Ilana ise fun saa kinni SS1 YORUBA  

FIRST TERM E-NOTE

 

SUBJECT:  YORUBA    

                                                                                          

CLASS:  SS1

Ilana ise fun saa kinni

Ose kinni-Ede

Atunyewo awon eya ifo

-Eyi ti a le fojuri ati eyi ti a o le fojuri

-Afipe asunsi ati akanmole

Asa-  Owe lorisiirisii-owe imoran ,ibawi abbi.

Litireso –Atunyewo  orisii eya litireso,ohun ti litireso je

Awon eya litireso.

Ose keji-Iro-ede Yoruba

Ohun ti iro-ede je

-orisii iro-ede ti o wa-konsonanti,faweli ati ohun.

Idako konsonanti ati faweli.

Asa-Awon owe ti o je mo asa Yoruba

-igbeyawo,isomoloruko,isinku abbi.

Litireso-Igbadun ti o wa ninu litireso alohun..

Ose keta-Apejuwe iro faweli

-oriki,abuda

-yiya ate faweli

Asa-Awon owe ti o suyo lati inu itan ati ise Yoruba.

Litireso-Eko lori igbadun ti o wa ninu litireso alohun ,ere onise,esa egungun,

Ijala abbl.

Ose kerin atiikarun -Apejuwe iro konsonanti

-oriki,abuda.

Asa    -Iwa omoluabi ati anfaani re

-Awon amuye iwa omoluabi

Litireso –Ogbon itopinpin litireso

Ose kefa –Itesiwaju lori iro-ede Yoruba

-iro-ohun.

Asa –Ise abinibi ile Yoruba

Litireso-Ogbon itopinpin litireso.

Ose keje –Silebu ninu ede Yoruba

-oriki,ihun silebu

-odo ati apaala silebu.

Asa –  Awon ise ona abinibi.

Litireso-kika iwe litireso.

Osekejo-Akoto ede Yoruba

-Itan bi ede Yoruba se di kiko sile

-awon ayipada to de ba kiko ede  Yoruba sile[ilana akoto ode-oni]

Asa- Awon ise abinibi ile Yoruba-eto ati ilana ekose,gbigba iyonda.

-anfaani ti o wa ninu ikose.

Litireso-kika iwe litireso

Ose kesan-an-Aroko kiko-ilana ati ogbon ti a n ta fun aroko kiko

-ifaara,ipinro,ilo-ede.

-orisii aroko ti o wa..

Asa-Elegbejegbe tabi irosiro

-ipa ti won n ko.

Litireso- kika iwe litireso.

Ose kewaa-Akanlo-ede

-iwulo akanlo-ede

akanlo-ede ati itumo won

Asa- asa iranra-eni-lowo

Litireso-kika iwe litireso.

Ose kokanla-Akanlo-ede

  • lilo won ni gbolohun lati fi itumo won han.
  • Asa – asa iranra-eni-lowo.
  • -Atupale asayan iwe litireso.

Iwe  itokasi

Imo,Ede,Asa Ati Litireso.S.Y Adewoyin

Eto Iro ati Girama fun sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.

Ijapa Tiroko.

 

 

OSE    KINNI

ORI-ORO : Awon Eya Ara Ifo

-Eyi ti a le fojuri ati eyi ti a ko le fojuri

-Afipe asunsi ati akanmole.

 

Akoonu

Eya ara ifo-;eyi ni awon eya arati won n sise papo lati gbeiro-ede jade.

Eya ara ifo-;eyi ni gbogbo awon eya ara ti o kopa nigba ti a ba n soro.

Apeere awon eya ara ifo ni;

Ahon,,ete,,afase, eyin, erigi,komookun,tan-an-na,olele,aja-enu,gogongo,alafo tan-an-na abbl.

Isori eya ara ifo

Eya ara ifo pin si ona meji

1.Awon eya ara ifo ti a le fojuri

ii.Awon eya ara ifo ti a ko le fojuri.

Eya ara ifo ti a le fojuri-;eyi ni awon eya ara ti a le fojuri paapaa ti a ba lo digi.

Ap;

Iwaju ahon

Aarin ahon

Eyin ahon

Ete oke

Ete isale

Olele

Afase

Erigi

Eyin oke abbl.

ii.Awon eya ara ifo ti a ko le fojuri-;eyi ni awon eya ara ifo ti a ko le fojuri,ti won wa ninu ikun wa.

Ap

Edofooro

Eka komookun

Tan-an-na

Inu gogongo

Kaa ofun

Afipe

Afipe-;eyi ni gbogbo awon eya ara ti o kopa nigba ti a ba n soro.afipe pin si ona meji

Afipe asunsi ati

akanmole.

Afipe asunsi-eyi ni awon eya ara ifo to le sun soke tabi sodo nigba ti a ba n soro.obere latiete isale wa si agbondo.

Apeere afipe asunsi ni;

Eyin isale

Ete isale

Iwaju ahon

Eyin ahon

Olele

Aarin ahon

Afipe akanmole;-Eyi ni awon eya ara ti ko le sun kuro ni oju kan,ti won maa n duro gbari nigba ti a ba n soro .o bere lati oke enu wa apeere

Ete oke

Eyin oke

Erigi oke

Afase

Kaa imu

Aja  enu

 

IGBELEWON

Daruko eya ara ifo mewaa.

ASA

ORI-ORO-;Owe ile Yoruba

AKOONU

Yoruba bo won ni ‘Owe ni esin oro,oro ni  esin owe,boro ba sonu owe ni a fi n wa.

Owe je ijinle tabi koko ewa-ede ti o n fi asa,ero,ati ise awon Yoruba han.

Owe wulo pupo ni  opolopo ona

Opolopo ona ni owe gba wulo, awon ohun ti a n lo owe fun niwonyii;

Owe ikilo

Owe ibawi

Owe efe

Owe imoran/isiri.

 

OWE IKILO.

Owe ikilo ni a n lo lati kilo iwa fun tomode –tagba.Bi omode kan ba n kegbe buruku awon,awon agbalagba le pe iru omo bee ki won wi fun-un pe ki o sora nitori pe;-

-Agutan ti o ba ba aja  rin yoo jegbe.

– Egbe buburu n ba iwa rere je..ohun ti won n wi fun omo bee nipe won kaa si omo rere sugbon o gbodo yera fun awon oniwa buburu.

– Arinrin gbere niyoo moye dele,asure tete kole roye je.

– A kii fi ikanju labe gbigbona.

– Kirakita ko  mola,ka sise  bi eru koda nnkan.

– A kii korira atokun kadigbo lu eegun.

– Puro ki o niyi,ete ni n mu wa.

 

LITIRESO

 

IGBELEWON

1.Kin ni afipe?

b.Salaye afipe asunsi ati akanmole.

2.kin ni owe?

b.Daruko orisii owe merin ti o mo.

 

IWE  AKATILEWA

Imo,Ede,Asa Ati Litireso Yoruba ss2 o.i 1-5.

 

ISE ASETILEWA

1.______ ni awon eya ara ti a n lo lati gbe iro-ede jade.

[a]enu [b]eya ara ifo [d]eya ara.

2.Apeere eya ara ti a le fojuri ni ——–

[a]Edofooro [b]gogongo [d]ete

3.Ona ——— ni litireso pin si

.[a]kan [b]meji [d]meta

4.Eya ara ti o le sun kuro ni ojukan nigba ti a ba n soro ni__

.[a]inu gogongo [b]asunsi  [d]akanmole.

5.________ ni esin oro,oro lesin owe.

[a]akanlo-ede ]b]owe [d] ijinle oro.

 

APA KEJI

1’Kin ni eya ara ifo

b.Daruko eya ara ifo mewaa.

2.Daruko ohun merin ti a n lo owe fun.

 

OSE KEJI

ORI-ORO-;IRO-EDE

ORIKI IRO-EDE

-ORISII IRO-EDE

AKOONU

Iro-ede -; ni ege ti  o kere julo ti a le fi eti gbo ninu ede,ti a ba n ba eniyan soro ,iro ifo ni ohun ti eni naa yoo maa gbo.

A le ko iro –ede sile nipa lilo leta tabi ami.Iro-ede ti a ni pin si ona meta;

Iro faweli

Iro konsonanti

Iro ohun.

Iro faweli ;ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.

Ona meji ni iro faweli pin si

Faweli airanmupe

Faweli aranmupe

Faweli airanmupe je meje,awon naa ni a,e,e,i,o,o,u.

Faweli aranmupe je marun-un,awon naa ni an,en,en,in,un..

 

 

IDAKO IRO FAWELI

Ilana akoto                              Ilana  fonetiiki

,           a                                  [a]

.           e                                  [e]

e                                  [  ]

I                                   [i]

o                                  [o]

o                                  [  ]

u                                  [u]

an                                [a]

en                                [ ]

in                                 [i]

on                                [c]

un                                [u]

 

 

IRO KONSONANTI

Iro konsonanti-;ni iro ti a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.iro konsonanti mejidinlogun lo wa ninu ede Yoruba.,awon naa ni;b,d,f,g,gb,h,j,k,l,m,n,p,r,s,s,t,w,y.

IRO OHUN

Iro ohun meta ni o wa ninu ede Yoruba awon naa ni

Iro ohun oke

Iro ohun aarin

Iro  ohun isale.

 

IGBELEWON

1.Kin ni iro-ede .

b.Daruko oridii iro-ede tio wa.

ASA

ORI-ORO-AWON OWE TI O JE MO ASA YORUBA

Akoonu

Awon Yoruba je eya Pataki ,ti kii soro ponbele laije pe won lo owe ti o si n tawo tase ninu oro won.

Owe je eroja  Pataki ninu awon asa Yoruba bii igbeyawo,isinku isomoloruko abbl.

Eyi ni die lara owe awon owe ti o je mo asa igbeyawo.

-Atigbeyawo o tejo owo obe lo soro.

-Iyawo ta gbe losu aga ti n fiyan mole,yoo ba a nibe lomo reyoo maa je.

-Obe ti bale ile kii je iyaale ile kii se e.

Eni won n gbe iyawo bowa ba kii garun

Baya ba moju oko tan alarina a yeba.

Ohun to wu mi ko wu o,ni o je a pawopo feyawo.

ISOMOLORUKO

-Ile laawo ka to somoloruko.

-Oruko eni ni ijanu eni.

-Tori bomo o daran, la see ni oruko..

IRANRA-ENI-LOWO

-Ajeje owo kan ko gbegba dori .

-Gba mi nigba ojo ki n gba o nigba eerun.

-Owo omode o to pepe tagbalagba o wo kengbe.

-Omode nise agba nise la fid a Ileefe.

 

IGBELEWON

Pa owe meji fun asa igbeyawo ati isinku

LITIRESO

ORI-ORO-IGBADUN TO WA NINU LITIRESO ALOHUN

AKOONU

Litireso alohun –ni awon litireso ti a jogun lodo awon baba-nla wa ,ti won ko ni akosile ni aye atijo ,opolopo eko ti ako le fowo ro seyin ni a maa n ba pade tabi gbadun ninu awon litireso atenudenu wa ni Pataki julo oro geere ati aalo apamo

ORO-GEERE-;je moitan iwase ati itan laelae,tomode tagba lo le so tabi gbo jtan.. Awon itan wonyii maa n fun wa ni ogbon,imo,eko itaniji atiiwuri nigba miiran lati se ohun ara ti a ro pe a o le se tele.

-O maa n je ki a mo nipa awon itan iranti awon akoni atijo.

-O maa n je ka mo bi idile tabi ilu kan se se,asa atieewo won.

AALO APAGBE

Agba le ko awon omo jotabi ki awon omode ko ara won jo funra won lati gbadun aalo onitan.

-Omaa n ko won ni eko iwa.

-Itan wonyii maa n so idi abajo tabifi ogbon ewe kan han.

-O fun won ni anfaani ipejopo ati idaraya..

-Won tun ni anfaani orin kiko ninu aalo pagbe,eyi ti won lepatewo tabi jo si.

 

IGBELEWON

1.Kin ni iro-ede?

  1. Ona meloo ni iro-ede pin si.

2.Pa owe mejimej ti o je mo awon asa Yoruba wonyii

isomoloruko

igbeyawo

 

IWE AKATILEWA

Imo,Ede,Asa Ati Litireso Yo Se Yoruba bo, won ni.

ruba.(ss2).Adewoyin S.Y. o.i 9-13.

 

ISE ASETILEWA

1._________ ni ege ti o kere julo ti a le fi  eti gbo. [a] ohun [b] iro [d]ede.

2._________ maa n wa ninu aalo apagbe [a]agogo [b]orin [d]ewi

3.Apeere litireso oloro geere ni ______ [a]rara [b]ere onise [d]aalo apamo.

4._______ omode o to pepe ,tagbalagba o wo kengbe. [a]ori [b]ese [d]owo.

5.A le ko iro –ede sile nipa lilo_______ [a]bairo [b]leta tabi ami [d]sisoro jade.

APA KEJI

1.Salaye ohun mejimeji ti a le gbadun ninu oro geere ati aalo apagbe.

2.Pa owe metameta fun awon asa Yoruba wonyii

isomoloruko

iranra-eni-lowo.

 

OSE KETA

ORI-ORO-      APEJUWE IRO FAWELI

ORIKI,ABUDA

IDAKO

ATE FAWELI

AKOONU

Iro faweli-;ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.        ORISII

Ona meji ni iro faweli pin si

Faweli airanmupe

Faweli  aranmupe

Abuda fun isapejuwe iro faweli

Eyi ni abuda ti a n lo fun isapejuwe iro faweli

Ipo ti ahon wa

Ipo ti ete wa

Ipo  ti afase wa

Ipo ti apa to gbe soke ga de ninu enu.

 

ABUDA

 

Ipo ti ahon wa-;bi a ba tele abuda yii,ona meta ni a le pin iro faweli si,nitori pe ona meta ni ahon wa pin si,ipo ahon kookan lo si ni iro faweli ti a fi n pe.

Faweli iwaju

faweli  aarin

faweli   eyin

Faweli iwaju- eyi ni faweli ti a fi iwaju ahon pe,ap I,e,e

Faweli aarin- eyi ni faweli ti a fi aarin ahon pe.ap “a”

Faweli eyin-eyi ni faweli ti afi eyi ahon pe .ap o,u ,o.

IPO TI ETE WA-;bi a ba tele abuda yii, ona meji ni a le pin iro faweli si

Faweli roboto

Faweli perese

Faweli roboto-eyi ni iro ti a pe nigba ti ete se roboto.ap u,o,o

Faweli perese-eyi ni iro ti a pe nigba ti ete wa se perese.ap i,e,

IPO TI AFASE WA-; bi a ba tele abuda yii,ona meji ni a le pin iro faweli si

Faweli airanmupe

Faweli aranmupe

Faweli airanmupe-;ni iro faweli ti a pe nigba ti afase gbe soke lati di kaa imu ,ti eemi si gba kaa enu jade.ap i,e,a.ou.

Faweli aranmupe-;eyi ni iro faweli ti a pe nigba ti afase wa sile lati di kaa enu ti eemi si gba kaa imu jade.ap a,e i.,u.

IPO TI APA TO  GBE SOKE JULO GA DE NINU ENU-;bi a ba tele abuda yii,ona merin ni a le pin iro faweli si

Faweli ahanupe

Faweli ahanudiepe

Faweli ayanudiepe

Faweli ayanupe

 

Faweli ahanupe/(oke) -;ni faweli ti a pe nigba ti apa kan lara ahon ba gbe soke ti o si fere ga de aja-enu.ap /I/,/u/,/i/,/u/.

Faweli ahanudiepe (ebake)-;ni faweli ti a pe nigba ti apa kan to gbe soke ni ara ahon de ebake ,ti a ha enu die pee.ap/e/,/o/.

Faweli ayanudiepe(ebado)-;ni faweli ti a pe nigba ti apa kan gbe soke to de ebado.ap/

/  /  /  /.

Faweli  ayanupe (odo)-;ni faweli ti a penigba ti apa kan gbe soke ni ara ahon wa ni odo.ap/a/.

 

 

ATE    FAWELI

Ate yii ni o n so ipo tabi irisi ahon ni enu ti a ba n gbe iro faweli jade.

 

ATE FAWELI AIRANMUPE

 

 

 

 

Ahanupe              i                                           u

 

Ahanudiepe      e                                             o

 

Ayanudiepe

Ayanupe                                         a

 

ATE  FAWELI  ARANMUPE

 

 

 

 

 

Ahanupe              i                                           u

 

Ahanudiepe      e                                             o

 

Ayanudiepe

Ayanupe                                         a

 

ISAPEJUWE  IRO  FAWELI

[a]-  aarin,   airanmupe,  ayanupe,          perese.

[e]-   iwaju , airanmupe,ahanudiepe,  perese

[  ]-  iwaju,  airanmupe, ayanudiepe,  perese.

[i ] – iwaju, airanmupe, ahanupe,       perese.

[o]-  eyin,   airanmupe  ahanudiepe,   roboto.

[  ]-  eyin,airanmupe,  ayanudiepe ,    roboto.

[u]-   eyin, airanmupe, ahanupe    ,      roboto.

[a]- aarin,  aranmupe,   ayanupe ,    perese.

[  ]- iwaju ,aranmupe, ayanudiepe,   perese.

[i]-  iwaju ,aranmupe ,ahanupe ,     perese.

[  ]- eyin  ,aranmupe,  ayanudiepe,     roboto.

[u]- eyin ,aranmupe ,    ahanupe,     roboto

 

IGBELEWON

  1. Kin ni iro faweli?
  2. Daruko awon abuda fun isapejuwe iro faweli
  3. Sapejuwe awon iro faweli wonyii a,e u o

 

IWE AKATILEWA

Imo,Ede,Asa Ati Litireso Yoruba fun sekondiri agba.Adewoyin S.Yo.i 40-49.

ISE  ASETILEWA

1,_______ ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.[a]ohun [b]konsonanti [d] faweli.

2.Iro faweli pin si ona _________ [a]meji [b] meta [d] merin.

3.Ewo ni ko wulo fun isapejuwe iro faweli? [a]ipo ti afase wa.[b]ipo ti alafo tan-an-na wa.[d]ipo ti ahon wa.

4.Idako faweli “e” ni ______ [a] /e/ [b]/E/ [d]

5.Faweli airanmupe je ______ [a]marun-un  [b]meje [d] mejo.

APA KEJI

1.Salaye ni soki lori awon faweli wonyii

/i/, faweli iwaju, ii faweli roboto iii faweli aarin.

 

OSE KERIN

ORI-ORO ;   APEJUWE IRO KONSONANTI

AKOONU

Iro konsonanti; ni iro ti a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o ti inu edofooro bo.Iro konsonanti mejidinlogun lo wa ninu ede Yoruba awon naa ni  b,d,f,g,gb,h,j,k,l,m,n,p,r,s,s,t,w.y.

ABUDA FUN ISAPEJUWE IRO KONSONANTI

Eyi ni awon abuda ti a maa tele ti a ba fe sapejuwe iro konsonanti

Ipo ti alafo tan-an-na wa

Ipo ti afase wa.

Ibi isenupe

Ona isenupe.

IPO TI ALAFO TAN-AN-NA WA

Bi a ba tele abuda yii,ona meji ni a le pin iro konsonanti si

Konsonantiaikunyun

Konsonanti akunyun

Konsonanti aikunyun-;ni iro ti ti a pe nigba ti alafo tan-an-na fi aye ti o to sile fun eemi ti o n ti inu edofooro bo,eyi ni pe  ko si idiwo.apeere konsonanti aikunyun ni t,k,p,f,s,s,h.

Konsonanti akunyun-;ni a pe nigba ti alafo tan-an-na sunmo ara won pekipeki,ti idiwo si wa fun eemi  ti n ti inu edofooro bo..ap/b/ /d/, /g/ //l/abbl

IPO TI AFASE WA

Bi a ba tele abuda yii,ona meji ni a le pin iro faweli si,awon naa ni

Konsonanti airanmupe

Konsonanti aranmupe

Konsonanti airanmupe-;ni iro ti a pe nigba ti afase gbe soke lati kaa imu,ti eemi si gba kaa- enu jade.ap/b/,/d/,/f//,/k/,/l/.

Konsonanti aranmupe-;ni iro konsonanti ti a pe nigba ti afase wa sile lati di kaa-enu ti eemi si gba kaa-imu jade.ap /m/,/n/

IBI ISENUPE

Ibi isenupe-;eyi ni o n tokasi afipe asunsi ati akanmole ti a lo lati gbe iro konsonanti jade.

Ibi isenupe pin si ona mejo

Afeji-ete-pe

Afeyin-fetepe

Aferigipe

Afaja-ferigipe

Afajape

Afafasepe

Afafase-fetepe

Afitan-an na-pe

ONA ISENUPE

Ona isenupe-;ni o n tokasi iru idiwo ti o wa fun eemi ni gbigbe awon iro konsonanti jade.

Ona meje ni ona isenupe pin si,awon naa ni

Asenupe

Afunnupe

Aranmu

Arehon

Afegbe-enu-pe

Aseesetan.

IGBELEWON

Kin ni iro konsonanti?

Daruko awon abuda fun isapejuwe iro konsonanti.

 

ASA

ORI-ORO        IWA OMOLUABI ATI ANFAANI RE

 

AKOONU

Iwa omoluabi-;ni iwa rere ti o to ti o  si ye ti eeyan n hu,ti o si farahan si gbogbo eniyan.

Omoluabi ni eni ti o ko gbogbo iwa rere po,ti egbe ati ogba ka si ojulowo eniyan nitori pe iwa rere leso eniyan.

Eyi ni awon iwa ti a fi n da omoluabi mo

Ikini-;omoluabi gbodo je eni ti o maa n ki eeyan yala aladuugbo,alabaagbetabi alabaasise po,laaro, losan an ati lale.

Iforiti-;omoluabi gbodo je eni ti o ni iforiti,nitori  pe ko si eni ti o wa laye ti ko ni isoro tire, gege bi omoluabi o gbodo je eni ti o ni emi iforiti.

Iwa iteriba ati irele-;omoluabi gbodo je eni ti o ni iteriba ati owo fun gbogbo eniyan ti o ba ju won lo.

Igboran-;sise igboran je iwa omoluabi nitori eni ti a n ba wi ti ko gboran ki i se omoluabi.

Mimo iyi akoko;omoluabi gbodo je eni ti o mo iyi akoko. Ti o n se ohun ti o ye ni akoko ti o to.

Iwa irele ati suuru;omoluabi gbodo je eni ti o ni suuru ati irele ti kii gberaga,eyi ni yoo si je ki ibagbe re tu awon eeyan lara.

ANFAANI IWA OMOLUABI

  • Iwa omoluabi maa n je ki a ba ojurere pade.
  • O maa n je ki gbogbo eniyan feran iru eni bee.
  • Gbogbo eeyan lo maa n sadura fun omoluabi.

 

 

IGBELEWON

1.Kin ni iro konsonanti?

b.Daruko abuda fun isapejuwe iro konsonanti.

2.Kin ni iwa omoluabi?

b.Daruko amuye iwa omoluabi marun-un ti o mo.

 

IWE AKATILEWA

Imo,Ede,Asa,Ati Litireso Yoruba .ss2.Adewoyin.S .Y o.i22-27.

 

ISE ASETILEWA

1.Iro konsonanti _______ lo wa ninu ede Yoruba [a[meji [b] mejila [d] mejidinlogun

2.Iro ______ ni a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.[a]ohun [b]konsonanti [d] faweli.

3._______ lo je ka mo iru iro konsonanti ti a pe [a[alafo tan-an-na [b[afase [d]ete.

4._____ ni a ti le huwa omoluabi [a[soosi [b] ile [d] ibi gbogbo

5.Ohun akoko ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti a fe ka ni _____ [a]itan inu iwe naa [b]eko ti a ri ko [d]oruko iwe ti a fe ka.

APA KEJI

1.Daroko awon abuda fun isapejuwe iro konsonanti..

b.Salaye meji ninu won.

2.Daruko amuye iwa omoluabi merin.

b.Salaye meji ninu won.

.

OSE KEFA

ORI-ORO      IRO- OHUN

ORIKI

ORISII

AKOONU

Iro-ohun-; ni lilo soke,lilo sodo tabi yiyo roketabi rodo ohun wa nigb ti  ba n soro.

Ona meji ni iro ohun pin si

Iro-ohun geere

Iro –ohun eleyoo.

IRO-OHUN GEERE- eyi ni ki iro-ohun eniyan duro si ipo kannaa laini eyo rara.Iro-ohunlo je ka mo iyato oro kan ti won ni sipeli kan naa yato si ikeji.

Ona meta ni iro-ohun geere pin si

Iro-ohun oke

Iro-ohun aarin

Iro-ohun isale.

Iro-ohun oke-;eyi ni iro –ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun si oke.Iro-ohun yii naa ni a mo si “mi”.Ami re ni o lo si apa otun  /

Ap

Wa

Gba

Mo

Iro-ohun aarin-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa si aarin meji.Iro ohun yii ni a mo si “re”.iro-ohun yii ko ni ami ninu akoto.ap

Mo

 

Iro-ohun isale-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa si isale.ami ni a mo si “do”.Ami re ni o lo si apa osi.ap ta

Ra

Gba

Ori faweli ati konsonanti aranmupe asesilebu ni a maa n fi ami ohun si.

 

Iro-ohun aarin-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa si aarin meji.Ohun ni a mo si (re),iro ohun yii ko ni ami ninu akoto.ap

Gba

Mo

Iro-ohun eleyoo-;eyi ni iro-ohun ti o yo roke tabi rodo nigba ti a ba n soro

Ona meji ni iro-ohun eleyo pin si

Iro-ohun eleyooroke

Iro-ohun eleyoorodo

Iro-ohun eleyooroke-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa lati iro-ohun isale lo si iro-ohun oke.

Ami idamo re ni V.

ap     yii, olopa.

Iro-ohun eleyoorodo-;eyi ni iro-ohun ti a gbe jade nipa gbigbe ohun wa lati ohun oke lo si iro-ohun isale ami re ni^

ap-; yoo,naa.

A o lo awon ami wonyi mo lode-oni.

ASA

ISE ABINIBI ILE YORUBA.

Ise iran tabi ebi-;je ise idile ti a jogun ba ninu ebi wa.Awon idile miiran wa ti a ara ilu mo won bi eni mowo nitori ise awon idile naa,awon idile miiran je Olode,idile onilu,idile onisegun,onisowo abbl.

 

AKOONU : – Yoruba bo won ni ‘eni ti ko sise ko ye ki o jeun’.iyen nip e won gba pe eni kookan gbodo ni iselowo.Iran Yoruba lodi si iwa ole,kekere ni won si ti n ko awon omo ni ise abinibi.          Ni kete ti won ba ti bimo saye ni awon obi re yoo ti da ifa akosejaye lati mo ise ti eleda yan fun omo naa.

Ise merin ni ise ti o wa ni ile Yoruba ni aye atijo pin si.Awon ni

  1. ise agbe.;-dida oko egan,oko etile
  2. Ise ode.: – ode igbe.ode etile, ode asode.
  • Ise awo : – babalawo,asawosesegun
  1. Ise ona : – aso hihun ,eni hihun, aro dida, ilu lilu,epo fifo, gbenagbena,emu dida, irun didi, ikoko mimo, ati bee bee lo.

 

LITIRESO

ORI ORO-; OGBON ITOPINPIN LITIRESO.

AKOONU-;

Eyi ni awon koko to se Pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti a ijoba yan,eyi ti a maa ka.

Ohun akoko ti a gbodo mo ni;

 

ORUKO IWE

Oruko onikowe,ibudo itan,itan ni soki,awon eda itan,ona isowolo-ede,eko ti a ri ko,asa Yoruba ati bee bee lo.

 

IGBELEWON

  • Kin ni iro-ohun?
  • Ona meloo ni iro-ohun pin si?

Salaye iro-ohun geere pelu apeere meji meji fun ikookan.

  1. kin ni ise abinibi?
  • Daruko ise abi
  1. nibi merin ti o mo.

 

IWE AKATILEWA

Simplified Yoruba Language,Literature&Culture.S.Y. Adewoyin o.i 70-76-Adakedajo-iran kinni.

 

ISE ASETILEWA

  1. Ami ohun geere…….. io wa ninu ede Yoruba.(a) Meji (b) Meta (d) Merin
  2. Ori……… ni kan ni a maa n fi ami ohun si (a) Faweli (b) Konsonanti ati faweli(d) Faweli ati konsonanti aranmupe asesilebu.
  3. ‘Ifa akosejaye’ je ki a mo.(a) Ojo ibi omo (b) Iru ise ti omo naa yoo se (d) Oruko ti yoo je
  4. Ise abinibi ti o je ti gbogbo omo Yoruba ni……(a) Ilu lilu (b) Ode (d) Agbe
  5. ……..ni Kanmi ati Alade koko fi owo ran ti ole si gbe owo naa lo.(a) Ajadi (b) Adigun (d)Aremu

APA KEJI

  1. Kin ni ise abinibi?
  2. Daruko ise abinibi merin ti o mo.
  3. Daruko awon ohun ti o se pataki ti a ni lati moi nipa iwe ti a we
    1. Salaye meji ninu won.

 

OSE KEFA

ORI ORO-SILEBU NINU EDE YORUBA

-ORIKI

-IHUN

-BATANI

-ODO ATI APALA SILEBU

AKOONU

Odo silebu;ni apa to gbe se pataki julo ninu ihun silebu kookan.Iro faweli ati iro konsonanti aranmupe asesilebu ni o maa n sise gege bi odo silebu.

Awon iro odo silebu ni a maa n gbo ju ninu oro.

Ori odo silebu ni a maa n fi ami ohun si

Kan-an-n-pa ni odo silebu je ninu ihun silebu.

Ap

wa

gba

sun

Apaala silebu -;je iro konsonanti yato si konsonanti aranmupe asesilebu [m,n] ni o maa n sise gege bi apaala silebu.

ap

gbo

dun

ko

we

IHUN SILEBU [F1,KF ATI N] NINU ORO OLOPO SILEBU.

Orisiirisii ona ni a le gba se ihunpo silebu ninu oro olopo silebu.

ORO                          IHUN                           IYE SILEBU

Aso                              A/ so                                        2

f /kf

Bata                             ba / ta                                      2

Kf / kf

Igbale                          i/gba / le                                   3

F/ kf /kf

Alupupu                     A/lu/pu/pu                                4

f/kf/kf/ kf

Konko                         ko/N/ko                                   3

Kf/N/kf

ASA

ORI-ORO-;AWON ISE ONA ABINIBI

AKOONU

Ise ona je okan lara awon ise abinibi ti o ti wa tipe ni ile Yoruba,ise ona pin si orisiirisii

Ise ona igi (agbegilere)

Ise ona okuta

Ise ona ogba finfin

Ise ona awo

Ise ona je ise ti o mu laakaye suuru ati ogbon atinuda dani,ise iran tabi idile ni

Igba finfin

Okan ninu ise ona ni igba finfin je,ni ilu Oyo ni o wopo si ju.Iran onirese lo ni igba finfin idi niyi ti won fi maa n paa lowe pe bi onirese o fingba mo,eyi to ti fin ko lee parun.

Ohun elo ise won ni Igba,abe,ada abbl.

IGBELEWON

1   Kin ni silebu?

  1. Daruko ihun silebu,salaye won pelu apeere mejimeji
  2. Daruko orisii ise ona abinibi merin ti o mo

IWE AKATILEWA

EKO EDE YORUBA TITUN SS1.

Oyebamiji Mustapha et al.o.i 35-37

ISE ASETILEWA

1  ……..ni ege oro ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekansoso.(a)Oro(b)Iro(d)Silebu

  1. Iran……..lo ni igba finfin(a)Onikoyi(b)Onigba(d)Onirese.
  2. Ise ode adedo ni……..pipa (a) Erin (b) Efon (d) Eja
  3. Ere gbigbe je apeere ise ona ……..(a) Awo (b) Agbegilere (d) Okuta.
  4. …….ni a maa n gbo ketekete ninu ihun silebu.(a) odo (b) Apaala (d) silebu iro.

APA KEJI

1.Kin ni silebu?

  1. Ge awon oro wonyi si silebu

Arogundade          Alagbalugbu

Konkojabele

Ojikutu bara orun saaro

2.Salaye odo ati apala silebu pelu apeere.

OSE KEJE

ORI-ORO    AKOTO  EDE YORUBA

ITAN BI EDE YORUBA SE DI KIKO SILE

AKOONU

Ki owo eru to bere ni iwo oorun Afirika,asa iwe kika sajeji ni ile Yoruba,a kan n so ede Yoruba lenu lasan ni,ko si akosile.

Nigba ti owo eru bere opolopo omo Yoruba ni awon onisowo alawo funfun ko leru lo si ilu won.

Leyin opolopo odun ni won fi opin si owo eru yii gbogbo awon ti won ko leru ni won so di ominira ni ile saro(Freetown) ti won si bere igbe aye titun.

Leyin opin owo eru yii ajosepo si n tesiwaju laarin iwo oorun pelu awon alawo funfun ,won wa ra ohun elo fun ile-ise okowo won.Laarin akokoyii, awon alawo funfun gbagbo pe eniyan dudu ko ni esin pe abogibope ni won, idi niyi ti won fi mu esin kristieni wa fun wa,ti esin titun yoo ba si fese mule,odi dandan ki awon ajhinrere to mu esin wa gbe ni aarin awon eniyan ti won n waasu fun.

Idi niyi ti awon ijo Siemeesi ( C. M. S) fi ran awon alufaa ati awon oluko tele awon onisowo wa si ile Adulawo . ki ise ihinrere ba le lo daadaa,awon ajihinrere wonyii bere sii ko bi a se n so ede Yoruba.

Laarin awon ajihinrere wonyii ni,Koelle, John Rabban,Clapperton, Hannah Kilham,ati awon Yoruba to ti ile Saro de lati se agbateru bi ede se maa di kiko sile.

Orisiirisii igbimo ni won gbe kale lati jiroro lori ona ti o to lati ko ede, Samuel Ajayi Crowther naa je okan ninu won,Osi se gudugudu meje atiyaaya mefa,Oun ni o tumo Bibeli si ede Yoruba.

AYIPADA TI O DE BA KIKO EDE YORUBA  SILE.

ILANA AKOTO ODE-ONI.

i.Awon igbimo to sise lori akoto ede Yoruba nip e gbogbo iro to se koko ni a gbodo   ko sile.

  1. Ami ohun kansoso ni o gbodo duro fun iro to se koko kookan.

SIPELI FAWELI

Ni abe sipeli faweli ,won ni iro faweli ti a ba pe nikan ni ki a ko sile.

Sipeli atijo                               Akoto ode-oni

Aiye                            aye

Eiye                             eye

Eiyele                          eyele

Pepeiye                                    pepeye

Yio                              yoo

 

Won ni bi a ba se pe oro ni ki a maa ko o sile.ap

 

 

 

Sipeli atijo                               Akoto ode-oni

Enia                                         Eniyan /eeyan

Obirin                                      obinrin

Okonrin                                   okunrin

On                                           oun

Kini                                         kin-in-ni

Ikini                                         ikinni

Fun u                                       fun  un

Kan a                                       kan  an

Gbon  o                                   gbon on

Sunmo o                                  sunmo on

Faweli aranmupe ti a fa gun ,a gbodo ko o sile.

Agbodo fa iru si idi e ati o ap

 

Sipeli atijo                               Akoto ode-oni

Eleja                            eleja

Aso                              aso

Ogbon                                     ogbon

Omo                            omo

Owo                            owo

Oko                             oko

Iwe

 

Ni aye atijo ni a maa n lo ami faagun lati fihan pe a gbodo fa iru faweli bee gun sugbon bayii a gbodo fi ami ohun ti o ye sori silebu kookan.

Ap

Sipeli atijo                               Akoto ode-oni

Ogun                                                               oogun

Orun                                                                oorun

Alafia                                                              alaafia

Egun                                                                eegun

Oloto                                                               oloooto

Papa                                                                paapaa

Dada                                                               daadaa

Karoojire                                                         kaaaro-o-o-jiire

Gan                                                                 gan –an

Gbun                                                               gbun-un

Ofon                                                                ofon-on

 

SIPELI    KONSONANTI

Iye iro konsonanti ti a b ape ninu oro ni a gbodo ko.Konsonanti meji ko gbodo jeyo ninu oro.

Ap

Sipeli atijo                                           Akoto ode-oni

Iddo                                                    ido

Offa                                                    ofa

Jebba                                                   Jeba

Ebutte metta                                       Ebute meta

Ottun                                                   Otun

Shola                                                   Sola

Shaki                                                   Saki

Ogbomosho                                         Ogbomoso

Shade                                                  Sade                            –

 

Ninu sipeli atijo ‘m’ ni a maa n ko sugbon bayii ‘n’ ni

Ap

Sipeli atijo                                                      Akoto ode-oni                                          o

Orombo                                                           oronbo                                                    bimbo                                                                       Binbo

M  bo                                                               N bo

Nyin                                                                Yin

Nwon                                                              Won

Enyin                                                               Eyin

Tinyin                                                              Ti yin

Yinka                                                              Yinnka

Ng                                                                   n

Nrin                                                                 n   rin

Nje                                                                  n  je

 

Sipeli titun fun ohun

Tele ami ohun meji ni a maa n fi si ori oro kan (v    )sugbon bayii,a gbodo fi ami ohun ti o ba ye sori oro kookan.

Ap

Sipeli atijo                                                       Akoto ode-oni

Yi                                                                    yii

Olopa                                                              olopaa

Akuse                                                              akusee

Miran                                                               miiran

Kowe                                                              kowee

Bayi                                                                 bayii

Ore                                                                  oore

Na                                                                   naa

Ma                                                                   maa

Ologbe                                                                        oloogbe

 

IPIN ORO

Awon oro kan wa to ye ki a maa ko ni otooto sugbon ti a n ko papo.

Ap

Sipeli atijo                                                       Akoto ode-oni

Nitoripe                                                           Nitori  pe

Nigbati                                                                        Nigba  ti

Gegebi                                                             Gege    bi

Biotilejepe                                                       bi o tile je pe

Bakannaa                                                        bakan  naa.

Wipe                                                                wi  pe

Nitoriti                                                                        nitori    ti

Gbagbo                                                           gba   gbo

Jeki                                                                  je    ki

Peki                                                                 pe    ki

Ibiti                                                                 ibi    ti

Ki ije                                                               ki  i   je

Ki  ise                                                              ki  i    se

Moo ko                                                            mo  on  ko

Dun u  se                                                         dun  un  se

 

Ninu gbolohun to di oruko a maa n fi daasi sii

Ap

Ajagbe-mo-keferi

Owo-ni-faari

Imo-lokun-ola.

 

Won ni ki a ma lo ‘y’ dipo ‘h’.

Sipeli atijo                                           Akoto ode-oni

Ehin                                                     Eyin

Ehin                                                     eyin

Irohin                                                  iroyin

Awun                                                  ahun

Onje                                                    ounje

Gbudo                                                 gbodo

Tuntun                                                 titun

 

IGBELEWON

Tun awon oro wonyii ko ni ilana akoto ti ode oni.

.           nigbagbogbo

eyiti

igbawo

niwonigbati

2          .Bawo ni ede Yoruba se di kiko sile?

IWE    AKATILEWA

 

 

 

ISE  ASETILEWA

1.__________ ni o tumo bibeli si ede Yoruba

[a] Clapperton [b] Bishop Ajayi Crowther [d]Hannah Kilham.

2.Ibo ni won ko awon  ti won so dominira lo? [a] ilu won  [b]Afirika

[d] Freetown.

3.Akoto ode-oni fun “akeko “ ni [a] akeeko [b] akekoo  [d]aakeko.

4.Shobanjo yoo di [a] Sobanjoo  [b]Sobanjo [d] Sobanjo.

APA KEJI

1.Se atunse ti o ye lori akoto awon gbolohun

1.Shola nlo si ebutte-metta lola.

ii.Ng o sun lodo hyin.

iii.Enyin ni Shobande nbawi.

iv.Igbawo ni orombo maa dinwo.

v.Nkan ti mo ri ni iddo ya mi lenu.

2.Aiye yi fele pupo,oto ni iwwa ti won n hu ni otto,otto ni eyi ti won n hu ni iddo.

 

OSE KEJO

ORI-ORO    ILANA ATI OGBON TI A N TA FUN AROKO KIKO

AKOONU

Itumo,

Orisiirisii Aroko

Aroko je ona ti a fi n mu eniyan ronu lori koko oro kan,ki o si ko ero re sile laifi atamo-mo-atamo..

 

ORISIIRISII AROKO.

Orisiirisii Aroko ni o wa ninu ede Yoruba,awon naa ni : –

Aroko oniroyin / asotan.

Aroko alapejuwe

Aroko onisorongbesi

Aroko ajemo-isipaya

Aroko alarinyanjiyan

Aroko leta kiko.

 

EROJA PATAKI FUN AROKO KIKO.

Eyi ni awon ohun ti o gbodo je akekoo logun,ti yoo fii je ki o le gbe aroko ti o gbamuse kale.

  • Yiyan ori oro: – Akekoo gbodo yan ori-oro ti o ba mo nipa re daadaa.
  • Sise ilapa ero : – Akekoo gbodo ronu jinle lori ori oro ti o yan,gbogbo ero ti o ba n wa si I ni okan ni yoo maa ko won sile,yoo maa tuna won koko wonyii to,ki aroko naa le wa ni sise-n tele.
  • Koko ero : – Akekoo gbodo to awon koko ero re lona ti yoo fi je ise ti o fe ran –an.Ki gbogbo ero baa le hun mo ara won.
  • Sise ilapa ero ; – Akekoo gbodo se ilapa ero fun ori-oro ti o bay an lati fihan pe o mo ohun ti o fe ko aroko le lori.
  • Aarin : – koko kan ni o gbodo wa ninu ipin afo kookan bi akekoo ba sele ronu jinle to bee ni koko re yoo se po to.
  • Igunle ; – Igunle aroko gbodo fa eeyan mora,o si gbodo je iso ni soki gbogbo ero aroko lati oke dele.

 

ASA

ORI-ORO        ELEGBEJEGBE

ORIKI

ORISII

IPA TI WON N KO NI AWUJO

AKOONU

– Elegbejegbe ni egbe ti awon odo,agba ni okunrin tabi ni obinrin ti won je iro da sile ni agbegbe won fun igbega ilu ati ara won.

Ni aye atijo,iwonba ni ise ti ijoba maa n se fun awon ara ilu.igbega ati idagbasoke ilu tabi igberiko maa n waye pelu iranlowo awon elegbejegbe wonyii,apeere iru egbe bee ni aye atijo ni egbe ogboni.

Apapo awon agba ilu ti won to omo bii Aadota odun ni won maa n wo egbe ogboni.Ojuse egbe ogboni ni lati fun oba ni imoran.Won ni agbara lati da oba lekun tabi le oba kuro lori ite ti o ba si agbara lo.

Ni ode-oni,awon elegbejegbe po jantirere.Apeere won ni :-

Lion’s club

Rotary club

Majeeobaje

Oredegbe ati bee bee lo.

Ni ilu tabi ileto ti awon egbe wonyii ba wa,orisiirisii ise idagbasoke ni won maa n se bii : – tite tabi titun afara se.

  • kiko ile ero kaakiri ibudoko.

 

IWULO ELEGBEJEGBE.

  1. Awon egbe ogboni maa n kopa ninu eto iselu awon baba-nla wa.
  2. Won maa n kopa ninu ise bii:- ona yiye,afara odo titun se,aafin oba kiko.
  • Won maa n kopa ninu pipese owo ajemonu fun awon akekoo ile-iwe giga,pipese eko ofe fun awon akekoo ile-iwe girama,sisan owo idanwo iwe mewaa.
  1. Aaro kiko,owe bibe,eesu kikojo fun iranlowo egbe ati enikookan omo egbe.

LITIRESO

Kika iwe Ijapa Tiroko

IGBELEWON

Kin ni elegbejegbe?

Salaye iwulo elegbejegbe merin ti o mo.

2.Se agekuru itan ti o ka ninu iwe Ijapa Tiroko.

IWE AKATILEWA

IWE KIKA

  • Y ADEWONYI,SIMPLIFIED YORUBA LANGUAGE CULTURE AND LITERATURE O.I 77-78
  • IWE IGBARADI FUN IDANWO ASEKAGBA O.I.165

 

ISE AMURELE.

  1. ——– Ki I se ara erongba elegbejegbe. [a] ona yiye [b] afara tite [d] aibowofagba.
  1. Apeere elegbejegbe laye atijo ni ——- [a] egbe onimototo [b] egbe ogboni [d] rotary club.
  2. Awon egbe —— ni o maa n da oba lekun laye atijo ti o ba si agbara lo. [a]  rotary club [b] lion’s club [d] ogboni.
  3. Elegbejegbe wa fun ——– ilu [a] idagbasoke [b] asorira [d] ayeye sise.
  4. won tun n ko ipa ribiribi nipa eto ——— [a] ile gbigbe [b] eko [d] oro-aje.

 

APA KEJI.

  1. Kin ni elegbejegbe?
  1. daruko apeere elegbejegbe ti a ni lode oni.
  2. salaye iwulo elegbejegbe.

 

 

OSE  KESAN- AN

ORI-ORO -;AKANLO   EDE

-ORIKI

-IWULO AKANLO EDE

– AKANLO EDE ATI ITUMO WON

 

 

Akoonu

Akanlo ede je ipede ti o kun fun ijinle oro eyi ti itumo re farasin pupo.

Isoro ni soki ni  akanlo ede wa fun.

O si tun wulo pupo nigba ti a ba fe pe oro so, ti a ko fe ki  gbogbo eniyan gbo nnkan ti a n so

 

 

Akanlo ede le je eyo oro kan pere apola tabi ki o je odidi gbolohun

ap

AKANLO-EDE                                                         ITUMO

o fori gbota                                                                o se konge aburu

o tele nibi ile gbe loju                                                          o si rin

o faraya                                                                      o binu gan an

na papa bora                                                                        salo

pa ni apafon                                                             pa ku patapata

pon omi sinu apere                                                 se asedanu

ara ile doko                                                               ajeji kan de

fi ara sin                                                                     pamo

di baraku                                                                   nnkan ti ko se e fi sile mo

gbe odo mi                                                                ko sinu wahala

se bi ose tii soju                                                        fi iya je ni

ko eti ikun                                                                  fi gbogbo se akiigbo

ta atapinse                                                                tuka lo ni otooto

igi da                                                                          nnkan ribiribi baje

gba odo mi                                                                bo sinu wahala

gbe itiju ta                                                                  mu itiju kuro

pa ina oro                                                                  mu oro ija wa sopin

ru igi oyin                                                                  daran

fi iru fonna                                                                daran, fa ijangbon

okete boru                                                                 nnkan b aje

ika kan ko woo nidii                                                 ipa ko kaa

owo re te eeku ida                                                   agbara wa lowo re

farasoko                                                                     sa pamo

kolofin                                                                                    ibi ti o pamo

wo sokoto kan naa                                                  dijo fa ijangbon

so oju abe nikoo                                                       so otito oro laiparo

 

IGBELEWON

  1. Kin ni akanlo –ede?

2.Lo akanlo-ede mewaa ni gbolohun

ASA

ORI –ORO -; ASA  IRANRA- ENI-LOWO

  • ORIKI
  • ORISIIRISII ONA TI AWON YORUBA N GBA RAN ARA WON

AKOONU

IRANRA-ENI-LOWO- – eyi ni o n tokasi ona ti awon Yoruba n gba ran ara won lowolaye atijo.

Orisii ona ti won n gba ran ara won lowo.

AKOONU: – Awon Yoruba gba pe ajeje owo kan ko gberu dori,won si gba pe ika ko dogba,idi niyi ti won fi maa n ran ara won lowo laye atijo.

Asa iranra-eni-lowo yii maa n mu ki ise nla ti o le gba enikan ni akoko di sise ni kiakia.Bakan naa,o n mu ki wahala dinku awon eniyan ti won n gbe ni agbegbe kan naa.

Orisii ona iranra-eni-lowo ; – Eyi ni ona ti awon babanla wa  n gba ran ara won lowo laye atijo.

Aaro

Owe

Esusu

Ajo

Owo ele

San diedie

Fifi omo/nnkan ini duro

Gbami-o-ra-mi..

 

 

Awon odo ti won ba je ore,ti won ni agbara dogba,ti oko won si wa nitosi ara won ni won jo maa n se aaro,gbogbo won yoo pawopo se ise naa ni ojokan.

Bi won ti n pari ise enikan tan ni won yoo lo se ti enikeji titi ti won yoo fi se ise naa kari,ounje ki I se dandan sugbon eni ti aaro kan le wa nnkan jije ati mimu.Won maa n fi orin da ara won laraya ki ise le ya.

 

      OWE : – Ni bibe opo eniyan bii ebi,ore,tabi ojulumo lati ba ni sise nla bii ile kiko,ise oko.A maa n da ojo owe ni,eni to be owe gbodo pese ounje ati nnkan mimu fun awon eniyan to be lowe.Ki I se dandan ni ki a san owe pada.

 

FIFI OMO TABI NNKAN INI DURO : – Bi eniyan ba ko si wahala tabi nilo owo,won maa n fi omo tabi nkan ini ti o niye lori duro lati ya owo.Igba ti iru eni bee ba to san-an tan ni yoo to gba nnkan-ki-nnkan ti o fi dogo pada.

 

OWO ELE KIKO/SOGUN DOGOJI : -Awon eeyan to ba wo wahala ni won maa n ko owo ele lati bo asiri ara won.Ilopo meji owo ti won ya ni won yoo san pada,idi niyi ti won fi n pe e ni sogun dogoji.

 

ESUSU/EESU: – Awon opo eniyan le maa ko owo pamo lati fe fi se nnkan gidi ni ojo iwaju.Eyi je ara ona ti a fi n gba lati fi ni owo lowo,ko si ere ninu eesu,iye ti eniyan bad a ni yoo ko.Won yoo yan olori ti yoo maa dari won.Bakan naa ni won yoo ti maa pade yala ni osoose tabi osoosu.

 

AJO : – Awon eeyan yoo maa da owo jo ni ojoojumo si owo akoko da,oun naa ni yoo se eto pinpin ajo ti osu ba pari.Gbogbo eni ti o bad a ajo ni yoo ko kari.

 

IGBELEWON.

1a. Kin ni asa iranra-eni-lowo?

2b. Salaye ona ti awon Yoruba ngba ran ara won lowo laye atijo.

 

IWE KIKA.

  • Simplified Yoruba language literature and culture 0.i 79-81.
  • Iwe igbaradi fun idanwo asekagba Yoruba 0.i.111-113,165-167.
  • Exam focus Yoruba language 0.i 4-5.

 

ISE AMURELE

  1. ———– Ni ohun ti a ka to ye ni yekeyeke. [a] akaye [b] oro [d] gbolohun.
  1. Akaye maa n je ki a mo boya ———– [a] akekoo mo oro o pe daadaa. [b] ohun ti akekoo ka ye e daradara. [d] akekoo ri ohun ti onkowe ko.
  2. Dandan ni a maa n san ——– pada [a] owe [b] san diedie [d] aaro.
  3. gbogbo owo ti a ba da ni a maa ko ninu ——— [a] esusu [b] ajo [d] owo ele.
  4. Dandan ni pipese ounje ninu ——— [a] eesu [b] owe [d] aaro.

 

APA KEJI.

  1. Salaye orisiirisii ona ti awon Yoruba n gba ran ara won lowo laye atijo.
  1. Kin ni iyato to wa laarin aaro ati owe?

2b. Daruko ona meji ti awon Yoruba fi n gba lati ko owe jo.

 

OSE  KEWAA

ORI –ORO  -;LILO AKANLO-EDE NI GBOLOHUN

AKOONU

Eyi ni lilo akanlo-ede ti a ti gbe yewo ni gbolohun lati fi itumo won han.

 

Gomina  Raji Fasola se gudugudu meje yaaya mefa ni ipinle Eko.

Gbogbo ise ti Alaaja n se lati odun yii wa, ajadi apere lo n pa owo si.

Nigba ti okunrin naa da wahala sile tan ni o ba fie se fee.

Iya ibeji tuto soke osi fi oju gba a nigba ti o gbo pe omo re feraku.

Omi ti Sola bu fun baba agba ti sewon.

 

IGBELEWON

Lo akanlo-ede marun-un ni gbolohun.

ASA

ORI-ORO -;ASA IRANRA-ENI-LOWO

AKOONU

Owo ele

San die-die.

Fifi omo duro.

: – Ona ti awon Yoruba fi n ran ara won lowo.

Owo ele kiko

Awon eniyan ti won ba wo wahala ni won maa n ko owo ele lati bo asiri ara won.I lopo meji owo ti won baya ni won yoo san pada,idi niyi ti won fi n pe e ni sogun-dogoji.

Sandie-die / osomaalo : –

Eniyan le ra oja awin pelu adehun lati maa san owo re die-die titi yoo fi tan.Oja bee le je nnkan elo ile tabi nnkan ini.Agidi ni osomaalo fi maa n gba owo won ni aye atijo.Won si wopo laarin awon ijesa.

Fifi omo tabi nnkan ini duro: –

Bi eniyan ba ko si wahala tabi nilo owo,won maa n fi omo tabi nnkan ini ti o niye lori duro lati ya owo.Igba ti iru eni bee ba to san owo ti o ya tan ni yoo to gba nnkan – ki –kan ti o ba fi dogo pada.

 

LITIRESO

Kika iwe litireso ti ijoba yan ‘Ijapa Tiroko’.

 

IGBELEWON.

  1. Salaye ona meta ti awon Yoruba n gba ran ara won lowo.

 

IWE KIKA.

  • Iwe imo ede.asa,ati litireso fun sekondiri agba.0.i 260.
  • Sinplified Yoruba language literature and culture 0.i 77.

 

ISE AMURELE.

  1. Ija wa laarin——- [A] Kike ati Bolu [b] Kike ati Kunbi [d] Kunbi ati Bunmi.
  1. —– ni o wa jise fun Olu. [a] Desola [b] Kike [d] Bunmi.
  2. ——– ni Olu ro pe o ti fi ile oko sile. [a] Kunbi [b] Bunmi [d] Kike.
  3. Nigba wo ni eni ti o fi nnkan duro fi yawo to le ri nnkan naa gba? [a] nigba to ba ku. [b] nigba ti o b ape [d] nigba ti o ba san owo ti o ya pada.
  4. Osomaalo wopo laarin awon ——- [a] ijebu [b] ijesa [d] Ekiti.

APA KEJI.

  1. Se agekuru itan ti o ka ninu iwe Ijapa Tiroko.
  1. Daruko awon ona ti awon Yoruba n gba ran ara won lowo.ki o si salaye meji ninu won.
Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share