ORUKO ABISO
Subject : Yoruba
Class: SS 3
TERM: FIRST TERM
WEEK: WEEK 10
OSE KEWAA
ORO-ORUKO
– oriki
– orisiirisii oro oruko.
– ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.
– lilo oro oruko ninu gbolohun.
AKOONU : –
Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa, abo tabi eyan ninu gbolohun. AP.
Baba ko ebe.
Tolu fo aso.
Mama se isu ewura.
EYA ORO ORUKO/ORISII ORO ORUKO.
- ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan, eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je mo eniyan. Ap
-Rotimi
– Dele
-Ahmed
– Dokita
– Iyalaje…abbl
- ORO-ORUKO ALAISEEYAN: -Eyi ni oruko to n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP.okuta,iwe, ewure,omi,iyanrin,bata abbl.
- Oro-oruko le je ohun Elemi : – Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.
- Oro-oruko le je ohun Alailemii: – Eyi ni awon nkan ti ko ni emi.ap iwe,ile,bata,ewe,igi,abbl.
- Oro-oruko le je ohun Aridimu : – Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan.apewa,eja,isu,tabili,sokoto,aga,ewedu,abbl.
- Oro-oruko le je oruko Ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won.Ap ibo lo n lo? Osodi,Meka,Soosi.
- Oro-oruko le je ohun Afoyemo : – Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nip aero opolo.Ap ogbon,ilera,ero,ife,alaafia,igbadun,wahala,imo.
- Oro-oruko le je Aseeka : – Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile,ilu,eniyan,iwe,tatapupu.
- Oro-oruko le je Alaiseeka : – Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka Ap Iyanrin,epo,omi,afefe,gaari,irun.
- Oro-oruko le je oruko Igba : – Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han.Ap Aaro,ana,odun,irole,oni,ola,ijeta.
IGBELEWON
- Ko eya oruko mewaa sile.
- Fun marun-un ni apeere mejimeji.
ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN
Ona meta pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun, o le sise:
i.Oluwa,
- abo
iii. eyan.
OLUWA: ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun. ap
Baba ko ebe.
Bola fo aso.
ABO: ni eni tabi ohun ti a se nnkan si,ap
Mama n se obe
Bolu ko leta.
EYAN: ni o maa n se afikun itunmo fun oro-orukoap
Mama se obe eja yiyan.
IGBELEWON
- Ko ise oro oruko ninu gbolohun sile ki o si fun ni apeere mmetameta.
- Bola se isu ewura.
Ona miiran ti a tun le gba da oro oruko mo ni pe
Oro-oruko maa n gba oro aropo bii eyan, ap:
‘oro yin ni a sese so tan yii.’
‘ile re ni mo n lo.’
Oro-oruko le see lo fun sise akiyesi alatenumo ti a ba gbe saaju wunren ‘ni’ap
‘iwe ni mo ra.’
Rira ni mo ra iwe yii.
ORO AROPO ORUKO.
- Oriki
- Abuda oro aropo oruko
- Ate oro aropo oruko
- Irisi oro aropo oruko.
AKOONU
Oro aropo oruko ni a maa n lo dipo oro-oruko ninu apola oruko.apeere
‘Bolu je akara.
‘O je e.’
‘ewure je agbado Bola’
‘ewure je agbado re.
Abuda Oro Aropo Oruko.
- Oro aropo oruko ni eto to n toka si iye bi eyo tabi opo.apeere
O lo [ eyo ni o ]
Won wa [ opo ni won]
- oro aropo oruko ni eto to n toka si eni.apeere.
enikinni /eyi ni eni ti o n soro.
Enikeji / eyi ni eni ti a n soro sii.
Eniketa / eyi ni eni tabi ohun ti a n soro re.
Mo ko leta.
O ko leta
O ko leta.
- Oro aropo oruko ni eto ipin si ipo.
IYE Eyo Opo
Enikin-in-ni mo a
Enikeji o e
Eniketa o won.
- A ko le fi oro-asopo so oro aropo oruko meji papo.apeere
mo ati o
wa ati won.
- A ko le lo oro aropo oruko pelu da ati nko,ni,ko.apeere
mo n ko?
E da?
O ko?
- A ko le lo eyan pelu oro aropo oruko.apeere
mo naa
e gan-an
IGBELEWON
- Kin ni oro aropo oruko?
- Salaye isori oro aropo oruko mejo pelu apeere.
- Salaye abuda oro aropo oruko.
IRISI ORO AROPO – ORUKO.
Ona meta Pataki ni a le gba lo oro aropo oruko ninu gbolohun.
- O le sise oluwa
- Abo
- Eyan ninu gbolohun.
Ipo oluwa; – oro aropo oruko maa n sise oluwa ninu gbolohun,
ENI EYO OPO.
Enikin-ni mo a
Enikeji o e
Eniketa o won
Apeere;-mo n jo
O n jo
Won n jo
E n jo
A n jo.
Ipo abo : – oro aropo oruko maa n sise abo bakan naa ninu gbolohun.
Eni Eyo Opo.
Enikin-in mi wa
Enikeji o/e yin
Eniketa fifa oro ise gun won
Oro-ise.
Baba na mi.
Bolu n pe o/e
Oluko pe e.
Oba ri wa.
Ipo eyan : -oro aropo oruko maa n ni ipo eyan ninu gbolohun.
ENI EYO OPO.
Enikin-ni mi wa
Enikeji re/e yi
Eniketa re/e won.
Apeere; –
Aja mi
Aja re
Aja re
Ile wa
Aso yin
Aja won.
Oro – Ise
ASA
Ori-oro:- Oruko Ile Yoruba
Akoonu
Oruko se pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii si deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.
Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.
- Oruko amutorunwa
- Oruko abiku
iii. Oruko Inagije
- Oruko abiso
Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii.
Ap
Oruko amutorunwa:-
Ige Omo ti o mu ese waye
Aina Omobinrin ti o gbe ibi korun.
Ojo Omokunrin ti o gbe ibi korun.
Oke Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won ma
anta si ara apo naa, ki o to le tun
Oke Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.
Dada Omo ti irun ori re ta koko.
Ilori Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun
Oni Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi
Babarinsa Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.
Abiona
Oruko abiku: Oruko ti a fun omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.
Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap
Oruko Itumo
Durojaye – Ki o duro ni ile aye je igbadun
Rotimi – Duro ti mi, ma se fi mi sile.
Malomo – Duro si aye, ma pada si orun mo
Kosoko – Ko si oko ti a o fi sin oku re mo
Kasimaawoo – Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.
Bamitale – Duro ti mi di ojo ale
Aja – Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.
Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.
Eyinafe: Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.
Ajisafe: Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise
Peleyeju: Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.
Oginni: Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.
Oruko Abiso: eyi ni awon oruko ti o n toka si ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bi.
Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.
Ipo Oruko abiso
Oba Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.
Eleegun Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi
Jagunjagun Akintola, Akinkunmi, Akindele
Onisona Onajide, Olonade
Elesin Ifa Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde
Onisango Sangobunmi, Sangodele
Orisa Oko/Idobatala Efunjoke, Opakunle, Soyinka.
Orisa Ogun Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.
Oruko to n tokasi ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.
Oruko Itumo
Ekundayo Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.
Olabode Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.
Tokunbo Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile okeere ti won gbe wa ile.
IGBELEWON
- a. Kin ni Oruko?
- Daruko orisii oruko ti o wa.
LITERESO
Ori-oro: Sise itupale iwe ti a ka
– Eko ti a ri ko.
asa Yoruba ti o je jade
Awon eda itan.
IGBELEWON
- Salaye awon oruko amutorunwa wonyi.
- Dada
- Oke
iii. Ilori
- Aina
- Salaye awon isori-oro wonyi pelu apeere.
- oro-oruko
- oro – ise
APAPO IGBELEWON
- Pelu apeere salaye Igbagbo awon Yoruba ni pa aseyinwaye ati abani-eda.
Ni kukuru, salaye iran kokanla si ekejila.
ISE SISE
- Ko oruko amutorunwa merin]
- Salaye awon iro yii g, t, s, b, f ati j.
IWE AKATILEWA
- Imo, Ede ASA ati Litireso Yor. SS2 o.i 34, 37, 18, 20
ISE ASETILEWA
- O je oro aropo oruko (a) enikninni eyo (b) enikeji opo (d) eniketa eyo
- Aja je apeere oruko ____ (a) abiku (b) amutorunwa (d) Inagije
- Omo ti won bi sile ti o n kigbe laisinmi ni _____ (a) ojo (b) oni (d) oke
- E row a ro ire, oro-ise inu gbolohun yii ni ____ (a)agbabo (b)Asapejuwe (d)alapedada
- Okan lara asa Yoruba ti o je yo ninu iwe Adakedajo _____ (a) Igbeyawo (b) Isomoloruko (d) oye jije
APA KEJI
- Salaye isori oro-oruko marun un, oro-ise pelu apeere mejimeji fun ikookan.
- Kin ni oruko?
- Daruko orisii oruko ti o wa pelu apesere meji meji fun ikookan.