AKAYE ÀYỌKÀ

Subject : Yoruba

Class: SS 3

TERM: FIRST TERM

WEEK: WEEK 9

 

 

OSE KESAN-AN

AKAYE

Akoonu

Eka pataki ni akaye je ninu ede Yoruba. Akaye gba suuru lati ka, o gba iyosira ati amodaju awon koko-oro ti ibeere ba da le lori.

Ayoka oloro wuuru

Ayoka  le je ewi

Ayoka le je asotan

Ayoka le je alariyanjiyan

Ifokan-ba-ayoka lo ti aba n kaa se pataki. Eyi ko ni je ki a fi ojo pe ojo ninu idahun si awon ibeere ti won ba gbe ka iwaju wa.

Ohun ti a nilati se lati kogo ja ninu akaye. Koko ka ayoka wa daadaa lati mo ero onkowe. Se akiyesi awon ona ede inu ayoka ati itumo won ni ibamu pelu bi onkowe se loo. Tun akaye wa ka pesepese ki a to dahun awon ibeere ti o tele akaye.

 

IGBELEWON

Ka akaye isale yii ki o si dahun ibeere ti o tele e.

Ni owuro ojo Satide, Akanni, Arije ati Alamu gbera lati abule nla, won fori le aba Adubi. Bi won ti de ibe, won wonu oko Raimi won si bere si sise laiweyin. Ki o to di ojo yii, won ti base lo bi ile bi eni.

Yoruba bo won ni oosa bi ona ofun ko si ojoojumo nii gbebo lowo eni.

Akanni ni o koko logun pe maanu n fagi. Oloko ko pese ohun ipanu gege bi adehun re. Ibi ti won ti n ronu ohun ti won yoo se ni Raimi de. Iyalenu ni o si je fun un nigba ti won bere si so kobakungbe oro si. O ranti pe oun fi ounje ranse si awon alagbase yii ni nnkan bi wakati merin sehin. Bi o ti n salaye pe oun ko gbagbe won ni omo re Foluso to fi ounje ran si won de pelu omije loju. Ase ohun to fa sababi ni pe ounje danu loju ona. Wiwa ti o way ii lo je ki oro lojutu lojo naa.

 

  1. “Maanu n faagi ti a fala si tumo si (a) Aare mu won (b)
  2. Wiwa ti o wa yii lo je ki oro loju tuu. Ta ni o n tokasi?
  3. Ta ni oloko?
  4. Oko wo ni awon alagbase yii ti n sise?
  5. Ojo wo ni won lo sise agbase yii?

ASA

EEWO

EEWO

Eewo je ohun ti a ko gbodo se rara, awon Yoruba si gbagbo pe ti a ba se awon nnkan wonyi tabi ti a ba dejaa nnkan buruku le sele.

Eewo ni ohun ti a agba ni ile Yoruba pe eniyan ko gbodo se, bi eniyan ba si dejaa yoo jiya re. A da eewo sile lati le ko awon omode ni iwa imototo, omoluwabi, ibowofagba ati igbe laruge ASA wa.

A le pin eewo ile Yoruba si awon isori wonyi:-

  • Eewo ikilo / ikonilogbon
  • Eewo iderubani
  • Eewo ti o je mo eri okan tabi ikora eni ni ijanu
  • Eewo idile
  • Eewo ilu
  • Eewo esin
  • Eewo fun ibagbepo eda

Eewo ikilo:  Eyi ni eewo ti a gbe kale lati fi kilo tabi lati fi ko ni logbon. Apeere:

–     Aboyun ko gbodo rin ni osan tabi ni oru ganjo

–     A ko gbodo fi igi owo dana

–     Omode ko gbodo fi owo gbe ojo

Eewo Iderubani:  Ni a maa n lo tabi deruba omode. Apeere:

–     Omode ko gbodo to si aarin aaro ki iya re ma baa ku

–     Omode ko gbodo jokoo si eti odo

–     Omode ko gbodo jokoo si enu ona nigba ti ojo ba n ro

–     A ko gbodo soro nigba ti a ba n jeun.

Eewo ti o je mo eri okan

  • Ode ko gbodo ba iyawo egbe re se nnkan papo
  • Babalawo ko gbodo gba iyawo babalawo lati dekun iwa odale

Eewo esin

  • Obatala ko gbodo mu emu ope
  • Onisango ko gbodo mu siga, je sese
  • A kii fi adi ko esu. Eni ti o ba dejaa yoo ri ija orisa re

Eewo Idile/orile:  Eyi ni eewo ti o je mo idile kookan. Apeere

  • Iran onikoyi ko gbodo je eran okete ati eran oore

Eewo Aisan

  • Eni ti warapa ba n se ko gbodo duro si ibi ti ariwo ba tip o.
  • Eni aromolegun ba n se ko gbodo fo egungun eran ki ara riro re ma baa po sii

Eewo fun Ibagbepo

A kii toju elese mesan-an kaa ki ija ma baa sele

 

LITIRESO

Kikai we Litireso

 

IGBELEWON

  1. a. Ki n ni eewo?
  2. Daruko orisii eewo ti o wa
  3. a. Salaye ohun ti eewo aisan je
  4. Kin ni anfaani eewo aisan

 

APAPO IGBELEWON

  1. a. Ki n ni eewo?
  2. Daruko orisii eewo ti o wa
  3. a. Salaye ohun ti eewo aisan je
  4. Kin ni anfaani eewo aisan
  5. Awon igbese marun-un wo ni eeyan maa n gbe ki o to le dahun akaye

 

ISE SISE

Ko aroko oniroyin kan.

 

IWE AKATILEWA

Imo Ede, asa ati Litireso Yoruba SS2

Adewoyin S.Y o.i 169 – 174.

Adakedajo

 

ISE AMURELE

  1. ______ ni o maa n tele ayoka (a) akonlo-ede (b) Ibeere (d) owe
  2. Ohun ti a ko gbodo se rara ni a n pe ni ___________ (a) Aise (b) eewo (d) Agbedo
  3. Oniwarapa ko gbodo _________ (a) je epo (b) ja (d) duro si ibi ti eeyan ba po ati ibi ti ariwo ba wa.
  4. Onikoyi ko gbodo je okete tabi eran oore je eewo (a) Idile (b) Ikilo (d) Igbe aye alaafia
  5. Idi ti o fi je eewo fun aboyun lati rin ni oru-ganjo tabi inu oorun ki (a) oyin re ma baa baje (b) abami omo ma baa ko wo o ninu. (d) o ma baa bimo dud fafa

 

APA KEJI

  1. a. Kin ni eewo?
  2. Daruko orisii eewo ti o wa
  3. a. Kin ni eewo aisan?
  4. Kin ni anfaani eewo aisan.

 

 

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share