AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.
Subject : Yoruba
Class : Jss 2
Term : Third Term
Week : Week 8
Topic :
EDE Ami Ohun Oro Onisilebu Meji.
ASA Awon Eya Yoruba ati ibi ti won tedo si.
LIT Kikai we Apileko ti Ijoba yan.
OSE KEJO
EDE
ATUNYEWO AWON AWE GBOLOHUN
Awe gbolohun ni apakan odindi gbolohun. Awe gbolohun pin si orisi meji. Awon naa ni awe gbolohun afrahe ati olori awe gbolohun.
Olori Awe Gbolohun: Olori awe gbolohun ni abala apakan odindi gbolohun ti o le da duro pelu itumo.Fun apeere.
- Mo ti lo ki ore mi de
- Gbogbo ilu gbo pe oba waja
- Akekoo naa mura ki o le gbebun
Awe Gbolohun Afarahe: Awe gbolohun afarahe je awe gbolohun ti ko le da duro pelu itumo. Omaa n fara he olori awe gbolohun ni. Fun apeere.
- Ore mi ti o lo si Eko ti de.
- Mo ti lo ki ore mi to de.
- Mo we nigba ti mo setan
- Awon eniyan mo pe ounje won.
IGBELEWON
1 Toka si olori awe gbolohun nihin-in
- Maa jeun bi mo ba se tan
- Tolu a ti lo ki o to de
- Ounje yii dun bi I pe ki n je tan
- Bade ri mi nigba ti mo de
- A tete lo ki a le tete de
2 Tokasi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi
- Oluko ri Dada ni oko oloko
- Mo we nigba ti mo ti oko de
- Bola mura sise ki o le yege
IWE AKATILEWA
1 Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S 2 ) oju iwe 29-32 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba
ASA
ASA ISINKU NI ILE YORUBA
Awon Yoruba gbagbo pe gbogbo wa ni a da agbada iku,won a ni ‘ma forum yo mi gbogbo wa la jo n lo.’atomode atagba ko si eni ti ko ni ku,gbogbo wa la je gbese iku.Ki Olorun ko fi iku rere pa ni.
Awon Yoruba gbagbo pe bi eniyan ba ku yoo lo si orun, yala rere tabi orun apaadi.
AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.
Ki Edumare ki o fi iku ire pa gbogbo wa bi a ti n sin oku kookan da lori eni ti o je ati iru iku ti o pa eni bee. Die ninu iru re niwonyii.
Eni ti sango pa. Awon mogba nii se etutu sisin re.
Eni ti sanponna pa inu igbo ni won maa n sin-in si awon adahunse ni
Si n se etutu sisin re.
Eni ti o ku sinu odo eti odo ti o ku si ni won maa n sin–in si, awon
alawo ni si n se etutu re.
Eni ti o ku toyuntoyun awon oloro nii se etutu sisin re.
Adete awon ogbontarigi adahunse ni i se etutu sisin re, inu
Igbo ni won a sin-in si, won a si sun gbogbo nnkan Ini re.
Eni ti o pokunso Awon onimole ni i sin in,idi igi ti o pokunso si naa
ni won o sin in si.
Abuke Awon babalawo ati adahunse ni i se etutu sinsin re,
Inu igbo ni won sin in si, ninu ikoko,won a si sin
Gbogbo nnkan ini re mo pelu.
Babalawo awon agba awo ni i se etutu sisin oku babalawo
pelu eye ti o ga ti won yoo fi se etutu lati yose re
kuro ninu egbe awo.
Ode awon ode nii se ayeye oku ode sisin,oro Pataki ti
Won ni lati se fun un ni sisipa ode ti a mo si ‘ ikopa ode’ eyi ni etutu ti won maa n se ki awon eran ti ode naa ti pa nigba aye re ma baa hun un,ki o sile je ki awon ode to ku laye maa ri eranko.
Onilu awon onilu nii se etutu onilu lati yowo elegbe won
ti o ti ku kuro ninu egbe ki awon to ku le maa ri se.
Alagbede Awon alagbede nii se oro igbeyin fun oku alagbede
lati yowo re kuro ninu egbe.Inu ile aro ti alagbede
naa ti n sise ki o to ku ni a ti maa n saba se etutu
Ikeyin yii.
Yato si gbogbo awon wonyii,awon Yoruba a maa ro oku paapaa eyi ti o ba je oku oroju ti
won gba pe iku re kii se lasan,awon agba adahunse tabi oloogun ni o maa n ro oku, ki
won to gbe e si koto, riro yii lo maa je ki o se iku pa eni ti o pa a. .
IGBELEWON : –
- salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv. Eni ti o pokunso.
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo,Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Oju iwe 1-35 Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd.
APAPO IGBELEWON
1 Toka si olori awe gbolohun nihin-in
- Maa jeun bi mo ba se tan
- Tolu a ti lo ki o to de
- Ounje yii dun bi I pe ki n je tan
- Bade ri mi nigba ti mo de
- A tete lo ki a le tete de
2 Tokasi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi
- Oluko ri Dada ni oko oloko
- Mo we nigba ti mo ti oko de
- Bola mura sise ki o le yege
LITIRESO
IGBELEWON
- Ko ise abinibi mewaa sile.
- Slaye okna ninu ise abinibi ti o ko.
KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.
IWE AKATILEWA
1 Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) oju iwe 10- 15 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.
ISE ASETILEWA
- Ewo lo kun ju lati gbe ero okan eni kale? (a) oro (b) awe gbolohun (d) gbolohun.
- Ewo ni ki I se orisii gbolohun Yoruba (a) olopo oro ise (b) alakanpo (d) alatunto
- Awe gbolohun wo lo le da duro bi odidi gbolohun (a) olori (b) afarahe (d) asaponle.
- Ewi alohun ajemayeye ni (a) ijala (b) dadakuada (d) Oku pipe.
- Eni ti won maa n sin pelu eru/gbogbo awon nnkan ti o ni ni? (a) adete (b) abuke (d) alawo
APA KEJI
- Iyato wo lo wa laarin awe gbolohun afarahe a ti olori awe gbolohun? Fun ni apeere meta
- Salaye bi won se n sin orisii oku marun-un.