Àwọn ohun tí ó wà ní inú Kíláàsì Yoruba Primary 1 Second Term Lesson Notes

 

DEETI: ỌJỌ́BỌ̀ ỌJỌ́ KỌKÀNLÁ OṢÙ SẸẸRẸ, 2024. KÍLÁÀSÌ: alákọ̀bẹ́rẹ̀ olódún kíní IṢẸ́: YORÙBÁ ỌJỌ́ ORÍ AKẸ́Ẹ̀KỌ́: ỌDÚN MẸ́FÀ SÍ MÉJE ORÍ Ọ̀RỌ̀: Àwọn ohun tí ó wà ní inú Kíláàsì ÌWÉ ÌTỌ́KASÍ: Ayọ̀ Adésànyà et’al(2018) Ìwé Kíkà Àsìkò Tuntun, Ojú ewé Kejì. OHUN ÈLÒ ÌKỌ́NI: Sáàtì tí ó ṣe àfihàn àẁorán nǹkan lórísìírísìí. ÌMỌ̀ ÀTẸ̀YÌNWÁ: Akẹ́kọ̀ọ́ ti ní ìmọ̀ nípa nǹkan inú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀ rí ÈRÒŃGBÀ: NÍ ÌPARÍ Ẹ̀KỌ́ YÌÍ, AKẸ́KỌ̀Ọ́ YÓÒ LE ṢE ÀWỌN NǸKAN WỌ̀NYÍ

  • Dárúkọ àwọn nǹkan inú yàrá ìkàwé
  • Dá àwọn nǹkan inú yàrá ìkàwé mọ̀ ní ọ̀kọ̀ọ̀kan
  • Ṣàlàyé ìwúlò nǹkan inú yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́

ÌJÍRÒRÒ: Àwọn nǹkan tó wà nínú kíláàsì

  1. Àga
  2. Tábìlì
  3. Aago
  4. Gègé
  5. Ìwé
  6. Tabili
  7. Pátákó ìkọ̀wé
  8. Ìfàlà
  9. Fáánù
  10. Ẹfun ìkọ̀wé

Ìgbésẹ̀ kínńí: olùkọ́ ṣàfihàn àwọn ohun èlò ìkọ́ni Ìgbésẹ̀ kejì : olùkọ́ ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ọjọ́ náà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Ìgbésẹ̀ kẹta: olùkọ́ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ààyè láti dárúkọ àwọn ohun èlò inú kíláàsì Ìgbésẹ̀ kẹrin: olùkọ́ fi ààyè sílẹ̀ fún akẹ́kòó láti ṣe ìdámọ̀ àwọn ohun èlò inú kíláàsì àti ìwúlò wọn ÌGBÉLÉWỌ̀N: olùkó bèèrè àwọn ìbéèrè wọ̀nyì lọ́wọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́

  1. Dárúkọ ohun márùn-ún tí ó wà ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ
  2. Sọ ìwúlò àwọn ohun èló yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́

IKADII: Olùkọ́ kádìí ẹ̀kọ́ náà nílẹ̀ nípa ṣíṣe àlàyé ráńpẹ́ nípa ẹ̀kọ́ ọjọ́ náà. IṢÉ ÀṢETILÉWÁ: Ya àwòrán ohun méjì tí ó wà ní yàrá ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ.

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share