JSS 2 THIRD TERM LESSON NOTE PLAN YORUBA

ILANA ISE FUN SAA KETA FUN OLODUN KEJI (JSS TWO)

OSE KIN-IN-NI: EDE: ATUNYEWEO ISE SAA KEJI

AROKO ALAPEJUWE/ONIROYIN

ASA: ATUNYEWO IWA OMOLUABI

LITIRESO: ATUNYEWO ISE SAA KEJI: EWI ALOHUN TO JE

MO ESIN IBILE BII; IJALA, IYERE IFA,

IWI EGUNGUN, abbl

OSE KEJI: EDE: LETA GBEFE

  • AWON WO NI A N KO O SI
  • AWON IGBESE INU LETA GBEFE
  • ORI ORO TO JE MO LETA GBEFE

ASA: IGBAGBO YORUBA NIPA OLODUMARE

LITIRESO: EWI ALOHUN TI A N FI ORO INU WON DA

WON MO

OSE KETA: EDE: APOLA ORUKO ATI ISE RE

ASA: IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA ORISA

LITIRESO: KIKA IWE LITIRESO APILEKO TI IJOBA YAN- EWI

OSE KERIN: EDE: APOLA ISE , ISE ATI IHUN RE

ASA: BI AWON AKONI EDA SE DI ORISA

LITIRESO: KIKA IWE LITIRESO TI IJOBA YAN

OSE KARUN-UN: EDE: ISEDA ORO ORUKO

  • NIPA LILO AFOMO IBERE
  • NIPA LILO AFOMO AARIM

ASA: ASA IKINI NI ILE YORUBA

LITIRESO: KIKA IWE TI IJOBA YA

OSE KEFA: EDE: ISEDA ORO ORUKO NIPA LILO APETUNPE

ASA: IGBAGBO YORUBA NIPA IYE LEYIN IKU

LITIRESO: EWI ALOHUN TI A FI ORO INU WON DA WON MO

OSE KEJE: EDE: LETA AIGBEFE

ASA : AWON OHUN MIMO NINU ESIN IBILE

EDE: ATUNYEWO AMI OHUN

OSE KEJO: EDE: AWE GBOLOHUN EDE YORUBA

LITIRESO: KIKA IWE EWI TI IJOBA YAN

OSE KESAN-AN: ASA: ASA ISINKUN NI ILE YORUBA

LITIRESO: KIKA IWE EWI TI IJOBA YAN

OSE KEWAA: EDE: IHUN APOLA APONLE ATI ISE TO N SE

NINU GBOLOHUN

ASA: OWE ILE YORUBA

LITIRESO: KIKA IWE EWI TI IJOBA YAN

OSE KOKANLA ATI IKEJILA: EDE: ATUNYEWO EKO LORI ISEDA ORO

ORUKO

ASA: ATUNYEWO ASA IKINI NI ILE YORUBA

LITIRESO: ATUPALE IWE EWI TI A KA

OSE KIN-IN-NI

EKA ISE: EDE

ORI ORO: AROKO ALAPEJUWE

Aroko je ohun ti a ro ti a si se akosile re .

Aroko asapejuwe ni aroko ti a fi n se apejuwe eniyan, nnkan tabi bi ayeye se ri

gan-an.

ILANA TO SE PATAKI FUN AROKO ALAPEJUWE

  1. Yiyan ori oro
  2. Sise arojinle ero lai fi kan bokan ninu
  3. Sise apejuwe ero leseese sin iwe ni ipin afo(paragraph) kookan

ORI ORO TO JE MO AROKO ALAPEJUWE

  1. Ile iwe mi
  2. Ounje ti mo feran
  3. Ijamba oko kan ti o sele loju mi abbl.

AROKO ASOTAN /ONIROYIN(NARATIVE ESSAY)

Aroko oniroyin ni arokko ti a fi n so nipa isele ti a fi oju war i tabi awon isele ti a gbo lenu enikan

ILANA FUN KIKO AROKO ONIROYIN

  1. Koko oro
  2. Ero: akekoo gbodo ni ero kan lokan nipa ori oro ti o fe soro le
  3. Eto: Agbekale aroko gbodo wan i sise-n-tele
  4. Ilo ede:Akekoo gbodo se amulo ilo ede bii; owe, akanlo ede, akoto, ifamisi ori oro, ati ona ede lorisirisi
  5. Igunle: eyi ni ipari aroko.awon akekoo yoo soro soki lori aero won nipa ori oro aroko ti won ko.

APEERE ORI ORO AROKO ASOTAN/ONIROYIN

  1. Ayeye ere onile-jile ti o koja ni ile iwe mi
  2. Ere boolu alafesegba kan ti mow o
  3. Ijamba oko kan ti o sele ni osodi
  4. Isomoloruko omo egbon mi obinrin

IGBELEWON:

  • Fun aroko ni oriki
  • Kin ni aroko asapejuwe ati asotan?
  • Salaye awon ilana fun kiko awon aroko wonyi
  • Ko ori oro to jemo aroko asotan ati ṣàpèjúwe [mediator_tech]

ISE ASETILEWA:

  • Ko aroko lori ayeye onile-jile ti o koja ni ile iwe re

ASA: IWA OMOLUABI

Omoluabi ni omo ti a bi ti a ko, ti o si gba eko rere.

Ise ati ise omoluabi bere lati inu ile ti a ti bi i

Die lara Ojuse omoluabi ni awujo

  • Iwa ikini
  • Ooto siso
  • Iwa irele
  • Iwa suuru
  • Bibowo ati iteriba fun agba
  • Iwa igbonran

Pataki iwa omoluabi

  • O maa n fi iru eni ti eniyan je han nitori eefin ni iwa
  • O maa n buyi kun ni
  • O maa n je ki a ma iru idile ti eniyan ti wa
  • O n je ki eniyan tojo

IGBELEWON:

  • Fun iwa omoluabi loriki
  • Ko iwa omoluabi marun-un
  • Salaye Pataki iwa omoluabi ni ile Yoruba

ISE ASETILEWA:

  • Salaye iwa omoluabi meji pelu apeere

LITIRESO: AWON EWI ALOHUN AJEMO ESIN IBILE ATI ORISA TI A N LO WON FUN:

 

Ewi Orisa

  1. Esa-pipe egungun
  2. Esu-pipe esu
  3. Sango-pipe sango
  4. Oya-pipe oya
  5. Ijala sisun ogun
  6. Iyere-ifa orunmila
  7. Orin arungbe oro

IGBELEWON:

  • Ko orisa ile Yoruba ati esin to room okookan won

ISE ASETILEWA:

Orisa wo lo romo awon esin wonyi:

  • Esa-pipe
  • Orin arungbe
  • Iyere-ifa

 

OSE KEJI

EKA ISE : EDE

ORI ORO : LETA KIKO

Leta kiko je ona ti a n gba gbe ero okan wa kale ni ori pepa ranse si elomiiran.

ISORI LETA

  • Leta gbefe
  • Leta aigbefe

LETA GBEFE

Leta gbefe ni leta ti a maa n ko si eni ti o sunmo wa; o le je molebi, ore, tabi alajose.

Leta gbefe fi aaye gba eniyan lati fi ero inu re han elomiiran. O le je baba, iya , egbo, aburo, ore ati ojulumo eni gbogbo.

Igbese kiko leta gbefe

  1. Adiresi akoleta : Apa otun ni oke tente ni adireesi akoleta maa n wa. Nonba ojule, opopona tabi apoti ile ifiwe ranse si (p.o. Box) , oruko ilu ati ipinle eni ti a n ko leta si ni yoo wa ninu adireesi yii.
  2. Deeti : ojo, osu, ati odun ti akoleta n kowe re yoo wa ninu adireesi yii.
  3. Ikini ibere : apa osin ni ibere ila ti o tele deeti ni a n ko eyi si pelu ami idanuduro die ni ipari re.
  4. Koko leta : eredi ti akoleta fi n ko leta re ni yoo so di mimo ninu ipin afo yii.
  5. Ipari/ikadi leta : owo otun ni akoleta yoo sun owo si ni ori pepa, oruko akoleta nikan ni yoo han ni opin leta yii pelu ami idanuduro die

Ori oro to je mo leta gbefe:

  • Ko Leta si baba re lati bere owo ile iwe saa keta ninu eto eko re ki awon alase ile iwe ma aba le o jade lenu ise.
  • Ko leta si ore re ti o wa ni ilu oba lati ran an leti ayeye ojo ibi re ti o n bo ninu osu kewaa odun yii
  • Ko leta si egbon re obinrin lati ki I fun ipalemo eto igbeyawo re to n bo lona ninu osu kefa, ojo kerinla odun ti a wa ninu re yii abbl

IGBELEWON:

  • Kin ni leta kiko?
  • Daruko ona meji ti a le pin leta kiko ede Yoruba si
  • Salaye awon ona ti a n gba lati ko leta gbefe

ISE ASETILEWA:

Ko leta si ore re kan ti o wa ni ilu odi keji lati wa si ayeye igbeyawo egbon re obinrin ti o n bo ni ojo karun-un osu keje odun ti a wa ninu re yii.

EKA ISE : ASA

ORI ORO : IGBAGBO YORUBA NIPA OLODUMARE

Aimokan-mokan lo mu ki awon oyinbo alawo funfun maa so pe Yoruba ko mo Olorun ati pe won ko tile gba pe Olorun wa, ohun ti a le fi owo re soya ni pe ki awon elesin kiritieni ati musulumi to mu esin ajeji won de aarin awon Yoruba ni won ti gbagbo pe eni kan n be to n je Olodumare ati pe oniruuru oruko ni won n pe Olodumare yii lati fi igbagbo won mule pe O n be.

Ba kan naa, Yoruba pe Olodumare wa nibi gbogbo;idi niyi ti won fi maa m so pe “Amookun-jale bi oba aye ko ri o,torun n wo o “

ONIRUURU ORUKO TI YORUBA N PE OLODUMARE

  1. Alaaanu ati oloore : eni to maa n se aanu fun gbogbo eniyan bakan naa ni o kun fun oore(o maa n soore kiri ni)
  2. Okan soso ajanaku to n migb kiji kiji : ajanaku je eranko to rinle to si tobi ju ninu igbo. O je oba fun awon eranko.Yoruba fi Olodumare we eranko yii lati f titobi re ati pe nibi kibi ti Olodumare ba wa gbogbo eniyan maa n ni imolara pe o wa nibe.bakan naa won gbagbo pe ko si ohun ti ko le e se
  3. Olu-orun, Olugbala : eni to ni orun, eni ti o n gba ni ninu isoro
  4. Eledaa Adedaa : oun ni o da gbogbo eda patapata. Olodumare je eni to n se eda nnkan yala eniyan , eranko tabi ohun ailai-lemi gbogbo
  5. Onidajo ododo : ko ki I segbe leyin enikeni.olotito ni, ki I gbe ebi fun alare bee ni ki I gbe are fun elebi
  6. Oba awon oba :olodumare je oba fun gbogbo awon Oba aye
  7. Olupese : oun lo n pese fun gbogbo eda laye.bakan naa, o n pese fun eye oju orun ati gbogbo eda miiran

Ni kukuru, awon Yoruba Gbagbo pe Olodumare wa ati pe o ni gbogbo nnkan lodu-lodu ni ikawo re,ko si eni ti a le fi we rara.

IGBELEWON:

  • Salaye igbagbo Yoruba nipa Olodumare
  • Daruko oniruuru oruko ti Yoruba n pe Olodumare
  • So itunmo okookan irufe oruko bee

ISE ASETILEWA:

  • N je looto nipe awon Yoruba ti ni igbagbo nipa Olodumare? Salaye oruko maru-un ti o fi igbagbo Yoruba mule nipa Olodumare

EKA ISE: LITIRESO

ORI ORO: EWI ALOHUN TI A FI ORO INU WON DA WON MO

Litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan tabi omiiran ti a fi ohun enu gbe jade tabi ti a se akosile re

Isori litireso

  • Litireso alohun(atenudenu)
  • Litireso apileko(alakosile)
  • Litireso alohun : litireso alohun ni awon ewi Yoruba ti a jogun lati enu awon baba nla wa

O je ewi ti awon babanla wa ti n lo lati igba iwase ki awon oyinbo alawo funfun to mu esin ajeji ati ogbon mo-on-ko- mo-on-ka wo ile wa

Awon esin ibile Yoruba ni wonyi;

  • Oya-pipe
  • Sango-pipe
  • Esu-pipe
  • Orin arungbe
  • Iyere- ifa
  • Ijala abbl

Bi a se le da awon esin ibile wonyi mo

  • Oya-pipe : akoko odun oya ni won maa pe oya. Awon olusin re ni a n pe ni “ iya oya” .oro inu ewi won maa n da lori ife oko

Ounje fun irubo: amala ati obe ilasapelu ewure

Eewo orisa : agbo tabi irun ori re ko gbodo de ojubo oya

  • Esu-pipe : Esu je iranse ati olopa okunkun fun Olodumare. Awon olubo re ni a n pe ni “Eleesu” akoko odun esu ni awon olusin re maa n pe, awon obinrin ni o wopo ninu awon aworo re

Ounje fun irubo : epo , ebo

Eewo esu : adi ati obi

  • Orin Arungbe : a tun le pe e ni orin oro. Awon oloro ni won maa n ko orin yii ni akoko odun re. won maa n fi orin naa bu oniwa ibaje lati le dekun iwa ibaje ati lati fi tu asiri ohun ikoko awon onise ibi ti won ro pe eniyan ko mo

Ounje fun irubo : efo ekuya, asaro, obuko, adiye, iyan ati obe egusi.

Eewo oro : a) obinrin ko gbodo ri oro

b) A ki I ri ajeku oro [mediator_tech]

IGBELEWON:

  • Kin ni litireso?
  • Ona meloo ni a pin litireso Yoruba si?
  • Fun litireso alohun loriki
  • Daruko esin ibile meta ni ile Yoruba ati bi a se le da won mo

ISE ASETILEWA:

  • Awon wo ni olusin ijala ati sango?salaye salaye won ni soki

 

OSE KETA

EKA ISE : EDE

ORI ORO : APOLA ORO-ORUKO ATI ISE RE

Apola je apa kan gbolohun,eyi ti o le je eyo oro tabi akojopo oro. Apeere;

  1. olumide ra oko ( eyo oro )
  2. ijoba ipinle Ekiti san owo osu awon osise ( akojopo oro )
  • Apola – oruko : Eyi ni eyo oro oruko kan tabi apapo oro oruko meji tabi ju bee lo ninu gbolohun. Apeere;
  1. Ige ra bata
  2. Igi wo
  3. Ade omo oba se igbeyawo
  4. Olumide Bakari gba ipo kin in ni
  5. Alani Aduke ile oloye se isile abbl

Ise ti Apola oruko n se ninu gbolohun

  1. O n sise Oluwa gbolohun : eyi ni eni ti o se nnkan ninu gbolohun, o le je oro oruko kan soso tabi eyi ti o je apapo oro oruko. Apeere;
  • Kolawole gba oye abobaku
  • Adufe koi le
  • Fijabi ta ile
  1. Apola oro oruko maa n sise abo : eyi ni olufaragba nnkan ti oluwa se ninu gbolohun. O le wa ni aarin tabi ipari gbolohun. Apeere;
  • Baba agba ra oko tuntun
  • Remi mu omi
  • Bolaji pa eye owiwi
  1. Apola oro oruko tun n sise eyan : nigba ti oro oruko meji ba tele ara ninu gbolhun, eyan ni oro oruko keji .eyi le jeyo ni aarin tabi ipari gbolohun. Apeere;
  • Ounje Jumoke ni mo fe je
  • Awa egbe ode ilu niyi
  • Ile oba oyingbo ni mo n lo
  • Okunrin oloro naa ti ku
  • Oluko na Anike Olowonifaari

IGBELEWON:

  • kin ni apola?
  • Fun apola oro oruko ni oriki
  • Salaye Pataki apola oro oruko ninu gbolohun.

ISE ASETILEWA:

Toka ise ti apola oruko kookan ti a fa ila si nidi n se ninu gbolohunisale yii;

  • Timileyin je oye
  • Jide Animasahun Agbejoro je ipe oluwa.
  • Yemi pa odu oya
  • Okunrin oloro ra oko tuntun
  • Oluko na olumide Arowolo

 

EKA ISE : ASA

ORI ORO : IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA ORISA

Awon orisa ile Yoruba je asoju , alarinna , alagata, alagbawi ati iranse fun Olodumare.

Yoruba Gbagbo wi pe okanlenirinwo (401) ni awon orisa ni ile Yoruba ati pe a le pin won si ona meji Pataki. Awon niyi ;

  • Awon orisa ti Olodumare ran wa si ile aye : awon orisa wonyii kii se eniyan rara, orisa ni Olodumare da won ati orun ni won si ti row a si ile aye. Apeere iru awon orisa bee ni; Ogun , Obatala , Orunmila , Esu ,
  • Awon orisa ti awon eda eniyan so di orisa leyin iku won nitori ise ribiribi ti won se nigba ti won wa laye. Apeere eyi ni ; Yemoja , Sango , Oya, Osun, Orisa oko, Moremi abbl.
  • Igbagbo ati ero Yoruba nipa Obatala (Orisa-nla)

Yoruba Gbagbo pe obatala ni asaaju gbogbo awon orisa patapata. Won si Gbagbo pe oun ni Olodumare koko seda o si je igbakeji Olodumare ninu ise iseda. Yoruba Gbagbo pe Obatala yii ni o sise iseda mimo oju, imu , eti, ati awon eya ara miiran nigba ti Eleda ba ti seda eniyan ni borogidi tan. Idi niyi ti awon Yoruba fi n pe obatala ni “ Ajala Alamo ti I mo ori “ tabi “ Alamo rere “ . igbagbo won si ni pe ise owo Obatala ni awon abuke, Aro, Afin, Afoju, Amukun-un. Idi niyi ti won fi n pe won ni “Eni Orisa”. [mediator_tech]

Eewo awon olusin Obatala: emu, ounje elepo,iyo, aja,elede tabi mu omi ikasi(omi ti won ti pon sile ti ki I se oojo)

Ounje obatala : obe eran igbin,obi ati otika( oti oka baba)

Ohun elo Obatala : ileke funfun, sese funfun, bata funfun, aso funfun, igba funfun, abbl. Gbogbo ohun elo Obatala funfun ni.

  • Igbagbo ati ero Yoruba nipa sango

Sango ni Yoruba n pe ni “Olufinran”. Won Gbagbo pe o ni oogun,igboya ati agbara lori ojo,ara ati monamona. O si je eniyan lile. Bi o ba n soro, ina maa n jade ni enu re. oruko awon iyawo re ni; oya,Osun ati oba. Sango da ija sile laaarin ijoye ilu meji nigba ti o si ri I wi pe asiri oun fe tu ati pea pa oun ko ka mo ni o fi ori oye sile ti o si binu pokunso.

Ounje Sango : amala, pelu obe ewedu,eran agbo,orogbo ati obi

Ilu Sango : ilu batas

Ohun idamo awon olusin re ; Irun ori didi t’okunrin ati t’obinrin

  • Igbagbo ati ero Yoruba nipa Orunmila

Orisa yii je eni ti Olodumare fun ni ogbon ati oye lati fi tun ile aye se. idi niyi ti won fi maa n ki I ni “Akere-finu-sogbon”. bakan naa won a maa pe e ni “ Elerii-ipin” nitori won Gbagbo pe o wa lodo Olodumare nigba ti o n se ipin eda. Awon Yoruba a si maa bere ohun kohun ti won ba fe lowo re nitori ogbon ti Olodumare fun un. Bakan naa, won gbagbo pe “Agbaye- gborun “ ni ,o binu fi ile aye sile osi fi ekuro ‘Ikin merindinlogun” ropo ara re ni ile aye. Ekuro yii ni awon babalawo n lo lati difa titi di oni olonii.

Ohun elo ifa : opon ifa, iyerosun,opele,ikin merindinlogun(16),irukere,awo ifa, abbl

Ohun elo ibo re : eku meji, eja meji,igbin,ewure,adiye,isu,aguntan,obi abbl.

IGBELEWON:

  • Salaye isori awon orisa ile Yoruba
  • Salaye igbagbo Yoruba nipa orunmila, Obatala ati sango

ISE ASETILEWA:

  • Bawo ni a se le sapejuwe awon orisa ile Yoruba
  • Fi igbagbo Yoruba han pe eniyan ni sango nigba kan ri nigba aye re.

EKA ISE : LITIRESO

ORI ORO : KIKA IWE LITIRESO APILEKO TI IJOBA YAN(EWI)

OSE KARUN-UN

EKA ISE: ASA

ORI ORO : ISEDA ORO ORUKO(NOMINALIZATION)

Iseda oro oruko naa ni isodoruko.

Oro oruko ni awon oro ti o le da duro ni ipo oluwa,abo tabi eyan ninu gbolohun.

Isodoruko ni ona ti a n gba seda oro ti ayorisi oro bee yoo je oro tuntun.

Orisi ona ti a le gba seda oro oruko

  • Nipa lilo afomo ibere(prefix)
  • Nipa lilo afomo aarin (infix)
  • Nipa sise apetunpe (reduplication)

Iseda oro oruko nipa lilo afomo ibere ati afomo aarin

  • Nipa lilo afomo ibere(prefix) : eyi ni kikan afomo ibere po mo oro ise tabi oro oruko. Apeere,
  • a + lo = alo
  • a + de = ada
  • i +jo = ijo
  • ai + lo =ailo
  • ai + san = aisan abbl
  • Nipa lilo afomo aarin (infix) : eyi maa n jeyo laaarin oro oruko meji. Apeere;
  • ore + si + ore = oresore
  • igba + de + igba = igbadigba
  • iso + ku + iso = isokuso
  • emi + ri +emi = emiremi
  • iran + de + Iran = irandiran
  • igba +ku +igba = igbakigba

IGBELEWON:

  • Fun oro oruko loriki
  • kin ni iseda oro oruko?
  • Salaye pelu apeere awon ona ti a n gba seda oro oruko ni ile Yoruba

ISE ASETILEWA:

Bawo ni a se seda awon oro oruko wonyi;

  • Onidajo
  • Igboya
  • Ogboogba
  • Jobijobi
  • bamgboye

EKA ISE : ASA

ORI ORO : ASA IKINI NI ILE YORUBA

Asa ikini je okan lara iwa omoluwabi; o je iwa ti a gbodo ba lowo omo ti a bi ti o gba eko rere.

Asa ikini se Pataki laaarin Yoruba idi niyi ti won fi n pe won ni “iran Aku” ati “omo-kaaaro-o-o-jiire”

Dandan ni fun omokunrin ati omobinrin ti a ko ni lati ile ire ki won ki awon obi ati gbogbo eni to ju ni lo nipa di dobale ati lilo lorikun mejeeji ni owuro ati ni gbogbo igba.

Ikini oniruuru ni ile Yoruba

Akoko Ikini Idahun

  • Ni owuro E kaaaro/se alaafia ni a ji? A dupe
  • Ni osan E kaasan O o
  • Ni irole E kurole O o
  • Ni ale E kale O o
  • Akoko ojo E ku ojo O o
  • Akoko oye E ku oye O o
  • Awon alaboyun Asokale anfaani O o
  • Awon o n tayo Mo kota mo kope Ota n je, ope

Ko gbodo fohun

  • Agbe Aroko bodunde Ase
  • Onidiri Ojugbooro E ku ewa Iyemoja a gbe o

Tabi ooya aya o

  • Iya olomo tuntun E ku owo lomi O o

IGBELEWON:

  • Fun asa ikini loriki
  • N je loooto ni awon Yoruba n fi iwa omoluabi han nipa asa ikini?

ISE ASETILEWA:

Bawo ni a se n ki awon wonyi ni ile Yoruba:

  • Akope
  • Ontaja
  • alaboyun

EKA ISE : LITIRESO

ORI ORO : KIKA IWE EWI TI IJOBA YAN

 

OSE KEFA

EKA ISE: EDE

ORI ORO: ISEDA ORO ORUKO NIPA LILO APETUNPE

  • A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe apola oro ise (Reduplication of verbs) : apeere;
  1. Gbomo + gbomo = gbomogbomo
  2. Jagun + jagun = jagunjagun
  3. Daran + daran = darandaran
  4. Peja + peja = pejapeja
  • A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe oro oruko (Reduplication of noun). Apeere;
  1. Ale + ale = Alaale
  2. Agba + agba = Agbaagba
  3. Omo + omo = Omoomo
  • A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe elebe (partial reduplication) : Eyi ni ki a fi faweli ‘I’ ti o je mofiimu olohun oke po mo konsonanti akoko ti o bere oro ise, ki a tun fi odidi oro ise ipinle bee kun-un. Apeere;
  1. Je – j + i = Jije
  2. Fe – f + I = Fife
  3. Ra – r + i = Rira
  4. Ta – t + i = Tita

IGBELEWON:

  • Fun isodoruko ni oriki
  • Seda oro oruko marun-un nipa lilo apetunpe

ISE ASETILEWA:

  • Seda oro oruko mewaa nipa lilo apetunpe

EKA ISE : ASA

ORI ORO: IGBAGBO YORUBA NIPA IYE LEYIN IKU

Yoruba Gbagbo pe “Awaye iku kan ko si, orun nikan ni aare-mabo”. Ohun ti eyi tunmo si nip e gbogbo eda ni o ti dagbada iku, ko si eni ti ko ni ku; olowo n ku, talaka n ku, oba ilu n ku, ijoye n ku, omode n ku, agbalagba n ku.

Yoruba Gbagbo pupo ninu iye leyin iku idi niyi ti eniyan ba ku ni ile Yoruba, dandan ni ki won se awon etutu kan bii; oku wiwe,, fifa irun ori oku okunrin, didi irun ori oku obinrin, wiwo aso ti o dara fun oku, fifi lofinda olooorun kun oku lara. Oniruuru ohun tie nu n je ni won yoo sin pelu oku ki o leri nnkan je ninu irin ajo re.

Ni kukuru, awon Yoruba Gbagbo pe gbogbo ohun ti awon n se ni oku n ri ati pe gbogbo oro ti awon n so ni o n teti si pelu.

IGBAGBO YORUBA NIPA IYE LEYIN IKU BI O SE JEYO NINU ASA YORUBA – AKUDAAYA, ISOMOLORUKO ATI ISINKU.

  • AKUDAAYA: Awon akudaaya ni Yoruba Gbagbo pe won ku ki ojo won to pe, ti won ki I le lo si oorun taara.

Yoruba Gbagbo pea won ti o ku lai pe ojo yoo maa lo gbe ni ilu miiran ti a ko ti I mo won ri ati pe bi won ba ri enikeni ti won mo nigba aye won ki won to ku, won yoo fi iru ilu naa sile lo ilu miiran. Pupo awon ti won fi ojo olojo lo yii ni awon eniyan ti se alabapade ni ilu miiran gege bi I eri.

  • ISOMOLORUKO : oniruuru oruko amutorunwa ni ile Yoruba ti fi iye leyin iku han. Bi baba agba ni idile oko ba papoda ti okan lara awon iyawo omo re ba bimo ni iru akoko bee ti omo naa si je okunrin, igbagbo Yoruba nipe baba agba ti o ku yii ni o tun pada wa saye ninu ebi won. Iru awon omo bee ni a n so ni ; babatunde, Babajide, Babarinde, abbl. Bi o ba si je iya agba ni idile oko ni o papoda igbagbo Yoruba nip e iya agba ti o ku ni o tun pada wa.

Won a so iru omobinrin bee ni; Iyabode, Iyejide, Yewand, Yetunde abbl.Bi irisi awon omo yii ba siba ti awon baba agba ati iya agba mu won a ma ape won ni “Baba agba ati Iya agba.

  • ISINKU: Yoruba Gbagbo pe irin ajo ni oku n rin lo si orun ati pe gbogbo oro ti awon ba n so si iru oku bee ni o n gbo. Orisirisi dukia bii; aso, owo, ileke, oti, ounje lorisirisi ni awon Yoruba maa n ko sinu posi oku lati le ri nnkan lo ninu irin ajo naa. Itoju oku bii; fifa irun ori oku okunrin, didi irun ori oku obinrin, fifi lofinda olooorun didun kun oku lara ni awon Yoruba maa n se nitori won Gbagbo pe iye n be leyin iku. Ba kan naa, won kii je ki ounje tan ninu ile won nitori igbagbo won nipe oku si le pada wa ile lati wa wo awon omo re ki o si le ri ounje je nigba ti o ba wa.

IGBELEWON:

  • N je Yoruba Gbagbo pe iye wa leyin iku?
  • Salaye igbagbo Yoruba nipa iye leyin iku bi o se jeyo ninu; asa isomoloruko,asa isinku ati akudaaya.

ISE ASETILEWA:

  • N je Yoruba gbagbo pe iye wa leyin iku? Ko oruko Yoruba marun-un ti o fi eyi han.

EKA ISE: LITIRESO

ORI ORO: EWI ALOHUN TI A FI ORO INU WON DA WON MO

Ewi alohun ni awon ewi ti a jogun lati enu awon baba nla wa.

O je okan lara litireso ti awon baba nla wa maa n lo lati iwase.

Agbara ti o ya ni lenu ati imo ijinle n be lowo awon Yoruba , idi niyi ti a fi n pe won lolopolo pipe ati alarojinle eda.

Apeere awon ewi alohun ti o fi idi otito mule pea won Yoruba je alarojinle ati olopolo pipe niyi;

OFO

Ofo fe oro ti a n so tabi fo jade ti a fi n segbe leyin oogon tabi ti a n pe lati mu ero okan wa se.

Lara awon oro ti a fi le da ofo mo niyi ;

  • Oruko awon emi airi ti a n pe
  • Awitunwi awon oro ninu ofo

Apeere ofo awure;

“ Itun lo ni ke e fohun rere tun mi se

Ifa lo ni ke e e fohun rere fa mi

Abeere lo ni ke e fohun rere beere mi

Tigi tope ni i saanu afomo

Omo araye e maa saanu emi lagbaja

Omo lagbaja loni o “

Itumo ofo yii ni pe, nibi ki bi ti o ba n de ki awon eniyan maa fi ohun rere le e lowo

Apeere miiran;

“ A-toju-maaro loruko aa peku

A-tagbon-muje loruko aa paarun

A-pantete-ori-rin-lojuto loruko aa pasasi

Adia femi omo iya aje

Won ni ki n maa lo ko sewu

A-toju-maaro ti iku n je ko ni jeku pami

A-tagbon-muje tarun n je ko ni jarun gbemi de

A-pantete-ori-rin ko ni je kasasi mu mi

O di to ! “

 

AYAJO

Omo iya ofo ni ayajo sugbon inu ese ifa ni oun ti maa n je jade. Oro enu lasan ni ko nilo oogun rara.

Apeere ayajo ti a fi n da inu rerun duro;

“ O-dorita-meta pete isale

O-dorita-meta pero orun oyela

Eyin le yo Olugbon asiri

Ti Oduduwa pa enu re mo

A-ka-woroko-ori-idodo

A-na-le-ori-iwo

Ojo lo de lo mu aganna alaganna gun

Kuro ninu aganna

Ki o wa ibomiiran lo”

OGEDE:

Ohun enu bii ti ayajo ni ogede sugbon ohun enu ti o ni agbara ju ohun enu lo ni. Enikeni ti o ba fe pe ogede gbodo ni ohun ti yoo koko se tabi je gege bii ero ki o to le pe e rara bee ni o gbodo ni ohun ti yoo sare je tabi to la ti o ba tip e e tan ki inira ma ba de ba a. eni ti yoo gbo ogede naa gbodo lo ero tabi ki eni ti yoo pe ogede ti se ohun ti ko ni je ki o se onitoun ba kan.

IGBELEWON:

  • Kin ni ewi alohun?
  • Salaye awon ewi alohun ti o je orisun ironu, agbara ati imo ijinle awon Yoruba. [mediator_tech]

ISE ASETILEWA:

  • N je ori oro to jo mo ofo ati ayajo wa ninu bibeli bi?

OSE KEJE

EKA ISE: EDE

ORI ORO: LETA AIGBEFE

Leta kiko je ona ti a n gba gbe ero okan wa kale ni ori pepa ranse si elomiiran.

Leta aigbefe nil eta ti a n ko si awon eniyan ti o wa ni ipo giga kan tabi ipo ase.

Awon wonyi le je oga ile iwe, olootu iwe iroyin, Giwa ile ise oba, Alaga igbimo eto ijoba , akowe agba ile ise, abbl.

Igbese kiko leta aigbefe

  • Adireesi : Adireesi meji nil eta yii maa n ni,adireesi akoleta ni apa otun loke tente ati adireesi agbaleta ni apa osin iwe ni ibere ila ti o tele adireesi akoleta.
  • Ikini ibeere : eyi ni lati fi mo eni ti a n ko leta si bii; “oloootu ile ise iwe iroyin”
  • Ori oro : eyi ni ori oro lete ti a n ko.
  • Koko leta : Alaye lekun rere lori ohun ti lete naa dale lori leseese ni ipin afo kookan. Leta aigbefe ko fi aaye gba efe tabi awada sise,eredi ti akoleta fi n ko leta re ni yoo so di mimo fun agbaleta.
  • Ikini ipari : fifi ifara eni jin si eni ti a n ko leta si tabi si ise eni ni a oo so di mimo (tiyin ni tooto ) ni ipin afo yii,leyin eyi ni ifamisi oruko akoleta ati oruko re ni kikun (full name) yoo wa ni abe re.
  • Apo iwe : odi keji apo iwe nibi ti goomu wa ni adireesi akoleta yoo wa,sitanbu yoo wa ni oju apo iwe ni apa otun loke tente, adireesi agbaleta yoo wa ni isale sitanbu yii.

Ori oro to je mo aroko aigbefe

  • Ko leta si oloootu ile ise iwe irioyin ‘AIT’ lati fi edun okan re han ijoba nipa ini lara ti o de ba ara ilu nipa owon gogo epo robi ni ipinle re.
  • Ko leta si Alaga ibile re lati mo riri ise takuntakun ti won n se lowolowo ni opopona marose ijoba ni Abule-egba ni ipinle eko.
  • Ko leta si oga ile eko re lati fi imoriri re han nipa atunse ti o de ba ayika ile iwe re ni saa yii.
  • Ko leta si olootu iwe iroyin Akede Oodua lati wa wo ere boolu oloree-soore ni ile iwe re ni ojo isegun, ose to n bo.

IGBELEWON:

  • Kin ni leta aigbefe?
  • Ko awon igbese ti a ni lati tele bi a ba n ko leta aigbefe
  • Ko ori oro to jo mo leta aigbefe meta

ISE ASETILEWA:

  • Ko leta si oloootu ile ise iwe irioyin ‘AIT’ lati fi edun okan re han ijoba nipa ini lara ti o de ba ara ilu nipa owon gogo epo robi ni ipinle re.

EKA ISE: LITIRESO

ORI ORO: AWON OHUN MIMO NINU ESIN IBILE

Esin ibile ni awon esin abalaye ti a jogun lati owo awon baba-nla-wa.

Yoruba Gbagbo pe Olodumare je mimo bee ni awon orisa re, Ile awon orisa ile Yoruba je mimo, awon ohun elo won bakan naa si je mimo.

Awon elo awon orisa ile Yoruba niyi ;

  • Ere orisa
  • Aso ala orisa
  • Ikoko omi orisa funfun
  • Sese efun
  • Igba funfun
  • Igi orisa funfun
  • Ebo orisa funfun
  • Agbada ati ada orisa funfun
  • Ileke funfun abbl.

Siwaju si I, mimo ni awon orisa ile Yoruba wonyi; Obatala, Orisa oko, Osun, Olokun, Obalufon abbl. Mimo ni awon eni orisa bii; abuke, afin, arara, aro, iya olorisa abbl, nitori pe Yoruba Gbagbo pe Obatala ni o seda won bee.

Mimo ni ‘omi ajifowuro’ pon nitori owuro kutukutu ni awon aworo Obatala n jip on omi naa fun iwosan ati fun mimu awon olusin re. Won Gbagbo ninu omi yii pe o dara fun alaboyun lati bi were, o dara fun iwure, o dara fun iwosan loniruuru.

Ojubo orisa je ibi owo, eewo ni fun aworo obinrin ti o n se nnkan osu lati de ibi ojubo orisa. Inu igbo kijikiji leyin odi ilu, inu ile, orita meta ni ojubo orisa maa n saba wa. Mariwo tabi aso funfun ni awon aworo orisa yoo ta si oju ona ojubo bee ni won yoo kun ara ogiri ni efun gege bii ami ohun mimo.

IGBELEWON:

  • Fun esin ibile loriki
  • Salaye awon ona tie sin ibile n gba fi ohun mimo han
  • Daruko ami idamo awon elesin ibile meta ti o je mimo
  • Daruko ibi meta ti awon elesin ibile n lo gege bi I ojubo.

ISE ASETILEWA:

  • Daruko ohun idamo obatala merin ti o je mimo.

OSE KEJO

EKA ISE : EDE

ORI ORO : AMI OHUN

Ami ohun je ami iyato laaarin iro kan si iro keji ninu ede Yoruba.

Iro ohun meta ni o se Pataki ninu ede Yoruba. Awon niyi;

  • Iro ohun oke / ( m )
  • Iro ohun aarin _ ( r )
  • Iro ohun isale \ ( d )

Apeere ami ohun lori oro Yoruba

  • Ta – to sell ( d )
  • Gbe – carry ( m )
  • Sun – sleep ( d )
  • Mu – drink (r )
  • Fe – love ( m )
  • Je – eat ( r ) abbl

IGBELEWON:

  • Kin ni ami ohun?
  • Ona meloo ni o se Pataki ti ale pin ami ohun Yoruba si
  • ko oro onisilebu meji ki o si fi ami ohun ti o ye si lori.

ISE ASETILEWA:

  • ko oro onisilebu meji ki o si fi ami ohun ti o ye si lori. Ko o kere tan mewaa

EKA ISE : LITIRESO

ORI ORO : KIKA IWE EWI TI IJOBA YAN

OSE KESAN-AN

EKA ISE: EDE

ORI ORO: AWE GBOLOHUN EDE YORUBA

Gbolohun onibo ni gbolohun ti a fi gbolohun miiran bo inu re.

Awe gbolohun Ede Yoruba ni gbolohun onibo. A pin gbolohun yii si ona meji, awon niyi;

  • Olori awe gbolohun
  • Awe gbolohun afibo/afarahe
  • Olori awe gbolohun : eyi ni awon gbolohun ti o le duro bii odindin gbolohun,o le da duro ki o ni itumo ti o peye. Apeere;
  • Ile naa dun-un wo
  • Omo naa yoo dake
  • Awon ole poora
  • Ebi alayo abbl.
  • Awe gbolohun afibo : gbolohun yii je eyi ti ko le da duro ki o ni itumo ti o peye. Apeere;
  • ……………….. bi o ba de
  • …………………pe o gbo
  • ………………..ti mob a dolowo
  • ………………..ki n to lo.

Ninu apeere oke yii, awe gbolohun afibo ko ni itumo, oro abo ni ti o ni lo olori gbolohun fun itumo kikun. Bi apeere;

  • Wa ri mi (olori awe gbolohun) bi o ba de ( awe gbolohun afarahe)
  • O ya mi lenu ( olori awe gbolohun ) pe o gbo ( awe gbolohun afarahe )
  • Ma ra oko fun baba mi (olori awe gbolohun ) ti mo ba dolowo ( awe gbolohun afarahe )
  • Ma a ri o (olori awe gbolohun) ki n to lo ( awe gbolohun afarahe ) abbl.

IGBELEWON:

  • Fun gbolohun onibo ni oriki
  • Ko ona meji ti a le pin gbolohun onibo si ki o si salaye pelu apeere

ISE ASETILEWA:

  • Pelu apeere ti o dangajia salaye ona meji ti a pin gbolohun ede Yoruba si

EKA ISE : ASA

ORI ORO : ASA ISINKU NI ILE YORUBA

Isinku ni eye ikeyin ti a se fun oku logan ti o ku titi di akoko ti a fi sin-in

Yoruba Gbagbo pe “eni sinku lo pale oku mo, eni sukun, ariwo lasan lo pa “

Igbese isinku ni ile Yoruba

  1. Itufo : eyi ni kikede iku oloogbe fun awon ebi ,ana ati gbogbo eniyan. Ilu liu, ariwo, ekun sisun, ibon yinyin ni a fi n tufo oku.
  2. Ile oku gbigbe : awon ana tabi omo okunrin ile oku ni yoo gbe ile iwon ese mefa lati sin oku
  3. Oku wiwe : won ni lati fa irun ori oku ti o ba je okunrin, won a si di irun ori oku ti o ba je obinrin. Gbogbo eekanna owo ati ese oku ni won yoo ge leyin naa ni won yoo fi ose ati kanin-kain pelu omi to loworo we e. leyin eyi ni won yoo wo aso to dara fun oku.
  4. Oku tite : inu yara tabi odede ti won se losoo ni won n te oku si ni ori ibusun pelu aso funfun ati lofinda olooorun bee ni won yoo fi owu di iho imu ati eti re mejeeji. Ni asiko yii, awon obinrin ile yoo maa ki I ni mesa-an mewaa.
  5. Alejo sise : Awon omo ati ebi oku yoo peae jije ati mimu fun awon okunrin ile, awon ana ti o gbele oku ati gbogbo alejo patapata.
  6. Isinku : eyi ni ayeye “fifi erupe fun erupe”. Won yoo gbe oku sinu posi pelu oniruuru nnkan bii; owo,ounje,ileke,aso,bata, opa itile ati nnkan meremere miiran lati lo ni iri ajo naa nitori Yoruba Gbagbo pe iye wa leyin iku ati pe irin ajo ni oku n rin lo si orun. Ni geere ti won ba ti gbe oku sinu koto, awon omo oloku ati ebi re yoo bu eeru si oku naa lara.

IGBELEWON:

  • Kin ni Yoruba n pe ni isinku?
  • Salaye igbese isinku ni ile yoruba

ISE ASETILEWA:

  • Salaye lekun-un rere isinku oba ni ile Yoruba.

EKA ISE : LITIRESO

ORI ORO : KIKA IWE EWI TI IJOBA YAN

OSE KEWAA

EKA ISE : EDE

ORI ORO: IHUN APOLA APONLE ATI ISE TO N SE NINU GBOLOHUN

Apola aponle ni oro aponle kan soso tabi apapo oro aponle pelu isori oro miiran ti o n sise gege bi epon fun oro ise ninu gbolohun.

Apeere;

  • Mo je iyan tan
  • Omo naa dudu fafa
  • O lo pelu ibinu abbl,

Akiyesi : apola aponle le je akanpo wunren oro atokun pelu oro oruko.

Orisi apola aponle meji ni o wa;

  • Apola-ajemopon-on-le asaaju ise : apeere oro epon fun oro ise ti a le ri labe isori yii ni ; n , ti , yoo , maa , ko , jaja , kuku , tile , tetye , papa , moomo , abbl. Apeere;
  • mo n lo
  • se o papa je ounje naa?
  • Mo tile maa papa gba owo naa
  • Apola ajemapon-on-le agbeyin ise: gege bi I oruko re , eyin oro ise ni o ti n jeyo ninu gbolohun lati fi kun itumo oro ise.

Apola ajemapon-on-le yii pin si isori. Awon niyi;

  • Apola ajemapon-on-le alafiwe : apola yii maa n so bi oro ise se ri nipa sise afiwe isele kan pelu omiiran. Apeere;
  1. Tope n korin bi I eye
  2. Adebiyi dudu bi I koro isin
  3. Olumiide n sare bi I ehoro abbl
  • Apola ajemapon-on-le – alasiko : O je apola afi akoko han. Apeere ;
  1. Ounje yoo po ni odun yii
  2. Alani Arowolo n se igbeyawo ni ola
  3. Mo fe ri o ni otunla
  • Apola ajemapon-on-le – onibi : Eyi n toka si ibi ti isele kan ti waye. Apeere ;
  1. Mo ri ayomide ni ilu Oyo
  2. Gaari po ni agbegbe ijebu
  3. Anike se ayeye ojo ibi re ni ilu oba
  • Apola ajemapon-on-le –onidii : Apola yii n so idi abajo ti isele kan fi waye. Apeere;
  1. A n sise nitori owo
  2. Iya n jiya pupo nitori omo. Abbl
  • Apola ajemapon-on-le oniba : Eyi n so bi nnkan se sele. Apeere;
  1. Won gba wa lalejo towotese
  2. Omo naa sun worowo
  3. Alaga se alaye oro naa ni sise-n-tele
  • Apola ajemapon-on-le onikani : Eyi n toka ohun ti iba sele ka ni ohun kan saaju re. Apeere ;
  1. Okete iba jeyan kani ile re gba odo
  2. Yemi iba jiya ka ni o kuna ninu eto eko

IGBELEWON:

  • So itunmo oro aponle
  • Salaye isori apola-aponle meta pelu apeere meji meji

ISE ASETILEWA:

  • Ko apeere soki lori isori oro apola-aponle méjì. [mediator_tech]

EKA ISE : ASA

ORI ORO : OWE ILE YORUBA

  • Owe ni afo ti o kun fun imo ijinle, ogbon ati iriri awon agba.
  • Owe lesin oro , oro lesin owe, bi oro ba sonu, owe ni a fi n wa.
  • Awon agba n lo owe lati yanju oro to takoko.

Orisi owe Yoruba

  • Owe fun ibawi : apeere;
  1. Agba ki I wa loja ki ori omo tuntun wo

Itumo : Awon agba je olutona iwa rere fun awon omode ni awujo.

  1. A n gba oromodie lowo iku, o ni won o je ki ohun lo ori aatan lo je.

Itumo : a maa n pa owe yii fun eni ti o n rin irin ti abayorisi lewu ti o si fi gbigbo se alai-gbo, o n te ife inu ara re lorun.

  • Owe ikilo :
  1. Aguntan to ba ba aja rin yoo je igbe

Itumo : ti awon agba ba se akiyesi pe eni kan n ba eniyan buburu kegbe po,won yoo fi owe yii kilo fun iru eni bee lati year ki o ma aba parun tabi ko irufe iwa buburu naa.

  1. Ise ni oogun ise

Itumo : eni ba fe se aseyori yala lenu ikose tabi ninu eto eko a tepa mose daadaa ( a mura si ise )

  • Owe fun imoran :
  1. Agba to ba je ajeeweyin ni yoo ru igba re dele koko

Itumo : agba to ba hawo ko ni ri omode tabi eniyan kankan ran-an lowo lati gba eru tabi jise fun-un.

  1. Bi ara ile eni ba n je kokoro arinya, bi a ko ba so fun un, here-huru re ko ni je ki a sun loru.

Itumo : bi ara ile eni ba n huwa ibaje ti a ko ba so fun un, nigba ti wahala tabi ijiya re ba de yoo ta ba ni ( eniyan yoo ni ipin tabi je ninu iya bee )

  • Owe fun alaye :
  1. Agba to n sare ninu oja, bi nnkan o le , a je pe o n le nnkan.

Itumo : Agba tabi eniyan to n sise karakara mo idi ti oun fi n se e loju mejeeji

  1. A ni ka je ekuru ko tan labo, n se ni a tun n gbon owo re sinu awo tan-n-gan-ran

Itumo : awon agba maa n pa owe yii bi wahala tabi ede aiyede kan ba sele ti won si n gbiyanju lati yanju re, ti won tun wa se akiyesi pe awon kan fe hu u sita ( awon kan ko fe ki o tan )

  • Owe fun isiri :
  1. Bi ori ba pe nile a dire

Itumo : bi iya ba n je eniyan de bi pe o fe si oro so tabi so ireti nu, awon agba a maa lo owe yii lati tu u ninu pe ojo ola yoo dara.

  1. Pipe ni yoo pe , akololo yoo pe baba

Itumo : ko si ipenija ti eniyan le maa la koja, o le dabi eni pe ko sona abayo sugbon ni ikeyin ireti n be

Iwulo owe ni ile Yoruba

  • O n je ki a fi ododo oro gun eniyan lara ( ba eniyan wi ) lai binu
  • Wo n lo o lati gbe oro to wuwo fun eniyan lati so kale ni ona ti ko fi ni binu.
  • Owe n gbe ogo ede yo
  • A n lo owe lati fi kilo iwa ibaje
  • A n lo o lati fi gba eniyan ni iyanju
  • Awon agba n lo owe lati fi yanju aawo abbl.

IGBELEWON:

  • Fun owe ni oriki
  • Ko orisi owe pelu apeere
  • Ki ni Pataki owe ni awujo Yoruba.

ISE ASETILEWA:

Ko owe ikilo marun-un pelu itumo okookan

EKA ISE : LITIRESO

ORI ORO: KIKA IWE LITIRESO TI IJOBA YAN

OSE KOKANLA ATI IKEJILA

EKA ISE : EDE

ORI ORO : ATUNYEWO ISE LORI ISEDA ORO ORUKO

Oro oruko ni awon oro ti o le da duro ni ipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun.

Isodoruko ni ona ti a n gba seda oro ti ayorisi oro bee yoo je oro tuntun.

Orisi ona ti a le gba seda oro oruko

  • Nipa lilo afomo ibere(prefix)
  • Nipa lilo afomo aarin (infix)
  • Nipa sise apetunpe (reduplication)

Apeere iseda oro oruko nipa lilo afomo ibere , afomo aarin ati apetunpe.

  • Nipa lilo afomo ibere (prefix) : eyi ni kikan afomo ibere po mo oro ise tabi oro oruko. Apeere,
  • a + lo = alo
  • a + de = ada
  • i +jo = ijo
  • ai + lo =ailo
  • ai + san = aisan abbl
  • Nipa lilo afomo aarin (infix) : Eyi maa n jeyo laaarin oro oruko meji. Apeere;
  • ore + si + ore = oresore
  • igba + de + igba = igbadigba
  • iso + ku + iso = isokuso
  • emi + ri +emi = emiremi
  • iran + de + Iran = irandiran
  • igba +ku +igba = igbakigba
  • A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe apola oro ise (Reduplication of verbs) : apeere;
  1. Gbomo + gbomo = gbomogbomo
  2. Jagun + jagun = jagunjagun
  • A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe oro oruko (Reduplication of noun). Apeere;
  1. Ale + ale = Alaale
  2. Omo + omo = Omoomo
  • A le seda oro oruko nipa lilo apetunpe elebe (partial reduplication): Eyi ni ki a fi faweli ‘I’ ti o je mofiimu olohun oke po mo konsonanti akoko ti o bere oro ise, ki a tun fi odidi oro ise ipinle bee kun-un. Apeere;
  1. Je – j + i = Jije
  2. Fe – f + I = Fife
  3. Ra – r + i = Rira

 

IGBELEWON:

  • Fun oro oruko loriki
  • kin ni iseda oro oruko?
  • Salaye pelu apeere awon ona ti a n gba seda oro oruko ni ile Yoruba

ISE ASETILEWA:

Bawo ni a se seda awon oro oruko wonyi;

  • Onidajo
  • Igboya
  • Ogboogba
  • Jobijobi
  • Bamgboye
  • Pejapeja
  • Fife

OSE KOKANLA ATI IKEJILA

EKA ISE: ASA

ORI ORO: ATUNYEWO ASA IKINI

Asa ikini je okan lara iwa omoluwabi; o je iwa ti a gbodo ba lowo omo ti a bi ti o gba eko rere.

Ikini oniruuru ni ile Yoruba

Akoko Ikini Idahun

  • Ni owuro E kaaaro/se alaafia ni a ji? A dupe
  • Ni osan E kaasan O o
  • Ni irole E kurole O o
  • Ni ale E kale O o
  • Akoko ojo E ku ojo O o
  • Akoko oye E ku oye O o
  • Awon alaboyun Asokale anfaani O o
  • Awon o n tayo Mo kota mo kope Ota n je, ope

Ko gbodo fohun

  • Agbe Aroko bodunde Ase
  • Onidiri Ojugbooro E ku ewa Iyemoja a gbe o

Tabi ooya aya o

  • Iya olomo tuntun E ku owo lomi oo

IGBELEWON:

  • Fun asa ikini loriki
  • N je loooto ni awon Yoruba n fi iwa omoluabi han nipa asa ikini?

ISE ASETILEWA:

Bawo ni a se n ki awon wonyi ni ile Yoruba:

  • Akope
  • Ontaja
  • alaboyun

[mediator_tech]

 

OSE KOKANLA ATI IKEJILA

EKA ISE: LITIRESO

ORI ORO: ATUPALE IWE EWI TI A KA NI TAAMU YII

IWE EWI YORUBA LAKOOTUN

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share