IBA ISELE ORÍKÌ ORÍṢI IBA ÌṢẸ̀LẸ̀

Subject : Yoruba

Class: SS 3

TERM: FIRST TERM

WEEK: WEEK 4

OSE KERIN

IBA-ISELE

– Oriki

– Orisii iba-isele

– Awon wunren ti o toka iba-isele

Akonu:

ORI-ORO:  ASIKO ATI IBA ISELE

ORIKI

EYA IBA ISELE

AKOONU

Asiko je oro girama ti a maa n lo lati fi toka si asiko ti isele kan waye.  Orisii asiko meji lo wa ninu ede Yoruba.

  • Asiko afanamoni.
  • Asiko ojo iwaju.

Asiko Afanamoni:  ni isele ti o ti sele koja tabi eyi ti o sele lowolowo ni asiko yii. Apeere

Olu lo ile

Baba je amala

Asiko Ojo Iwaju:  eyi ni isele ti ko tii sele sugbon ti o si maa sele ni ojo iwaju. Apeere:

Bade yoo lo si ilu oba.

Baba yoo joba.

Iba Isele:  Eyi ni oro girama ti o maa n siwaju oro-ise lati toka si iba isele ni pato

 

Eya iba-isele

Orisii iba-isele meta lo wa ninu ede Yoruba

  1. Iba-isele Adawa
  2. Iba-isele Aisetan

Aterere/Baraku

  • Iba-isele Asetan

Ibere /Ipari

Iba-isele ninu asiko afanamonii

  1. Iba-isele Adawa

 

Iba-isele ninu asiko afanamonii ko ni atoka Kankan. Apeere:

Olu lo si oja

Won ra moto

  1. Iba-isele aisetan aterere

Eyi ni isele ti o si n lo lowolowo, isele ti ko kii pari, erun oro-ise ‘n’ ni atoka re. Apeere

Bolu n korin.

Won n fo aso.

 

Iba-Isele Aisetan Baraku

Eyi ni isele ti o maa n sele ni gbogbo igba.  Atoka iba-isele yii ni a maa, maa n. Apeere:

Dayo a maa pariwo soro

Maa maa n we ni alaale

 

iii. Iba-Isele Asetan: Asetan ibere. Eyi ni isele ti ibere re ti bere sugbon ti gbogbo isele maa ko ti i pari tan.  Atoka iba-isele yii ni, ti n, ti maa n ati maa. Apeere

Mama ti n dana

Bade ti maa n jeun

Sade a ti maa bo

 

Asetan Ipari: Eyi ni isele ti o ti pari patapata.  Atoka iba-isele yii ni ‘ti’. Apeere:

Ayo ti korin.

Mama ti gbale.

Bolu ti de.

 

IGBELEWON

Kin ni iba-isele?

Salaye awon iba-isele wonyi – aterete, asetan ipari

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 174-176

 

ASA

IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA OSO ATI AJE

Akoonu

Awon  Yoruba gba pe oso ati aje wa, won  tile ni igbagbo yii to bee ti o fi je pe, o soro lati ri eni ti o ku, yagan tabi ti wahala sele si, ti won ko ni so o mo oso ati aje.

 

Bakan naa awon Yoruba gbagbo pe oso ati aje ni agbara oogun ti won le fi pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe inu ipade aje ni won ti maa n duna-dura bi won yoo se pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe ona meji ni okunrin fi n gba oso

-ajogunba

wiwo egbe oso bee naa ni ti aje o le je, nipa ajogunba/wiwo egbe aje

Iyato laarin oso ati aye

Iyato to wa laarin oso ati aje ni pe awon okunrin lo maa n je oso nigba ti awon aje je obinrin.

Litireso:- KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN

Iran  keta ati ikerin

 

IGBELEWON

  1. a. Kin ni iba-isele?
  2. Salaye orisii iba-isele ti owa pelu apeere mejimeji fun ikookan.
  3. Salaye igbagbo ati ero awon Yoruba nipa oso ati aje.

 

APAPO IGBELEWON

  1. a. Kin ni iba-isele?
  2. Salaye orisii iba-isele ti owa pelu apeere mejimeji fun ikookan.
  3. Salaye igbagbo ati ero awon Yoruba nipa oso ati ajo.

3    Kin ni iba-isele?

4    Salaye awon iba-isele wonyi – aterete, asetan ipari

 

ISE SISE

  1. Salaye lori ise abinibi kan ti o yeo yekeyeke
  2. Ipaje ni
  3. Ko apeere mejo.

 

IWE AKATILEWA

Mustapha, O.Eko  Ede Yoruba Titun S.S. 2 o.i 85 – 93

 

ISE ASETILEWA

  1. ____ ni isele ti o ti bere sugbon ti ko tii pari (a) asetan ibere (b) aterere (d) aisetan

2    Atoka fun iba – isele aisetan aterere ni ____ (a) ni  (b) n (d) ti

  1. Iba-isele ti ko ni atoka kankan ni ____ (a) Adawa (b) asetan (d) aisetan
  2. Kin lo poju ninu ohun ti oso ati aje n lo agbara won fun? (a) ire (b) ibe (d) alaafia
  3. ____ ni won n lo si inu to n run Adigun. (a) Apoogun (b) Apooro epa ijebu (d) oogun jedi

 

APA KEJI

  1. Salaye awon iba-isele won yii pelu apeere mejimeji fun ikookan.

Iba- isele asetan ibere

Iba-isele aisetan aterere

Iba-isele aisetan baraku

Iba-isele asetan ipari

  1. Salaye lekun-un rere ohun ti o sele si Adigun ati owo ti won fi ran-an nise.