ASA IGBEYAWO

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Third  Term

 

Week : Week 9

 

Previous Topics : 

1                      Atunyewo ise saa keji.

2          EDE    Leta gbefe. Ohun ti leta gbefe je, awon ona ti a le gba ko leta gbefe

                        (deeti, ikini, Ipari).

            ASA    Igbagbo awon Yoruba nipa Olodumare.

            LIT     Awon ewi ti a n fi oro inu won da won mo. 

 3         EDE    Apola oruko

            ASA    Igbagbo ati ero Yoruba nipa orisa.

            LIT     Kika iwe apileko ti ijoba yan.

Topic :

 

EDE    Atunyewo awon awe gbolohun ede Yoruba ( olori awe gbolohun ati

awe gbolohun afibo)

ASA    Asa Isinku ni Ile Yoruba.

LIT     Kika iwe apileko.

 

 

 

 

4          EDE    Apola ise.

            ASA    Bi awon akoni eda se di orisa akunlebo (Sango, Ogun abbl)

            LIT     Kika iwe apileko ewi ti ijoba yan

 5         EDE    Iseda oro oruko ( lilo afomo ibere ati afomo aarin.

            ASA    Ikini.

            LIT     Kika iwe apileko ti ijoba yan.

6          EDE    Iseda oro oruko (lilo ilana apetunpe).

            ASA    Igbagbo awon Yoruba nipa iye leyin iku. Bo se suyo ninu asa Yoruba-

                        Isomoloruko, isinku, akudaaya (abbl).

            LIT     Awon ewi ti a fi oro inu won da won mo-ofo. Awon igbese-maye, ape

                        mora, ewu.

7          EDE    Leta aigbefe (1) ohun ti leta aigbefe je (2) awon ilana ti a le gba ko le

                        ta aigbefe-adireesi, deeti,adireesi agbaleta,ikini ibere,koko leta, ipari.

            ASA    Awon ohun mimo ninu esin ibile- igba funfun,ileke funfun, awo funfun

                        Ogiri  funfun abbl.

 

 

 

 

OSE KESA-AN

 

EDE

APOLA APONLE

Oro aponle ni awon oro tabi akojopo oro to n sise aponle fun oro ise. Apeere oro aponle ni daradara, kiakia, foo. Orisiirisii oro aponle ti ani ninu ede Yoruba ni: apola aponle oniba, apola aponle alasiko, apola aponle onibi, apola aponle onidii, apola aponle alafiwe.

Apola Aponle Oniba: Apola aponle yii maa n toka si isesi, iba tabi bi a se n se nnkan ninu gbolohun. A le lo wuren ibeere *Bawo ni* fun irufe awon gbolohun wonnyi. Fun apeere:

Pupa foo

Tutu nini

Ga fiofio

Ara baba naa ya diedie

Igi agala naa ga fiofio.

 

 

 

 

Apola Aponle Alasiko: Gege bi oruko re se ri ni. Awon wonyi ni i se pelu asiko (time). Wuren ibeere ti o wulo fun eleyi julo ni * igba wo ni*. Fun apeere:

Teni n bo ni ola

Efo ki I po ni eerun

Wa bi o ba di ale

N o wa ri o bi mo ba setan

Dolapo yoo lo si Oke Oya bi o ba gba olude olojo gbooro.

Apola Aponle Onibi: Iru apola aponle yii ni o n toka si ibi (place). Wuren ti a le lo fun eleyi ni *ibo, ibo ni*. Fun apeere:

Oloselu naa wa ni ewon (lewon)

Awon akekoo wa ni kilaasi

Kola wa ni Ibadan.

A bi Olu ni Eko

Apola Aponle Alafiwe: Apola aponle alafiwe ni a maa n lo lati fi nnkan kan we ekeji re ninu gbolohun, (bi/bii) ni o maa n se atoka won. Fun apeere.

O n se bi omugo

Biola n soro bi ologbon

Awon eniyan po repete bi i yanrin

Omo ile-iwe n gbese kemokemo bi i oga ologun.

Apola Aponle Onidii: Eyi ni o maa n toka si idi ti isele inu gbolohun da le lori. Eleyi ni o maa n toka si idi ti nnkan kan se sele ninu gbolohun. Tori/nitorii ni o maa bere aponle oro aponle lopolopo igba inu gbolohun.

A n fe iyawo nitori omo

E huwa nitori ola

Sade n lo si yunifasiti tori imo

Mo fe jeun tori ebi.

Apola Aponle Onikani: Apola oro aponle yii maa n gbe oye ‘ ki a ni ‘ jade ninu gbolohun ni.

Oga yoo sebe bi o ba ri owo gba

A o ba dupe bi baalu ba fo

Agbe yoo jo igbo naa raurau.

IGBELEWON

A    Fi oro-aponle to ba ye di alafo inu gbolohun wonyi:

 1. Ile iya agba mo……….
 2. Aja naa feju…………..
 3. Igi agbon ga ………….ninu igbo.
 4. Aja fo………… mo olowo re.
 5. wu ……. . bi i buredi olomi.

B   Fa si idi apola aponle nihin-in:

 1. A a bi ile bas u
 2. Ile Akede wa ni Ibadan.
 3. Olu fe e nitori ewa
 4. Mo gba a tayotayo
 5. lo kiakia.

IWE AKATILEWA

Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) oju iwe 128-132 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

ASA

OWE

Owe ni awon oro ti itumo won jinle ninu asa. Won maa n jeyo ti a ba n so nipa asa Yoruba kan. Bi apeere:

ASA IGBEYAWO

Bi aya ba moju oko tan, alarina a yeba

Obe ti bale ile ki i je iyaale ile ki i se

Eni fun ni lobinrin pari ore.

ASA ISOMOLORUKO

Ile laawo ki a to somoloruko.

Agba ki I wa loja ki ori omo tuntun wo.

Oruko omo ni ijanu omo.

Ti oko ba mo oju aya tan alarina a yeba

IFOWOSOWOPO

Ajeji owo kan o gbe eru dori.

Owo omode ko to pepe, ti agbalagba kan ko wo keregbe.

Gba mi lojo, ki n gba o leerun.

IGBELEWON

 • Pa owe meta ti a lo fun ifowosowopo.
 • Pa owe meji ti a le ri nibi igbeyawo.

 

AKATILEWA

 • New simplified Yoruba L1 iwe keta oju iwe 68-69 lati owo S.Y Adewoyin

APAPO IGBELEWON

A    Fi oro-aponle to ba ye di alafo inu gbolohun wonyi:

 1. Ile iya agba mo……….
 2. Aja naa feju…………..
 3. Igi agbon ga ………….ninu igbo.
 4. Aja fo………… mo olowo re.
 5. wu ……. . bi i buredi olomi.

B   Fa si idi apola aponle nihin-in:

 1. A a bi ile bas u
 2. Ile Akede wa ni Ibadan.
 3. Olu fe e nitori ewa
 4. Mo gba a tayotayo
 5. lo kiakia.
 1. Pa owe ti o je mo as igbeyawo, ifowosowopo, igbeyawo ati isomoloruko.

 

IGBELEWON

 1. Ko ona mejo ti a gba ran ara wa lowo.
 2. Salaye meta ninu awon asa iranra-eni-lowo.

 

AKATILEWA

Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 44-50 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.

 

ISE ASETILEWA

 1. Toka si atoka apola aponle ninu awon wonyi. (a) a (b) mo lo (d) nitori.
 2. Ewo ni ki i se wuren ibeere apola aponle nihin-in? (a) ewo (b) nibo/ibo (d) bi i.
 3. Fa ila si idi apola aponle ninu gbolohun yii: Biola n soro bi ologbon (a) Biola (b) soro bi (d) bi ologbon.
 4. Owo omode ko pepe ……. ? (a) ki o gun oke (b) ti agbalagba ko wo keregbe (d) ki agba gbe e.
 5. ‘Eyin iyawo ko ni mo eni’ oro yii maa n suyo ninu asa (a) igbeyawo (b) isomoloruko (d) ifowosowopo.

 

APA KEJI

 • Fa ila si idi apola aponle ninu awon wonyi:
  • Ole naa ko le soro paa lagoo olopaa
  • Ojo ro pupo gan-an lale ana
  • Ara re ya daadaa nile iwosan nigba ti a de.
  • Owo Jide tutu nini bi omi yinyin
  • O fe olomoge naa kiakia nitori ewa

 

 

8          EDE    Ami Ohun Oro Onisilebu Meji.

            ASA    Awon  Eya Yoruba ati ibi ti won tedo si.

            LIT     Kikai we Apileko ti Ijoba yan.