Asa ikini ni ile yoruba

Date: Friday, 1st May, 2020.

Class: Pry six

Subject: Yoruba Studies

 

Akole: Asa ikini ni ile yoruba

Orisirisi ona ni awa yoruba ngba ki ara wa ninu asa ikini ati lati mo omo yoruba lawujo. Awon ona naa ni awon wonyii:

 

1.) ikini ni asiko

2.) ikini ni igba

3.) ikini si ipo ti aba wa tabi ohun tio ba sele sii eniyan

4.) ikini ni enu ise ati bi won se dahun

5.) kiki oba ati ijoye gege bi ipo won

 

1.) IKINI NI ASIKO:

Ni dede agogo meje owuro si agogo mokanla abo (11:30) ekaaro o pelu ido bale ati ikunle ni fun omokunrin ati omobinrin

Ni dede agogo mejila osan si agogo meta abo e kaasan o

Ni dede agogo merin irole si agogo mefa abo ni e ku irole o

Ni dede agogo meje ale si agogo mokanla abo e kaale o

Ni asiko ti aba fe sun o daaro ki olorun ji wa re o kamaa toju orun de iju iku oo layo ni a o ji o

 

2.) Bi ase nki onise owo ati bi won se nda wo lohun

 

Alaro:

Ikini- Areduo Areye o Amuabe o

idahun- olokun agbe o

 

Awako:

Ikini- oko aree foo

idahun- ogun a gbe o

 

Akope:

Ikini- igba aroo, emose o

idahun- amin o adupe o

 

Babalawo:

Ikini- aboruboye o baba

idahun- aboye bo sise ifa agbe ooo

 

Agbe:

ikini- aroko bodun deo

idahun- ami oo adupe o

 

Ode:

Ikini- ogun afo wo jono o

Idahun- arinpa nto ogun

 

Onidiri:

ikini- oju gbooro o

idahun- oya yao iyemoja a gbe oo

 

Alayo:

Ikini- moki ota moki ope

idahun- ota nje ope o gbodo foun

 

Alagbede:

Ikini- Aroye o, owu aroo

idahun- ogun a gbe o

 

Oni sowo:

Ikini- atajere o, aje awogba oo

idahun- amin adupe o

 

Review work:

 

Bawo ni awon yoruba se nki awon onise owo wonyii bawo sii ni won se dahun?

 

1.) Alaro:

Ikini: __________________________

Idahun: __________________________

 

2.) Onidiri:

Ikini: ________________________

Idahun: ______________________

 

3.) Babalawo:

Ikini: __________________________

Idahun: ________________________

 

4.) Ode :

Ikini: __________________________

Idahun: _________________________

 

5.) Alagbede :

Ikini: ____________________________

Idahun: __________________________

 

6 Alayo

Ikini:

Idahun:

 

 

Yoruba Primary 6 First Term Examinations

 

AWON OWE ILE YORUBA

 

FIRST TERM EXAMINATION PRIMARY 6 YORUBA LANGUAGE

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share

Add a Comment

Your email address will not be published. Required fields are marked *