ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE.

OSE KESA-AN

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE.

Aroko je ohun ti a ro ti a si se akosile re lori pepa

ILANA FUN KIKO AROKO

  1. yiyan Ori-oro: A ni lati fa ila teere si abe ori-oro ti a n ko aroko le lori
  2. sise ilapa ero: A ni lati ronu jinle ki a si to ero okan wa ni okookan ninu ipinro kookan ki o le ye onkawe
  • Kiko Aroko:-
  • Alaroko gbodo ronu ohun ti o ye ki o je ifaara, ko gbodo gun ju
  • Aarin aroko ni a o ti lo awon ojulowo koko oro bi a se lo won ninu ilapa ero. sipeli akoto ode-oni ni ki a fi ko aroko yii
  • Ikadii:- eyi ni ipari aroko
  1. Ojulowo ede se pataki ninu aroko bii, Afiwe, akanlo ede abbl , ni akekoo gbodo se amulo.

 

ORISI AROKO

  1. Aroko atonisona alepejuwe
  2. Aroko asariyanjiyan
  • Aroko atonisona oniroyin
  1. Aroko onileta
  2. Aroko ajemo – isipaya abbl

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: ISOMOLORUKO II – AWON ORISIRISI ORUKO ABISO AMUTORUNWA ABBL.

Gege bi owe Yoruba ti o wipe “ile la n wo, ki ato so omo loruko” A kii dede fun omo ni oruko ni ile Yoruba, ki won to fun omo loruko, won a se akiyesi iru ipo ti omo wa nigba ti iya re bii tabi ipo ti ebi wa tabi ojo ati asiko ti a bi omo naa.

A pin oruko jije ni ile Yoruba si isori isori. Awon ni wonyi

  1. Oruko Abiso
  2. Oruko Amutorunwa
  • Oruko Oriki
  1. Oruko Abiku
  2. Oruko Inagije
  3. Oruko Idile

 

Oruko Abiso: Eyi ni oruko ti a fun omo ni ibamu pelu iru ipo ti ebi baba tabi iya omo naa wa nigba ti abi

Apeere ati itumo

  1. Fijabi- omo ti a bi ni asiko ti ija wa ninu ebi
  2. Kuponiyi – omo ti a bi leyin iku alafokantan tabi akikanju
  • Abosede – omo ti a bi lojo ose
  1. Odunjo – omo ti a bi lasiko odun ifa tabi odun miiran abbl

Oruko amutorunwa:- Eyi ni oruko ti a fun omo gege bi ipo ti omo wa nigba ti iya re bi. Apeere,

  1. Taiwo: Omo ti o koko jade nigba ti a bi ibeji
  2. Kehinde: omo ti o keyinde nigba ti a bi ibeji
  • Idowu: omo ti a bi tele ibeji
  1. Alaba: omo ti a bi tele idowu
  2. Idogbe: omo ti a bi tele alaba
  3. idoha: omo ti a bi tele idogbe
  • Olugbodi: omo ti a bi ti oni ika owo tabi ika ese mefa
  • Ilori: omo ti a bi nigba ti iya re ko se nnkan osun
  1. Omope: omo ti o lo ju osu mesan-an lo ninu iya re ki a to bi.

Oruko oriki: Eyi ni oruko iwuri ti awon Yoruba n fun omo tuntun. Won n lo o lati fi ki ni tabi gbori yin fun eniyan. Apeere,

Adeola, Abefe, Aduke, Adufe, Amoke, Asake, Ayinde, Ariike, Akanni abbl

 

Oruko Abiku: Eyi ni oruko ti a fun omo ti o je pe bi a se nbi ni o n ku,  nigba ti a ba tun bi won pada ti won a tun pada ku. Apeere

Kosoko, kukoyi, durojaye, oruko tan duroriike, bamijokoo, abii na, omotunde, aja, durosimi, kokumo malomo abbl.

 

Oruko inajije: eyi ni oruko apeje ti ore tabi ebi fi n pe eniyan. O je oruko gbajumo. Apeere,

Ibadiaran, Idileke, Owonifaari, olowojebutu, epolanta, Aponbepore, Awelewa, Ekufunjowo, Eyinmenugun, Dudummadan abbl.

oruko idile: Opo idile ni o maa n fun awon omo ni oruko ni ibamu pelu ipo idile tabi ibamu pelu orisa, ise abinibi ti idile naa n se. apeere,

Idile oloye: Oyebele, Oyediran, Oyewole, Oyekanmi

Idile Oba: Adeooti, Adekanmibi, Adeniyi, Adesola

Idile ola: Oladoye, Oladapo, Olayeni, Olajide

Idile Olorisa: Orisatele, Orisaseye, Orisagbemi, Aborisade

Idile Alawo/Onifa: Faleti, Fabunmi, Fafuke, Fagbohun.

Idile Eleeyin: Olojede, Ojewole, Eeyinjobi

Idile Ede: Oderinde, Odewole, Odeyemi abbl.

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ERE-ONITAN

Litireso apileko ere-onitan ni iwe ere atinude ti onkowe ko lati so ohun ti o sele ninu itan tabi ti o sele loju aye.

Apeere iwe ere-onitan ni “Efusetan Aniwura ti Akinwumi Isola ko

 

Onkawe ere-onitan gbode mo awon koko wonyi,

  1. O gbodo mo nipa igbesi-aye onkowe
  2. O gbodo mo itan inu iwe naa
  3. O gbodo mo awon eda itan inu iwe naa
  4. O gbodo mo ibudo itan – adugbo tabi ilu ti ere naa ti waye
  5. Onkawe gbodo maa fi oye ba awon isele inu ere-onitan naa lo ni sise-n-tele.
  6. Koko oro-onkawe gbodo mo ohun ti itan naa dale lori , ki o si le toko si ete ti won ri ko.
  7. O gbo mo asa Yoruba ti o suyo
  8. O gbodo mo nipa ihuwasi eda itan
  9. Akekoo gbedo sakiyesi ohun ti o gbadun ninu ere-onitan naa.

Igbelewon:

  • Kin ni aroko?
  • Ko ilana kiko aroko
  • Daruko orisi aroko marunun
  • Fun asa isomoloruko ni oriki
  • Ko orisi oruko jije ni ile Yoruba marun un ki o si salaye pelu apeere
  • Kini litireso apileko ere onitan?
  • Ko awon ohun ti onkawelitireso ere onitan gbodo fi sokan

Ise asetilewa: Ise sise inu Yoruba Akayege JSSone

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share