SS 1 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA

ODUN IGBEKO YORUBA-SS 1

ISE OOJO-SAA KIN-IN-NI

 • Atunyewo awon eya ara ifo

Atunyewo Eko ile- asa ikini 

Atunyewo orisirisi eya litireso 

 • Itesiwaju lori eko nipa iro ede

Ise abinibi

Eko lori igbadun ti o wa ninu litireso alohun

 • Itesiwaju lori eko nipa iro ede

Owe

Eko lori igbadun ti o wa ninu litireso alohun 

 • Itesiwaju lori eko nipa iro ede 

Sise ounje awujo Yoruba

Ogbon itopinpin litireso ede Yoruba

 • Itesiwaju lori eko lori iro ede (iro ohun )

Awon owe ti o je mo asa yoruba

Itupale asayan iwe itan aroso ti ajo WAEC/NECO yan

 • Silebu

Awon owe ti o suyo ninu ise ati ise Yoruba 

 • Akoto ede Yoruba

Iwa omoluabi ati anfaani re

 • Aroko kiko

Ise abinibi ile Yoruba

Itupale asayan iwe ti ajo WAEC/NECO yan.

 

 

OSE KIN-IN-NI

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ATUYEWO AWON EYA ARA – IFO (EYA ARA ISORO)

Eya ara ifo ni eya ara ti a maa n lo fun gbigbe iro ifo jade

A le pin eya ara ifo si isori meji, awon ni;

 1. Eya ara ifo ti a le fi oju ri: apeere: ete oke, ete isale, eyin oke, e yin isale, evigi, aja enu, iwaju a lo n, aarin lion, eyin ahon, afase, ita gongongo, olele, aja-enu, kaa imu
 2. Eya ara ifo ti a ko le fi oju ri: Apeere; Edo-foro, komookun, eka-komookun, tan-an-na, inu gogongo, kaa ofun.

 

AWON EYA ARA TI A FI N PE IRO EDE

AFIPE: Afipe ni gbogbo eya ara ifo ti won kopa ninu pipe iro ede jede. A le pin awon afipe wonyi si meji; awon nii

 1. APIPE ASUNSI: Eyi ni afipe ti o le gbera nigba ti a aba n pe iro won maa n sun soke sodo ti aban soro. Apeere; Afipe asunsi ni, Ete Isale, Eju isale, iwaju alion, aarin alion, eyin ahon, olele.
 2. AFIPE AKANMOLE: Eyi ni awon afipe ti ko le gbara soke sugbon ti won maa n duro gbari bi a ba n pe iro jade. Apeere afipe akonmole ni, ete oke, aja-enu, afase, iganna ofun, eyin oke, erigi, olele.

Ipo ti ahon ati ete wa ninu pipe faweli ede Yoruba

 1. IPO AHON: Nigba ti a ba pe iro faweli, ape kan ara ahon maa n gbe soke ti yoo su ike ninu enu

A le pin ahon si isori meta ninu pipe iro jade. Awon ni;

 1. Faweli waju: Eyi ni faweli ti a pe nigba ti iwaju ahon gbe soke ju lo ninu enu awon faweli naa ni,I,e,e,in,en.
 2. Faweli aarin: Eyi ni faweli ti a pe nigba ti aarin gbe soke ju lo ninu enu. Awon ni, a, en.
 3. Faweli eyin: Faweli eyin ni faweli ti a pe nigba tie yin ahon gbe soke ju lo ninu enu, awon faweli naa ni, u, o,o,un,on.
 1. IPO ETE: Ipo meji ni ete le wa bi a ba n pe iro faweli.  Ete le te perese tabi ki o su roboto.

Faweli perese: Eyi ni faweli ti a gbe jade nigba ti ete fe seyin ti alafo gigun tin-in-rin wa laarin ete memeeji.  Awon faweli naa ni, a,e,e,I,an,en,in.

Faweli roboto: Eyi ni awon faweli ti a gba jade nigba ti ete ka roboto. Awon ni, o,u,o,un,on.

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: EKO ILE- ASA IKINI

Eko ile ni eko iwa hihu: iwa rere, iwa to to, iwa to ye ti obi fi n ko omo lati kekere.

Eko ile je iwa omoluabi, ati kekere ni iru eko yii ti n bere ti yoo si di baraku fun omo titi ojo aye re.

Dandan ni fun omo lati mo bi ati n ki baba, iya ati awon miran ti o ju ni lo ni gbogbo igba.

 

Ikini akoko / igba

IGBA / AKOKO IKINI
I Ojo  Eku  ojo / otutu
Ii Oye Eku oye
Iii Iyan Eku aheje kiri o
Iv Ni owuro Ekaa oro
V Ni osan Ekaa san
Vi Ni irole Eeku irole
Vii Ni oru Ekuaajin 

 

Ikini akoko Ise

ISE  IKINI IDAHUN
I Agbe Aroko bodu de o Ase
Ii Onidiri Oju gbooro, eku ewa Iyemoja
Iii Babalawo Aboru boye, sboye bo sise Amin
Iv Awako Oko a re foo, goun a pana mo o Amin o
V Akope Igba a ro o O o
Vi Osise ijoba Oko oba ko ni sa yin lese Ase
Viii Iya oloja Aje a wo gba o Ase 

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: ATUYEWO ORISIRISI EYA LITIRESO

Litireso ni akojopo ti a fi oro ni ede kan tabi ti e ko sile.

Isori litireso

 1. Litireso alohun (atenudenu)
 2. Litireso apileko (alakosile)

Litireso alohun: Eyi  ni awon ewi ti a jogun lati enu awonn babanla wa.

Ohun enu ni a fi n gbe litireso jade, ko si ni akosile rara.

Litireso alohun kun fun o gbon imo ati oye agba, nigba ti imo moo ko moo-ke ko ti de ile wa ohun ni awon baba nla wa n lo ninu igbo ke gbodo won.

 

Litireso alohun pin si ona meta

 1. ewi
 2. oro geere
 3. ere onise.

Litireso apileko : Eyi ni litireso ti a se akosile nigba ti imo mooko-mooka de ile wa.

Litireso yin je litireso alakosile.

Litireso alohun ni ategun tabi orison litireso apileko

Isori litireso apileko ni wonyi,

a.ewi

 1. Ese-onitan
 2. itan aroso.

Igbelewon: 

 • Fun eya ara ifo loriki
 • Pin eya ifo si isori
 • Salaye awon eya ara ti a fi n pe iro
 • Kin ni litireso?
 • Salaye isori litireso
 • Fun eko ile loriki

Ise asetilewa: bawo ni a se n ki awon wonyi ni ile Yoruba:

 1. Oba
 2. Ontayo
 3. Alaboyun
 4. Ijoye ilu
 5. Iya olomo tuntun
 6. Akope

 

OSE KEJI

EKA ISE: EDE

Akole ise: Itesiwaju lori eko iro ede Yoruba.

Iro ede ni ege ti o kere julo ninu oro eyi ti a le gboninu ede.

Orisi iro meta ti o se Pataki ninu ede Yoruba ni,

a.iro konsonanti

 1. iro faweli
 2. iro ohun

Iro konsonanti ni iro ti idiwo maa n wa fun eeni ti a fig be won jade apepo iro konsonanti ede Yoruba je meji dinlogun (18). B d f g gb h j k l m n p r s s t w y.

Idako konsonanti ni liana international phonetic association (IPA)

B /b/

D /d/

F /f/

G /g/

Gb /gb/

H /h/

J /d3/

K /k/

L /l/

M /m/

N /n/

P /kp/

R /r/

S /s/

S /s/

T /t/

W /w/

Y /j/

 

Iro faweli ni iro ti a pe laisi idiwo kan kan fun eeni.

A le pin iro faweli si ona meji

 1. Iro faweli airamupe – a e e I o o u
 2. Iro faweli aranmupe – an en in on un

Apapo iro faweli Yoruba je mejia (12)

 

Adako iro faweli ni ilana IPA.

A       /an/

E       /e/ 

I      /i/

O   /o/

O   />/ 

U /u/

An /a/

En /£/

In /i/

On />/

Un /u/

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: ISE ABINIBI

Ise abinibi je ise iran ti a jogun lati  owo awon baba nla wa.

Yoruba gbagbp pe “ise loogun ise”, won lodi si iwa imele idi niyi ti o fi je pe iran kookan ni o ni ise abinibi ti won n se.

Lara ise abinibi ile Yoruba ni wonyi;

 • Ise agbe
 • Ise ode
 • Ise owo bii,
 • Aso hihu
 • Eni hihu
 • Ilu lilu
 • Ise isegun
 • Ise agbede
 • Ise gbenagbena
 • Epo fifo
 • Ikoko mimo
 • Igba finfin
 • Irun didi

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: EKO LORI IGBADUN TI O WA NINU LITIRESO ALOHUN

Orisirisi igbadun ni onworan ati onkowe maa n je ninu litireso alohun.

 lara awon igbadun naa ni wonyi;

 1. Isowo-lo-ona ede: Ilo ede Yoruba je ijinle aladun litireso. Elo ede ti a maa n ba pade ninu litireso alohun ni wonyi; owe, akanlo-ede, ewi tunwi, afiwe taara, afiwe ela loo, iforodara, asorege, oro apara, abbl.

Awon ona ede yii kii je ki litireso atenudanu su eniyan, o si maa n mu ki awon eniya gbadu re to bee gee de ibi wi pe won kii fe ki o tan.

Awon oluworan yoo maa ho yee, won yoo si ma patewo nitori pe o n mu ki inu won dun.

 1. Ilo ohun didun: ohun didun ninu ewi kika, orin kiko, alo pipa ati itan siso ko gbeyi ebun ni ohun, olodumare si fun wa ni esun yii ju ara wa lo de bi pe ti elomiran ba n ke ewi tabi ko orin bi eni pe ki o maa dake mo ni.
 2. Ilu, orin ati ijo: Ni akoko odun ibile bii, odun egungun, odun ifa, odun oro, odun ogun, odun sango odun obatala,lasiko ayeye bii, oye jije, isile, igbeyawo, isomoloruko, isinku agba abbl ni a maa n ko okoojokan orin oladun ati onirunru ilu ni a n li si orin yii ti a si n jo si.

 

Igbelewon: 

 • Fun iro ede loriki
 • Salaye orisi iro ede ti o wa ninu ede Yoruba
 • Kin ni ise abinibi?
 • Daruko oniruuru ise abinibi ile Yoruba
 • Ko igbadun ti o wa ninu litireso alohun

Ise asetilewa: ya ate faweli  aranmupe ati airanmupe sori kadiboodu feregede

 

OSE KETA

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE YORUBA

Apejuwe iro faweli

A le sapejuwe iro faweli ni ona merin wonyi;

 1. Ipo ti afase wa
 2. Apa kan ara ahon to gbe soke ju lo ninu enu
 3. Bi apa to ga soke naa se ga to ninu enu
 4. Ipo ti ete wa
 • Ipo ti afase wa: Afase le gbera soke di ona si imu la.

Iro faweli airanmupe ni a pe nigba ti afase gbe soke – a e e I o o u

Iro faweli aranmupe ni a pe nigba ti afase wa sile – an en in on un

 • Ipo ahon: ti a ba pe faweli, apa kan ara ahon maa n gba soke ti yoo su ike mu eny. Bi apa
 • Bi apa to ga soke naa se to ninu enu: Eyi ni iwon bi ahon se ga to ninu enu
 • Ipo ete: Ipo meji ni ete maa n we ti a ba n pe iro faweli.

Ete le ri perese: Ti ete bari perese awon faweli ti a n pe jade ni, a e e I an en in

Ete le ri roboto: Ti ete ba ri roboto awon iro faweli ti a n pe jade ni, o, u, o, un, on

 

Apejuwe iro faweli airanmupe

 1. Faweli airanmupe ayanupe (odo), aarin, perese

e- Faweli airanmupe ahanu diepe (ebake) iwaju, perese

e- Faweli airanmupe ayanu diepe (ebado) iwaju, perese

 1. Faweli airanmupe hanupe (oke) iwaju, perese

o- Faweli airanmupe ahanu diepe (ebake) eyin roboto

o- Faweli airanmupe ayanu diepe (ebado) eyin roboto

u- Faweli airanmupe ahanupe (oke) eyin roboto

Apejuwe iro faweli aranmupe

An- Faweli aranmupe ayanupe (odo) aarin perese

En- Faweli aranmupe ayanu diepe (ebado) iwaju perese

In- Faweli aranmupe ahanupe (oke) iwaju perese

On- Faweli aranmupe ayanu diepe (ebado) eyin roboto

Un- Faweli aranmupe ahanupe (oke) eyin roboto

 

ATE FAWELI

Iwaju     aarin               eyin                 iwaju         aarin                          eyin     

Ahanupe        i                           U                       in      

Ahanupe                                                         un

 

Ahanudiepe   e o

 

en                           on                                        

Ayanudiepe         e           o            Ayanudiepe                                an 

Ayanupe a Ayanupe

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: OWE

Owe ni afo to kun fun imo ijinle ogbon ati iriir awon agba.

Owe lesin oro, oro lesin owe, bi oro ba sonu owe ni a fi n wa.

Awon agba n lo owe lati yaju oro to takoko.

 

Orisi owe

Isori marun-un ni a le pin owe Yoruba si. Awon niyi,

 1. OWE FUN IBAWI
 • Bi omode ba n se bi omode, agba a si maa sibi agba.

ITUNMO: Iwa ogbon lo ye ki a ba lowo agba

 • Agba ku wa loja ki ori omo tuntun wo

ITUNMO: Agba je olutona iwa rere fun awon omode ni awujo

 • A n gba oromodie lowo iku, o ni won o je ki oun lo ori aatan lo je

ITUNMO: a n pa owe yii fun eni to ba wa ninu ewu kan  ti a si s fun-un to sin fe se ife inu ara re.

 

 1. OWE FUN IKILO:
 • Aguntan to ba ba aja rin a je igbe

ITUNMO: Ti awon agba ba se akiyesi pe enikan n ba eniyan buburu kan rin, won yoo fi owe kilo fun pe ki o yera ki o ma ba a ti ibe ko iwa buburu.

 • Alaso ala kii ba elepo sore

ITUNMO: Oniwa rere kii ba eniyan buruku rin

 • Ise ni oogun ise

ITUNMO: Eni ba fe segun osi a tepa (mura) mo se

 • OWE FUN IMORAN
 • Agba to ba je ajeeweyin ni yoo ru igba re de ile koko

ITUNMO: Agba to ba hawo ko ni ri omode jise fun oun

 • Igi ganganran ma gun ni loju ati okere ni a ti n yee

ITUNMO: Ohun ti o le se akoba fun eniyan ko gbodo ja fara lori re

 • Bi ara ile eni ba n je kokoro arinya, bi a ko ba so fun un, here-huru re ko ni je ki a sun loru

ITUNMO: Bi ara ile eni ba n huwa ibaje ti a ko ba so fun un, nigba ti wahala tabi ijiya re ba de yio ta ba ni

 • OWE FUN ALAYE
 • A ni ka je ekuru ko tan ni abo, n se ni a tun n gbon owo re sinu awo tan- n- ganran

ITUNMO:  awon agba maa n pa owe yii bi wahala tabi ede aiyede kan ba sele ti won si n gbiyanju lati yanju re, ti won tun wa se akiyesi pe awon kan fe hu u sita ( awon kan ko fe ki o tan )

 • Agba to n sare ninu oja ni, bi nnkan o le, a je pe o n le nnkan

ITUNMO: Eni to n sise karakara mo idi ti oun fi n se loju mejeeji

 

 1. OWE FUN ISIRI
 • Bi ori ba pe nile yoo dire

ITUNMO: Bi iya ba n je eniyan de ibi lo pe o fe bohun, won a maa pa owe yii lati fun un ni isiri pe ojo ola yoo dara

 • Pipe ni yoo pe, akololo yoo pe baba

ITUNMO: Ko si ipenija ti eniyan le maa la koja, o le dabi eni pe ko sona abayo sugbon ni ikeyin ireti wa.

 

IWULO OWE

 1. Owe maa n je ki a fi ododo oro gun eniyan lara lai ni binu
 2. Awon agba n lo owe  lati so oro to ba wuwo lati so
 3. Owe n gbe ogo ede yo
 4. A n lo owe lati fi ba ni wi fun iwa ti ko dara
 5. A n lo owe lati kilo iwa ibaje
 6. A n lo owe lati fi gbani ni yaju
 7. Awon agba n lo owe lati fi yaju oro to ta koko.

 

EKA ISE: LITIRESO

AKoLE ISE: EKO LORI IGBADUN TI O WA NINU LITIRESO ALOHUN

Ere – onise –  ese/iwi egungun , ijala

 1. Oriki itan isedele tabi eyi to n so idi abajo litireso atenudenu Yoruba ni eyi, awon ohun ti o n suyo nibe ni oriki itan isedale ati awon asa ajogunba Yoruba. 
 2. Kiki ati kike je okan lara igbadun litireso atenudenu. Awon itan isedala ti a maa n ba pade ninu litireso atenudenu maa ran ni leti orirun ibi ti awon eniyan kan ti se, ti o si n je ki a ni ife sii daadaa. 
 3. Ba kan naa, awon itan idi abajo , bi ori igun se pa, idi ti oju orun fi jinna si ile , idi ti a fi n bo oku mole abbl ni a maa n ba pade ninu litireso atenudenu.
 4. Eko ati ogbon: onirunru eko ni a maa n ba pade ninu litireso atenudenu , o maa n fi oye awon ohun ti o ye  ki a maa se ati eyi ti ko ye ki a hu niwa han ni.
 5. Ikorajopo, idaraya, ipanilerin ati tita-opolo ji po jatirere ninu litireso atenudenu lati gbe asa Yoruba laruge.

 

Igbelewon: 

 • Sapejuwe iro faweeli ni ona merin
 • Fun owe ni oriki
 • Salaye orisi owe pelu apeere
 • Ko igbadun ti o wa ninu litireso alohun ere onise

 

Ise asetilewa 1. salaye awon owe wonyi  gege bi o ti ye o si pelu apeere irufe owe bee meji meji

 1. owe imoran 
 2. Owe ibawi
 3. Owe ikilo

 

OSE KERIN

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE

Apejuwe  iro konsonanti

Iro konsonanti ni iro ti idiwo maa n wa fun eemi ti a fi gbe won jade.

A le pin iro konsonanti si ona wonyi;

 1. Ibi isenupe
 2. Ona isenupe
 3. Ipo alafo tan-an-na

Ibi isenupe: Eyi ni ogangan ibi ti a ti pe iro konsonanti ni enu. O le je afipe asunsi tabi akanmole.

 

Alaye lori ibi isenupe

IBI ISENUPE KONSONANTI TI A PE ISESI AFIPE
Afeji-ete-pe B, m Ete oke ati ate isale pade-apipe akanmole ati asunsi pade
Afeyin fetepe F Ete isale ati eyin oke pade afipe asunsi ati akanmole pade
Aferigipe T, d,s,n,r,l Iwaju ahon sun lo ba erigi oke . afipe asunsi ati afipe akanmole
Afaja ferigipe J,s Iwaju ahon sun kan erigi ati aarin aja enu. afipe ati afipe
Afajape Y Aarin ahon sun lo ba aja enu.  afipe asunsi ati akanmole
Afafasepe K, g Eyin ahon sun lo kan afase .afipe asunsi ati akanmole
Afafasefetepe Kp, gb,w Ete mejeji papo pelu eyin ahon kan afase . afipe asunsi ati afipe akanmole
Afitan – an-na – pe H Inu alafo tan-an na ni a fi pe e

 

Ona isenupe: Eyi  toke si iru idiwo ti awon afipe n se fun eemi ti a fi pe konsonanti, ipo ti afase wa ati iru eemi ti afi gbe konsonanti jade.

 

Alaye lori ona isenupe

ONA ISENUPE KONSONANTI TI A PE IRU IDIWO TI AFIPE SE FUN EEMI
Asenupe B,t,d,k,g,p,gb Konsonanti ti a gbe jade pelu idiwo ti o po julo fun eemi afase gbe soke di ona si imu awon afipe pade lati so eemi, asenu ba kan na ni eemi inu enu ro jade nigba ti a si
Afunnupe F,s,s,h Awon afipe sun mo ara debi pe ona eemi di tooro, eemi si gba ibe jade pelu ariwo bi igba ti taya n yo jo
Asesi J A se afipe po, eemi to gbarajo ni enu jade yee bi awon afipe se si sile
Aranmu M,n Awon afipe pade lati di ona eemi, afase wale, ona si imu le, eemi gba kaa imu jade
Arehon R Ahon kako soke ati seyin, abe iwaju ahon fere lu erigi, eemi koja lori igori ahon
Afegbe-enu-pe I Ona eemi se patapata ni aarin enu, eemi gbe egbe enu jade
Aseesetan W,y Awon afipe sun to ara, won fi alafo sile ni aarin enu fun eemi lati jade laisi idiwo

 

Ipo tan-an-na: ibi alafo tan-an-na ni a fi n mo awon iro konsonanti akunyun ati aikunyun.

Alaye ni kikun

IRO KONSONANTI ALAYE
Konsonanti akunyun D,j,gb,m,n,r,l,y,w Awon konsonanti  ti a gbe jade nigba ti alafo tan-an-na wa ni ipo ikun, eemi kori Aaye koja,eyi fa ki tan-an-na gbon riri
Konsonanti aikunyun P,k,f,s,s,h,t Eyi ni awon konsonanti ti a gbe jade nigba ti alafo tan-an-na wa ni ipo imi eemi ri aaye gba inu alafo yii koja woo rowo

 

ATE IRO KONSONANTI

Ona isenupe Afeji-

Etepe

Efeyin-

fetepe

Aferi-gipe Afaja- ferigipe Afaja-pe Afafa-

sepe

Afafaseu

Fetepe

Afitan-an-na pe
Asenupe Akunyun B D Gb
Aikunyun T K Kp 
Afunnupe Aikunyun F S S H
Asesi Akinyun Dz
Aranmu Akinyun M N
Arehon Akinyun R
Afegbe-

Enupe

Akunyun I

Aseesetan Akunyun J W

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: SISE OUNJE AWUJO YORUBA 

Ouje ni awon ohun ti eniyan ati aranko n je tabi mu ti o fun ara wa ni okun ati agbara.

Won ni “Bi ebi ba kuro ninu ise, ise buse. Ouje ni oogun ebi.

Ise Agbe ni ise ti o gbajumo julo ni ile Yoruba, awon agbe yii ni on pese ire-oko ti eniyan ati eranko n je bii isu, ewa, agbado, gbaguda, eso lorisirisi bii, igba, ope, oyinbo, orogbo, asala, agbalumo, oronbo, obi abbl.

Ire oko ati bi a se n se won

 • Iyan: Isu

A o be isu le na, ti isu ba jina, a o tu si odo. A o gun, bee ni a o ma ta omi sii titi yoo fi fele bi eti ti a o ko sinu abo fun jije pelu obe to gbamuse bii, efo riro tabi isapa.

 • Amala: Ogede

Bi ogede ba ti gbe, won yoo lo o kuna . Elubo yii ni won yoo dasi omi hiho, ti a o fi omorogun ro o titi ti yoo fi dan. Leyin eyi ni a o fa sinu abo tabi inu ora iponmola. Obe gbegiri dara lati fi je amala ogede

 • Aadun: Agbado

Ti a ba ti yan agbado, a o loo kuna. A o wa egeere epo ati eree ti a ti se,  ti a si din, won yoo ro epo ati eree yii mo agbado ti a lo. Aadun de niyen

 

LITIRESO:  OGBON ITOPINPIN LITIRESO EDE YORUBA

 

Koko ti a ni lati mo ti a ba n ko iwe litireso niyi:

 1. Koko-oro (theme):   Litireso apileko gbodo ni koko oro ti onkowe fe ki a mo tabi kogbon
 2. Ilo-ede (use of language): onkowe kookan ni won ni batani ilo-ede won. Bi apeere, fagunwa faran owe, asodun ati awitunwi, bee ni olu owolabi  feran akanpo owe ati akanlo-ede. Die lara ona ede ti a lo ba pade ninu litireso ni wonyi; owe, akanlo-ede, afiwe taara, afiwe eleloo, awada, asorege, ifohun-peniyan, ifohundara, awitunwi abbl.
 3. Asa Yoruba (Yoruba culture): Asa je mo ajumohu iwa ati ise awon eniyan kan. Die lara asa ile Yoruba ni, ikini, igbayewo, isomo loruko, itoju omo, iranra-eni lowo, isinku, oge sise iwa omoluabi, ogun jije, ise sise, ogun jije abbl.
 4. Eda itan (character): eda itan ni onirunru eniyan ti o kopa ninu litireso alohun tabi apileko. Eni ti o kopa ju lo ninu isele inu litireso kan ni olu ede itan

Ni opo igba, oruko awon eda itan wonyi maa n fi ero, iwa ati ise won han

 1.  Ibudo itan: Eyi ni ibi, agbegbe tabi ilu ti isele inu itan ti waye.

Igbelewon: 

 • Fun iro konsonanti loriki
 • Salaye isori iro konsonanti ni sisentele
 • Kin ni ounje?
 • Ko ire oko marun un ki o si salaye bi a se n se won
 • Salaye koko ti onkowe gbodo mo bi o ba n ko iwe litireso

Ise asetilewa: bawo ni a se n se ounje ile Yoruba wonyii:

 1. Gbegiri
 2. Ekuru
 3. ikokore

 

OSE KARUN-UN

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE YORUBA (ILO OHUN).

Iro ohun ni lilo soke, lilo sodo ohun eniyan nigba ti a ba n soro.

Iro ohun inu ede Yoruba pin si ona meji;

 1. Iro ohun geere
 2. Iro ohun eleyoo

Iro ohun geere: Eyi ni iro ohun ti o duro ni ori silebu lai ni eyo rara.

Awon iro bee ni;

 1. Iro ohun oke ( / ) – M
 2. Iro ohun isale ( \ ) – D
 3. Iro ohun aarin ( – ) – R

Apeere iro ohun oke –                              mimo

titi

jide

kola abbl.

Apeere iro ohun Isale –                              ogede

Isale

Iwa abbl

Apeere iro ohun aarin –                              rere

Igba

Akin abbl

Iro ohun eleyoo: Eyi ni iro ti o n yo lati ipo iro ohun tire lo si ipo iro ohun miiran.

Iro ohun eleyo meji ni o wa;

 1. Iro ohun eleyoo roke (V): eyi ni awon iro ohun ti a pe nigba ti a gbe ohun wa towa si isale lo si oke lee kan naa. Apeere

Olopaa – olopa

Paapaa – paapaa 

Yii – yii

 1. Iro ohun eleyoo rodo (^): eyi ni awon iro ohun ti a pe nigba ti a gbe ohun wa lati oke lo si isale leekan naa. Apeere

Yoo – yoo

Naa – naa

Akiyesi: A kii lo ami ohun eleyooroke ati eleyorodo mo ninu akoto ede Yoruba ode oni.

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: AWON OWE TI O JE MO ASA YORUBA

Asa igbeyawo

 1. Ati gbeyawo ko to pon, owo obe lo soro
 2. Bi aya ba moju oko tan, alarina a yeba

Asa iran-ra-eni lowo

 1. Ajeje owo kan ko gberudori
 2. Ka fi owo we owo ni owo se I mo
 3. Ka ro so mo di, ka rodi maso, a ni ki idi sa ti ma gbofo
 4. Ko kunrin rejo, kobinrin paa, a ni ki ejo sa ti ma lo abbl.

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: ITUPALE ASAYAN IWE ITAN AROSO APILEKO TI AJO WAEC/ NECO YAN

 

Igbelewon: 

 • Fun iro ede loriki
 • Salaye pelu apeere isori iro ede Yoruba
 • Ko owe ti o je mo asa igbeyawo ati asa iran-ra-eni-lowo

 

Ise asetilewa:  ko apeere iro ohun eleyoo-rodo ati eleyoo-roke marun-un marun-un

 

OSE KEFA

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: SILEBU

Silebu ni ege oro ti okere julo ti a le pe jade ni enu ni ori isemii kan soso

Batani / Ihun Silebu

Ihun silebu maa n toka si awon ege iro otooto ti won n je yo ni apa silebu. 

 

Apeere apa silebu ni wonyi;

APA ALEYE APEERE ORO APA
 • Odo

Silebu

Eyi ni ipin ti a maa 

n gbo julo ti a ba pa silebu sita. Iro faweli tabi konsonanti aranmupe asesilebu ‘n’ ni won le duro bii odo silebu

I – le

I – tan

Du-n-du

‘I’ ati ‘e’

‘I’ ati ‘on’

‘U’, ‘n’ ati ‘u’

 • Apaala
Eyi ni awon iro ti a kii gbo kete kete ti a ba pe oro sita I – we

I – tan

Du-n-du

‘w’

‘t’

‘d’ ati ‘d’

 • Abere silebu
Eyi ni iro ti o bere silebu ninu ihun. O le je faweli tabi konsonanti Kan – ge

I – we

I – le

‘k’ ati ‘g’

‘I’ ati ‘w’

‘I’ ati ‘I’

 • Apekun silebu
Eyi ni iro faweli ti o pari silebu Wa

Je

Kun

‘a’

‘e’

‘un’ abbl.

 

EYA IHUN SILEBU

Eya ihun silebu meta ni ede Yoruba ni . Eya ihun naa ni wonyi;

 1. Ihun eleyo faweli (f)
 2. Ihun akanpo konsonanti ati faweli (kf)
 3. Ihun eyo konsonanti aranmupe ase silebu (n)

Faweli airanmupe faweli aranmupe le duro bi silebu kan apeere;

Mo ri i

Mo ra a

Ran – an

Fun – un abbl

Apapo konsonanti ati faweli leje silebu kan soso apeere;

 • Ke k – e
 • Je j – e
 • Fe f – e
 • Gba gb – a
 • Sun s – un

Eyo konsonanti aranmupe ase silebu le da duro bii silebu apeere;

 • Ko m ko – ko – n-ko
 • Gbangba – gba – n-gba
 • Ogedengbe – o – ge – de – n-gbe
 • Gbanjo – gba – n-jo abbl.

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: AWON OWE TI O SUYO NINU ISE ATI ISE YORUBA

Oniruuru owe ni awon agba n lo gege bii oro ijinle ogbon lari pe akiyesi ede si ohun ti o wa ni ayika won tabi lati ronu jinle.

 • Owe to je mo iwa ati ise ede eniyan ni woyi;
 1. Omo ti a fi ise wo ni degba omo ti a fi oju ojo bi ko to gege
 2. Ogun omode ku sere gba ogun odun
 3. Eni roar pa eere, yoo rifun re
 4. Woso de mi ko le dabi oniso, n o se bi iya ko le jo iya to bi ni lomo.
 • Owe to je mo ise ni wony i-

     ise agba

 1. Ila kii ga ju onire lo
 2. A kii gbin alubosa ko hu efo
 3. Iti ogede ko to ohun a a pon ada si

Ise ode

 1. Kin ni kan lo ba ajao je, apa re gun ju itan lo
 2. Kaka ki kiniun se akapo ekun, olukuluku yoo se ode re lotooto ni
 3. Awodi oke ko mo pe ara ile n wo oun
 4. Obo n jogede, obo n yundi, obo ko mo pe ohun to dun lo n pa ni

 (D)    Owe to jemo onsowo tabi owo sise

 1. Kin ni iya alaso n ta to yo egba dani, abi ewure n je leesi ni
 2. Ona kan ko wo oja

iii. Eni ti a n ba na oja ni a n wo,  a kii wo ariwo oja.

Igbelewon:

 • Fun silebu loriki
 • Salaye batani silebu inu ede Yoruba
 • Ko eya ihun silebu pelu apeere
 • Ko owe ti o suyo ninu ise ati ise Yoruba

 

Ise asetilewa:  ko owe ti o je mo meji lara ise abinibi ile Yoruba 

 

OSE KEJE

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: AKOTO EDE YORUBA

Akoto ni sipeli tuntun ti awon onimo ede Yoruba fi enu ko le lori ni odun 1974 lati fi maa ko ede Yoruba sile.

Awon ayipada ti o de ba kiko ede Yoruba sile ni wonyi

SIPELI ATIJO  SIPELI TUNTUN IFIYESI
Aiya 

Aiye

Eiye

Aya

Aye

Eye

A gbodo yo faweli “I” 

nitori a ko pe e

Otta

Oshogbo

Ogbomosho

Ebute-Meta

Ota

Osogbo

Ogbomoso

Ebute-Meta

Konsonanti meji kii tele ara ninu ihun ede Yoruba
Olopa

Alanu

Lailai

Na

Papa

Miran

Yi

Olopaa

Alaaanu

Laelae

Naa

Paapaa

Miiran

Yii

Iye iro faweli ti a ba pe ni ki a ko sile
On 

Enia

Okorin

Obirin

Nkan

Onje

Oun 

Eniyan

Okunrin

Obinrin

Nnkan

Ounje

Tani

Kini

Gegebi

Gbagbo

Nitoripe

Lehina

Biotilejepe

Ta ni

Kin ni

Wi pe

Gege bi

Gba gbo

Nitori pe

Leyin naa

Bi o tile jepe

A ni lati ya awon oro yii soto

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: IWA OMOLUABI ATI ANFAANI RE

Omoluabi ni omo ti a bi ti a si ko ti o gba eko rere.

Ile ni a ti n ko eso rode. ise ati iwa omoluabi bere lati inu ile ti a ti bii.

Lara awon iwa omoluabi ni,

 1. Iwa ikini
 2. Bibowo ati titeriba fun agba
 3. Hihuwa pele lawujo
 4. Ooto sise
 5. Iwa irele ati suuru
 6. Iwa igboran
 7. Sise oyaye
 8. Iwa iran-ra-eni lowo.

Igbelewon:

 • Kin ni akoto?
 • Ko sipeli atijo mewaa ki o si ko akoto re gege bii awon onimo se so
 • Fun iwa omoluabi loriki
 • Ko iwa omoluabi marun-un ki o si salaye

 

Ise asetilewa: ko sipeli atijo mewaa ki o si salaye awon ayipada ti o de ba okookan won gege bi awon onimo se fi enu ko ni odun 1974

 

OSE KEJO

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: AROKO KIKO

Aroko ni atinuda ero eni, ti a ko lori ori oro kan Pataki si inu iwe fun onkawe lati ka.

Orisi aroko ti o wa niyi;

 1. Aroko oni leta
 2. Aroko onisorogbesi
 3. Aroko alariyanyan
 4. Aroko alapejuwe
 5. Aroko ojemo – isipaya
 6. Aroko atonisona asotan
 7. Aroko oniroyin

Awon ilana to se Pataki fun aroko kiko

 • Yiyan ori-oro: A ni lati fa ile tere si ebe ori-oro ti a n ko aroko le lori
 • Sise ilepa ero: A ni lati ronu jinle ki a si to ero wa kale ni okookan ninu ipinro kookan
 • Kiko aroko: Ifaara ko gbodo gun ju o si gbodo ba akoko mu.
 • Ipinro: Akoto ode-oni se Pataki ni ipinro kookan bii afiwe, owe, akanlo ede abbl.
 • ILO-EDE: Ojulowo ede se Pataki ninu aroko
 • IGUNLE/IKADi: Eyi ni ipin afo ti o pari aroko o gbodo se akotan gbodo koko, ero ati ori oro ti a yan.

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: ISE ABINIBI ILE YORUBA

Ise abinibi/isenbeye ni ise iran ti a jogun lati owo awon baba nla wa.

Iran kookan ni o ni ise abinibi ti a mo ti o si f ease-file omo lowo. Yoruba lodi si iwa ole, lati kakore ni won si ti maa n ko awon omo won ni ise abinibi won. Ni geere ti a ba ti bimo ni awon obi re yoo ti da ifa akosejaye lati mo iru ise ti ele daa yan fun omo naa. Awon ise abinibi  Yoruba niwonyi;

    Awon ise isembaye Yoruba ni wonyi;                

 • Ise Agbe
 • Ilu lilu
 • Ikoko mimo 
 • eni hihun
 • aro dida
 • Ise ode
 • Ise onidiri
 • Ise akope
 • Ise Alagbede
 • Ise ona bii;
 • Ona igi
 • Ona okuta
 • Ona awo 

[mediator_tech]

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: ITUPALE ASAYAN IWE LITIRESO APILEKO TI AJO WAEC /NECO YAN.

Igbelewon : 

 • Fun aroko ni oriki
 • Ko orisi aroko mefa
 • Salaye awon ilana ti alaroko yoo fi sokan bi o ba n ko aroko
 • Kin ni ise isembaye/
 • Ko awon ise isembaye ile Yoruba

Ise aetilewa: mu okan lara ise isembaye ile Yoruba ki o si salaye lekun-un-rere

SS 3 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA

SS 2 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA