JSS 1 THIRD TERM LESSON NOTES YORUBA

 

ILANA ISE FUN SAA KETA OLODUN KIN-IN-NI (JSSONE)

OSE KIN-IN-NI: ATUNYEWO ISE SAA KEJI

OSE KEJI: EDE: LETA KIKO

ASA: AWON ISE ISEMBAYE ILE YORUBA

OSE KETA: LITIRESO: ASAYAN IWE TI IJOBA YAN

ASA: ISE AGBE

OSE KERIN: EDE: ISE ORO ISE NINU GBOLOHUN

ASA: ISE ILU LILU

OSE KARUN-UN: EDE: IHUN GBOLOHUN ABODE ATI ATUPALE

GBOLOHUN ABODE

OSE KEFA: ASA: IGBESE TI AGBE YOO GBE KI IRE OKO TO JADE

OSE KEJE: EDE: IHUN GBOLOHUN OLOPO ORO ISE ATI ATUPALE

GBOLOHUN OLOPO ORO ISE

OSE KEJO: ASA: ASA IRAN-RA-ENI LOWO LAWUJO YORUBA

OSE KESAN –AN: ASA: IWA OMOLUABI

OSE KIN-IN NI

ATUNYEWO ISE SAA KEJI

EKA ISE: EDE

ORI ORO: AROKO ATONISONA ONIROYIN (NARRATIVE ESSAY)

Aroko oniroyin je aroko ti o je mo iroyin sise.

AWON IGBESE TI A NI LATI TELE TI A BA N KO AROKO ONIROYIN

  • Mimu ori oro ti a fe ko oro le
  • Kiko koko ohun ti a fe soro le lori leseese ni ipin afo kookan (in paragraph)

Apeere ori oro aroko oniroyin :

 

  • Ijamba oko kan ti o sele loju mi
  • Ayeye isile kan ti won se ni adugbo mi.
  • Ere onile-ji-le ti o koja ni ile iwe mi.

IGBELEWON:

  • Fun aroko oniroyin loriki
  • Ko awon igbese ti a ni lati tele bi a ba n ko aroko oniroyin
  • Awon ori oro wo ni o jemo aroko oniroyin

ISE ASETILEWA:

  • Simplified Yoruba L1 work book for JSS one. Page 26-27

EKA ISE: ASA

ORI ORO: OGE SISE NI ILE YORUBA(FASHION)

Oge sise je asa imototo ati sise ara losoo

Awon ona ti a n gba se oge laye atijo ati lode-oni

  • Aso wiwo
  • Iwe wiwe
  • Laali lile
  • Tiroo lile
  • Osun kikun
  • Ila kiko
  • Itoju irun ori
  • Lilo ohun eso lorisirisi

PATAKI OGE SISE

  • O n je ki ara eniyan mo toni-toni
  • O n le aisan jinna si eniyan
  • Ko ki i je ki ara wo ni
  • O n bu ewa kun ni
  • Tiroo lile maa n ti idoti oju kuro

IGBELEWON:

  • Kin ni oge sise?
  • Ko awon ona ti Yoruba n gba se oge laye atijo
  • N je oge sise se Pataki ni ile Yoruba? Ko Pataki oge sise merin

ISE ASETILEWA:

  • Gege bi i akekoo, n je o se Pataki lati toju ara ki o to wa si ile iwe? Salaye Pataki oge sise.

EKA ISE: LITIRESO

ORI ORO: ORIN IBILE TO JEMO PIPA OGO OBINRIN MO,

ASA IGBEYAWO,ISE AGBE

Orin to je mo asa igbeyawo:

Baba mo mi lo

Fadura sin mi o

Iya mo mi lo

Fadura sin mi o

Kin maa ke’su

Kin maa ka’gbako nile oko

Kin maa ke’su

Kin maa ka’gbako nile oko

Baba mo mi lo

Iya mo mi lo

E fadura sin mi [mediator_tech]

Orin to je mo pipa ogo obinrin mo:

Ibaale

Ibaale o!

Ibaale logo obinrin

Ibaale o!

Olomoge,

Pa ara re mo

Pa ara re mo o!

Ibaale logo obinrin

Ibaale o

Orin ibile to jemo ise Agbe:

Ise Agbe ni’se ile wa

Eni ko sise

A maa jale

Iwe kiko

Lai si oko ati ada

Ko I pe o!

Rara

Koi pe o!

IGBELEWON:

  • Fun oge sise ni oriki
  • Ko ona marun-un ti Yoruba n gba soge laye atijo
  • Ko orin ibile ti o je mo pipa ogo obinrin mo,ise agbe ati asa igbeyawo

ISE ASETILEWA:

  • Ko orin ibile kan ti o je mo Eto Eko.

OSE KEJI

EKA ISE: EDE

ORI ORO: LETA KIKO

Leta kiko je ona ti a n gba gbe ero okan wa kale ni ori pepa ranse si elomiiran

ORISI LETA

  • Leta gbefe
  • Leta Aigbefe

AWON IYATO TI O WA LAARIN LETA GBEFE ATI LETA AIGBEFE

LETA GBEFE LETA AIGBEFE
O je leta ti a n ko si baba,iya Egbon, aburo ati ojulumo O je leta ti a n ko si awon eniyan ti o wa ni ipo giga tabi oga ileese
Adireesi kan ni o maa n ni Adireesi meji ni o n ni
Ko nilo ori oro(Topic) Ori oro pondondan ninu leta yii
O fi aye sile fun awada tabi efe sise

 

Kos i aaye fun awada tabi efe
Ifamisi oruko akoleta ko pondandan ninu leta gbefe Ifamisi oruko akoleta pondandan
Oruko akoleta nikan ni o se Pataki ni ikini ipari Oruko akoleta ni kikun(With surname) se Pataki labe ifamisi oruko

[mediator_tech]

IGBELEWON:

  • Kin ni leta?
  • Ona meloo ni leta pin si?
  • Ko iyato marun-un laarin irufe leta ti o wa

ISE ASETILEWA:

  • Ko leta si baba re lati wa san owo ile-iwe re ki awon alase eto eko ma a ba di o lowo ise ni ile iwe.

EKA ISE: ASA

ORI ORO: AWON ISE ISEMBAYE ILE YORUBA

Ise isembaye je ise ti a jogun ba lati iran kan de iran miiran ti a si n ko won bi a ti n dagba

Awon ise isembaye Yoruba ni wonyi;

  • Ise Agbe
  • Ilu lilu
  • Ikoko mimo
  • eni hihun
  • aro dida
  • Ise ode
  • Ise onidiri
  • Ise akope
  • Ise Alagbede
  • Ise ona bii;
  • Ona igi
  • Ona okuta
  • Ona awo abbl

IGBELEWON:

  • Fun ise isembaye loriki
  • Ko ise isembaye meje

ISE ASETILEWA:

  • Ise isembaye wo ni e jogun ba ninu ebi yii? Salaye lekun-un rere.

 

OSE KEJI

EKA ISE: LITIRESO

Kika iwe asayan ti ijoba yan fun saa yii

Ayoka Ewi YORUBA LAKKOOTUN

IGBELEWON:

Ninu ewi yorruba Lakotun ko eko marun-un ti ewi naa ko e gege bii akeekoo

ISE ASETILEWA:

  • Ko eko marun ti imele akekoo ko e gege bi I akekoo

EKA ISE: EDE

ORI ORO: ISE AGBE

Ise Agbe je kiko ati mimo nipa oko riro tabi dida

Ise Agbe je ise akoko se eda,gege bi a se ri I ninu Bibeli ninu iwe Genesiisi ori kin in ni ese .

Awon to n pese ohun elo ti a n je ni a n pen i AGBE

OHUN ELO ISE AGBE NI AYE ATIJO ATI NI ODE ONI

  • Oko
  • Ada
  • Aake
  • Obe
  • Ero irole tabi iko ebe
  • Ero ktakata
  • Oogun ajile abbl

ORISI AGBE TI O WA

  1. AGBE ALAROJE: Iwonba oko fun atije ebi ni agbe alaroje maa n da.Awon ohun ogbin bii; isu ogede,agbado, ata,ati ewebe ni won maa n gbin. Ni gba miiran ti o ba seku ni won maa n ta loja
  2. AGBE ALADA-N-LA/OLOKO N-LA: Awon wonyi ni won n fi ise agbe se ise loju mejeeji.won a maa da oko nla bii; oko koko,oko roba,oko agbo,oko owu,oko obi,oko ope oyinbo,oko anamo,oko egusi abbl.

Agbe alada-n-la pin si ona meji.Awon niyi;

  • Agbe olohun ogbin: Awon ni o n gbin gbogbo ounje ti a n je kaari aye
  • Agbe olohun osin: Awon Agbe wonyi lo n sin oniruuru ohun osin bii; Aja,Ewure, Elede, Adiye, Ehoro, Oya, Eja, Igbin, Oyin abbl

IGBELEWON:

  • Fun ise Agbe ni oriki
  • Orisi agbe meloo ni o wa?
  • Salaye orisi agbe lekun un rere
  • Daruko awon ohun elo ise agbe laye atijo ati lode-oni

ISE ASETILEWA:

Ko ohun elo ise agbe laye atijo ati lode oni marun-un

OSE KERIN- IN

EKA ISE: EDE

ORI ORO: ISE ORO ISE NINU GBOLOHUN

Oro ise ni koko fonran to n toka isele tabi nnkan ti oluwa n se ninu gbolohun

Oro ise ni opomulero gbolohun.Lai si oro ise ninu gbolohun, gbolohun ko le ni itumo

ISE ORO ISE NINU GBOLOHUN

  • O maa n toka isele inu gbolohun laaarin oluwa ati abo(oro ise kikun). Apeere;
  1. Iyabo je isu
  2. Adufe ka iwe
  3. Ige pa ejo
  • Kii gba abo ninu gbolohun.( oro miiran kii jeyo leyin oro ise) Apeere;
  1. Yemi sun
  2. Toju kawe
  3. Olu da?
  4. Olorun wa abbl
  • O maa n gba abo ninu gbolohun(oro miiran le jeyo leyin oro ise). Apeere;
  1. Aja gbe eran
  2. Kehinde ra keke
  3. Layemi ge igi
  • O maa n sise akanpo: eyi ni akanpo oro ise ati aro oruko ti o bere pelu faweli (ipaje a maa waye).Apeere;
  1. Se + ere = sere
  2. Je+ isu = jesu
  3. Gun+ iyan = gunyan
  4. Ko + orin = korin

IGBELEWON:

  • Kin ni oro ise?
  • N je loooto ni pe oro ise se Pataki ninu gbolohun
  • Salaye ise ti oro ise n se ninu gbolohun

ISE ASETILEWA:

  • Ko gbolohun kikun marun-un ki o si fa ila si oro ise inu re

EKA ISE: ASA

ORI ORO: ISE ILU LILU

  • Itan so pe eniyan ni Ayan ni igba aye re
  • Oruko abiso re ni “Kusanrin Ayan “
  • Itan so pe oun ni eni akoko ti o koko lu ilu ni ile Yoruba
  • Ile Barapa ni o ti wa
  • Leyin iku re ni awon onilu egbe re so o di Orisa
  • Ise ilu lilu ni a n pen i “Ise Ayan”
  • Awon ti o n fi ilu se ise se ni a n pen i “Alayan”
  • Ise ilu lilu je ise àti rán-dé-ìran. [mediator_tech]

ORISI ILU TI A N LU NI ILE YORUBA:

  • Ilu Bata
  • Ilu Benbe
  • Ilu Gbedu
  • Ilu Dundun
  • Ilu Igbin
  • Ilu Agere
  • Ilu Gongo

IWULO ILU LILU:

  • O wa fun idaraya ati faaji
  • A n lu ilu nibi inawo bii; igbeyawo,ikomojade,isinku agba,oye jije,isile,odun ibile lorisirisi
  • A n lo ilu lati fi tufo oku oba,oku ijoye,oku agba,oku awon olorisa
  • A n lo ilu lati fi ye awon oba ati ijoye ilu si
  • A n lo ilu ni ile ijosin lati fi yin Olodumare,ile iwe,ibi apejo oloselu abbl

IGBELEWON:

  • So itan soki nipa ilu lilu ni ile Yoruba
  • Ko orisi ilu marun-un ni ile Yoruba
  • Ko iwulo ilu ni awujo Yoruba

ISE ASETILEWA:

Ko iwulo ilu lilu meta pere ni ile ijosin.

OSE KARUN-UN

EKA ISE: EDE

ORI ORO: IHUN GBOLOHUN ABODE ATI ATUPALE GBOLOHUN ABODE

Gbolohun ni akojopo oro ti o ni oro ise ati ise yi o n je ninu ipede

Gbolohun ni olori iso

GBOLOHUN ABODE/ELEYO-ORO ISE

Gbolohun abode tabi eleyo oro ise je gbolohun ti kii gun ti ko si ni ju eyo oro ise kan lo. Apeere;

  • Ade je iresi
  • Adufe fe iyawo
  • Sade mu omi

IHUN GBOLOHUN ABODE/ELEYO ORO ISE

  • O le je oro ise nikan. Apeere; jade,joko,dide lo
  • O le je oluwa,oro ise kan ati oro aponle.apeere;
  • Baba sun fonfon
  • Ile ga gogoro
  • O le je oluwa,oro ise kan ati abo.apeere
  • Anike je ewa
  • Ige gba ise
  • Yemi ka iwe
  • O le je oluwa,oro ise kan,abo ati apola atokun.apeere;
  • Tunde ra keke ni ana
  • Subomi ta aso ni oja
  • Bimpe da omi si ile
  • O le je oluwa,oro ise kan ati apola atokun.apeere
  • Mo lo si odo
  • Abiola lo si oja abbl

IGBELEWON:

  • Fun gbolohun abode ni oriki
  • Oruko miiran won i a le pe gbolohun abode
  • Salaye ihun gbolohun abode pelu apeere

ISE ASETILEWA:

Ko gbolohun abode marun-un ki o si fa ila si oro ise inu re.

OSE KEFA

EKA ISE: ASA

ORI ORO: AWON IGBESE TI AGBE YOO GBE KI IRE OKO TO JADE

Awon to n fi ise oko riro se ise ati bi a se n toju ohun osin ni a n pen i “Agbe”

Awon igbese naa leseese ni yi:

  • Awon agbe ni lati se itoju oko won loore-koore nipa lilo ero irole,katakataata,iko ebe
  • Won gbodo se amulo oogun ajile(fertilizer)
  • Rira irugbin ti o ba asiko ogbin mu
  • Awon agbe olohun osin gbodo koi le fun ohun osin won
  • Ayika ohun osin gbodo mo toni-toni
  • Ounje amaradan ati amara-dagba lore-koore fun awon ohun osin
  • Ayewo ara ni gbogbo igba fun awon ohun osin

PATAKI /ANFAANI ISE AGBE LAWUJO

  • Awon agbe lo n pese ounje lawujo
  • Ise agbe n pese ise fun ogunlogo eniyan lawujo
  • O n pese ohun elo ise fun awon ile ise gbogbo bii;awon to n se iwe, won ile ise ona igi abbl
  • Ise agbe n pese owo si apo ijoba nitori pupo awon ohun ogbin ni ile yii ni a n fi sowo si oke okun bii; koko

IGBELEWON:

  • Awon won ni Agbe?
  • Ona meloo ni a le pin awon agbe si?
  • So igbese ti agbe ni lati gbe ki ire oko to jade
  • Ko Pataki ise agbe merin ni awujo wa

ISE ASETILEWA:

  • N je loooto nipe awon agbe se Pataki ni awujo? Ko koko marun un lati gbe idahun re lese.

OSE KEJE

EKA ISE: EDE

ORI ORO: IHUN GBOLOHUN OLOPO ORO ISE ATI ITUPALE RE

Gbolohun olopo oro ise ni gbolohun ti a fi gbolohun miiran bo inu re.oruko miiran fun gbolohun yii ni ‘gbolohun onibo’

Gbolohun onibo pin si ona meta.awon niyi;

  • Gbolohun onibo asaponle
  • Gbolohun onibo asapejuwe
  • Gbolohun onibo asodoruko

GBOLOHUN ONIBO ASAPONLE

Eyi ni gbolohun ti a fi n se aponle oro ninu gbolohun nipa lilo atoka “ti” tabi “bi”. Apeere ;

  1. Awon ole yoo sa bi awon ode ba fon fere
  2. Ti awon ode ba fon fere awon ole yoo sa
  3. Awon akekoo yoo se aseyori bi awon oluko ba ko omo daadaa
  4. Ti awon oluko ba ko omo daadaa,awon akeekoo yoo se aseyori.

 

GBOLOHUN ONIBO ASAPEJUWE

Inu apola oruko ni gbolohun yii maa n wa(eyi ni oro oruko kan soso pelu isori oro oruko miiran). Atoka ‘ti’ ni a n lo.

  1. Ile ti Ola n gbe dara
  2. Tuned ra aso ti o ni awo ewe
  3. Oko ti oluko ra rewa

GBOLHUN ONIBO ASODORUKO

Atoka gbolohun yin ii “pe”. Atokka yii maa n yipada di oro oruko ninu gbolohun.Apeere;

  1. Pe o o le jale o dun mi pupo
  2. O dara pe o gbegba-o-roke ninu idanwob asekagba.
  3. O dara pe o ri ise si ile-epo abbl.

IGBELEWON:

  • Kin ni gbolohun olopo oro ise
  • Ona meloo ni o pin sii?
  • Salaye orisi gbolohun olopo oro ise
  • Ko apeere gbolohun olopo oro ise

ISE ASETILEWA:

  • Ko apeere gbolohun olopo oro ise marun –un ki o si fa ila si oro ise inu re.

OSE KEJO

EKA ISE:A SA

ORI ORO: ASA IRAN-RA-ENI LOWO LAWUJO YORUBA

Asa iran-ra –eni lowo je ona ti awon yoruba n gba ran ara won lowo nibi ise won gbogbo

Yoruba gbagbo ninu ki won se iranwo fun omonikeji. Won a maa ko ara jo lati da oko,koi le,ko ebe,kore oko,fo epo,gbe odo,la ona,gbe koto abbl. Ba kan naa,won a maa se iranlowo owo fun ara won nipa dida ajo, dida esusu ati kikorajopo lati da egbe alafowosowopo ode oni sílè. [mediator_tech]

ORISI ONA TI YORUBA N GBA RAN ARA WON LOWO LAYE ATIJO

  • Ajo
  • Esusu
  • Ebese
  • Owe
  • Aaro
  • Arokodoko

IGBELEWON:

  • Salaye asa iran-ra-eni lowo ni soki
  • Daruko awon ona ti Yoruba n gba ran ara won lowo ni ile Yoruba

ISE ASETILEWA:

  • Salaye ona iranra-eni-lowo ode-oni ni kikun.

OSE KESAN-AN

EKA EDE: IASA

ORI ORO: IWA OMOLUABI

Omoluabi ni omo ti a bi, ti a ko, ti o si gba eko rere

Yoruba bo won ni “ile ni a ti n ko eso rode”. Iwa omoluabi bere lati inu ile.

AWON IWA OMOLUABI

  • Iwa ikini: dandan ki omo okunrin ti a ko lati ile ire ki o dobale fun awon obi re ni geere ti o ba ji ni owuro,ba kan naa lo pon dandan fun omo obinrin ki o kunle ese mejeeji fun awon obi re nitori awon ni alagbato Olodumare fun won.kii se awon obi eni nikan ni a gbodo maa ki,gbogbo awon ti o ju ni lo lojo ori ibaa se egbon eni, oluko,aladugbo,awon agba akekoo ni ile eko,abbl ni a gbodo maa kin i igba gbogbo.
  • Ibowo ati iteriba fun agba: iwa ikini ko so pe eniyan ni ibowo fun agba nikan.bibowo fun agba ninu oro enu, ise jije,gbigba eru lowo agba ati awon ohun amuye miiran lo n fihan iru eni ti eniyan je
  • Iwa pele lawujo: pupo omo lo huwa janduku lawujo ti won ti ba oruko ebi ati ojo iwaju won je.iwa pel nibikibi ti a bat i ba ara wa yala ni ile iwe,ibi ikose,ibi ijeun,ori ila,yara idanwo,ile ijosin ati ni awujo se Pataki fun omo oluwabi.
  • Otito siso: otito lo n gbe eniyan leke. Ni ibikibi ti a bat i ba ara wa gege bi omo oluwabi a gbodo le jeri w ape oloooto eniyan ni wa
  • Iwa igbonran: ninu iwe mimo bibeli,igbonran llo n fi han boya a gba Olorun gbo.ba kan naa ,igbonran lo n fi han iru omo ti a je ati iru ile ti a ti jade wa.ni ile eko igboran si awon alase,igboran si awon oluko,igboran si Olorun se koko
  • Iwa iran-ra-eni-lowo:Asa yii wopo laaarin awon omo Yoruba.o n fi han pe a nife ara wa.riran obi lowo ninu ile,sise irnwo fun omolakeji eni se Pataki gege bi omoluabi.

AWON IWA TI KO YE OMOLUABI

  • Ojukokoro
  • Ole
  • Imele
  • Iwa aigbonran
  • Igberaga
  • Ipanle
  • Iro pipa
  • Oole ,abbl

IGBELEWON:

  • Ta ni omoluabi?
  • Ko iwa omoluabi marun-un pelu alaye
  • Ko awon iwa ti ko ye omoluabi ni ile Yoruba

ISE ASETILEWA:

  • Gege bi akekoo ti o ni iwa omoluabi, ko iwa marun-un ti ko ye ki a ba lowo omoluabi ni ile Yoruba ki o si salaye.

[mediator_tech]

Third Term JSS 1 EXAMS QUESTIONS YORUBA

 

ILAANA ISE NI SAA KETA FUN JSS 3 THIRD TERM LESSON NOTES YORUBA

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share