AAYAN OGBUFO

Subject : Yoruba

Class: SS 3

TERM: FIRST TERM

WEEK: WEEK 8

OSE KEJO

AAYAN OGBUFO

Aayan ogbufo ni ise titumo ede kan si ede miiran.

  • Ki ogbufo to le kogo ja ninu itumo ede, o gbodo mo tifun tedo ede Geesi , ki o si le tusu ede Yoruba naa de isale ikoko.
  • Kii se gbogbo oro inu ede kan naa le tumo si ede miiran.
  • A ko gbodo mu gbolohun ni okookan lati tumo, sise bee yoo so ewa ati itumo iru ayoka bee nu.

 

  • A ko gbodo mu oro ni eyo kookan lati tumo, ti a ba se bee yoo so itumo oro ti a fe tu nu.
  • Akaye ati akatunka ayoka se pataki ki o to le se ogbufo to peye. Rii pe o lo akoto to munadoko eyi ni yoo je ki o see ka.
  • Lilo itumo erefee ko bojumu, eyi ko ni fun wa ni itumo ti o kun, itumo ijinle ni o ye ogbufo.
  • O san ki ogbufo lo oruko ti o wa ninu ayoka.

 

IGBELEWON

Tumo ayoka isale yii si ede Yoruba

Yoruba languagesis one of the developing Nigeria languages.

Many books have been written in Yoruba for Pimary, Secondary and tertiary institutions.

As Yoruba, it is necessary that we know, not only how to speak the language, but also read it.

 

The knowledge of how to read and write Yoruba, would certainly enable the language to compete with other Nigerian languages.

 

In pursuance of this objective, Yoruba language experts have put in much efforts towards the development of the language.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 234-254.

 

ASA

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ASEYIN WAYE ATI AWON ABANI EDA.

  • Itumo aseyinwaye (iye leyin iku)
  • Ohun to mu Yoruba gbagbo pe ajinde n be leyin iku

AKOONU

Awon Yoruba ni igbagbo ninu iye leyin iku, won gbagbo pe bi eni won ba fi owo rori ku, o le pada wa ya lodo omo re ki won si tun bi.  Eyi ni o mu won maa so oruko bii Babawale, Babajide, Iyabode, Yejide.  Bakan naa won gbagbo pe eni ti o ba ku ni rewerewe ko le lo si orun taara, kaka bee yoo maa rin kaakiri ni, o si tun le lo si ile ibomiran lati maa gbe, iru awon bee ni a mo si akudaaya. Bakan naa nitori igbagbo ti won ni ninu iye leyin iku ni won se maa n sin owo, ounje ati awon nnkan miiran mo oku laye atijo pe ti oba je ile ibomiran, a le ri owo ati ounje lo lohun-un.

 

Igbagbo awon baba-nla wa nipa abiku tun fi igbagbo ninu iye, leyin iku han, eyi ni o mu ki won maa so omo won loruko bii Malomo, Okoya, Kokumo, Kosoko abbl.

Igbagbo awon baba wa tun han nipa abobaku, ni aye atijo ti oba ba ku, ti won ba maa sin-in pelu Abobaku ni, awon wonyi logbodo ku pelu oba, won gbagbo pe ti oba ba ji si ile ibomiran, ko le ri awon eru ti a maa ran nise.

 

IKINI

Awon Yoruba ni igbagbo ninu iye leyin iku. Eyi si han ninu ikini won lakoko ti oku ba ku . Won a ni iya a ya o. Baba a somo o.

IGBELEWON

Pelu apeere salaye  Igbagbo awon Yoruba ni pa aseyinwaye ati abani-eda.

 

Litireso KIKA APILEKO TI AJO WAEC/NECO

Iran kejila – Ikeedogun

 

IGBELEWON

Pelu apeere  Salaye igbagbo awon Yoruba nipa aseyinwaye.

 

APAPO IGBELEWON

Pelu apeere salaye  Igbagbo awon Yoruba ni pa aseyinwaye ati abani-eda.

Ni kukuru, salaye iran kokanla si ekejila.

 

ISE SISE

  1. Ko iwa omoluwabi mewaa sile.
  2. Fun iba isele aterere ni apeere meji
  3. Fun iba isele baraku ni apeere meji
  4. Fun iba isele asetan ni apeere meji

 

IWE AKATILEWA

Imo, Ede, asa Ati Litireso Yoruba SS2

Adewoyin S.Y. O.i 166 -168

Adakedajo o.i 77 -89

 

ISE ASETILEWA

  1. Aseyinwaye tumo si (a)Ati eyin waye (b) Iye leyin iku (d) Atunwa
  2. ______ ni a n pe eni ti o ku, ti o tun ji si ile ibomiran (a) Akudaaye (b) eni ti o ye leyin iku (d) atunbi
  3. Igbagb aseyin-waye han nibi afi (a)isomoloruko (b) Ikini nibi oku (d) Oye idile jije
  4. Elo ni Aremu san fun owo emu? (a) Egberun meji (b)meta (d)merin.
  5. Aremu lo owo ti o ba Kanmi paaro fun (a) Isomoloruko (b) Isinku (d) Oye

 

APA KEJI

  1. a. Kin ni aseyinwaye?
  2. Nje awon Yoruba gbagbo ninu aseyinwaye? Salaye re lekun-un-rere.
  3. Salaye lekun-un rere ohun ti o sele si Kanmi nigba ti o lo beere owo re lodo Aremu.