JSS 1 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA

 

 

YORUBA LANGUAGE SCHEME OF WORK JSS 1

 

SAA ETO ISE FUN SAA KIN-IN-NI

 1. Alifabeeti ede Yoruba

Itan isedale Yoruba

Oriki litireso

 1. Ami ohun lori awon faweeli ati oro onisilebu kan

Ile-ife saaju dide oduduwa

 1. Ami ohun

Awon eya Yoruba ati ibi ti won tedo si

Awon ohun to ya litireso soto si ede ojoojumo

 1. Silebu

Ikini ni aarin eya Yoruba, ounje won ati bi won se n se won

 1. Akoto ode oni

Ikini II Akoko

Litireso alohun to je mo Aseye

 1. Akoto awon oro ti a sunki

Iwulo Ede Yoruba

Litireso Alohun to je mo esin

 1. Onka Yoruba lati ookan de aadota (1-50)

Bi asa se jeyo ninu ede Yoruba

Litireso Apileko

 1. Onka lati ookan lelaadota de ogorun-un (51-100)

Asa ati ohun-elo isomoloruko

 1. Oriki ati liana kiko aroko Yoruba pelu apeere

Isomoloruko II

Awon litir//so Apileko – Ere onitan.

 1. Aroko atonisona Alapejuwe

Oye jije ati ohu elo oye jije

Awon litireso apileko ewi

 1. Isori oro +ninu gbolohun

Isinku nile Yoruba

 

AKOLE ISE – ALIFABETI YORUBA

ALIFABEETI JE AKOJOPO LETA TI ASE AKOSILE RE GEGE BI IRO NINU EDE YORUBA.

ALIFABETI EDE YORUBA

Aa     Bb    Dd    Ee    Ee     Ff    Gg     GB gb   Hh    Ii    Jj    Kk    Ll    Mm    Nn    Oo    Oo      Pp      Rr      Ss      Ss      Tt    Uu     Ww       Yy   

Apapo alifabeti ede Yoruba je meedogun (25)

Ona meji ni a le pin alifabeeti ede Yoruba si. Awon niyi;

 1. Iro Konsonanti
 2. Iro Faweli

Iro Konsonanti: Eyi ni iro ti a pe ni igba ti idiwo wa fun eemi.

Awon Konsonanti naa ni:

Bb    Dd    Ff    Gg    GB gb    Hh    Jj    Kk    Ll     Mm    Nn    Pp    Rr    Ss    Ss    Tt    Ww    Yy  

Apapo konsonanti ede Yoruba je mejidilogun (18)

Iro faweli: Eyi  ni iro ti a pe nigba ti  ko si idiwo fun eemi

Eyi pin si ona  meji:

Iro faweli airanmupe: A kii ran mu pe iro yii rara bee ni ko  si idiwo fun eemi tabi afefe ti a n pe.

Meje (7) ni iro faweli airanmupe

Aa           Ee        Ee          Ii          Oo         Oo               Uu

Iro faweli aranmupe: A maa n ran mu pe awon iro yii. Ni gba ti a ba n pe awon iro yii jade, eemi maan gba iho imu ati enu jade lee kan naa.

Marun-un (5) ni iro faweli aranmupe – an, en, in, on, un

Apapo iro faweli ede Yoruba je mejila (12)

Igbelewon: 

 • Kin ni alifabeeti ede Yoruba?
 • Ona meloo ni a pin alifabeeti ede Yoruba si?
 • Ko won sita

Ise asetilewa :ISE SISE NINU IWE ILEWO YORUBA AKAYEGE

EKA ISE ASA

AKOLE ISE   Itan Isedale Yoruba

 1. Itan so pe ilu meka ni Yoruba ti wa
 2. Itan fi ye wa pe Lamurudu ni baba nla Yoruba
 3. Lamurudu je Ogbontegi abogipa
 4. Itan so pe awon elesin musulumi gbe ogun ti Lamurudu lati fi esin iborisa sile
 5. Itan fi ye wa pe inu ogun yii ni Lamurudu ku si
 6. Ba kan naa, itan so pe Lamurudu ni baba Oduduwa
 7. Leyin iku Lamurudu, Oduduwa ati awon eniyan re sa wa si ilu ile ife
 8. Ilu ile-ife ni o je orisun fun gbogbo ile Yoruba
 9. Oruko omo Oduduwa ni Okanbi
 10. Okanbi ti o je omo Oduduwa bi omo meje. Awon ni:
S/N ORUKO ILU TI WON TE DO SI OGUN TI WON PIN
A Olowu Owu Aso
B Alaketu Ketu Ade
D Oba Ibini Bini Owo eyo
E Orangun Ila Iyewo
E Oni Sabe Sabe Eran Osu
F Onipopo Popo ILeke
G Oranmiyan Oyo Ile

 

Igbelewon:

 •  Ni sisentele so itan isedale Yoruba
 • Daruko awon omo Okanbi pelu ogun ti won pin leyin iku baba won

Ise asetilewa: ya maapu omo eya ile yoruba

EKA ISE:  LITIRESO

AKOLE ISE:   ORIKI LITIRESO.

Litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan tabi omiiran.

Litireso je ona ti Yoruba n gba fi ero inu won han nipa iriri  won gbogbo.

Ona meji ni a le pin litireso si, awon ni

 1. Litireso alohun
 2. Litireso apileko

 

Litireso Alohun: Eyi ni litireso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon baba nla wa.

Litireso alohun pin si;

 1. Ewi
 2. Oro geere
 3. Ere Onise.

Litireso Apileko: Eyi ni litireso ti a se akosile ni gba ti imo moo- ko – moo-ka de.

Litireso apileko pin si;

 1. Ewi apileko
 2. Ere Onitan
 3. Itan Oroso

Igbelewon: 

 • Fun litireso ni oriki
 • Ona meloo ni a pin litireso ede Yoruba si
 • Salaye lekun-un rere

Ise asetilewa: ko apeere ewi alohun Yoruba marun-un

OSE KEJI

EKA ISE EDE

AKOLE ISE Ami Ohun lori awon faweli ati oro onisilebu kan.

Ami ohun ni o maa n fi iyato han laarin iro kan si iro keji.

 1. Ohun Isale     \      (d) o doju  ko opa osi
 2. Ohun aarin     –      (r) O wa ni ibu
 3. Ohun Oke      /      (m) O  doju ko apa otun

Ami Ohun lori  faweli:

A      E        E      I     O    O   U    (Faweli airanmupe)

 

AN      EN    IN    ON   UN        (Faweli aranmupe)

 

Ami Ohun lori oro onisilebu kan 

silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso lai si idiwo

 

Akiyesi:   Iye ami ori oro ni iye silebu inu oro bee.

Apeere oro onisilebu kan

 1. Ta (sell)  –  ohun isale  (d)  kf
 2. Sun (sleep) –  ohun isale  (d) kf
 3. We  (bath) –  ohun isale (d)  kf
 4. Mu (drink) –  ohun aarin (r) kf
 5. Ko (write) ohun aarin (r) kf
 6. Lo  (go)                –         Ohun aarin (r) kf
 7. Ji  (steal) Ohun Oke (m) kf
 8. Fe (love) Ohun Oke (m) kf
 9. Si  (open) Ohun Oke (m) kf

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: Ile – Ife saaju dide oduduwa ati idagbasoke ti oduduwa mu ba awujo naa.

 1. Itan so peilu ile-ife ni orisun Yoruba
 2. Itan fi ye wa pe inu igbo kijikiji ni ilu ile – ife wa
 3. Itan so pe awon Yoruba ni ibasepo pelu awon Tapa ati ibaripa
 4. Ilu ile-ife di agbogoyo eto oselu, esin abalaye ati awon asa Yoruba leyin dide oduduwa.
 5. Ninu eto eko ni odun 1962 ni a gbe ile eko giga yunifasiti lo si ilu ile-ife
 6. Ayipada otun de ba oro aje ilu ile ife leyin dide oduduwa

Igbelewon:

 • Fun ami ohun loriki
 • Ona meloo ni ami ohun ede Yoruba pin si?
 • Kin ni silebu?
 • Salaye idagbasoke ti o de ba ilu ile ife saaju dide oduduwa

Ise asetilewa:  Ko oro onisilebu mewaa ki o si fi ami ohun ti o ba  okookan won mu si i

 

OSE KETA

Eka Ise Ede

Akole Ise Ede

Ami Ohun lori oro onisilebu meji

 i ba – ta(shoe) (dd) – kf – kf

 ii        E –  we(leaf) (rd) – f – kf

 iii A– ja(dog) (rm) – f – kf

 iv Ba – ba (father)(dm) – kf – kf

 v Ti – ti(a name of a person) (mm) – kf – kf

 

AMI OHUN LORI KONSONANTI ARAMUPE

Ninu ede Yoruba konsonati aramupe asesilebu ti a ni ni “N” konsonanti yii le jeyo ninu oro bi eyo silebu kan nitori o le gba ami ohun lori. apeere,

i n lo –(mr) –k –kf

ii n sun – (md) – k-kf

iii o –ro –n –bo (drdm)-kf-k-kf

iv ba-n-te (ddm)-kf-k-kf

v ko-n-ko (ddd)-kf-k-kf  abbl

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: Awon eya Yoruba ati Ibi ti won tedo si

Osusu owo ni gbogbo omo kaaro-o-o jiire se ara won. Bi o ti le je pe won ko si ni ojukan, si be omo iya ni gbogbo won.

Oniruuru eya ati ede ni awon omo Yoruba pin si kaakiri orile-ede Naijiria.

 

Awon eya Yoruba ati ilu ti won tedo si

 

OYO Ibadan, Iwo, Iseyin,Saki, Ogbonoso, Ikoyi-ile,

Igbo-ora, Eruwa, Ikeru, Ejigbo.

 

IFE Osogbo, Ile-ife, Obaluri, Ifetedoo, Araromi,

Oke igbo abbl

 

IJESA Ilesa, Ibolan, Ipetu-ijesa, Ijebu, Ijesa, 

Esa-oke, Esa-odo, Imesi-ile abbl

 

EKITI Ado, Ikere, Ikole, Okamesi, Otun, Oya, Isan,

Omuo, Ifaki, abbl

 

Ondo Akure, Ondo, Owo, Idanre, Ore, Okitipupa,

Ikere, Akoko, Isua, Oke-igbo abbl

 

EGBA Abeokuta, Sagamu, Ijebu-ode, Epe, Igbesa,

Awori, Egbedo, Ayetoro, Ibora, Iberekodo,

Oke-odon, abbl

 

YEWA Ilaroo, Ayetoro, Imeko, Ifo, Isaya, Igbogila,

Ilobi, Ibese, abbl

 

IGBOMINA Ila-orayan, Omu-Aran, Oke-ila, Omupo,

Ajase-ipo abbl

 

ILORIN             Ilorin, Okeoyi, Iponrin, Afon, Bala,

Ogbondoroko, abbl

EKO Isale-eko, Epetedo, Osodi, Ikotun, Egbe,

Agege, Ilupeju, Ikeja, Musin, Ikorodu,

Egbeda abbl.

 

EGUN Ajase, Ibereko, Aradagun abbl

 

EKA ISE: LETIRESO

AKOLE ISE: Awon Ohun to ya litireso Soto si Ede Ojoojumo

 • Ede ni ohun to jade lenu ti o ni itumo ti o si je ami iyato laarin eniyan ati eranko.
 • Ede ni a n lo lati gbe ero okan wa kale fun elomiiran
 • Akojopo ede ti o di oro ijinle ni litireso.
 • Ede joojumo je ipede igbora eni ye lawujo ti o ya eniyan ati eranko soto.
 • Ijinle ede ti o kun fun ogbon, imo, oye, iriri,asa, igbagbo, ati eto awujo ni litireso.

IGBELEWON:

 • Ko oro onisilebu marun-un ki o si fi ami ohun ti o ye si i
 • So iyato meta ti o ya litireso soto si ede ojoojumo
 • Ko eya Yoruba marun-un ati ibi ti won tedo si

ISE SISE: ko oro onii- konsonanti arnmupe marun-un pelu ami ohun to dangajia

OSE KERIN

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: SILEBU

Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso lai si idiwo.

Iye ami ohun ti o jeyo ninu oro  kan ni iye silebu iru oro bee.

Ihun oro orusilebu kan le je,

I faweli nikan –(F)

ii Apapo konsonati ati  faweli (KF)

iii Konsonati aranmupe asesilebu (N)

Apeere faweli nikan,

Gbogbo faweli aramupe ati aramupe je ihun oro onisilebu kan       a e e I o o u

                                                                                                                         an en in on un.

Lilo won

Mo-ra-a (silebu kan ni “a, I, on, ati un”)

              Mo-ri-i

Tolu mo-on

Baba-fun-un

Apeere apapo konsonati ati faweli (KF)

Lo – KF

Je – KF

Sun – KF

Fe – KF

Gba – KF

Ta – KF

Ge – KF

Ke – KF

Ra – KF

Ran – KF

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: Ikini ni aarin eya Yoruba, ounje won ati bi won se n se won

Asa ikini je okan lara iwa omoluabi. o je iwa ti a gbodo ba lowo omo ti a bi, ti a ko ti o si gba eko rere dandan ni ki omokurin dobale gbalaja ki omobirin si wa lori ikunle ti won ba n ki agba.

Ikini ni aarin eya Yoruba.

Ede Ajumolo           Ede Adugbo Ilu

E kaa-aro Wen kaaaro Ijebu

Nkoo Oro Ekiti

In kuo u ro o Ilesa

O koo ri ro Akoko

E kaaro                 Ife

 

Apeere miran

Alangbaa ti wo le Alangbaa ti wo le Oyo

Olo do gba ti ole Ijesa

Ijon gba ti wo le               Ijebu

Ounje eya Yoruba

Ouje je ohunkohun ti eniyan tabi eranko n je tabi mu ti o si n sara lore.

Orisirisi awon  agbegbe ni ile Yoruba ni o ni iru ounje ti won feran.

 

Ondo ati Ekiti      –         Iyan

Ijebu Ikokore

Egba Laafu

Ibadan   Oka/amola abbl

 

Ona ti a n gba se awon ounje ni ile Yoruba

Ewa

Won a sa ewa

Won a gbe omi ka ori ina

Bi omi ba ho won a da ewa sii

Won a re alubosa sii

Bi ewa ba ti fe jinna, won a fi ata lilo epo ati iyo sii

Leyin ti o ba ti jinna, o ti di jije

 

Oole / moin moin

Won a bo eepo ewa kuro

Won a lo ewa pelu ata ati alubosa

Won a pon ewa sinu ewe

Won a gbe e kana

Bi o ba jina, o di jije

 

Akara

Won abo ewa

Won a lo ewa pelu ata

Won a gbe epo kana

Won a re alubosa si ewa lilo

Won a da ewa lilo die die sinu epo gbigba

Bi o ba din tan, o di jije

 

Isu sise

Won a bo eepo ara isu danu

Won a gee si wewe

Won a gbe e kana pelu omi

Won a fi iyo sii, won a si de ikoko naa

Bi o ba jina, o jije

 

Iyan

Won a be isu

Won a gee si wewe

Won a da isu si ori ina pleu omi ninu re

Won kii fi iyo si bi isu jije

Bi o ba jinna, won a gun ninu odo

Leyin eyi won a fi obe ti o wu won jee

 

Asaro

Won a be epo isu danu

Won a gee si wewe

Won a gbe omi lena

Won a da eroja bi ata, epo, eja, iyo, ede alubosa abbl sinu re

Bi omi ba ti ho, won a da isu sii

Won a roo po

Bi o ba jinna, o di jije abbl

Igbelewon:

 • Fun ounje ni oriki
 • Ko eya Yoruba merin ki o si ko ounje ti won feran ju
 • Kin ni silebu?
 • Ko ihun silebu pelu apeere meji meji

Ise asetilewa: bawo ni a se n se ekuru ati obe gbegiri nin ile yoruba

 

OSE KARUN-UN

EKA ISEl LITIRESO

AKOLE ISE: Akoto ode-oni

Akoto ni ona ti a n gba ko ede Yoruba ni ona ti o bojumu ju ti ateyinwa lo. 

Alaye lori akoto ode-oni

Ede Yoruba di kiko sile ni odun 1842

Pelu iranlowo awon ajihinrere ijo siemesi bisobu Samueli Ajayi crowther ati Henry Townsend. 

Ile ijosin metodiisi, katoliki ati CMS se ipade lori akoto ede Yoruba ni odun 1875 – 1974

Abajade ipade won ni a n lo ninu  ede Yoruba titi di oni.

Iwonba iro ti a ba pe ni ki a se akosile re.

Apeere sipeli atijo ati sipeli tuntun

SIPELI ATIJO SIPELI  TUNTUN

Aiye Aye

Aiya Aya

Eiye Eye

Yio Yoo

Pepeiye               Pepeye

Eiyele Eyele

Enia Eniyan

Okorin           Okunrin

Obirin Obinrin

Onje Ouje

Shola Sola

Shango               Sango

Oshogbo Osogbo

Ilesha Ilesa

Shagamu Sagamu

Offa Ofa

Ebute metta Ebute-meta

Shade Sade

Ottun Otun

Iddo Ido

Akiyesi:- A ko gbodo ko konsonati meeji po ninu ede Yoruba. Ba kan naa, awon oro tabi iro ti a ko pe jade lenu yiyo ni a oo yo won

 

AKA ISE: ASA

AKOLE ISE: Ikini II – Akoko

Asa Ikini sa Pataki ni ile Yoruba.

Idi niyi ti won fi n pe won ni “Omo Kaaro – o-o – jiire”.

Ori ikunle ni omo obinrin yo wa ti omo okunrin yoo si dobale gbalaja ti won ba n ki agba.

Oniruuru ikini ni ile Yoruba.

 

AKOKO IKINI IDAHUN

Ni aaro               E kaaro               O o

E-e-jiire bi? Oo

Se alaafia ni aji           Adupe

Osan E kaasan Oo

Irole E kuurole Oo

Oru E ku aajin Oo

Ni akoko Ojo               E ku ojo               O o

Ni akoko Oye             E ku oye               O o

Ni akoko Iyan             E ku  aheje kiri o Olorun a yo wa

Alaboun Asokale aanfani o O o

Eni to bimo E ku owo lomi           Ire  a kari

E ku ewu omo                                             oo

              

 

Agbe Aroko bodun de o Ase

Babalawo Aborun boye             Amin

Aboye bo sise

Aweko     oko a refoo, ogun a pana mo                           Amin o

Osise ijoba       Oko oba ko ni sa yin lese Ase

Onidiri           Oju gboro         ooya a ya

          E ku ewa

Oba Kabiyesi       Oba yoo ju irukere

Alase Igba keji orisa         Iranse oba yoo dahun pe;

Ki ade pe lori                                   “Oba n ki o”

Ki bata pe lese

Awon ti won n ta ayo Mo kota mo kope Ota n je, ope ko gbodo fohun

Oloja Aje a wo gba o Ase

 

EKA ISE:  LITIRESO

AKOLE ISE: LITIRESO ALOHUN TO JE MO ASEYE.

Litrreso alohun ni litireso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon babanla wa.

Apeere litireso alohun ajemayeye ni

i Ekun Iyawo

ii rara

ii Bolojo

iv Apepe

v Dadakuada abbl

 

Ekun iyawo gege bi litireso alohun ayeye

Ekun Iyawo je ewi ti omo binrin ti n lo si ile oko maa n sun lojo igbe yawo.

Koko inu ewi ekun iyawo

 • O n je ki a mo riri itoju ti awon obi re se lori re lati igba ewe.
 • O wa fun idagbere fun ebi ati ara
 • O wa fun omobinrin lati bere imoran lodo obi
 • O wa fun eko fun awon wundia to ku lati pa ara won mo dojo igbeyawo 

Agbegbe ti ekun iyawo ti n waye,

i Ilu iseyin

ii Ilu Ikirun

iii Ilu Osogbo

iv Ilu Oyo Alaafin

v Ilu Ogbomoso abbl

 

Rara gege bi litireso alohun Ajemayeye 

 • Rara je litireso alohun atigbadegba lawujo Yoruba.
 • Awon obinrin ile ti won mo itupale oriki orisun oko ni won maa nfi rara sisu pon oko won le.
 • Akoko ayeye bii ifinijoye igbeyawo, isomoloruko, isile abbl ni awon asurara maa n sun rara ju lati fi ki awon eniyan ja-n-kan lawujo.
 • Asun rara le je Okunrin tabi obinrin

Agbegbe ti awon asurara wopo ju si,

I Ede v Oyo Alaafin

ii Ikirun vi Iseyin

iii Ogbomoso vii Ibadan abbl

iv Osogbo

 

Bolojo gege bi litireso alohun ajemayeye

 • Awon omokunrin yewa ni o n sabe maa n ko bolojo lati fi se aponle, tu asiri ,se efe, soro nipa oro ilu, oro aje abbl.
 • Won maa nko bolojo ni ibi ayeye bii, igbeyawo, isomoloruko, oye jije, isile abbl.

Igbelewon:

 • Kin ni akoto?
 • Ko oro atiji mewaa ki o si ko akoto irufe awon oro bee
 • Fun litireso alohun ni oriki
 • Ko litireso alohun ajemayeye marun un ki o si salaye

Ise asetilewa:  ko apeere ewi ekun iyawo kan lati fi han pe obinrin ti o n lo ile oko ni o maa n sun ekun iyawo lati fi moriri awon obi re.

 

OSE KEFA

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: AKOTO AWON ORO TI A SUNKI

Akoto ni sipeli titun ti awon onimo ede Yoruba fi enu ko le lori ni odun 1974 lati maa lo.

Sipeli atijo Sipelu titun

Olopa             Olopaa

Na Naa

Orun Oorun

Ogun Oogun

Anu Aanu

Papa Paapaa

Suru Suusu

Alafia Alaafia

Oloto Oloooto

Dada Daadaa

Eleyi Eleyii

Marun               Marun-un

Alanu Alaaanu

Ologbe             Oloogbe

Miran Miiran

Are Aare

Akiyesi:- Iye iro faweli ti a ba pe ni a gbodo se akosile re.

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: IWULO  EDE YORUBA

 1. Ede Yoruba ni a n lo lati ba ara wa so asoye
 2. Ede ni a fi n se ipolowo oja
 3. Ohun ni a fi n korin nibi ayeye bii, igbeyawo, Isinku, Isile abbl
 4. A tun le lo ede fun oro asiri
 5. Ede Yoruba ni a n lo lati fi ke ewi ti yoo dun-un gbo leti,
 6. Ede ni a n lo lati  fi koni ni eko ile nipa eewo ati asa ile wa.

 

EKA ISE: LETIRESO

AKOLE ISE: LITIRESO ALOHUN TO JE MO ESIN 

AWON LITIRESO ALOHUN TO JE MO ESIN KAN TABI OMIIRAN NI ILE YORUBA NI WONYI,

i Oya – pipe

ii Esu – pipe

iii Orin – arungba

iv Ijala -sisun

v Sango – pipe

vi Iyere

vii Ese – Ifa

 

ESA – IFA / ORUNMILA:

 •  Awon olusi re ni babalowo ati awon aloye ifa .
 • Akoko odun ifa tabi ni gba ti nnkan ba ru awon olusin re loju ni won n pe e.

Ounje ifa

Adie

Ewure

Eyele

Igbin

Eja

Epo abbl

 

Eewo ifa/Orunmila

 • Jije isu titun saaju odun 

igbagbo Yoruba ti o suyo ni

 •  Ayanmo
 • Ebo-riru ati Olodumare.

IJALA

 • O je Orisa Ogun
 • Awon Ode, agbe, alagbede ati awon onise irin gbogbo ni olusi ogun. 
 • Akoko odun ogun ni won maa n sun ijala.

Ounje Ogun.

Aja

Iyan

Obi

Emu

Esun-isu

Akukodie

 

Eewo Ogun

 • Gbigbe ofifo agbe duro

 igbagbo Yoruba ti o suyo 

 igi, aranko, eye.

 • Won maa n sun ijala lati fi juba ogun ati lati fi wa oju rere  re

SANGO PIPE:

 •  orisa yii je olufiran
 • Awon adosun sango ati oloye re ni olusin re
 •  Asiko odun sango ni won maa n pe e
 •  ilu bata ni ilu sango

Ounje Sango.

Orogbo, agbo funfun 

Eewo Sango

Siga mimu, Obi, Ewa sese abbl.

Akiyesi: Sango ni o ni ara ati monamona.

ORIN ARUNGBE:

 •  Awon Oloro ni olu sin re.
 •  Asiko odun oro ni a n ko orin yii

Ounje oro

Emu

Aja

Eewo Oro

 •  Obinrin ko gbodo ri oro
 •  a kii ri ajeku oro

orisa yii je orisa atunluuse

igbelewon :

 • Ko iwulo ede Yoruba marun un
 • Ko oro atijo marun un ki o si ko akoto irufe oro bee
 • Ko litireso ajemo esin marun-un ki o si salaye

Ise asetilewa: se ise sise lori akole yii ninu iwe ilewo Yoruba Akayege

JSS 2 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA

OSE KEJE

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ONKA YORUBA LATI OOKAN DE AADOTA (1-50).

Onka Yoruba je ona ti a n gba lati ka nnkan ni ona ti yoo rorun.

Nonba

1 Ookan
2 Eeji
3 Eeta
4 Eerin
5 Aarun-un
6 Eefa
7 Eeje
8 Eejo
9 Eesan-an
10 Eewaa
11 Ookanla 10+1=11
12 Eejila 10+2=12
13 Eetala 10+3=13
14 Eerinla 10+4=14
15 Aarun din logun 20-5=15
16 Eerin din logun 20-4=16
17 Eeta din logun 20-3=17
18 Eeji din logun 20-2=18
19 Ooka din logun 20-1=19
20 Ogun 20
21 Ookan le logun 20+1=21
22 Eeji le logun 20+2=22
23 Eeta le logun 20+3=23
24 Eerin le logun 20+4=24
25 Aarun din logbon 30-5=25
26 Eerin dni logbon 30-4=26
27 Eeta din logbon 30-3=27
28 Eeji din logbon 30-2=28
29 Ookan din logbon 30-1=29
30 Ogbon 30
31 Ookan le logbon 30+1=31
32 Eeji le logbon 30+2=32
33 Eeta le logbon 30+3=33
34 Eerin le logbon 30+4=34
35 Aarun din logoji 40-5=35
36 Eerin din logoji 40-4=36
37 Eeta din logoji 40-3=37
38 Eeji din logoji 40-2=38
39 Ookan din logoji 40-1=39
40 Ogoji 40
41 Ookan le logoji 40+1=41
42 Eeji le logoji 40+2=42
43 Eeta le logoji 40+3=43
44 Eerin le logoji 40+4=44
45 Aarun din laadota 50-5=45
46 Eerin din laadota 50-4=46
47 Eeta din laadota 50-3=47
48 Eeji din laadota 50-2=48
49 Ookan din laadota 50-1=49
50 Aadota 50

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: BI ASA SE JEYO NINU EDE YORUBA

Asa jeyo ninu Ede Yoruba ninu ipede bii owe, akanlo-ede, ewi ,ise sise abbl.

Apeere

              OWE ASA TI O JEYO EKO TI AWON ASA YII KO WA
1 N o le waa ku ko le ri oye ile baba re je Oye jije A gbodo ni igboya 
2 Faari aseju oko olowo ni mu ni lo Oge sise Ki a maa se koja agbara wa, ki a maa ba te
3 Aroba sa kii Sojo  Eru jeje ni awon oba alaye (oye jije) Ki a maa bu ola fun awon alase
4 Obe ti bale ile kii je iyaale ile kii see Igbeyawo Agbodo maa gbe igbe aye alaaafia pelu eni ti ajo n gbe, a ko gbodo se ohun ti enikeji ko fe
Apeere akanlo-ede
5 Baba ti sun Asa Isinku Baba ti ku
6 O ta teru ni pa a Asa Isinku O ti  ku                abbl.

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: LITIRESO APILEKO

Eyi ni litireso ti a se akosile ni gba ti imo mooko – mooka de si ile wa.

Litireso apileko pin si ona meta,

i Ewi

ii Ere-Onitan
iii Itan aroso

 

Litireso Apileko – Itan aroso 

koko ti a gbodo tele ti a ba n ka litireso apileko itan aroso.

 1. Onkawe gbodo le salaye itan ni soki 
 2. O gbodo le salaye ihuwasi awon eda itan inu iwe itan aroso
 3. O gbodo le mo koko oro itan naa
 4. Onkawe gbodo ko awon eko ti o ri ko jade
 5. O gbodo le fa awon isowolo ede jade bii owe, akanlo ede, abbl
 6. Onkawe gbodo le fa awon asa Yoruba ti o suyo jade
 7. Ba ka naa, O gbodo le mo ibudo itan aroso naa.

Igbelewon:

 • Kin ni litireso apileko?
 • Ona meloo ni o pin si?
 • Ko awon koko to onkawe gbodo tele ti a ba n ka litireso apileko
 • Ko onka lati ookan de aadota

Ise asetilewa: Ko owe ati akanlo ede meji meji ki o si fa asa ti o jeyo ninu okookan ati eko ti o ri ko jade

OSE KEJO

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ONKA – OOKALELAADOTA DE OGORUN-UN (51-100).

51 Ookan le laadota 50+1=51
52 Eeji le laadota 50+2=52
53 Eeta le laadota 50+3=53
54 Eerin le laadota 50+4=54
55 Aarun din logota 60-5=55
56 Eerin din logota 60-4=56
57 Eeta din logota 60-3=57
58 Eeji din logota  60-2=58
59 Ookan din logota 60-1=59
60 Ogota 60
61 Ookan le logota 60+1=61
62 Eeji le logota 60+2=62
63 Eeta le logota 60+3=63
64 Eerin le logota 60+4=64
65 Aarun din laadorin 70-5=65
66 Eerin din laadorin 70-4=66
67 Eeta din laadorin 70-3=67
68 Eeji din laadorin 70-2=68
69 Ookan din laadorin 70-1=69
70 Aadorin  70
71 Ookan le laadorin 70+1=71
72 Eeji le laadorin 70+2=72
73 Eeta le laadorin 70+3=73
74 Eerin le laadorin 70+4=74
75 Aarun din logorin 80-5=75
76 Eerin din logorin 80-4=76
77 Eeta din logorin 80-3=77
78 Eeji din logorin 80-2=78
79 Ookan din logorin 80-1=79
80 Ogorin 80
81 Ookan le logorin 80+1=81
82 Eeji le logorin 80+2=82
83 Eeta le logorin 80+3=83
84 Eerin le logorin 80+4=84
85 Aarun din laa dorun-un 90-5=85
86 Eerin din laa dorun-un 90-4=86
87 Eeta din laa dorun-un 90-3=87
88 Eeji din laa dorun-un 90-2=88
89 Ookan din laa dorun-un 90-1=89
90 Aadorun-un 90
91 Ooksn le laa dorun-un 90+1=91
92 Eeji le laa dorun-un 90+2=92
93 Eeta le laa dorun-un 90+3=93
94 Eerin le laa dorun-un 90+4=94
95 Aarun din logorun-un 100-5=95
96 Eerin din logorun-un 100-4=96
97 Eeta din logorun-un 100-3=97
98 Eeji din logorun-un 100-2=98
99 Ookan din logorun-un 100-1=99
100 Ogorun-un  100

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: ASA ATI OHUN ELO ISOMOLORUKO.

Asa isomoloruko je ona ti a n gba fun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lae ni ile Yoruba.

Gbogbo ohun ti olodumare da saye lo ni oruko. oniruuru ohun-elo tabi eronja ni Yoruba si maa n lo ni gba Ikomojade . Ojo kefa ni Yoruba n so omo loruko, I ba se omokurin tabi omobinrin tabi ibeji sugbon ni ibo miiran , ojo kesan-an ni won n so omokunrin lorunko, ojo keje ni ti obinrin ti awon ibeji ni ojo kejo.

 

Die lara ohun elo isomoloruko niyi,

Ohun elo Iwure/adura
Obi  Bibi lobi n biku danu, bibi lobi n baarun danu, obi a bi ibi aye re danu.
Orogbo Orogbo maa n gbo saye ni, o o gbo o, wa a to, wa a gbo kejekeje, o ko ni gbo igbo iya.
Oyin A kii foyin senu ka roju koko, oro bi oyin bi adun ko ni dagbere fun o o koni je ikoso laye.
Oti Oti kii ti, oko ni ti laye bee ni oti kii te, o ko ni t e
Epo pupa Epo ni iroju obe, aye re a roju.
Iyo Iyo nii mu obe dun, iwo ni o maa mu inu awon obi re dun.
Ataare Ataare kii bimo tire laabo, fofo ni le ataare n kun, oye re a kun fomo.
Aadun adun adun ni a n ba nile aadun, ibaje oni wole to o.
Ireke A kii ba kikan ninu ireke, ikoro ko ni wo aye re lae, aye re yoo dun
Omi tutu Omi la buwe, omi la bumu enikan kii ba omi sota,koo mu to

Ko ni gbodi ninu re o 

Ko si ni sa pa o lori………

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ITAN AROSO – KIKA IW E TI IJOBA YAN

Igbelewon: 

 • Kin ni asa isomoloruko?
 • Ko ohun elo isomoloruko marun un ki o si so bi a se n fi wure fun omo tuntun
 • Ko onka lati aadota de ogoorun

Ise asetilewa:Ise sise inu Yoruba Akayege for jssone 

 

OSE KESA-AN

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE.

Aroko je ohun ti a ro ti a si se akosile re lori pepa

ILANA FUN KIKO AROKO

 1.  yiyan Ori-oro: A ni lati fa ila teere si abe ori-oro ti a n ko aroko le lori
 2.  sise ilapa ero: A ni lati ronu jinle ki a si to ero okan wa ni okookan ninu ipinro kookan ki o le ye onkawe
 3. Kiko Aroko:-
 1. Alaroko gbodo ronu ohun ti o ye ki o je ifaara, ko gbodo gun ju
 2. Aarin aroko ni a o ti lo awon ojulowo koko oro bi a se lo won ninu ilapa ero. sipeli akoto ode-oni ni ki a fi ko aroko yii
 1. Ikadii:- eyi ni ipari aroko
 1. Ojulowo ede se pataki ninu aroko bii, Afiwe, akanlo ede abbl , ni akekoo gbodo se amulo.

 

ORISI AROKO

 1. Aroko atonisona alepejuwe
 2. Aroko asariyanjiyan
 3. Aroko atonisona oniroyin
 4. Aroko onileta
 5. Aroko ajemo – isipaya abbl

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: ISOMOLORUKO II – AWON ORISIRISI ORUKO ABISO AMUTORUNWA ABBL.

Gege bi owe Yoruba ti o wipe “ile la n wo, ki a to so omo loruko” A kii dede fun omo ni oruko ni ile Yoruba, ki won to fun omo loruko, won a se akiyesi iru ipo ti omo wa ni gba ti iya re bii tabi ipo ti ebi wa tabi ojo ati asiko ti a bi omo naa.

A pin oruko jije ni ile Yoruba si isori isori. Awon ni wonyi

 1. Oruko Abiso
 2. Oruko Amutorunwa
 3. Oruko Oriki
 4. Oruko Abiku
 5. Oruko Inagije
 6. Oruko Idile 

 

Oruko Abiso: Eyi ni oruko ti a fun omo ni ibamu pelu iru ipo ti ebi baba tabi iya omo naa wa nigba ti abi

Apeere ati itumo

 1. Fijabi- omo ti a bi ni asiko ti ija wa ninu ebi 
 2. Kuponiyi – omo ti a bi leyin iku alafokantan tabi akikanju
 3. Abosede – omo ti a bi lojo ose
 4. Odunjo – omo ti a bi lasiko odun ifa tabi odun miiran abbl 

Oruko amutorunwa:- Eyi ni oruko ti a fun omo gege bi ipo ti omo wa ni gba ti iya re bi. Apeere,

 1. Taiwo: Omo ti o koko jade nigba ti a bi ibeji
 2. Kehinde: omo ti o keyin de nigba ti a bi ibeji
 3. Idowu: omo ti a bi tele ibeji
 4. Alaba: omo ti a bi tele idowu
 5. Idogbe: omo ti a bi tele alaba
 6. idoha: omo ti a bi tele idogbe
 7. Olugbodi: omo ti a bi ti oni ika owo tabi ika ese mefa
 8. Ilori: omo ti a bi nigba ti iya re ko se nnkan osun
 9. Omope: omo ti o lo ju osu mesan-an lo ninu iya re ki a to bi.

Oruko oriki: Eyi ni oruko iwuri ti awon Yoruba n fun omo tuntun. Won n lo o lati fi ki ni tabi gbori yin fun eniyan. Apeere,

Adeola, Abefe, Aduke, Adufe, Amoke, Asake, Ayinde, Ariike, Akanni abbl

 

Oruko Abiku: Eyi ni oruko ti a fun omo ti o je pe bi a se n bi ni o n ku,  nigba ti a ba tun bi won pada ti won a tun pada ku. Apeere

Kosoko, kukoyi, durojaye, oruko tan duroriike, bamijokoo, abii na, omotunde, aja, durosimi, kokumo malomo abbl.

 

Oruko inajije: eyi ni oruko apeje ti ore tabi ebi fi n pe eniyan. O je oruko gbajumo. Apeere,

Ibadiaran, Idileke, Owonifaari, olowojebutu, epolanta, Aponbepore, Awelewa, Ekufunjowo, Eyinmenugun, Dudummadan abbl.

oruko idile: Opo idile ni o maa n fun awon omo ni oruko ni ibamu pelu ipo idile tabi ibamu pelu orisa, ise abinibi ti idile naa n se. apeere,

Idile oloye: Oyebele, Oyediran, Oyewole, Oyekanmi

Idile Oba: Adeooti, Adekanmibi, Adeniyi, Adesola

Idile ola: Oladoye, Oladapo, Olayeni, Olajide

Idile Olorisa: Orisatele, Orisaseye, Orisagbemi, Aborisade

Idile Alawo/Onifa: Faleti, Fabunmi, Fafuke, Fagbohun.

Idile Eleeyin: Olojede, Ojewole, Eeyinjobi

Idile Ede: Oderinde, Odewole, Odeyemi abbl.

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ERE-ONITAN

Litireso apileko ere-onitan ni iwe ere atinude ti onkowe ko lati so ohun ti o sele ninu itan tabi ti o sele loju aye.

Apeere iwe ere-onitan ni “Efusetan Aniwura ti Akinwumi Isola ko

 

Onkawe ere-onitan gbode mo awon koko wonyi,

 1. O gbodo mo nipa igbesi-aye onkowe
 2. O gbodo mo itan inu iwe naa
 3. O gbodo mo awon eda itan inu iwe naa
 4. O gbodo mo ibudo itan – adugbo tabi ilu ti ere naa ti waye
 5. Onkawe gbodo maa fi oye ba awon isele inu ere-onitan naa lo ni sise-n-tele.
 6. Koko oro-onkawe gbodo mo ohun ti itan naa dale lori , ki o si le toko si ete ti won ri ko.
 7. O gbo mo asa Yoruba ti o suyo
 8. O gbodo mo nipa ihuwasi eda itan
 9. Akekoo gbedo sakiyesi ohun ti o gbadun ninu ere-onitan naa.

Igbelewon: 

 • Kin ni aroko?
 • Ko ilana kiko aroko 
 • Daruko orisi aroko marunun
 • Fun asa isomoloruko ni oriki
 • Ko orisi oruko jije ni ile Yoruba marun un ki o si salaye pelu apeere
 • Kini litireso apileko ere onitan?
 • Ko awon ohun ti onkawelitireso ere onitan gbodo  fi sokan

Ise asetilewa: Ise sise inu Yoruba Akayege JSSone

OSE KEWAA

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: AROKO ATONISONA ALAPEJUWE.

Aroko je ohun ti a ro ti a sise akosile.

Aroko alapejuwe ni aroko ti o man sapejuwe eniyan, ibikan ati nnkan to n sele gege bi a se ri i gan-an. Apeere:

 1. Oja ilu mi
 2. Egbon mi 
 3. Ile-iwe mi
 4. Ouje ti mo feran
 5. Ilu mi abbl.

Aroko lori Ile-Iwe mi

Oruko Ile-eko mi ni Elias International School. O wa ni Ojule keji-Ikerin ,Opopona ile-Epo, Oke-odo, ipile Eko. Oludasile ile iwe mi  ni Dokita  Dosumu. ile-iwe mije ile oloke meta meta ti o fegbe kegbe ti a si fi ilekun onirin si enu ona abawole re.

A kun ile-iwe mi ni awo ewe gege bi aso ile iwe wa. Iyara ikawe fun kilaasi girama ati alakobere po jantirere bee ofisi awon oluko ati alase ile-iwe naa ko kere niye.

A ni yara ero ayara bi asa, yara imo sayensi, yara imo ede, yara ibi ikawe ati iyawe, yara ijeun.

A fi ododo se ile-iwe mi losoo bee. Leyin ile iwe mi, a ni papa isere fun awon ere idaraya bi boolu alafese gba, ere idije, boolu alafowo gba abbl.

Apapo awon omo-ile mi le ni oodunrun, awon oluko wa le ni aadota. Awon omo ile-iwe mi je omo gidi nitori won n ko wa ni eko-iwa, akojopo eko ile, bi a ti n huwa ni awujo ati eko bibeli.

Ti a ba n soro nipa awon oluko wa awon oluko wa dangajia, won ni oyaya, iwa pele, bee ni won mo bi a ti n ba awon obi se.

Opolopo obi feran ile-iwe mi pupo nitori pe ibe ni awon looko-looko ti o di ipo giga mu ni orile ede yii ti jade bee ni esin idanwo ase kegba wo ile eko giga ti yunifaasiti won maa n dara pupo. mo feran ile-iwe mi nitori pe,

 1. Awon oluko wa kun ojo osuwon
 2. O ni awon  ero ikawe igbalode
 3. Agbegbe re dun-un kawe
 4. Won n ko ni bi ati n je omo rere ni ile ati fun orile ede lapapo

JSS 3 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: OYA JIJE ATI OHUN ELO OYE JIJE.

Bi a se n joye ni ilu kan yato si bi a se n joye ni ilu miran.

Makan –makan ni oye jije je ni ile Yoruba.

Oniruuru oye jije ni ile Yoruba.

 1. Oye Oba
 2. Oye Baale
 3. Oye Iyalode
 4. Oye Ajiroba
 5. Oye Bobajiro
 6. Oye Iyalaje
 7. Oye Afobaje
 8. Oye Majekobaje
 9. Oye Ile
 10. Oye Eleto
 11. Oye Baba-Isegun
 12. Oye Gbajumo. Abbl

 

Ohun elo Oye Jije

 1. Ewe oye
 2. Etutu lorisirisi
 1. Ileke owo, orun, ese
 2. Ade-oba
 1. Ilu lorisirisi
 1. Igba oye
 2. Irukere

 

EKA ISE: LITIRESO

AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO-EWI 

Ewi apileko litireso je ijinle oro ti o ku fun laakaye, ogbon ati oye ti a fi ona ede ati oro ijinle gbekele.

Awon koko ti a ni lati tele ti a ba n ko ewi apileko.

 1. Eni ti o ko ewi naa: mimo itan igbesi aye akewi
 2. Koko oro: onka-ewi gbodo mo koko ti ewi naa dale lori
 3. Eko ti ewi naa n ko wa se Pataki lati mo
 4. Ona ede ati asa ti o suyo: onkawe gbodo le toka asa Yoruba ati oniruuru ona ede bii, owe, akanlo ede, afiwe, asorege abbl.

Igbelewon:

 • Kin ni aroko?
 • Fun aroko atonisona asapejuwe loriki
 • Ko apeere aroko asapejuwe meta
 • Ko oniruuru oye jije ile Yoruba marunun ati ohun elo oye naa
 • Fun ewi apileko litireso ni oriki
 • Ko ilana kiko litireso naa

Ise asetilewa: ko aroko lori ounje ti o feran ju

 

OSE KOKANLA

EKA ISE: EDE

AKOLE ISE: ISORI ORO NINU GBOLOHUN

 Isori oro ni abala ti a pin awon oro inu ede yoruba si.

Isori oro Yoruba 

 1. oro-oruko (NOUN)
 2. oro-aropo oruko (PRONOUN)
 3. oro ise  (VERB)
 4. oro Aropo afarajoruko (PROMINAL )
 5. oro apejuwe ( ADJECTIVE )
 6. oro atoku (PREPOSITION)
 7. oro asopo ( CONJUCTION )

 

EKA ISE: ASA

AKOLE ISE: ISINKU

Isinku ni eye ikeyin ti a se fun oku logan ti o ku titi di akoko ti a fi sin.

Orisi oku sinsin ni ile Yoruba

 1. Oku Oba
 2. Oku Ijoye
 3. Oku Alaboyun
 4. Oku Adete
 5. Oku Abuke
 6. Oku Afin
 7. Oku Odo
 8. Oku Aro
 9. Oku eni ti o pokunso
 10. Oku eni ti sango pa
 11. Oku eni ti igi yalu pa abbl.

 

Ohun elo oku sin-sin.

 1. Aso funfun
 2. poosi oku/eni
 3. etutu lorisirisi
 4. owu tutu
 5. igi ora
 6. eepe (iyepe)
 7. lofinde oloorun
 8. Oniruuru nnkan ti enu n je, ileke owo, bata, opa itile abbl.

Igbelewon:

 • Fun asa isinku ni oriki
 • Ko orisi oku sin sin ni ile Yoruba mewaa
 • Ko ohun elo oku sin sin nile Yoruba
 • Ko isori oro ede Yoruba mefa

Ise asetilewa: fun awon isori oro wonyi loriki pelu apeere meji meji:

 1. Oro oruko
 2. Oro ise

 

Someone might need this, Help others, Click on any of the Social Media Icon To Share !