Ìmọ̀ Alifabeti Yorùbá, Itan, àti Litireso Yorùbá JSS 1 First Term Lesson Notes Week 1
Yorùbá JSS 1 Ọsẹ Kínní Akọ́lé
Kẹ̀kọ́: Yorùbá
Kíláàsì: JSS 1
Ọ̀sẹ̀: Kínní
Ọmọ ọdún: 12 ọdun
Akọ́lé: Alifabeti Yorùbá, Itan Isedale Yorùbá, àti Litireso
Ẹ̀ka: Alifabeti Yorùbá, Itan Isedale Yorùbá, àti Iru Litireso
Ìpinnu Akoko: 1 wakati 30 ìsẹ́jú
Àfojúsùn Ẹ̀kọ́:
- Kọ́ àwọn ọmọ kéékèèké láti mọ̀ àti sọ alifabeti Yorùbá.
- Ṣàpèjúwe itan àti ìtàn-akọọlẹ àwọn Yorùbá.
- Ṣàlàyé àwọn oríṣìíríṣìí litireso Yorùbá.
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀: Alifabeti, Konsonanti, Faweli, Itan, Litireso, Ewi, Oro Geere, Ere Onise
Ìtẹ̀sí: Bẹrẹ́ pẹ̀lú ìjíròrò kékèké nípa pàtàkì ìmọ̀ èdè Yorùbá àti aṣa rẹ̀. Béèrè lórí ohun tí àwọn ọmọ mọ̀ nípa alifabeti Yorùbá àti àtọkànwá rẹ̀.
Ìṣe ìbẹ̀rẹ̀: Àwọn ọmọ yẹ kí wọ́n ní ìmọ̀ àkọ́kọ́ nípa èdè Yorùbá àti aṣa rẹ̀.
Àwọn Ẹ̀rọ ìkọ́ni àti Àmúlò: Àtẹ̀jáde alifabeti Yorùbá, àwọn ìwé itan, àpẹẹrẹ litireso, ọ̀rọ̀-ìkànsí, àpèèrè àti àwọn ẹ̀rọ ìkọ́ni Yorùbá
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́: Jẹ́ kó dájú pé àwọn ọmọ ní ìmọ̀ ṣáájú nípa ohun tí wọ́n ti kọ́ nípa aṣa Yorùbá àti èdè wọn.
Ọ̀gbọ́n Tí A Ní: Kíkà, ìmọ̀ ọrọ̀, ìmọ̀ iṣe, ìmọ̀ itan
Àwọn Ẹ̀rọ ìkọ́ni: Àtẹ̀jáde alifabeti Yorùbá, àwọn ìwé itan, àpẹẹrẹ litireso
Ìtàn
- Alifabeti Yorùbá:
- Alifabeti Yorùbá ní lẹ́tà 25.
- Ó ní konsonanti àti faweli.
- Konsonanti: Bb, Dd, Ff, Gg, GB gb, Hh, Jj, Kk, Ll, Mm, Nn, Pp, Rr, Ss, Tt, Ww, Yy
- Faweli: Aa, Ee, Ii, Oo, Uu (pẹ̀lú faweli nasali: an, en, in, on, un)
- Itan Isedale Yorùbá:
- Àwọn Yorùbá ti ṣe àtẹ̀jáde láti àwọn ìlú ni ilẹ̀ Yorùbá.
- Lamurudu ni a kà sí ẹni pàtàkì àti baba Oduduwa.
- Léyìn ikú Lamurudu, Oduduwa àti àwọn alákóso rẹ̀ bọ̀ sí Ifẹ̀, tó jẹ́ ìpẹ̀yà fún gbogbo ìlú Yorùbá.
- Àwọn ọmọ Oduduwa: Okanbi àti ọmọ méje rẹ̀.
- Ìlú àti àwọn ìpín rẹ̀.
- Ìru Litireso Yorùbá:
- Litireso Alohun: Litireso tí a fi ohun ènu hàn, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ Ewi (poetry), Oro Geere (àtúmò̀ ìtàn), àti Ere Onise (drama).
- Litireso Apileko: Litireso tí a kọ, pẹ̀lú Ewi Apileko (poetry tí a kọ), Ere Onitan (epic narratives), àti Itan Oroso (ìtàn ìtàn).
AKOLE ISE – ALIFABETI YORUBA
ALIFABEETI JE AKOJOPO LETA TI ASE AKOSILE RE GEGE BI IRO NINU EDE YORUBA.
ALIFABETI EDE YORUBA
Aa Bb Dd Ee Ee Ff Gg GB gb Hh Ii Jj Kk Ll Mm Nn Oo Oo Pp Rr Ss Ss Tt Uu Ww Yy
Apapo alifabeti ede Yoruba je meedogun (25)
Ona meji ni a le pin alifabeeti ede Yoruba si. Awon niyi;
- Iro Konsonanti
- Iro Faweli
Iro Konsonanti: Eyi ni iro ti a pe ni igba ti idiwo wa fun eemi.
Awon Konsonanti naa ni:
Bb Dd Ff Gg GB gb Hh Jj Kk Ll Mm Nn Pp Rr Ss Ss Tt Ww Yy
Apapo konsonanti edeYoruba je mejidilogun (18)
Iro faweli: Eyi ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi
Eyi pin si ona meji:
Iro faweli airanmupe: A kii ran mu pe iro yii rara bee ni ko si idiwo fun eemi tabi afefe ti a n pe.
Meje (7) ni iro faweli airanmupe
Aa Ee Ee Ii Oo Oo Uu
Iro faweli aranmupe: A maa n ran mu pe awon iro yii. Nigba ti a ba n pe awon iro yii jade, eemi maan gba iho imu ati enu jade lee kan naa.
Marun-un (5) ni iro faweli aranmupe – an, en, in, on, un
Apapo iro faweli ede Yoruba je mejila (12)
Igbelewon:
- Kin ni alifabeeti ede Yoruba?
- Ona meloo ni a pin alifabeeti ede Yoruba si?
- Ko won sita
Ise asetilewa :ISE SISE NINU IWE ILEWO YORUBA AKAYEGE
EKA ISE ASA
AKOLE ISE Itan Isedale Yoruba
- Itan so pe ilu meka ni Yoruba ti wa
- Itan fi ye wa pe Lamurudu ni baba nla Yoruba
- Lamurudu je Ogbontegi abogipa
- Itan so pe awon elesin musulumi gbe ogun ti Lamurudu lati fi esin iborisa sile
- Itan fi ye wa pe inu ogun yii ni Lamurudu ku si
- Ba kan naa, itan so pe Lamurudu ni baba Oduduwa
- Leyin iku Lamurudu, Oduduwa ati awon eniyan re sa wa si ilu ile ife
- Ilu ile-ife ni o je orisun fun gbogbo ile Yoruba
- Oruko omo Oduduwa ni Okanbi
Okanbi ti o je omo Oduduwa bi omo meje. Awon ni:
S/N | ORUKO | ILU TI WON TE DO SI | OGUN TI WON PIN |
A | Olowu | Owu | Aso |
B | Alaketu | Ketu | Ade |
D | Oba Ibini | Bini | Owo eyo |
E | Orangun | Ila | Iyewo |
E | Oni Sabe | Sabe | Eran Osu |
F | Onipopo | Popo | ILeke |
G | Oranmiyan | Oyo | Ile |
Igbelewon:
- Ni sisentele so itan isedale Yoruba
- Daruko awon omo Okanbi pelu ogun ti won pin leyin iku baba won
Ise asetilewa: ya maapu omo eya ile yoruba
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: ORIKI LITIRESO.
Litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan tabi omiiran.
Litireso je ona ti Yoruba n gba fi ero inu won han nipa iriri won gbogbo.
Ona meji ni a le pin litireso si, awon ni
- Litireso alohun
- Litireso apileko
Litireso Alohun: Eyi ni litireso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon baba nla wa.
Litireso alohun pin si;
- Ewi
- Oro geere
- Ere Onise.
Litireso Apileko: Eyi ni litireso ti a se akosile ni gba ti imo moo- ko – moo-ka de.
Litireso apileko pin si;
- Ewi apileko
- Ere Onitan
- Itan Oroso
Igbelewon:
- Fun litireso ni oriki
- Ona meloo ni a pin litireso ede Yoruba si
- Salaye lekun-un rere
Ise asetilewa:ko apeere ewi alohun Yoruba marun-un