Silebu Ninu Èdè Yorùbá JSS 1 First Term Lesson Notes Week 4
OSE KERIN
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: SILEBU
Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso lai si idiwo. Iye ami ohun ti o jeyo ninu oro kan ni iye silebu iru oro bee.
Ihun oro orusilebu kan le je:
- Faweli nikan – (F)
- Apapo konsonanti ati faweli (KF)
- Konsonanti aranmupe asesilebu (N)
Apeere faweli nikan:
Gbogbo faweli aramupe ati aramupe je ihun oro onisilebu kan:
- a, e, i, o, u
- an, en, in, on, un
Lilo won:
- Mo-ra-a (silebu kan ni “a, i, on, ati un”)
- Mo-ri-i
- Tolu mo-on
- Baba-fun-un
Apeere apapo konsonanti ati faweli (KF):
- Lo – KF
- Je – KF
- Sun – KF
- Fe – KF
- Gba – KF
- Ta – KF
- Ge – KF
- Ke – KF
- Ra – KF
- Ran – KF
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Ikini ni aarin eya Yoruba, ounje won ati bi won se n se won
Asa ikini je okan lara iwa omoluabi. O je iwa ti a gbodo ba lowo omo ti a bi, ti a ko ti o si gba eko rere dandan ni ki omokurin dobale gbalaja ki omobirin si wa lori ikunle ti won ba n ki agba.
Ikini ni aarin eya Yoruba:
Ede Ajumolo
- Ede Adugbo
- Ilu
- E kaa-aro – Wen kaaaro (Ijebu)
- Nkoo Oro – Ekiti
- In kuo u ro o – Ilesa
- O koo ri ro – Akoko
- E kaaro – Ife
Apeere miran:
- Alangbaa ti wo le – Oyo
- Olo do gba ti ole – Ijesa
- Ijon gba ti wo le – Ijebu
Ounje eya Yoruba:
Ouje je ohunkohun ti eniyan tabi eranko n je tabi mu ti o si n sara lore. Orisirisi awon agbegbe ni ile Yoruba ni o ni iru ounje ti won feran.
- Ondo ati Ekiti – Iyan
- Ijebu – Ikokore
- Egba – Laafu
- Ibadan – Oka/amola
Ona ti a n gba se awon ounje ni ile Yoruba:
- Ewa:
- Won a sa ewa
- Won a gbe omi ka ori ina
- Bi omi ba ho, won a da ewa sii
- Won a re alubosa sii
- Bi ewa ba ti fe jinna, won a fi ata lilo epo ati iyo sii
- Leyin ti o ba ti jinna, o ti di jije
- Oole / Moin Moin:
- Won a bo eepo ewa kuro
- Won a lo ewa pelu ata ati alubosa
- Won a pon ewa sinu ewe
- Won a gbe e kana
- Bi o ba jina, o di jije
- Akara:
- Won a bo ewa
- Won a lo ewa pelu ata
- Won a gbe epo kana
- Won a re alubosa si ewa lilo
- Won a da ewa lilo die die sinu epo gbigba
- Bi o ba din tan, o di jije
- Isu Sise:
- Won a bo eepo ara isu danu
- Won a gee si wewe
- Won a gbe ekana pelu omi
- Won a fi iyo sii, won a si de ikoko naa
- Bi o ba jina, o jije
- Iyan:
- Won a be isu
- Won a gee si wewe
- Won a da isu si ori ina pelu omi ninu re
- Won kii fi iyo si bi isu jije
- Bi o ba jinna, won a gun ninu odo
- Leyin eyi, won a fi obe ti o wu won jee
- Asaro:
- Won a be epo isu danu
- Won a gee si wewe
- Won a gbe omi lena
- Won a da eroja bi ata, epo, eja, iyo, ede alubosa abbl sinu re
- Bi omi ba ti ho, won a da isu sii
- Won a roo po
- Bi o ba jinna, o di jije
Igbelewon:
- Fun ounje ni oriki.
- Ko eya Yoruba merin ki o si ko ounje ti won feran ju.
- Kin ni silebu?
- Ko ihun silebu pelu apeere meji meji.
Ise asetilewa: Bawo ni a se n se ekuru ati obe gbegiri nin ile Yoruba.
Related Posts
Parler de Couleur French JSS 1 First Term Lesson Notes Week 5


Difference Between Plants and Animals Basic Science JSS 1 First Term Lesson Notes Week 3


Mid Term Test Social Studies Jss 1 Second Term Lesson Notes Week 7
About The Author
Edu Delight Tutors
Am a dedicated educator with a passion for learning and a keen interest in technology. I believe that technology can revolutionize education and am committed to creating an online hub of knowledge, inspiration, and growth for both educators and students. Welcome to Edu Delight Tutors, where learning knows no boundaries.