ISEDA ORO ORUKO
Subject : Yoruba
Class : Jss 2
Term : Third Term
Week : Week 5
Topic :
OSE KARUN-UN
EDE
ISEDA ORO ORUKO
APETUNPE
(a) Igba, asiko ati onka ni awon oro oruko ti a n seda bayii maa n ba lo ju.
Apeere:-
Osu + osu = osoosun
Odun + Odun = Odoodun
Orun + Orun = Oroorun
Egbe + egbe = Egbeegbe
Mejo + mejo = Mejeejo
(b) A maa n se apetupe oro ise ati oro oruko nipa sise isunki oro oruko ati oro ise naa.
Oro ise Oro oruko Isunki Oro oruko ti a seda
Da eran daran darandaran
Wo ile wole wolewole
Gbe omo gbomo gbomogbomo
Ko ile kole kolekole
Je eyin jeyin jeyinjeyin
A maa n lo afomo aarin pelu apetunpe oro oruko. Awon weren afomo aarin ni “ki, ku, de, ri. Apeere:-
Oro oruko Afomo aarin Apetunpe oro Oro oruko ti a seda
Oruko/Afomoaarin
Eni + ki + eni = enikeni
Ile + ki + ile = ilekile
Ije + ku + ije = ijekuje
Iso + ku + iso = isokuso
Ile + ji + ile = iledeile
Aye + ri + aye = ayeraye
IGBELEWON
Se itupale awon oro wonyi:
Enikeni, ijokijo, jagunjagun, pejapeja, gbomogbomo.
IWE AKATILEWA
Oyebamiji Mustapha (2002) EKO EDE YORUBA TITUN iwe keji (J.S.S.2) University Press oju iwe 37-39 .
- Y Adewoyin (2004) New Simplified Yoruba L1 iwe keji [J. s. s .2] Copromutt (publishers) Nigeria oju iwe 37-38 Limited.
ASA
IGBAGBO AWON YORUBA NIPA IYE LEYIN IKU
Iranse Olodumare ni iku je. Oun ni Olodumare n ran lati pa mu eniyan. Gbese ni iku ko si eni ti ko ni ku. Irinajo ni iku si orun. Leyin iku, awon Yoruba gbagbo pe iye wa leyin iku. Awon ohun ti o fi idi re mule ni wonyi:
Odun Eegun: Awon Yoruba gbagbo wi pe egungun je ara orun. Won maa n sin esin egungun fun iranti baba won ti o ti ku.
Asa Isomoloruko: bi baba tabi iya agba ba ku, awon Yoruba maa n so omo won ni oruko bi Babatunde, Yetunde, Yejide lati fi han pe ajinde wa.
Asa Ikini: Paapaa nibi isinku agba, won a ni *baba wa somo* won gbagbo pe eni to ku yoo tun jinde ni orun was aye.
Akudaaya: awon wonyi ni awon ti won ti ku ti won o tun farahan ni ibomiran. Iru awon eeyan bayi ni won gbagbo pe ojo iku won ko I ti I pe. Won le fe iyawo ki won tun bi omo nibo miiran.
IGBELEWON
So oruko marun-un ti o fi han pe iye wa leyin iku
IWE AKATILEWA
Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.2) University Press oju iwe 105-110.
- Y Adewoyin (2004) New Simplified Yoruba L1 iwe keji [J. s. s .2] Copromutt (publishers) Nigeria Limited oju iwe 53-55
LIT
AWON EWI TI A FI ORO INU WON DA WON MO
AKOONU: Oriki.
Ofo.
Iyere Ifa.
Awon litireso atenudenu ti a n fi oro inu won won da won mo ni: Oriki, ofo, Iyere Ifa.
ORIKI-ORILE: ni ami ti o n toka idile eniyan kookan to je abinibi omo Yoruba. Awon iran ti a n ki omo Yoruba mo ni (oriki orile): onikoyi, Oluoje, Oko irese, Ajisola, Erin, Onikoyi, Olofa, Ologbin-in, Aresa, Olokun-esin, Alaran-an, Aagberi, Ijamogbo, Olufe, Iloko, Osunlakesan, Ijese. Awon ohun ti a gbo ninu oriki ni: ( orirun iran, irisi iran,esin iran, ise iran, Aleebu.
OFO: Ofo je oro enu ti o ni agbara ase ninu. Oun lo fi igbagbo awon Yoruba ninu agbara oro han. Bi a se le da ofo mo.
Oruko eroja oogun: itun lo ni e fi ohun rere tun mi se
Ifa lo ni e fa mi mora……
Lilo apola: a ki i…..
Ki i…….
Alaye fun awijare: Alara se tire, o gun
Ajero se tire o ye….
Awimayhun/ase: Ohun ta wi fun ogbo
Oun ogbo n gbo…..
Lilo oro ebe: ela iwori
Ma je n ri abo ota mi…..
IFA: Orunmila ni awon Yoruba n pe ni akerefinsogbon. Awon babalawo ni won n te ifa. Bi a se le da ese ifa mo.
A dia fun
O dia fun
O pawo lekee
Ebo riru
Itan
Ewa ede
IGBELEWON
- Daruko awon oriki orile marun-un.
- awon nnkan wo ni a fi maa n da oriki mo?
APAPO IGBELEWON
- Se itupale awon oro wonyi:
- Enikeni, ijokijo, jagunjagun, pejapeja, gbomogbomo.
- So oruko marun-un ti o fi han pe iye wa leyin iku
- Daruko awon oriki orile marun-un.
- awon nnkan wo ni a fi maa n da oriki mo?
ATUNYEWO EKO
- Ko ilana asa igbeyawo mejo sile.\
- Salaye awon igbese naa.
IWE AKATILEWA
Oyebamiji Mustapha (2006) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) University Press oju iwe 44-51.
- Y Adewoyin (2004) New Simplified Yoruba L1 iwe keji [J. s. s .2] Copromutt (publishers) Nigeria Limited oju iwe 39-43
Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc oju iwe 16.
ISE ASETILEWA
- Nipase _____ ni a seda “odoodun” (a) Sise apetunpe oro ise ati oro oruko (b) Sise apejuwe oro oruko (d) Lilo afomo ibere mo oro ise kan.
- Sise apetunpe oro ise ati oro oruko la fi seda _______ (a) Egbeegbe (b) Oja [d) Arerumaso.
- Oro oruko maa n sise pelu oro ise ninu iseda oro oruko (a) Beeko (B0 Bee ni (d) ko kan mi.
- Ewo ninu awon wonyi ni o fi han pe iye wa leyin iku? (a) Romoke (b) Ajagbe (d) kosoko.
- Inu awon oro wo ni a ti maa n gbo awon oro bi ewe ati egbo? (a) ofo (b) ifa (d) oriki.
APA KEJI
- Ko oriki ara re sile.
- Ko oruko meta ti o fi han pe iye wa leyin iku sile