Jss 1 Yoruba Asanya Iwe Kika
Ayanse Iwe
Kika:
Ninu
iwe kika ede Yoruba Titun J.S.S. Iwe kinin ni, Ek[ ò, ni oju ewe k[kanlelogoji,
ka b[ lati ile.
EKA ORI – ORO 3 Deeti
______________________
ORIKI LITIRESO
Litireso ni akojopo oro ogbon ati oro
ijinle to n fi ise, asa, esin ati ihuwasi awon akojopo eniyan kan han. Awon
oro ogbon yii le wa lagbari awon eniyan naa tabi ko je eyi ti a ko sinu iwe.
Die lara
ona ti awon oro ogbon wonyi ti maa n jeyo lawujo awon Yoruba nigba laelae
niwonyii:
1. Awon
ipede babalawo nigba to n ki ifa
2. Oro
ijinle to n suyo lenu eegun nigba to n pesa
3. Awon oro idagbere ati
igbare lenu obi ti iyawo tuntun to n lo sile oko re maa n sun.
4. Orisirisi oriki; orile
ati orin fun idaraya nibi orisirisi aseye.
IGBELEWON – 1. Kin ni oriki litireso ?
2. Daruko meta ninu ona
ti oro ogbon ati oro ijinle awon Yoruba se n jeyo ninu Igbe-aye ojoojumo won?
AWON IWE FUN KIKA LATI ILE
1. Ijinle ede ati
litireso iwe kiini: Olu Owolabi; Bayo Aderanti, Taiwo Olunlade, Afolabi
Olabimtan,
2. Eko ede Yoruba
ode-oni (1):
3. Akomolede Ijinle
Yoruba (1): Adebisi Aromolaran Oyebamiji Mustapha Macmillan Nig. Pub. Ltd.
1974 oju-ewe 5-6.
4. Eko ede ati asa
Yoruba: Alhaji Oyebamiji Mustapha, Omowe Dele Ajayi, Diipo Gbenro, 2001
ojue-ewe 1-2, 11-12, 34-35, 39, 55-57, 61-62.
ISE ASETILEWA FUN OPIN OSE
IPIN A
1. ______ ni iro ti ki i
si idiwo fun eemi inu edoforo nigba ti a pe e
2. Iro faweli aranmupe
meloo lo wa ninu ede Yoruba?
3. Iro faweli airanmupe meloo
lo wa ninu ede Yoruba?
4. ______ ni iro ti idiwo
maa n wa fun eemi inu edoforo nigba ti a n pe e.
5. Ta ni baba Yoruba?
6. Ibo ni orirun awon eya
Yoruba
(a) Ketu (b) Oyo ile
(d) Ile – Ife (e) Ibini.
IPIN B
i. Kin ni Oriki
litireso?
ii. Se isonisoki itan bi
Oduduwa se fi Meka sile wa tedo si Ile – Ife.
_______________
oro onisilebu kan (nipa aropo konsonanti ati faweli)
– Ile-Ife
saaju dide Oduduwa ati idagbasoke ti Oduduwa mu
– sisori Litireso (Irufe litireso to wa).
IHUN ORO ONISILEBU KAN
Yoruba
kii saaba pe iro konsonanti tabi faweli ni otooto nigba ti won ba n soro.
Sugbon won maa n toka si won gege bi won ti wa ni ege-n-ge ninu afo won.
oro ti a le pe jade lenu lori isemii kan ni Yoruba n pe ni silebu ninu eto
amulo iro ede. (ti a n pe ni fonoloji).
Oro Yoruba kan le ni
silebu kan tabi ki o ni ju silebu kan lo. Ihun die lara oro Yoruba to je
onisilebu kan maa n saaba je aropo konsonanti ati faweli. Iru faweli ti a o
kan po mo konsonanti naa le je airanmupe tabi aranmupe bi apeere:
(1) K + F
Airanmupe = oro onisilebu kan
O = LO
e = Se
Aranmupe = oro onisilebu kan
K + un = Kun
IGBELEWON – 1. Kin
ni oruko ti a n pe ege oro ti a le pe jade lenu lori isemii
kan?
2. Se
akosile orisi oro mefa toje onisilebu kan labe ihun K + F.
EKA ORI – ORO 3 Deeti______________
IPIN – SISORI LITIRESO
Siwaju
ki awon Yoruba to ni imo mimo on ko mo on ka, awon Geesi so pe won ko ni
litireso. Amo sa oro ogbon ati oro ijinle to n fi asa, ise, esin ati ihuwasi
awon Yoruba han. (eyi ti a n pe ni litireso) wa ninu agbara won, ti won si n fi
ohun enu gbe e kale ni igba laelae bee si ni opo awon nnkan wonyi ni a ti ko
sinu iwe ti eniyan le ka lode-oni.
Pelu alaaye oke yii,
a le so pe irufe litireso Yoruba to wa pin si ona meji (1)
Litireso alohun ati (2) Litireso apileko orisi litireso Yoruba mejeeji yii ni
a tun le pin si isori meta wonyi (1) Ewi (2) Itan aroso/oro geere ati (3)
Ere – onise, bi apeere :
Ewi Oro
geere / itan aroso Ere – onise
APILEKO
Ewi
Oro geere / itan aroso Ere – onise
O se pataki ki akekoo
mo pe siso lenu ati kiko sile sinu iwe ni koko iyato to wa laarin litireso
alohun ati litireso apileko.
IGBELEWON – 1. So ona meji
ti a le pin litireso si?
2.
Kin ni iyato gbogi to wa laarin litireso alohun ati apileko?
3.
Kin ni idi ti awon Geesi se so pe Yoruba ko ni litireso nigba kan ri?
AWON IWE FUN KIKA LATI ILE
1. Akomolede
Ijinle Yoruba (1) Adebisi Aromolaran, Oyebamiji Mustapha Machillan Nig. Pub.
Ltd. 1974 oju ewe 5.
2. Ijinle
ede ati litireso iwe kiini: Olu Owolabi, Bayo Aderanti, Taiwo Olunlade,
Afolabi Olabimtan, Evans Nig. Pub. Ltd. 1985 oju ewe, 82 – 83, 63.
3. Eko
ede Yoruba ode – oni (1) Ade Adeeboyeje, Yiwola Awoyale, Tunde Ekundayo,
Martina oni. Macmillan Nig. Pub. Ltd. 1986 oju – ewe 5, 6-7.
4. Eko
ede ati asa Yoruba. Alhaji Oyebamiji Mustapha, Longman Nig. Plc 2001 oju-ewe
62, 64-65, 73-74.
ISE
ASETILEWA FUN OPIN OSE
IPIN
A
1. Silebu
meloo lo wa ninu oro yii? “f5n”
2. Ta
ni itan so pe Olodumare koko ran wa lati wa be aye wo?
(a)
Agemo (b) Oduduwa (d) Orunmila (e) Obatala
3. Kin
lo di obatala lowo lati ko iko re de ile-aye?
4. So
eya/ipin meta ti litireso Yoruba le je boya alohun tabi apileko.
5. Nibo
ni awon Yoruba fi se aka tabi ibi isura fun litireso alohun ni igba laelae.
IPIN
B
1. Kin
ni ero tire lori oro yii pe Yoruba ko ni litireso siwaju mimo on ko mo on ka?
2. Kin
ni oriki silebu ede Yoruba?
3. (i) Se
Isonisoki ipo ti ile-ife wa siwaju dide Oduduwa.
(ii) Ona
wo lo gbe mu idagbasoke ba awujo naa.
OSE 3 Deeti__________________
ORI
– ORO ATI
AKOONU
ISE – Ilana kiko awon iro ti ko ni itumo ati oro ti a kanpo
– Eya
Yoruba ati ibi ti won tedo si
– Ibasepo
litireso ati ede ojoojumo.
ILANA KIKO AWON IRO TI KO NI
ITUMO ATI ORO TI A KANPO
Ilana kiko ede kan
sile lona to se itewogba fun gbogbo elede naa ni a n pe ni Akoto. Ki awon
oyinbo to de ko si eto kiko ati kika ede Yoruba. Gbogbo oro ogbon (ti an pe ni
litireso) to maa n suyo ninu ewi itan ati ere onise awon Yoruba wa ninu agbari
won.
O fere je pe bi awon
ojise olorun se n wo orile-ede wa ni akitiyan kiko ede Yoruba sile ti bere ni
perehu. Orisirisi igbimo lo sise lori akoto ede Yoruba sugbon abajade igbimo
Odun 1974 ni ile – ise eto eko ijoba apapo orile-ede yii fowo si.
Igbimo yii se atunse kiko iro
ti ko ni itumo ninu oro bi apeere aiya, eiye, otta offa abbl. Akiyesi won ni
pe bi a ba se pe oro gan-an ni a gbodo se koo sile ati pe eyi yoo mu ki kika
oro naa rorun yoo si ye ni yeke. Nitori naa awon iro faweli ti ko ni itumo
ninu awon oro wa ni a ko gbodo ko mo, bee ni a ko gbodo ko asupo konsonanti.
Apeere ilana kiko iro faweli
ati konsonanti laarin oro Yoruba.
Atijo | Ode oni |
Aiye | Aye |
Offa | Ofa |
Otta | Ota |
Eiye | Eye |
Taiye | Taye |
Igbimo yii tun se
akiyesi awon oro kan ti a maa n ko papo sugbon ti ko ye ki a maa ko won papo
bi apeere wipe, ibiti, jeki, tani nlo mbo abbl. Wo apeere bi a se n ko awon
oro naa tele ati bi a se n ko o lode – oni.
Atijo Ode-oni Atijo Ode-oni
wipe
wi pe nlo n lo
jeki
je ki mbo n bo
Tani
Ta ni Ibiti Ibi ti
IGBELEWON (1) Kin ni
akoto (2) Ko awon oro wonyi ni ilana akoto ode-oni nigbati, beeni,
oshogbo.
EKA ORI – ORO 2 Deeti________________
EYA YORUBA ATI IBI TI WON TEDO SI
Eya Yoruba po ju
eyi ti eniyan kan le so pe oun mo won tan lo; Sugbon awon to han si gbangba
ninu won ni Egba, Yewa, Ondo, Ijesa, Ife Oriko Oyo, Ekiti Igbomina, Ikale,
Awori, Owo Ijebu akoko abbl. Yato si awon to wa ni ile – Nigeria, ogunlogo
won wa kaakiri agbala-aye bii ile saro, Gana, Togo, Bini Amerika Burasiti,
Jamaika ati erekusu to yi okun atilantiki ka. Lakootan Oduduwa lo se gbogbo awon Yoruba sile lati
ile ketu to n be ni orile-ede bini titi o fi de Ado ibini to n be leti odo oya.
Bi a se so tele nipa itan
isedale Yoruba pe lamurudu ti ile meka lo bi Oduduwa ati pe Okanbi omo Oduduwa
lo bi awon oba alade meje to se awon Yoruba.
Akobi omo Okanbi iyen iya olowu
gbe omo re Okunrin lo ki Oduduwa baba nla re to si n fa mo ade ori re, ni o ba
fi dee lori ti omo naa si gbagbe sun lo toun tade lori. Awon eya Yoruba yii lo
tan de gbogbo ibi a ti le ri awon owu omo a-sunkun gbade lonii.
Alaketu omo keji fi
ile-ife sile, o gba apa iwo oorun ife lo. Awon eya yii ni a le ri kaakiri ile
ketu ni ketu ti orile – ede bini, imeko, idofa, igan alade abbl. Eketa to je
oba edo ibini lo tedo si ile bini titi di oni. Ekerin Orangun ile-ila tedo si
ile ila nigba ti onisabe ti n se ikarun-un tedo si sabe to wa ni orile-ede
bini. Ikefa ti n se oluupopo ni awon kan gba pe o se awon egun, Aganyin,
Anago, Gaa ati Aigbe sile. Ikeje ti n se Oranmiyan lo te oyo ile do, oun si ni
o se opolopo awon iran ile kaaro-oojiire yoku sile.
Itan miiran so pe
Alake oba egba ati owa obokun ti ile ijesa wa ninu awon omo Oduduwa. Ninu itan
naa omonide iya awon omo Oduduwa ku si aafin Alake ati pe oru agbo too fi to
awon omo re dagba wa ni aafin Alake titi di oni. A tun gbo pe Owa Obokun ni
Oduduwa ran lo bu omi ati yanrin okun lati fi la oju Oduduwa nigba ti ko riran.
IGBELEWON
–
1.
(i) Daruko meta ninu awon ipinle to wa ni orile-ede yii ti a ti le ri
awon eya Yoruba (ii) Daruko
eya Yoruba meta meta tabi awon ipinle ti o menu ba ni (1)
2. Se akosile oruko awon mesan-an
ninu awon oba Alade ti itan so
pe won je omo Oduduwa ati eya
Yoruba ti okookan won se.
AKOONU
ISE – Ilana kiko awon oro ti faweli inu re ko pe ati isepataki
yiyanmo sidii leta
lona to to.
–
Eya Yoruba: Ounje
won ati awon nnkan to se pataki nipa won
–
Yoruba.
KO PE ATI ISEPATAKI YIYANMO SIDII ORO LONA TO TO.
1974 tun so pe ki a ma se ko ami faagun / / eyi ti kii je ki faweli inu oro
pe. Dipo eyi, ki a maa ko iye faweli ti a ba pe jade ninu oro. Ti a ba se
bee, yoo mu ki oro naa rorun lati pe ki itumo re si ye ni yeke, bi apeere
Yato si eyi, igbimo naa tun pereke lu isepataki
yiyanmo sidii oro ni ona to to. Won
so pe ki a maa fi iru si idi oro bi apeere.
o
e
s
(Dooti) /./ sugbon ki a ma fa ila ibu si i nidii (Daasi) /_ /eyi ko tona rara
bi apeere
Atijo Ode-oni
e
e
s
s
Idi ti won fi so bee ni pe Ila
Ibu ti a ba fa soro nidii le farasin lori ila to wa ninu iwe ti a n ko oro naa
si sugbon iru ti a ba fa si oro nidii tabi omo ti a kan sii ko le farasin se
gongo lo maa yo sile labe oro naa.
IGBELEWON :- (1) Ko
awon oro wonyi ni ilana akoto ode-oni Alafia arin.
(2) Ewo
ni a ko ni ilana akoto ode-oni (a) oorun (b) orun
(d)
orun (e) orun.
EKA ORI ORO 2 Deeti_______________
EYA YORUBA: OUNJE WON ATI
AWON NNKAN TO SE PATAKI NIPA WON
Itan fi ye wa pe ibi
kan naa ni gbogbo awon ti a mo si Yoruba lonii ti se, ati pe ede kan ni won n
so nile pepe, Sugbon won ti fon kaakiri lori ile aye. Adugbo kookan lo ni eka
ede tire to yaa soto si awon Yoruba yoku bi apeere ni ipinle meje ti
kaaaro-oojiire to wa lorile ede yii, a le ri awon eka-ede Yoruba wonyi.
1. Ogun =
Egba – Owu – Egba
Yewa – Ketu – Yewa – Awori
Ijebu
– Remo – Ijebu – Ode
2. Osun = Osun
– Ijesa – Ife – Igbomina
3. Oyo = Oyo
– Oriko – Ibarapa
4. Ondo = Akure
– Akoko – Owo – Ikale
5. Eko = Awori
– Egba – Ijebu
6. Kuwara = Ilorin
– Igbomina
7. Ekiti = Ekiti
– Ado – Aramoko
Yoruba ajumolo ni ede
kan ti o ye teru tomo ni gbogbo ile kaaaro – oojiire. Ede naa si ni ile-ise eto
eko ijoba apapo ile wa fowo si fun kiko ati sise igbelewon awon akekoo lori ede
Yoruba.
Awon eka-ede kookan
ati awon ounje ile-wa to gbajugbaja laarin won:
Egba – Lafun
Ijebu – Ikokore
Oyo – Oka
Ijesa/Ekiti – Iyan
Ilorin – Tuwo
Eko – Eja
Ondo – Aja
IGBELEWON
:- (1) Daruko eka ede meta ti a le ri ni ipinle osun ni orile-ede
Naijiria.
(2) Ewo
ni kii se eka ede ti a le ri ni ipinle ogun (a) Onko (b) Yewa (d) Ketu (e)
Awori.