Third Term SS 1 Lesson Notes Yoruba
ISE-:EDE YORUBA
CLASS: SS1
ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KETA
Ose:
- EDE: Isori oro;Oro Oruko: Oriki, Orisii Oruko, Ise Oro-Oruko ninu Gbolohun
ASA: Asa- Asa Isomoloruko: Amutorunwa, abiso, inagije abbl.
LIT: Itupale ewi apileko. Amuye ewi, koko ewi abbl.
- EDE: Oro Aropo-Oruko
ASA: Ipolowo Oja: iwulo ati pataki, orisii ona ti a n gba polowo oja.
LIT: Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.
- EDE: Oro-Ise: Agbabo, Alaigbabo, elela, Alailela.
ASA: Ere Idaraya: Ere Osupa, aojoojumo, Ita gbangba, abele.
LIT: Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.
- EDE: Onka; Egbaa titi de egbaa-run-un(2,000-10,000)-Ilana onkaye lati
egbaa-egbaa-run.
ASA: Ere Omode, Odo, Giripa ati agba. Ofin to de ere kookan, ohun elo
ere kookan ati anfaani ere kookan
LIT: Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.
- EDE: Aroko Ajemo Isipaya
ASA: Ere idaraya-;Ere igbalode. Ayipada ti o ti de ba ere idaraya abinibi
LIT: Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.
- EDE: isori Oro: Oro-Aropo Afarajoruko, Oro Apejuwe. Lilo won ni
gbolohun.
ASA: Owo Yiya: Ohun ti o le sun eniyan de ibi owo yia, ona ti a n gba ya
owo,
ipa ti onigbowo n ko ninu eto iyawo, anfaani ati aleebu owo yiya.
LIT: Ewi Alohun gege bi orison ironu Yoruba: Ese Ifa, Alo Apagbe.
- EDE: Itupale gbolohun oniponna: oriki, Dida gbolohun oniponna mo,
ASA: Ona ti a n gba gba gbese – osomaalo,elemun-un. Ipa ti awon elesin
ati ijoye n ko ninu gbigba gbese.
LIT: Ewi Alohun gege bi orison ironu Yoruba: Ofo, Ogede, Itan riro
- EDE: Aroko asariyanjiyan: Ilana kiko aroko asariyanjiyan, Awon ori-oro ti
o je mo aroko asariiyanjiyan, ijiroro lori ori-oro ti o je mo aroko asariiyanjiyan, kiko ilapa ero
ASA: Asa Isinku ni Ile Yoruba: Orisiirisii ona ti a n gba sin oku, oku omode, oku agba, itufo, itoju oku ati sisin oku agba sinu ile
LIT: Ewi Alohun alohun ti o je mo asa isinku, oku pipe, ijala, rara, Olele, Ege, Iremoje.
- EDE: Akaye oloro geere –kika ayoka ni akaye, didahun ibeere ti o wa labe ayoka. Awon oro ti o takoko ninu ayoka.
ASA: Asa isinku ni ileYoruba: Isinku oba, isinku abami eniyan.
LIT: Akojopo awon owe ti o jeyo lati inu iwe Asayan ewi ti ajo WAEC/NECO
- EDE: Aroko; Leta kiko-Gbefe, ilana fun leta gbefe
ASA: Oku sise, sise oro oku.
LIT: Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.
- EDE: Atunyewo eko lori ise saa yii ninu ede, asa, ati litireso.
- Atunyewo idanwo lori ise odun yii ninu ede, asa ati litirso.
IWE ITOKASI
- Imo, Ede, Asa Ati Litireso. S.Y Adewoyin
- Eto Iro ati Girama fun Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.
- Akojopo Alo Apagbe: Amoo A. (WAEC).
- Oriki Orile Metadinlogbon: Babalola, A (WAEC).
- Iremoje Ere Isipa Ode: Ajuwon B. (WAEC).
- Igbeyin Lalayonta: Ajewole O. (WAEC).
- Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
- Ore Mi: Aderibigbe, M. (WAEC).
- Egun Ori Ikunle: Lasunkanmi Tela. (NECO).
- Omo Ti A Fise Wo: Ojukorola Oluwadamilare. (NECO).
- Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).
OSE KINNI
ORO- ORUKO
– oriki
– orisiirisii oro oruko.
– ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.
– lilo oro oruko ninu gbolohun.
Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun. AP.
Baba ko ebe.
Tolu fo aso.
Mama se isu ewura.
EYA ORO ORUKO.
- ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan, eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je eniyan. Ap
-Rotimi
– Dele
-Ahmed
– Dokita
– Iyalaje…abbl
- ORO-ORUKO ALAISEEYAN:- Eyi ni oruko to n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP. okuta, iwe, ewure, omi, iyanrin, bata abbl.
- Oro-oruko le je ohun elemi : – Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.
- Oro-oruko le je ohun alailemii: – Eyi ni awon nkan ti ko ni emi. ap iwe, ile, bata, ewe, igi: abbl.
- Oro-oruko le je ohun aridimu:- Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan. apewa, eja,isu, tabili, sokoto, aga, ewedu, abbl.
- Oro-oruko le je oruko ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won. Ap ibo lo n lo? Osodi, Meka, Soosi.
- Oro-oruko le je ohun afoyemo:- Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nipa ero opolo. Ap ogbon, ilera, ero, ife, alaafia, igbadun, wahala, imo.
- Oro-oruko le je aseeka : – Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile, ilu, eniyan, iwe, tatapupu.
- Oro-oruko le je alaiseeka : – Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka Ap Iyanrin, epo, omi, afefe, gaari, irun.
- Oro-oruko le je oruko igba:- Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han. Ap Aaro, ana, odun, irole, oni, ola, ijeta [mediator_tech]
ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN.
Ona meta pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun, o le sise:
i.Oluwa,
- abo
iii. eyan.
OLUWA: ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun.
Baba ko ebe.
Bola fo aso.
ABO:ni eni tabi ohun ti a se nnkan si, ap
Mama se obe
Bolu ko leta.
EYAN; ni o maa n se afikun itunmo fun oro-oruko ap
Mama se eja yiyan.
Bola ka iwe mewaa.
Daruko orisii ere idaraya merin ti o mo.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 137-141.
ASA
ORISII ORUKO TI A LE SO OMO NILE YORUBA
Akoonu
Oruko se Pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii sii deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.
Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.
Oruko amutorunwa
- Oruko abiku
iii. Oruko Inagije
- Oruko abiso
Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii. Apeere:
Oruko amutorunwa:-
Ige Omo ti o mu ese waye
Aina Omobinrin ti o gbe ibi korun.
Ojo Omokunrin ti o gbe ibi korun.
Oke Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won maa
n ta si ara apo naa, ki o to le tu.
Oke Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.
Dada Omo ti irun ori re ta koko.
Ilori Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun
Oni Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi
Babarinsa Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.
Abiona
Oruko abiku: Oruko ti a fun omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.
Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap
Oruko Itumo
Durojaye – Ki o duro ni ile aye je igbadun
Rotimi – Duro ti mi, ma se fi mi sile.
Malomo – Duro si aye, ma pada si orun mo
Kosoko – Ko si oko ti a o fi sin oku re mo
Kasimaawoo – Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.
Bamitale – Duro ti mi di ojo ale
Aja – Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.
Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.
Eyinafe: Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.
Ajisafe: Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise
Peleyeju: Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.
Oginni: Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.
Oruko abiso: eyi ni awon oruko ti o n tokasi ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bii.
Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.
Ipo Oruko abiso
Oba Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.
Eleegun Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi
Jagunjagun Akintola, Akinkunmi, Akindele
Onisona Onajide, Olonade
Elesin Ifa Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde
Onisango Sangobunmi, Sangodele
Orisa Oko/Idobatala Efunjoke, Opakunle, Soyinka.
Orisa Ogun Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.
Oruko to n toka si ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.
Oruko Itumo
Ekundayo Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.
Olabode Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.
Tokunbo Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile
okeere ti won gbe wa ile.
IGBELEWON
- Daruko ohun marun-un ninu ohun elo isomoloruko ki o si salaye bi won se n lo won.
- Ko apeere oruko marun-un ninu oruko ile Yoruba pelu alaye.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 101-119.
ITUPALE EWI APILEKO
Ewi je awon akojopo ijinle oro ti a ko sile tabi eyi ti a n ke pelu ohun didun. A maa n ko ni ila si ila ni. A ki i ko o bi aroko. ni abe ewi ni ati maa n se agbeyewo akanlo ede ayaworan akanlo ede ayaworan tumo si awon eroja ti o maa n mu ki ewi dun daadaa. Apeere won ni: awitunwi, asorege/ asodun, owe, akanlo ede, akude gbolohun, afiwe.
AWITUNWI: ninu awitun ni a ti maa n tenumo oro ju eekan lo. A le pe oro bi eemeji tabi eemeta. Awiunwi eleyoro oro wa, akude gbolohun wa
ASOREGE/ASODUN: eyi ni ki a maa pon nnkan ju bi o se ye lo. Won le wi pe, a se inawo ti aye gbo orun si mo. ounje po bi ile bi eni. Eniyan po nibe bi yanrin eti okun.
OWE: Yoruba bo won ni owe lesin oro, oro lesin owe, bo oro ba sonu owe ni a fi maa n wa. owe je ona ti a fi maa n mo bi eniyan so gbo ede Yoruba to.
AKANLO EDE: Yoruba ki i fi gbogbo enu soro. Won maa n pe oro so ni. Awon agba le wi pe o feraku. Itumo eyi ni wi pe onitohun ti loyun. Baba agba tit a teru nipa tumo si wi pe baba agba ti ku.
IFORODARA: ninu iforodara ni won ti maa n fi oro da lorisiirisii. Fun apeere:
Aso funfun ma funfun ni funfun
O ti le funfun ni funfun ki funfun ju.
Yaya ki ba ti je eran oya
Bi ki i ba se iya Yaya ti n tae ran oya ni Moniya.
IGBELEWON
Se itupale asayan iwe ewi kin-in-ni ti ijoba yan.
APAPO IGBELEWON.
- Ko apeere oro oruko mewaa sile
- Ko apeere oro-oruko marun fun oruko abiso, amutoruwa, inagije.
- Ko apeere akanlo ede ayaworan mefa.
ISE AMURELE.
- Salako gbe igunnu. Ew ni oro oruko ti o n se ise oluwa?[a] Salako [b] Salako gbe [d] Igunnu.
- Oro-oruko a maa sise oluwa, ….. ati eyan [a] ise [b] aatokun [d] abo.
- Baba pe mi. Abo inu gbolohun yii ni ——- [a] baba [b] pe [d] mi.
- Ewo ni ki i se ara won? Taiwo, Kehinde, ige, Ojo ………[a] Olugbodi [b] Idoha [d] Salako.
- Oruko ti o je mo ise ilu ni ……. [a] Alayande [b] Oje kunle [d] Malamo.
APA KEJI
- Ko apeere oruko amutorunwa marun-un sile.
- Ko apeere abuda oro oruko marun-n sile pelu apeere mejimeji.
OSE KEJI
ORO AROPO ORUKO.
- Oriki
- Abuda oro aropo oruko
- Ate oro aropo oruko
- Irisi oro aropo oruko.
AKOONU
Oro aropo oruko ni a maa n lo dipo oro-oruko ninu apola oruko.apeere
‘Bolu je akara.
‘O je e.’
‘ewure je agbado Bola’
‘ewure je agbado re.
Abuda oro aropo oruko.
- Oro aropo oruko ni eto to n toka si iye bi eyo tabi opo.apeere
O lo [ eyo ni o ]
Won wa [ opo ni won]
- oro aropo oruko ni eto to n toka si eni.apeere.
enikinni /eyi ni eni ti o n soro.
Enikeji / eyi ni eni ti a n soro sii.
Eniketa / eyi ni eni tabi ohun ti a n soro re.
Mo ko leta.
O ko leta
O ko leta.
- Oro aropo oruko ni eto ipin si ipo.
IYE Eyo opo
Enikin-in-ni mo a
Enikeji o e
Eniketa o won.
- A ko le fi oro-asopo so oro aropo oruko meji papo.apeere
mo ati o
wa ati won.
- A ko le lo oro aropo oruko pelu da ati nko,ni,ko.apeere
mo n ko?
E da?
O ko?
- A ko le lo eyan pelu oro aropo oruko.apeere
mo naa
e gan-an
IRISI ORO AROPO – ORUKO.
Ona meta Pataki ni a le gba lo oro aropo oruko ninu gbolohun.
- O le sise oluwa
- Abo
- Eyan ninu gbolohun.
Ipo oluwa; – oro aropo oruko maa n sise oluwa ninu gbolohun,
IYE EYO OPO.
Enikin-ni mo a
Enikeji o e
Eniketa o won
Apeere;- mo n jo
O n jo
Won n jo
E n jo
A n jo.
Ipo abo : – oro aropo oruko maa n sise abo bakan naa ninu gbolohun.
Iye Eyo Opo.
Enikin-in mi wa
Enikeji o/e yin
Eniketa faweli won
Oro-ise.
Baba na mi.
Bolu n pe o/e
Oluko pe e.
Oba ri wa.
o eyan : -oro aropo oruko maa n ni ipo eyan ninu gbolohun.
[mediator_tech]
IYE EYO OPO.
Enikin-ni mi wa
Enikeji re/e yin
Eniketa re/e won.
Apeere; –
Aja mi
Aja re
Aja re
Ile wa
Aso yin
Aja won.
IGBELEWON.
- Kin ni oro aropo oruko?
- salaye awon oro aropo oruko pelu apeere.
ASA
IPOLOWO OJA
Ipolowo oja
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S.S. 2 Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 101-119.
LITIRESO
SISE ATUPALE EWI KEJI NINU IWE TI IJOBA YAN.
Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
APAPO IGBELEWON.
- Kin ni oro aropo oruko?
- salaye awon oro aropo oruko pelu apeere.
- Ko abuda oro aropo oruko marun-un sile.
- Ko apeere aka nlo ede ayaworan mefa sile.
ISE AMURELE.
- ——- ni o maa n dipo oro oruko ninu gbolohun. [a] oro oruko [b] oro ise [d] oro aropo oruko.
- Orisii ona meta ti a le ri oro aropo oruko ni ——— [a] ipo eyan,oluwa,abo. [b] apejuwe abo,oro oruko [d] aponle,apejuwe,eya.
- Baba pe mi. Abo inu gbolohun yii ni ——- [a] baba [b] pe [d] mi.
- ‘E’ je oro aropo oruko ——– [a] enikin-ni eyo opo,[b] enikeji eyo [d] enikeji opo.
- ….. ni agunmu owo. (a) ipolowo oja (b) ate (d) awin.
APA KEJI.
- Ko ona ti won ngba polowo oja ni aye atijo marun-un.
- Ko ona ti won ngba polowo oja ni aye ode oni marun-un
- Polowo awon nnkan yii: gari, oole, eja.
- Ko abuda oro aropo oruko marun-un sile
- Salaye akanlo ayaworan merin.
OSE KETA
ORO ISE.
-Oriki
Iwulo oro ise
Ona ti a le gba lati da oro ise mo.
Isori oro ise.
“`AKOONU : –
Oro-ise ni oro ti o ba le duro bii koko fonran ninu gbolohunoro-ise ni oro ti o n toka si ohun ti oluwa se ninu gbolohun laisi oro ise ninu gbolohun ko le ni itunmo nitori ohun ni o je opomulero fun gbolohun.Ap.
Baba ra bata.
Olu fo aso.
Bi a ba yo oro-ise kuro ninu awon gbolohun wonyii ko le ni itunmo.
ONA TI A FI LE DA ORO-ISE MO.
- Oro-ise ni o maa n jeyo leyin oluwa
.ap
‘mo je eba.’
won gba owo’.
- oro ti o ba le tele erun oro-ise ‘n’ gbodo je oro-ise.ap
Ade n ko iwe.’
mama n se obe.’
- oro ti o ba jeyo leyin yoo,maa,fi ati ti gbodo je oro-ise.
ap ‘Akekoo yoo se idanwo.’
oluko maa wa.’
Baba ti de’.
- oro ti o ba tele atoka iyisodi ‘ko/o gbodo je oro-ise.
Ap
Bayo ko ra aso.
Oluko ko je eba’.
ISORI ORO ISE.
Orisiirisii isori ni awon onimo girama pin oro ise si ninu ede Yoruba.
- Oro –ise Agbabo : – ni oro-ise ti a maa n lo abo pelu re ninu ede Yoruba.
Ap
Tolu sun.
Tope kuru.
Ojo ro’.
- Oro ise asebeere : – meji naa ni o wa ninu ede Yoruba, awon naa ni da ati nko.
fun apeere
mama da.
Bisi nko’.
- Oro ise asokunfa : – Eyi ni oro –ise ti o maa n se okunfa isele, awon oro-ise asokunfa ni; so, mu, se, ko, fi, da.
Apeere
Bola da erin pa mi.
Bade fi iya je Sola.
O se iku pa aja re.
- Oro-ise Elela: – Eyi ni oro-ise ti a le fi oro-oruko ti o duro fun abo bo laarin ninu gbolohun.
Apeere
bawi,reje,pada,danu.
mama ba omo wi.
Bola re mi je.
Baba da isu nu.
- Oro ise akanmoruko : – Eyi ni a seda lati ara apapo oro-ise ati oro-oruko.
Apeere
Tope muti yo. [mu oti].
mama gunyan je [gun iyan].
Abiola lawo pupo [la owo].
- Oro-ise Asapejuwe : – ni oro-ise ti a maa n lo lati so irisi nnkan.
Apeere
Bisi pupa foo.
Eyin Tolu funfun.
Tope ga’.
- Oro ise Asoluwadabo : – ni oro-ise ti oluwa ati abo le gbapo ara won.Eyi ni pe a le si oluwa ati abo ni ipo pada laisi iyato ninu gbolohun naa.
Apeere-
Aja n se were.
were n se aja.
mo ti oju.
Oju ti mi.
mo jaya.
Aya mi ja’.
- Oro-ise Alapepada: – ni oro ise ti a maa n se apetunpe fun ninu gbolohun.
apeere
Iwo ni o ku mi ku.
E rowa ro ire.
Aye ko fe ni fe oro.
Ma da mi da wahala.
- Oro-ise Asinpo : – ni oro-ise ti o maa n je meji tabi meta ninu gbolohun pelu oluwa kan.iye oro ise ti o wa ninu gbolohun yii ni iye gbolohun ti a le ri fayo.fun apeere.
Ola sun isu ta.
Ola sun isu.
Ola ta isu.
Tope ji eran je..
Tope je eran.
Tope ji eran.
Bolu sare lo gbe aga wa.
- Bolu sare
- Bolu lo
- Bolu gbe aga
- Bolu wa.
IGBELEWON
- Ko abuda oro ise mefa.
- Ko apeere oro-ise mefa pelu apeere mejimeji.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 115-162
.
ERE IDARAYA
Ere Osupa
Ere Osupa ni eere ti awon omode maa n se ti ile bas u ni akoko osupa. Awon ere bee ni Bojuboju, Ekunmearan, Eye eta Tolongo waye, Bookobooko, Isansalubo, Buuru, Para-Onidemode, Gbadiigbadii, Adendele, Porogun ila Ki ni Hewu, Alo apamo ati Alo apagbe.
Ere Ojoojumo
Ere Ita Gbangba
Iwonyi ni awon ere ti tomode-tagba n se ni owo osan si irole ni ita. Apeere iru ere bee ni Okoto, Arin Tita, Ijakadi abbl.
Ere Abele
Ere Abele ni awon ere ti a le se a bile. Apeere ere bee ni Alo Pipa, ayo Tita, abbl.
Ayo tita je ere abele ti o wopo laarin awon agbalagba. Awon omode naa maa n se. Eniyan meji ni o maa n ta ayo. Ope ati ota. Ope ni ko mo ayo ta nigba ti ota mo ayo ta daadaa.
Oju mejila ni opon ayo maa n ni. Mefa wa fun ope nigba ti mefa wa fun ota.
IGBELEWON
- Salaye okan lara ere ita gbanagba.
- Salaye okan lara ere abele.
- Ko meta ninu ewu ti o wa ninu ere idaraya.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 256-299.
LITIRESO APILEKO
KIKA IWE APILEKO ORI KETA ATI EKERIN
Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
IGBELEWON
Sise atupale ori keta ati ekerin.
APAPO IGBELEWON
- Ko abuda oro ise mefa.
- Ko apeere oro-ise mefa pelu apeere mejimeji.
- Sise atupale ori keta ati ekerin.
- Salaye koko ewi keta ati ekerin.
ISE ASETILEWA
- Ewo ni oro-ise ninu gbolohun yii ‘Ade gun keke’(A) Ade (B) gun (C) keke (D) gun keke.
- Ewo ni ki i se abuda oro-ise? (A) o je opomulero gbolohun (B) o maa n tle oluwa (C) o maa n tele erun oro-ise (D) o maa n ni agbara.
- Oro-Ise akanmoruko ni (A) sare (B) lo (C) ko (D) jeun.
- …. je ere abele (A) ayo tita (B) ekun meran (C) ijakadi (D) lakanlaka.
- Eniyan meloo ni o n ta ayo ni eekan soso? (A) okan (B) meji (C) meta (D) merin.
APA KEJI
- Fun ere idaraya ni oriki pelu apeere
- Se akosile abuda oro-ise marun-un pelu apeere.
OSE KERIN
ONKA YORUBA
OOKAN DE EGBAA
ONA MEJI PATAKI NI ONKA YORUBA PIN SIN
ONKAYE (ON – KA – IYE)
ONKAPO (ON – KA – IPO)
‘m’ ni a fi n da pupo ninu awon onkaye Yoruba mo nigba ti a n fi (i) mo onkapo
Apeere
ONKAYE ONKAPO
Meni (mu eni) = 1 Ikini (iko eni) = 1st
Meji (mu eji) = 2 Ikeji (iko eji) = 2nd
Meta (mu eta) = 3 Iketa (iko eta) = 3rd
Merin (mu erin) = 4 Ikerin (iko erin) = 4th
Marun-un (mu aarun = 5 Ikarun-un (iko arun) = 5th
Mefa (mu efa) = 6 Ikefa (iko efa) = 6th
Meje (mu eje) = 7 Ikeje (iko eje) = 7th
Mejo (mu ejo) = 8 Ikejo (iko ejo) = 8th
Mesan-an (mu esan) = 9 Ikesan (iko esan) = 9th
Mewaa (mu ewa) = 10 Ikewaa (iko ewa) = 10th
Mokanla (mu okan-le-ewa) 11 Ikokanla (Iko-okan-le-ewa) 11th
Mejila (Mu-eji-le-ewa) 12 Ikejila (iko-eji-le-ewa)= 12th
Metala (mu-eta-le-ewa) 13 Iketala (iko-eta-le-ewa) 13th
Merinla (mu-erin-le-ewa) 14 Ikerinla (iko-erin-le-ewa) 14th
—- le mo itumo awon onka marun-un to tele merinla (14) a nilati wo iwaju ki a ri ogun (20) ki a tun woe yin ki a wo iye ti okookan awon onka wonyi (15-19) fi din si ogun bayii.
Meedogun (mu arun-din-ni-ogun) 15
Ikeedogun (iko-arun-din-ni-ogun) 15th
Merindinlogun (mu-erin-din-ni-ogun) 16
Ikerindinlogun (iko-erin-din-ni-ogun) 16th
Metadinlogun (mu-eta-din-ni-ogun) 17
Iketadinlogun (iko-eta-din-ni-ogun) 17th
Mejidinlogun (mu-eji-din-ni-ogun) 18
Ikejidinlogun (iko-eji-din-ni-ogun) 18th
Mokandinlogun (mu-okan-din-ni-ogun) 19
Ikokandinlogun (iko-okan-din-ni-ogun) 19th
Ogun (20) da duro funra re, ko si tumo si
eewa meji, o je akanda onka, oun naa ni a mo si okoo
mokanlelogun (mu-okan-le-ni-ogun) 21
Mejilelogun (mu-eji-le-ni-ogun) 22
Metalelogun (mu-eta-le-ni-ogun) 23
Merinlelogun (mu-erin-le-ni-ogun) 24
A o wo iwaju ri ogbon, ki atun woe yin wo iye ti okookan awon onka yii fi din.
Meedogbon (Mu-arun-din-ni-ogbon) 25
Merindinlogbon (mu-erin-din-ni-ogbon) 26
Metadinlogbon (mu-eta-din-ni-ogbon) 27
Mejidinlogbon (mu-eji-din-ni-ogbon) 28
Mokandinlogbon (mu-ookan-din-ni-ogbon) 29
Ogbon 30
Bi a o se kaa niyi titi de ori
Ogoji (ogun eji = 20 x 2 = 40
Ogota eta (ogun eta) = 20 x 3 = 60
Ogorin (ogun erin) = 20 x 4 = 80
Ogorun-un (ogun arun) 20 x 5 = 100
Ogofa (ogun efa) = 20 x 6 = 120
Ogoje (ogun eje) = 20 x 7 = 140
Ogojo (ogun ejo) = 20 x 8 = 160
Ogosan (ogun esan) = 20 x 9 = 180
Ogowaa (ogun ewa) = 20 x 10 = 200
Ogowaa yii tun ni akanda oruko kan pataki ninu ede Yoruba
Ilo aadin-(ewa din)
Aadotan (ewa-din-ni-ota) = (20 x 3) – 10 = 50
Aadorin (ewa-din-ni-orin) = (20 x 4) -10 = 70
Aadorun-un (ewa din ni orun) (20 x 5) – 10 = 90
Aadofa (ewa-din-ni-ofa) = (20 x 6) – 10 = 110
Aadoje (ewa-din-ni-oje) = (20 x 7) – 10 = 130
Aadojo (ewa-din-ni-ojo) = (20 x 8) – 10 = 150
Aadosan (ewa-din-ni-osan) = (20 x 9) – 10 = 170
Aadowaa (ewa-din-ni-owa) = (20 x 10) – 10 = 190
Ogowaa (ogun mewaa) = (20 x 10) = 200
Ti a ba lo isiro ilopo ogun, onka naa lo bayii
220 (200 + 20) = Okoolenigba
230 (200 + 30) = Ogbonlenigba
240 (200 + 40) = Ojilenigba
260 (200 + 60) = Otalenigba
280 (200 + 80) = Orinlenigba
300 (200 + 100) = Oodunrun
320 (300 + 20) = Okoolelodunrun
340 (300 + 40) = Ojileloodunrun
360 (300 + 60) = Otaleloodunrun
380 (300 + 80) = Orinleloodunrun
400 (300 + 100) = Irinwo
420 (400 + 20) = Okoolenirinwo
440 (400 + 40) = Ojilenirinwo
460 (400 + 60) = Otalenirinwo
500 (400 + 100) = Eedegbeta (200 x 30) – 100
600 (400 + 200) = Egbeta (200 x 3) = 600
700 (400 + 300) = Eedegberin (200 x 4) – 100
800 (200 x 4) = Egberin
900 (200 x 5) – 100 = Eedegberun
1000 (200 x 5) = Egberun
1200 (200 x 6) (Igba mefa) = Egbefa
1400 (200 x 7) (Igba meje = Egbeje
1600 (200 x 8 (igba mejo = Egbejo
1800 (200 x 9) (igba mesan-an) egbesan
2000 (200 x 10) Igba mewaa) Egbawa (egbaa)
[mediator_tech]
IGBELEWON
Ko awon onka sile. 700, 710, 720, 730, 740, 750, 760, 770,780, 790, 800
IWE AKATILEWA
Mustapha Oyebamji (2006) EKO EDE ATI ASA YORUBA TITUN (S.S.S) University Press Oju iwe 12-15
.
ASA
ERE OMODE
Ere omode je ere ti o wopo laarin awon omo keeekeeke, apeere omode ni; eye kiko, sise oko ati iyawo, fifi yerupe se ounje, eye meloo tolongo waye, ekun meran talo wa ninu ogba naa, Booko-Booko,
ERE GIRIPA/AGBA
Eyi je ere ti o wopo laarin awon agbalagba. Apeere ere naa ni ayo tita, gidigbo, okoto Tita, ere arin abbl.
OFIN TI O DE ERE IDARAYA
Won ki i ta ao si owo eyin
Omo oju ayo kookan ki i ju merin lo.
ANFAANI ATI EWU ERE IDARAYA
- O maa n fa irepo laarin awon omode.
- O maa n se afihan ebun omode
- O maa n je ki omode ni iwa akin ati akinkanju.
Awon omode maa n ni ipalara.
O le fa ikunsinu.
IGBELEWON
Salaye ere omode ati ere agba.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 256-299.
LITIRESO APILEKO
KIKA IWE APILEKO ORI KETA ATI EKERIN
Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
IGBELEWON
Sise atupale ori keta ati ekerin.
APAPO IGBELEWON
- Salaye ere omode ati ere agba.
- Ko awon onka sile. 700, 710, 720, 730, 740, 750, 760, 770,780, 790, 800
ISE AMURELE.
- 500 je . [a] egbeta [b] eedegbeta [d] ogorin
- 1,000 je [a] egberun [b] eedegberun [d] ogoje.
- Egberin ni (a) 800 (b) 8,000 (d) 700.
- Atenumo oro ju ni (a) awitunwi (b) akanlo ede (d) owe.
- Ajayi dudu bi koro isin. Ipede yii je (a) akanlo ede (b) afiwe (d) asorege.
APA KEJI
- Kin ni owo yiya?
- Daruko idi ti a fi n ya owo?
2.Salaye abuda oro aropo afarajoruko merin pelu apeere.
- Lo oro apejuwe ni gbolohun marun-un.
OSE KARUN-UN
AROKO AJEMO ISIPAYA
Aroko ajemo isipaya je aroko ti o gba sise alaye kikun nipa nnkan ayika eni. Bi apeere aroko alaye ekunrere lori bi won se n se ounjeti a feran julo yato si pa ki a se apejuwe re. Apeere aroko ajemo-isipaya ni:
- Ise Tisa
- Oge Seise.
- Aso Ebi
- Imototo.
- Ise ti mo fe lojo iwaju.
Ki a to le ko akoyawo lori okookan ori-oro wonyi, a gbodo ni arojnle ohun ti won je, itumo ati itumo won miiran to farasin tabi ohun ti o ni abuda won. A nila ti wo anfaani ati aleebu ki a si fi arojinle ero gbe won kale.
IGBELEWON: ko aroko lori Oge sise tabi omi.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 155-156.
ASA
ERE IDARAYA IGBALODE
Opolopo ere idaraya ni o wopo ni aye ode oni. Lara awon ere idaraya aye ode oni ni ludo tita, dirafuti, ere boolu afesegba abbl.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 256-299.
APAPO IGBELEWON : –
- Salaye ere idaraya aye ode oni kan.
- ko aroko lori Oge sise tabi omi.
ISE AMURELE.
- Ewo ni o je mo aroko ajemo isipaya? [a] omi [b] ore [d] ilu Ibadan.
- Ewo no ki i se ara won? [a] eran osin [b] ojo ti ko le gbagbe [d] ile iwe mi.
- Toka si eyi ti ki i se ere idaraya ode oni? [a]ayo tita [b] boolu afesegba [d] ludo.
- Atenumo oro ju ni (a) awitunwi (b) akanlo ede (d) owe.
- Ajayi dudu bi koro isin. Ipede yii je (a) akanlo ede (b) afiwe (d) asorege.
APA KEJI.
- Ko apeere aroko ajemo isipaya mejo sile?
- Salaye ere idaraya ode oni.
OSE KEFA
ORO AROPO AFARAJORUKO
Oriki
- Abuda oro aropo afarajoruko
- Irisi oro aropo afarajoruko.
- AKOONU : –
Oro aropo-afarajoruko ni isesi to frajo ti oro-oruko sugbon o mu eto iye ati eni lara abuda oro aropo oruko.Awon oro aropo afarajoruko ni wonyii; – emi,iwo,oun,awa,eyin, awon.fun apeere.
Emi ko ri Bola.
Ile awa dun.
Abuda oro aropo afarajoruko.
- Oro aropo afarajoruko ni eto iye ati eni.
Ate oro aropo afarajoruko.
IYE EYO OPO.
Enikin-ni emi awa
Enikeji iwo eyin
Eniketa oun awon.
Fun apeere : – iwo ni won ran
Awa naa n bo.
- A le lo oro asopo lati so oro aropo afarajoruko meji papo.apeere.
emi ati iwo.
Awa ati eyin.
iii. Oro aropo afarajoruko le jeyo pelu awon wunren bii da,nko,ko.Fun apeere
iwo n ko?
Oun da?
Eyin ko.
- Silebu meji ni oro aropo afarajoruko maa n ni.apeere.
emi – e /mi.
iwo – I /wo.
- Oro aropo afarajoruko le gba eyan.Apeere
emi naa wa.
Awon gan-an wa.
- A le gbe oro –aropo afarajoruko saaju wunren akiyesi alatenumo ‘ni’ fun apeere
- Eyin ni oga n pe.
- emi ni mo ra iwe naa.
IRISI ORO AROPO AFARAJORUKO.
Ise oluwa ni oro aropo afarajoruko maa n se ninu gbolohun.ap.
Emi naa mu osan.
Oun ni won n bawi.
IGBELEWON
Lo okookan awon oro aropo afajoruko ni gbolohun.
IWE AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S. 3 Corpromutt Publihers Nig Ltd Oju iwe 147-150.
ASA
OWO YIYA
- Oriki
- Awon idi ti a fi n ya owo
- Anfaani ati aleebu owo yiya.
AKOONU : –
Owo yiya je wiwa
iranlowo owo lo si odo elomiran ti a mo pe o ni ju wa lo ni akoko isoro.Se bi ko ba nidii obinrin kii je kumolu,bi ko ba nidii eeyan o le deede lo ya owo.Eyi ni awon idi Pataki ti eeyan fi maa n ya owo laye atijo.
- Inawo pajawiri
- Aisan
- Oran dida
- Oku agba.
ANFAANI OWO YIYA.
- Owo yiya maa n bo ni ni asiri lojo isoro.
- Ki I je ki eeyan di eni yepere tabi eni yeye lowo awon eeyan.
ALEEBU.
- Owo yiya kii fi ni lokan bale.
- Ele gegere ori owo ki I je ki eni yawo tete bo ninu gbese.
- O maa n soro lati le ri owo ti a ya san pada.
- Owo yiya miiran le fa fifi nnkan ini tabi omo wa duro
- Awon ona ti a n gba ya owo ni aye atijo.
AKOONU : –
Awon ona ti a n gba ya owo laye atijo ni; –
- Kiko owo ele: – eyi ni ki a ya owo,ki a si gba lati maa san ele lori owo ti a ya.
- Fifi nnkan ini duro tabi dogo: – eyi ni fifi nnkan ini wa duro,o le je ile,ile tabi moto sugbon ti eni ti o ya owo ko ba ri owo san won le gbe nnkan ini re ta dipo owo ti o ya.Iru owo bayii kii ni ele lori.
- Fifi omo kowo tabi sofa : – eyi nip e iwofa yoo maa se abose loko olowo titi yoo fi ri owo ti won ya san.ise ti iwofa n se fun olowo duro gege bi ele lori owo ti o ya.
IPA TI ONIGBOWO N KO.
Onigbowo je alarinna laarin eni to fe ya owo ati eni ti o fe ya eniyan lowo,onigbowo yii ni o maa duro fun eni to feya owo.Sugbon ti eni to ya owo ko ba ri I san onigbowo yii ni won yoo maa wo bi won ba ti n wo o bee ni oun naa yoo maa ni eni ti o duro fun lara.
IGBELEWON
- Ko aleebu merin nibi owo yiya.
- Ko aafaani owo yiya meta sile.
- Salaye ona ti won gba gbese.
LITIRESO
EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN IRONU ;
- ESE IFA
- AALO APAGBE
AKOONU
Ese-Ifa
Ewi atenudenu Yoruba kun fun ogbon, ironu ati iwoye tabi akiyesi awon baba-nla wa, okookan awon ewi yii lo si je orisun ironu,agbara, ati imo-ijinle Yoruba.
Ero ati akiyesi Yoruba.
Awon Yoruba gbagbo pe nigba ti eeyan ba n bow a si ile aye lati orun,yoo kunle si iwaju Olodumare lati yan ipin, ipin yii ni ori ti eeyan mu waye, ti o je mo gbogbo ohun ti yoo sele sioluware laye, titi kan ohun ti eniyan yoo da, ojo iku re, ati iku ti yoo ku pelu, eyi ni o mu gbolohun w ape;
‘A kunle, a yanpin
A kunleyan ni adayeba
Ero Yoruba ni pe Orunmila, baba Ifa, wa ni odo Olodumare nigba ti olukuluku n yan ipin tire, nitori naa ni a se pe e ni Elerii ipin. Gbara ti eeyan ba si ti de ile-aye lo ti gbagbe iru ipin ti ti o yan waye.
Lati mo bi ojo iwaju yoo ti ri ati lati wadii nipa ohun kan ti a fe dawole, tabi lati wa ona lati jade ninu isoro kan, odo Ifa ni eeyan yoo lo lati lo se ayewo, ero awon Yoruba ni pe Orunmila lo ranti iru ipin ti onikaluku yan waye, oun lo si le ba ni se atunnse si oro eni.
Idi niyi ti won fi n kii ni
Okitibiri, Apajo –iku-da
Atori-alaisunwon se.
Imo-ijinle Yoruba
Ese-Ifa-; je akojo ogbon ati imo-ijinle Yoruba lati irandiran. Ko si ogbon tabi imo –ijinle nipa ohunkohun ti a n wa ti ko si ninu odu ati ese-ifa. Ko si isorokisoro ti o de ba eda laye tabi ohunkohun ti eda le fe se iwadii re ti apeere re ko si ninu ese-Ifa. Nitori naa, ni o fi je pe nigba ti eeyan ba lo se ayewo lodo babalawo, babalawo yoo difa lati mo odu ati ese Ifa ti oro oluware yan. Babalawo yoo so itan latinu ese Ifa, iru eni ti iru re ti sele si ri ati ohun ti o se si oro naa, yoo si so fun eni naa lati se bee gege.
Afihan agbara Yoruba
Agbara nla ni imo ti a fun Orunmila, baba Ifa, lati ode-orun gege bi Elerii ipin, lati le mo ohun ti o le sele si laye ati lati ba eda wa atunse si oro re.