ÀRỌKO ONIROYIN

Subject : Yoruba

Class: SS 3

TERM: FIRST TERM

WEEK: WEEK 6

OSE KEFA

AROKO ONIROYIN

Akoonu:

Aroko Oniroyin:- je mo iroyin sise tabi itan isele ti o ti koja seyin ti o si se oju eni ti a n royin re ni sise-n-tele ninu aroko oniroyin fun elomiran ti ko si nibe. A rii wi pe o fi ara pe aroko Asapejuwe. Ki a to le se iroyin yori, a gbodo je eni ti o ni ife si gbigbo tabi kika iwe itan kekere.

Eyi ni apeere ori-oro, to je mo aroko oniroyin.

Iroyin ipade maje–o–baje kan ti mo lo.

Ayeye odun eyo ni ilu eko

Ojo buruku, esu gbomi mu.

Ipolongo eto idibo ti o koja

Bi mo se lo isinmi mi ti o koja

Isomoloruko kan ti won se ni odede wa laipe yii.

 

IGBELEWON

Ko aroko lori ‘Isomoloruko kan ti won se ni adugbo wa laipe yi’.

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 23-26

 

ASA

OJUSE ENI NI AWUJO

Ojuse: ni ohun ti a n reti ki enikookan se fun ilosiwaju awujo re.  Gege bi ara ilu, a ni ojuse ti a ni lati se fun awujo wa.

 

  • Akoko, gege bi omo ilu, ti o ni ife ilu re, a gbodo pa ofin ilu wa tabi awujo wa mo fun alaafia ati ilosiwaju awujo wa.
  • Ojuse wa ni lati san owo ori wa, eyi a le je ki awon ijoba ri owo lati le pese iwosan, omi, eko ofe, ina, oju ona to dara fun wa, bi a ba ko lati se ojuse wa, awon ijoba naa ko ni to to fun wa.
  • Ojuse wa ni lati lowo ninu ise ajumose ilu bii yiye ona, tite afara, abbl. Fun idagbasoke ilu tabi awujo wa.
  • Bakan naa, ojuse wa ni lati je olooto nibikibi ti a ba wa, ki won si le gba eri wa je.
  • Ojuse wa ni lati je asoju rere fun ilu awujo ati orile ede.

 

Lapapo, ki a mase ba oruko ilu wa je.  Ibi ti a ti le se ojuse wa ni ibikibi ti a ba ti ba ara wa ni a ti gbodo se ojuse wa.  O bere lati inu ile wa, laarin ebi, egbe lodo ala adugbo, alabaagbe, ilu, ati ni awujo lapapo.

 

IGBELEWON

  1. a. Kin ni iwa ojuse?
  2. Daruko awon ohun to je ojuse wa ni awujo

 

Litireso: ORI IRAN KOKANLA.

 

IGBELEWON

Se agekuru ohun to sele ni iran ti a ka yi.

APAPO IGBELEWON

  1. a. Kin ni iwa ojuse?
  2. Daruko awon ohun to je ojuse wa ni awujo
  3. Se agekuru ohun to sele ni iran ti a ka yi.

ISE SISE

Ko apeere gbolo:

  1. Ase
  2. Ibeere
  • Alaye
  1. Olopo oro-ise

 

IWE AKATILEWA

Imo Ede ASA ati litireso Yoruba fun sekondiri agba S.S. 2  S.Y. Adewoyin o.i 71 – 73

Adakedajo – Iran kejila – Ikeedogun.

 

ISE ASETILEWA

  1. Aroko oniroyin jemo _____(a) Itan siso (b) Alaye (d) Iroyin sise
  2. okan lara amuye iwa omoluabi ni (a) Ipanle (b) suuru (d) Igberaga
  3. ______ lo ye ki a ti maa huwa omoluabi (a) ile (b) adugbo (d) Ibi gbogbo
  4. ____ ni moto ti Alade wo ti ni ijamba (a) Jebba (b) Ilorin (d) Kano
  5. Nibo ni Alade fi sese (a) ori (b) eyin (d) ese

 

APA KEJI

  1. a. Kin ni iwa omoluabi?
  2. Ibo lo ye ki a ti huwa omoluabi?
  3. a. Daruko amuye iwa omoluabi mefa.
  4. Salaye meji ninu won.