JSS 2 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA
YORUBA LANGUAGE SCHEME OF WORK JSS TWO
ODUN IGBEKO 2016/2017 YORUBA JSSTWO
ISE OOJO FUN SAA KIN-IN-NI
- Sise atunyewo fonoloji ede Yoruba
Atunyewo awon asa ninu ise olodun kin-in-ni
Atunyewo awon ewi alohun yoruba
- Eya gbolohun nipa ise won
Asa igbeyawo ni ile Yoruba
Kika iwe apileko ti ijoba yan
- Eya gbolohun
Asa igbeyawo ni ile Yoruba (igbeyawo ode-oni)
Kika iwe apileko oloro geere
- Gbolohun ede Yoruba nipa fifi oju ihun wo o
Sise akanse ise awujo Yoruba (project)
Litireso alohun to je mo ayeye
- Onka Yoruba (101-300)
Ise akanse kan ni awujo (project)
Litireso alohun to je mo ayeye
Kika iwe apileko ti ijoba yan
- Onka Yoruba (300-500)
Sise itoju oyun ni ona abinibi ati ode-oni
- Akaye oloro geere
Ise omo bibi (oro idile baba olomo)
Kika iwe apileko ti ijoba yan
- Akaye oloro geere
Asa isomoloruko
Kika iwe apileko ti ijoba yan
- Akoto
Igbagbo Yoruba nipa orisirisi owe ile Yoruba
Kika iwe apileko oloro geere ti ijoba yan
- Kiko Yoruba ni ilana akoto ode-oni
Orisirisi oruko ile Yoruba (igbagbo Yoruba nipa abiku)
OSE KIN – IN – NI
EKA ISE – EDE
AKOLE ISE – SISE ATUNYEWO FONOLOJI EDE YORUBA
Fonoloji ni eko nipa eto iro.
A le saleye eko nipa eto iro labe awon ori oro wonyi ninu ede Yoruba
- Iro faweli
- Iro konsonanti
- Eto silebu
- Ohun
- Ipaje
- Aranmo
- Oro ayalo
- Apetunpe abbl.
Atunyewo faweli ati konsonanti
faweli ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi.
Iro faweli pin si ona meji,
- Iro faweli airanmupe (7) meje
Aa Ee Ee Ii Oo Oo Uu
- Iro faweli aranmupe (5) marun-un
an en in on un
Bi a se n ko faweli ni ilana fonetiki niyi
A [ a]
e [e]
e [e]
i [i]
o [o]
o [ o ]
u [u]
an [ an]
en [Ệ]
in [Ῐ]
on [ on]
un [u]
Konsonanti ni iro ti a gbe jade nigba ti idiwo wa fun eemi.
Apapo konsonanti ede Yoruba je meji-dinlogun (18)
Bi a se n ko konsonanti ni ilana fonetiki.
b [b]
d [d]
f [f]
g [g]
gb [gb]
h [h]
j [j]
k [k]
L [L]
M [m]
n [n]
p [kp]
r [r]
s [s]
ṣ [ ]
t [t]
w [w]
y [j]
ATUNYEWO SILEBU
Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade lee kan so so lai si idiwo.
Iye ami ohun ti o jeyo ninu oro kan ni iye silebu iru oro bee.
IHUN SILEBU
- Faweli nikan (F)
- Apapo konsonanti at faweli (KF)
- Konsonanti aranmupe asesilebu (N)
Apeere silebu faweli nikan (F)
- Mo sun un je
- Oluko ran an leti ounje
- Mo ri i
- Mo ra a
Akiyesi: Gbogbo faweli airanmupe ati faweli aranmupe le duro gege bi silebu kan ninu oro.
Apeere apapo konsonanti ati faweli (KF)
- Gb + o
- R + in
- W + on
- T + a
- J + e
Apeere konsonanti konsonanti aranmupe asesilebu (n)
- Tade n je isu
- Mo n lo
- Ba-n-gba-de
- o-ge-de-n-gbe
Akiyesi: Konsonanti aranmupe asesilebu le duro gege bii silebu kan.
Eka ise: Asa
Akole Ise: ATUNYEWO AWON ASA NINU ISE OLODUN KIN-IN – NI.
Asa ni iwa ajumolo awon eniyan ati isesi won. Yoruba ka asa si lopolopo, orisirisi asa si ni awon Yoruba le mu yangan lawujo. Lara awon asa naa niyi
- Asa iranra-eni-lowo
- Asa ikini
- Asa ogun jije abbl.
ASA IKINI
Asa ikini je okan lara iwa omoluabi ti a gbodo ba lowo omo ti a bi, ti a ko ti o si gba eko rere.
Yoruba bo won ni “ka ri ni lokeere, ka sayesi, o yoni, o ju ounje lo” ni ile Yoruba omokunrin maa n do bale gbalaja ti awon omobinrin yo si lo lori ikunle ti won ba n ki obi tabi awon ti o ju won lo.
Omo ti o ba ka asa ikini si ti o si n bowo fun agba, Yoruba ka iru omo bee si omo gidi, to gbon ti o si ni eko ile.
ASA OGUN JIJE.
Ti eru kan ba ku ni ile Yoruba, gbogbo dukia tabi eni ti o ba fi sile ni a n pe ni ogun.
Eto wa lori bi a se n pin ogun ni ile Yoruba. leyin ti won ba ti sofo eni ti o ku tan ni won maa n pin ogun re ki dukia re maa ba da ija sile.
Eni ti o ba dagbe ju ninu agboole kan ni o maa n seto ogun pinpin ni ile Yoruba, awon agba yii yoo se iwadii bii oloogbe se se ilana pinpin ogun re sile ko to jade laye, ti eyi ba wa, won yoo lo o, sugbon ti ko ba si , awon agba ile yoo lo laakaya won lati se iwadii lori gbogbo ohun ti oloogbe fi saye won yoo si pin bi o ti to laaarin awon omo, iyawo ati aburo oloogbe.
Lara awon ohun ti a le pin gege bii ogun ni ile, ile, aso, oko, iyawo, omo oku to kere, oso ara, gbese abbl.
ASA IRANRA-ENI LOWO
Asa iranra-eni lowo je okan lara ona ti Yoruba n gba lati ran ara won lowo nibi ise won gbogbo.
Orisi ona ti Yoruba n gba ran ara won lowo laaye atijo niyi,
- Esusu: Iye owo ti eniyan ba da ni yoo gba
- Ajo: Eniyan le gba ju iye ti o ba da lo
- Owe: Omokunrin ti o ni iyawo ni o maa n be awon ore re lowe
- Aaro: Sisise ni oko awon ti o sun mora titi yoo fi kari
- Aroko doko: Eyi ni sisise ni oko eni-kookan titi yoo fi kari sugbon kii se oko awon ti o sun mora nikan.
Lode-oni: Egbe alafowosowopo je ona ti a n gba ran ara eni lowo.
Egbe yii n bo asiri nipa yiya ni lowo , o si fi aaye sile lati daa pada ni diedie.
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: ATUNYEWO AWON EWI ALOHUN YORUBA.
Litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan tabi omiiran.
Litireso alohun je apa kan ninu isori litireso. Eyi ni ewi ti a jogun lati enu awon babanla wa.
Lara awon ewi alohun Yoruba ni,
- Ofo
- Oriki
- Ese-ifa
- Ayajo
- Ogede abbl.
Ewi je akojopo oro ijinle ti o kun fun ogbon, imo ati oye.
Ese-ifa: O je amu fun ogbon, imo ati oye awon Yoruba. Orunmila ni orisa awon onifa.
Ofo: Ofo je awon oro ti a n so jade ti a fi n segba leyin oogun tabi ti a n pe lati mu ero okan wa se.
Ayajo: inu ese-ifa ni a ti mu ayajo jade. Oro enu lasan ni ko nilo oogun bii ti ofo.
Ogede: Ohun enu ti o lagbara ju ohun enu lo ni ogede. Eni ti o ba fe pe ogede gbodo bii ero ki o to le pe ogede bee ni yoo ni ohun ti yoo to le bi o be ti pee tan.
Oriki: Yoruba n lo oriki fun iwin a ni oriki oruko, oriki orike, oriki boro kinni, oriki idile abbl.
Igbelewon:
- Fun fonoloji loriki
- Sapejuwe iro faweeli ati iro konsonanti
- Kin ni silebu?
- Salaye ihun silebu ede Yoruba
- Fun asa loriki
- Daruko awon asa ile Yoruba
- Salaye awon asa naa ni kukuru
Ise asetilewa: salaye asa iranra-eni lowo ode-oni lekun-un rere
OSE KEJI
EKA ISE – EDE
AKOLE ISE EYA GBOLOHUN NIPA ISE WON
Gbolohun ni afo ti o kun, to si ni ise to n se nibikibi ti won ba ti je jade.
Gbolohun ni olori iso.
Eya gbolohun nipa ise won
- Gbolohun alalaye
- Gbolohun Ibeere
- Gbolohun ase
- Gbolohun ebe
- Gbolohun ayisodi
Gbolohun alalaye:Eyi ni a fi n se iroyin bi isele tabi nnkan se ri fun elomiran lati gbo. Apeere;
- Ebi n pa mi
- Tisa lo gba iwe e mi
- A ti ri gbogbo won abbl.
Gbolohun Ibeere:Eyi ni ona ti a n gba se ibeere nipa lilo atoka asebeere bii, ta ni, ki ni, ba wo, me loo, igba wo, nibo, sebi, abi abbl.
- Nje won gba?
- Se Ade wa?
- Eran meloo lo je?
- Ta ni o jale?
Gbolohun Ase: Eyi ni gbolohun ti a fi n pase fun eni ti a n ba soro. Apeere.
- Dide duro
- E dake jeje
- Wa ri mi
Gbolohun Ebe: A n lo gbolohun ebe lati fi bebe fun ohun kan. Apeere
- Fun mi ni omi mu
- Jowo maa bu mi mo
- Bami toju re daa daa
Gbolohun Ayi sodi:Gbolohun yii maa n fihan pe isele kan ko waye. Itunmo re ni beeko. Awon oro atoka gbolohun ayisodi ni; ko, kii, ko i, le
Apeere;
- Olu ko le lo
- Jide kii se ako igba
- Oluko koi ti lo le
- Bola ko wa ni ana
EKA ISE ASA
AKOLE ISE ASA IGBEYAWO NI ILE YORUBA.
Asa Yoruba je okan lara awon asa to se Pataki ni awujo Yoruba. Igbeyawo je asa ti Eledumare pa fun eniyan lati maa bi sii ki a si maa re sii.
Gege bi owe Yoruba ti o wi pe “bi omode ba to loko ni a n fun loko” Omokunrin ni o maa n gbe iyawo, ti a si n fomo obinrin foko ni ile Yoruba.
Ilana asa Igbeyawo Ibile.
- Eto Ifo jusode: Eyi ni ohun akoko ti awon obi omokunrin ti o ti to laya yoo se lati ba omo won okunrin wa omo binrin ti o lewa ti o si niwa.’
- Alarina: Eyi ni eni ti yoo maa sotun-sosin laarin awon omokunrin ati omobinrin leyin ti a ba ti se iwadii nk,.idile ati iru ebi ti omobinrin naa ti wa.
- Ijohen/Isihun: Ni gba ti omobinrin ba ti gba lati fe odomokunrin ni a n pe ni Ijohen. Leyin eyi ni omokunrin yoo fun omobinrin ni owo akoko ti a n pe ni “Owo Ijohen”
- Itoro: Awon obi ati ebi omokunrin ni yoo lo si ile awon omobinrin lati lo toro re gege bii iyawo afesona fun omo won.
- Idana: Oniruuru ohun ti enu nje bii igo oyin, ogoji isu, obi, orogbo, apo iyo kan, igo oti, aadun, eso lorisirisi aso iro meji, owo idana, ni ebi omo kunrin naa yoo ko lo ile obi omobinrin ti won fe fi se aya fun omo won leyin naa, won a mu ojo igbeyawo.
- Ipalemo: Eyi ni sise eto lori bi ojo igbeyawo yoo se yori si ayo.
- Igbeyawo: Ojo yii gan-an ni eto igbeyawo lekun-un rere. Sise –siso yoo wa nile iyawo ati oko, iyawo yoo maa gba ebun lorisirisi ati owo. Ojo yii gan-an ni iyawo yoo fi a yo, orin ati ekun gba adura lodo awon obi re.
ASA IBAALE
Ibaale je asa ti o se Pataki ninu igbeyawo ibile. O je apeere pe iyawo ko tii ni ibasepo kan-kan ri pelu okunrin.
Ti oko ba ba iyawo re nile, yoo gbe paali isana ti o kun fofo, ekun akeegbe emu ati owo ibale ranse si awon obi iyawo re lati fihan pe won to omo won daadaa ati lati fi dupe.
PATAKI IBAALE
- O je ami iyi ati eye fun iyawo, obi iyawo ati gbogbo ebi iyawo
- Ko si ifoya pe iyawo ti ko aarun ibalopo.
- O n so ife laarin lokolaya ati ebi po.
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE kika iwe apileko alohun to je mo aseye ti ijoba yan.
Igbelewon:
- Fun gbolohun loriki
- Salaye eya gbolohun ede Yoruba
- Salaye ilana igbeyawo ibile lekun-un-rere
Ise asetilewa: bawo ni asa ibale se ye o si? Ko Pataki ibale meta pere
OSE KETA
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: EYA GBOLOHUN
Gbolohun Onibo
Eyi ni gbolohun ti a fi gbolohun miiran bo inu re.
Gbolohun onibo pin si;
- Gbolohun onibo asaponle
- Gbolohun onibo asapejuwe
- Gbolohun onibo asodoruko
Gbolohun Onibo asaponle
Eyi ni gbolohun ti a fi n se aponle ninu gbolohun nipa lilo oro atoka “ti” tabi “bi”. Apeere.
- Awon ole yoo sa bi awon ode ba fon fere
- Ti awon ode ba fon fere awon ole yoo sa.
Akiyesi: A le gbe won funra lai so itumo gbolohun naa nu.
Gbolohun onibo asapejuwe.
Inu apola-Oruko ni gbolohun onibo asapejuwe maa n wa. Oro atoka “ti” ni o n lo.
- Ile ti ola n gbe dara
- Tunde ra aso ti o ni awo ewe.
- Oko ti oluko ra rewa
Gbolohun onibo asodoruko
Atoka gbolohun onibo asodoruko ni “pe”. Atoka yii maa n yipada di oro oruko ninu gbolohun. Apeere;
- O dara pe o ri se si ile epo
- Pe o le jale o dun mi pupo.
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: ASA IGBEYAWO NI ILE YORUBA – IGBEYAWO ODE -ONI
Ni aye ode –oni omokunrin ati omobinrin ni o n ri ara won ba soro laisi alarina tabi ifojusode obi.
A le pin igbeyawo ode-oni si ona meta. Awon ni yi;
- Igbeyawo soosi
- Igbeyawo Mosalasi/yigi siso
- Igbeyawo Kootu
IGBEYAWO SOOSI
Eyi ni igbeyawo laaarin omokunrin ati omobinrin ninu soosi. Igbeyawo yii wopo laarin elesin kiristi. Alufaa ijo ni o maa n so okunrin ati obinrin po pelu eleri lati inu ebi mejeeji. Ko si aaya fun ikosile tabi ki okunrin ni ju aya kan lo ni igbeyawo soosi.
Eto Igbeyawo Soosi.
- Baba iyawo ni yoo mu iyawo wo inu soosi
- Alufaa yoo gba tokotaya ni imoran bi won se le gbe igbe aye alaafia ninu Jesu.
- Ikede: Alufaa yoo bere lowo ijo boya a ri enikan ti o ni idi kan ti ko fi ye ki a so took taya po ki o wi tabi ki a pa enu mo titi Jesu yoo fi de.
- Alufaa yoo so pe ki tokotaya wa si waju, lati so won po pelu eje pe iku nikan ni yoo ya won.
- Alufaa yoo fun won ni oruka gege bi edidi igbeyawo.
- Alufaa yoo fi won han gbogbo ijo gege bi oko ati aya.
- Ifowo si iwe: Oko, Iyawo ati awon obi won yoo fi owo si eri igbeyawo pelu ijo ati ayo.
- Leyin eyi ni gbogbo ijo yoo lo si yara igbalejo fun jije, mimu, bibu akara oyinbo, ijo, gbigba ebun abbl.
IGBEYAWO MOSALASI/YIGI SISO
Eyi ni igbeyawo laarin okunrin ati obinrin ti o waye ni mosalasi,tabi ibudo miiran ti oko ati aya ba fe.
Eto Igbeyawo Mosalasi
- Adura Ibeere
- Aafaa yoo bere lowo obi oko ati aya boya won gba lati je ki awon omo won fe ara won.
- Aafaa yoo kewi bee ni yoo gba oko ati iyawo ni imoran lati gbe aye alaafia gege bi loko laya.
- Awon obi mejeeji yoo sadura fun awon omo won pelu owo adura lowo
- Aafaa yoo fi oruka si oko ati iyawo lowo pe gege bi edidi ife won
- Bakan naa, Aafaa yoo se ifilo pe aaye wa fun oko lati fe iyawo miiran le iyawo to fe ati pe won le fi ara won sile ti won ba ri pe ko si ife mo laarin won.
IGBEYAWO KOOTU
Eyi ni igbeyawo ti okunrin ati obinrin yoo lo si kootu ijoba lati so ara won po pelu ofin. A tun le pee ni igbe yawo Alarede.
ETO IGBEYAWO KOOTU
- Okunrin ati obinrin yoo koko lo fi oruko sile lodo akowe kootu
- Leyin naa ni won a gbe ohun jije, ati mimu bii, bisikiti, eso, oti elerin didun abbl. Lo si kootu.
- Adajo ile ejo, yoo kede boya ariwisi wa si isopo awon mejeeji
- Ni ojo igbeyawo, oko iyawo ati awon asoju won yoo lo si ile ejo lati bura gege bi esin won
- Oko, iyawo, awon obi, asoju ati awon eleri meji yoo fi owo si iwe eri igbeyawo.
- Ba kan naa, oko ati iyawo yoo fi oruka si ara won lowo.
- Leyin eyi, akowe kootu yoo se ifilo pe oko ko le fe iyawo miiran lai se pe o jawe ikosile fun iyawo re ni ilana ofin.
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: Kika Iwe Apileko Oloro Geere Ti Ijoba Yan
Igbelewon :
- Kin ni gbolohun onibo?
- Ko isori gbolohun onibo
- Salaye asa igbeyawo ode-oni lekun-un-rere
Ise asetilewa: Gege bi esin re, salaye ilana igbeyawo ode-oni
OSE KERIN
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: Gbolohun Ede Yoruba nipa fifi oju ihun wo o.
Gbolohun je akojopo oro ti o ni oro ise ati ise ti o n je nibikibi ti o ba ti jeyo.
Gbolohun Abode/Eleyo oro-ise
Eyi ni gbolohun ti ko ni ju oro-ise kan lo.
Gbolohun Abode kii gun, gbolohun inu re si gbode, je oro ise kikun.
Apeere;
- Dosunmu mu gaari
- Aduke sun
- Olu ra iwe
Ihun gbolohun Abode/Eleyo Oro –Ise
- O le je oro-ise kan Apeere; lo, sun, joko, dide, jade, wole
- Oro ise kan ati oro apola Apeere;
- Aniike sun fonfon
- Alufaa ke tantan
- Ile ga gogoro
- d) Oluwa, oro ise ati abo Apeere
- Ige je ebe
- Ibikunle pon omi
- Oluko ra oko
- e) O le je oluwa, oro ise kan, abo ati apola atokun. Apeere.
- Aina ru igi ni ona
- Ojo da ile si odo
- e) O le je oluwa oro ise kan ati oro atokun. Apeere;
- Mo lo si oko
- Baba wa si ibe
Gbolohun Alakanpo.
Eyi ni gbolohun ti a fi oro asopo kanpo mora won.
Akanpo gbolohun eleyo oro-ise meji nipa lilo oro asopo ni gbolohun alakanpo.
Awon oro asopo ti a le fi so gbolohun eleyo oro-ise meji po ni wonyi, Ayafi, sugbon, oun, ati, anbosi, amo, nitori, pelu, tabi, koda, boya, yala abbl. Apeere;
- Olu ke sugbon n ko gbo.
- Atanda je isu amo ko yo
- Tunde yoo ra aso tabi ki o ra iwe
- Mo san owo nitori mo fe ka we abbl.
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE; SISE AKANSE ISE AWUJO YORUBA (PROJECT)
Awon Ise awujo Yoruba je ise abinibi/ise isenbaye.
Ise isebaye ni ise iran ti ajogun lati owo awon babanla wa.
Iran Yoruba lodi si iwa imele idi niyi ti won fi mu ise sise ni Pataki.
AWON ISE AKANSE ILE YORUBA
- Eni hihun
- Ikoko mimu
- Irin riro
- Aro dida
- Igba finfin abbl.
Alaye lori die lara ise akanse ile Yoruba.
- ISE IKOKO MIMO: ise ikoko mimo wopo ni agbegbe Ilorin, oyo, ipetunmodun, ise obinrin ni ise ikoko mimo, awon ohun elo ikoko mimo ni wonyi; Amo, omi, odo, isaasun obe, ekusu agbado.
IGBESE MIMO IKOKO.
Gigun amo ninu odo pelu omi die, yoo mu dada.A oo gbe ikoko miiran/isaasun lati fi se ipinle bee ni a oo da oju ikoko naa de ile nipa mimo amo sii ni idi yika lati se odiwon ohun ti a fe mo.
Ti amo yii ba gbe die, a oo yo ikoko ti a fi se ipinle kuro, a oo si fi ekusu gbado se ona si ikoko ti a mo lara , a oo si sa sinu oorun.
Leyin ti o ba ti gbe tan, a o fi ina sun ikoko amo naa jinna daada.
- ISE AGBEDE
Okan lara ise ona ni ise yii je. Awon alagbede ni won n ro ohun elo bii, ada, oko, obe,
Irinse ise Agbede/irin riro ni wonyi
Owu | Gbinrin | Ikoko omi abbl |
Omo owu | Ewiri | |
Iponrin | Emu |
- ISE ARO DIDA
Kaakiri ile Yoruba ni ise aro-dida ti wopo. Ise obinrin ti o gba nini imo kikun nipa aro pipo, imo nipa awo ati batani ni ise aro-dida je.
Ohun elo-ise ni: ikoko nla,omi, aro, orogun gigun/opa, paafa, aso teru, abbl.
Opa ti a fi n ro aro ninu ikoko aro ni a n pe ni “opa aro”. “ori paafa” ni a n yo aso ti a yo ni aro si.
IGBESE ARO – DIDA
A oo fi aso teeru sinu aro fun iseju bi mewaa leyin naa, a oo ju aso naa si ori paafa, yoo lo bii iseju mewa pelu lori paafa.
Leyin iseju mewaa naa, a oo tun so pada sinu aro, eyi ni a oo se titi aso naa yoo fi dudu bi a se fe. Ni gba ti o ba ti mu abajade ti a fe jade, a oo yo kuro ninu aro lati sa.
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: LITIRESO ALOHUN TO JE MO AYEYE.
Litireso je ona ti Yoruba n gba lati fi ero inu won han lori ohun ti a je koko tabi iriri aye won.
ISORI LITIRESO
- Litireso alohun
- Litireso apileko
Litireso alohun ni litiresso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon babanla wa.
Litireso apileko ni litireso ti a se akosile re nigba ti imo moo ko – moo ka de si ile wa.
Litireso alohun ajemayeye
Eyi ni awon litireso ti a n lo lati gbe asa laruge nibi ayeye gbogbo.
Awon ewi alohun ajemayeye niwonyi,
- Ekun iyawo
- Dadakuada
- Bolojo
- Etiyeri
- Rara
- Alamo
- Oku pipe
- Efe abbl
EKUN IYAWO
Eyi ni ewi ti a maa n lo ni ibi ayeye ti omobinrin ti n lo si ile oko.
O je ewi ti omobinrin ti o n lo si ile oko maan sin lojo igbeyawo lati je ki a mo pe oun mo riri, itoju ti awon obi se nigba ti oun wa ni ewe.
Ewi yii wopo laarin agbegbe bi, iseyin ikirun, Ede, Osogbo, oyo, ogbomoso. Ekun iyawo je ewi ti o nko wondia leko lati pa ara re mo titi di ojo igbeyawo.
Apeere ekun iyawo sisun
Iya mo n lo
Mo wa gbare temi n to maa lo
E ba sure ki n lowo lowo
E ba sure ki n sowo, n jere
E ba sure ki n bimo lemo
E ba sure ki n ma kelenini loode oko
Ire loni, ori mi a fi re
Hi hi hihin (ekun)
ETIYERI
Etiyeri je ere awon odo okunrin ni gbegbe oyo. Awon ohun elo orin etiyeri ni, Agogo, ilu sakara, sekere.
Etiyeri maa n gbe ago/eku bori bi egungun sugbon kii bo gbogbo ara re tan. olori ti o gbe ago wo ni yoo maa le orin ti awon yooku yoo si maa gbe.
Oro awada, eebu, yeye, apara, po ninu orin etiyeri bee ni oro bi epe bi epe ni won fi n se ihure won
Apeere
Lile: Mo setan
Eyin menugun
Mo setan ti n o rode
Kikona ko ma ko mi lona o
Egbe: Ha ha ha, mo se tan
Eyin menugun
Mo setan ti n o rode
Kikona ko ma ko mi lona o
Lile: mo setan
Eyin menugun
Mo setan ti n o korin
Ko gbigba ko ma gba mi lohun o
Egbe: Mo se tan
Eyi menugun
Mo setan ti n o korin
Kogbigba ko ma gba mi lohun o……
DADAKUADA
Ewi yii je adapo ilu ati orin.
Iwulo orin dadakuada
- Won fi n ki eniyan
- Won fi n panilerin
- Won fi n bu eniyan
- Won fi n kilo iwa
- Won fi n toka aleebu awujo
Orin Dadakuada wopo ni agbegbe Ilorin, awon okunrin ni o saaba maa n se ere yi. Olori yoo ma le orin, enikan yoo si maa soro lori orin naa ki awon elegbe to gbe e.
Apeere: “Ko sohun t’olorun o lee se
Amo ohun t’olorun le se ti o ni
Se lopo
Keeyan o geri maagoro ko ka
Ibepe ni be
Oloun le se e o
Amo bo ba se e, iru wa o tu bu
Emi mo pe n o lee j’Alaafin oyo
Laelae
Iwo naa o si lee joba ilu Ilorin wa
Afonja enu dun juyo waa te
Yan – an – yan”.
Igbelewon :
- Kin ni gbolohun?
- Fun gbolohun abode loriki
- Salaye ihun gbolohun abode
- Fun ise isembaye loriki
- Daruko awon ise isembaye ile Yoruba
- Kin ni litireso?
- Ko isori litireso ede Yoruba
- Salaye litireso ajemayeye pelu apeere
Ise asetilewa: ise sise ninu iwe ilewo Yoruba Akayege
OSE KARUN – UN
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: Onka Yoruba (101 – 300)
Onka Yoruba je ona ti a n gba lati ka nnkan ni ona ti yoo rorun.
Onka ni bi a se n siro nnkan ni ilana Yoruba.
JSS 3 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA
Onka Yoruba lati ookanlelogorun-un de eedegbeta
ONKA FIGO | ONKA NI EDE YORUBA |
101 | OOkanlelogorun-un |
102 | Eejilelogorun-un |
103 | Eetalelogorun-un |
104 | Eerinlelogorun-un |
105 | Aarundulaa-adofa |
106 | Eerindinlaa-adofa |
107 | Eetadinlaa-adofa |
108 | Eejidinlaa-adofa |
109 | Ookandinlaa – adofa |
110 | Aadofa |
111` | Ookanlelaa-adofa |
112 | Eejilelaa-adofa |
113 | Eetalelaa-adofa |
114 | Eerinlelaa-adofa |
115 | Aarundinlogofa |
116 | Eerindinlogofa |
117 | Eetedinlogofa |
118 | Eejidinlogofa |
119 | Ookandinlogofa |
120 | Ogofa |
121 | Ookanlelogofa |
122 | Eejilelogofa |
123 | Eetalelogofa |
124 | Eerunlelogofa |
125 | Aarundinlaa-adoje |
126 | Eerundunlaa-adoje |
127 | Eetadunlaa-adoje |
128 | Eejidunlaa-adoje |
129 | Oookadinlaa- adooje |
130 | Aadoje |
131 | Ookanlelaa –adoje |
132 | Eejilelaa-adoje |
133 | Eetalelaa-adoje |
134 | Eerunlelaa-adoje |
135 | Aarundinlo-goje |
136 | Eerundinlogoje |
137 | Eetadiinlogoje |
138 | Eejidinlogoje |
140 | Ogoje |
141 | Okandinlogoje |
142 | Eejilelogoje |
143 | Eetalegoje |
144 | Eerunlelogoje |
145 | Aarundunlaa-adoje |
146 | Eerundinlaa-adoje |
147 | Eetadinlaa-adoje |
148 | Eejidinlaa-adoje |
149 | Ookandinlaa-adoje |
150 | Aadojo |
151 | Ookanlelaa-adojo |
152 | Eejilelaa-adojo ` |
153 | Eetalelaa-adojo |
154 | Eerunlelaa-adojo |
155 | Aarundinlogojo |
156 | Eerundinlogojo |
157 | Eetadinlogojo |
158 | Eejidinlogojo |
159 | Ookandinlogojo |
160 | Ogojo |
161 | Ookanlelogojo |
162 | Eejilelogojo |
163 | Eetalelogojo |
164 | Eerunlelogojo |
165 | Aarundinlaa-adosan-an |
166 | Eerundinlaa-adosan-an |
167 | Eetadinlaa-adosan-an |
168 | Eejidinlaa-adosan-an |
169 | Ookandinlaa-adosan-an |
170 | Aadosan-an |
171 | Ookanlelaa-adosan-an |
172 | Eejilelaa-adosan-an |
173 | Eetalelaa-adosan-an |
174 | Eerunlelaa-adosan-an |
175 | Aarundinlogosan-an |
176 | Eerundinlogosan-an |
177 | Eetadinlogosan –an |
178 | Eejidinlogosan-an |
179 | Ookandinlogosan-an |
180 | Ogosan-an |
181 | Ookanlelogosan-an |
181 | Ooknlelogosan-an |
182 | Eejilelogosan-an |
183 | Eetalelogan-an |
184 | Eerunlelogosan-an |
185 | Aarundinlaa-adowaa |
186 | Eerundunlaa-adowaa |
187 | Eetadinlaa-adowaa |
188 | Eejidinlaa-adowaa |
189 | Ookandinlaa-adowaa |
190 | Aadowa/igba-o-din kewa |
191 | Ookanlelaa –adowa |
192 | Eejilelaaa-adowa |
193 | Eetalelaa-adowa |
194 | Eerunlelaa-adowa |
195 | Aarundiin-nigba |
196 | Eerundin-nigba |
197 | Eetadin-nigba |
198 | Eejidin-nigba |
199 | Ookandin-nigba |
200 | Igba/ogowaa |
201 | Igba ole-kan |
202 | Igba ole-meji |
203 | Igba ole-meta |
204 | Igba ole-merin |
205 | Igba ole marun-un |
206 | Igba ole-mefa |
207 | Igba ole-meje |
208 | Igba ole-mejo |
209 | Igba ole-mesan-an |
210 | Igba ole-mewaa |
211 | Ookoolenigba-odun mesan (220-9) |
212 | Okoolenigba-odun mejo (220-8) |
213 | Okoolenigba-odun meje (220-7) |
214 | Okoolenigba-odun mefa (220-6) |
215 | Okoolenigba-odun marun-un (220-5) |
216 | Okoolenigba-odun merun (220-4) |
217 | Okoolenigba –odun meta (220-3) |
218 | Okoolenigba- odun meji (220-2) |
219 | Okoolenigba-odin kan (220-1) |
220 | Okoolenigba |
221 | Okoolenigba ole-kan |
222 | Okoolenigba ole-meji |
223 | Okoolenigba ole-meta |
224 | Okoolenigba ole- merin |
225 | Okoolenigba ole-marun-un |
226 | Okoolenigba ole-mefa |
227 | Okoolenigba ole-meje |
228 | Okoolenigba ole-mejo |
229 | Okoolenigba ole-mesan-an |
230 | Okoolenigba ole-mewaa/ojilenigba odin mewaa |
231 | Ojinlenigba odin-mesan-an |
232 | Ijilenigba odin-mejo |
233 | Ojilenigba odin-meje |
234 | Ojilenigba odin- mefa |
235 | Ojilenigba odin -marun-un |
236 | Ojilenigba odin-merin |
237 | Ojilenigba odin-meta |
238 | Ojilenigba odin-meji |
239 | Ojilenigba odin-kan |
240 | Ojilenigba |
241 | Ojilenigba ole-kan |
242 | Ojilenigba ole-meji |
243 | Ojilenigba ole-meta |
244 | Ojilenigba ole-merin |
245 | Ojilenigba ole-marun-un |
246 | Ojilenigba ole-mefa |
247 | Ojilenigba ole-meje |
248 | Ojilenigba ole-mejo |
249 | Ojilenigba ole-mesan-an |
250 | Ojilenigba odin-mesan-an |
252 | Otalenigba odin-mejo |
253 | Otalenigba odin- meje |
254 | Otalenigba odin-mefa |
255 | Otalenigba odin-marun-un |
256 | Otalenigba odin-merin |
257 | Otalenigba odin- meta |
258 | Otalenigba odin-meji |
259 | Otalenigba odin-kan |
260 | Otalenigba |
261 | Otalenigba ole-kan |
262 | Otalenigba ole-meji |
263 | Otalenigba ole-meta |
264 | Otalenigba ole-merin |
265 | Otalenigba ole-marun-un |
266 | Otalenigba ole-mefa |
267 | Otalenigba ole-meje |
268 | Otalenigba ole-mejo |
269 | Otalenigba ole-mesan-an |
270 | Otalenigba ole-mewa/orulenigba odin-mewaa |
271 | Orinlenigba odin-mesan-an |
272 | Orinlenigba odin-mejo |
273 | Orinlenigba odin-meje |
274 | Orinlenigba odin mefa |
275 | Orinlenigba odin-marun-un |
276 | Orinlenigba odin-merin |
277 | Orinlenigba odin-meta |
278 | Orinlenigba odin-meji |
279 | Orinlenigba odin-kan |
280 | Orinlenigba |
281 | Orinlenigba ole-kan |
282 | Orinlenigba ole-meji |
283 | Orinlenigba ole-meta |
284 | Orinlenigba ole-merin |
285 | Orinlenigba ole-marun-un |
286 | Orinlenigba ole-mefa |
287 | Orinlenigba ole-meje |
288 | Orinlenigba ole-mejo |
289 | Orinlenigba ole-mesan-an (280+10) |
290 | Orinlelugba ole-mewaa/odunrin odin-mewaa (300-10) |
291 | Odunrun odin mesan-an (300-9) |
292 | Odunrin odin mejo (300-8) |
293 | Odunrin odin meje 300-7) |
294 | Odunrin odin mefa (300-6) |
295 | Odunrun odin marun-un (300-5) |
296 | Odunrun odin merin (300-4) |
297 | Odunrun odin meta (300-3) |
298 | Odunrun odin meji (300-2) |
299 | Odunrun odin kan (300-1) |
300 | Oodunrun |
Eka ise:- Asa
Akole ise: ise akanse kan ni Awujo Yoruba (project)
Gege bi a se salaye ninu idanilekoo ti o koja pe oniruru ise isenbaye/abinibi ni a n se ni ile Yoruba.
Lara ise akanse ile awujo Yoruba ti a oo da wole ni sise ni ose yii ni ;
- Aro dida
- Ikoko mimo
Eka ise:- litreso
Akole ise:- litreso alohun to je mo ayeye /kika iwe apileko ti ijoba fowo si.
Lara litreso alohun ti o je mo ayeye ni,
- Rara
- Bolojo
- Alamo
Rara
Rara je litreso atigbadegba lawujo Yoruba. A n lo o lati fi oba, ijoye, olowo, olola, gbajum han .
Awon obinrin ile to mo atupale oriki oko daadaa maa n fi rara sisun pon oko le. Tokunrin tobinrin ni o n sun rara. Ewi yii wopo ni agbegbe Iseyin, Ogbomoso, Ede, Ikirun, Ibadan. Apeere,
Akanni o
Omo lofamojo
Omo ola lomi
Kekere olowo oko mi o
T ‘ori’ lukuluku
B ‘emo eebo
Bolojo
A n ko orin bolojo lati fi se aponle, tu asiri, se efe, soro nipa oro ilu, oro aje, ki eniyan to n se rere ati lati dekun iwa aito.
Awon okunrin yewa ni o saba maa n ko orin bolojo. A n ko orin bolojo ni ibi ayeye igbeyawo isomoloruko, oye jije, isile abbl. Apeere
Bo sale e wa ba mi lale
Bo si je koro wa ba mi o jare
Bo sale e wa ba mi lale
Ohun o ba fi mi se
Gbogbo aye ni n o ro o fun
Alamo
Won n salamo lati bu eniyan ti n huwa ibaje bee ni won n loo lati ki eni to ba n nawo fun won ni bi ayeye.
Ewi yii gbajumo laarin awon ekiti. Awon obinrin ni o maa n salamo pelu eka ede ekiti.
Igbelewon :
- Kin ni onka?
- Ka onka lati 101-300
- Mu ise akanse kan ni awujo ki o si salaye lekun un rere
- Daruko awon litireso alohun ajemayeye ki o si salaye
Ise asetilewa: mu okan lara ise akanse ile Yoruba wonyi ki o fi se ise se:
- Ikoko mimo
- Eni hihun
OSE KEFA
Eka Ise:- Ede
Akole ise: onka Yoruba (300-500)
Onka Yoruba lati oodunrun de Eedegbeta
Figo | |
300 | Oodunrun |
305 | Oodunrun ole-marun-un |
310 | Oodunrun ole-mewa |
315 | Okooleloodunrun odunarun-un |
320 | Okooleloodunrun |
325 | Okooleloodunrun ole-marun-un |
330 | Okooleloodunrun ole-mewaa |
335 | Ojileloodunrun odin marun-un |
345 | Ojileloodunrun ole-marun-un |
350 | Ojileloodunrin ole-mewaa |
360 | Otaleloodunrin |
365 | Otaleloodunrun ole-marun-un |
370 | Otaleloodunrun ole-mewaa |
375 | Orinleloodunrun odin- marun-un |
380 | Orinle looduunrun |
385 | Orunleloodunrun ole-marun-un |
390 | Orunleloodunrun ole-mewaa |
395 | Irinwo odin- marun-un |
400 | Irinwo |
405 | Irinwo ole- marun-un |
410 | Irinwo ole-mewaa |
415 | Okoolenirinwo odin- marun-un |
420 | Okoolenirinwo |
425 | Okoolenirinwo ole marun-un |
430 | Okooleni rinwo ole-mewaa |
435 | Ojilenirinwo odiin marun-un |
440 | Ojilenirinwo |
445 | Ojilenirinwo ole-marun-un |
450 | Ojilenirinwo ole-mewaa |
455 | Otaleiriinwo odin marun-un |
460 | Otalenirinwo |
465 | Otalenirinwo ole-marun-un |
470 | Orinlenirinwo odin-mewaa |
475 | Orinlenirinwo odin-marun-un |
480 | Orinlenirinwo |
485 | Orinlenirinwo ole-marun-un |
490 | Edagbeta odin-marun-un |
500 | Eedegbeta |
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Sise Itoju Oyun Ni Ona Abinibi Ati Ode-Oni
Ipo alailegbe ni Yoruba ka omo bibi si nitori won gbagbo pe lai si omo idile ko le e gboro bee si ni itesiwaju ko le si ni awujo.
BI A SE N TOJU ABOYUN NI AYE ATIJO
- Dide oyun:- itoju aboyun bere ni kete ti won ba ti fi ye si pe oyun naa ti duro . oko tabi agba obinrin ile yoo mu alaboyun lo odo onisegun agbebi tabi babalawo, onisegun agbebi yii yoo de oyun naa ki o maa ba wale tabi baje titi di akoko ti yoo fi bi omo naa
- Sise orisi aseje fun alaboyun:- awon aseje yii lo maa n dena aisan bii, oyi oju, ori fifo, inu rirun, ooru inu abbl ti yoo si mu ki omo naa maa dagba ninu ki o si le gbo daradara
- Wiwe ati mimu awon egbo igi: eyi yoo fun aboyun ati omo inu re lokun .
[mediator_tech]
BI A SE N TOJU ABOYUN (ODE-ONI)
NI ode-ni, ni kete ti obinrin ko ba ri nnkan osu re ni yoo ti gba ile iwosan lo lati mo boya oyun ti duro. Oniruru idanlekoo ni awon eleto ilara nse fun awon aboyun lara idanlekoo naa ni yi:
- Lilo si ile- iwosan fun ayewo to peye
- Gbigba abere ajesara lati le daabobo omo inu
- Jije awon ouje asaraloore bii, ewa eje, eran, wara abbl
- Mimu omi daradara
- Jije eso ati ewebe
- Sise ere idaraya ni asiko ti o wo
- Sise imototo ara atin ayika
EKA ISE: LOTIRESO
AKOLE ISE: KEKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.
Igbelewon:
- Ka onka lati 300-500
- Salaye bi a se n se itoju alaboyun laye atijo ati lode-oni
Ise asetilewa: ise sise inu iwe ilewo Yoruba Akayege
OSE KEJE
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: AKAYE OLORO GEERE.
Akaye ni kika ayoka kan ti o ni itumo ni ona ti o le gba yeni yekeyeke
Igbese ayoka kika
- kika ati mimo ohun ti ayoka naa dale lori
- sise itupale ayoka ni finifinni
- fifi imo ede, laakaye ati iforabale ka ayoka naa sinu
- dida awon koko oro, owe ati akanlo ede inu ayoka naa mo
- mimo orisirisi ibeere ti o wa labe ayoka naa
- didahun awon ibeere pelu laakaye
apeere ibeere ti owa labe akaye
i.ibeere ewo-ni-idahun
- ibeere ajemo itumo-ede
iii.Ibeere agboroko
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE OMO BIBI ( ORO IDILE BABA OLOMO)
Oniruru esin abalaye ni o wa ni ile Yoruba. Eya kookan ni o si ni esin ti won sin kaari ile kaaro-oo-jiire. Esin bii,
Sango-pipe
Oya-pipe
Obatala
Esu
Ifa
Egngun abbl.
Asa isomoloruko ati oro ti won n se yato lati ile kan si ekeji, lati ebi kan si ekeji tabi lati iran kan si ekeji.
Okan laar oro ti a maa nse fun omo tuntun ni ile Yoruba ni gbigbe omo si igbasoro ni ita, won yoo si da omi si orule, won yoo wa je ki omi naa ro si omo naa lara. Leyin eyi ni baba omo yoo fun omo ni oruko ati oriki, gbogbo ebi yoo si so fun omo naa pe “ki olorun je ki a mo on mo oruko re o, iwo naa yoo so omo loruko”
Awon obi omo yoo to awon babalawo lo lati lo da ifa, won yoo fi ese omo naa te opon ifa bee ni won yoo si beere ohun ti omo naa yoo da laye lowo ifa. Gbogbo akunleyan omo yii lati orun ni ifa yoo so. Eyi ti o ba si nilo etutu ki aye re le tuba-tuse ni won yoo se.
EKA ISE LITIRESO
AKOLE ISE: KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.
Igbelewon:
- Fun akaye loriki
- Ko awon igbese ti a ni lati tele bi a ba n ka akaye
- Salaye apeere ibeere ti o wa labe akaye
- Bawo ni oro idile se ye o si?
Ise asetilewa: salaye lekun un rere bi oro idile baba olomo se ye o si. Lo apeere oro idile re lati gbe idahun re lese
OSE KEJO
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: AKAYE OLORO GEERE
Ayoka kika-yoruba fun sekondu olodun meta akeko iwa keji, lati owo ola m. ajuwon etal (2014).
Pg43.
Itosona- Ka ayoka yii ki o si dahun awon ibeere to tele.
Ni asale leyin ti aduke ati iya re je oka ati efo riro tan, iya re pe e sodo, o sin gbaa ni imoran bi yoo se huwa omoluabi ni ilu eko. Aduke sese pari ile-iwe eko grama ni ilu Ibadan. Egbon baba re adisa wa ni ilu eko, aduke si n re ilu eko lati lo ko ise karakata.
Asako gba omo re niyanju lati mo omo eni ti se, ki o si toju iwa re nitori iwa loba awure.
Aduke ni omo kan soso ti eledaa fun awon obi re, o si je omo ti a ko ti o si gba eko.
Dahun awon ibeere wonyi,
- Nigba wo ni aduke ati iya re je oka ati efo riro? (a) owuro (b) irole (d) osa (e) asale
- Ki ni iya aduke se leyin ti won je ounje tan? (a) on na aduke (b) o n gba ile ile (d) o ngba omo re ni iyanju (e) ofunomo re ni owo
- …………. Ni oruko iya aduke (a) amope (b) asabi (d) Asake (e) awele
- …………. Ni egbon baba aduke (a) akanni (b) ajayi (d) adisa (e) ajani
- Aduke n re ilu eko lati lo ko ise…………… (a) Dokita (b) aso-liehun (d) oleko (e) karakata
- Fun ayoko yii ni akole ti o ba mu
- Salaye ni ranpe ohun ti owe yii tunmo si “iwa loba awure”
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: ASA ISOMOLORUKO
Isomoloruko ni fifun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lae ni ile Yoruba. oruko je dandan fun eniyan nitori pe Yoruba bo won ni “oruko omo ni ijanu omo” gbogbo ohun ti olodumare da saye patapata ni o ni oruko ti a fi n pe won.
Yoruba gbagbo ninu oruko pupo idi niyi ti won fi wi pe “oruko a maa ro eniyan” oruko maa n sapejuwe ipo tabi iru idile ti eniyan ti jade, o maa n fi iru iwa ti eniyan le hu han.
Onirunruu ohun-elo ni a n lo lati so omo loruko nile Yoruba awon ohun-elo wonyi ni a n lo lati fi se iwure/adura fun omo tuntun loo- Koo kan bi won ti n fun loruko.
OHUN ELO-ISOMOLORUKO | ADURA/IWURE |
Orogbo | Orogbo niyi, o o gbo-o, o o to o orogbo nii gboni saye ko o gbo, ko o to o. |
Iyo | Iyo re e o iyo ni a n fi se obe ti obe fii dun ki olorun fi adun si aye re |
Epo | Epo niyi
Epo ti I se obe loju pese, o ko ni ri oran airi repo fi sebe. Ara ope ni epo ti n wa, o o pe to ope…. |
Omi | Omi niyi o
Omi ko ni pa o lori O ko ni ba omi loo Aye re yoo toro bi omi Atowuro pon. |
Oyin/aadun | Oyin ree, aadun ree , didundidun ni le oloyin,
Adun ni a n ba lara aadun, Olorun yoo je ki aye re dun o o ni mo ikoro laye re. |
Obi | Obi re e
Obi n bi iku ni o Ki obi bi iku siwaju fun o Ki obi bi aarun siwaju fun o |
Oti | Oti re e
Ajimuti kii ti O ko ni ti laarin ile, ebi, Ataare, O ko ni ti laarin egbe Ati agbe…. |
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.
Igbelewon:
- Fun asa isomoloruko loriki
- Ko ohun elo isomoloruko marun-un ki o si salaye bi a se n fi sadura fun omo tuntun
Ise asetilewa: ko ohun elo isomoloruko meta ki o si salaye lekun-un rere bi a se n lo lati fi sadura fun omo tuntun
OSE KESAN-AN
EKA ISA: EDE
AKOLE ISE: AKOTO
Akoto je ona ti a n gba ko sipeli awon oro ede Yoruba sile lona to boju mu lode oni.
Sipeli atijo ni ona ti a n gba ko awon oro ede Yoruba sile ki ijobe orile-ede Naijiria to fi owo si ona tuntun ti a le gba ko awon oro yii sile ni odun 1974.
IYATO TI O DE BA SIPELI FAWELI
Sipeli atijo | Sipeli ode-oni |
Atiya | Aya |
Eiyele | Eyele |
Pepeiye | pepeye |
[mediator_tech]
Alaye: A ni lati yo faweli “I” kuro ninu awon oro yii nitori pe a ko pe e jade.
Sipeli atijo | Sipeli ode-oni |
Enia | Eniyan |
Okonrin | Okunrin |
Obirin | Obinrin |
On | Oun |
Kini | Kin-in-ni |
Alaye: A ni lati ko awon oro wonyi sile gege bi a se pe e nipa yiyo awon iro kan kuro ki a si fi iro miran kun.
Sipeli atijo | Sipeli ode-oni |
Mo o | Mo-on |
Fun u | Fun-un |
Sunmo-o | Sunmo-on |
Dunu | Dun-un |
Alaye: A maa n fa oro aropo oruko eniketa to n sise abo ninu gbolohun gun.
Sipeli atijo | Sipeli ode-oni |
Titun | Tuntun |
Lailai | Laelae |
Alafia | Alaafia |
Olotu | Olootu |
Papa | Paapaa |
Miran | Miiran |
Alaye: A ni lati ko awon iro faweli nee sile gege bi a se pe e.
Sipeli atijo | Sipeli ode-oni |
Gan | Gan-an |
Tanna | Tan-an-na |
Ofon | Ofon-on |
Akiyesi: A o lo ami asoropo (-) nibi ti a ba ti se afagun faweli aranmupe
Sipeli atijo | Sipeli ode-oni |
Iban | Ibon |
Ahan | Ahon |
Iton | Itan |
Alaye: A ni lati ko awon iro faweli aranmupe naa sile gege bi a se pe e.
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Igbagbo Yoruba Nipa Orisirisi Oruko Ile Yoruba.
Igbagbo Yoruba ni pe “ile la n wo ki a to so omo loruko”. A kii dede fun omo ni oruko ni ile Yoruba, akiyesi iru ipo ti omo naa wa nigba ti a bi, ipo ti ebi wa tabi ojo ati asiko ti a bi omo naa ni yoo so iru oruko ti a o so iru omo bee ni ile Yoruba.
Isori Oruko nile Yoruba
Oruko abiso
Oruko amutorunwa
Oruko Oriki
Oruko abiku
Oruko inagije
Oruko idile.
Oruo Abiso: Eyi ni oruko ti a fun omo ni banu pelu iru ipo ti obi, ebi, idile, agbegbe tabi ilu wa. Ba kan, o n toka igba ati asiko ti a bi omo naa. Apeere ati itunmo irufe oruko bee;
Otegbeye: Omo ti a bi leyin ote ilu ti ote naa si ja si eye ninu ebi
Tokunbo: Omo ti a bi si oke okun
Abi ona: Omo ti a bi si ona
Babajide: Omokunrin ti a bi ni asiko ti baba agba ku.
Fijabi: Omo ti a bi Iasiko ti ija wa ninu ebi tabi omo ti abi ja si.
Oruko Amutorunwa: Eyi ni oruko ti a n fun awon omo ti o gba ona ara waye tabi ti won mu nkan ara waye lara eya ara won. Apeere ati itumo oruko bee:
Taiwo: Omo ti o koko jade nigba ti abi ibeji
Kehinde: Omo ti o tele Taiwo, oun ni Kehinde gba egbon.
Dada: Omo ti irun ori re ta koko nigba ti abi
Ige: Omo ti o mu ese waye
Ojo: Omo kunrin ti a bi ti o gbe ibi ko run
Aina: Omo binrin ti a bi ti o gbe ibi ko run
Olugbodi: Omo ti a bi ti oni ika owo tabi ika ese mefa abbl.
Oruko Oriki: eyi ni oruko iwuri ti awon Yoruba n fun omo tuntun lati fi ki ni tabi gboriyin fun eniyan. Apeere.
Oruko Oriki Okunrin: Akanni, Ajani, Ajao, Adufe, Akande, Alade, Akanbi, Abefe, abbi.
Oruko Oriki Obinrin: Asake, Ayoka, Awele, Anike, Ajike, Asabi, Amope abbi.
Oruko Abiku: Eyi ni oruko ti a fun omo ti o je pe bi won se n bi lo n ku. Iru awon omo bee le para odo iya won lee meta tabi ju bee lo ki won to le duro gbe ile aye.
Apeere irufe oruko bee ni,
Akisatan, Durojaye, Malomo, Kokumo, Kosoko, Matanmi, Aja, Omitanloju, Kasimowoo, Durosinmi, Bamijoko, Omolanbe,.
Oruko Inagije
Eyi ni oruko apeje tie bi ore fun eniyan kan tabi eyi ti enyan fun ara re lati buyi kun ni tabi eyi ti won fun enyan kan nitori iwa re. Apeere.
Olowojebute, Owonifaari, Ekun, Olowomojuore, Dudumaadan, Epolanta, Eyinfunjowo, Eyinmenugun, Awelewa, Aponbepore, Ibadiaran abbl.
Oruko Idile: Orisi idile ni o wa ni ile Yoruba, opo idile ni o si ma fun awon omo won ni oruko ni idamu pelu ipo idile, orisa ati ise abinibi ti won n se.
Apeere:
Idile Oloye: Oyeniyi, Oyeyemi, Oyede, Oyewunmi
Idile Alade: Adekanmibi, Adegbite, Adesina
Idile Ola: Oladoye, Oladapo, Afolabi, Olayomi
Idile Olorisa: Orisatole, Orisabunmi, Orisatade
Idile Ode: Oderinde, Odelana, Odefunke
Idile Ogun: Ogunbiyi, Ogunleke, Ogunmole
Idile Onifa: Faleti, Falade, Awojobi, Awolowo
Eka Isa: Litireso
Akole Ise: Kika iwe apileko Oloro geere ti ijoba yan.
Igbelewon:
- Kin ni akoto?
- Salaye awon iyato ti o wa ninu sipeli aye atijo ati ti ode-oni
- Ko isori oruko ile Yoruba pelu apeere okookan won
Ise asetilewa: Gege bi omo ti o jade lati ile ire, ko oruko ti o jemo idile re yala nipa ise tabi awon ohun ti a mo mo idile re mewaa
OSE KEWAA
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: Kiko Yoruba ni ilana Akoto Ode-Oni
Iyato ti o de ba iro konsonati ninu akoto ode-oni
Sipele Atijo Sipele Ode Oni
Iddo Ido
Otta Ota
Jebba Jeba
Offa Ofa
Ebute-Metta Ebute-Meta
Ottun Otun
Shagamu Sagamu
Oshogbo Osogbo
Shaki Saki
Shango Sango
Ilesha Ilesa
Alaye: Konsonanti kii supo ninu ede Yoruba bee ni a o fi “s” ropo “sh” nitori ko si “shi” ninu alifaabeti ede Yoruba.
Yi yii
Bayi Bayii
Marun Marun-un
Akuse Akusee
Alaye: A o fa awon faweli ti o gbeyin gun gege bi a ti pe won
Ogun Oogun
Orin Oorin
Egun Eegun
Alaye: Afagun faweli
Bakana Bakan naa
Fihan fi han
Nitoripe Nitori pe
Gbagbo gba gbo
Leyinna Leyin naa
Nigbati Nigba ti
Alaye: A gbodo pin oro si bi a se pee.
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Orisirisi oruko ile Yoruba. (Igbagbo Yoruba nipa Abiku)
Abiku ni awon omo ti won man wa, ti won si tun maa n lo. Eyi ni awon omo ti abi ti won ku, ti iya ti o bi won tele tun pada bi won ti won a si tun ku.
Yoruba gba gba pe elere omo ni won ati pe won maa n rin kiri ni awon orita meta, bebe omi, eyin aatan, Ona Oko tabi ninu oorun losan gangan.
Idi ni yi ti won fi maa n so fun awon alaboyun ki won mase rin ni osan gangan, ni asale tabi ni oru oganjo.
Yoruba tun gba gbo pe alailaanu ati odaju omo ni awon abiku. Yoruba bo won ni “Abiku so oloogun deke”. Won ko beru oloogun rara.
Ona ti Yoruba n gba din abiku ku laye atijo.
- Won a fa iru omo bee le owo babalawo ti o ba gboju daradara lati le se abojuto tabi se aajo ti ko fi ni pada
- Siso won ni oruko ebe tabi aponle ki won le gbaye. Apeere, Durosinmi, Malomo, Banjoko abbl.
- Siso awon abiku ni oruko lasan, Oruko abuku lati fi saata won ki oju le ti won ki won si le gbe ile aye. Apeere iru oruko bee ni, Aja, Akisatan, Omitanloju, Kilanko, abbl.
- Ni gba miiran awon obi omo abiku yin le mu ika owo ati ese ki won ge, ki won si dana sun –un patapata ki won to gbe omo naa sin. Eyi tunmo si pe abiku naa ko le gbe ara abo pada wa aye lati wa daamu awon obi re mo, bi o ba si pada wa, oju yoo ti, lati gbe ara abo pada lo sinu egbe re.
- Pupo obi tun maa n dana sun omo abiku leyin ti won ba ti ku tan.
Ona ti a le gba segun Abiku lode oni
Lode Oni, awon kan ti le gba gbo pe ko si ohun ti o n je abiku rara. Igbagbo won ni pe aini imo ijinle ti o kun lo mu ki awon omo maa ku ni kekere.
A le segun bibi abiku lode oni nipa:
- Sise ayewo eje: Iwadii ijinle fi ye wa pe bi oko ati aya ba ni eje ti o da eyin ko ara ara won eyi lefa abiku omo nipa ki omo maa se aisan nigba gbogbo.
- Siso eto imototo lati fi dena awon aarun tabi aisan ti n maa pa awon omo ni kekere.
Gbigba abere ajesara lati le dena awon aarun tabi aisan to le fa ki omo kun ni rewerewe.
Igbelewon :
- Ko sipeli atijo mewaa ki o si ko akoto re
- Salaye omo abiku ni ile Yoruba
- Ko ona ti Yoruba n gba dekun abiku laye atijo
- Salaye awon ona ti Yoruba n gba segun abiku lod-oni
Ise asetilewa: N je loooto ni abiku wa? Tu keke oro.
SS 1 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA
[mediator_tech]