Daruko ewi atenudenu merin to je mo esin abalaye pelu awon orisa ti won n fi awon ewi naa bo.

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Second Term

 

Week : Week 2

 

Topic :

EDE: Aroso Alapejuwe (ilana bi a se le ko aroko Yoruba )

ASA: Asa Iranra Eni lowo- Ajo, Esusu, Egbe Alafowosowopo

LIT: Litireso Alohun to je mo Esin Ibile- Iyere Ifa, Iwi, Ijala Iremoje.

 

 

 

OSE KEJI

AROSO ALAPEJUWE

AKOONU: Deeti………………..

 • Itumo.
 • Apeere.

Aroso ni ohun ti a ro lati inu arojinle wa ti a fe ko sile. Orisiirisii aroso lo wa, a ni aroko oniroyin, onileta, alalaye, onisorogbesi, alapejuwe, alariyanjiyan.


AROSO ALAPEJUWE

Eyi je mo sise apejuwe eniyan, ibikan tabi ohun kan lona ti o se pekipeki nnkan naa. Tori a le so wi pe aroso alapejuwe ni aroso ti a fi n se apejuwe eniyan tabi ibi kan(Descriptive essay). Apejuwe wa gbodo fi han pe a mo ohun ti a n soro nipa re. Apeere ori oro aroko alapejuwe ni:-

 • Ile baba mi
 • Oja ilu mi
 • Ore mi ti mo feran ju
 • Ile iwe mi

ILANA AROKO (ILE BABA MI)

Ilu wo ni ile naa wa

Adireesi ibi ti ile naa wa

Bawo ni ile naa se ri ( ile ile/alaja)

Oda wo ni ile naa ni?

Ki ni a koko maa ri ni ile naa

Ojule melo ni ile naa

Nje iyato wa laarin ile yii si omiiran bi?

Ko boya o feran ile naa tabi o ko feran re, salaye

IGBELEWON

1 Ki ni a n pe ni aroko?

2 Orisii aroko melo lo wa?

 1. Salaye aroko alapejuwe
 2. Ko ilana lori aroko “ore mi ti mo feran ju”

ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ

Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji ( J.s.s.2) oju iwe 49-53 Longman Nig Plc.

 

 

Yoruba Taamu Keji 

 

Oruko Amutoorunwa Ni Ile Yoruba

 

Oge  Sise Nile Yoruba 

 

ASA

AKORI ISE: ASA IRANRA – ENI – LOWO. Deeti………………..

Gege bi a ti so saaju tele pe orisiirisii ona ni awon Yoruba maa n gba ran arawon lowo. E je ki a tun gbe awon wonyi wo ninu ona ti awon Yorba maa n gba ran arawon lowo.

Owe: Ise ti o po pupo ti eniyan kan ko le da se funra re bi o ti wu ki o lagbara to ni won n fi owe se, Tokunrin, tobinrin, tomode, tagba ni a n be lowe tori gbogbo won ni o ni ipa ti won o n ko nibe. Iru ise ile kiko ni a maa n be eniyan lowe si. ki i se dandan ki a san owe pada bi aaro ti o je adire irana.

Arokodoko: Eniyan meji, meta lo maa n se iru ise yii, won a sise ninu oko enikan ni oni bi o ba di ojo keji oko enikeji ni won o lo. Bi o ba di ojo keta, won o gba oko eniketa lo lati sise. Bayi ni won o se maa se titi won o fi pari ise.

Ebese: ona iranra eni lowo miiran ti awon Yoruba n gba ran arawon lowo ni ebese. Oun ni ona iranra eni lowo fun inawo ti o n bo lona. Fun apeere ti inawo kan ba ku si dede bi igbeyawo, isomoloruko. Enikan ko le se gbogbo imurasile iru inawo yii. Awon to maa lo ra orisiirisii ounje, awon to maa lo ge igi ni oko bakan naa ni awon ti won yoo se eto omi yoo wa. Gbogbo ona won yii ti a n gba lati ran eniyan lowo fun iru inawo yii ni a n pe ni ebese.

Aaro: Awon ti ojo ori won ko ju ara won lo ni won maa n se aaro. O maa n wopo laarin awon agbe.Won le to mefa, mejo tabi ju bee lo.

IGBELEWON

Ko ona marun-un ti a n gba ra ara wa lowo ki o si salaye won lokookan.

 

 

AWON EWI ALOHUN AJEMESIN ABALAYE

– Iyere Ifa

– Esa Egungun / Iwi

Ijala

 

Ni aye atijo ki awon alawo funfun to mu awon esin igbalode wa saarin awon Yoruba, orisirisi esin ni awon baba nla wa n sin ti awa si jogun ba lowo won. Bi orisii awon esin yii se wa naa ni a ni awon ewi alohun tabi ewi atenudenu ti a n lo fun okookan won. Iyen ni pe oni irufe ewi ti a fi maa n ki awon orisa kookan ti a n sin ni ile Yoruba.

Iyere Ifa: ni orin awon babalawo ti won saba maa n ko ni asiko ti won ba n se odun ifa, sugbon iyere sisun le waye nigba ti babalawo ba n ki ifa lowo tabi ti won ba n se ayeye kan bii etutu ati igba ti won ba fe bo ifa.

Esa Egungun/Iwi: ni ewi alohun ti awon olusin egungun maa n lo nigba ti won ba n se odun egungun. Awon lo maa n je oruko mo oje, awon oruko bii Ojekunle Ojeniyi Ojedele ati bee bee lo. Tako-tabo idile oloje lo le pe esa.

Ijala: awon ode ati awon alagbede ni won n sun ijala ni akoko odunlati fi yin ogun ati lati fi wa oju rere Ogun. Oloye: Oluode, jagun Ode, Abogun, Eleede.

Ounje Ode: aja, iyan, obi, emu, esun isun, akukodie.

Ohun Elo Orin: fere ekutu, ilu dundun, ati agree.

Apeere Ijala ni:

Ogun lakaaye Osinmole

Onile kangun kangun orun

O lomi nile feje we

O laso nile fimokimo bora

Ogun alada meji o fi okan sanko

O fi okan yena ……….

IWE AKATILEWA

S.Y Adewoyin (2003) NEW SIMPLIFIED YORUBA L1 Corpromutt Publishers Oju iwe 12-13.

Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe Keta Oju Iwe 14 – 16.

IGBELEWON

 1. Daruko ewi atenudenu merin to je mo esin abalaye pelu awon orisa ti won n fi awon ewi naa bo.
 2. Salaye lori Oro

APAPO IGBELEWON

 1. Iroyin ti a n so fun eiyan ti a ko t ii so ni?
 2. Ko ewi alohun esin abalaye marun-un sile.
 3. Salaye awon oro yii: owe, ebese, aaro, arokodoko.

Aroko Alarojinle 

 1. Salaye irinajo Oduduwa lati ilu Meka si Ile-Ife.
 2. Ki ni gbolohun? ko apeere merin.

ISE ASETILEWA

 1. ….. je ohun ti a ro ti a ko ti ko sile ni . A. akaye B. gbolohun D. aroko E. aroso.
 2. Iyato laarin aroso ati aroko ni pe a kii ti ….. aroso sile. A. ko B. ro D. wi E. ri
 3. Aroko wa gbodo ……. A. koni logbon B. panilerin D. mu eniyan sun E. je iro pipa
 4. Ewo ninu awon wonyi ni o ni eto ijoba ninu? A. egbe alafowosowopo B. ajo D. esusu E. aaro
 5. Iru eniyan wo lo le se olori elesusu. Eni ti o ba je ….. A. olowo B.ologbon D. olooto E. osise ile ifowopamosi

APA KEJI

1 Salaye esusu ajo

 1. Awon nnkan wo ni a gbodo koko mo bi a ba fe ko aroko?