LETA AIGBEFE

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Third  Term

 

Week : Week 6

 

Topic :

 

OSE KEFA

 

EDE

LETA AIGBEFE

Akoonu:

 • Leta aigbefe
 • Igbese kiko leta aigbefe

Leta aigbefe je leta ti ko gbefe rara, ti a n ko si eni ti o wa ni ipo tabi aaye owo. O le je leta iwase, leta ifisun, leta igbaaye lenu ise, leta si ijoba ibile. Igbese meje ni a ni lati tele bi a ba fe ko leta aigbefe. Awon naa ni:

 • Kiko adireesi akoleta
 • Kiko deeti ( ojo, osu ati odun ti a ko leta)
 • Ipo ati adireesi eni ti a ko leta si
 • Ikini ibere leta
 • Akole leta
 • Koko oro inu leta
 • Ipari ati oruko akoleta

Kiko adireesi akoleta: bakana ni eleyi ri pelu leta gbefe.

Kiko deeti: eleyi naa ko fi bee yato si ti leta gbefe. 22/3/2011., 22 Erena, 2011.

Ipo ati adireesi eni ti a ko leta si: apeere iru ipo ati adireesi ni eyi:

 

 

Oga Agba,

Good Shepherd Schools

3, Opopona Bolaji ,

Ebutte Meta ,

Ilu Eko.

Ikini Ibere: Apa owo osi leyi maa n wa bi I ti leta gbefe, sugbon oun ki I fi ipo ti akoleta wa si eni ti a ko leta si han. Apeere: Alagba, Oga, Madaamu, Olootu abbl.

Akole Leta: ibi yii ni akoleta ti maa n ko akole koko idi ti o fi ko leta gan-an. Apeere:

ITORO AAYE LATI MA WA SI SI ILE EKO

TABI

Itoro Aaye Lati Ma Wa Si Ile Eko

Koko Oro Inu Leta: gege bi a ti so pe leta aigbefe ni eyi. Ko si aaye awada ninu iru leta yii. Ibi koko oro ni lo ni kiko taara. Ki a ranti pe abala meta naa ni eyi pin  si  bi I ti leta gbefe: ifaara, aarin ati igunle.

Ipari ati Oruko Akoleta: ni ipari leta ni owo otun ni eyi maa n wa bi i ti leta gbefe sugbon awon oro ti a maa n ko yato si ti leta gbefe. Kotan sibe, akoleta maa n bu owo lu leta aigbefe leyin eyi ni yoo ko oruko re. Apeere:

Emi ni tiyin ni tooto,

 

Ajoke Adeniyi

 

 

 

Emi ni,

 

Adewale Ayuba

 

[the_ad id=”40090″]

IGBELEWON

 1. Ko adireesi ile yin sile pelu deeti
 2. Ko adireesi ijoba ibile re sile
 3. Ko leta lori akole yii sile. Ko leta si oga ile iwe re *lori idi ti o fi wa si ile iwe ni ana.*

IWE AKATIWA

Oyebamji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun (J.S.S.1 )oju iwe 185-190 University Press Plc.

Oyembamji Mustapha (2006) Eko Ede Yoruba Titun (s.s.s 1) iwe kin-in-ni. University Press Plc. Oju iwe 16-17.

 

IGBELEWON

 1. Ko adireesi ile yin sile pelu deeti
 2. Ko adireesi ijoba ibile re sile
 3. Ko leta lori akole yii sile. Ko leta si oga ile iwe re *lori idi ti o fi wa si ile iwe ni ana.*

 

 

 

 

 

[the_ad id=”40090″]

 

ASA

AKORI ISE:                      AWON OHUN MIMO NINU ESIN IBILE

AKOONU

 • AWON ESIN IBILE TABI ESIN ABALAYE
 • AWON OHUN MIMO NINU ESIN IBILE
 • OHUN TI AWON ORISA DURO FUN

Orisiirisii esin ni awon baba nla wa n sin ni aye atijo ki awon oyinbo alawo funfun to mu awon esin igbalode wa saarin awa Yoruba nitori pe won ro pe a ko mo nipa Olorun rara.  Olorun ni a n sin ninu gbogbo esin abalaye tabi esin ibile Yoruba, sugbon ona ti onikaluku n gba sin-in lo yato si ara won.  Ni aye atijo, awon orisa bi i ifa, sango, obatala, esu, oro, egungun, ogun, oya ati bee bee lo ni awon baba wa maa n bo, awon orisa wonyi lo duro gege bi abenugo laarin awa eniyan ati Olorun, Olorun yii si je mimo idi niyi ti a fi maa n pe ni Olorun mimo.  Niwon igba to si je pe Olorun mimo ni a n sin, awon ohun mimo ni ona mimo kole fara sin ninu esin abalaye wa.

Niwon igba to je pe Olorun mimo ni a n sin nipase awon orisa wonyii, ohun mimo akoko ni ojubo awon orisa gbogbo. Mimo ni o gbodo maa wa ni gbogbo igba, ko gbodo si ohun eeri tabi idoti kankan nibe rara, ayika ibe gbodo mo tonitoni.

Eni to duro gege bi oludari tabi asoju awon olusin ni a n pe ni Abore tabi Aworo Orisa, oun paapaa gbodo maa wa ni mimo ninu iwa ati ise re ko ma ba a si idena ninu esin won, nitori oludari ni awon olusin yoo ma fi se awokose.  Oro ti yoo maa jade lenu re paapaa gbodo je rere, idi niyi ti won fi maa n so pe “A kii gbo buburu lenu abore.

Awon ohun elo ti a fi n bo awon orisa paapaa tun je afihan ohun mimo ninu esin abalaye.  Awon ohun elo ti a fi n bo awon orisa yii kii se ohunkohun ti a ba ri tabi awon ohun ti a je ku.  Ti won ba fe bo awon orisa yii, to ba je orisa ti won n fi isu bo ni, iru isu bee gbodo je eyi to dun wo loju.  Fun apeere, omi je okan pataki ninu ohun ti a fi n bo orisa.  Omi yii gbodo je eyi to mo lolo, eni ti yoo pon iru omi bee naa gbodo wa ni mimo, nitori idi eyi ni won se maa  n lo odobinrin to ko tii mo okunrin lati pon iru omi bee tabi obinrin to ti kuro lowo omo bibi ki ohun gbogbo le je mimo. Iru omi bayii ni won n pe ni omi-ajifowuro-pon

Omi ti a ji pon ni aaro kutukutu ni a maa n pon omi ti a ba fe lo nidi orisa nitori omi ajipon la gba pe o je mimo ju nitori enikeni ko ti de odo naa lati ba a je, eni to ba si lo pon-on aso funfun ni o gbodo wo, ko si gbodo soro si enikeni.  Ojoojumo ni won maa n pon iru omi yii.

A tile gba wi pe awa eniyan gbodo wa ni mimo ninu iwa, isesi, oro ati ero wa ki a to le ri oju rere olodumare, nnkan funfun si ni Yoruba saba ma fi n se apeere nnkan mimo.

Ko tan sibe, won maa n lo awon nnkan bi igba funfun, ileke funfun bakan naa ni won maa lo aso funfun. Gbogbo eyi fi iha ti awon Yoruba ko si Olorun han nipe eni mimo ni.

IGBELEWON

 1. Awon nnkan wo loje mimo ninu esin abalaye
 2. Daruko mefa ninu esin ti awon baba nla wa n sin laye atijo
 3. Kini ohun ti a won orisa duro fun larin awa eniyan ati Olorun
 4. Iru awon eniyan wo lo maa n pon omi idi oosa.

 

IWE AKATIWA

Oyebamji Mustapha (2006) Eko Ede Yoruba Titun University Press Plc oju iwe 120-127.

 1. Y Adewoyin (2004) New simplified L1Yoruba iwe keji [J. s. s .2] oju iwe 71-72 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

 

 

[the_ad id=”40091″]

 

 

 

LITIRESO

 

KIKA IWE LITIRESO

 

 

APAPO IGBELEWON

 1. Ko adireesi ile yin sile pelu deeti
 2. Ko adireesi ijoba ibile re sile
 3. Ko leta lori akole yii sile. Ko leta si oga ile iwe re *lori idi ti o fi wa si ile iwe ni ana.*
 4. Awon nnkan wo loje mimo ninu esin abalaye
 5. Daruko mefa ninu esin ti awon baba nla wa n sin laye atijo
 6. Kini ohun ti a won orisa duro fun larin awa eniyan ati Olorun
 7. Iru awon eniyan wo lo maa n pon omi idi oosa.
 8. Salaye ona meji ti a le gba ya ofo yato si oro geere

 

IGBELEWON

 1. Salaye igbeyawo aye ode oni.
 2. Ko iyato merin laarin igbeyawo aye atijo ati aye ode oni.

 

IWE AKATIWA

Oyebamji Mustapha (2006) Eko Ede Yorba Titun University Press Plc oju iwe 50-51.

 

ISE ASETILEWA

 1. Leta …….ni leta iwase. (a) ore (b) gbefe (d) alaigbefe.
 2. Ibi ti adiresi eni ti a n ko leta si maa n wa ni….. (a) isale leta patapata ni apa osi (b) oke leta ni apa otun (d) oke leta ni apa osi
 3. Adiresi eni ti  n ko leta maa n wa ni ….. (a) isale leta  ni apa otun (b) oke leta ni apa osi (d) oke leta ni apa otun.
 4. ______ni ohun mimo akoko ninu esin abalaye. (a) ojubo       (b) ile aworo (d) omi orisa (e)  eni to n pon omi.
 5. Okan ninu awon wonyi lo maa n pon omi orisa. (a) Odomokunrin (b) obinrin to n toju omo lowo (d) Aworo (e) Omobinrin ti ko ti mo okunrin
 6. Idaji ni a maa n pon omi orisa nitori ______ (a) omi bee lo mo ju (b) A ko fe komi tan lodo (d) Aworo feran iru omi bee (e) A ko fe ki o damu lona

APA KEJI

 1. Ko adireesi ile re ati adireesi ijoba ibile re sile.
 2. ko awon mimo meta sile ninu awon ohun mimo esin ibile Yoruba sile.

[the_ad id=”40091″]