JSS 1 SECOND YORUBA LESSON NOTE

 

SECOND TERM

YORUBA LANGUAGE – JSS ONE

ETO ISE FUN SAA KEJI

Ose Kin-In-Ni: Atunyewo ise saa kin-in-ni

Ose Keji: Ede: Orik ati eya gbolohun Ede Yoruba pelu apeere 

Asa: Oge sise ni ile Yoruba 

Litireso: Orin ibile to je mo asa igbeyawo, pipa ogo obinrin   

                                           Mo,ise Agbe, ise ode.  Pataki orin lawujo Yoruba.

Ose Keta: Ede: Aroko, Atonisona Oniroyin 

Ose Kerin: Ede: Ise Oro-oruko ati oro aropo-oruko ninu gbolohun

Litireso: Litireso Apileko oloro geere

Ose Karun-un: Ede: Ise oro Apejuwe ati oro aponle ninu gbolohun

  Onka ni ede Yoruba – Ookanlelogorun-un de igba(101 – 200)

 

Ose kin-in-in

Akole Ise: Atunyewo ise saa kin-in-ni

 

OSE KEJI

Akole Ise – Ede: Oriki Ati Eya gbolohun ede Yoruba pelu apeere (sentence)

Gbolohun ni akojopo oro ti o ni oro-ise ati ise ti o n je nibikibi ti o ba ti jeyo.

 

Eya gbolohun pin si ona meji 

  1. Gbolohun Abode/eleyo oro-ise
  2. Gbolohun onibo/olo po oro-ise

 

Gbolohun Abode/Ele yo oro-ise

Gbolohun Abode je gbolohun ti kii gun

Gbolohun Abode kii ni ju oro-ise eyokan lo. Apeere,

  1. Bata re ja
  2. Adufe sun
  3. Oluko ko ise
  4. Dayo fe iyawo

 

Ihun gbolohun abode/eleyo oro-ise

  1. Gbolohun eleyo oro-ise le je oro-ise ni kan: – Apeere; lo, jokoo, wole, jade, gbo, fe, abbl.
  2. Gbolohun eleyo oro-ise le je oluwa oro-ise ati oro-aponle.  Apeere 
  1. Ile ga gogoro

Oluwa oro-ise oro-aponle

  1. Jolade sun fonfon

Oluwa oro-ise oro aponle

(D) Gbolohun eleyo oro-ise le je oluwa.

  1. Oro-ise kan ati abo.  Apeere
  1. Ige je iyan

Oluwa oro-ise abo

  1. Asake pon omo

Oluwa oro-ise abo

(E) Gbolohun eleyo oro-ise le je oluwa, oro-ise kan, abo ati apola atokun.  Apeere

  1. Aina je eba ni ana

Oluwa oro-ise abo apola atokun

  1. Ojo gbe owo si ori

Oluwa oro-ise abo apola atokun

(E) Gbolohun eleyo oro-ise le je Oluwa, oro-ise kan ati apola atokun.  Apeere,

  1. Folakemi lo si odo

Oluwa oro-ise apola atokun

  1. Idowu lo si oja

Oluwa oro-ise apole atokun

 

(i) folakemi lo si odo

Oluwa oro apole atokun

(ii) Idowu lo si oja

Oluwa oro ise   apole atokun

Gbolohun onibo/olopo oro –ise

Eyi ni gbolohun ti a fi gbolohun miran bo inu re.  apeere re;

(i) Awon ole yoo sa bi awon ode ba fon fere

Alaye:- (a)  Awon ole yoo sa

(b)  Bi awon ode ba fon fere.

Gbolohun oke yii je gbolohun keji.  A le gbe won fun ra won bay ii ti won ko si ni so itumo gbolohun naa nu;

=) Ti awon ode ba fon fere awon ole yo sa – gbolohun onibo a saponle 

(ii) Oko ti Ade ra dara

(a) Oko dara

(b) Ade ra oko

Gbolohun meji ni a gbe wonu ara won – gbolohun onibo asapejuwe.  (descriptive)

(iii) O dara pe o rise si ile-epo – pe o rise si ile-epo o dara – gbolohun onibo asodoruko (personification).

 

Igbelewon:-

  1. Kin ni gbolohun?
  2. Eye meloo ni gbolohun pin si?
  1. Saleye gbolohun abode ati onibo pelu apeere meji meji.

 

Ise Asetilewa:- 

Irufe gbolohun wo niyi :

  1. Bola ra aso 
  2. Awon akekoo yoo se aseyori ti awon Oluko ba ko won
  3. Tomi pon omi
  4. Baba  agba ko ni ku bi awon Dokita ba se ayewo to to fun un
  5. Yomi fe iyawo

ASA – OGE SISE NI ILE YORUBA (FASHION)

Oge sise je asa imototo ati sise ara losoo.

Awon ona ti a n gbe se oge ni ile Yoruba laye atijo.

  1. Iwe wiwe:- Eyi maa n mu ara eniyan mo tonitoni bee ni ou san bi kuruna, ara wiwo yoo jinna si eni to ba n we dee de.
  2. Aso wiwo:- Awon Yoruba ni igbagbo pe aso lo n bo asiri ara, idi niyi ti awon Yoruba fi n da oniruwu aso fun igba ayeye lorisiris.  Aso bii, Dansiki, Kenbe, Agbada, Buba ati soro fun awon okunrun, iro ati buba, gele, iboru ati ipele fun awon obinrin
  3. Itoju irun ori:- Eyi se Pataki nitori na ni Yoruba fi n pa owe pe “Irun kikun ni ipilese were”.  Ona ti awon obinrin fi n toju irun won ni irun didi ni aye atijo. Orisirisi irun didi bii, suku, patewo, ipako elede, panumo, kolese, koju-soko, koroba abbl ni o gbajumo laarin awon obinrin.  Awon ti o n di irun ta ni onidiri”.

Awon okunrin a maa fa irun ori, ge irun ori tabi dida osu si ori bii oni sango.

  1. Tiroo lile:- Asa obinrin ni tiroo lile, ko wopo laarin okunrin.  Ti roo maa n mu ki oju tutu ki o si dun-un wo be ni o dara fun awon ti eyinju won maa n pon lati le je ki idoti oju won ba ipin oju jade.
  2. Laali lile:- Aajo ewa ni laali lile.  Aarin Hausa ati tapa ni o wopo ju si.  Awo elesin musulim ni o mu loo inu asa Yoruba.
  3. Ila oju kiko:- Ila kiko je asa Yoruba lati da eru mo si ojulowo omo ni aye atijo.  Ila kiko wopo laarin awo oyo, ibadan, ogbomoso, ondo, osogbo, abbl.  Apeere ila kiko ni, pele, abaja, olowu, gonbo, bamu, keke, ture, abbl.

OGE SISE LODE-ONI

  1. Aso wiwo:- Oniruru aso igbalode ni okunrin ati obinrin n wo lode-oni.  Aso obinrin-solate, kabe, bonfo. Tabi mafogota ati bilaosi.

Aso Okunrin:- Kootu, seeti, tai ati sokoto tinrin

  1. Lilo ohun eso bii bata, bagi, biidi igbalode, goolu ati selifa, oruka owo ati ese
  2. Itoju oju, enu ati ete bii, leedi ati atike alawo oniruuru, itote ni oniruuru awo.
  3. Itoju ara:- Yiya tatuu si ara .
  4. Itoju irun ori:- Awon obinrin ama fo irun ori tabi ki won jo o ni ina, lilo wiigi, fifi adamodi irun kun irun ki owo re le gun lo gbode kan loni.

Awon Okunrin a maa ge sitai ori bii, bob merley koko, weefu, all back abbl.

Aleebu oge-sise lode-oni

  1. Olaju iwe ati asa ti mu ki oge sise yato ni ile Yoruba
  2. Opo aso ode-ori kii bo asiri ara mo.

 

PATAKI OGE-SISE

  1.  O n je ki ara eniyan mo toni toni                   
  2. O n le aisan jinna si eniyan
  3. Ko kii je ki ara wo ni
  4. O n bo asiri ara
  5. Tiroo lile maa nti idoti oju jade 
  6. O n bu ewa kun ni

 

Igbelewon:-

  1. Fun oge sise ni oriki
  2. Ko ona marun-un ti a n gbe se oge laye atijo
  3. Salaye aleebu ogesisi lode-oni ni soki

 

ISE ASETILEWA:-  

Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe kejilelogun Eko kejidinlogun

 

LITIRESO:-  Orin Ibile To Jemo Asa Igbeyawo, Pipa Ogo Obinrin Mo Ise Agbe Ise Ode.

Orin to je mo asa igbeyawo

  1. Tun mi gbe

Oko mi tun mi yan

Iyawo dun lo sin-gin

Irin eyi wu wa o

Iyawo dun losin-gin o 

Tun mi gbe

  1. Baba mo mi lo

Fadura sin mi o

Iya mo mi lo

Fadura sin mi o

Kin maa kesu

Kin maa kagbako nile oko

Kin maa kesu

Kin maa kagbako  nile oko

Iya mo mi lo

Fadura sin mi o.

Orin ibile to je mo ise Agbe:-

Ise agbe nise ile wa

Eni ko sise, a maa jale

Iwe kiko lai si oko ati ada

Ko I pe o!

Ko I pe o!

Orin ibile to je mo pipa ogo obinrin mo:-

Ibaale ibaale o!

Ibaale logo’binrin

Ibaale o!

Olomoge pa’ra re mo

Pa’ra re mo o

Ibaale logo obinrin

Ibaale o!

 

Iwulo/Pataki orin

  1. O wa fun idoraya
  2. O n mu inu eni dun
  3. O wa fun iwuri

 

Igbelewon:-  Ko orin ibile meji meji fun awon Asa ati ise ibile wonyi:-

  1. Igbeyawo
  2. Pipa ogo obinrin mo
  3. Ise agbe

 

Ise Asetilewa:-  Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe kejidinlogun Eko kerinla

 

OSE KETA

AKOLE ISE- EDE:- AROKO ATONISONA ONIROYIN (NARRATIVE ESSAY)

Aroko ni ohun ti a ro ninu okan wa ti a si se akosile re.

Aroko oniroyin je aroko ti o jo mo iroyin sise.

Eyi le je kiko sile tabi si so lenu.

Yoruba JSS 1 Lesson Plan and scheme of work with lesson notes

Awon Igbese/Ilara Kiko Aroko Oniroyin

  1. Mi mu ori-oro ti a fe ko nnkan le
  2. Ki ko koko ohun ti a fe soro le lori le see se ni ipinro (paragraph) kookan.

Apeere Ori Oro Aroko Oniroyin Ni Wonyi:-

  1. Ijanba oko kan ti o se oju mi
  2. Ayeye isile kan ti won seni adigbo mi

 

Apeere Aroko oniroyin:-

IJAMBA OKO KAN TI O SE OJU MI

Ojo buruku esu gbomi mu ni irole ojo aiku, ojo keji, osu kefa odun 2015 ni dede ago meje aaro.  Emi ati aburo mi Ade gbera lati Ilu Ilorin a n  lo si ile egbon baba wa ni Ilu Ibadan lati lo ba a se ajo yo isile.

 

Ni keeti ti oko wa rin de ilu Ogbomoso, sa deede ni oko tanka elepo ya bara si ona ibomiiran nigba ti bureeki oko yii feeli lojiji, n se ni o run oko jiipu kan ti oko ati iyawo pelu awon omo won wa nibe mole.  N se ni ibosi oro ya lenu awon awako ati ero to n rin iyin apopona marose ogbomoso.

 

Bi eniyan ba je ori ahun onitohun yoo kaa anu abiyemo lojo naa.  Opelope awon ogbofinro to se iranlowo lati gbe awon ero inu oko jiipu yii lo si ile iwosan.  Sugbon epa ko boro mo fun awako jiipu yii, loju kan  naa ni o gbe emi mi.  

 

Imoran mi si awon ijoba ni pe ki awon agbofinro maa boju to awon da reba ki won si maa fi oju ba ile ejo fun idajo ti oba ye.  Ijoba gbodo se ofin ti yoo nii ki olukuluku se atunse si oko won loorekore, ki iru ijanba bayii ma ba waye mo.

 

Igbelewon:-  Dahun ibeeree wonyi;

  1. Fun aroko oniroyin ni oriki
  2. Ko ilana kiko oroko oniroyin meji

 

Ise Asetilewa:- Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe keedogun Eko kokandinlogun

 

OSE KERIN

Akole Ise – Ede:- ISE ORO ORUKO ATI ORO AROPO ORUKO NINU GBOLOHUN

Oro Oruko:-  Oro Oruko ni awon oro ti won le da duro ni ipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun.

Ise Oro-Oruko

  1. Oro-Oruko maa n sise oluwa ninu gbolohun – Oluwa ni oluse nnkan ninu gbolohun apeere;
  1. Ayinde ra aso
  2. Ojo je ewa
  1. Oro oruko maa n wa ni ipo abo ninu gbolohun – Eyi ni eni ti a se nnkan si ninu gbolohun.  Apeere;
  1. Mo ra oko
  2. Onilu lu ilu
  1. Oro-Oruko maa n se ise eyan fun oro oruko miiran.  Apeere;
  1. Baba agbe ge igi
  2. Kunle oluko na yemi
  1. Binpe pa ejo obokun
  1. Oro-Oruko tun maa n sise abo fun oro-atokun. Apeere;
  1. Ade lo si oja
  2. Emi lo ba ni ile

 

ORO AROPO ORUKO:-Eyi ni awon oro ti a n lo dipo oro oruko ninu gbolohun.

Ise Oro Aropo – Oruko

  1. Oro Aropo- Oruko le se ise oluwa ninu gbolohun.  A le pin-in si ipo eyo ati opo

Eni Eyo Opo

Kin-in-ni Mo/n ‘A’

Keji O E

Keta O Won

Apeere;

  1. Mo je ebe Eyi eni kin-in-ni 

n o je eba

  1. A je eba – opo eni kin-in-ni
  1. Oro aropo-oruko le se ise abo ninu oro-ise ninu gbolohun.

Eyo opo

Eni kin-in-ni Mi Wa

Eni Keji O/E Yin

Eni keta Afaagun faweli won

Apeere;

Eni  kin-in-ni

  1. Tolu ri mi – eyo

Tolu ri wa – opo

Eni keji

  1. Orun pa o

orun pa e

orun pa yin – opo

eni keta

iii. O so fun un

Ade  gbe e

  1. Oro aropo-oruko maa n se ise eyan ninu gbolohun

Eyo Opo

Eni kin-in-ni ‘Mi’ wa

Eni keji re/e yin

Eni keta Re/e won

Apeere

Aso re wu mi – Eni keta eyo

Igba gbe se won – eni keta opo

Ile yin dara – eni keji opo.

Igbelewon:-

(i) So itumo oro oruko ati oro aropo oruko

(ii) Ko ise oro-oruko ati aropo oro meji meji pelu apeere

 

ISE ASETILEWA:-

  1.  ko isori awon oro yoruba inu gbolohun wonyii jade.
  1. Mo ra epa
  2. Oluko na mi

D  Mo ri gbogbo yin

E  Eyin re funfun bii egbon owu

  1. Ile wa gbayi o gbeye

 

  1. Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o   L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe ogun Eko kerindinlogun

 

AKOLE ISE:-

LITRESO – Litreso Apileko Oloro geere ti ijoba yan. Ewi Yoruba lakotun fun ile iwe sekondiri kekere lati owo M.A,Olowu ati awon akeegbe re.

 

Igbelewon:-

(i) Iwe itan apileko oloro geere wo ni a yan fun kika ni taamu yin?

(ii) Ta ni onkowe iwe naa?

ISE ASETILEWA:- Ewi Yoruba Lakootun(ibeere ewi ti a ka)

 

OSE KARUN-UN

AKOLE ISE – Ede:- Ise oro – Apejuwe at oro-aponle ninu gbolohun 

Oro Apejuwe:-Eyi ni awon oro ti o n toka isele inu gbolohun .

Oro oruko ni o maa n yan.

Ise oro Apejuwe

  1. O le se ise eyan ninu gbolohu 

(a)  Oro apejuwe le yan oro – oruko ni ipo oluwa.  Apeere;

Oruko rere san ju wura oun fadaka lo

Iwa bukuku ko ye eniyan

(b)  Oro apejuwe le yan oro-oruko ni ipo abo.  Apeere;

Inioluwa la igi gbigbe

Ayinde wo aso funfun

  1. A le seda oro apejuwe lati ara oro-ise.  Apeere;

Oro Ise Oro apejuwe ti a seda

  1. ga giga
  2. le lile

iii. sun sisun

  1. fe fife
  2. ka kike

akiyesi:- A le se atenumo awon oro apejuwe wonyi ninu gbolohun.  Apeere;

(a)  Ere lile lile ni Bolu n se

(b)  Ibi giga giga ni mo n lo

  1. Oro apejuwe n se ise atenumo:-  A le gbe oro apejuwe yi saaju oro oruko to yan lati fi se atenumo.  Apeere;

(a) Omugo  omo ko dara

(b)  Agbere aya ko sun won

(d)  Ako okuta ni a fin pa ekuro

ORO-APONLE:-  Oro aponle maa n fi kon itumo oro-ise ki o le ye nisi.  Oro aponle maa n sise epon ninu gbolohun.

Isori oro Aponle:

(a) Oro-aponle pon-n-bele – Eyi ni oro aponle ti a ko seda.  Apeere;

(i)  Aso re mo toni

(ii)  Yemi pupa foo

(iii)  ile ga gogoro

(b) Oro aponle ti a seda:-  Eyi ni oro aponle ti a seda o maa n se ise apetunpe oro aponle pon-n-bele.  Apeere;

Oro aponle pon-n-bele oro aponle ti a seda

Toni tonitoni

Were werewere

Lau laulau

Rako rakorako abbl.

Ise oro aponle ninu gbolohun

  1. O maa n toka si isesi; Apeere

(a)  Olu yo kelekele wo ile

(b)  Omo naa n rin jauajau

  1. O maa n toka siohun kan ti a n se to ti de gongo (climax).  Apeere.

(a)  Oko naa jona raurau

(b)  Adupe je ounje naa patapata

(d)  Ile naa wo womuwomu

  1. O maa n toka ibi kan pato ti isele ti wa ye;  Apeere.

(a) Awon ologin sa pamo sinu igbo

(b)  Remileku se igbeyawo ni ile ijosin

(d)  Jolade lo ki kabiyesi ni aafin

  1. O n toka idi ti isele fi n se.  Apeere.

(a)  A n sise  kia a le lowo lowo

(b)  Sade ko kawe nitori ko lowo

(d)  Obi n to omo ki won le fun won ni isinmi abbl.

  1. A n lo oro aponle lati fi irisi nnkan han.  Apeere;

(a)  Osupa naa mole rokoso

(b)  Ina naa n wo rakorako

Igbelewon:

Ko ise oro apejuwe ati oro aponle mejimeji pelu apeere;

 

Ise Asetilewa: Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe kerindinlogun Eko ketala

Ede:- Onka ni ede Yoruba (ookan-lelogoorun-un de igba) 101-200

Onka Yoruba ni ona ti a n gba ka nnkan ni ona ti yoo rorun.

101 Ookanlelogorun-un

102 Ejilelogorun-un

103 Eetalelogorun-un

104 Eerinlelogorun-un

105 Aarundinlaadofa

106 Eerindinlaadofa

107 Eetadinlaadofa

108 Eejidinlaadofa

109 Ookandinlaadofa

110 Aadofa

111 Ookanlelaa-adofa

112 Eeejilelaa-adofa

113 Eetalelaa-adofa

114 Eerinlelaa-adofa

115 Aarundinlogofa

116 Eerindinlogofa

117 Eetadinlogofa

118 Eejidinlogofa

119 Ookandinlogofa

120 Ogofa

121 Ookanlelogofa

122 Eejilelogofa

123 Eetalelogofa

124 Eerinlelogofa

125 Aarundinlaa-adoje

126 Eerindinlaa-adoje

127 Eetadinlaa-adoje

128 Eejidinlaa-adoje

129 Ookandinlaa-adoje

130 Aadoje

131 Ookanlelaa-adoje

132 Eejilelaa-adoje

133 Eetalelaa-adoje

134 Eerinlelaa-adoje

135 Aarundinlogoje

136 Eerindinlogoje

137 Eetadinlogoje

138 Eejidinlogoje

139 Ookandinlogoje

140 Ogoje

141 Ookanlelegoje

142 Eejilelogoje

143 Eetalelogoje

144 Eerinlelogoje

145 Aarindinlaa-adojo

146 Eerindinlaaadojo

147 Eetadinlaa-adojo

148 Eejidinla-adojo

149 Ookandinlaa-adojo

150 Aadojo

151 Ookanleladojo

152 Eejilelaa adojo

153 Eetalelaa-adojo

154 Eerinlelaa-adojo

155 Aarindinlogojo

156 Eerindinlogojo

157 Eetadinlogojo

158 Eejidinlogojo

159 Ookandinlogojo

160 Ogojo

161 Ookanlelogojo

162 Eejilelogojo

163 Eetalelogojo

164 Eerinlelogojo

165 Aarindinlaa-adosan-an

166 Eerindinlaa-adosan-an

167 Eetadinlaa-adosan-an

168 Eejidinlaa-adosan-an

169 Ookandinlaa-adosan-an

170 Aadosan-an

171 Ookanlelaa-adosan-an

172 Eejilelaa-adosan-an

173 Eetalelaa-adosan-an

174 Eerinlelaa-adosan-an

175 Aarundinlogosan-an

176 Eerindinlogosa-an

178 Eejidinlogosan-an

179 Ookandinlogosan-an

180 Ogosan-an

181 Ookanlelogosan-an

182 Eejilelogosan-an

183 Eetalelogosan-an

184 Eerinlelogosan-an

185 Aarundinlaa-aadowa

186 Eerindinlaa-adowaa

187 Eetadinlaa-adowaa

188 Eejindinlaa-adowaa

190 Aadowa/igba-o-din-mewa

191 Ookanlelaa-adowa

192 Eejilelaa-adowa

193 Eetalelaa-adowa

194 Eerinlelaa-adowa

195 Aarundin-nigba

196 Eerindin-nigba

197 Eetadin-nigba

198 Eejidin-nigba

199 Ookandin-nigba

200 Igba

OONKALELAADOTA DE OGORUN-UN (51-100).

Igbelewon:-

(i) Kin ni onka?

(ii) Ka onka Yoruba lati ookanlelogoorun-un de igba.

 

Ise Asetilewa:- Yoruba akayege iwe Amusese fun ile eko sekondiri kekere iwe kin-in-ni lati owo o L. Orimogunje, K. Adebayo, F. Okiki. Oju iwe kewa Eko keje