BI AWON AKONI EDA SE DI ORISA AKUNLEBO
Subject : Yoruba
Class : Jss 2
Term : Third Term
Week : Week 3
Topic :
OSE KETA
APOLA-ISE
(verb phrase)
Ninu apola-ise ni koko gbolohun maa n wa. orisiirisii isori oro ni o le jeyo po ninu apola-ise. Apola-ise le je:
- Oro-Ise Alaigbabo.
Iji ja
Mo sun
Iyan naa kan
- Oro-ise ati oro-oruko ni ipo abo. Apeere:
Dolapo ra keke
Mo je akara.
Femi pari idanwo
- Oro-Ise agbabo ati Eyan. (oro aponle). Apeere:
Bola mu oti yo.
Jide gun igi giga fiofio.
Mo rerin-in arintakiti.
- Oro-Ise ati Apola Atokun apeere:
Bola lo si Obilende ni ana.
Mo ti ilekun si ita.
- Eyo Oro-Ise ti o n sise odidi gbolohun. Apeere:
Jade
Jokoo
Dide
IGBELEWON
- Ko apeere Apola-Ise marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.
IWE AKATILEWA
S.Y Adewoyin (2003) SIMPLIFIED YORUBA L1 J.S.S.2 Corpromutt Publishers Nig Lld O. I. 24-25.
BI AWON AKONI EDA SE DI ORISA AKUNLEBO
Ona meji pataki ni a le pin awon orisa ile Yoruba si. Awon orisa kan wa to je pe won ro wa lati orun, orisa ni Olorun da won, won ki i se eniyan nigba kan kan ri. Awon orisa ipin keji ni awon eniyan ti a so di orisa nitori ise ribiribi owo won nigba ti won wa laye. Awon wonyi ki i se orisa lati orun wa. Apeere awon orisa ti won ro wa lati orun ni Obatala, Orumila, Ogun, Esu. Awon ti a so di orisa akunlebo ni yemoja, sango, oya, osun, oba, meremi, orisa oko ati bee bee lo.
MOREMI: Ni asiko kan ti awon igbo n dun mohuru mo awon ara Ile-Ife, Moremi ni o je je lodo Esinminrin pe oun a fi omo oun rubo si i to ba le ba won segun Igbo to n du mo won. Leyin eyi won gbogun ti awon igbo naa won si segun. Eyi lo mu ki won so Moremi di orisa akunlebo leyin iku re.
OGUN( god of iron): Ode ni Ogun ni aye atijo. Tabutu ni oruko iya ogun.Oririnna si ni baba re O je oye Osinmole ni ile Ife, ki o to lo si ilu ire Ekiti. Mariwo ni aso Ogun, eje lo si maa n mu. Gbogbo ohun to je mo irin je ti ogun Ogun korira ki won gbe koronfo agbe emu duro. O tun korira iwa eke, iro pipa, ole jija
SANGO (god of lithning & thunder): je okan lara awon oba to ti je ni Oyo ile laye atijo. Gege bi oba, sango ni agbara, oogun ati igboya, ina si maa n jade lenu re bulabula to ba n soro, Nitori agbara yii o bere si ni si abgbara lo. Awon ilu wa dite mo nitori asilo agbara re. Idi inyii ti o fi lo pokun so nidi igi aayan ni ibi ti won n pe ni koso. Oriki sango lo maa n poju ninu sango pipe won maa nlo lati yin-in lati dupe lowo re bi oba se won loore ati lati be e fun idaabobo, bibo asiri won ati lati beere fun awon nnkan ti won se alaini. Awon nnkan ti sango n lo gege bi agbara ni ose sango, edun ara ati ina to maa n yo lenu re. Iyawo meta ni sango ni nigba aye re, oya, osun ati oba, oya wole ni Ira o si di odo ti a mo si odo oya di oni oloni. Sango korira siga mimu, obi, ewa ati eku ago jije.
IGBELEWON
- Salaye ona meji ti a pin awon orisa ile Yoruba si.
- Ki lo so Moremi di orisa akunlebo.
LITIRESO KIKA IWE APILEKO
APAPPO IGBELEWON
- Ko apeere Apola-Ise marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.
- Salaye ona meji ti a pin awon orisa ile Yoruba si.
- Ki lo so Moremi di orisa akunlebo.
IWE AKATILEWA
Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun University Press oju iwe 198-204
ISE ASETILEWA
- ‘Ade gun keke’ apola ise inu gbolohun yii ni (a) Ade (b) gun (d) gun keke.
- ‘Olu ki i ja’ iru apola yii ni …… (a) oro ise agbabo (b) oro ise alaigbabo (d) ibeere pesije.
- Apola ise odidi gbolohun ni (a) Jade (b) Olu ki i sun (d) Ola n korin lowo.
- Orisa wo ni awon Yoruba gbagbo pe o maa n yo ina lenu ………..(a) sango (b) Moremi (d) ogun.
- Atenumo oro ju eekan lo ninu ewi ni …………. (a) ibeere pesije (b) awitunwi (d) iforodara.
APA KEJI
-
- Ko apeere Apola-Ise marun-un sile pelu apeere metameta yato si eyi ti o wa ninu iwe yii.?
- ko awon orisa meta ti won di orisa akunlebo nipa agbara.
Ko akanlo ede ayaworan merin ninu iwe apileko pelu alaye.