I am sharing ‘JSS 1-3 Yoruba.docx’ with you from WPS Office

SECOND TERM EXAMINATION

Subject: YORUBA Class: JSS 3 Time:2hrs

Ka ayoka isale yi ki o si dahun ibeere ti o tele

Meji meji ni olorun da ohun gbogbo ti o wa laye. Nigba miran, yoo da okan sile, yoo si okan yooku sinu igbo.

Olorun seda adie sinu ile, aparo ni omo iya re ti o wa ninu igbo. Iyato ti o wa lara ewure ati etu ko ju pe ewure je eran ile, etu si wa ninu igbo.

Olorun seda eyele ki o maa ba eniyan gbele, o si seda adaba losoo sinu igbo. Ko si iyato laarin awon eye wonyi. Kolo kolo ati aja, bakan naa ni won ri. Iyato won koju pe, kolo kolo wa ninu igbo, aja si wa ninu ile. Ejo nikan ni olorun ko seda re ni meji meji. Okan ti olorun seda, inu igbo lo seda re si . Idi ti olorun ko fi seda ejo si aarin igboro ni nitori ika ati oro ti o wa ninu ejo.

IBERE EWO NIDAHUN

 1. Ewo ni ki gbe igboro ninu awon wonyi? (A) adaba (B) adiye (C) eyele (D) ewure
 2. Fa eyi ti o je omo iya aparo yo ni awon wonyi (A) adaba (B) adiye (C) aja (D) eyele
 3. Idi wo ni olorun ko fi seda ejo si igboro? (A) Eniyan ko le be ejo gbe (B) ika ati oro inu ejo po (C) olorun ko nife sip e ki ejo ma a gbe nigboro (D) ounje ejo kosi nigboro
 4. Ewo ni ki se ooto bi o ti ka ninu ayoka yi? (A) aparo ni omo iya adie (B) ejo wa ninu igbo (C) igboro ni olorun seda kolo kolo si (D) inu igbo ni etu gbe
 5. Gbogbo awon wonyi ni o n gbe inu igbo ayafi (A) adaba (B) kolokolo (C) eyele (D) etu
 6. Gege bi igbagbo awon Yoruba ohun wonyi je mimo ayafi gbogbo ohun ti ko ba (A) la idoti lo (B) ni nkan abuku (C) ni oorun ninu (D) ni iwa toto
 7. Iwa wonyi fi ara han ninu esin ibile gege bi aroko iwa mimo afi (A) iwa okanjuwa (B) iwa ododo (C) iwa otito (D) iwa irele
 8. Orin yi “Bi mo ba seke o, bi mo ba dale, ogun a dajo” fi han pe orisa ogun (A) korira iwa(A) odale (B) feran iwa ile dida (C) je adajo (D) ko fe ejo dida
 9. Orisa alaso funfun ni orisa (A) ogun (B) sango (C) obatala (D) sanponna
 10. Aso ogun ni ________ (A) aso pupa (B) aso dudu (C) mariwo ope (D) aso Ankara
 11. Orisa wo lo ni aso pupa (A) obatala (B) olokun (C) ogun (D) sango
 12. ________ ni Yoruba gba pe won n so oja di owon (A) alagbata (B) onisowo (C) onibara (D) ero oja
 13. ________ ki saaba fi eni si oja (A) onigaari (B) alaso (C) alata (D) elepa
 14. Ki a to le di onisowo, a gbodo ni nkan wonyi, ayafi (A) owo okowo (B) kose kara kata (C) darapo mo egbe oloja (D) di arugbo kege kege
 15. Nibo ni orirun awon Yoruba? (A) ekiti (B) oyo (C) ife (D) ondo
 16. Oruko omo kan soso ti oduduwa bi ni (A) Agbomiregun (B) Buraimo (C) Okanbi (D) Onipopo
 17. Ta ni abigbeyin omo Okanbi? (A) alaketu (B) Oranmiyan (C) Oba ibini (D) Onisabe
 18. Okan lara okunfa airise se ni orile ede naijiria ni ________ (A) aini fe si ise osu awon odo (B) aini ife si eko iwe awon odo (C) inu awon obi ko dun si ise (D) oro aye ti o se aisan
 19. “langbe jina o, oroku ori ebe” _______ ni a n polowo bayi (A) isu sise (B) agbado sise (C) eko gbigbona (D) ewa sise
 20. “dodo ______ re e o” (A) osu (B) ikire (C) osogbo (D) ede
 21. Ikede fun gbogbo eniyan ohun ti a n ta lati mu won nifee si I lati ra ni a n pe ni (A) ipate oja (B) ikiri oja (C) ipolowo oja (D) rira oja
 22. Gbigbe ohun ti a n ta si oju kan fun onibaara lati ra ni a mo si (A) ipate oja (B) ipolowo oja (C) ikiri oja (D) nina oja
 23. Aarin awon wo ni airiisese ti wopo? aarin awon (A) arugbo (B) abileko (C) odo (D) abirun eda
 24. Ni ile yoruba _____ ni a maa n pe obinrin ti ko ba tete ri omo bi (A) adelebo (B) agan (C) apon (D) iyawo
 25. Awon wonyi ni oyun nini wa fun, awon _______ (A) omo ile iwe (B) omo ekose (C) toko-taya (D) arugbo
 26. Ohun ti o le fa ki obinrin ya agan ni (A) isekuse (B) aisan ara (C) ibinu (D) ijajija
 27. Igbagbo yoruba ni wi pe ________ ni agan (A) ako ibepe (B) abo ibepe (C) esin inu iwe (D) akura
 28. Omo ti won bi ti o n ku lera lera ni a n pe ni (A) agan (B) oku (C) abiku (D) elere omo
 29. Eni ti o n toju aboyun ni ilana ibile ni a n pe ni (A) onisegun awebi(B) onisegun agbebi (C) onisegun agan (D) iya olomo
 30. Aajo ti a fi le da oyun bibaje duro lara obinrin ni (A) ose abiwere (B) gboyun pamo (C) oyun dide (D) agbo awebi

APA KEJI

Dahun ibere meta ni abala yi sugbon nomba (1) se Pataki

 1. Ko aroko lori okan ninu koko wonyi
 2. Awon obi mi
 3. Ojo akoko mi ni sekondiri
 4. Ko leta si ore re ti ko wa si ile iwe lati bi ojo meta salaye fun lori awon isele ti o sele lati igba ti ko ti wa
 5. Idije onile jile ti owaye ni ile iwe mi
 6. Toka si awon ohun marun ti o gbodo wa ni mimo ninu esin ibile Yoruba

b. Daruko awon aworo orisa wonyi

i. sango ii. Oro iii. Egugun iv. Osun v. orunmila

 1. Toka si idi marun (5) Pataki ti a fi n sowo

b. Menuba okunfa airisese marun(5) ni orile- ede Naijiria

 1. Menuba orisii aajo aboyun (5) ni aye atijo

b. Toka si ona marun (5) ti afi le din bibi abiku ku lawujo

 1. Daruko orisii aroko pipa marun(5) ni aye atijo
 2. Daruko awon omo oduduwa mejeeje ati ilu ti enikookan won tedo si.

SECOND TERM EXAMINATION

Subject: YORUBA Class: JSS 2 Time:2hrs

Ka ayoka iasle yii, ki o si dahun ibeere ti o teele.

Ogede je okan lara awon ogbin ile wa. Awon agbe to wa ni ile igbo lo ma n gbin ogede. Omi se Pataki fun didagba ogede.

A ni orisii ogede meji.

Ekinni ni eyi ti a pe ni ogede agbagba. Iru ogede yi ma n tobi daadaa. Orisii keji ni ogede wewe. Eyi lo n je paranta tabi omini. igi to n so ogede yala paranta tabi agbagba ko dabi orisii igi yooku. O rorun lati fi ada ge nitori pe igi re ro. Nigbati ogede ba dagba ti eso re si ti gbo, a ma sa a. ogede miran a ti so ni idi eyi ti a sa omo lori re, a o wa ge igi re lule idi niyii ti a fi n powe pe “Bi ina ba ku a fi eeru boju, bi ogede ba ku a fi omo re ropo”. Igi ogede ti o so ni idi eyi ti a sa yii ni o fi ropo eyi ti a n ge lule. Igba eerun ni ogede ma n po loja. Ogede were ni a fi ma n panu ti o ba ti pon.

Iwulo ogede agbagba po pupo. A le fi dudu re se elubo, a le se mo isu lati gun iyan je. A tun le fi se asaro tabi ki a fi din ipekere. Bi ogede agbagba ba pon, a le je e ni tutu tabi ki a se e je. Ti a ba fe, a le se mo ewa tabi ki a fi din dodo, awon miran a si maa fi pon oti agadagidi.

IBERE

 1. Ewo ni kii se otito nipa ogede ninu awon wonyi (A) igba ojo ni ogede ma n po ni oja (B) orisii ogede meji lo wa (C) ile igbo ni o dara ju fun ogede (D) eso ni ogede paranta
 2. Ogede ni a n fi se awon ounje wonyi ayafi (A) egbo (B) elubo (C) ipekere (D) dodo
 3. A le lo ogede dudu fun okan ninu ounje wonyi (A) asaro (B) egbo (C) lafun (D) ikokore
 4. Kini igi ogede fi yato si awon igi ti o ku? Igi ogede maa n (A) pe (B) ro (C) le (D) ga
 5. Igba _______ ni ogede maa n po loja (A) eerun (B) ojo (C) otutu (D) oye
 6. Awon wo ni o ni dadakuada (A) egba (B) yewa (C) igbomina (D) ijesa
 7. Eya yoruba wo ni lo ni Efe (A) Ekiti (B) Egbado (C) Egba (D) Ife
 8. Gbogbo awon wonyi lo je mo ewi alohun ajemayeye ayafi (A) bolojo (B) ekun yawo (C) iyere (D) orin etiyeri
 9. Eya Yoruba wo lo n alamo sisa(A) egba (B) ekiti (C) ijesa (D) yewa
 10. Orisa wo lo ni esa pipe (A) oro (B) ogun (C) egungun (D) sango
 11. Ewo ninu ewi alohun wonyi ni o wopo ni ondo (A) ekun iyawo (B) obitun (C) bolojo (D) adamo
 12. Ewi alohun awon ijebu ni (A) orin etiyeri (B) apepe (C) olele (D) iremonje
 13. Awon ti a mo pe won je iran Yoruba niwonyi ayafi (A) ogun (B) niger (C) osun (D) ondo
 14. Orin imototo je okan lara apeere orin (A) amuseya (B) eremode (C) aremo lekun (D) igbeyawo
 15. Lati fi emi imore han si obi ati molebi, orin ________ ni iyawo maa nko (A) isinku (B) amuseya (C) eremode (D) igbeyawo

IBAJE ALEJO

 1. Olu eda itan iwe yii ni (A) alonge (B) kemisola (C) doyin (D) gbolahan
 2. Eni ti won sin oku re ti aye gbo,ti orun mo ni (A) Alonge (B) oloye Boladale (C) Jimo (D) oloye Gbolahan
 3. Maalu melo ni won pa nibi isinku yii? Maluu (A) mejila (B) mejidinogun (C) metalelogbon (D) merinlelogun
 4. “Ha! Baba oloye se ona ti eyin gba lowo ko dara ni”

Tani o so gbolohun yii? (A) Alonge (B) Gbolahan (C) Olawunmi (D) Aremo

 1. Ta ni ore oloye Gbolahan lati kekere (A) Oyeniran (B) Olawunmi (C) Irepodun (D) Olawale
 2. ______ ni o se iku pa Gbolahan (A) awon ole (B) Olawunmi (C) Oyeniran (D) Alonge
 3. Ta ni o ran awon adigunjale si Oyeniran (A) Gbolahan (B) Olawunmi (C) Doyin (D) Bangbade
 4. Ojo keloo ti Oyeniran de ile iwosan ni o to laju saye (A) ojo keta (B) ojo kerin (C) ojo kaarun (D) ojo keji
 5. Nibo ni oloye Gbolahan ati ojogbon Asaolu ti koko pade (A) amerika (B) shikago (C) saina (D) Naija
 6. Kini ojogbon Asaolu n ta ? (A) paati oko (B) oko (C) baagi (D) bata
 7. Awon melo ni oloye Gbolahan ran losi meka (A) ogun (B) mesan (C) merin (D) mewa
 8. Awon meloo ni o ran lo si Jerusalemu? (A) marun (B) merin (C) meji (D) meta
 9. Osise melo ni Gbolahan ra oko fun ? (A) meje (B) mefa (C) mewa (D) eyo kan
 10. Ojo wo ni oloye Gbolahan ma n din pofu pofu fun awon osise re ? ojo (A) eti (B) abameta (C) aiku (D) isegun
 11. Nibo ni oloye Gbolahan maa n mu oruko awon osise re lo? (A) hindia (B) gabon (C) amerika (D) jerusalemu

APA KEJI

Dahun ibeere meta ni abala yii, sugbon nomba (1) se Pataki

 1. Ko aroko oju ewe kan (1pg) lori okan ninu koko wonyi
 2. Ore mi ti mo feran julo

Ii Ko leta si ore re kan lori idije onilejile ti o waye ni ile-iwe re laipe yii.

 1. Ko orin igbeyawp kan ti o mo sile
 2. Ki ni isare ajemesin?

b. ko isare ajemesin merin ati orisa ti o ni won sile

 1. Daruko isare ajemeyeye (5) ati ilu ti o ni okookan won sile
 2. Ninu iwe ibaje alejo, bawo ni Oloye Gbolahan se fi iya je Audu .

SECOND TERM EXAMINATION

Subject: YORUBA Class: JSS 1 Time:2hrs

Ka ayoka isale yi ki o si dahun ibeere ti o tele e.

Okurin agbe kan gbin isu si oko re. Awon ole maa n wa ji isu re. Ni ojo kan okunrin ole kan wa lati ji isu naa wa. O wa isu ti o po, ko si le e da a gberu. Gbogbo awon ti won rii ni ko duro gberu u. O wa nibe fun igba pipe.

Nigbati o se, ojise Olorun kan de odo re. O be e ki o ran oun lowo. Bi okunrin ojise Olorun yii ti bere ki o gbe ru u, ole yi fi osuka le e lori, won si n ja le eru titi ti oloko fi de. O gba ojise olorun yi leti, o si mu won lo si odo olopaa.

Won ye ejo won wo, won si ju ole naa si ewon. Sugbon won da ojise olorun naa sile, nitori olorun gbeja re.

IBEERE

 1. Ta ni o gbeja iranse olorun yi? (A) olopaa (B) olorun (C) oba (D) awon ero
 2. Ki ni okunrin ole yii ji? (A) ata (B) isu (C) ogede (D) agbado
 3. Tani o ran ole yii lowo? (A) awon ero (B) ojise olorun (C) olopaa (D) adajo
 4. Ta ni won gba leti? (A) ojise olorun (B) ole (C) oloko (D) olopaa
 5. Ki ni okunrin agbe naa gbin (A) isu (B) ogede (C) epa (D) ata
 6. Eka ede ti o sunmo Yoruba ajumolo julo ni (A) oyo (B) egba (C) ondo (D) ofa
 7. Lara ipinle wonyi lati ba omo Yoruba pade ayafi (A) ondo (B) kuara (C) anambra (D) ogun
 8. Okan lara ilu wonyi ni o n so eka ede akoko (A) ilesa (B) osogbo (C) arigidi (D) ipetu
 9. Eka ede _______ ni itele n so (A) ekiti (B) egun (C) egba (D) awori
 10. Eka ede egba ni awon wonyi n so (A) owu (B) bariga (C) iseyin (D) ikorodu
 11. Ojo Sunday ni Yoruba pe ni (A) aje (B) ojoru (C) isegun (D) aiku
 12. Ojo eti ni a n pe ni (A) Friday (B) Monday (C) Thursday (D) Saturday
 13. Osu karun odun ni Yoruba n pe ni ________ (A) ebibi (B) igbe (C) owara (D) ope
 14. Bawo ni Yoruba se n pe osu kini odun? (A) ogun (B) igbe (C) seere (D) erena
 15. Osu march ni a mo si (A) igbe (B) erena (C) ope (D) pelu
 16. “Introduction”ninu aroko ni ede Yoruba ni a n pe ni (A) akoto (B) ifaara (C) koko oro (D) akole
 17. Igbese akoko ninu aroko kiko ni (A) koko oro (B) ikadii (C) ifara (D) akole
 18. Ilapa ero ni a n pe ni (A) topic (B) guide line (C) paragraph (D) conclusion
 19. Ipin afo ti o pari aroko ni (A) koko ona (B) ifaara (C) ikadi (D) akole
 20. Aroko asapejuwe ni a n pe ni (A) Declarative essay (B) descriptive essay (C) narrative essay (D) expository essay
 21. Are du, arepon ni yoruba n ki (A) akope (B) agbe (C) alaro (D) babalawo
 22. Omobinrin ni lati ________ ti o ba n ki eni ti o ju lo (A) dobale (B) kunle (C) bowo (D) na duro
 23. Akoko wo ni a le ki eniyan (A) igba gbogbo (B) aaro (C) osan (D) asale
 24. Okan lara litireso atenudenu ti o ran mo esin ni (A) iyere (B) ekun iyawo (C) bolojo (D) rara
 25. Awon oyo ni o ni rara sisun nigba ti olele mimu je ti awon (A) osogbo (B) ijebu (C) ijesa (D) igbomina
 26. Awon egba lo ni _____ (A) efe (B) dadakuada (C) oku pipe (D) adamo
 27. Orisa ti o ni arungbe ni (A) oro (B) egugun (C) sango (D) oya
 28. Okan lara ona isoge Yoruba ni aye atijo ni (A) wiigi dide (B) eekanna lile (C) imu lilu (D) ila kiko
 29. Aso okunrin ni (A) kijipa (B) iro (C) mariwo (D) dandogo
 30. Eyi je ara ona isoge ni ode oni (A) ara fifin (B) eyin pupa (C) ila kika (D) eti lilu

APA KEJI

Dahun ibeere meta ni abala yi sugbon nomba one se Pataki

 1. Ko aroko oju ewe kan lori ara mi
 2. Ko osu Yoruba sile ni sise n tele
 3. Daruko eka ede Yoruba marun (5) ki o si ko ilu meji ti o wa ni abe won sile
 4. Ko orisii ila marun ti o wa ni awujo Yoruba sile
 5. Toka si abuda litireso alohun marun (5)

WPS Office: Complete office suite with PDF editor Here’s the link to the file: https://eu.docworkspace.com/d/sIJy7sPcJ7f7rsAY Get WPS Office for PC: https://www.wps.com/d/?from=t

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share