BI A SE N KI NI IKINI ATI IDAHUN
Subject : Yoruba
Class : Jss 2
Term : Third Term
Week : Week 4
Topic :
OSE KERIN
EDE
ISEDA ORO ORUKO
AKOONU:-
__ Afomo ibere
Afomo aarin
NOOTI
Orisiirisii igbese ni a le gbe lati seda oro oruko yato si awon oro oruko ponbele ti a ni ninu ede Yoruba, sugbon ise kan naa ni gbogbo won n se ninu gbolohun.
AFOMO IBERE
(A) A maa n seda oro oruko nipa fifi afomo ibere mo oro ise kan. Awon wunren afomo ibere ni:-
a e e i o o
a e i o o
Ati, on, ,oni, olu
Apeere: –
Afomo ibere Oro ise Oro oruko ti a seda
a bo abo
e be ebe
o ku oku
e gbe egbe
ai lo ailo
(B) A maa n fi afomo ibere mo oro ise meji
Afomo ibere Oro ise (1) Oro (2) Oro oruko ti a seda
I gba gbo Igbagbo
a ko jo Akojo
I tan je Itanje
a be wo Abewo
a pe je Apeje
(D) A maa n fi afomo ibere mo oro ise pelu oro oruko miiran. Isunki maa n waye laarin oro ise ati oro oruko ti o tele e ki a to wa seda oro oruko tuntun lara afomo ibere ati isunki.
Afomo ibere Oro ise Oro Oruko Isunki Oro oruko ti a seda
a pa eja peja Apeja
on ra oja raja Oaraja
a de irin derin Aderin
ati gun igi gungi atigungi
Olu wa idi wadii Oluwadii
(E) A maa n fi afomo ibere mo apola oro ise lati di oro oruko miran.
Afomo ibere Apola ise Oro oruko ti a seda
I da eni ni eko Idanilekoo
a ru eru ma so Arerumaso
a pa eni ma yo ida apanimayoda
ai ro inu pa iwa da aironupiwada
ai fi agba fun enikan aifagbafenikan
(E) A maa n fi afomo ibere “oni” mo oro oruko lati seda oro oruko miran.
Apeere:-
Oni + Ile = onile
Oni + aso = Alaso
Oni + oogun = oloogun
Oni + oko = oloko
Oni + igi = Onigi
IGBELEWON
- Awon ona wo ni a le gba lo afomo ibere lati seda oro oruko.
- Awon wunren wo ni a n lo gege bi afomo aarin
- Seda oro oruko merin nipa lilo afomo ibere “oni”
AWON IWE KIKA
- Egbe akomolede ati asa Yoruba (2002) Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) oju iwe 57-58 Longman Nig Plc.
- Oyebamiji Mustapha (2002) Eko ede Yoruba titun iwe keji (J.S.S.2) oju iwe 32-36 university Press .
ASA
IKINI (GREETINGS)
Ikini je okan lara asa Yoruba. O je ona ti a fi n gba mo omoluwabi. Yoruba ko fi owo yepere mu asa ikini. Ti omode ba n koja ni odo agbalagba o gbodo ki won afi ti o ba je wi pe omo naa ko ni eko ile. Okunrin maa n dobale ki eniyan ni ni igba ti obinrin yoo kunle.
IDOBALE ATI IKUNLE
AKOKO IKINI IDAHUN
Aaro/owuro Ekaaro o o o, a dupe
E e jiire bi o
Osan E kaasan o o o.
Irole E kuurole o o o
Ale E kale o o o
BI A SE N KI NI IKINI IDAHUN
Aboyun Asokale anfaani o e se o
Nibi isomoloruko E ku ijade oni adun a kari o
Nibi oku E ku aseyinde o eyin naa a gbeyin arugbo yin o
Onidiri Eku ewa/oju gbooro o o
Agbe Aroko bodun de o ase o
Osise Ijoba oko oba o ni sayin lese o ami o
Ijoye kara o le wa a gbo.
Oba Kabiyesi o oba n ki o
Eni to n jeun lowo E bamiire o omo rere a ba o je
Nibi oku agba E ku aseyinde o e se o, eyin naa a gbeyin arugbo yin o
Ipo Iloyun afon a gbo ko to wo
A a gbohun iya ati ti omo o
Were ni a o gbo o
Agbe o ni fo, omi o ni danu o
ÌWÉ ÀKÀTILÉWÁ
Oyèbámjí Mustapha (2013) ÈKÓ ÈDÈ YORÙBÁ TITUN ìwé kìn-ín-ní University Press Plc oju iwe 116-120
IGBELEWON
- Ko ona meta ti a n gba ki awon onise owo meta.
Bawo ni won se n ki (eniyan ni): osan, alaboyun, ogilniti ati eni ti o n jeun lowo.
APAPO IGBELEWON
- Awon ona wo ni a le gba lo afomo ibere lati seda oro oruko.
- Awon wunren wo ni a n lo gege bi afomo aarin
- Seda oro oruko merin nipa lilo afomo ibere “oni”
- Salaye bi a se n ki awon wonyi: aboyun agbe, osise ijoba, oba
ATUNYEWO EKO
- Ko gbogbo iro konsonanti sile
- Ko gbogbo iro faweli sile.
IWE AKATILEWA
- Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) university Press oju iwe 198-200
- Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc oju iwe 17.
ISE ASETILEWA
1 A seda “ebe” nipa fifi afomo ibere mo _______ (a) oro ise kan (b) Oro ise meji (d) Oro ise pelu oro oruko
- Afomo ibere mo oro ise meji ni _______ (a) Ebe (b) Oluwadii (d) Apeje.
3 Oro oruko maa n sise pelu oro ise ninu iseda oro oruko (a) Beeko (B0 Bee ni (d) ko ye mi.
4 igba a ro o ni won maa n ki (a) oba (b) ijoye (d) alaboyun
5 eni ti o maa n dobale ni (a) okunrin (b) obinrin (d) agbe.
APA KEJI
- Lo awon oro wonyi lati seda oro oruko: oni, ati, e.
- salaye lekun rere.