JSS 1 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA
YORUBA LANGUAGE SCHEME OF WORK JSS 1
SAA ETO ISE FUN SAA KIN-IN-NI
- Alifabeeti ede Yoruba
Itan isedale Yoruba
Oriki litireso
- Ami ohun lori awon faweeli ati oro onisilebu kan
Ile-ife saaju dide oduduwa
- Ami ohun
Awon eya Yoruba ati ibi ti won tedo si
Awon ohun to ya litireso soto si ede ojoojumo
- Silebu
Ikini ni aarin eya Yoruba, ounje won ati bi won se n se won
- Akoto ode oni
Ikini II Akoko
Litireso alohun to je mo Aseye
- Akoto awon oro ti a sunki
Iwulo Ede Yoruba
Litireso Alohun to je mo esin
- Onka Yoruba lati ookan de aadota (1-50)
Bi asa se jeyo ninu ede Yoruba
Litireso Apileko
- Onka lati ookan lelaadota de ogorun-un (51-100)
Asa ati ohun-elo isomoloruko
- Oriki ati liana kiko aroko Yoruba pelu apeere
Isomoloruko II
Awon litir//so Apileko – Ere onitan.
- Aroko atonisona Alapejuwe
Oye jije ati ohu elo oye jije
Awon litireso apileko ewi
- Isori oro +ninu gbolohun
Isinku nile Yoruba
AKOLE ISE – ALIFABETI YORUBA
ALIFABEETI JE AKOJOPO LETA TI ASE AKOSILE RE GEGE BI IRO NINU EDE YORUBA.
ALIFABETI EDE YORUBA
Aa Bb Dd Ee Ee Ff Gg GB gb Hh Ii Jj Kk Ll Mm Nn Oo Oo Pp Rr Ss Ss Tt Uu Ww Yy
Apapo alifabeti ede Yoruba je meedogun (25)
Ona meji ni a le pin alifabeeti ede Yoruba si. Awon niyi;
- Iro Konsonanti
- Iro Faweli
Iro Konsonanti: Eyi ni iro ti a pe ni igba ti idiwo wa fun eemi.
Awon Konsonanti naa ni:
Bb Dd Ff Gg GB gb Hh Jj Kk Ll Mm Nn Pp Rr Ss Ss Tt Ww Yy
Apapo konsonanti ede Yoruba je mejidilogun (18)
Iro faweli: Eyi ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi
Eyi pin si ona meji:
Iro faweli airanmupe: A kii ran mu pe iro yii rara bee ni ko si idiwo fun eemi tabi afefe ti a n pe.
Meje (7) ni iro faweli airanmupe
Aa Ee Ee Ii Oo Oo Uu
Iro faweli aranmupe: A maa n ran mu pe awon iro yii. Ni gba ti a ba n pe awon iro yii jade, eemi maan gba iho imu ati enu jade lee kan naa.
Marun-un (5) ni iro faweli aranmupe – an, en, in, on, un
Apapo iro faweli ede Yoruba je mejila (12)
Igbelewon:
- Kin ni alifabeeti ede Yoruba?
- Ona meloo ni a pin alifabeeti ede Yoruba si?
- Ko won sita
Ise asetilewa :ISE SISE NINU IWE ILEWO YORUBA AKAYEGE
EKA ISE ASA
AKOLE ISE Itan Isedale Yoruba
- Itan so pe ilu meka ni Yoruba ti wa
- Itan fi ye wa pe Lamurudu ni baba nla Yoruba
- Lamurudu je Ogbontegi abogipa
- Itan so pe awon elesin musulumi gbe ogun ti Lamurudu lati fi esin iborisa sile
- Itan fi ye wa pe inu ogun yii ni Lamurudu ku si
- Ba kan naa, itan so pe Lamurudu ni baba Oduduwa
- Leyin iku Lamurudu, Oduduwa ati awon eniyan re sa wa si ilu ile ife
- Ilu ile-ife ni o je orisun fun gbogbo ile Yoruba
- Oruko omo Oduduwa ni Okanbi
- Okanbi ti o je omo Oduduwa bi omo meje. Awon ni:
S/N | ORUKO | ILU TI WON TE DO SI | OGUN TI WON PIN |
A | Olowu | Owu | Aso |
B | Alaketu | Ketu | Ade |
D | Oba Ibini | Bini | Owo eyo |
E | Orangun | Ila | Iyewo |
E | Oni Sabe | Sabe | Eran Osu |
F | Onipopo | Popo | ILeke |
G | Oranmiyan | Oyo | Ile |
Igbelewon:
- Ni sisentele so itan isedale Yoruba
- Daruko awon omo Okanbi pelu ogun ti won pin leyin iku baba won
Ise asetilewa: ya maapu omo eya ile yoruba
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: ORIKI LITIRESO.
Litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan tabi omiiran.
Litireso je ona ti Yoruba n gba fi ero inu won han nipa iriri won gbogbo.
Ona meji ni a le pin litireso si, awon ni
- Litireso alohun
- Litireso apileko
Litireso Alohun: Eyi ni litireso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon baba nla wa.
Litireso alohun pin si;
- Ewi
- Oro geere
- Ere Onise.
Litireso Apileko: Eyi ni litireso ti a se akosile ni gba ti imo moo- ko – moo-ka de.
Litireso apileko pin si;
- Ewi apileko
- Ere Onitan
- Itan Oroso
Igbelewon:
- Fun litireso ni oriki
- Ona meloo ni a pin litireso ede Yoruba si
- Salaye lekun-un rere
Ise asetilewa: ko apeere ewi alohun Yoruba marun-un
OSE KEJI
EKA ISE EDE
AKOLE ISE Ami Ohun lori awon faweli ati oro onisilebu kan.
Ami ohun ni o maa n fi iyato han laarin iro kan si iro keji.
- Ohun Isale \ (d) o doju ko opa osi
- Ohun aarin – (r) O wa ni ibu
- Ohun Oke / (m) O doju ko apa otun
Ami Ohun lori faweli:
A E E I O O U (Faweli airanmupe)
AN EN IN ON UN (Faweli aranmupe)
Ami Ohun lori oro onisilebu kan
silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso lai si idiwo
Akiyesi: Iye ami ori oro ni iye silebu inu oro bee.
Apeere oro onisilebu kan
- Ta (sell) – ohun isale (d) kf
- Sun (sleep) – ohun isale (d) kf
- We (bath) – ohun isale (d) kf
- Mu (drink) – ohun aarin (r) kf
- Ko (write) – ohun aarin (r) kf
- Lo (go) – Ohun aarin (r) kf
- Ji (steal) – Ohun Oke (m) kf
- Fe (love) – Ohun Oke (m) kf
- Si (open) – Ohun Oke (m) kf
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Ile – Ife saaju dide oduduwa ati idagbasoke ti oduduwa mu ba awujo naa.
- Itan so peilu ile-ife ni orisun Yoruba
- Itan fi ye wa pe inu igbo kijikiji ni ilu ile – ife wa
- Itan so pe awon Yoruba ni ibasepo pelu awon Tapa ati ibaripa
- Ilu ile-ife di agbogoyo eto oselu, esin abalaye ati awon asa Yoruba leyin dide oduduwa.
- Ninu eto eko ni odun 1962 ni a gbe ile eko giga yunifasiti lo si ilu ile-ife
- Ayipada otun de ba oro aje ilu ile ife leyin dide oduduwa
Igbelewon:
- Fun ami ohun loriki
- Ona meloo ni ami ohun ede Yoruba pin si?
- Kin ni silebu?
- Salaye idagbasoke ti o de ba ilu ile ife saaju dide oduduwa
Ise asetilewa: Ko oro onisilebu mewaa ki o si fi ami ohun ti o ba okookan won mu si i
OSE KETA
Eka Ise Ede
Akole Ise Ede
Ami Ohun lori oro onisilebu meji
i ba – ta(shoe) (dd) – kf – kf
ii E – we(leaf) (rd) – f – kf
iii A– ja(dog) (rm) – f – kf
iv Ba – ba (father)(dm) – kf – kf
v Ti – ti(a name of a person) (mm) – kf – kf
AMI OHUN LORI KONSONANTI ARAMUPE
Ninu ede Yoruba konsonati aramupe asesilebu ti a ni ni “N” konsonanti yii le jeyo ninu oro bi eyo silebu kan nitori o le gba ami ohun lori. apeere,
i n lo –(mr) –k –kf
ii n sun – (md) – k-kf
iii o –ro –n –bo (drdm)-kf-k-kf
iv ba-n-te (ddm)-kf-k-kf
v ko-n-ko (ddd)-kf-k-kf abbl
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Awon eya Yoruba ati Ibi ti won tedo si
Osusu owo ni gbogbo omo kaaro-o-o jiire se ara won. Bi o ti le je pe won ko si ni ojukan, si be omo iya ni gbogbo won.
Oniruuru eya ati ede ni awon omo Yoruba pin si kaakiri orile-ede Naijiria.
Awon eya Yoruba ati ilu ti won tedo si
OYO Ibadan, Iwo, Iseyin,Saki, Ogbonoso, Ikoyi-ile,
Igbo-ora, Eruwa, Ikeru, Ejigbo.
IFE Osogbo, Ile-ife, Obaluri, Ifetedoo, Araromi,
Oke igbo abbl
IJESA Ilesa, Ibolan, Ipetu-ijesa, Ijebu, Ijesa,
Esa-oke, Esa-odo, Imesi-ile abbl
EKITI Ado, Ikere, Ikole, Okamesi, Otun, Oya, Isan,
Omuo, Ifaki, abbl
Ondo Akure, Ondo, Owo, Idanre, Ore, Okitipupa,
Ikere, Akoko, Isua, Oke-igbo abbl
EGBA Abeokuta, Sagamu, Ijebu-ode, Epe, Igbesa,
Awori, Egbedo, Ayetoro, Ibora, Iberekodo,
Oke-odon, abbl
YEWA Ilaroo, Ayetoro, Imeko, Ifo, Isaya, Igbogila,
Ilobi, Ibese, abbl
IGBOMINA Ila-orayan, Omu-Aran, Oke-ila, Omupo,
Ajase-ipo abbl
ILORIN Ilorin, Okeoyi, Iponrin, Afon, Bala,
Ogbondoroko, abbl
EKO Isale-eko, Epetedo, Osodi, Ikotun, Egbe,
Agege, Ilupeju, Ikeja, Musin, Ikorodu,
Egbeda abbl.
EGUN Ajase, Ibereko, Aradagun abbl
EKA ISE: LETIRESO
AKOLE ISE: Awon Ohun to ya litireso Soto si Ede Ojoojumo
- Ede ni ohun to jade lenu ti o ni itumo ti o si je ami iyato laarin eniyan ati eranko.
- Ede ni a n lo lati gbe ero okan wa kale fun elomiiran
- Akojopo ede ti o di oro ijinle ni litireso.
- Ede joojumo je ipede igbora eni ye lawujo ti o ya eniyan ati eranko soto.
- Ijinle ede ti o kun fun ogbon, imo, oye, iriri,asa, igbagbo, ati eto awujo ni litireso.
IGBELEWON:
- Ko oro onisilebu marun-un ki o si fi ami ohun ti o ye si i
- So iyato meta ti o ya litireso soto si ede ojoojumo
- Ko eya Yoruba marun-un ati ibi ti won tedo si
ISE SISE: ko oro onii- konsonanti arnmupe marun-un pelu ami ohun to dangajia
OSE KERIN
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: SILEBU
Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso lai si idiwo.
Iye ami ohun ti o jeyo ninu oro kan ni iye silebu iru oro bee.
Ihun oro orusilebu kan le je,
I faweli nikan –(F)
ii Apapo konsonati ati faweli (KF)
iii Konsonati aranmupe asesilebu (N)
Apeere faweli nikan,
Gbogbo faweli aramupe ati aramupe je ihun oro onisilebu kan a e e I o o u
an en in on un.
Lilo won
Mo-ra-a (silebu kan ni “a, I, on, ati un”)
Mo-ri-i
Tolu mo-on
Baba-fun-un
Apeere apapo konsonati ati faweli (KF)
Lo – KF
Je – KF
Sun – KF
Fe – KF
Gba – KF
Ta – KF
Ge – KF
Ke – KF
Ra – KF
Ran – KF
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Ikini ni aarin eya Yoruba, ounje won ati bi won se n se won
Asa ikini je okan lara iwa omoluabi. o je iwa ti a gbodo ba lowo omo ti a bi, ti a ko ti o si gba eko rere dandan ni ki omokurin dobale gbalaja ki omobirin si wa lori ikunle ti won ba n ki agba.
Ikini ni aarin eya Yoruba.
Ede Ajumolo Ede Adugbo Ilu
E kaa-aro Wen kaaaro Ijebu
Nkoo Oro Ekiti
In kuo u ro o Ilesa
O koo ri ro Akoko
E kaaro Ife
Apeere miran
Alangbaa ti wo le Alangbaa ti wo le Oyo
Olo do gba ti ole Ijesa
Ijon gba ti wo le Ijebu
Ounje eya Yoruba
Ouje je ohunkohun ti eniyan tabi eranko n je tabi mu ti o si n sara lore.
Orisirisi awon agbegbe ni ile Yoruba ni o ni iru ounje ti won feran.
Ondo ati Ekiti – Iyan
Ijebu – Ikokore
Egba – Laafu
Ibadan – Oka/amola abbl
Ona ti a n gba se awon ounje ni ile Yoruba
Ewa
Won a sa ewa
Won a gbe omi ka ori ina
Bi omi ba ho won a da ewa sii
Won a re alubosa sii
Bi ewa ba ti fe jinna, won a fi ata lilo epo ati iyo sii
Leyin ti o ba ti jinna, o ti di jije
Oole / moin moin
Won a bo eepo ewa kuro
Won a lo ewa pelu ata ati alubosa
Won a pon ewa sinu ewe
Won a gbe e kana
Bi o ba jina, o di jije
Akara
Won abo ewa
Won a lo ewa pelu ata
Won a gbe epo kana
Won a re alubosa si ewa lilo
Won a da ewa lilo die die sinu epo gbigba
Bi o ba din tan, o di jije
Isu sise
Won a bo eepo ara isu danu
Won a gee si wewe
Won a gbe e kana pelu omi
Won a fi iyo sii, won a si de ikoko naa
Bi o ba jina, o jije
Iyan
Won a be isu
Won a gee si wewe
Won a da isu si ori ina pleu omi ninu re
Won kii fi iyo si bi isu jije
Bi o ba jinna, won a gun ninu odo
Leyin eyi won a fi obe ti o wu won jee
Asaro
Won a be epo isu danu
Won a gee si wewe
Won a gbe omi lena
Won a da eroja bi ata, epo, eja, iyo, ede alubosa abbl sinu re
Bi omi ba ti ho, won a da isu sii
Won a roo po
Bi o ba jinna, o di jije abbl
Igbelewon:
- Fun ounje ni oriki
- Ko eya Yoruba merin ki o si ko ounje ti won feran ju
- Kin ni silebu?
- Ko ihun silebu pelu apeere meji meji
Ise asetilewa: bawo ni a se n se ekuru ati obe gbegiri nin ile yoruba
OSE KARUN-UN
EKA ISEl LITIRESO
AKOLE ISE: Akoto ode-oni
Akoto ni ona ti a n gba ko ede Yoruba ni ona ti o bojumu ju ti ateyinwa lo.
Alaye lori akoto ode-oni
Ede Yoruba di kiko sile ni odun 1842
Pelu iranlowo awon ajihinrere ijo siemesi bisobu Samueli Ajayi crowther ati Henry Townsend.
Ile ijosin metodiisi, katoliki ati CMS se ipade lori akoto ede Yoruba ni odun 1875 – 1974
Abajade ipade won ni a n lo ninu ede Yoruba titi di oni.
Iwonba iro ti a ba pe ni ki a se akosile re.
Apeere sipeli atijo ati sipeli tuntun
SIPELI ATIJO SIPELI TUNTUN
Aiye Aye
Aiya Aya
Eiye Eye
Yio Yoo
Pepeiye Pepeye
Eiyele Eyele
Enia Eniyan
Okorin Okunrin
Obirin Obinrin
Onje Ouje
Shola Sola
Shango Sango
Oshogbo Osogbo
Ilesha Ilesa
Shagamu Sagamu
Offa Ofa
Ebute metta Ebute-meta
Shade Sade
Ottun Otun
Iddo Ido
Akiyesi:- A ko gbodo ko konsonati meeji po ninu ede Yoruba. Ba kan naa, awon oro tabi iro ti a ko pe jade lenu yiyo ni a oo yo won
AKA ISE: ASA
AKOLE ISE: Ikini II – Akoko
Asa Ikini sa Pataki ni ile Yoruba.
Idi niyi ti won fi n pe won ni “Omo Kaaro – o-o – jiire”.
Ori ikunle ni omo obinrin yo wa ti omo okunrin yoo si dobale gbalaja ti won ba n ki agba.
Oniruuru ikini ni ile Yoruba.
AKOKO IKINI IDAHUN
Ni aaro E kaaro O o
E-e-jiire bi? Oo
Se alaafia ni aji Adupe
Osan E kaasan Oo
Irole E kuurole Oo
Oru E ku aajin Oo
Ni akoko Ojo E ku ojo O o
Ni akoko Oye E ku oye O o
Ni akoko Iyan E ku aheje kiri o Olorun a yo wa
Alaboun Asokale aanfani o O o
Eni to bimo E ku owo lomi Ire a kari
E ku ewu omo oo
Agbe Aroko bodun de o Ase
Babalawo Aborun boye Amin
Aboye bo sise
Aweko oko a refoo, ogun a pana mo Amin o
Osise ijoba Oko oba ko ni sa yin lese Ase
Onidiri Oju gboro ooya a ya
E ku ewa
Oba Kabiyesi Oba yoo ju irukere
Alase Igba keji orisa Iranse oba yoo dahun pe;
Ki ade pe lori “Oba n ki o”
Ki bata pe lese
Awon ti won n ta ayo Mo kota mo kope Ota n je, ope ko gbodo fohun
Oloja Aje a wo gba o Ase
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: LITIRESO ALOHUN TO JE MO ASEYE.
Litrreso alohun ni litireso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon babanla wa.
Apeere litireso alohun ajemayeye ni
i Ekun Iyawo
ii rara
ii Bolojo
iv Apepe
v Dadakuada abbl
Ekun iyawo gege bi litireso alohun ayeye
Ekun Iyawo je ewi ti omo binrin ti n lo si ile oko maa n sun lojo igbe yawo.
Koko inu ewi ekun iyawo
- O n je ki a mo riri itoju ti awon obi re se lori re lati igba ewe.
- O wa fun idagbere fun ebi ati ara
- O wa fun omobinrin lati bere imoran lodo obi
- O wa fun eko fun awon wundia to ku lati pa ara won mo dojo igbeyawo
Agbegbe ti ekun iyawo ti n waye,
i Ilu iseyin
ii Ilu Ikirun
iii Ilu Osogbo
iv Ilu Oyo Alaafin
v Ilu Ogbomoso abbl
Rara gege bi litireso alohun Ajemayeye
- Rara je litireso alohun atigbadegba lawujo Yoruba.
- Awon obinrin ile ti won mo itupale oriki orisun oko ni won maa nfi rara sisu pon oko won le.
- Akoko ayeye bii ifinijoye igbeyawo, isomoloruko, isile abbl ni awon asurara maa n sun rara ju lati fi ki awon eniyan ja-n-kan lawujo.
- Asun rara le je Okunrin tabi obinrin
Agbegbe ti awon asurara wopo ju si,
I Ede v Oyo Alaafin
ii Ikirun vi Iseyin
iii Ogbomoso vii Ibadan abbl
iv Osogbo
Bolojo gege bi litireso alohun ajemayeye
- Awon omokunrin yewa ni o n sabe maa n ko bolojo lati fi se aponle, tu asiri ,se efe, soro nipa oro ilu, oro aje abbl.
- Won maa nko bolojo ni ibi ayeye bii, igbeyawo, isomoloruko, oye jije, isile abbl.
Igbelewon:
- Kin ni akoto?
- Ko oro atiji mewaa ki o si ko akoto irufe awon oro bee
- Fun litireso alohun ni oriki
- Ko litireso alohun ajemayeye marun un ki o si salaye
Ise asetilewa: ko apeere ewi ekun iyawo kan lati fi han pe obinrin ti o n lo ile oko ni o maa n sun ekun iyawo lati fi moriri awon obi re.
OSE KEFA
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: AKOTO AWON ORO TI A SUNKI
Akoto ni sipeli titun ti awon onimo ede Yoruba fi enu ko le lori ni odun 1974 lati maa lo.
Sipeli atijo Sipelu titun
Olopa Olopaa
Na Naa
Orun Oorun
Ogun Oogun
Anu Aanu
Papa Paapaa
Suru Suusu
Alafia Alaafia
Oloto Oloooto
Dada Daadaa
Eleyi Eleyii
Marun Marun-un
Alanu Alaaanu
Ologbe Oloogbe
Miran Miiran
Are Aare
Akiyesi:- Iye iro faweli ti a ba pe ni a gbodo se akosile re.
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: IWULO EDE YORUBA
- Ede Yoruba ni a n lo lati ba ara wa so asoye
- Ede ni a fi n se ipolowo oja
- Ohun ni a fi n korin nibi ayeye bii, igbeyawo, Isinku, Isile abbl
- A tun le lo ede fun oro asiri
- Ede Yoruba ni a n lo lati fi ke ewi ti yoo dun-un gbo leti,
- Ede ni a n lo lati fi koni ni eko ile nipa eewo ati asa ile wa.
EKA ISE: LETIRESO
AKOLE ISE: LITIRESO ALOHUN TO JE MO ESIN
AWON LITIRESO ALOHUN TO JE MO ESIN KAN TABI OMIIRAN NI ILE YORUBA NI WONYI,
i Oya – pipe
ii Esu – pipe
iii Orin – arungba
iv Ijala -sisun
v Sango – pipe
vi Iyere
vii Ese – Ifa
ESA – IFA / ORUNMILA:
- Awon olusi re ni babalowo ati awon aloye ifa .
- Akoko odun ifa tabi ni gba ti nnkan ba ru awon olusin re loju ni won n pe e.
Ounje ifa
Adie
Ewure
Eyele
Igbin
Eja
Epo abbl
Eewo ifa/Orunmila
- Jije isu titun saaju odun
igbagbo Yoruba ti o suyo ni
- Ayanmo
- Ebo-riru ati Olodumare.
IJALA:
- O je Orisa Ogun
- Awon Ode, agbe, alagbede ati awon onise irin gbogbo ni olusi ogun.
- Akoko odun ogun ni won maa n sun ijala.
Ounje Ogun.
Aja
Iyan
Obi
Emu
Esun-isu
Akukodie
Eewo Ogun
- Gbigbe ofifo agbe duro
igbagbo Yoruba ti o suyo
igi, aranko, eye.
- Won maa n sun ijala lati fi juba ogun ati lati fi wa oju rere re
SANGO PIPE:
- orisa yii je olufiran
- Awon adosun sango ati oloye re ni olusin re
- Asiko odun sango ni won maa n pe e
- ilu bata ni ilu sango
Ounje Sango.
Orogbo, agbo funfun
Eewo Sango
Siga mimu, Obi, Ewa sese abbl.
Akiyesi: Sango ni o ni ara ati monamona.
ORIN ARUNGBE:
- Awon Oloro ni olu sin re.
- Asiko odun oro ni a n ko orin yii
Ounje oro
Emu
Aja
Eewo Oro
- Obinrin ko gbodo ri oro
- a kii ri ajeku oro
orisa yii je orisa atunluuse
igbelewon :
- Ko iwulo ede Yoruba marun un
- Ko oro atijo marun un ki o si ko akoto irufe oro bee
- Ko litireso ajemo esin marun-un ki o si salaye
Ise asetilewa: se ise sise lori akole yii ninu iwe ilewo Yoruba Akayege
JSS 2 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA
OSE KEJE
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: ONKA YORUBA LATI OOKAN DE AADOTA (1-50).
Onka Yoruba je ona ti a n gba lati ka nnkan ni ona ti yoo rorun.
Nonba
1 | Ookan | |
2 | Eeji | |
3 | Eeta | |
4 | Eerin | |
5 | Aarun-un | |
6 | Eefa | |
7 | Eeje | |
8 | Eejo | |
9 | Eesan-an | |
10 | Eewaa | |
11 | Ookanla | 10+1=11 |
12 | Eejila | 10+2=12 |
13 | Eetala | 10+3=13 |
14 | Eerinla | 10+4=14 |
15 | Aarun din logun | 20-5=15 |
16 | Eerin din logun | 20-4=16 |
17 | Eeta din logun | 20-3=17 |
18 | Eeji din logun | 20-2=18 |
19 | Ooka din logun | 20-1=19 |
20 | Ogun | 20 |
21 | Ookan le logun | 20+1=21 |
22 | Eeji le logun | 20+2=22 |
23 | Eeta le logun | 20+3=23 |
24 | Eerin le logun | 20+4=24 |
25 | Aarun din logbon | 30-5=25 |
26 | Eerin dni logbon | 30-4=26 |
27 | Eeta din logbon | 30-3=27 |
28 | Eeji din logbon | 30-2=28 |
29 | Ookan din logbon | 30-1=29 |
30 | Ogbon | 30 |
31 | Ookan le logbon | 30+1=31 |
32 | Eeji le logbon | 30+2=32 |
33 | Eeta le logbon | 30+3=33 |
34 | Eerin le logbon | 30+4=34 |
35 | Aarun din logoji | 40-5=35 |
36 | Eerin din logoji | 40-4=36 |
37 | Eeta din logoji | 40-3=37 |
38 | Eeji din logoji | 40-2=38 |
39 | Ookan din logoji | 40-1=39 |
40 | Ogoji | 40 |
41 | Ookan le logoji | 40+1=41 |
42 | Eeji le logoji | 40+2=42 |
43 | Eeta le logoji | 40+3=43 |
44 | Eerin le logoji | 40+4=44 |
45 | Aarun din laadota | 50-5=45 |
46 | Eerin din laadota | 50-4=46 |
47 | Eeta din laadota | 50-3=47 |
48 | Eeji din laadota | 50-2=48 |
49 | Ookan din laadota | 50-1=49 |
50 | Aadota | 50 |
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: BI ASA SE JEYO NINU EDE YORUBA
Asa jeyo ninu Ede Yoruba ninu ipede bii owe, akanlo-ede, ewi ,ise sise abbl.
Apeere
OWE | ASA TI O JEYO | EKO TI AWON ASA YII KO WA | |
1 | N o le waa ku ko le ri oye ile baba re je | Oye jije | A gbodo ni igboya |
2 | Faari aseju oko olowo ni mu ni lo | Oge sise | Ki a maa se koja agbara wa, ki a maa ba te |
3 | Aroba sa kii Sojo | Eru jeje ni awon oba alaye (oye jije) | Ki a maa bu ola fun awon alase |
4 | Obe ti bale ile kii je iyaale ile kii see | Igbeyawo | Agbodo maa gbe igbe aye alaaafia pelu eni ti ajo n gbe, a ko gbodo se ohun ti enikeji ko fe |
Apeere akanlo-ede | |||
5 | Baba ti sun | Asa Isinku | Baba ti ku |
6 | O ta teru ni pa a | Asa Isinku | O ti ku abbl. |
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: LITIRESO APILEKO
Eyi ni litireso ti a se akosile ni gba ti imo mooko – mooka de si ile wa.
Litireso apileko pin si ona meta,
i Ewi
ii Ere-Onitan
iii Itan aroso
Litireso Apileko – Itan aroso
koko ti a gbodo tele ti a ba n ka litireso apileko itan aroso.
- Onkawe gbodo le salaye itan ni soki
- O gbodo le salaye ihuwasi awon eda itan inu iwe itan aroso
- O gbodo le mo koko oro itan naa
- Onkawe gbodo ko awon eko ti o ri ko jade
- O gbodo le fa awon isowolo ede jade bii owe, akanlo ede, abbl
- Onkawe gbodo le fa awon asa Yoruba ti o suyo jade
- Ba ka naa, O gbodo le mo ibudo itan aroso naa.
Igbelewon:
- Kin ni litireso apileko?
- Ona meloo ni o pin si?
- Ko awon koko to onkawe gbodo tele ti a ba n ka litireso apileko
- Ko onka lati ookan de aadota
Ise asetilewa: Ko owe ati akanlo ede meji meji ki o si fa asa ti o jeyo ninu okookan ati eko ti o ri ko jade
OSE KEJO
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: ONKA – OOKALELAADOTA DE OGORUN-UN (51-100).
51 | Ookan le laadota | 50+1=51 |
52 | Eeji le laadota | 50+2=52 |
53 | Eeta le laadota | 50+3=53 |
54 | Eerin le laadota | 50+4=54 |
55 | Aarun din logota | 60-5=55 |
56 | Eerin din logota | 60-4=56 |
57 | Eeta din logota | 60-3=57 |
58 | Eeji din logota | 60-2=58 |
59 | Ookan din logota | 60-1=59 |
60 | Ogota | 60 |
61 | Ookan le logota | 60+1=61 |
62 | Eeji le logota | 60+2=62 |
63 | Eeta le logota | 60+3=63 |
64 | Eerin le logota | 60+4=64 |
65 | Aarun din laadorin | 70-5=65 |
66 | Eerin din laadorin | 70-4=66 |
67 | Eeta din laadorin | 70-3=67 |
68 | Eeji din laadorin | 70-2=68 |
69 | Ookan din laadorin | 70-1=69 |
70 | Aadorin | 70 |
71 | Ookan le laadorin | 70+1=71 |
72 | Eeji le laadorin | 70+2=72 |
73 | Eeta le laadorin | 70+3=73 |
74 | Eerin le laadorin | 70+4=74 |
75 | Aarun din logorin | 80-5=75 |
76 | Eerin din logorin | 80-4=76 |
77 | Eeta din logorin | 80-3=77 |
78 | Eeji din logorin | 80-2=78 |
79 | Ookan din logorin | 80-1=79 |
80 | Ogorin | 80 |
81 | Ookan le logorin | 80+1=81 |
82 | Eeji le logorin | 80+2=82 |
83 | Eeta le logorin | 80+3=83 |
84 | Eerin le logorin | 80+4=84 |
85 | Aarun din laa dorun-un | 90-5=85 |
86 | Eerin din laa dorun-un | 90-4=86 |
87 | Eeta din laa dorun-un | 90-3=87 |
88 | Eeji din laa dorun-un | 90-2=88 |
89 | Ookan din laa dorun-un | 90-1=89 |
90 | Aadorun-un | 90 |
91 | Ooksn le laa dorun-un | 90+1=91 |
92 | Eeji le laa dorun-un | 90+2=92 |
93 | Eeta le laa dorun-un | 90+3=93 |
94 | Eerin le laa dorun-un | 90+4=94 |
95 | Aarun din logorun-un | 100-5=95 |
96 | Eerin din logorun-un | 100-4=96 |
97 | Eeta din logorun-un | 100-3=97 |
98 | Eeji din logorun-un | 100-2=98 |
99 | Ookan din logorun-un | 100-1=99 |
100 | Ogorun-un | 100 |
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: ASA ATI OHUN ELO ISOMOLORUKO.
Asa isomoloruko je ona ti a n gba fun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lae ni ile Yoruba.
Gbogbo ohun ti olodumare da saye lo ni oruko. oniruuru ohun-elo tabi eronja ni Yoruba si maa n lo ni gba Ikomojade . Ojo kefa ni Yoruba n so omo loruko, I ba se omokurin tabi omobinrin tabi ibeji sugbon ni ibo miiran , ojo kesan-an ni won n so omokunrin lorunko, ojo keje ni ti obinrin ti awon ibeji ni ojo kejo.
Die lara ohun elo isomoloruko niyi,
Ohun elo | Iwure/adura |
Obi | Bibi lobi n biku danu, bibi lobi n baarun danu, obi a bi ibi aye re danu. |
Orogbo | Orogbo maa n gbo saye ni, o o gbo o, wa a to, wa a gbo kejekeje, o ko ni gbo igbo iya. |
Oyin | A kii foyin senu ka roju koko, oro bi oyin bi adun ko ni dagbere fun o o koni je ikoso laye. |
Oti | Oti kii ti, oko ni ti laye bee ni oti kii te, o ko ni t e |
Epo pupa | Epo ni iroju obe, aye re a roju. |
Iyo | Iyo nii mu obe dun, iwo ni o maa mu inu awon obi re dun. |
Ataare | Ataare kii bimo tire laabo, fofo ni le ataare n kun, oye re a kun fomo. |
Aadun | adun adun ni a n ba nile aadun, ibaje oni wole to o. |
Ireke | A kii ba kikan ninu ireke, ikoro ko ni wo aye re lae, aye re yoo dun |
Omi tutu | Omi la buwe, omi la bumu enikan kii ba omi sota,koo mu to
Ko ni gbodi ninu re o Ko si ni sa pa o lori……… |
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ITAN AROSO – KIKA IW E TI IJOBA YAN
Igbelewon:
- Kin ni asa isomoloruko?
- Ko ohun elo isomoloruko marun un ki o si so bi a se n fi wure fun omo tuntun
- Ko onka lati aadota de ogoorun
Ise asetilewa:Ise sise inu Yoruba Akayege for jssone
OSE KESA-AN
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE.
Aroko je ohun ti a ro ti a si se akosile re lori pepa
ILANA FUN KIKO AROKO
- yiyan Ori-oro: A ni lati fa ila teere si abe ori-oro ti a n ko aroko le lori
- sise ilapa ero: A ni lati ronu jinle ki a si to ero okan wa ni okookan ninu ipinro kookan ki o le ye onkawe
- Kiko Aroko:-
- Alaroko gbodo ronu ohun ti o ye ki o je ifaara, ko gbodo gun ju
- Aarin aroko ni a o ti lo awon ojulowo koko oro bi a se lo won ninu ilapa ero. sipeli akoto ode-oni ni ki a fi ko aroko yii
- Ikadii:- eyi ni ipari aroko
- Ojulowo ede se pataki ninu aroko bii, Afiwe, akanlo ede abbl , ni akekoo gbodo se amulo.
ORISI AROKO
- Aroko atonisona alepejuwe
- Aroko asariyanjiyan
- Aroko atonisona oniroyin
- Aroko onileta
- Aroko ajemo – isipaya abbl
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: ISOMOLORUKO II – AWON ORISIRISI ORUKO ABISO AMUTORUNWA ABBL.
Gege bi owe Yoruba ti o wipe “ile la n wo, ki a to so omo loruko” A kii dede fun omo ni oruko ni ile Yoruba, ki won to fun omo loruko, won a se akiyesi iru ipo ti omo wa ni gba ti iya re bii tabi ipo ti ebi wa tabi ojo ati asiko ti a bi omo naa.
A pin oruko jije ni ile Yoruba si isori isori. Awon ni wonyi
- Oruko Abiso
- Oruko Amutorunwa
- Oruko Oriki
- Oruko Abiku
- Oruko Inagije
- Oruko Idile
Oruko Abiso: Eyi ni oruko ti a fun omo ni ibamu pelu iru ipo ti ebi baba tabi iya omo naa wa nigba ti abi
Apeere ati itumo
- Fijabi- omo ti a bi ni asiko ti ija wa ninu ebi
- Kuponiyi – omo ti a bi leyin iku alafokantan tabi akikanju
- Abosede – omo ti a bi lojo ose
- Odunjo – omo ti a bi lasiko odun ifa tabi odun miiran abbl
Oruko amutorunwa:- Eyi ni oruko ti a fun omo gege bi ipo ti omo wa ni gba ti iya re bi. Apeere,
- Taiwo: Omo ti o koko jade nigba ti a bi ibeji
- Kehinde: omo ti o keyin de nigba ti a bi ibeji
- Idowu: omo ti a bi tele ibeji
- Alaba: omo ti a bi tele idowu
- Idogbe: omo ti a bi tele alaba
- idoha: omo ti a bi tele idogbe
- Olugbodi: omo ti a bi ti oni ika owo tabi ika ese mefa
- Ilori: omo ti a bi nigba ti iya re ko se nnkan osun
- Omope: omo ti o lo ju osu mesan-an lo ninu iya re ki a to bi.
Oruko oriki: Eyi ni oruko iwuri ti awon Yoruba n fun omo tuntun. Won n lo o lati fi ki ni tabi gbori yin fun eniyan. Apeere,
Adeola, Abefe, Aduke, Adufe, Amoke, Asake, Ayinde, Ariike, Akanni abbl
Oruko Abiku: Eyi ni oruko ti a fun omo ti o je pe bi a se n bi ni o n ku, nigba ti a ba tun bi won pada ti won a tun pada ku. Apeere
Kosoko, kukoyi, durojaye, oruko tan duroriike, bamijokoo, abii na, omotunde, aja, durosimi, kokumo malomo abbl.
Oruko inajije: eyi ni oruko apeje ti ore tabi ebi fi n pe eniyan. O je oruko gbajumo. Apeere,
Ibadiaran, Idileke, Owonifaari, olowojebutu, epolanta, Aponbepore, Awelewa, Ekufunjowo, Eyinmenugun, Dudummadan abbl.
oruko idile: Opo idile ni o maa n fun awon omo ni oruko ni ibamu pelu ipo idile tabi ibamu pelu orisa, ise abinibi ti idile naa n se. apeere,
Idile oloye: Oyebele, Oyediran, Oyewole, Oyekanmi
Idile Oba: Adeooti, Adekanmibi, Adeniyi, Adesola
Idile ola: Oladoye, Oladapo, Olayeni, Olajide
Idile Olorisa: Orisatele, Orisaseye, Orisagbemi, Aborisade
Idile Alawo/Onifa: Faleti, Fabunmi, Fafuke, Fagbohun.
Idile Eleeyin: Olojede, Ojewole, Eeyinjobi
Idile Ede: Oderinde, Odewole, Odeyemi abbl.
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ERE-ONITAN
Litireso apileko ere-onitan ni iwe ere atinude ti onkowe ko lati so ohun ti o sele ninu itan tabi ti o sele loju aye.
Apeere iwe ere-onitan ni “Efusetan Aniwura ti Akinwumi Isola ko
Onkawe ere-onitan gbode mo awon koko wonyi,
- O gbodo mo nipa igbesi-aye onkowe
- O gbodo mo itan inu iwe naa
- O gbodo mo awon eda itan inu iwe naa
- O gbodo mo ibudo itan – adugbo tabi ilu ti ere naa ti waye
- Onkawe gbodo maa fi oye ba awon isele inu ere-onitan naa lo ni sise-n-tele.
- Koko oro-onkawe gbodo mo ohun ti itan naa dale lori , ki o si le toko si ete ti won ri ko.
- O gbo mo asa Yoruba ti o suyo
- O gbodo mo nipa ihuwasi eda itan
- Akekoo gbedo sakiyesi ohun ti o gbadun ninu ere-onitan naa.
Igbelewon:
- Kin ni aroko?
- Ko ilana kiko aroko
- Daruko orisi aroko marunun
- Fun asa isomoloruko ni oriki
- Ko orisi oruko jije ni ile Yoruba marun un ki o si salaye pelu apeere
- Kini litireso apileko ere onitan?
- Ko awon ohun ti onkawelitireso ere onitan gbodo fi sokan
Ise asetilewa: Ise sise inu Yoruba Akayege JSSone
OSE KEWAA
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: AROKO ATONISONA ALAPEJUWE.
Aroko je ohun ti a ro ti a sise akosile.
Aroko alapejuwe ni aroko ti o man sapejuwe eniyan, ibikan ati nnkan to n sele gege bi a se ri i gan-an. Apeere:
- Oja ilu mi
- Egbon mi
- Ile-iwe mi
- Ouje ti mo feran
- Ilu mi abbl.
Aroko lori Ile-Iwe mi
Oruko Ile-eko mi ni Elias International School. O wa ni Ojule keji-Ikerin ,Opopona ile-Epo, Oke-odo, ipile Eko. Oludasile ile iwe mi ni Dokita Dosumu. ile-iwe mije ile oloke meta meta ti o fegbe kegbe ti a si fi ilekun onirin si enu ona abawole re.
A kun ile-iwe mi ni awo ewe gege bi aso ile iwe wa. Iyara ikawe fun kilaasi girama ati alakobere po jantirere bee ofisi awon oluko ati alase ile-iwe naa ko kere niye.
A ni yara ero ayara bi asa, yara imo sayensi, yara imo ede, yara ibi ikawe ati iyawe, yara ijeun.
A fi ododo se ile-iwe mi losoo bee. Leyin ile iwe mi, a ni papa isere fun awon ere idaraya bi boolu alafese gba, ere idije, boolu alafowo gba abbl.
Apapo awon omo-ile mi le ni oodunrun, awon oluko wa le ni aadota. Awon omo ile-iwe mi je omo gidi nitori won n ko wa ni eko-iwa, akojopo eko ile, bi a ti n huwa ni awujo ati eko bibeli.
Ti a ba n soro nipa awon oluko wa awon oluko wa dangajia, won ni oyaya, iwa pele, bee ni won mo bi a ti n ba awon obi se.
Opolopo obi feran ile-iwe mi pupo nitori pe ibe ni awon looko-looko ti o di ipo giga mu ni orile ede yii ti jade bee ni esin idanwo ase kegba wo ile eko giga ti yunifaasiti won maa n dara pupo. mo feran ile-iwe mi nitori pe,
- Awon oluko wa kun ojo osuwon
- O ni awon ero ikawe igbalode
- Agbegbe re dun-un kawe
- Won n ko ni bi ati n je omo rere ni ile ati fun orile ede lapapo
JSS 3 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: OYA JIJE ATI OHUN ELO OYE JIJE.
Bi a se n joye ni ilu kan yato si bi a se n joye ni ilu miran.
Makan –makan ni oye jije je ni ile Yoruba.
Oniruuru oye jije ni ile Yoruba.
- Oye Oba
- Oye Baale
- Oye Iyalode
- Oye Ajiroba
- Oye Bobajiro
- Oye Iyalaje
- Oye Afobaje
- Oye Majekobaje
- Oye Ile
- Oye Eleto
- Oye Baba-Isegun
- Oye Gbajumo. Abbl
Ohun elo Oye Jije
- Ewe oye
- Etutu lorisirisi
- Ileke owo, orun, ese
- Ade-oba
- Ilu lorisirisi
- Igba oye
- Irukere
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO-EWI
Ewi apileko litireso je ijinle oro ti o ku fun laakaye, ogbon ati oye ti a fi ona ede ati oro ijinle gbekele.
Awon koko ti a ni lati tele ti a ba n ko ewi apileko.
- Eni ti o ko ewi naa: mimo itan igbesi aye akewi
- Koko oro: onka-ewi gbodo mo koko ti ewi naa dale lori
- Eko ti ewi naa n ko wa se Pataki lati mo
- Ona ede ati asa ti o suyo: onkawe gbodo le toka asa Yoruba ati oniruuru ona ede bii, owe, akanlo ede, afiwe, asorege abbl.
Igbelewon:
- Kin ni aroko?
- Fun aroko atonisona asapejuwe loriki
- Ko apeere aroko asapejuwe meta
- Ko oniruuru oye jije ile Yoruba marunun ati ohun elo oye naa
- Fun ewi apileko litireso ni oriki
- Ko ilana kiko litireso naa
Ise asetilewa: ko aroko lori ounje ti o feran ju
OSE KOKANLA
EKA ISE: EDE
AKOLE ISE: ISORI ORO NINU GBOLOHUN
Isori oro ni abala ti a pin awon oro inu ede yoruba si.
Isori oro Yoruba
- oro-oruko (NOUN)
- oro-aropo oruko (PRONOUN)
- oro ise (VERB)
- oro Aropo afarajoruko (PROMINAL )
- oro apejuwe ( ADJECTIVE )
- oro atoku (PREPOSITION)
- oro asopo ( CONJUCTION )
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: ISINKU
Isinku ni eye ikeyin ti a se fun oku logan ti o ku titi di akoko ti a fi sin.
Orisi oku sinsin ni ile Yoruba
- Oku Oba
- Oku Ijoye
- Oku Alaboyun
- Oku Adete
- Oku Abuke
- Oku Afin
- Oku Odo
- Oku Aro
- Oku eni ti o pokunso
- Oku eni ti sango pa
- Oku eni ti igi yalu pa abbl.
Ohun elo oku sin-sin.
- Aso funfun
- poosi oku/eni
- etutu lorisirisi
- owu tutu
- igi ora
- eepe (iyepe)
- lofinde oloorun
- Oniruuru nnkan ti enu n je, ileke owo, bata, opa itile abbl.
Igbelewon:
- Fun asa isinku ni oriki
- Ko orisi oku sin sin ni ile Yoruba mewaa
- Ko ohun elo oku sin sin nile Yoruba
- Ko isori oro ede Yoruba mefa
Ise asetilewa: fun awon isori oro wonyi loriki pelu apeere meji meji:
- Oro oruko
- Oro ise