
Salaye iyato merin ti o wa laarin leta gbefe ati aigbagbefe.
IWE AKATILEWA
S.Y dewoyin (2006) Imo, Ede, Asa ati litireso Yoruba fun Ile Eko Sekondiri Agba S.S.S 3 Copromutt Publishers Nigeria Limited Oju Iwe 34
ASA
AWON ORISA ILE YORUBA
- Obatala
- Orunmila
AKOONU
Orunmila je okan ninu awon iranse Olodumare ti o ran wa sile aye. Olodumare fun Orunmila ni ogbon, imo ati oye lati wa fi tun ile aye se. Orunmila je okan lara awon orisa ti o fi ewon ro wa saye sugbon oun nikan lo ni agbara lati tun fi ewon goke to Olodumare lo. Orunmila maa n lo sode orun ti o si maa n bo wa sile aye.
Itan miiran fi ye wa pe Orunmila ti gbe ile aye ri fun igba pipe. A gbo pe Ile-ife ni o koko gbe ki o to lo si Ado. Nigba ti o wa laye, o bi omo mejo. Okan ninu awon omo re ti o je abikeyin (olowo) ni o se afojudi si orunmila, o si fi ibinu lo sorun lori ope agunka. Nigba ti o lo tan ni nnkan o ba lo deede mo nile aye. Ni won ba lo pe Orunmila pe ki o pada wa sile aye sugbon Orunmila ko. Nigba ti ebe po ni Orunmila ba fun won ni ekuro merindinlogun. O ni gbogbo ohun ti won ba n fe ki won maa beere lowo ekuro merindinlogun naa. Gbogbo ibeere won yoo si maa ri bi won ti fe.
Ekuro merindinlogun naa lo di Ikin ti awon babalawo fi n difa lonii. Loooto nigba ti won dele aye gbogbo ire ti won n fe lo n te won lowo. Ogbon imo ati oye ti Olodumare fun Orunmila lo so o di okan pataki laarin awon orisa ile Yoruba. Orunmila ni ifa, Ifa naa ni Orunmila. Oriki Ifa:
Ajiginni aringinni
Orunmila Elaasode, Afedefeyo
Omo enikan saka bi agbon
Eiri nile Ado
Orisa ndota
Akoni loro bi iyekan eni
Akere finu sogbon
OHUN – ELO IFA
Ikin merindinlogun, opon ifa, iroke, opele ati ibo
OHUN TI A FI N BO IFA
Ohun ti a fi n bo Ifa ni: Adiye, obi, ewure, eja, eku ati awon ohun tenu n je miiran. Ilu Ipese ati Agogo ni ilu Ifa. Awon to n bo ifa tabi sin-in ni a n pe ni Onifa tabi Babalawo. Olori won ni Oluwo tabi Araba. Ohun ti a fi n da Babalawo mo ni apo Jerugbe (to je apo ifa).
EEWO IFA
Ifa ko ireje, iro pipa, ile dida, agbere sise abbl. Ewi atenudenu ti a n lo fun ifa ni iyere ifa.
IGBELEWON
- a. Kin ni leta gbefe ati aigbagbefe?
- Salaye iyato to wa laarin leta mejeeji .
- Ni soki salaye itan Orunmila
IWE AKATILEWA
Olu Owolabi et al Ijinle Ede ati LITIRESO Yoruba. Iwe keta oju iwe 35 -39
APAPO IGBELEWON
- Ko iya meta ti o wa laarin leta gbefe ati leta aigbefe.
- Kin ni leta gbefe ati aigbagbefe?
- Ni soki, salaye itan Orunmila
ISE ASETILEWA
- Apa ______ ni adiresi akoleta maa n wa (a) Otun loke (b) Osi loke (d) Otun nisale
- ____ lo maa n ni adiresi meji (a) leta gbefe (b) leta aigbafe (d) koro.
- Orunmila bi omo _____ (a) mefa (b) mejo (d) mewaa
- Orunmila fi ekuro _____ ranse si awon omo re pe ki won maa beere ohun ti won ba fe lowo re
(a) merinlelogun (b) merindinlogbon (d) merindinlogbon
- A kii mo ajosepo laarin eni ti o ko leta ninu leta_____ (a) aigbefe (b) gbefe
APA KEJI
- Ko leta si ore re, ki o si salaye fun awon ona ti o n gba lati mura fun idanwo ti o n bo.
- Ni soki salaye awon nnkan wonyi:
Eewo Ifa/Orunmila.
Ohun ti a fi n bo Ifa.