Third Term SSS 1 Yoruba

Table of Contents

ISE-:EDE YORUBA                                                                    CLASS: SS1

ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KETA

Ose:

  1. EDE: Isori oro;Oro Oruko: Oriki, Orisii Oruko, Ise Oro-Oruko ninu Gbolohun

ASA:   Asa- Asa Isomoloruko: Amutorunwa, abiso, inagije abbl.

LIT:     Itupale ewi apileko. Amuye ewi, koko ewi abbl.

  1. EDE: Oro Aropo-Oruko

ASA:   Ipolowo Oja: iwulo ati pataki, orisii ona ti a n gba polowo oja.

LIT:     Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  1. EDE: Oro-Ise: Agbabo, Alaigbabo, elela, Alailela.

ASA:   Ere Idaraya: Ere Osupa, aojoojumo, Ita gbangba, abele.

LIT:     Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  1. EDE: Onka; Egbaa titi de egbaa-run-un(2,000-10,000)-Ilana onkaye lati

egbaa-egbaa-run.

ASA:   Ere Omode, Odo, Giripa ati agba. Ofin to de ere kookan, ohun elo

ere kookan ati anfaani ere kookan

LIT:     Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  1. EDE: Aroko Ajemo Isipaya

ASA:   Ere idaraya-;Ere igbalode. Ayipada ti o ti de ba ere idaraya abinibi

LIT:     Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  1. EDE: isori Oro: Oro-Aropo Afarajoruko, Oro Apejuwe. Lilo won ni

gbolohun.

ASA:   Owo Yiya: Ohun ti o le sun eniyan de ibi owo yia, ona ti a n gba ya

owo,

ipa ti onigbowo n ko ninu eto iyawo, anfaani ati aleebu owo yiya.

LIT:     Ewi Alohun gege bi orison ironu Yoruba: Ese Ifa, Alo Apagbe.

  1. EDE: Itupale gbolohun oniponna: oriki, Dida gbolohun oniponna mo,

ASA:   Ona ti a n gba gba gbese – osomaalo,elemun-un. Ipa ti awon elesin

ati ijoye n ko ninu gbigba gbese.

LIT:     Ewi Alohun gege bi orison ironu Yoruba: Ofo, Ogede, Itan riro

  1. EDE: Aroko asariyanjiyan: Ilana kiko aroko asariyanjiyan, Awon ori-oro ti

o je mo aroko asariiyanjiyan, ijiroro lori ori-oro ti o je mo aroko asariiyanjiyan, kiko ilapa ero

ASA:   Asa Isinku ni Ile Yoruba: Orisiirisii ona ti a n gba sin oku, oku omode, oku agba, itufo, itoju oku ati sisin oku agba sinu ile

LIT:     Ewi Alohun alohun ti o je mo asa isinku, oku pipe, ijala, rara, Olele, Ege, Iremoje.

  1. EDE: Akaye oloro geere –kika ayoka ni akaye, didahun ibeere ti o wa labe           Awon oro ti o takoko ninu ayoka.

ASA:   Asa isinku ni ileYoruba: Isinku oba, isinku abami eniyan.

LIT:     Akojopo awon owe ti o jeyo lati inu iwe Asayan ewi ti ajo WAEC/NECO

  1. EDE: Aroko; Leta kiko-Gbefe, ilana fun leta gbefe

ASA:   Oku sise, sise oro oku.

LIT:     Itupale iwe asayan ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  1. EDE: Atunyewo eko lori ise saa yii ninu ede, asa, ati litireso.
  2. Atunyewo  idanwo lori ise odun yii ninu ede, asa ati litirso.

 

 

 

IWE  ITOKASI

  1. Imo, Ede, Asa Ati Litireso. S.Y Adewoyin
  2. Eto Iro ati Girama fun Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.
  3. Akojopo Alo Apagbe: Amoo A. (WAEC).
  4. Oriki Orile Metadinlogbon: Babalola, A (WAEC).
  5. Iremoje Ere Isipa Ode: Ajuwon B. (WAEC).
  6. Igbeyin Lalayonta: Ajewole O. (WAEC).
  7. Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
  8. Ore Mi: Aderibigbe, M. (WAEC).
  9. Egun Ori Ikunle: Lasunkanmi Tela. (NECO).
  10. Omo Ti A Fise Wo: Ojukorola Oluwadamilare. (NECO).
  11. Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).

 

 

 

OSE KINNI

 

ORO- ORUKO

– oriki

– orisiirisii oro oruko.

– ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.

– lilo oro oruko ninu gbolohun.

Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun. AP.

Baba ko ebe.

Tolu fo aso.

Mama se isu ewura.

 

EYA ORO ORUKO.

  1. ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan, eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je eniyan. Ap

-Rotimi

– Dele

-Ahmed

– Dokita

– Iyalaje…abbl

  1. ORO-ORUKO ALAISEEYAN:- Eyi ni oruko to n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP. okuta, iwe, ewure, omi, iyanrin, bata abbl.
  2. Oro-oruko le je ohun elemi : – Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.
  3. Oro-oruko le je ohun alailemii: – Eyi ni awon nkan ti ko ni emi. ap iwe, ile, bata, ewe, igi: abbl.
  4. Oro-oruko le je ohun aridimu:- Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan. apewa, eja,isu, tabili, sokoto, aga, ewedu, abbl.
  5. Oro-oruko le je oruko ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won. Ap ibo lo n lo? Osodi, Meka, Soosi.
  6. Oro-oruko le je ohun afoyemo:- Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nipa ero opolo. Ap ogbon, ilera, ero, ife, alaafia, igbadun, wahala, imo.
  7. Oro-oruko le je aseeka : – Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile, ilu, eniyan, iwe, tatapupu.
  8. Oro-oruko le je alaiseeka : – Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka Ap Iyanrin, epo, omi, afefe, gaari, irun.
  9. Oro-oruko le je oruko igba:- Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han. Ap Aaro, ana, odun, irole, oni, ola, ijeta

 

ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN.

Ona meta pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun, o le sise:

i.Oluwa,

  1. abo

iii. eyan.

 

OLUWA: ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun.

Baba ko ebe.

Bola fo aso.

 

ABO:ni eni tabi ohun ti a se nnkan si, ap

Mama se obe

Bolu ko leta.

 

EYAN; ni o maa n se afikun itunmo fun oro-oruko ap

Mama se eja yiyan.

Bola ka iwe mewaa.

Daruko orisii ere idaraya merin ti o mo.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 137-141.

 

ASA

ORISII ORUKO TI A LE SO OMO NILE YORUBA

Akoonu

Oruko se Pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii sii deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.

Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.

Oruko amutorunwa

  1. Oruko abiku

iii. Oruko Inagije

  1. Oruko abiso

Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii. Apeere:

 

Oruko amutorunwa:-

Ige                                           Omo ti o mu ese waye

Aina                                        Omobinrin ti o gbe ibi korun.

Ojo                                          Omokunrin ti o gbe ibi korun.

Oke                                         Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won maa

n ta si ara apo naa, ki o to le tu.

Oke                                         Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.

Dada                                       Omo ti irun ori re ta koko.

Ilori                                         Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun

Oni                                          Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi

Babarinsa                               Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.

Abiona

 

Oruko abiku: Oruko ti a fun  omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.

Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap

Oruko                                     Itumo

Durojaye         –           Ki o duro ni ile aye je igbadun

Rotimi             –           Duro ti mi, ma se fi mi sile.

Malomo         –           Duro si aye, ma pada si orun mo

Kosoko           –           Ko si oko ti a o fi sin oku re mo

Kasimaawoo  –           Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.

Bamitale         –           Duro ti mi di ojo ale

Aja                   –           Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.

 

Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.

Eyinafe:          Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.

Ajisafe:           Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise

Peleyeju:        Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.

Oginni:            Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.

 

Oruko abiso: eyi ni awon oruko ti o n tokasi ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bii.

Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.

 

Ipo                                                      Oruko abiso

Oba                                                     Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.

Eleegun                                               Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi

Jagunjagun                                         Akintola, Akinkunmi, Akindele

Onisona                                              Onajide, Olonade

Elesin Ifa                                             Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde

Onisango                                            Sangobunmi, Sangodele

Orisa Oko/Idobatala                         Efunjoke, Opakunle, Soyinka.

Orisa Ogun                                         Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.

 

Oruko to n toka si ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.

Oruko                                                             Itumo

Ekundayo                                                       Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.

 

Olabode                                                          Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.

 

Tokunbo                                                         Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile

okeere ti won gbe wa ile.

 

IGBELEWON

  1. Daruko ohun marun-un ninu ohun elo isomoloruko ki o si salaye bi won se n lo won.
  2. Ko apeere oruko marun-un ninu oruko ile Yoruba pelu alaye.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 101-119.

 

ITUPALE EWI APILEKO

Ewi je awon akojopo ijinle oro ti a ko sile tabi eyi ti a n ke pelu ohun didun. A maa n ko ni ila si ila ni. A ki i ko o bi aroko. ni abe ewi ni ati maa n se agbeyewo akanlo ede ayaworan  akanlo ede ayaworan tumo si awon eroja ti o maa n mu ki ewi dun daadaa. Apeere won ni: awitunwi, asorege/ asodun, owe, akanlo ede, akude gbolohun, afiwe.

AWITUNWI: ninu awitun ni a ti maa n tenumo oro ju eekan lo. A le pe oro bi eemeji tabi eemeta. Awiunwi eleyoro oro wa, akude gbolohun wa

ASOREGE/ASODUN: eyi ni ki a maa pon nnkan ju bi o se ye lo. Won le wi pe, a se inawo ti aye gbo orun si mo. ounje po bi ile bi eni. Eniyan po nibe bi yanrin eti okun.

OWE: Yoruba bo won ni owe lesin oro, oro lesin owe, bo oro ba sonu owe ni a fi maa n wa. owe je ona ti a fi maa n mo bi eniyan so gbo ede Yoruba to.

AKANLO EDE: Yoruba ki i fi gbogbo enu soro. Won maa n pe oro so ni. Awon agba le wi pe o feraku. Itumo eyi ni wi pe onitohun ti loyun. Baba agba tit a teru nipa tumo si wi pe baba agba ti ku.

IFORODARA: ninu iforodara ni won ti maa n fi oro da lorisiirisii. Fun apeere:

Aso funfun ma funfun ni funfun

O ti le funfun ni funfun ki funfun ju.

 

Yaya ki ba ti je eran oya

Bi ki i ba se iya Yaya ti n tae ran oya ni Moniya.

 

IGBELEWON

Se itupale asayan iwe ewi kin-in-ni ti ijoba yan.

 

 APAPO IGBELEWON.

  1. Ko apeere oro oruko mewaa sile
  2. Ko apeere oro-oruko marun fun oruko abiso, amutoruwa, inagije.
  3. Ko apeere akanlo ede ayaworan mefa.

 

 

ISE AMURELE.

  1. Salako gbe igunnu. Ew ni oro oruko ti o n se ise oluwa?[a] Salako [b] Salako gbe [d] Igunnu.
  2. Oro-oruko a maa sise oluwa, ….. ati eyan [a] ise [b] aatokun [d] abo.
  3. Baba pe mi. Abo inu gbolohun yii ni ——- [a] baba [b] pe [d] mi.
  4. Ewo ni ki i se ara won? Taiwo, Kehinde, ige, Ojo ………[a] Olugbodi [b] Idoha [d] Salako.
  5. Oruko ti o je mo ise ilu ni ……. [a] Alayande [b] Oje kunle [d] Malamo.

APA  KEJI

  1. Ko apeere oruko amutorunwa marun-un sile.
  2. Ko apeere abuda oro oruko marun-n sile pelu apeere mejimeji.

 

OSE KEJI

ORO AROPO ORUKO.

  • Oriki
  • Abuda oro aropo oruko
  • Ate oro aropo oruko
  • Irisi oro aropo oruko.

AKOONU

Oro aropo oruko ni a maa n lo dipo oro-oruko ninu apola oruko.apeere

‘Bolu je akara.

‘O je e.’

‘ewure je agbado Bola’

‘ewure je agbado re.

Abuda oro aropo oruko.

  1. Oro aropo oruko ni eto to n toka si iye bi eyo tabi opo.apeere

O lo [ eyo ni o ]

Won wa [ opo ni won]

  1. oro aropo oruko ni eto to n toka si eni.apeere.

enikinni /eyi ni eni ti o n soro.

Enikeji / eyi ni eni ti a n soro sii.

Eniketa / eyi ni eni tabi ohun ti a n soro re.

Mo ko leta.

O ko leta

O ko leta.

  1. Oro aropo oruko ni eto ipin si ipo.

IYE                             Eyo          opo

Enikin-in-ni                    mo       a

Enikeji                             o          e

Eniketa                             o          won.

 

  1. A ko le fi oro-asopo so oro aropo oruko meji papo.apeere

mo ati o

wa ati won.

 

  1. A ko le lo oro aropo oruko pelu da ati nko,ni,ko.apeere

mo n ko?

E da?

O ko?

  1. A ko le lo eyan pelu oro aropo oruko.apeere

mo naa

e gan-an

 

IRISI ORO AROPO – ORUKO.

Ona meta Pataki ni a le gba lo oro aropo oruko ninu gbolohun.

  • O le sise oluwa
  • Abo
  • Eyan ninu gbolohun.

Ipo oluwa; – oro aropo oruko maa n sise oluwa ninu gbolohun,

 

IYE                 EYO                OPO.

Enikin-ni       mo                   a

Enikeji           o                      e

Eniketa           o                      won

 

Apeere;- mo n jo

O n jo

Won n jo

E n jo

A n jo.

Ipo abo : – oro aropo oruko maa n sise abo bakan naa ninu gbolohun.

 

Iye                   Eyo                 Opo.

Enikin-in       mi                    wa

Enikeji           o/e                   yin

Eniketa           faweli             won

Oro-ise.

 

Baba na mi.

Bolu n pe o/e

Oluko pe e.

Oba ri wa.

o eyan : -oro aropo oruko maa n ni ipo eyan ninu gbolohun.

 

IYE                             EYO                OPO.

Enikin-ni                   mi                    wa

Enikeji                       re/e                 yin

Eniketa                       re/e                 won.

Apeere; –

Aja mi

Aja re

Aja re

Ile wa

Aso yin

Aja won.

 

IGBELEWON.

  1. Kin ni oro aropo oruko?
  • salaye awon oro aropo oruko pelu apeere.

 

ASA

IPOLOWO OJA

Ipolowo oja

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2014) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S.S. 2 Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 101-119.

 

LITIRESO

SISE ATUPALE EWI KEJI NINU IWE TI IJOBA YAN.

 

Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).

 

APAPO IGBELEWON.

  1. Kin ni oro aropo oruko?
  2. salaye awon oro aropo oruko pelu apeere.
  3. Ko abuda oro aropo oruko marun-un sile.
  4. Ko apeere aka nlo ede ayaworan mefa sile.

 

ISE AMURELE.

  1. ——- ni o maa n dipo oro oruko ninu gbolohun. [a] oro oruko [b] oro ise [d] oro aropo oruko.
  2. Orisii ona meta ti a le ri oro aropo oruko ni ——— [a] ipo eyan,oluwa,abo. [b] apejuwe abo,oro oruko [d] aponle,apejuwe,eya.
  3. Baba pe mi. Abo inu gbolohun yii ni ——- [a] baba [b] pe [d] mi.
  4. ‘E’ je oro aropo oruko ——– [a] enikin-ni eyo opo,[b] enikeji eyo [d] enikeji opo.
  5. ….. ni agunmu owo. (a) ipolowo oja (b) ate (d) awin.

APA KEJI.

  1. Ko ona ti won ngba polowo oja ni aye atijo marun-un.
  2. Ko ona ti won ngba polowo oja ni aye ode oni marun-un
  3. Polowo awon nnkan yii: gari, oole, eja.
  4. Ko abuda oro aropo oruko marun-un sile
  5. Salaye akanlo ayaworan merin.

 

 

 

 

 

 

 

 

OSE KETA

                                    ORO ISE.

                              -Oriki

Iwulo oro ise

Ona ti a le gba lati da oro ise mo.

Isori oro ise.

“`AKOONU : –

Oro-ise ni oro ti o ba le duro bii koko fonran ninu gbolohunoro-ise ni oro ti o n toka si ohun ti oluwa se ninu gbolohun laisi oro ise ninu gbolohun ko le ni itunmo nitori ohun ni o je opomulero fun gbolohun.Ap.

Baba ra bata.

Olu fo aso.

Bi a ba yo oro-ise kuro ninu awon gbolohun wonyii ko le ni itunmo.

 

ONA TI A FI LE DA ORO-ISE MO.

  1. Oro-ise ni o maa n jeyo leyin oluwa

.ap

‘mo je eba.’

won gba owo’.

  1. oro ti o ba le tele erun oro-ise ‘n’ gbodo je oro-ise.ap

Ade n ko iwe.’

mama n se obe.’

  1. oro ti o ba jeyo leyin yoo,maa,fi ati ti gbodo je oro-ise.

ap ‘Akekoo yoo se idanwo.’

oluko maa wa.’

Baba ti de’.

  1. oro ti o ba tele atoka iyisodi ‘ko/o gbodo je oro-ise.

Ap

Bayo ko ra aso.

Oluko ko je eba’.

ISORI ORO ISE.

Orisiirisii isori ni awon onimo girama pin oro ise si ninu ede Yoruba.

  1. Oro –ise Agbabo : – ni oro-ise ti a maa n lo abo pelu re ninu ede Yoruba.

Ap

Tolu sun.

Tope kuru.

Ojo ro’.

  1. Oro ise asebeere : – meji naa ni o wa ninu ede Yoruba, awon naa ni da ati nko.

fun apeere

mama da.

Bisi nko’.

  1. Oro ise asokunfa : – Eyi ni oro –ise ti o maa n se okunfa isele, awon oro-ise asokunfa ni; so, mu, se, ko, fi, da.

Apeere

Bola da erin pa mi.

Bade fi iya je Sola.

O se iku pa aja re.

  1. Oro-ise Elela: – Eyi ni oro-ise ti a le fi oro-oruko ti o duro fun abo bo laarin ninu gbolohun.

Apeere

bawi,reje,pada,danu.

mama ba omo wi.

Bola re mi je.

Baba da isu nu.

  1. Oro ise akanmoruko : – Eyi ni a seda lati ara apapo oro-ise ati oro-oruko.

Apeere

Tope muti yo. [mu oti].

mama gunyan je [gun iyan].

Abiola lawo pupo [la owo].

  1. Oro-ise Asapejuwe : – ni oro-ise ti a maa n lo lati so irisi nnkan.

Apeere

Bisi pupa foo.

Eyin Tolu funfun.

Tope ga’.

  1. Oro ise Asoluwadabo : – ni oro-ise ti oluwa ati abo le gbapo ara won.Eyi ni pe a le si oluwa ati abo ni ipo pada laisi iyato ninu gbolohun naa.

Apeere-

Aja n se were.

were n se aja.

mo ti oju.

Oju ti mi.

mo jaya.

Aya mi ja’.

  1. Oro-ise Alapepada: – ni oro ise ti a maa n se apetunpe fun ninu gbolohun.

apeere

Iwo ni o ku mi ku.

E rowa  ro ire.

Aye ko fe ni fe oro.

Ma da mi da wahala.

  1. Oro-ise Asinpo : – ni oro-ise ti o maa n je meji tabi meta ninu gbolohun pelu oluwa kan.iye oro ise ti o wa ninu gbolohun yii ni iye gbolohun ti a le ri fayo.fun apeere.

Ola sun isu ta.

Ola sun isu.

Ola ta isu.

Tope ji eran je..

Tope je eran.

Tope ji eran.

Bolu sare lo gbe aga wa.

  • Bolu sare
  • Bolu lo
  • Bolu gbe aga
  • Bolu wa.

 

IGBELEWON

  1. Ko abuda oro ise mefa.
  2. Ko apeere oro-ise mefa pelu apeere mejimeji.

 

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 115-162

.

ERE IDARAYA

Ere Osupa

Ere Osupa ni eere ti awon omode maa n se ti ile bas u ni akoko osupa. Awon ere bee ni Bojuboju, Ekunmearan, Eye eta Tolongo waye, Bookobooko, Isansalubo, Buuru, Para-Onidemode, Gbadiigbadii, Adendele, Porogun ila Ki ni Hewu, Alo apamo ati Alo apagbe.

 

Ere Ojoojumo

 

Ere Ita Gbangba

Iwonyi ni awon ere ti tomode-tagba n se ni owo osan si irole ni ita. Apeere iru ere bee ni Okoto,  Arin Tita, Ijakadi abbl.

 

Ere Abele

Ere Abele ni awon ere ti a le se a bile. Apeere ere bee ni Alo Pipa, ayo Tita, abbl.

Ayo tita je ere abele ti o wopo laarin awon agbalagba. Awon omode naa maa n se. Eniyan meji ni o maa n ta ayo. Ope ati ota. Ope ni ko mo ayo ta nigba ti ota mo ayo ta daadaa.

Oju mejila ni opon ayo maa n ni. Mefa wa fun ope nigba ti mefa wa fun ota.

 

IGBELEWON

  1. Salaye okan lara ere ita gbanagba.
  2. Salaye okan lara ere abele.
  3. Ko meta ninu ewu ti o wa ninu ere idaraya.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 256-299.

 

LITIRESO APILEKO

 

KIKA IWE APILEKO ORI KETA ATI EKERIN

Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).

IGBELEWON

Sise atupale ori keta ati ekerin.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ko abuda oro ise mefa.
  2. Ko apeere oro-ise mefa pelu apeere mejimeji.
  3. Sise atupale ori keta ati ekerin.
  4. Salaye koko ewi keta ati ekerin.

 

 

 

ISE ASETILEWA

  1. Ewo ni oro-ise ninu gbolohun yii ‘Ade gun keke’(A) Ade (B) gun (C) keke (D) gun keke.
  2. Ewo ni ki i se abuda oro-ise? (A) o je opomulero gbolohun (B) o maa n tle oluwa (C) o maa n tele erun oro-ise (D) o maa n ni agbara.
  3. Oro-Ise akanmoruko ni (A) sare (B) lo (C) ko (D) jeun.
  4. …. je ere abele (A) ayo tita (B) ekun meran (C) ijakadi (D) lakanlaka.
  5. Eniyan meloo ni o n ta ayo ni eekan soso? (A) okan (B) meji (C) meta (D) merin.

APA KEJI

  1. Fun ere idaraya ni oriki pelu apeere
  2. Se akosile abuda oro-ise marun-un pelu apeere.

 

OSE KERIN

 

ONKA  YORUBA

OOKAN  DE EGBAA

 

ONA MEJI PATAKI NI ONKA YORUBA PIN SIN

ONKAYE       (ON – KA – IYE)

ONKAPO       (ON – KA – IPO)

‘m’ ni a fi n da pupo ninu awon onkaye Yoruba mo nigba ti a n fi (i) mo onkapo

 

Apeere

ONKAYE                                                       ONKAPO

Meni (mu eni)                       =          1                      Ikini (iko eni)                        =          1st

Meji (mu eji)             =          2                      Ikeji (iko eji)             =          2nd

Meta (mu eta)                       =          3                      Iketa (iko eta)                       =          3rd

Merin (mu erin)        =          4                      Ikerin (iko erin)        =          4th

Marun-un  (mu aarun          =          5                      Ikarun-un (iko arun)            =          5th

Mefa (mu efa)                       =          6                      Ikefa (iko efa)                       =          6th

Meje (mu eje)                       =          7                      Ikeje (iko eje)                       =          7th

Mejo (mu ejo)                       =          8                      Ikejo (iko ejo)                       =          8th

Mesan-an (mu esan)            =          9                      Ikesan (iko esan)      =          9th

Mewaa (mu ewa)      =          10                    Ikewaa (iko ewa)      =          10th

Mokanla (mu okan-le-ewa)            11                    Ikokanla (Iko-okan-le-ewa)           11th

Mejila (Mu-eji-le-ewa)       12                    Ikejila (iko-eji-le-ewa)=     12th

Metala (mu-eta-le-ewa)      13                    Iketala (iko-eta-le-ewa)      13th

Merinla (mu-erin-le-ewa)   14                    Ikerinla (iko-erin-le-ewa)   14th

—- le mo itumo awon onka marun-un to tele merinla (14) a nilati wo iwaju ki a ri ogun (20) ki a tun woe yin ki a wo iye ti okookan awon onka wonyi (15-19) fi din si ogun bayii.

Meedogun (mu arun-din-ni-ogun)                        15

Ikeedogun (iko-arun-din-ni-ogun)                        15th

Merindinlogun (mu-erin-din-ni-ogun)                 16

Ikerindinlogun (iko-erin-din-ni-ogun)                 16th

Metadinlogun (mu-eta-din-ni-ogun)                     17

Iketadinlogun (iko-eta-din-ni-ogun)                     17th

Mejidinlogun (mu-eji-din-ni-ogun)                      18

Ikejidinlogun (iko-eji-din-ni-ogun)                      18th

Mokandinlogun (mu-okan-din-ni-ogun)              19

Ikokandinlogun (iko-okan-din-ni-ogun)              19th

Ogun (20) da duro funra re, ko si tumo si

eewa meji, o je akanda onka, oun naa ni a mo si okoo

mokanlelogun (mu-okan-le-ni-ogun)                   21

Mejilelogun (mu-eji-le-ni-ogun)                           22

Metalelogun (mu-eta-le-ni-ogun)              23

Merinlelogun (mu-erin-le-ni-ogun)                      24

A o wo iwaju ri ogbon, ki atun woe yin wo iye ti okookan awon onka yii fi din.

Meedogbon (Mu-arun-din-ni-ogbon)                   25

Merindinlogbon (mu-erin-din-ni-ogbon) 26

Metadinlogbon (mu-eta-din-ni-ogbon)    27

Mejidinlogbon (mu-eji-din-ni-ogbon)      28

Mokandinlogbon (mu-ookan-din-ni-ogbon)       29

Ogbon                                                                        30

Bi a o se kaa niyi titi de ori

Ogoji (ogun eji          =          20 x 2             =                      40

Ogota eta (ogun eta)            =          20 x 3 =          60

Ogorin            (ogun erin)    =          20 x 4 =          80

Ogorun-un (ogun arun)       20 x 5 =                      100

Ogofa (ogun efa)      =          20 x 6 =          120

Ogoje (ogun eje)       =          20 x 7 =          140

Ogojo (ogun ejo)      =          20 x 8 =          160

Ogosan (ogun esan) =          20 x 9 =          180

Ogowaa (ogun ewa) =          20 x 10 =       200

Ogowaa yii tun ni akanda oruko kan pataki ninu ede Yoruba

Ilo aadin-(ewa din)

Aadotan (ewa-din-ni-ota)   =          (20 x 3) – 10 =          50

Aadorin (ewa-din-ni-orin)  =          (20 x 4) -10   =          70

Aadorun-un  (ewa din ni orun)      (20 x 5) – 10 =          90

Aadofa (ewa-din-ni-ofa)     =          (20 x 6) – 10 =          110

Aadoje (ewa-din-ni-oje)     =          (20 x 7) – 10 =          130

Aadojo (ewa-din-ni-ojo)     =          (20 x 8) – 10 =          150

Aadosan (ewa-din-ni-osan)            =          (20 x 9) – 10 =          170

Aadowaa (ewa-din-ni-owa)            =          (20 x 10) – 10           =          190

Ogowaa (ogun mewaa)        =          (20 x 10)        =          200

Ti a ba lo isiro ilopo ogun, onka naa lo bayii

220     (200 + 20)                 =          Okoolenigba

230     (200 + 30)                 =          Ogbonlenigba

240     (200 + 40)                 =          Ojilenigba

260     (200 + 60)                 =          Otalenigba

280     (200 +  80)                =          Orinlenigba

300     (200 + 100)               =          Oodunrun

320     (300 + 20)                 =          Okoolelodunrun

340     (300 + 40)                 =          Ojileloodunrun

360     (300 + 60)                 =          Otaleloodunrun

380     (300 + 80)                 =          Orinleloodunrun

400     (300 + 100)               =          Irinwo

420     (400 + 20)                 =          Okoolenirinwo

440     (400 + 40)                 =          Ojilenirinwo

460     (400 + 60)                 =          Otalenirinwo

500     (400 + 100)               =          Eedegbeta (200 x 30) – 100

600     (400 + 200)               =          Egbeta (200 x 3) = 600

700     (400 + 300)               =          Eedegberin (200 x 4) – 100

800     (200 x 4)                    =          Egberin

900     (200 x 5) – 100                     =          Eedegberun

1000   (200 x 5)                    =          Egberun

1200   (200 x 6) (Igba mefa)           =          Egbefa

1400   (200 x 7) (Igba meje            =          Egbeje

1600   (200 x 8 (igba mejo  =          Egbejo

1800   (200 x 9) (igba mesan-an)  egbesan

2000   (200 x 10) Igba mewaa)      Egbawa (egbaa)

 

IGBELEWON

Ko awon onka sile. 700, 710, 720, 730, 740, 750, 760, 770,780, 790, 800

 

IWE AKATILEWA

Mustapha Oyebamji (2006) EKO EDE ATI ASA YORUBA TITUN (S.S.S) University Press Oju iwe 12-15

.

ASA

 

ERE OMODE

Ere omode je ere ti o wopo laarin awon omo keeekeeke, apeere omode ni; eye kiko, sise oko ati iyawo, fifi yerupe se ounje, eye meloo tolongo waye, ekun meran talo wa ninu ogba naa, Booko-Booko,

 

ERE GIRIPA/AGBA

Eyi je ere ti o wopo laarin awon agbalagba. Apeere ere naa ni ayo tita, gidigbo, okoto Tita, ere arin abbl.

 

OFIN TI O DE ERE IDARAYA

Won ki i ta ao si owo eyin

Omo oju ayo kookan ki i ju merin lo.

 

ANFAANI ATI EWU ERE IDARAYA

  1. O maa n fa irepo laarin awon omode.
  2. O maa n se afihan ebun omode
  3. O maa n je ki omode ni iwa akin ati akinkanju.

 

Awon omode maa n ni ipalara.

O le fa ikunsinu.

 

 

IGBELEWON

Salaye ere omode ati ere agba.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 256-299.

 

LITIRESO APILEKO

 

KIKA IWE APILEKO ORI KETA ATI EKERIN

 

 

Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).

 

 

IGBELEWON

Sise atupale ori keta ati ekerin.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Salaye ere omode ati ere agba.
  2. Ko awon onka sile. 700, 710, 720, 730, 740, 750, 760, 770,780, 790, 800

 

ISE AMURELE.

  1. 500 je . [a] egbeta [b] eedegbeta [d] ogorin
  2. 1,000 je [a] egberun [b] eedegberun  [d] ogoje.
  3. Egberin ni (a) 800 (b) 8,000  (d) 700.
  4. Atenumo oro ju ni (a) awitunwi (b) akanlo ede  (d) owe.
  5. Ajayi dudu bi koro isin. Ipede yii je (a) akanlo ede (b) afiwe (d) asorege.

 

APA KEJI

  1. Kin ni owo yiya?
  2. Daruko idi ti a fi n ya owo?

2.Salaye abuda oro aropo afarajoruko merin pelu apeere.

  1. Lo oro apejuwe ni gbolohun marun-un.

 

OSE KARUN-UN

 

AROKO AJEMO ISIPAYA

Aroko ajemo isipaya je aroko ti o gba sise alaye kikun nipa nnkan ayika eni. Bi apeere aroko alaye ekunrere lori bi won se n se ounjeti a feran julo yato si pa ki a se apejuwe re. Apeere aroko ajemo-isipaya ni:

  1. Ise Tisa
  2. Oge Seise.
  • Aso Ebi
  1. Ise ti mo fe lojo iwaju.

Ki a to le ko akoyawo lori okookan ori-oro wonyi, a gbodo ni arojnle ohun ti won je, itumo ati itumo won miiran to farasin tabi ohun ti o ni abuda won. A nila ti wo anfaani ati aleebu ki a si fi arojinle ero gbe won kale.

 

IGBELEWON: ko aroko lori Oge sise tabi omi.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 155-156.

 

ASA

ERE IDARAYA IGBALODE

Opolopo ere idaraya ni o wopo ni aye ode oni. Lara awon ere idaraya aye ode oni ni ludo tita, dirafuti, ere boolu afesegba abbl.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 256-299.

 

APAPO IGBELEWON : –

  1. Salaye ere idaraya aye ode oni kan.
  2. ko aroko lori Oge sise tabi omi.

 

ISE AMURELE.

  1. Ewo ni o je mo aroko ajemo isipaya? [a] omi [b] ore [d] ilu Ibadan.
  2. Ewo no ki i se ara won? [a] eran osin [b] ojo ti ko le gbagbe [d] ile iwe mi.
  3. Toka si eyi ti ki i se ere idaraya ode oni? [a]ayo tita [b] boolu afesegba [d] ludo.
  4. Atenumo oro ju ni (a) awitunwi (b) akanlo ede  (d) owe.
  5. Ajayi dudu bi koro isin. Ipede yii je (a) akanlo ede (b) afiwe (d) asorege.

 

APA KEJI.

  1. Ko apeere aroko ajemo isipaya mejo sile?
  2. Salaye ere idaraya ode oni.

 

OSE KEFA

ORO AROPO AFARAJORUKO

Oriki

  • Abuda oro aropo afarajoruko
  • Irisi oro aropo afarajoruko.
  • AKOONU : –

Oro aropo-afarajoruko ni isesi to frajo ti oro-oruko sugbon o mu eto iye ati eni lara abuda oro aropo oruko.Awon oro aropo afarajoruko ni wonyii; – emi,iwo,oun,awa,eyin, awon.fun apeere.

Emi ko ri Bola.

Ile awa dun.

Abuda oro aropo afarajoruko.

  1. Oro aropo afarajoruko ni eto iye ati eni.

Ate oro aropo afarajoruko.

 

IYE                       EYO                OPO.

Enikin-ni             emi                  awa

Enikeji                 iwo                  eyin

Eniketa                 oun                 awon.

Fun apeere : – iwo ni won ran

Awa naa n bo.

  1. A le lo oro asopo lati so oro aropo afarajoruko meji papo.apeere.

emi ati iwo.

Awa ati eyin.

iii. Oro aropo afarajoruko le jeyo pelu awon wunren bii da,nko,ko.Fun apeere

iwo  n ko?

Oun da?

Eyin ko.

  1. Silebu meji ni oro aropo afarajoruko maa n ni.apeere.

emi – e /mi.

iwo – I /wo.

 

  1. Oro aropo afarajoruko le gba eyan.Apeere

emi naa wa.

Awon gan-an wa.

  1. A le gbe oro –aropo afarajoruko saaju wunren akiyesi alatenumo ‘ni’ fun apeere
    1. Eyin ni oga n pe.
    2. emi ni mo ra iwe naa.

 

IRISI ORO AROPO AFARAJORUKO.

Ise oluwa ni oro aropo afarajoruko maa n se ninu gbolohun.ap.

Emi naa mu osan.

Oun ni won n bawi.

 

IGBELEWON

Lo okookan awon oro aropo afajoruko ni gbolohun.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S. 3 Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 147-150.

ASA

 

OWO YIYA

  • Oriki
  • Awon idi ti a fi n ya owo
  • Anfaani ati aleebu owo yiya.

AKOONU : –

Owo yiya je wiwa

iranlowo owo lo si odo elomiran ti a mo pe o ni ju wa lo ni akoko isoro.Se bi ko ba nidii obinrin kii je kumolu,bi ko ba nidii eeyan o le deede lo ya owo.Eyi ni awon idi Pataki ti eeyan fi maa n ya owo laye atijo.

  • Inawo pajawiri
  • Aisan
  • Oran dida
  • Oku agba.

ANFAANI OWO YIYA.

  • Owo yiya maa n bo ni ni asiri lojo isoro.
  • Ki I je ki eeyan di eni yepere tabi eni yeye lowo awon eeyan.

ALEEBU.

  • Owo yiya kii fi ni lokan bale.
  • Ele gegere ori owo ki I je ki eni yawo tete bo ninu gbese.
  • O maa n soro lati le ri owo ti a ya san pada.
  • Owo yiya miiran le fa fifi nnkan ini tabi omo wa duro
  • Awon ona ti a n gba ya owo ni aye atijo.

AKOONU : –

Awon ona ti a n gba ya owo laye atijo ni; –

  • Kiko owo ele: – eyi ni ki a ya owo,ki a si gba lati maa san ele lori owo ti a ya.
  • Fifi nnkan ini duro tabi dogo: – eyi ni fifi nnkan ini wa duro,o le je ile,ile tabi moto sugbon ti eni ti o ya owo ko ba ri owo san won le gbe nnkan ini re ta dipo owo ti o ya.Iru owo bayii kii ni ele lori.
  • Fifi omo kowo tabi sofa : – eyi nip e iwofa yoo maa se abose loko olowo titi yoo fi ri owo ti won ya san.ise ti iwofa n se fun olowo duro gege bi ele lori owo ti o ya.

 

IPA TI ONIGBOWO N KO.

Onigbowo je alarinna laarin eni to fe ya owo ati eni ti o fe ya eniyan lowo,onigbowo yii ni o maa duro fun eni to feya owo.Sugbon ti eni to ya owo ko ba ri I san onigbowo yii ni won yoo maa wo bi won ba ti n wo o bee ni oun naa yoo maa ni eni ti o duro fun lara.

 

IGBELEWON

  1. Ko aleebu merin nibi owo yiya.
  2. Ko aafaani owo yiya meta sile.
  3. Salaye ona ti won gba gbese.

 

LITIRESO

EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN IRONU ;

  • ESE IFA
  • AALO APAGBE

AKOONU

Ese-Ifa

Ewi atenudenu Yoruba kun fun ogbon, ironu ati iwoye tabi akiyesi awon baba-nla wa, okookan awon ewi yii lo si je orisun ironu,agbara, ati imo-ijinle Yoruba.

Ero ati akiyesi Yoruba.

Awon  Yoruba gbagbo pe nigba ti eeyan ba n bow a si ile aye lati orun,yoo kunle si iwaju Olodumare lati yan ipin, ipin yii ni ori ti eeyan mu waye, ti o je mo gbogbo ohun ti yoo sele sioluware laye, titi kan ohun ti eniyan yoo da, ojo iku re, ati iku ti yoo ku pelu, eyi ni o mu gbolohun w ape;

‘A kunle, a yanpin

A kunleyan ni adayeba

Ero Yoruba ni pe Orunmila, baba Ifa, wa ni odo Olodumare nigba ti olukuluku n yan ipin tire, nitori naa ni a se pe e ni Elerii ipin. Gbara ti eeyan ba si ti de ile-aye lo ti gbagbe iru ipin ti ti o yan waye.

Lati mo bi ojo iwaju yoo ti ri ati lati wadii nipa ohun kan ti a fe dawole, tabi lati wa ona lati jade ninu isoro kan, odo Ifa ni eeyan yoo lo lati lo se ayewo, ero awon Yoruba ni pe Orunmila lo ranti iru ipin ti onikaluku yan waye, oun lo si le ba ni se atunnse si oro eni.

Idi niyi ti won fi n kii ni

Okitibiri, Apajo –iku-da

Atori-alaisunwon se.

Imo-ijinle Yoruba

Ese-Ifa-; je akojo ogbon ati imo-ijinle Yoruba lati irandiran. Ko si ogbon tabi imo –ijinle nipa ohunkohun ti a n wa ti ko si ninu odu ati ese-ifa. Ko si isorokisoro ti o de ba eda laye tabi ohunkohun ti eda le fe se iwadii re ti apeere re ko si ninu ese-Ifa. Nitori naa, ni o fi je pe nigba ti eeyan ba lo se ayewo lodo babalawo, babalawo yoo difa lati mo odu ati ese Ifa ti oro oluware yan. Babalawo yoo so itan latinu ese Ifa, iru eni ti iru re ti sele si ri ati ohun ti o se si oro naa, yoo si so fun eni naa lati se bee gege.

Afihan agbara  Yoruba

Agbara nla ni imo ti a fun Orunmila, baba Ifa, lati ode-orun gege bi Elerii ipin, lati le mo ohun ti o le sele si laye ati lati ba eda wa atunse si oro re.

Afihan agbara yii tun han nipa aroko ti itan inu Ifa pa fun eni to wa se ayewo, nigba ti babalawo ba n so itan eni ti nnkan yii ti sele si ri lati inu ese ifa, eni ti o wa se ayewo gbodo fi ara re si ipo eni ti a n so itan re, ki o si fi okan sip e bi onitoun yanju isoro re ni oun naa yoo yanju isoro toun, yoo si gbiyanju lati se gbogbo ohun ti won ba ni ko se nipa ti ebo riru, yoo si ri ona abayo, oro re yoo si dayo.

IGBELEWON

  1. Salaye ayolo isale  yii

“A kunle a yanpin

Akunleyan ni  adayeba.

 

APAPO IGBELEWON : –

  1. salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete,iv. Eni ti o pokunso.
  2. Ko orisii ewi gege bi orisii itan isedale Yoruba.
  3. Awon nnkan wo ni a maa n se ayewo re ti a ba n ko aroko?

 

IWE KIKA.

  • Iwe imodotun Yoruba odun kin-in-ni oju iwe 136,142,151.
  • Eto iro ati girama Yoruba.0.i 99.

 

 

ISE AMURELE.

  1. ——- je okan lara awon ona ti a n gba ya owo laye atijo. [a] yiya owo ele [b] yiya owo ni banki [d] yiya owo ninu apo egbe.
  2. Iwofa yoo maa se ——— loko olowo [a] ise [b] abose [d] agbase.
  3. Eyin ni won n pe. Oro aropo afarajoruko inu gbolohun yii ni ———

(a) won   (b) pe  (d) eyin.

  1. eyo ni (a) emi (b) awon (d) eyin.
  2. Awa je (a) emi (b) awon (d) eyin.

 

 

APA KEJI

  1. Kin ni owo yiya?
  2. Daruko idi ti a fi n ya owo.

2.Salaye abuda oro aropo afarajoruko merin pelu apeere.

Ko koko ohun ti ewi apileko ti o ka dale lori.

 

OSE KEJE

 

GBOLOHUN ONIPONNA

ITUPALE GBOLOHUN ONIPONNA.

  • Oriki
  • Ibi ti o ti n jeyo.
  • Apeere/itupale oro-oniponna ninu gbolohun.

AKOONU : –

Gbolohun oniponna-; ni gbolohun ti o ni ju itumo kan lo.gbolohun oniponna le je eyo oro tabi apola kan ni o maa ni ponna.

Itupale eyo oro oniponna ninu gbolohun.

Ayo ko le da mi. o tumo si pe

.        Ayo ko le da mi [ se eda mi ].

Ayo ko le segun mi.

Isu rira ni Badejo gbin.Tumo si-

isu ti o ti ra[baje] ni Badejo gbin.

Isu ti o ra ni oja ni o gbin.

Ogun ile ni Ariyibi gbonju ba.tumo si  pe-;

ile ogun ni  Ariyiibi gbonju ba[20],o tun le tumo si

ogun ile ti oloogbe fi sile ni Ariyibi gbonju ba.

Itupale apola oniponna ninu gbolohun.

Gbolohun                                          Itumo

Ayo wu mi                                Mo feran Ayo

Mo  fe idunnu

Omo Akin                                  Omo ti Akin bi.

Akinkanju omo.

Omo-ise Akin.

Iya aje naa ti de                        Iya ti o bi iya aje.

Iya ti o je aje gan-an ti de.

Akanlo-ede oniponna

Mo buta                                     Mo jeun

Ki a fi owo bu ata si inu nnkan

Oba waja                                    Oba ilu ku.

Oba ilu wo inu orule ile lo.

 

IGBELEWON

Se itupale fun awon gbolohun isale yii

Eran afoju naa ti jade

 

  • Owo sinkun tite omo ole ifo.
  • Ode aperin da iyepe lu abami eda naa ni oju ese.
  • Baba ru agbe emu merin lo si oja.

 

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I  226-230.

 

ASA

ONA TI A N GBA GBA GBESE NI AYE ATIJO

AKOONU: –

Eyi ni orisiirisii ona ti awon Yoruba n gba lati gba owo ti ajegbese je pada lowo re leyin ti akoko to da ti koja.Awon ona naa niwonyii

  • sisingbese
  • didogo ti ajegbese ati fifooro emi re titi yoo fi ri owo ti o ya san.
  • Riran elemun-un
  • Gbigbe edan lo sile ajegbese

 

SISINGBESE : – Eyi nipe olowo ti ajegbese je lowo yoo funra re to onigbese lo tabi ran elomiran si I lati ran-an leti pee to ni ki o wa.

IDOGOTI : – Eyi ni diduro ti ajegbese ati fifooro emi re titi ti yoo fi ri owo san.Bi o fe jeun,won a gbe ounje niwaju re,bi o fe to tabi yagbe yoo telee lo sibe bayii ni won yoo se maa yo o lenu titi ti yoo fi wa owo won san.

 

RIRAN ELEMU-UN : – Ti gbese ti ajegbese je ba ti pe ti o si je eyi ti a n ta ewure tabi agbo le ka,olowo yoo seto ki gende kunrin kan ki o ba oun mu ohun osin ni agboole ajegbese tita ni ohun osin naa yoo da lati fi ri owo ropo gbese ti ajegbese je sugbon ki I se dandan ki o je ohun osin.

Elemu-un ni a n pe gende kunrin ti olowo ran nise yii.

 

GBIGBE EDAN LO SILE AJEGBESE: – Laye atijo eru jeje ni awon egbe ogboni je fun awon ara ilu nitori naa ti olowo ba loo fi ejo ajegbese to taku sun awon ogboni,awon ogboni yoo fi edan[amin ase ogboni]ran onise si ajegbese naa,itunmo eyi nip e ki ajegbese naa o maa bo wa si ile ogboni won a da si oro gbese naa,won a si pase fun ajegbese naa ki o san owo yii eru won nii mu ajegbese wa ona kiakia lati san gbese.

IFIBIYA : – Olowo yoo ra oja lowo ajegbese tabi lowo ebi re ti o to iye owo ti o je e, yoo si so fun eni ti o ra oja naa lowo re pe ki o lo gba owo lowo ajegbese oun.

 

IGBELEWON : –

  1. Kin ni gbolohun oniponna?
  2. Daruko awon ona ti a n gba lati gba gbese ni aye atijo.

 

APAPO IGBELEWON : –

  1. (a) Kin ni gbolohun oniponna?

(b) ko apeere gbolohun oniponna marun-un sile

  1. Daruko awon ona ti a n gba lati gba gbese ni aye atijo

 

 

 

 

 

 

LITIRESO

EWI ALOHUN GEGE BI ORISUN AGBARA ATI IMO IJINLE YORUBA

– OFO

– OGEDE

– ITAN RIRO

AKOONU

Ewi alohun je orisun fun ofo ati ogede nitori pe  ohun enu ni a fi gbe awon ewi yii jade.

Oro ni ofo,apa kan oogun si ni.oun si ni eniyan fi n mu ohun gbogbo ni ayika re wa ni ikawo re,yala ohun to lemii tabi eyi ti ko ni.

Ofo je mo pipe awon oro enu bi a se n pe e latayebaye laiyi pada ati pipe awon oro naa ni aimoye igba.Ofo ni awon miiran maa n pe ni ogede,bi ofo se wa fun ire naa ni o wa fun ise ibi.

Yoruba gbagbo pe ohun gbogbo to wa ninu aye yii lo ni agbara tire bi o tile je pe agbara inu okan ju ti ikeji,Iru ero yii lo fa pipa orisii ewe,egbo,eepo igi ati awon nnkan miiran po se oogun fun anfaani eniyan.

Agbara oro ti a fa yo ninu oruko ti a fun ohun-elo oogun kookan ni o wa ninu ihun ofo ti a pe si oogun naa.

Bakan naa ni gbolohun maye maa n wa ninu ofo pipe.

 

Ero awon Yoruba ni pe gbogbo ohun to wa laye lo ni oruko asiri,ti eniyan le mo ,to le fi pe ohun naa lati sise ti eniyan fe.Bakan naa ni pe ti eeyan ba mo orirun tabi iseda nnkan, eeyan le lo won fun anfaani tire.

Gbogbo eleyii lo si maa n je ki oogun o je kiakia.okan ninu agbara Yoruba niyi,ninu ofo oke yii ni a ti fa oro-ise yo lara  oruko ti a fun ewe tabi ohun elo ti a papo se oogun naa.

Ap

Eni ba dari so apa,apa a pa a

Eni ba dari so Iroko,iroko a ko o

Eni ba dari so Oruru

Se ni won-on ru u bo oko.

Eni ba dari so emi lagbja,omo lagbaja

Ojiji lada ba igi eba ona

Ojiji ni ka gbo kuu re,ko dero orun.

Ninu ohun-elo ti won lo fun oogun yii ni eepo igi apa,eepo igi iroko,eepo igi oruru ati eeku ada,ati awon ohun elo miiran.Oluranlowo ni ofo je fun oogun,o maa n ba oogun sise ni.

 

IWE KIKA

Eko Ede Yoruba Titun. Iwe keji oju iwe 39-43.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Iyato meloo ni o wa laarin ofo ati ogede? Se alaye kikun.
  2. Pelu alaye kikun bawo ni itan riro se je orisun agbara Yoruba.
  3. Ko ona merin ti a n gba gba gbeses?

 

ISE AMURELE

  1. Nibo ni won maa n sin oku oba si laye atijo?

(a) aafin  (b) koso    (d) Bara

2.______ ni won fi maa n tufo oku oba?

(a) ekun     (b) fere okinkin ati ilu koso     (d)  orin

  1. Bi won ba n lo sin oku oba ona meloo ni awon ijoye ti maa duro?

(a) mokanla    (b) mejila  (d) mewaa.

4.______ je orirun fun ofo ati ogede

(a)oro      (b)  orin (d)ewi alohun.

5._______  ni oruko oloye ti oye re je mo isinku oba

(a)Abobaku  (b)Asetutu oba  (d)Ona onse-awo.

Apa keji

1.Salaye lekun-un rere bi a se n sin oku oba.

2.Pelu apeere salaye ohun ti ofo tabi ogede je.

 

OSE KEJO

AROKO ASARIYANJIYAN

AKOONU : –

Iha meji ni aroko alarinyanjiyan gbodo ni,iha beeni ati iha beeko.Iha eyi ti a faramo ati eyi ti a ko faramo.Eyi ni wi pe akekoo yoo gbenuso fun egbe kin-in-ni ti o faramo,oun kan naa ni yoo se atako fun eyi ti ko faramo.

Akekoo gbodo soro lori egbe mejeeji bi o tile je pe yoo fi si ibi kan ju ibi kan lo.Akekoo koko gbodo soro lori egbe ti ko faramo lori awon ohu n ti o dara ti o wa nibe,yoo wa soro lekunrere lori iha ti o faramo gbogbo awon ohun ti o ba so nibi ni yoo fibi ohun ti o wa ninu koko eyi ti ko faramo subu,ibi ni yoo ti fi idi iha ti o yan mule.

Akekoo gbodo fi idi iha ti o yan mule ninu igunle aroko re.A ko gbodo so itan tabi pa aalo ninu iru aroko bayii.

ETO INU ARIYANJIYAN

Gege bi ohun ti mo so saaju,nigba ti akekoo ba fe tako ero elomiran nipa koko kan, ohun ti yoo se ni sise-n-tele niwonyi

  • Ki o toka si ero elomiran naa ni soki.
  • Ki o so idi re ti o fi tako ero naa,eyi gbodo je pelu ekun rere alaye.
  • Akekoo yoo wa gbe ero tire kale ni eseese, ki koko re wa ni ipari ohun ti o ba ko.

      ILO EDE

Akekoo gbodo sa awon oro inu gbolohun re lo lona ti onkawe/oluko yoo fi maa fokan baalo.

Iru awon gbolohun wonyi dara lopolopo fun ariyanjiyan sise

-Ero awon kan nip e———    sugbon eyi ko ri bee nitori pe

– Ati gbo pe——-  bi o tile je pe

-Awon kan gbagbo pe——–  sugbon won ti gbagbe pe——-

-Awon elomiran ro wi pe———    sugbon won ti gbagbe pe

Akekoo gbodo lo akoto ode oni lati gbe ise re kale.

Siwaju si i, owe naa wulo fun ariyanjiyan sise, nigba ti a ba ti lo won lona ti o to ti o si ye.

Apeere ori oro aroko alarinyanjiyan ni : –

Owo legbon,omo laburo.

Iyawo kan dara loode.

Kiko ede abinibi san ju kiko ede okeere lo.

Ise adani mowo wole ju ise akowe lo.

Dokita wulo fun ilu ju agbe lo.

Igba eerun dara ju igba ojo lo.

Ohun ti okunrin le se,obinrin naale se e.

Nje o to ki obinrin abileko maa sise ijoba?

Nje o to ki a maa pa awon adigunjale?

 

IGBELEWON

Se ilapa ero fun ori-oro yii

Ise adani mowo wole ju ise osu lo.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S. 1. Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 182-188.

 

ASA

ASA ISINKU NI ILE YORUBA

Awon Yoruba gbagbo pe gbogbo wa ni a da agbada iku,won a ni ‘ma forum yo mi gbogbo wa la jo n lo.’atomode atagba ko si eni ti ko ni ku,gbogbo wa la je gbese iku.Ki Olorun ko fi iku rere pa ni.

Awon Yoruba gbagbo pe bi eniyan ba ku yoo lo si orun,yala rere tabi orun apaadi.

AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.

AKOONU : –

Ki Edumare ki o fi iku ire pa gbogbo wa bi a ti n sin oku kookan da lori eni ti o je ati iru iku ti o pa eni bee.Die ninu iru re niwonyii.

Eni ti sango pa.                           Awon mogba nii se etutu  sisin re.

Eni ti sanponna pa                                 inu igbo ni won maa n sin-in si awon adahunse n

sii se etutu sisin re.

eni ti o ku sinu odo                            eti odo ti o ku si ni won maa n sin –in si,awon

alawo ni si n se etutu re.

eni ti o ku  toyuntoyun                    awon oloro nii se etutu sisin re.

Adete                                                  awon ogbontarigi  adahunse ni i se etutu sisin re,inu

Igbo ni won a sin-in si, won a si sun gbogbo nnkan                                                                    Ini re.

Eni ti o pokunso                               Awon onimole ni i sin in,idi igi ti o pokunso si naa

ni won o sin in si.

Abuke                                                            Awon babalawo ati adahunse ni i se etutu sinsin re,

Inu igbo ni won sin in si, ninu ikoko,won a si sin

Gbogbo nnkan ini re mo pelu.

Babalawo                                           awon agba awo ni i se etutu sisin oku babalawo

pelu eye ti o ga ti won yoo fi se etutu lati yose re

kuro ninu egbe awo.

Ode                                                     awon ode nii se ayeye oku ode sisin,oro pataki

ti Won ni lati se fun un ni sisipa ode ti a mo si ‘ ikopa ode’ eyi ni etutu ti won maa  n se ki awon eran ti ode naa ti pa nigba aye re ma baa hun un,ki o sile je ki awon ode to ku laye maa ri eranko.

Onilu                                                  awon onilu nii se etutu onilu lati yowo elegbe won

ti o ti ku kuro ninu egbe ki awon to ku le maa ri se.

Alagbede                                           Awon alagbede nii se oro igbeyin fun oku alagbede

lati yowo re kuro ninu egbe.Inu ile aro ti alagbede

naa ti n sise ki o to ku ni a ti maa n saba se etutu

Ikeyin yii.

Yato si gbogbo awon wonyii,awon Yoruba a maa ro oku paapaa eyi ti o ba je oku oroju ti

won gba pe iku re kii se lasan,awon agba adahunse tabi oloogun ni o maa n ro oku, ki

won to gbe e si koto, riro yii lo maa je ki o se iku pa eni ti o pa a.   .

IGBELEWON : –

salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete iv. Eni ti o pokunso.

 

LITIRESO

EWI ALOHUN TO JE MO ASA ISINKU

Ewi alohun-;je ewi ti a jogun lodo awon baba –nla wa,nitori pe awon Yoruba je eya to feran ewi lopolopo,bi won se ni ewi fun asa isinku naa ni won ni ewi atenudenu fun orisiirisii ayeye to ku.

Lara awon ewi atenudenu ti a ya soto fun isinku ni;

Oku pipe

Igbala sisin

Iremoje.

Bakan naa ni won le lo awon ewi atenudenu miiran fun ayeye isinku, ki i  se dandan ki o je awon ti a ko soke yii nikan.

Oku  pipe

Yoruba ka iku si ohun ibanuje pupo. Nigba ti iku ba de, igbe ekun a gba ile,okiki a gba ode.Awon eniyan yoo bere si pohunrere ekun, won yoo si maa so orisiirisii ohun ti o ba bo si won lenu, lati fi edu okan won han.Iru ekun bayii ti awon agbalagba obinrin maa n sun ti won si maa fi n pe oku bi eni pe ko dide soro ni a n pe ni oku pipe.

Ohun ti o maa suyo ninu ewi tabi arofo oku pipe ni

– iwa ati ise eni ti o ku.

– irisi re

– itan igbesi aye re

– awon aseyori re

– oriki-orile

– ise re.

Bi eniyan ba teti si oku pipe yoo mo oruko eni ti o ku,awon obi re,oruko awon omo re ati oruko awon aya re(bi o ba je okunrin) tabi oruko oko re(bi o ba je obinrin).Gbara ti oku ba ti ku ni arofo oku pipe yoo ti bere titi di igba ti won yoo sin in.

Asiko ti enikan ba ku ni a o maa gbo ninu oku pipe bi o se lawo to, bi o se je oninu-un-re to,bi o se ko eniyan mora to abbl.

Eyi ni apeere oku pipe

A a ri ni lode a a beere

A a ri ni lode a a beere

Ki n poloro mi ku,  abo sun ni?

Abinbolu Akanji lo gbaa n o rii?

Baba Foyeke,baba Ejire fi mi sile lo sorun alakeji.

Iku gboko lowo mi po o.

Iya nla je mi n o lolugbeja

Iku pomo Farounbi

O lo ba baba to bi i lomo

Akanbi omo olu-oje

Omo olomi tutu ese oke.

Bi a ba wo apeere oku pipe ti a fun wa yii, a o ri i pe gbogbo awon ohun ti a menuba pata ni o wa nibe.

Iremoje ni ewi atenudenu ti awon ode maa n lo lati dagbere fun ode egbe won ti o ba ku ati lati yo ese re kuro ninu egbe ode ti aye.

 

IGBELEWON

Daruko awon koko ti o maa n jeyo ninu oku pipe pelu apeere.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S. 1. Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 106-112

 

APAPO IGBELEWON

  1. Daruko awon koko ti o maa n jeyo ninu oku pipe pelu apeere.
  2. Ko apeere ewi alohun ti o je mo asa isinku.

 

ISE ASETILEWA

1.Leta ——— ni a maa n ko si ore,ara,ebi ati ojulumo.

(a) eni mimo    (b) gbefe   (d) aigbagbefe

2.Adiresi meloo ni leta si ore wa maa n ni?

(a) kan    (b) meji   (d) meta.

3———- ni ewi atenudenu ti awon ode maa n lo lati dagbere fun ode egbe won.

(a)oku pipe   (b) igbala    (d) iremoje.

4.Okan lara ohun ti o maa n jeyo ninu oku pipe re ni ———

(a)oriki oku  (b) iwa re (d) iye ile ti o ko.

5.ojo——— isinku ni won maa n yo ese obinrin agba kuro ninu ebi.

(a) keta     (b) kejidinlogun   (d) kejidinlogbon.

 

APA KEJI

1.Ko leta si ore re,ki o si salaye fun un nipa ile-iwe re titun ti o wa bayii.

2.Daruko awon ewi atenudenu ti a n lo fun oku pipe.

b.Salaye koko ti o maa n je jade ninu won pelu apeere

 

 

 

 

 

 

OSE KESAN-AN

AKAYE 1

Bi a ti se mo pe asa je ihuwasi, isesi ati ibasepo awon eniyan ni agbegbe kan. Ara asa ni ounje ti a n je, aso ti a n wo, ikini, igbeyawo, isomoloruko ati iteriba fun agbalagba.

Asa ijo jijo eyi ti o maa n suyo ninu tilu-tifon yala nibi ayeye isile, igbeyawo ati ikomojade tabi ni idi orisa Sango, Obatala, Orunmila ati bee bee lo se pataki. O ni bi a ti n tase agere si awon orisiirisii ilu ati orin ile Yoruba, bi a ti n repa-rese ti a si n gbe genge owo ijo si ilu bata yato gedegbe si bi a ti n gbepa-gbese si ilu dundu nidii Ogun. Eyi lo fa a ti a fi n so pe Onisango  to jo ti ko tapa ta abuku  ara re.

Awon eegun alarinjo ni won maa n fi orin, ijo ati idan pipa da awon omo kaaro-oo-jiire lara ya laye atijo sugbon olaju ati imo ero ni aye ode-oni ti so o di ere ori-itage, ori ero asoromagbesi ati ti amohun-maworan. (NECO 2002)

  1. Ohun ti a ko ka kun asa gege bi a ti se ka a ninu ayoka yii ni (A) aso wiwo (B) igbeyawo (C) ihuwasi (D) imo ero (E) ounje jije.
  2. Ijo jijo maa n suyo nibi (A) ayeye (B) ikini (C) imo ero (D) iteriba (E) olaju
  3. Awon ti o n da omo kaaro-oo-jiire lara ya ni (A) Eegun alarinjo (B) Obatala (C) Ogun bibo (D) Orunmila (E) Sango
  4. ‘’so o di ere ori-itage …. ‘‘ ‘’o’’ n toka si (A) asa Yoruba (B) Obatala (C) orin, ijo ati idan pipa (D) Orunmila (E) Sango bibo.
  5. Akole ti o ba ayoka yii mu ju ni (A) ijo jijo (B) ikomojade (C) oosa bibo (D) igbepe-igbese (E) tilu-tifon.

AKAYE 2

Ajike ati Bola se igbeyawo ni nnkan bi odun mefa seyin. Bola je omo odun ogbon nigba ti o laya, o fi odun  meji ju iyawo re lo. Laarin odun mefa yii, Bola ti di oga agba ni ile itaja kan ni Eko. Won n sanwo daradara fun un nibe, bee ni awon to n raja naa si maa n fun un lebun. O maa n gbebun lowo awon onibara kookan, o si maa n ko ebun opolopo to ba tan-mo-on pe iru ebun bee yoo mu ki oun se ojusaju lenu ise oun. Lara awon to maa n ba raja ni Dele ati Ayoka. Ilu ni won, ero won si ni pe oko-kan-kun-koboodu. O to odun meta ti okookan won ti kuro nile oko.

Bola sakiyesi pe Dele ati Ayoka ko se e dara de afi bi oluwa re ba fe kan abuku. O maa n se won daradara sugbon ki i gba ebun lowo won. Awon naa se akiyesi iwa Bola yii nitori won mo  pe o maa n gba ebun lowo awon kan. Won pinnu lati fa oju re mora sugbon bi eyi ko ba se e se, won yoo wa ona atisakoba fun-un. Lodi si iru ajosepo bee, Dele dibon pe oun ko mo nipa oro to n lo. O fi ebun ran Tadese, eni ti Bola tele nibi ise sugbon Bola fi towotowo ko ebun naa.

Bola fi ete onibara re to iyawo re leti, won si pinnu po lati fi adura ati isera bi ogun esu wo. Loooto, onise awon araabi je. Gbogbo eru ibi ise to wa labe akoso Bola ni awon kan ko loru ojo kan. Awon onise ibi pa ode kan, won si sa awon marun-un yooku yannayanna. Won fi isele yii to awon olopaa leti, iwadii si bere  ni kiakia. Bola ati awon omo ise re di ero atimole lagoo olopaa. Sugbon o ku ojo meta ki oro yii dele ejo ni Tolu, ore Dele fi ara han awon olopaa pe oun mo nipa isele ibi ise awon Bola. Oun le so bi isu se ku ati bi obe se be e. Laipe, owo te Dele, Ayoka ati awon isongbe re, Ooto leke ran Tolu ni ewon odun mefa, o si dajo iku fun awon yooku, Bola naa si gba ominira.

  • ki ni Olorun fi ta Bola lore? (a) owo (b) iyawo (c) omo (d) igbega.
  • Bola n sise ni …… (a) ile itaja (b) ago olopaa (c) kootu (d) soosi.
  • Omo odun meloo ni Ajike nigba ti o loko? (a) mejilelogbon (b) ogbon (c) merinlelogbon (d) merindinlogoji.
  • Ta ni oga Bola? (a) Dele (b) Tolu (c) Tadese (d) Ootoleke.
  • Bola ko ebun awon onibara re nitori pe (a) owo osu re po (b) o fe yera fun abuku (c) ko f eta oja fun won (d) ko fe ni won lara.
  • ‘onitohun’ toka si (a) Ayoka (b) Dele (c) Bola (d) Tadese.
  • Leta ti Ayoka ko fi han gege bi (a) oninuuru (b) osonu (c) alapepe (d) apaniyan.
  • ‘O’ ti a fala si nidii n toka si (a) Tadese (b) Dele (c) Bola (d) ayoka.
  • ……. ni Ootoleke (a) olopaa (b) ontaja (c) ode (d) adajo.
  • Ewo ni ooto? (a) Ajike je oga dele (b) Bola je onibara ayoka ati Dele (c) Bola gba awe ati adura (d) awon ode pa ole.

 

ASA

ASA ISINKU NI ILE YORUBA

-ISINKU OBA ATI ABAMI EDA.

AKOONU

Bi a ti n sin oku oba yato patapata si bi a ti n sin oku eniyan lasan.Awon oba alade po ni ile Yoruba,bi a si ti n sinku oba ni ilu kan yato si ti ikeji, ati pe ipo oba kan yato si ara won. Isinku Alaafin ni a o fi se apeere.

Ilu ati ibon yiyin ni  a fi n tufo oba ati arugbo,won ki i tete tufo oku oba, ki awon omo to fi to awon oloye leti ni won yoo to palemo gbogbo ohun ti o ba je ohun ini ti oba ni won yoo ti palemo.

Leyin eyi ni awon omo oba yoo lo so fun awon ijoye pe ara baba awon ko ya, nitori pe won ko ni ase lati so fun won pe oba waja.Nigba ti awon ijoye ba de aafin ni won yoo to mo pe oba ti gbe emi mi, a ki i so pe oba ku, nitori pe oba ki i ku,oba wo aja-ile.A tun le so pe erin wo,opo ye tabi ile baje.

Gbara ti oba ba ku,ni awon ijoye ati awon agbaagba ti ise tabi ipo oye won ba je mo isinku oba, yoo ti bere etutu ati oro –isinku oba nitori pe aki i sinku oba gege bi a ti i sinku eniyan lasan.Oku gbogbo ilu ni oku oba,ni Oyo ilu koso ati fere Okinkin ti a fi eyin gbe.

Ni Bara ni won maa n sin oku Alaafin si ni aye atijo,lale si ni won maa n se eto oku naa,opolopo etutu ni won o ti se.

Ona-Onse Awo ni oloye ti ipo oye re jemo isinku oba Alaafin.Oloye yii ni yoo ge ori oba to waja,inu yara kan to wa laafin, ti a n pe ni ile ori ni yoo gbe ori oba si fun ilo oba ti yoo tun je tele e.

Bi won ba fe lo sin oku oba to ku ni Bara, won a fon fere Okinkin,a o si lu ilu koso lati so fun awon ara ilu  pe oba n re ile igbeyin lati lo sun.

Ibi mokanla ni awon oloye to gbe oba yoo ti duro ki won to de Bara nitori pe ibe jinna die si aarin ilu.Nibi kookan ti won ba ti duro si ni won yoo ti fi eeyan kan ati agbo kan rubo.

Koto ti a o sin oku Alaafin si maa n fe pupo,yoo gun daadaa,bee ni yoo si jin gidi nitori opolopo nnkan ti a o sin pelu re,aso dudu ati aso funfun ni a fi n sinku oba Alaafin.

Bi won se n sinku oba ni pe won a te oku oba si aarin koto ti a gbe,leyin eyi won a pa obinrin mejo,won a te merin si igberi re ati merin si igbase re .won a tun pa awon giripa okunrin merin,won o te meji si egbe re otun ati osi,leyin eyi ni won yoo wa ko oku awon mokanla ti a fi rubo loju ona,ki a to de Bara sinu koto nla naa.

Awon metalelogun ti a sin pelu oba ni won gbagbo pe yoo maa se iranse fun oba lona orun ati ni orun nibi ti o n lo.

Igbagbo won ni pe ipo ti oba wa laye ni yoo wa ni orun,nitori naa oba  ni lati ni opolopo obinrin  ati iranse.leyin gbogbo re ni won yoo pa eni ti o gbe ina lowo ti a fi se gbogbo eto isinku yii,won yoo gbe oku re pelu awon iranse ti o wa ninu koto.

Awon iyawo,omo,ore,ati ebi yoo wa bere si ko ebun,ounje ti won ko way ii ni won lero pe yoo wulo fun oba lona irin-ajo ti o n lo.leyin gbogbo eyi ni won yoo wa ro eepe bo gbogbo ohun ti o wa ninu koto.

Ayipada ti de ba bi a ti n sin oku oba laye ode-oni,won ko fi eniyan se etutu mo ni ilu oyo esin ati maluu ni won n lo bayii.

 

LITIRESO

KIKA IWE TI IJOBA YAN.

IWE KIKA-;

Eto Iro Ati Girama Fun Ile-Iwe Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.o.i 75.

ISE ASETILEWA

AKAYE KIN-IN-NI

Ka awon ayoka wonyi, ki o si dahun awon ibeere ti o tele won.

Igba oye je igba ti awon eniyan koriira ni ile Yoruba, nitori ni asiko yii ni otutu maa n mu gidi gan-an ati dide lori ibusun maa n soro ati kowo bo omi tutu je ise beeni iwe wiwe ko rorun, opolopo awon eniyan lo n pe de ibi ise won, gbogbo awon oloja tita ki i de ibi ise loju ojo.

Ategun oye maa n se akoba fun igi oko nitori gbogbo itanna igi eleso ni o n gbon danu, nipa bee, igi eleso ko ni le so to bee, omi inu odo a gbe kiakia, beeni opolopo kanga ko si ni sun omi, omi a wa di owon gogo. Bakan naa, eran igbe ki i pop o loja nitori awon ode ki i ri eran pa ninu igbo, bee gege ni eso igi kii saba pon lasiko yii. Imura awon miiran maa n buru jojo bee si ni awon miiran kii we lasiko yii, won yoo wo dandogo si isale buba, won yoo wa dabi oba awon igare, ti iru won ba yo lokankan ko si iyato laarin won ati inaki.

Bi awon eniyan se korira igba oye to yii, sibe aisan Kankan ko wopo, oorun asun gbadun ni eniyan maa n sun, oju ogbe maa n san kiakia ati wi pe awon efon maa n dinku. Bi awon aleebu igba oye yii se po to sibe igba oye si dara ju igba ooru lo nitori iku maa n wopo nigba ooru.

Dahun awon ibeere wonyi:

  1. Ki ni idi re ti alayoka yii fi faramo igba oye ju igba ooru lo? (A) atiwe maa n soro (B) awon eniyan maa n mura bi oba iganre (C) awon eniyan maa n pe de ibi ise (D) iku maa n dinku (E) omi odo maa n gbe.
  2. Gbogbo nnkan wonyi ni isoro igba oye lara awon eniyan ayafi isoro. (A) airoorun sun (B) atidide lori ibusun (C) atifowo kan omi (D) iwe wiwe (E) pipe de ibi ise.
  3. Ki ni idi ti igi eleso ki i fi so tobee lasiko oye? Lasiko oye (A) awon itanna ti o tan yoo (B) igi eleso kii tanna (C) igi eleso maa n gbe danu (D) itanna igi eleso ti o maa n po (E) itanna igi eleso ti o maa n re danu.
  4. Ewo ni ko si lara anfaani oye ninu akaye yii? (A) aisankaisan ko wopo (B) eso igi ki i saba pon (C) efon n dinku (D) oju ogbe n san kiakia (E) oorun asungbadun.
  5. Ewo ni ki i se aleebu igba oye ninu awon wonyi? (A) awon oloja tita maa n pe de pe de oja (B) eran igbe kii po loja (C) imura awon eniyan kii dara to (D) kanga maa n lomi ninu (E) oorun asungbadun maa n wa.

AKAYE KEJI

Ka awon ayoka yii, ki o si dahun awon ibeere ti o tele won.

Leyin osu merin ti awon igara olosa ko iwe ranse si adugbo Karonwi ni won mu ileri won se. Idaamu ti ko legbe ni won ko ba awon ara adugbo paapaa julo Ayinla oko Mosunmola, okunrin bi obinrin lati igba ti won ti gba leta yii. Se ti eti ko ba gbo yinkin, inu ki i baje ipade adugbo ti won maa n se ni osu meji-meji ti di osoose latari ati jiroro lori aabo awon ara adugbo naa.

 

Afemoju ojo eti ni nnkan bii aago kan aajin ni awon elekeri wo adugbo Karonwi pelu oniruuru ohun ija ati oogun ti won so mo ara won. Logan ni awon ode ti bere si ni fon feere foo, faa lati ji awon ara adugbo. Awon onile ati ayalegbe gbogbo gbe iku ta, won ya sita bi eesu pelu ibon , ada, ofa, igi, obe-ere, ati kumo. Se anikan rin nii je omo ejo niya. Bi awon ole yii se ri opo ero ni won bere si ni yin ibon. Oro wa di ‘’eni to fe ku pade eni ti yoo pa a’’ iro ibon yii ko da awon ara adugbo duro rara, se ti a ba sun ewure kan ogiri o le bu ni je. Leekan naa ni awon olosa yii poora sinu ile alapa kan ti won sa wo.

 

Ara awon eniyan yii ko gba a, won si ina bo inu ile alapa yii. Aja dudu meta ni won ri ti o sa jade ninu ina yii won si ri okan ninu won sa ladaa. Bi won ti sa ladaa ni o yipada di eniyan. Oro di pen-n-tuka. Ayinla ni o saaju awon ti o koko ba ese won soro. Sugbon awon agba taku pe ojo ti a ba ri ibi ni ibi n wole. Won ba a woya ija, won si dana sun oku re ni ita gbangba. Awon to je ode aperin le awon meji yooku wo inu igbo, nibe ni won si yanju won si.

Dahun awon ibeere wonyi:

  1. Toka si gbolohun ti o je ooto nipa akaye yii. (A) awon adigunjale pa die lara awon ara Karonwi (B) Monisola ni iyawo Ayinla. (C) awon ayalegbe ko da si oro awon ara adugbo (D) awon ode aperin ni o ba aja dudu wo iya ija (E) kii se gbogbo eniyan ni o lagbara lati doju ko awon ole yii.
  2. Kin ni awon adigunjale se nigba ti won ri i pe ibon won ko deru ba awon ara Karonwi? Won (A) bere sii pofo (B) poora (C) sa pada (D) sa won ladaa (E) yo igi si won.
  3. Oro ti o le dipo ‘’ba ese won soro’’ ti afa ila si ni idi ni (A) ja (B) korin (C) palemo (D) ranti (E) salo.
  4. Ewo ninu awon wonyi ni ko si lara ohun ija awon ara adugbo? (A) ada, igi, ofa (B) ada, ofa, ibon (C) igi, kumo,, obe-ere (D) kumo, ofa, ada (E) obe-ere, ida, ofa.
  5. Akole wo ni o ba akaye yii mu julo? (A) aitete mole, ole mu oloko (B) awon ode adugbo Karonwi (C) awon olosa fese fe (D) leta adigunjale (E) ojo gbogbo ni ti ole, ojo kan ni ti olohun.

Apa keji

1.salaye isinku oba

 

OSE KEWAA

LETA GBEFE KIKO

AKOONU

Leta gbefe-;ni leta ti a ko si eniyan ti a mo dunju bii obi, ore ,ebi ,egbon, aburo,ara ile eni tabi eniyan miiran ti a mo ri.

Ninu leta gbefe, a le da apara tabi se efe ti o ba wu wa.

Ilana fun leta gbefe kiko

Ti a ba fe ko leta gbefe, eyi ni awon igbese ti a gbodo tele nigba ti a ba fe ko o

(i) Kiko adiresi akoleta-;eyi yoo wa ni apa otun ni oke iwe.

Muslim Grammar School,

  1. O.Box 224,

Eko.

21st March 2011.

 

(ii) Deeti kiko-; ila ti o tele adiresi ni a maa n ko deeti si.

(iii) Ikini-;owo osi ni ibere ila ti o tele deeti ni a n ko ikini si pelu ami koma ni ipar.-        baba mi tooto,Egbon mi owon,Aduke mi atata abbl.

(iv) Inu leta-;ibi yii gan-an ni a o ti soro lori idi ti a fi n ko leta

-“idi pataki ti mo fi n ko iwe yii si yin ni wi pe”………..

(v) Ikadii-; Owo otun pepa ni a o o sun owo si lati dagbere pelu ami koma ni ipari.

Emi ni tire ni tooto,

(vi) Oruko akoleta-;oruko abiso nikan ni akoleta gbodo ko pelu ami idanuduro.

Kola.

Fadeke.

 

IWE AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso fun ile Sekondiri Agba S.S. 3. Corpromutt Publihers Nig Ltd  Oju iwe 35-45.

 

ASA

OKU SISE

– SISE ORO OKU.

AKOONU

Oku sise-;ni imojuto oro ile pelu ipese ohun jije ati ohun mimu ti awon eniyan oku olomo tabi oku agba maa n se fun oku ati awon a-bani-saajo ti o waa ki won ni ile oku.

Bi oku tile je odokunrin ti o ba ti ni omo nile,oku sise yoo wa bi ko tile ni koja akara dindin gege bi saraa fun oku.Ara etutu ki ona oku o le la gaaraga lo si ajule orun ni awon Yoruba ka oku sise si.

Fun oku ayo,oku agba,oku arugbo,eto oku sise repete lo wa ninu asa Yoruba.Bi owo po lowo awon omo olooku nigba naa won ni lati  lo wa owo ya ki asiri won o le bo lori sise eyin baba tabi iya.

Laye atijo odidi ojo meje, mesan-an tabi ju bee lo ni ariya oku sise maa n gba ni ile oku agba.Awon okorin yoo maa ki oriki oku,awon onilu yoo si maaa sise owo won.

Ni ojo isinku; Akara didin ni awon omolooku yoo pese lopolopo fun awon eniyan lati aaro di ale.

Ni ojo keji isinku; akara dindin naa ni yoo gba gbogbo ile oku kan.

Ni ojo keta isinku abbl.; Awon omo olooku yoo kita; eyi nip e won o se eto ariya ojo keta.Ojo yii ni ipese jije ati mimu yoo bere ni pereu,eran pipa,obe sise lorisiirisii,oka riro,iyan gigun abbl. Ni yoo wa ni ki ounje le kari gbogbo eni ti o wa ati gbogbo eni ti omolooku ni lati gbe ounje ranse si ni aarin ilu..Awon onilu paapaa naa yoo maa lulu kikankikan ni agboole oku; ipese ounje ati mimu yoo wa fun awon naa.

Bee ni awon omolokuu ni lati se eto ariya yii ni ojo kerin titi di ojo kesan-an,sugbon eyi ti o wopo julo ni ki awon oku o kije lati pari oku sise,eyi nip e eto ariya ojo keje mu oku sise naa dopin.

Ni ojo kejidinlogun isinku ni eto yiyo ese oku agba obinrin kuro ni nu ebi

 

ASA

 

OKU SISE

– SISE ORO OKU.

AKOONU

Oku sise-;ni imojuto oro ile pelu ipese ohun jije ati ohun mimu ti awon eniyan oku olomo tabi oku agba maa n se fun oku ati awon a-bani-saajo ti o waa ki won ni ile oku.

Bi oku tile je odokunrin ti o ba ti ni omo nile,oku sise yoo wa bi ko tile ni koja akara dindin gege bi saraa fun oku.Ara etutu ki ona oku o le la gaaraga lo si ajule orun ni awon Yoruba ka oku sise si.

Fun oku ayo,oku agba,oku arugbo,eto oku sise repete lo wa ninu asa Yoruba.Bi owo po lowo awon omo olooku nigba naa won ni lati  lo wa owo ya ki asiri won o le bo lori sise eyin baba tabi iya.

Laye atijo odidi ojo meje, mesan-an tabi ju bee lo ni ariya oku sise maa n gba ni ile oku agba.Awon okorin yoo maa ki oriki oku,awon onilu yoo si maaa sise owo won.

Ni ojo isinku; Akara didin ni awon omolooku yoo pese lopolopo fun awon eniyan lati aaro di ale.

Ni ojo keji isinku; akara dindin naa ni yoo gba gbogbo ile oku kan.

Ni ojo keta isinku abbl.; Awon omo olooku yoo kita; eyi nip e won o se eto ariya ojo keta.Ojo yii ni ipese jije ati mimu yoo bere ni pereu,eran pipa,obe sise lorisiirisii,oka riro,iyan gigun abbl. Ni yoo wa ni ki ounje le kari gbogbo eni ti o wa ati gbogbo eni ti omolooku ni lati gbe ounje ranse si ni aarin ilu..Awon onilu paapaa naa yoo maa lulu kikankikan ni agboole oku; ipese ounje ati mimu yoo wa fun awon naa.

Bee ni awon omolokuu ni lati se eto ariya yii ni ojo kerin titi di ojo kesan-an,sugbon eyi ti o wopo julo ni ki awon oku o kije lati pari oku sise,eyi nip e eto ariya ojo keje mu oku sise naa dopin.

Ni ojo kejidinlogun isinku ni eto yiyo ese oku agba obinrin kuro ni nu ebi

 

IGBELEWON

Salaye awon koko ti o ro mo oku sise

Ise Asetilewa

1.Leta ——— ni a maa n ko si ore,ara,ebi ati ojulumo.

(a) eni mimo    (b) gbefe   (d) aigbagbefe

2.Adiresi meloo ni leta si ore wa maa n ni?

(a) kan    (b) meji   (d) meta.

3———- ni ewi atenudenu ti awon ode maa n lo lati dagbere fun ode egbe won.

(a)oku pipe   (b) igbala    (d) iremoje.

4.Okan lara ohun ti o maa n jeyo ninu oku pipe re ni ———

(a)oriki oku  (b) iwa re (d) iye ile ti o ko.

5.ojo——— isinku ni won maa n yo ese obinrin agba kuro ninu ebi.

(a) keta     (b) kejidinlogun   (d) kejidinlogbon.

 

Apa keji

1.Ko leta si ore re,ki o si salaye fun un nipa ile-iwe re titun ti o wa bayii.

2.Daruko awon ewi atenudenu ti a n lo fun oku pipe.

b.Salaye koko ti o maa n je jade ninu won pelu apeere.