Second Term SSS 3 Yoruba

Table of Contents

ILANA ISE SAA KEJI FUN OLODUN KETA AGBA

 

ISE:  EDE YORUBA                                                                                         KILAASI:  SS3

 

Ose Kinni        Atunyewo eko kikun lori Silebu Ede Yoruba

                        Asa – Elegbejegbe tabi Irosiro

Litireso – Agbeyewo asayan iwe ti ajo WAEC/NECO yan

Ose Keji          Fonoloji Ede Yoruba

Foniimi, Konsonanti, Faweli, ohun Konsonanti Aranmupe, Eda Foniimu kons. Ati ohun.

Asa: Agbeyewo awon Orisa Ile Yoruba: Obatala, Orunmila/Ifa. Itan ni soki nipa  Aworo Orisa.

Litireso – Itupale iwe ti ajo WAEC/NECO yan.

Ose Keta         Atunyewo eko lori Oro- Ayalo

Asa – Eto Ebi ati Iserun Eni

Litireso – Kika iwe ti ajo WAEC/NECO yan

Ose Kerin        Ihun Oro – Iseda Oro – Oruko

Asa – Eto Iselu Abinibi ati ti Ode-Oni

Lit: Itupale iwe ti ajo WAEC/NECO yan.

Ose Karun       Atunyewo eko lori Isori Oro: Oruko, Aropo Oruko, Aropo Afarajoruko, Ise abbl.

Asa: Atunyewo eko lori Oge Sise. Aso wiwo, itoju ara, ila kiko abbl.

Lit: atunyewo eko lori alo apamo, apagbe, itandowe abbl.

Ose Kefa         Atunyewo eko lori Isori Oro: Apejuwe, Aponle, Asopo, Atokun

Asa: atunyewo kikun lori Asa Igbeyawo nile Yoruba.

Lit: Itupale iwe ti ajo WAEC/NECO yan.

 

IWE ITOKASI

  • Imo, Ede, Asa Ati Litireso. S.Y Adewoyin
  • Eto Iro ati Girama fun Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.
  • Akojopo Alo Apagbe: Amoo A. (WAEC).
  • Oriki Orile Metadinlogbon: Babalola, A (WAEC).
  • Iremoje Ere Isipa Ode: Ajuwon B. (WAEC).
  • Igbeyin Lalayonta: Ajewole O. (WAEC).
  • Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
  • Oremi Mi: Aderibigbe, M. (WAEC).
  • Egun Ori Ikunle: Lasunkanmi Tela. (NECO)
  • Omo Ti A Fise Wo: Ojukorola Oluwadamilare. (NECO).
  • Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).

OSE KINNI

SILEBU EDE YORUBA

AKOONU

Silebu ni ege oro ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekan soso. Apeere:

Ajayi:              A-ja-yi  =         silebu meta

Olabisi             O-la-bi-si         silebu merin.

Adeleke           A-de-le-ke       silebu merin

Olopaa             O-lo-pa-a         silebu merin

Gbangbadekun  gba-n-gba-de-kun     silebu marun-un.

 

Odo Silebu: ni apa ti o se pataki julo ninu ihun silebu kookan. Iro faweli ati iro

konsonanti aranmupe asesilebu ni o maa n sise gege bi odo silebu. Odo silebu ni o maa n dun ju ninu silebu.

 

Awon iro odo silebu ni a maa n gbo ju ninu oro.

Ori odo silebu ni a maa n fi ami ohun si

Kan-an-n-pa ni odo silebu je ninu ihun silebu.

Ap

wa

gba

sun

 

Apaala silebu -;je iro konsonanti yato si konsonanti aranmupe asesilebu [m,n] ni o maa n sise gege bi apaala silebu.

ap

gbo

dun

ko

we

 

IHUN SILEBU [F1,KF ATI N] NINU ORO OLOPO SILEBU.

Orisiirisii ona ni a le gba se ihunpo silebu ninu oro olopo silebu.

ORO                          IHUN                           IYE SILEBU

Aso                              A/ so                                        2

f /kf

Bata                             ba / ta                                      2

Kf / kf

Igbale                          i/gba / le                                   3

F/ kf /kf

Alupupu                     A/lu/pu/pu                                4

f/kf/kf/ kf

Konko                         ko/N/ko                                   3

Kf/N/kf

 

IGBELEWON

  1. Kin ni silebu?
  2. Salaye ihun silebu pelu apeere.
  3. Pin awon oro yii si silebu

Agbalagbaakan

Olowolayemo

Gbangbalakoogbo

Oji ku tu ba-ra orunsaaro

Operekete

 

IGBELEWON

  1. Salaye ni ekunrere lori odo silebu ati apaala silebu pelu apeere.
  2. Eya ihun silebu meloo ni o wa? Fi apeere gbe idahun re lese.
  3. Ki ni pataki konsonanti aranmupe n ati m ninu ege silebu?

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

ASA

ELEGBEJEGBE

ORIKI

ORISII

IPA TI WON N KO NI AWUJO

AKOONU

– Elegbejegbe ni egbe ti awon odo, agba ni okunrin tabi ni obinrin ti won je iro da sile ni agbegbe won fun igbega ilu ati ara won.

Ni aye atijo,iwonba ni ise ti ijoba maa n se fun awon ara ilu.igbega ati idagbasoke ilu tabi igberiko maa n waye pelu iranlowo awon elegbejegbe wonyi, apeere iru egbe bee ni aye atijo ni egbe ogboni.

Apapo awon agba ilu ti won to omo bii Aadota odun ni won maa n wo egbe ogboni. Ojuse egbe ogboni ni lati fun oba ni imoran.Won ni agbara lati da oba lekun tabi le oba kuro lori ite ti o ba si agbara lo.

Ni ode-oni,awon elegbejegbe po jantirere. Apeere won ni :-

Lion’s club

Rotary club

Majeeobaje

Oredegbe ati bee bee lo.

Ni ilu tabi ileto ti awon egbe wonyii ba wa,orisiirisii ise idagbasoke ni won maa n se bii : – tite tabi titun afara se.

  • kiko ile ero kaakiri ibudoko.

 

IWULO ELEGBEJEGBE.

  1. Awon egbe ogboni maa n kopa ninu eto iselu awon baba-nla wa.
  2. Won maa n kopa ninu ise bii:- ona yiye,afara odo titun se,aafin oba kiko.
  • Won maa n kopa ninu pipese owo ajemonu fun awon akekoo ile-iwe giga,pipese eko ofe fun awon akekoo ile-iwe girama,sisan owo idanwo iwe mewaa.
  1. Aaro kikojo,owe bibe,eesu kikojo fun iranlowo egbe ati enikookan omo egbe.

 

IGBELEWON

  1. Nje egbejegbe ni anfaani Kankan ninu asa Yoruba bi? Se alaye kikun.
  2. Daruko egbejegbe ibile Yoruba marun-un ti o mo.

 

LITIRESO

OGBON ITOPINPIN LITIRESO

Akoonu:

Eyi ni awon koko to se pataki ti a gbodo mo nipa iwe litireso ti ijoba ya eyi ti a maa ka. Oun akoko ti a gbodo mo ni   oruko iwe, Oruko onkowe, ibudo itan, itan ni soki, awon eda itan, ona isowolo-ede, eko ti a ri ko, asa Yoruba ati beebee lo.

Iwe ti a maa gbe yewo ni  OMO TI A TI A FI ISE WO ati ORE MI.

Oruko Onkowe: oruko awon onkowe iwe naa ni: Ojukorola O. ati Aderibigbe M.

Ibudo Itan: n’ toka si ilu ti itan inu iwe yii ti waye, awon ilu ti itan naa ti waye ni:

Itan ni soki:

Awon Eda Itan:

Akanlo Ede Ayaworan: owe, akanlo ede, afiwe, awitunwi, asorege, ifohunpeniyan, iforodara abbl.

 

IWE AKATILEWA

Simplified Yoruba ati litireso

 

APAPO IGBELEWON

  1. a. Kin ni silebu?
  2. Salaye ihun silebu pelu apeere.
  3. Pin awon oro yii si silebu
  4. Nje egbejegbe ni anfaani Kankan ninu asa Yoruba bi? Se alaye kikun.
  5. Daruko egbejegbe ibile Yoruba marun-un ti o mo.

 

ATUNYEWO EKO

  1. Salaye iro konsonanti.
  2. Salaye iro faweli

 

ISE ASETILEWA

  1. ………ni ege oro ti eni lo gba jade leekansoso (a) oro (b) apola (d) silebu
  2. ………..ni a n lo fun idagbasoke ilu. (a) iro (b) egbe (d) aaro.
  3. …………ni maa n gbo ju ninu silebu. (a) odo silebu (b) ihun silebu (d) apaala silebu.
  4. …… ki i se ara erongba elegbejegbe. (a) ona yiye (b) afara tite (d) aibowofagba.
  5. Apeere elegbejegbe laye atijo ni ………. (a) egbe onimototo (b) egbe ogboni (d) Rotary.

 

THEORY

  1. ki ni silebu?
  2. salaye ihun silebu pelu apeere.
  3. a. kin ni odo ati apaala silebu? Fi idahun re han pelu apeere.
  4. kin ni elegbejegbe?
  5. salaye iwulo elegbejegbe merin ti o mo.

 

 

OSE KEJI

FONOLOJI EDE YORUBA

Foniimu konsonanti

Foniimu faweli ati ohun

Eda foniimu konsonanti ati faweli

Akoonu

(Iro aseyato)

Foniimu ni awon iro ti o le fi iyato han laaarin oro kan tabi omiran

Ap

Foniimu ni /b/ /d/ /t/, eyi ti o tumo si pe  bi a ba fi iro kan dipo ikeji iyato yoo wa

Ap

Ede

Ere

Epe

Ege

Egbe

 

Idako foonu faweli – a {a}

Baba ko ebe – {baba k כ ebe}

 

Foniimu ede Yoruba pin si ona meta

  • Foniimu konsonanti
  • Foniimu faweli
  • Foniimu ohun
  • Foniimu konsonanti -: iro aseyato ni gbogbo iro konsonanti ede Yoruba fere je ba, pa, wa

Ap

/b/ ni eda {b} – to je konsonanti akunyun afeji – ete – pe asenupe.

O le jeyo nibi gbogbo ap bo /b כ[b כ

Foniimu Faweli: naa je iro aseyato bi a ba fi faweli kan ropo ikeji iyato yoo wa ninu oro naa.

Ap.

Wa

Wo

We

Foniimu faweli pin si ona meji

Faweli airanmupe

Faweli aranmupe

Apejuwe fonimu faweli

/a/ ni eda [a] – ayanupe, aarin, perese

o maa n jeyo nibi gbogbo ap s /Sa/ [Sa]

apa /akpa/ [akpa]

 

FONIIMU OHUN

Iro ohun a maa je foniimu tabi  toniimu. Eyi nipe  ohun ori silebu kan le mu ki oro kan yato si ikeji paapaa ninu ede olohun bii ede Yoruba.

Foniimu ohun pin si ona meta.

  1. / | / toniimu oke ap Ja
  • | \ | toniimu isale ap iwa
  • toniimu aarin

ap

wi

wa

so

igba (re re)

igba (garden egg)

igba (time)

igba (calabash)

 

Eda Foniimu :- ni awon iro ti ko le fi iyato han laarin itumo oro kan ati omiran. Eda foniimu je ifonka alaiseyato ninu ede Yoruba.

Apeere eda foniimu faweli in

\ I/ ati / n/

eyi ni pe bi a ba fi won ropo ara won ninu oro ko ni si iyato.

Ap.

ni aya – laya

ni ana  – I anaa

mo ni aso – mo laso.

Ogunbambo – Ogunbanbo

Oronbo – Orombo.

O kan je eda ikeji bee ni ko si iyato kankan laarin won.

Eda faweli: eda faweli foniimu faweli ede Yoruba ni / a / an ati כ// on.

Ap

Itan      –           Iton

Iran      –           Iren

Okan   –           Okon

 

IGBELEWON

  1. ki ni foniimu? Salaye ni ekunrere.
  2. Ki ni eda foniimu? Salaye ni ekunrere.
  3. Fun fonoloji ni oriki.

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

{BZTQLQ/)R*XZ]NLQ

Itan so nipa Obatala wi pe oun ni ipo re ga julo ninu gbogbo orisa. Oun ni o lagbara julo ninu won, oun si ni asaaju won patapata. Oruko meji ni a le pe orisa yii nile Yoruba. A le pe e ni Obatala, eyi ti o ja si ‘Oba ti ala’, a tun le pe e ni Orisa-nla eyi ti o ja si ‘Oba ti-o-nla’, Oba ti o tobi.

 

Oun kan naa ni a gbo pe o je igba keji eledaa Olodumare. O di igba keji nitori pe oun gan-na ni Eledaa koko da. Leyin eyi ni Eledaa fun un ni agbara lati ran oun lowo ninu ise re gege bi Eledaa. A gbo pe Obatala ni i se oju, imu, enu, eti ati awon eya ara yooku leyin ti Eledaa ba ti da ara borogidi tan.

 

Awon aro, amunkun, afin, abuke, afoju ati awon miiran bee la n pe ni ‘eni orisa’.

Awon wonyi ni Obatala fi ise tabi owo agbara re han. A sit un n pe e ni ‘Alamo Rere’ nitori pe o ni anfaani lati lo amo re fun siseda eniyan. Igbagbo awon oloosa Obatala nip e bi Olodumare ba se ara tan, yoo fi ara naa ranse si Obatala ki o tan eda naa wa si aye, ti yoo si maa so titi ojo aye re.

 

Obatala ko fe epo, osun bi ko se ala. Aso funfun ni awon aworo Obatala ati awon olusin re maa n lo ni ojo odun re. Iyan ati obe funfun ni ti Obatala, inu igba funfun ni a o de iyan re si. Obe ti a fi eran igbin ati ori se ni ti Obatala. Aso funfun gele funfun ileke fun ni iyawo Obatala sa maa n lo ni ojo odun re.

 

IGBELEWON

Salaye orisa Orunmila.

 

IWE ITOKASI

Olu, D. ati Jeje, A. (1970) AWON ASA ATI ORISA ILE YORUBA Onibonoje Press.

 

IFA

Nigba ti a ba daruko Ifa, okan opolopo eniyan ni o maa n lo si odo Orunmila. Looto ni Orunmila je baba Ifa sugbon kii se oun nikan ni Ifa ti a n d anile Yoruba.

 

Ni aye atijo ko si ohunkohun ti a le se nile Yoruba lailo beere lodo Ifa. Ti a ba fe fe iyawo, a o lo beere boya wundia ti okan wa so ni yoo je iyawo rere abi bee ko. Bi a ba bimo a nila ti lo beere esentaye omo lodo Ifa abbl. Awon ohun ti a n se nile Yoruba ti a kii fi ti Ifa si ko wopo. Owo Ifa ni a ti n beere eni ti o maa j’Oba ohun ni o mo eni ti yoo yooku ni aarin ilu. Paripari re ni wi pe owo Ifa ni a ti beere ojo ti o ba to ti o si ye lati bo Ifa ni odun. Eleyi fi han kedere lori ipo ti awon Yoruba fi ifa si.

 

Yato si orunmila, awon Ifa miiran ti o wa ni ile Yoruba ni Agbigba, obi, Ile, olokun, Olokun-awo, wo-mi-pee.

 

Awon onitan so fun wa pe Orunmila ni eni naa ti o Olodumare ran lati wa se igba keji re ni aye. Odo re ni a o ti maa beere orisii nnkan nitori o je eni ti o gbon lopolopo. Awon tile so pe o wa nibe nigba ti Olodumare da gbogbo ohun ti o n be ninu aye pelu eniyan paapaa idi re e ti a fi n pe e ni Eleri-ipin. Apeja oruko Orunmila ni ‘Orun-mo-eni-ti-o-maa-la’

 

Itan kan so w ape o ni baba ati iya sugbon won ko gbe ile aye pelu re. )rok9 ni or5k[ bzbq Zlqj3ru ni or5k[ 8yq r2 ni 0de =run. +sany8n j1 oluran lowo pztzk8 f5n +r5nm8lz.

 

Ekuro ni Ifa ti o j1 irinsc f5n +r5nm8lz. Ifa je irinse fun +r5nm8lz. Awon babalawo ni o je aworo Orunmila tabi Ifa.

 

IGBELEWON

Salaye iyato ti o wa laarin orunmila ati Ifa.

 

IWE ITOKASI

Olu, D. ati Jeje, A. (1970) AWON ASA ATI ORISA ILE YORUBA Onibonoje Press.

 

LITIRESO

Kika iwe ti ijoba yan

 

IGBELEWON

  1. Kin ni foniimu
  2. Ona meloo ni foniimu pin sii
  3. Se agekuru ohun ti e ka ninu iwe adakedajo.

 

IWE AKATILEWA

Imo Ede Asa ati Litreso Yoruba SS3. S.Y Ademoyin o.i 83 – 90

 

APAPO IGBELEWON

  1. Salaye orisa Orunmila.
  2. ki ni foniimu? Salaye ni ekunrere.
  3. Ki ni eda foniimu? Salaye ni ekunrere.
  4. Fun fonoloji ni oriki.

 

ATUNYEWO EKO

Ko iyato merin laarin iro konsonanti ati iro faweli sile.

 

ISE ASETILEWA

  1. Foniimu ni _______ (a) iro ti a pe (b) to le fi iyato han (d) iro ti o dun
  2. Faweli pin si ona ____ (a) meji (b) meta (d) merin
  3. Iro ______ naa ni a mo si toniimu (a) faweli (b) konsonanti (d) ohun
  4. eda foniimu konsonanti ni _______ (a) / b/ ati / d/ (b) /i/ ati m (d) /I/ ati / n/
  5. Idako ‘on’ ni _____ (a) / on / (b) /c/ (d) / כ

 

APA KEJI

  1. Pelu apeere salaye iyato to wa laarin iro foniimu ati eda foniimu .
  2. Se adako – foonu fun awon faweli ti a fala si nidi ninu awon oro wonyi: Imu, Won, Yen,

Esin, Aso, Eyele, ati Sola lo si ile ijosin.

  1. Salaye iyato ti o wa laarin Obatala ati Orunmila.

 

 

OSE KETA

ORO – AYALO.

Inu ede ti a ti n ya oro lo.

Ona ti a n gba ya oro wonu ede Yoruba.

 

Akoonu

Oro – ayalo -: ni awon oro ajeji ti a maa n ya wonu ede Yoruba lati inu ede miiran

Oro – ayalo -: ni mimu oro lati inu ede kan wo inu ede miiran lona ti pipe ati kiko re yoo fi wa ni ibamu pelu ede ti a mu-un wo.

Oro – ayalo maa n mu ki ede dagba.

Bakan naa, o maa n je ki oruko wa fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba n sese n wo awujo wa

 

Yoruba ni ilana meji ti won n gba ya oro wo inu ede Yoruba, awon naa ni

–         Ilana afetiya

–         ilana afojuya

Ilana afetiya -: eyi ni pipe oro ayalo ni ona to sunmo bi awon elede se n pe oro gan-an

 

Bible –             Baibu

Peter    –           Pita

Table   –           Tebu

Esther –                        Esita

Deacon –          Dikin

Council –         kansu

Al- basal –        alubosa

 

Ilana afojuya :- eyi ni kiko oro ni liana eyi to sunmo bi awon elede se n ko.awon elede se n saaba maa n lo ilana yii

 

Soldier             –          soja

Table              –           tabili

Peter                –           peteru

Esther             –           esiteri

Bible                –           Bibeli

Deacon            –           Diakoni

Paradise           –           paradise

Hebrew           –           Heberu

 

Inu awon ede wonyii ni a ti n ya oro wo inu ede Yoruba

Ede  Geesi

Ede  Larubawa

Ede  Faranse

 

Bi oro ayalo se wonu ede Yoruba

Eyi ni orisirisii ona ti oro ayalo gba wonu ede Yoruba

  1. Esin:- nipase esin musulumi ati esin Kristi ti won mu wa fun wa ni a se ni awon oro wonyi:  mosalasi, soosi, alijanna, angeli bibeli, pasito, kurani abbl
  2. Ajose owo:- eyi ni ajose owo laarin Yoruba ati awon eya miiran ap: senji, korensi, wisiki, buluu
  • Eto iselu:- Nipase ijoba ajeji ti awon larubawa ati Geesi mu wa ni a ti ya opolopo oro bii seria, kootu, sinato
  1. Asa ati olaju:- ajumose nipa asa ati olaju mu ki a ya opolopo oro lo ap: yigi, marede
  2. Eto eko:- eyi ni oro ti a ya nipa eto eko ap tisa, boodu,

 

AWON IRO TI A FI N SE AARO ARA WON

Ki oro ede Geesi ti a ya lo to le di ara oro mu ede Yoruba, o gbodo tele ofin ede Yoruba

  1. Konsonanti ki i gbeyin oro ninu  ede Yoruba bi oro ayalo ba ni, a o fi faweli ti o ye seyin re, o le je: i, u   a tabi o, ap

Bread – buredi

Gum – goomu

Bed – beedi

Shirt – seeti

fail – feeli

Glass – gilaasi

Gold – goolu

 

  1. Yiyo konsonanti ipari oro ayalo kuro ap

Mobil – mobi

Moses – mose

Jesus – jesu

Lazarus – lasaru

 

iii.        Yiya isupo konsonanti oro- ayalo fifi faweli ya isupo konsonanti ap

bread – buredi

milk – miliiki

iray – Tiree

station – Tesan

belt – beliiti

 

  1. Ifiropo konsonanti ninu oro ayalo Nigba miirran konsonanti oro Geesi maa n yato si ti Yoruba ap:

Lazarus – lasaru

Church – soosi

Queen – kun-yin

Valve – faafu

Stamp – sitanbu

Cup – koobu

 

  • Ami gbodo wa lori oro- ayalo
  • Oro ayalo lo maa n bere pelu ami ohun oke
  • Faweli aranmupe maa n bere oro ayalo
  • Iwulo oro ayalo
  • Oro ayalo lo maa n mu ki edi dagba
  • Nipa yiya oro lo a maa n ri oruko fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba sese n wo awujo wa.

Ofin ti o de oro ayalo

 

IGBELEWON

  1. Kin ni oro-ayalo?

Ona meloo ni a n gba lati ya oro lo? Salaye won pelu apeere

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

ASA

AWON ISERUN ENI

Akoonu

Awon iserun  eni tumo si baba-nla eni, ti o se iran eni sile tabi ori eni ti iran kan ti bere. Ko si iran kan ni ile Yoruba ti ko ni awon ti o see nitori pe ‘okun ki i gun titi ki o ma ni ibi ti o ti fa wa.

Awon baba-nla wa ti a n toka si yii ti wa nigba iwase, won ti se gudugudu meje ohun yaaya mefa nigba aye  won.

Awon Yoruba gbagbo pe odo ki san ki o gbagbe orisun re, opolopo igba ni won maa n pe oruko baba-nla  fun iyonu  ati aabo nitori pe won gbagbo pe eni to ba ti ku ni agbara nla lati bukun  awon ti won je iran won ni aye.

Akoko odun tabi loorekoore ni a maa n se etutu lati tu awon iserun eni loju fun oore ti won n reti lodo won.

Odoodun ni awon iran miiran maa n bo iserun won tabi nigba ti wahala tabi idarudapo ba wa ninu ebi won.

 

Ebi kookan ni o ni ojubo ti won ti n bo iserun won, o le je agboole tabi ni eyin odi ilu. Iru eyin odi yii le je ibi ti baba-nla won tedo si nigba  iwase.

 

Ogangan ibi ti oku ba kori si ni won ti n se etutu

Orisiirisii ohun jije mimu ni won n bo iserun eni, agbo tabi agutan adie abbl. Won yoo si  ro eje re si oju oori iserun won naa, won yoo da obi, ti o ba si ti yan, o ti  gba niyen, akoko ayeye  ni o maa n je fun gbogbo ebi

 

Ni ile Ijebu Agemo ni  won nse. Awon ni ipinle Eko kii fi Adamu – Orisa sere.

Ila oju, oriki –orile ati isesi iran kookan je eyi ti a fi n da ara wa mo, ti o si n mu iserun eni wa si iranti.

 

Inu oriki-orile ise, ise, iwa, esin, ati eewo iran ni a ti n gbo oniruuru oruko ti an baba-nla wa ti je seyin.

Ap

 

Iran onikoyi je iran jagun, eyi si han ninu oriki ati itan iran won, baba –nla won je jagunjagun.

Iwa akin hihu ko si fi iran yii sile. Iran aagberi ko fe gbagbe oogun abenu gongo.

Iran Olofa kan o je gbagbe ijakadi.

 

IGBELEWON

  1. Ki ni iserun eni tumo si?
  2. Daruko awon iserun ile Yoruba ti o mo.

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

ETO EBI

Ni ile Yoruba, ebi ni a tun n pe ni alajobi tabi molebi. Alajobi ni iya, baba, egbon, aburo ati ibatan eni ni apapo. Eto ebi ni opomulero ti o gbe asa, ise, ati ibara-eni-gbepo awon Yoruba duro. omo nibi-niran ni awon Yoruba. Bi won se tan si ile baba ni won tan si ile iya.

 

Eto ebi bere lati inu ile. Gege bi asa baba ni olori ile, iya ni atele ki o kan awon omo gege bi ojo ori won. Iko kokan ni o ni ipa ti o n ko lati mu ki ife, isokan, laafia ati ajosepo wa ninu ebi.

 

Lara awon ibasepo ti o wa ninu ebi ni:

Ise obi si omo

Ise omo si obi.

Ibasepo laarin omo iya si omo iya

Ibasepo laarin Obakan si Obakan

Ibasepo laarin idile eni ati baba eni

Ipo Baale ati ojuse re

Ipo Iyaale Ile ati ise re

Ipo Obinrin ile

Ipo Orogun

Ipo Omo Osu ati ise won

Ipo Omokunrin Ile ati ise won

Ipo Omobinrin ile

Awon Alejo tabi Alabagbe

 

IGBELEWON

  1. Salaye awon wonyi: Obakan, Iyekan-eni, Omo Osu, Obinrin Ile ati Omobinrin Ile.
  2. Ki ni ojuse Baale Ile? Salaye ni kikun.

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

LITIRESO

Kika iwe ti ajo WAEC yan

IGBELEWON

  1. a. Kin ni iserun eni?
  2. Igba wo ni a n bo iserun eni?
  3. Kin ni a fi n bo won?

 

IWE AKATILEWA

Imo Ede Asa ati Litireso Yoruba  (SS3)  S.Y  Adewoyin 277 – 279

 

APAPO IGBELEWON

  1. Kin ni oro-ayalo?
  2. Ona meloo ni a n gba lati ya oro lo? Salaye won pelu apeere
  3. Salaye awon wonyi: Obakan, Iyekan-eni, Omo Osu, Obinrin Ile ati Omobinrin Ile.
  4. Ki ni ojuse Baale Ile? Salaye ni kikun.

 

ATUNYEWO EKO

  1. Ki ni oro oruko?
  2. Ki ni oro aropo oruko?
  3. Ko iyato merin laarin oro oruko ati oro aropo oruko.

 

ISE ASETILEWA

  1. Awon Iserun eni tumo si (a) Baba-nla eni (b) eni ti o se iran eni sile (d) eni to na omokunrin ile
  2. Inu _______ ni a ti n gbo nipa oniruuru oruko idile (a) oriki orile (b) iwure (d) ofo
  3. Ojubo iserun eni le wa ni _____ ati (a) Inui le (b)agboole (d) ilu odikeji
  4. Ona _____________ ni a le gba ya oro lo ninu ed Yoruba (a) meji (b) meta (d) merin
  5. A ya pasito ni pase _____(a) esin (b) eto eko (d) imo ero

 

APA KEJI

  1. Kin ni oro – ayalo?
  2. Ona meloo ni a n gba ya oro wonu ede Yoruba
  3. Ko irisi awon oro Geesi wonyi sile leyin igba ti a ba ti ya won wonu ede Yoruba

Teacher, Starch, Milk, bread, class, scale, block, trouser, brother, shilling

  1. Kin ni iserun eni
  2. Daruko apeere Iserun eni meta nile Yoruba
  3. Daruko igba ati ohun ti a si n bo iserun eni.
  4. Salaye eto ebi ni kikun.

 

 

OSE KERIN

ISEDA ORO-ORUKO

IHUN ORO (ISODORUKO)

IGBESE

Bi a se n seda oro oruko nipa lilo afomo ibere

AKOONU:-

Iseda oro-oruko je siseda oro-oruko lati ara oro-oruko tabi oro-ise nipa afomo lilo.  Bi  a ba fe seda oro oruko eyi ni awon igbese ti a ni lati tele.

  1. Nipa lilo afomo ibere

Nipa lilo afomo aarin

Nipa sise apetunpe kikun

Nipa sise apetunpe elebe

Nipa sise akanpo oro-oruko

Nipa sise isunki odidi gbolohun

  1. Lilo afomo ibere

A le lo afomo ibere pelu oro-ise tabi lati seda oro-oruko.  Iru oro-oruko bayii gbodo ni ajose pelu oro ise ti a lo pelu afomo.  Awon afomo ibere naa ni a, e, e, i o o u, alai, ai, o ni, oni abbl.

 

Apeere

a          +          yo        =          ayo

a          +          lo         =          alo

a          +          to         =          ato

o          +          ku        =          oku

o          +          bi         =          obi

i           +          to         =          ito

i           +          fe         =          ife

e          +          gbe      =          egbe

e          +          to         =          eto

e          +          te         =          ete

e          +          ko        =          eko

o          +          le         =          ole

o          +          mu       =          omu

i           +          rin        =          irin

ai         +          sun       =          aisun

ai         +          ni         =          aini

ati        +          lo         =          atilo

ati        +          je         =          atije

on        +          te         =          onte

alai       +          gbon    =          alaigbon

alai       +          mo       =          alaimo

oni       +          igi        =          onigi

oni       +          omo     =          olomo

 

  1. A le lo afomo ibere pelu apola-ise eyi ni pe oro-ise ati oro-oruko

Apeere

a          +          ko        +          orin      =          akorin

a          +          ko        +          ope      =          akope

a          +          da        +          ejo       =          adajo

o          +          da        +          oran     =          odaran

ati        +          de        +          ade      =          atidade

o          +          se         +          ere       =          osere

o          +          da        +          oju       =          odaju

 

IGBELEWON

Kin ni iseda oro-oruko?

Daruko ona ti a n gba seda oro- oruko

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA J. S.S.3 Copromutt Publishers.

 

Asa

ETO ISELU ABINIBI ATI ODE ONI

Ipa ti  baale  ile, Iyaale-ile omobinrin ile, omokunrin ile, omo osu n ko ninu eto       isakoso agbo ile ati ebi gbigboona.

 

Eto iselu ni ile Yoruba bere lati inu ile, gege bi asa ,baba ni Olori ile, iya ni atele bee ni awon omo naa ni ojuse bi ojo ori won ba se telera.

Eto agbo-ile ni ipile eto ijoba ni ile Yoruba. Olori agbo-ile ni

 

Baale: ni  eni ti o ba dagba ju lo ni o n je oye yii. Kii se oye ti a maa n du, ti bale kan ba ku ni eni ti o ba tun dagba ju miran yoo je.

 

Baale ni alase ati alakooso agbo ile, Ohun ti o ba so ni abe ge. Ko si eni ti o gbodo fi owo pa ida re loju.

 

Ile maa n to beere ninu agbo ile nla ni won a wa mo ogiri yii gbogbo ile bee ka,       ilekun kan yoo wa ni enu ona  abawole tabi abajade kuro ninu agbo ile.

 

Baale kii gbe eyin odi, aarin agbo – ile ni o maa n gbe lati mojuto gbogbo ohun ti o ba n lo.

Igbejo maa n wa ti won maa n jokoo si lati gbo ejo pelu awon agbaagba bii merin. Omo kekere kan yoo maa fe abebe si baba ni ara.

 

ISE Baale

Ija pipari ni agbo-ile: ti  ede aiyede ba waye ise baale ni lati yanju re. Totun tosi yoo ro ejo, ki in to da ejo, bale lo maa kadii ninu ohun to ba si so ni abe ge.

Fifi omo foko: bi omobinrin ile bafe loko, odede bale ni won yoo ti wule fun-un. Bi iyawo tuntun ba si wole o gbodo de odede baale fun adura.

 

Imojuto omo ile lokunrin ati lobinrin o gbodo mo Ijade at iwole awon odo agbo ile.

Ogun pipin: Odede baale ni won ti n saato bi won yoo se pin ogun fun awon omo oku ni idi igi kookan.

Iyaale: ni Obinrin ti o dagba ju ni iye odun ti won wo ile oko. Oun ni igbakeji bale ninu eto iselu agbo ile.

 

O je asoju ati alamojuto awon iyawo ile ati omobinrin ile.

Ise re ni lati mo igba ati akoko ti a bi omo lati yanju aawo ti o waye nipa ojo ori.

Oun ni yoo toju iyawo asesegbe oyun inu, omo ikoko ati eto ila kiko fun omo tuntun.

Iyaale gbodo ni imo kikun nipa ita idile, oriki ile oko, ti yoo si maa ko awon atele re gbogbo.

 

Omokunrin Ile: ni awon gende okunrin ti won ti laya tabi ki won je odo.

Awon ni bale maa n ran ni ise bi ile oku gbigbe, oko ile riro, ona yiye, oju ogun lilo sisin ibi omo si baluwe abbl awon ni won n pa eran nibi inawo apa eran ni won maa n fun won. Won maa n wa nibi ti bale ti n pari ija.

 

Obinrin ile,! Awon ni iyawo agbo-ile, ojuse won ni lati rogba yi iyaale ka, ki won sa pa ofin re mo.

 

Awon ni won maa n dana ounje ni akoko odun tabi ayeye. Awon ni won maa n sun rara nibi inawo idile oko won.

 

Awon lo maa n se itoju iyawo titun ati iyawo ile to ba bimo.  Awon lo maa n jora fun iya omoawon lo maa n gba eyin eran.

 

Omo osu Ile -: ni awon agba obinrin ti won ti losi ile oko, ti won wa pada wa maa gbe ni ile baba won.

Won maa n ni enu ninu oro ebi, awon lo maa n gba aya eran ti won ba pa.

 

Omobinrin ile-: ni awon omobinrin ti ko tii lo si ile oko.  Won maa n kopa ninu oro ile

 

Ojuse won ni lati lo ki iyaawo ile to ba bimo.

 

IGBELEWON

  1. Salaye lori Bqql3, Bqql2, *j0y4 zti {ba
  2. Salaye lori Ijoba Ibile Ijoba Ipinle ati Ijoba Apapo.

 

ETO ISELU ODE-ONI

Ni aye ode-oni eto iselu ti yato patapata is ti aye  atijo.

Ni aye ode-oni, eto iselu ti aye ode-oni ni a n lo gomina ni Olori ati alase ni ilu kookan ti o si ni awon komisanna ti won jo n tuko eto ilu. Loooto ni awon oba si wa sugbon won ko ni agbara bii ti aye atijo mo

 

Bee naa ni a ni awon alaga fun ijoba ibile ati awon Kanselo fun agbegbe ti won n ri si idagbasoke ilosiwaju agbegbe won nigbat ti olori orile –ede je olori patapata fun orile-ede, ti ohunkohun ba sele ni ipinle Olori-onle-ede ni won yoo ti to leti, ti o ba si je ni agbegbe tabi adugbo ni kaunselo a fi to alaga leti, ti apa alaga ba kaa yoo see sugbon ti o ba ju agbara re lo, o fi to gomina leti ise naa yoo si di sise.

 

Ti o ba ju agbara gomina lo, oun naa a fi to Olori Orile-ede leti

Ajosepo to dan moran si wa laarin ijoba ode-oni pelu awon oba nitori pe gbogbo won jo n sise po fun idagbasoke, alaafia ati ilosiwaju ilu ni.

Bee naa ni a ni Orisiirisii awon alamojuto to n ri si or nipa awon obinrin, odo eto nipa oro aje, ayika, eto irinna, ina monmona abbl. Omi  ero.

Eto abinibi is n tesiwaju ni awon igberiko wa sugbon ko fi bee fese rinle mo bii ti aye atijo.

Fun tie to idajo-ni aye ode oni a ni ile ejo ni ti adajo yoo ti dajo bee ni awon soja, Olopaa, Omo ogun oju omi ati ti ofurufu fun idaabobo ilu in aye ode-oni.

 

IGBELEWON

  1. Salaye lori Bqql3, Bqql2, *j0y4 zti {ba
  2. Salaye lori Ijoba Ibile Ijoba Ipinle ati Ijoba Apapo.

 

APAPO IGBELEWO

  1. Seda oro oruko 10 nipa: afomo ibere.
  2. Seda oro oruko 10 nipa afomo aarin
  3. Seda oro oruko 10 nipa apetunpe.

 

ATUNYEWO EKO

  1. Fun awon oro oruko yii ni apeere mejimeji: afoyemo, ibikan, asonka, alaisonka. Aridimu.
  2. ko apeere oro aropo oruko: eni kin-in-ni eyo oluwa. Enikeji opo oluwa, eniketa eyo opo.

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

ISE AMURELE

  1. Aseda ife nipa lolo ____________________________

(a)        afomo aarin     (b)        afomo ibere     (d)       apetunpe

  1. Afomo ibere ninu alaigbon ni ________________

(a)        ala                    (b)        alai                   (d)       gbon

  1. Nje awon Yoruba gbagbo ninu iye leyin iku

(a)        rara                  (b)        won gbagbo

  1. Awon ___________________________ni won maa n ku pelu Oba laye atijo ki o ba le ri won ran nise ni ile ibomiran ti o ba ja si.

(a)        Abobaku         (b)        eru                   (d)       ara ile oba

  1. ___________________ni a n pe eni ti o ti ku, ti o tun lo si ile ibomiran

(a)        ayorunbo         (b)        Akudaaya        (d)       eni irapada

APA KEJI

  1. Awon ona wo ni a le gba seda oro-oruko ninu ede Yoruba?
  2. Lo afomo ibere lati seda oro-oruko marun-un
  3. Nje awon Yoruba gbagbo ninu iye leyin iku

 

 

finfin: Ara finfin je okan lara oge sise ile Yoruba.Oloola (awon to maa n ko ila fun eeyan ) ni o maa n se ara finfin fun eeyan. Won le ya orisiirisii batani si ara eniyan bi alangba, Ooya idirun tabi akekee. Gbogbo nnkan won yii ni won n lo lati bu kun ewa  ara won.

 

Eyin Pipa: Eyin pipa ni asa ki a da iho tabi alafo si aarin eyin meji to wa laarin gbungbun enu. Awon Yoruba gba pe eni ti o ba ni eji maa n ni ewa. Awon oloola ni o maa n se eyi pelu.

 

Tiroo: Awon obinrin ni ni o maa n le tiroo ju. Won yoo maa fi igi iye ediye le si oju. O maa n wulo fun oju pipon ati eyikeyi arun oju. Awon iya olomo naa maa n lo o fun omode, ero won ni wi pe o maa n mu idoti kuro loju.

 

Laali: Awon obinrin maa n le laali si atelewo ati egbeegbe ese won mejeeji. Bi o ba gbe tan won yoo ko ewe laali yii kuro ni oju ibi ti won ti koo kuro yi maa n dudu lati bu kun ewa won.  Iru eyi maa n wopo ni Igbomina/Ilorin ati eya Hausa.

 

IGBELEWON:

  1. Kin ni oge sise?
  2. Ko ona merin ti a n gba soge laye atijo.

 

IWE AKATILEWA:

1          Eko ede Yoruba titun (SSS) iwe kin-in-Eko ede ati asa Yoruba iwe kin-in-ni (JSS 1) oju iwe 90 – 93 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

2          Eko ede Yoruba titun iwe kin-in-ni (J S S1 ) oju iwe 153-158 lati owo Oyebamji Mustapha.

 

 

APAPO IGBELEWON

  1. Fa 8lz s7 8d7 =r= 8se n7n5 zr0k[ y87:

On7r5ur5 kzy34f8 ni 9 k5n il3 ay3. Ol9w9 zti tql7kz l[ s6z. {l-gb-n 0un 0m6g= l[ bi r1rc. Ibi 8gb7n ti n sunk5n z8l9r7 ni zjznzk5 ti n pariwo or7 t7t9bi. Cni in5 n run n jow5 cni or7 n f-. Il3 ay3 y87 nqz ni K-l3dow9 ti bi [m[ m1j[ t7 Oy7b9y7 fi w[n dqj[, t7 8yq ol9w9 y[y[ wq di zgzn =sqn-an-gan.

  1. Salaye lori oge sise abinibi ile Yoruba.

 

ATUNYEWO EKO

  1. Salaye lori aseyinwaye.
  2. Salaye lori asa eewo nile Yoruba.
  3. Salaye lori eto abinibi nie Yoruba.

 

ISE ASETILEWA

  1. _____ ni opomulero fun gbolohun (a) oro-oruko (b) oro-ise (d) eyan
  2. E rowa ro ire je apeere oro-ise _____ (a) asoluwadabo (b) alapepada (d) agbabo
  3. Sola da obe nu. Oro_ise iru gbolohun yi ni (a) da (b) obe (d) danu.
  4. Awon wo lo maa n lo laali ju? (a) obinrin (b) okunrin (d) omode (e) arugbo
  5. Idi ti won fi maa n korin nibi ikomojade ati igbeyawo ni _________ (a) ounje jije (b) nitori ilu lilu ti o wa nibe (d) nitori a ki i saba korin lojoojumo (e) inu didun

 

APA KEJI

  1. Salaye iyato meta laarin oro aropo oruko ati oro aropo aafarajoruko.
  2. Salaye iyato marun-un laarin oro oruko ati oro aropo oruko.
  3. Ko orisii ila marun-un ti awon Yoruba n ko.

 

OSE KEFA

ETO IGBEYAWO ABINIBI

AKOONU   

  • IFOJUSODE
  • ALARINA
  • IJOHEN/ISIHUN
  • ITOORO
  • IDANA

ASA IGBEYAWO ATIJO (IBILE)

IGBESE IGBEYAWO                                 ALAYE

Ifojusode                    Awon obi okunrin yoo maa fi oju sile wa obinrin.

Iwadii                         Won yoo se iwadii idile obinrin naa ni aarin ilu. Won yoo tun se,

iwadi lowo ifa.

Alarina                       Alarina ni won yoo maa ran si ara won (oko ati Iyawo afesona), Boko ba

moju aya tan, alarina a yeba.

Isihun/ijohen Gbigba ti obinrin gba lati fe okunrin.

Itoro                            Awon ebi okunrin yoo wa toro omobinrin ni owo obi re.

Baba gbo, iya Awon ebi mejeeji gbo, won si gba pe ki obinrin ati okunrin fera

gbo 

Idana                          Ebi oko yoo gbe eru idana lo fun ebi omobinrin ti ojo igbeyawo won

ba ku feere. Isu ogoji, orogbo ogoji, obi ogoji.

Ifa iyawo                    Baba iyawo yoo difa ni aaro ojo igbeyawo lati mo ile oko naa yoo se

ri boya yoo san sowo somo.

Ojo igbeyawo Ale ni awon ebi ati ore iyawo yoo ba a palemo, won yoo sin iyawo lo

si ile oko pelu orin ati ijo titi yoo fi de enu ona oko re.

Ese iyawo                   Ni enu ona abawole won yoo fi omi we ese iyawo naa.

wiwe

 

Ibale                            Ti iyawo ko ba ti i mo okunrin kan ri, ti oko re ba a nile, oko yoo gbe

ekun agbe emu tabi ile isana kikun ranse si obi iyawo pelu owo ibale.

 

IGBELEWON

  1. Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi
  2. Se alaye ise alarena
  3. Kini ijohen tabi isihun tumo si?
  4. Kini iyato laarin itoro ati idana?

 

IGBEYAWO ODE ONI            DEETI……………………

 

AKORI ISE:                                                                                 

AKOONU:-

  • IGBEYAWO SOOSI
  • IGBEYAWO MOSOLASI
  • IGBEYAWO KOOTU

Lode oni, aye ti di amulumala. Orisirisii ona ni a n gba gbe iyawo.  A n gbe iyawo ni ile Olorun, a n gbe e ni kootu, a si n gbe ni mosalasi.  Igbeyawo soosi yii fese mule laarin awon onigbagbo, igbeyawo mosalasi si mule laarin awon musulumi.

 

Igbeyawo soosi ni eyi to maa n waye laarin awon elesin Kristeni ninu ile ijosin won, sugbon ki eto igbeyawo yii to waye ni won yoo ti maa kede eni to ba ri idi ti won ko le fi so oko ati iyawo naa papo ko tete wa so bi bee ko, ki eni be gbe enu re dake laelae.  Bi won ko ba tiri enikeni ko yoju ni won to le so awon mejeeji po.  Iru igbeyawo yii ko faye gba ju iyawo kan lo.

 

Igbeyawo mosolasi maa n waye laarin awon musulumi, eyi faye gba ju iyawo kan lo nitori won  ni “me” ni Olorun wi, ti agbara eniyan ba ti kaa.  Awon musulumi a maa fi omo se saara lai je pe onitohuni fi okan sii tele eyi ni pe ki won fun eniyan ni iyawo lairo tele (ki won fun eeyan ni iyawo ofe).  Eyi ni won naa n pe ni iyawo saara.

 

Orisii igbeyawo yii fese mule daadaa nile Yoruba nitori esin igbagbo ati Isilamu to fese mule lode oni.  Gbogbo ilana lati ibi itoro titi de idana maa n saba je eyi ti a n tele.

 

Awon loko laya miiran a ma n se igbeyawo alarede ti o je pe won a lo si olu ile-ise ijoba ibile tabi Kootu lati fowo si iwe ase lodo ijoba, won a si fi bee gba oruka arede.  Eleyii naa ko faye gba ju iyawo kan ati oko kan lo.Igbeyawo kootu ni a n pe e.

 

Ni aye ode oni ko si ohun to n je ekun iyawo mo, opolopo awon wundia iwoyi ni won ti daju, gbogbo won ni oju n kan lati lo ile oko.  Ko tile sohun to fe pawon

lekun nitori won ko ka ile oko si ohun babara.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Salaye lori igbeyawo aye ode oni
  2. Ko iyato meta laarin igbeyawo aye ode oni ati aye atijo.
  3. Salaye lori ise ode

 

ISE ASETILEWA

  1. Awon………….. lo n se igbeyawo soosi (a) Musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
  2. Awon …………………………lo n se igbeyawo Mosolasi (a) musulumi (b) Igbagbo (d) Aborisa.
  3. Awon ……………………………lo maa fi omo se saara (a) Onigbagbo (b) Alarede (d) Musulumi
  4. Awon to maa n fe iyawo ju eyo kan lo lode oni ni (a) musulumi (b) soosi (d) kootu
  5. ‘titi iku yoo fi ya won’ inu inu irufe igbeyawo aye ode oni wo ni eyi je mo?. (a) musulumi (b) soosi (d) kootu.

 

APA KEJI

  1. Kini a n pe ni idana ninu eto igbeyawo nile Yoruba
  2. Kini ijohen, lati odo tani ijohen ti n wa?