OSE KIN-IN-NI ORO – ISE
SUBJECT: YORUBA
CLASS: SS 3
TERM: FIRST TERM
ORO – ISE
OSE KIN-IN-NI
ORO – ISE
Oro – ise ni oro tabi akojopo oro ti o n toka si isele tabi nnkan ti Oluwa se ninu gbolohun.
Oro–ise je opomulero fun gbolohun laisi oro–ise ninu gbolohun ko le ni itumo.
Apeere
- Ade ra iwe Yoruba
- Bolu fo aso
- Ra ati fo lo je oro–ise ti a fi mo nnkan ti oluwa se.
EYA / ORISII ORO – ISE
- Oro – Ise kikun-: ni oro–ise to le da duro ti o si ni itumo kikun laisi pe a fi oro – ise miiran kun-un.
Apeere
Sade ra dundu
Bisi gba iwe kan
- Oro – Ise agbabo-: ni awon oro – ise ti won ko le ma gba abo ninu gbólóhùn.
Apeere
Kike je eja
Bisi ra epa
Awon abo inu gbolohun yii ni eja ati epa.
iii. Oro – Ise alaigbabo-: ni oro – ise ti a kii lo abo pelu re ninu gbólóhùn.
Apeere
Ojo ro
Moji sun
Bolu ga
Bola jo.
- Oro – Ise elela
Eyi ni awon oro – ise onisilebu meji ti a le la si meji gege bi oruko re lati fi oro miiran bo o ni aarin.
Apeere pamo, bawi, baje, reje, pade
Bola pa ile mo (pamo)
Mo ba Bola wi (bawi)
Olu ba aga je (baje)
- Oro–Ise ASApejuwe
ni awon oro – ise ti a maa ri lo lati se irisi nnkan
Apeere
Obinrin naa pupa
Tope ga
Eja naa tobi
- Oro – Ise alapepada -: ni oro – ise ti a maa n se apetunpe re ninu gbólóhùn
Apeere
O ku o ku iwa re
Ma da mi da bukaata mi.
Aye o fe ni fe oro.
vii. Oro – Ise Asokunfa-: ni o maa n fa nnkan tabi to mu ki nnkan kan sele. Awon oro – ise asokunfa ni fi, da, se, mu, ko .
Apeere
O fi igi gba mi.
O da oorun mo mi loju.
O se iku pa awako re.
O ko mi si wahala.
viii. Oro – Ise asoluwadabo-: ni iru gbólóhùn ti Oluwa ati abo ti le gba ipo ara won ninu iso.
Apeere
Mo kanju ( kan oju ) – oju kan mi
Mo jaya ( ja aya ) – Aya ja mi
Sade jiya ( je iya ) – iya je sade
- Oro – Ise asebeere -: ni a maa n lo lati gbe ibeere kale. Meji pere ni o wa ninu ede Yoruba, awon naa ni da ati nko
Apeere
Awon omo nko?
Ile yIn da?
IGBELEWON
- Kin ni oro – Ise?
- Daruko isori oro-ise marun-un
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 137-147
ASA
AFIWE ASA ISINKU ABINIBI, OMO LEYIN KRISTI ATI MUSULUMI
Afiwe asa isinku abinibi ati eto isinku ti awon omo leyin Kristi ati ti musulumi. Ninu isinku abinibi, won kii gbe oku kale. Ojo ti oku ba ku ni o maa n wole afi ti o ba je pe ilu odikeji ni o ku si ti won fe gbe e wa si ile bakan naa ni eyi ninu isinku awon musulumi bi o ti wule ki o ri ojo ti oku musulumi ba ku ni o maa n wole sugbon fun ti awon omo leyin krisit kii se dandan ki oku won wole kiakia awon maa n fi oku sinu yinyin di igbakuugba ti won ba fe.
Ninu isinku ti abinibi ati ti omo leyin Kristi, won maa n lo posi (ile ikeyin) sugbon awon musulumi kii lo posi.
Bi awon abinibi ba fe sinku won maa n lo adie irana won gbagbo pe kii se ohun ajegbe sugbon awon musulumi ati omoleyin Kristi kii lo o
Sugbon awon abinibi omoleyin ati musulumi awon omo oku maa n bu eepe si oku lara ti won ba ti gbe ile
Awon metata lo n se eye fun oku agba
IGBELEWON
Awon ona wo ni asa isinku aye atijo ati aye ode oni fi jo ara won?
Litireso
OGBON ITOPINPIN LITIRESO
Akoonu:
Eyi ni awon koko to se pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti ijoba ya eyi ti a maa ka. Oun akoko ti a gbodo mo ni oruko iwe, Oruko onkowe, ibudo itan, itan ni soki, awon eda itan, ona isowolo-ede, eko ti a ri ko, asa Yoruba ati beebee lo.
Iwe ti a maa gbe yewo ni ORIKI ORILE METADINLOGBON ati IREMOJE ERE ISIPA ODE won je ewi alohun abalaye.
Oruko Onkowe: oruko awon onkowe iwe naa ni: BABALOLA A. ati AJUWON B.
Ibudo Itan: n’ toka si ilu ti itan inu iwe yii ti waye.
Itan ni soki:
Eda Itan:
Akanlo Ede Ayaworan: owe, akanlo ede, afiwe, awitunwi, asorege, ifohunpeniyan, iforodara abbl.
IGBELEWON
- Kin ni oro – ise
- Salaye isori oro-ise merin pelu apeere mejimeji fun ikookan.
- Daruko awon koko to se pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti a fe ka.
APAPO IGBELEWON
- Kin ni oro – Ise?
- Daruko isori oro-ise marun-un
- Kin ni oro – ise
- Salaye isori oro-ise merin pelu apeere mejimeji fun ikookan.
- Daruko awon koko to se pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti a fe ka.
ISE SISE
- Ki ni oro aponle?
- Ko apeere oro oruko mmefa
- Salaye ni soki lori asa igbeyawo ile Yoruba.
- Ki ni silebu?
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 334
ISE AKATILEWA
- _____ ni opomulero fun gbolohun (a) oro-oruko (b) oro-ise (d) eyan
- E rowa ro ire je apeere oro-ise _____ (a) asoluwadabo (b) alapepada (d) agbabo
- Sola da obe nu. Oro_ise iru gbolohun yi ni (a) da (b) obe (d) danu.
- Awon ______ lo maa n lo adie irana ninu isinku won. (a) Omo leyin Kristi (b) Musulumi (d) abinibi
- Awon _________ ki lo posi fun oku won (a) abinibi (b) Musulumi (d) Omo leyin Kristi.
APA KEJI
- Kin ni oro-ise?
- Daruko isori oro-ise marun-un
- Salaye meji ninu won pelu apeere.
- Se afiwe asa isinku abinibi, omo leyin Kristi ati musulumi.
- Eyin ni awon ona wo to se pataki ti awon gbodo mo nipa iwe litireso ti o maa je ninu igbelewon.
- Daruko isori oro-ise marun-un
- Salaye meji ninu won pelu apeere.
IGBELEWON
- Kin ni oro-ise?
- Daruko isori oro-ise marun-un
- Salaye meji ninu won pelu apeere.
- Se afiwe asa isinku abinibi, omo leyin Kristi ati musulumi.
- Eyin ni awon ona wo to se pataki ti awon gbodo mo nipa iwe litireso ti o maa je ninu igbelewon.
- Daruko isori oro-ise marun-un
- Salaye meji ninu won pelu apeere.
- Oro-ise kin ni?