Second Term SSS 2 Yoruba
ISE: EDE YORUBA S.S.S.2
ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KEJI
OSE
- EDE: Aroko Onileta (Leta Gbefe ati Leta Aigbagbefe).
ASA: Isinku ni ile Yoruba 1: orisii bi iku se n pani ( ijamba, aisan), itufo ati itoju oku ibanikedun ati sise oku agba.
LIT: Asayan iwe litireso ti ajo WAEC/NECO yan ti egbe akomolede ipinle Eko fowosi.
- EDE: Aayan Ogbufo- titumo ewi ede geesi si ede Yoruba, Awon ofin to romo aayan ogbufo.
ASA: Isinku ni ile Yoruba 1: orisii oku ati bi a se n sin won, oku riro ati etutu oku sise bi ti eleegun
LIT: Itupale lori iwe Litireso ti Ajo WAEC/NECO yan fun S.S.S.2. Eda itan, ibudo itan.
- EDE: Aayan Ogbufo wuuru titumo eyo oro gbolohun ede geesi si ede Yoruba.
ASA: Eto ogun jije I: oriki, iyato laarin ogun baba ati ogun iya, ona ti a n gba pin ogun, awon ti o ni eto si ogun pinpin, aleebu ti o romo ogun pinpin.
LIT: Itupale iwe litireso: ahunpo itan ati asa Yoruba to suyo ninu itan naa.
- EDE: Aroko Onileta (Leta Aigbagbefe). Igbese, adiresi, Deeti, Akole, Koko oro, Ikadi, oruko ati ifowosi.
ASA: Eto ogun pinpin II. Ipa ofin ijoba lori ogun laye ode oni.
LIT: Sise itupale asayan iwe litireso: ilo ede ati akanlo ede, sise orinkinniwin won.
- EDE: Iparoje ati Isunki. Pipa Iro je ninu Iso Isunki to waye, Awon Ihun ti ipaje ti
le waye. Dida Awon Oro tabi Iso ti Isunki ti le waye.
ASA: Eto idajo laye atijo: Ona ti a n gba se idajo laye atijo, ipa ti emese/ilari n ko ninu eto idajo.
LIT: Asayan iwe litireso ti ajo WAEC/NECO yan ti egbe akomolede ipinle Eko fowosi.
- EDE: Aranmo
ASA: Eto idajo lode oni.
LIT: Asayan iwe litireso ti ajo WAEC/NECO yan ti egbe akomolede ipinle Eko
- EDE: Oro Agbaso
ASA: Aroko pipa.
LIT: Kika iwe litireso ti ijoba yan.
- EDE: Oro/Gbolohun Oniponna.
ASA: Eewo nile Yoruba.
LIT: Kika iwe litireso ti ijoba yan.
- EDE: Awe gbolohun ede Yoruba.
ASA: Igbagbo ati ero Yoruba nipa ajinde leyin iku.
LIT: Awon eka ede Yoruba.
- EDE: Apola ninu gbolohun ede Yoruba: apola oruko, oro ise, ihun apola, isori oro ti a le
ba labe apola ise ati apola oruko.
ASA: Igbagbo Yoruba nipa Olodumare
LIT: Kika iwe ti ijoba yan
- Atunyewo lori gbogbo ise saa yii.
*W# *T_KAS&
- Oy4bqmj7 Mustapha (2006) @K_ $D$ YOR^BQ TITUN Iwe kej8 University Press Plc.
- Ay= Bqmgb9s3 (1990) FON_L_J* $D$ YOR^BQ University
- Ad3w[yin S.Y (2006) *M+, $D$, ZXZ zti L&T&R#S+ Ile 2k- Sekondiri Zgbz. Copromutt
- Zm=-, A. Zk9j[p= Zl- Zpav4: (WAEC).
- Babal[lq, A. Or7k8 Or7l2 M1tzd7nl-v=n: (WAEC).
- Zj6w=n, B. *r4m=j3 Er3 *s7pq {dc: (WAEC).
- Aj3w[l3, O. *v2y8n Lalqy0nta: (WAEC).
- Fqd7yz, *yq Ztztz: (WAEC).
- Ad3r7bigb3, M. +r1 Mi: (WAEC).
- Lqs5nkznm8 T2lz. $g5n Or7 *k5nl2: (NECO).
- Oj5k0r-lq Ol5wadqmilqre. {m[ T7 A F8s1 W0: (NECO).
- Tq8w0 Ol5nlqd3. Ew8 *gbzl9d3: (NECO).
OSE KIN-IN-NI
EDE
AROKO ONILETA
AKOONU
Orisii leta meji lo wa ninu ede Yoruba, awon naa ni:
Leta Gbefe ati
Leta Aigbagbefe.
Leta mejeeji ni o ni eto ati ilana ti a n gba ko won.
Leta gbefe ni leta ti a ko si obi, ara, ore, ebi, egbon, aburo tabi si eni ti a mo ri.
ILANA LETA GBEFE NI
- kiko adiresi eni ti a ko leta si. (Eyi le je olooro tabi elebe ni owo otun oke leta naa).
- Deeti
- Ibere leta pelu ikini ibere. (Tunji bawo, Aunti mi, Baba mi owon, Mama mi owon. ikini ni o maa n bere leta.a le wi pe ‘ se alaafia ni o wa ati gbogbo ara ile.
- Inu leta.
- Ni ipari leta gbefe, a o dagbere fun eni ti a ko leta si pelu.apeere; – ire o, o digba. ‘ tire ni tooto’.
- Oruko eni ti o ko leta ni o maa n gbeyin. Apeere Kola, Bolu, Tope, Seun.
Ninu leta gbefe aaye wa fun ikini, apara ati awada.
LETA AIGBAGBEFE.
Eyi ni leta ti a ko si ile-ise ijoba bii ile-ise amohun-maworan,ile-ise itewe,yunifasiti abbl.
Ninu leta aigbagbefe eni ti o di ipo kan mu ni a maa n ko leta si ki I se enikan ni pato.
- ko si pe a n ki ni, sere tabi se awada ninu leta aigbagbefe ibi koko leta ni a maa n lo taara.
- Adiresi meji ni o maa n wa ninu leta aigbagbefe,adiresi eni ti o ko leta ati eni ti a n ko leta si.A maa n mo ipo eni ti a n ko leta si.apeere,alaga,akowe,oga agba.
- Ori-oro tabi akole maa n wa ninu leta aigbagbefe.
- Inu leta/koko ti a fe bog an-an ni a gbodo lo taara.
- Ipari leta. ‘emi ni tiyin ni a gbodo fi pari.
- Oruko eni ti o ko leta. Apeere:
LETA AIGBAGBEFE.
12 Adeoti street,
Oyo,
23rd may,1996.
The Director,
Iwe Iroyin Yoruba press,
77, Kadara Street,
Lagos.
Olootu
IBEERE FUN IPO AKOWE ATEWE.
Koko inu leta.
Emi ni tiyin
Adebisi Raheem.
IGBELEWON:
Salaye iyato to wa laarin leta gbefe ati aigbagbefe
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo,Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Oju iwe 1-35 Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd.
Deeti …………………
ETO ENI SI OGUN JIJE
- Oriki
- Ohun ti a n je logun
- Ona ti a n gba pin Ogun
- Opo Sisu ati Omo Ajemogun
- Ire ati Ibi to ro mo Ogun Pipin
- Iyato laarin Ogun Iya ati Baba
AKOONU
Ogun ni gbogbo dukia ti oloogbe fi sile fun omo ati awon ebi. Adura gbogbo obi ni pe ki won ri omo rere gbeyin won.
Oro ogun pipin yii gbelege pupo ni pataki julo, ogun baba lo gbelege julo nitori opolopo iyawo ti won maa n ni laye atijo. Baba – n – sinku ni o ni ase lori isinku ati ogun pipin
Awon ohun ti won maa n pin logun. Gbogbo ohun ti oku ni ni dukia. Bii
- Ile
- Ile
- Oko
- Iso
- Iyawo
Gbogbo awon nnkan wonyi ni won maa n pin logun. Obinrin (Iyawo) ti oku fi sile naa ni a le su lopo fun aburo tabi molebi oku ti o ba kan-an gbongbon.
ONA TI A N GBA PIN OGUN
Ona meji ni won n gba pin ogun ni aye atijo. i. ori –o- jori ati ii.idi igi.
ORI- O-JORI -: eyi tumo si pe ogun ti oloogbe ba fi sile ni won yoo pin ni deede fun gbogbo omo ti o bi.
IDI IGI-: bi oku ba ku laye atijo, ti o si ni iyawo pupo. Idi igi ni won fi maa n pin ogun bee. Iyawo to bi omo kan ati olomo mejo ogun kan naa ni won yoo pin fun awon mejeeji. Ireje maa n wa ninu ogun pipun. idi niyi ti ogun baba si fi lewu pupo nitori pe inu olomo mejo ko le dun si ogun ti won pin fun-un, koda won maa n se orogun si ara won lori ogun.
Iyato laarin ogun iya ati baba. Ogun iya lo fi okan bale julo nitori pe ko si orogun ninu ogun iya. idi niyi ti won fi n paa lowe pe – “Gbede bi ogun iya, anini lara ba ogun baba”.
Igbelewon
1a Kin ni ogun pinpin
- Daruko awon ohun ti a n je logun.
Iwe Akatilewa
Imo Ede Asa ati Litireso SS3 o.i 200-203
Adakedajo.
APAPO IGBELEWON
1a Kin ni ogun pinpin
- Daruko awon ohun ti a n je logun.
- Salaye iyato to wa laarin leta gbefe ati aigbagbefe
ZT%NY@W) IX!
- Ko eya ara ifo mejo sile.
- Ko eya ara ifo afojuri mefa sile.
- Ko eya ara ifo aifojuri mefa sile.
ISE ASETILEWA
- Leta ti o maa n ni adiresi meji ni leta A. gbefe B. aigbefe C. asotan D. asapejuwe
- Leta ti a maa n bu owo lu ipari re ni A. gbefe B. aigbefe C. asotan D. asapejuwe
- ….. ni a maa n ko eni ti o sun mo wa A. gbefe B. aigbefe C. asotan D. asapejuwe
- Eni ti won maa n pe ni eni orisa ni A. eniyan dudu B. eni giga C. afin D. afinju
- ….. n sunkun oku akasoleri n sunkun ara won A. eniyan B. ara orun C. oku D. eni maa ku.
APA KEJI
- Salaye bi won se n sin:
- Adete
- Abuke
- Agba ode
- Eni ti Sango pa.
OSE KEJI
EDE
Aayan Ogbufo
AKOONU
Aayan ogbufo ni ise titumo ede kan si ede miiran. Ki ogbufo to le kogo ja ninu itumo ede, o gbodo mo tifun tedo ede Geesi , ki o si le tusu ede Yoruba naa de isale ikoko.
Kii se gbogbo oro inu ede kan naa le tumo si ode miiran.
A ko gbodo mu gbolohun ni okookan lati tumo, sise bee yoo so ewa ati itumo iru ayoka bee nu.
A ko gbodo mu oro ni eyo kookan lati tumo, ti a ba se bee yoo so itumo oro ti a fe tu nu.
Akaye ati akatunka ayoka se pataki ki o to le se ogbufo to peye. Rii pe o lo akoto to muna doko eyi ni yoo je ki o see ka.
Lilo itumo erefee ko bojumu, eyi ko ni fun wa ni itumo ti o kun, itumo ijinle ni o ye ogbufo.
O san ki ogbufo lo oruko ti o wa ninu ayoka.
Eyi ni aayan ogbufo sise laarin awon akekoo ninu kilaasi.
Please bury the harchet
Jowo fiye denu
He who fight and run away, leaves to fight the other day
Agbo to feyinrin, agbara lo lo mu wa.
Time and tide wait for no man
Akoko ati igba ko duro de enikan.
Paddle your own canoe
Gbo tire
They may have been drumming
Won ti le maa lu ilu
He came in reluctantly
O wole tikotiko
Tumo ayoka yii si ede Yoruba
Birds take a great deal of trouble to give their young a good start in life. The female bird lays hard-shelled egg from which the young animal gradually develop with supplies of good good and air. In most cases the eggs are laid in a carefully prepared nest which is hidden from enemies or out of their reach.
Awon eye a maa se opo wahala lati fun awon omo won ni ibere rere ni aye. Iya eye a maa ye eyin eleepo lile.
Ninu eyin yii ni awon omo eye yo ti maa ri ounje ati afefe ti yo mu won maa gbora diedie. Ni opolopo igba inu ite ti won farablae ko ti o sa pamo fun ota ni won maa n ye won si.
Don’t give it a chance
When problem comes
Don’t give a chance
When joy comes
Rejoice moderately
Joy is a fragile thing
IGBELEWON
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd Oju Iwe 234-254.
ASA ISINKU NI ILE YORUBA
Awon Yoruba gbagbo pe gbogbo wa ni a da agbada iku,won a ni ‘ma forum yo mi gbogbo wa la jo n lo.’atomode atagba ko si eni ti ko ni ku,gbogbo wa la je gbese iku.Ki Olorun ko fi iku rere pa ni.
Awon Yoruba gbagbo pe bi eniyan ba ku yoo lo si orun, yala rere tabi orun apaadi.
AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.
Ki Edumare ki o fi iku ire pa gbogbo wa bi a ti n sin oku kookan da lori eni ti o je ati iru iku ti o pa eni bee. Die ninu iru re niwonyii.
Eni ti sango pa. Awon mogba nii se etutu sisin re.
Eni ti sanponna pa inu igbo ni won maa n sin-in si awon adahunse ni
Si n se etutu sisin re.
Eni ti o ku sinu odo eti odo ti o ku si ni won maa n sin–in si, awon
alawo ni si n se etutu re.
Eni ti o ku toyuntoyun awon oloro nii se etutu sisin re.
Adete awon ogbontarigi adahunse ni i se etutu sisin re, inu
Igbo ni won a sin-in si, won a si sun gbogbo nnkan Ini re.
Eni ti o pokunso Awon onimole ni i sin in,idi igi ti o pokunso si naa
ni won o sin in si.
Abuke Awon babalawo ati adahunse ni i se etutu sinsin re,
Inu igbo ni won sin in si, ninu ikoko,won a si sin
Gbogbo nnkan ini re mo pelu.
Babalawo awon agba awo ni i se etutu sisin oku babalawo
pelu eye ti o ga ti won yoo fi se etutu lati yose re
kuro ninu egbe awo.
Ode awon ode nii se ayeye oku ode sisin,oro Pataki ti
Won ni lati se fun un ni sisipa ode ti a mo si ‘ ikopa ode’ eyi ni etutu ti won maa n se ki awon eran ti ode naa ti pa nigba aye re ma baa hun un,ki o sile je ki awon ode to ku laye maa ri eranko.
Onilu awon onilu nii se etutu onilu lati yowo elegbe won
ti o ti ku kuro ninu egbe ki awon to ku le maa ri se.
Alagbede Awon alagbede nii se oro igbeyin fun oku alagbede
lati yowo re kuro ninu egbe.Inu ile aro ti alagbede
naa ti n sise ki o to ku ni a ti maa n saba se etutu
Ikeyin yii.
Yato si gbogbo awon wonyii,awon Yoruba a maa ro oku paapaa eyi ti o ba je oku oroju ti
won gba pe iku re kii se lasan,awon agba adahunse tabi oloogun ni o maa n ro oku, ki
won to gbe e si koto, riro yii lo maa je ki o se iku pa eni ti o pa a. .
IGBELEWON : –
- salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv. Eni ti o pokunso.
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo,Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Oju iwe 1-35 Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd.
APAPO IGBELEWON
- salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv. Eni ti o pokunso.
ZT%NY@W) IX!
- Ko aroko lori ‘ojo kan ti o ko le gbagbe’
salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi, ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv. Eni ti o pokunso.
ISE ASETILEWA
- Intuition A. ironinu B. oye inu C. inu kan D. oye oju.
- Interpreter A. atufo B. onpade C. ogbufo D. olusoro.
- Compare A. fi kan B. fi ran C. fi gba D. fi we.
- Mood A. imulara B. ifarasin C. imoloju D. ifokase.
- Decide A. pinnu B. ronu C. ro D. so.
APA KEJI
- Tumo awon oro yii:
- Mislead
- Tammerer
- Competition
- Verify
- Bawo ni won se n sin: abuke, oba, afin.
OSE KETA
EDE
AAYAN OGBUFO
Qayan 0gbuf= ni s7se 8tum= 4d4 kan si 4d4 miiran. K7 0gbuf= to le k9go jq n7n5 8tum= 4d4, 9 gb[d= m[ tif5n t2d= 4d4 Geesi, k7 o si le t5su 4d4 Yor6bq nqz d3 8szl2 8k0k0.
K8 8 se gbogbo =r= in5 4d4 kan nqz le t5m= s7 0de m87rzn.
A k0 gb[d= mu v9l9h6n ni =k==kan lzti t5m=, s7se bee yoo so ewa zti 8tum= ir5 zy[kz bee nu.
A k0 gbodo mu +r= ni eyo kookan lzti tumo, ti a ba se bee yoo so 8tum= =r= t7 a f1 tu nu.
Zkzy3 zti zkzt5nkz zy[kz se pztzk8 k7 9 t9 le se 0gbuf= t9 p3ye. R7 I p3 o lo zk-t- t9 m5nq d9ko 4y7 ni y90 j1 k7 9 see ka.
Lilo 8tum= erefee ko bojumu, 4y7 k0 ni f5n wa ni 8tum= t7 o kun, 8tum= 8j8nl2 ni 9 ye 0gbuf=.
O san k7 0gbuf= lo or5k[ t7 9 wz n7n5 zy[kz. $y7 ni aayan 0gbuf= s7se lqzrin zw[n ak1k=- n7n5 kilaasi.
Please bury the harchet
Jowo fiye denu
He who fight and run away, leaves to fight the other day
Agbo to f4y7nrin, agbara lo lo mu wa.
Time and tide wait for no man
Akoko zti igba ko duro de enikan.
Paddle your own canoe
Gb- t8rc
They may have been drumming
Won ti le mqq lu ilu
He came in reluctantly
( w[l3 t8k=t8k=
T5m= zy[kz y87 s7 4d4 Yor6bq
Birds take a great deal of trouble to give their young a good start in life. The female bird lays hard.shelled egg from which the young animal gradually develop with supplies of good good and air. In most cases the eggs are laid in a carefully prepared nest which is hidden from enemies or out of their reach.
Zw[n eye a mqq se =p= wzhqlz lzti f5n zw[n [m[ w[n ni 8b2r2 rere ni ay3. Iya eye a mqq ye 4y7n eleepo lile.
N7n5 4y7n yii ni zw[n [m[ cyc yo ti mqq ri ounjc zti af1f1 ti y90 m5 w[n mqq gbora diedie. Ni =p=l[p= 8gbz inu 8t1 t7 w-n farablae ko ti o sa pamo f5n ota ni won mqq n ye won si.
8v3l3w=n
- It is the duty of vulture to eat sacrifice. (A) ise adan ni ebo jije. (B) ise igun ni ebo jije (C) ise lekeleke ni ebo jije (D) o je ise adaba lati je abo (E) ojuse awon eye ni lati je ebo.
- Punctuality is the soul of business. (A) aitete de ni ibere okuta (B) enu ise eni la tii moni lole (C) imura si ise ni a fi n mo owo se (D) nibi ise ni a ti mo onisowo tooto (E) titete de ni i mu ise ya.
- ‘The sun shines everyday’ oorun ……………. ni ojoojumo. (A) fe maa ran (B) n ran (C) ti maa n ran (D) ti n ran (E) yoo maa ran.
- Time and tide wait for no man. (A) agogo ati igba ko duro de okunrin kankan (B) akoko ati igba ko duro de enikankan (C) akoko ati igba ti n duro de enikan (D) asiko ati akoko ko duro de okunrin (E) asiko ati akoko ko pe rara.
‘My grandfather has passed on’ Baba mi agba ti (A) koja lo (B) ku (C) n sun sun lo (D) rin lo (E) yege.
EDE GEESI SI EDE YORUBA
AKAYE 1
Yoruba language is one of the developing Nigeria languages. Many books have been written in Yoruba for primary , secondary and tertiary institutions. As Yoruba, it is necessary that we know, not only how to speak the language, but also to read it. The knowledge of how to read and write Yoruba would certainly enable the language compete favorably with the other Nigerian language.
In pursuance of this objective, Yoruba language experts have put in much efforts towards the development of the language.
AKAYE 2
We cook the food to make it palatable, easier to digest and more hygienic. Cooking makes meals tender and easier to chew. The taste of meat is also improved by cooking and is more attractive than raw meat. Cooking will destroy harmful parasites and bacteria. One of the parasites that is carried by meat not properly cooked is tape worm. Cereals and root vegetables cannot be easily digested unless they are cooked but many fruits and green vegetables can be eaten raw.
Nutrients can be lost during cooking in two ways. They can be lost in the cooking water. Secondly, heat may destroy some of the nutrients. But the effect of cooking on the nutritive value of foods will depend on the method of cooking used. Meat, vegetable, beans and maize can all be stewed together in the same pot the result is nutritious meat.
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Copromutt Publishers Oju Iwe 252.
AKORI ISE (ASA): OGUN PINPIN
AKOONU: Ogun Pinpin.
Ilana Ogun Pinpin.
Ohun ti a le pin gege bi Ogun.
Ona ti a n gba pin Ogun.
Leyin osu meta ti baba ba ku ni a to le pin ogun re, leyin ti obinrin ba jade opo. Nile
Yoruba, egbon ki i jogun aburo afi ti koba si elomiran mo sugbon apeere ori buruku ni ki
egbon o jogun aburo re.Ki won to pin ogun, won yoo difa tabi ki won pe awon agbagba
lati jiroro laarin awon omo oku. Iru ipade bayi je ipade asiri. Won a kiyesi ohun ti awon
omo naa fe ati ohun ti o le te oku lorun. Aaro kutukutu ni a maa n jokoo ni odede bale lati
se eto ogun pinpin. Awon nnkan ti a n pin bi ogun ni: Aso, owo, ohun eso, ohun osin,
orisa, oko, iyawo ati gbese. Ona meji ni a n gba pin ogun ni ile Yoruba awon naa ni: ori
– ko – ju – ori ati idi – igi – si – idigi. Ori ko–ju ori – ni pinpin ogun si iye omo oku
sugbon idi si idi igi ni pinpin ogun si iye iyawo ti o bimo fun oko naa.
IGBELEWON
- Ko awon nnkan marun – un ti a le pin gege bi ogun nile Yoruba.
- Awon ona wo ni a le gba pin ogun?
IWE AKATILEWA
Oyebamiji Mustapha Eko Ede Yoruba Titun SSS Iwe Keji Oju Iwe 76 – 79.
ZT%NY@W) IX!
- Ko aroko lori ‘afefe’
APAPO IGBELEWON
- Ko awon nnkan marun – un ti a le pin gege bi ogun nile Yoruba.
- Awon ona wo ni a le gba pin ogun?
- salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete,iv. Eni ti o pokunso.
- Ko ohun elo mewaa inu ile sile ki o si ko itumo won ni ede geesi
ISE ASETILEWA
- Punctuality is the soul of business. (A) aitete de ni ibere okuta (B) enu ise eni la tii moni lole (C) imura si ise ni a fi n mo owo se (D) nibi ise ni a ti mo onisowo tooto (E) titete de ni i mu ise ya.
- ‘The sun shines everyday’ oorun ……………. ni ojoojumo. (A) fe maa ran (B) n ran (C) ti maa n ran (D) ti n ran (E) yoo maa ran.
- Time and tide wait for no man. (A) agogo ati igba ko duro de okunrin kankan (B) akoko ati igba ko duro de enikankan (C) akoko ati igba ti n duro de enikan (D) asiko ati akoko ko duro de okunrin (E) asiko ati akoko ko pe rara.
- Ona meloo ni a n gba pin ogun nile Yoruba? A. Meta B. Nerin C. meji D. mefa.
- Ogun ti o rorun ju lati pin ni …….. A. Baba B. Iya C. egbon D. ebi.
APA KEJI
- Ko aleebu marun ti o ro mo ogun pinpin nile Yoruba.
- (a) Fun aayan ogbufo ni oriki (b) Taa ni ogbufo?
OSE KERIN
LETA AIGBAGBEFE:
Eyi ni leta ti a n ko si ile-ise ijoba bii ile-ise amohun-maworan, ile-ise itewe, Yunifasiti abbl. Ninu leta aigbagbefe eni ti o di ipo kan mu ni a maa n ko leta si ki i se enikan ni pato.
- Ko si pe a n ki ni, sere tabi se awada ninu leta aigbefe. Ibi koko leta ni a maa n lo taara.
- Adiresi meji ni o maa n wa ninu leta aigbagbefe. (adiresi eni ti o ko leta ati eni ti a n ko leta si). A maa n mo ipo eni ti a n ko si. Apeere: Alaga, Akowe, Oga Agba.
- Ori-oro tabi akole maa n wa ninu leta aigbagbefe.
- Inu leta/koko ti a fe bo gan-an ni a gbodo lo taara.
- Ipari leta. ‘Emi ni tiyin’ ni a gbodo fi pari.
- Oruko eni ti o ko leta. Apeere
IGBESE LETA AIGBEFE
Adiresi
Deeti
Ikini
Akole
Koko Oro
Ikaadi
Oruko ati ifowosi.
LETA AIGBAGBEFE.
12, Adeoti Street,
Oyo,
23rd May,1996.
The Director,
Iwe Iroyin Yoruba Press,
77,Kadara Street,
Lagos.
Olootu,
IBEERE FUN IPO AKOWE ATEWE.
Koko inu leta.
Emi ni tiyin
Adebisi Raheem.
Igbelewon:
Salaye iyato merin ti o wa laarin leta gbefe ati aigbagbefe.
IWE AKATILEWA
S.Y dewoyin (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Yoruba fun Ile Eko Sekondiri Agba S.S.S
Copromutt Publishers Nigeria Limited Oju Iwe 34.
ETO OGUN PINPIN
Yoruba maa n ronu jinle ki won to pin ogun nile Yoruba. Leyin poposinsin eto oku sise, ohun ti o kan ni ki won won pin ogun fun awon ti won ni eto si ogun eni ti o ku. Egbon eni ti o ku, iya ati baba eni ti o ku ko ni eto si ogun nitori eyi je apeere ori buruku nile Yoruba. Awon agbalagba ni o maa n pin ogun nile Yoruba. Won si maa n pin ogun ni aaro tori won ka eyi kun owo ero.
Won maa n wo eni ogun ti omo kookan le se amojuto re ki won to pin ogun nitori ki ogun naa ma ba di akurun. Awon agbalagba gbagbo wi pe ti won ba pin ogun kan fun eeyan ti inu eni ti o ni ogun (oku) ko ba dun si, won gbagbo wi pe iru ogun bee maa n tete parun. Ki won to pin ogun awon agbalagba ile yoo ti se ipade ki won to pin ogun. Ni aye igba kan won difa ki won ma baa se asise ninu oun pinpin.
IGBELEWON
Salaye lori eto ogun pinpin nile Yoruba.
IWE ITOKASI
ASA ATI AWON ORISA ILE YORUBA Oju Iwe 237
APAPO IGBELEWON
- Salaye iyato merin ti o wa laarin leta gbefe ati aigbagbefe.
- Salaye lori eto ogun pinpin nile Yoruba.
- Ko asa marun-un sile ninu iwe apileko ti ijoba yan.
LITIRESO APILEKO
Itupale iwe litireso: ahunpo itan ati asa Yoruba to suyo ninu itan naa.
ZT%NY@W) IX!
- Ko leta si ore re kan ti o ti ri tipe, salaye nnkan kan ti o wu o fun un ninu aroko naa.
ISE ASETILEWA
- Your grandfather has passed on. A. baba re agba ti rin lo B. baba re agba ti lo. C. baba re agba a ti ku D. baba re agba a koja.
- The master of ceremony funmbled. A. adari eto ayeye naa kunna. B. adari eto ayeye naa binu C. adari eto ayeye naa faraya D. adari eto ayeye naa yege.
- Our teacher is generous. A. oluko gbajumo B. oluko wa gbajumo C. oluko wa gbaju D. oluko wa lawo.
- It rained cats and dogs yesterday. A. ojo ana pa awon eranko B. ojo ana pa ologbo ati aja C. ojo ro pupo lanaa D. ojo ana pa awon aja ati ologbo.
- Ona ti a le gba dena ogun jija ni A. alo pipa B. idobale C. ebe bibe D. wiwa yara.
APA KEJI
- Tumo:
- the boy is running after his shadow.
- All that glitters is not gold.
- Pride goes before the a fall
- Punctuality is the soul o business.
- Ko awon oloye ogun mefa sile.
OSE KARUN-UN
IPAROJE ATI ISUNKI
AKOONU
Iparoje: Ni fifo awon iro tabi siso awon iro nu nigba ti a ba n yara soro. Ti a ba n yara soro, a maa n pa awon iro kan je, awon iro ti a maa n paje ni:
- Iro konsonanti.
- Faweli ati ohun.
- Apapo konsonanti, fawli ati ohun ninu oro.
Nibi ti a ba ti pa iro je, alafo yoo wa nibe, a o wa pa iro mejeeji po di eyokan. Pipapo apa oro eyo kan ni a mo si isunki.
Se ise = S( ) ise = sise (faweli ‘e’ ni a paje)
Adiye = adi ( ) e adie (kons ‘y’ ni a paje)
IPAJE KONSONANTI
Opolopo iro Konsonanti ede Yoruba ni a le paje ninu afo/oro siso. Eyi ni awon eyo oro ti a ti pa konsonanti je ni ikookan ati ayorisi ipaje
Oro | Iro ti a paje | Abajade ipaje (isunki) |
Ebibi Daradara Olorun Kehinde Gbolohun Olele Ajayi Adiye Jowo | (eibi) b r r ‘h’ ‘h’ i y y w | Eebi Daadaa Oloun Keinde Gboloun Oole Ajai Adie Joo |
Omoluwabi Adura Ekuro Akara Dara Akitan | W r r r r k | Omoluabi Adua Ekuo Akaa Daa Aatan |
Itupale oro ti iparoje ati aranmo ti waye
Eyi ni awon oro ti iparoje ati aranmo ti waye laaarin faweli.
Eyo oro konsonanti ti a paje Aranmo laarin faweli Isunki
Bawo bao (w) “a” ati “o” boo
Egbewa egbaa (w) “e” ati “a” egbaa
siwaju siaju (w) “i” ati “a” saaju
otito Oito (t) “o” ati “i” ooto
akike aike (k) “a” ati “i” aake
orirun oirun “o” ati “i” oorun
alila aila “a” ati “i” aala
oyiya oiya “o” ati “i” ooya
edidu eidu “e” ati “i” eedu
otutu outu “o” ati “u” ootu
okankan oankan “o” ati an ookan
efinfin eifin “e” ati in eefin
egungun eungun “e” ati un eegun
IGBELEWON
1.Kin ni iparoje?
b.Daruko ibi ti iparoje ti maa n waye.
IWE ITOKASI
S.Y Adewoyin (2006) Imo, Ede, Asa Ati Litireso Yoruba Corpromutt Publishers Oju iwe
ORAN DIDA ATI IJIYA TI O TO
Oran dida ati ijiya ti o to
- Itumo
- Ohun ti o faa
- Orisii oran ti eeyan le da
- Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je odaran
- Orisirisi oran ti eeyan le da
- Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je arufin
AKOONU
Se Yoruba bo won ni ‘ilu ti ko si ofin ese ko si, bakan naa awon Yoruba ni igbagbo ninu idajo ododo won ki i si i fi ejo se egbe. Bakan naa, won ni elese kan ki yoo lo laijiya nitori idi eyi gbogbo oran lo ni ijiya. Oba, ijoye ati awon ologboni lo maa n se eto idajo ni aye atijo.
Oran Dida: Ni ti tapa si ofin tabi rire ofin ilu kan koja ni pa sise ohun ti won ni won ko gbodo se tabi sise omonikeji ni ibi. Ohun ti o n fa oran dida orisiirisii ni ohun ti o le fa oran dida, die ninu won niyi:-
- Ojukokoro
- Iwa imotara eni nikan
- Aini itelorun
- Etanu
- Aigboran abbl.
Orisiirisii oran ti eeyan le da ati ijiya ti o to sii. Eyi ni orisiirisii oran ti eeyan le da:
ipaniyan, ole jija, idigunjale, ifadiya, jibiti lilu, aje sise, biba iyawo oniyawo lopo, lilo oogun ika, gbomogbomo abbl. Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je odaran.
Ipa kekere ko ni oba ati awon ogboni n ko ninu fifi iya je odaran. Gege bi a se mo pe oba ni olori ati alase ilu, ti o n ri si idagbasoke ati aabo ilu, ti odaran ba daran, ti o si ju eyi ti Baale tabi Baale le pari lo, aafin oba ni won yoo mu iru odaran bee lo, ti oba ati awon ijoye yoo si jiroro lori iru iya ti won yoo fi je iru odaran bee. Bakan naa ni awon ogboni naa ko gbeyin ninu fifi iya je arufin.
IJIYA FUN ILE DIDA
Yoruba gbagbo pe eni ti o ba dale a ba ile lo ati pe eni ba n yo ile da pelu, ohun werewere yoo maa yoo se. Bi eni kan tabi ilu kan ba gbangba, ti o si dale gbangba, orisiirisii ona ni iya le maa gba je odale yii. O le sadeede ku lojiji. Sobia le gbe e sanle ki o ma le dide fun odun meta. o le lu agbana, ijamba si le se e bi ki aake sa a lese, o si le maa se aare ogeu ti ko loju, ti ko si gbo wiwo. Iku ni opin gbogbo nnkan wonyi fun odale.
Igbelewon
- Daruko oran marun-un ti eeyan le da.
APAPO IGBELEWON
- Daruko oran marun-un ti eeyan le da.
- Kin ni iparoje?
- Daruko ibi ti iparoje ti maa n waye.
ZT%NY@W) IX!
- Ko apeere oro oruko afoyemo mefa sile.
- Ko apeere oro oruko aridimu mefa sile.
- Ko apeere oro oruko ibi kan mefa sile.
- Ko apeere oro oruko aseeka mefa sile
IWE ITOKASI
ASA ATI AWON ORISA ILE YORUBA Oju Iwe 237
ISE ASETILEWA
- ________ lo ma koko sele ki isunki to waye aranmo B. iparoje C. ihun oro.
- Apeere Isunki to waye ninu oro to ni ju konsonanti kan lo ni _______ A. Joo B. Ibebe C. Ponmi.
- Se isunki/ipaje awon oro wonyi: edidu, esisu, orisa. A. Eedu, eeesu, osa. B. Eedu, eesu, oosa. C. edu, esuu, oosa.
- Ewo ninu awon wonyi ni aranmo maa n waye leyin isunki ati ipaje ba ti waye A. Eeke B. Laelae C. aatan.
- …… ni le fa oran dida. A. Oju kokokro B. Iwa omoluwabi C. akikanju.
APA KEJI
- Ko apeere oran dida mefa sile.
- Ko asa marun-un sile ninu iwe apileko ti ijoba yan ki o si salaye meji ninu asa naa.
OSE KEFA
ARANMO
Aranmo ni agbara ti iro kan ni lori miiran eyi ti o le f ape ki iro mejeeji yipada di iru kan naa tabi ki won fi abuda jo ara. Apeere:
Ara ile —-à araale
Omo ise —à omoose.
Oni owo –à olowo.
Iro Afaramo: iro afaranmo ni iro ti o ni agbara lati yi abuda iro tabi die lara abuda iro miiran pada si tire. Apeere:
Owo ile —-à owoole.
Ise ilu —–à iseelu.
Iro Agbaranmo: iro agbaranmo ni iro ti o yi pada gba abuda iro miiran. Apeere.
Ile iwe —-à ileewe
Ara ile —-à araale.
ORISII ARANMO
- ARANMO IWAJU
Iro Afaranmo Iro Agbaranmo Aranmo Iwaju
Ile ise ileese
Ku irole kuurole
- ARANMO EYIN
Iro Agbaranmo Iro Afaranmo Aranmo Eyin
Ara orun aroorun
Ku ale kale
- ARANMO ALAIFORO
Ojo iku ojooku
Ile ise ileese
Ara orun aroorun.
- ARANMMO AFORO
Oni epo -àelepo
Oni owo -àolowo
Oni eran -àeleran.
- ARANNMO KIKUN
Agbo + ile -àagboole
Oku + igbe -àokuugbe
Ile + ise -àileese.
IGBELEWON
Sakaye awon wonyi ki o si fi apeere mejimeji gbe alaye re lese: Aranmo: i. Iwaju, ii. Eyin. iii. Aforo . iv. alaiforo. v. kikun. vi. iro agbaranmo ati iro vii. afaranmo.
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3)
Copromutt Publishers Oju Iwe 119-124.
ETO IDAJO LODE ONI
Yoruba bo won ni ibi ti ko si ofin ese ko si nibe. Itapa si ofin ni o n je oran dida. Aye ki ba ti ma roju bi ki i ba se ofin ti o de eniyan. Gbogbo ofin ni o n sise alaafia, idaabobo fun gbogbo eniyan. Ti eniyan ba tapa si ofin tan, ohun ti o kan ni idajo.
Ejo Dida/ Eto Idajo ki i se ohun ajeji nile Yoruba, o ti wa laarin awon agba aye atijio.
Awon ti o maa n se idajo ni aye atijo ni baba, iya, olori ebi aale ati Oba. Oba je olori eni ti o n se idajo. Ohun ti o ba so ni abe n ge. Sugbon ki o to di wi pe o soro ni gbogbo awon oloye yoo ti se idajo ki oba to pase.
Ni ode-oni, awon adajo ni won maa n da ejo. Ko si eni ti won ko le da ni ejo.
Awon agbejoro naa wa ninu eto idajo lode-oni. Awon mejeeji ni won maa n se iwadii finnifinni ki won to da eniyan lejo ki won ma lo gbe ebi fun alare. Ile ejo ni won ti maa n da ejo. Orisiirisii ile ejo ni o w anile Yoruba awon naa ni:
Ile ejo ibile.
Ile ejo giga.
Ile ejo Kotemilorun.
Ile Ejo ti o ga julo.
IPA TI OLOPAA ATI WODA N KO NINU IDAJO ODE ONI
Awon olopaa ati awon woda je agbofinro. Awon ni won maa je ki ofin ti ijoba se di mimuse. Won maa n ri wi pe gbogbo eniyan ni o gbodo tele ofin. Bakan naa won tun maa n se idanileko ati isininiye lori ofin ti ijoba ba gba jade lati le ki awon eniyan mo pe ofin wa anfaani ara ilu. Won leto lati fa odaran (iyen eni ti ko rufin ti ko tele ofin) lo si ile ejo ki adajo si so ijiya ti o to fun eni naa.
ISE AGBEJORO NINU IDAJO
Agbejoro maa n je akosemose. Awon ni won maa n se iwadii finnifinni lori oran. Ti won ba mu odaran pe o rufin ni ile ejo, awon agbejoro ni won maa n gbenu odaran soro. Won gbodo se iwadii ti o to lori ejo ti won n sise le lori.
ETO YIYANJU AAWO LORI REDIO ATI TELIFISAN
Opolopo eto ni o wopo lode oni ti o maa n da lori yiyanju aawo laarin awon eniyan. Eyi je ohun igbalode ti ko sele ni aye atijo. Opolopo igba ti awon awon ba jaye familete ki ntuto, awon kan n fi owo ola gbaniloju ti iru eni ti won n fi owo ola gba loju yi ko ni eni Kankan ni iru awon eniyan yii maa n ke gbejeri lo si ori redio tabi telifisan lati ri iran lowo. Ki a ma paro iru awon eniyan bayi maa n ri iran-lowo daadaa.
IGBELEWON
- Salaye lori: i. Agbejoro ati adajo ii. Ile ejo kotemilorun iii. Ile ejo ibile.
IWE ITOKASI
LITIRESO
KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.
APAPO IGBELEWON
- Sakaye awon wonyi ki o si fi apeere mejimeji gbe alaye re lese: Aranmo: i. Iwaju, ii. Eyin. iii. Aforo . iv. alaiforo. v. kikun. vi. iro agbaranmo ati iro vii. afaranmo.
Salaye lori: i. Agbejoro ati adajo ii. Ile ejo kotemilorun iii. Ile ejo ibile.
ZT%NY@W) IX!
- Ki ni oro aropo oruko?
- Ko apeere oro aropo oruko mejo sile.
- Ko apeere oro oruko opo mesan-an sile.
- Ko apeere oro oruko eyo mesan-an sile.
ISE ASETILEWA
- Aranmo ni …………..A.iro ti o yi pada di iro Iro ti o yi pada di iro miira C. agbara ti iro kan ni lati yi abuda iro miiran di ara re. D. iro ti o maa n parade.
- Iro agbaranmo ninu ‘’ ara oko’’ ni ….. A. a. B. o. C. k. D. r.
- Iro ti yi abuda iro miiran pada di ara re ni ……… A. afaranmo B. agbaranmo C. aranmo iwaju D. aranmo eyin.
- Ewo ninu awon wonyi ni aranmo aforo? A. araale B. kale C. akaa D. eleran.
- Awon ti maa n da eniyan lejo ni ……….. A. olopaa B. woda C. adajo D. agbejoro.
APA KEJI
- Ko apeere mejimeji fun aranmo: i. Iwaju ii. Eyin iii. Aforo iv. kikun.
- Salaye lori: i. Eto idajo aye atijo ii. Eto idajo ode oni iii. Ile ejo ti o ga julo.
OSE KEJE
Oro – Agbaso
Akoonu
Oro agbaso naa ni a mo si afo agbaran.
Oro agbaso:- je siso oro ti a gbo lenu oloro fun elomiran. Iru oro tabi iroyin bee gbodo je eyi to ti koja. Oro agbaso le je ohun ti enikan so nipa wa tabi elomiran. O si le je iroyin ohun to sele nibi kan. Awon wunren atoka oro agbaso ni so, wi, ni, ki, pase, wi pe, salaye, so fun abbl
Tunde ni oun ko ni wa si ipade
Sola beere boya a ti jeun
Bi a ba n se agbaso, ayipada maa n de ba oro aropo oruko tabi oro aropo afarajoruko, ti eni to n soro ba lo oro aropo-oruko tabi oro aropo-afarajoruko enikinni ninu oro re – oro aropo –oruko tabi afarajoruko eniketa ni eni to n se agbaso yoo lo. Apeere:
Mo ri owo he.
Agbaso- O ni oun ri owo he.
A ko mo won ri
Won ni awon ko mo won ri
Mo fo aso
O ni oun fo aso
Atunse maa n sele si oro-oruko
ap
Afo asafo: Eyi ni ki o ra.
O pase pe iyen ni ki o ra.
IGBELEWON
- Se agbaran awon afo asafo wonyi:
- Oye: Seun, se o ti jeun?
- Obasa: Banjo, bawo ni o se rin lanna?
- Folake: Suberu fe gbe ise fun mi.
- Se afo asafo awon afo agbaran wonyi:
- Tunde ni oun fe mo idi ti n ko fi wa.
- Basiru so pe omo naa ki i wa deede.
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3)
Copromutt Publishers Oju Iwe 231-233.
AROKO PIPA
Aroko je ona ti awon baba-nla wa fi n ba ara won soro laye atijo. Ami ni won fi maa n ranse si eni ti ko si ni tosi. A le fi aroko aye atijo we leta kiko lode oni.
ORISII AROKO AYE ATIJO
Aale: ni ami ti a maa n le lori eru tabi eso. A maa n fi ni kilo fun eniyan pe nnkan ti a ta mo ti ni oluwa ki enikeni ma di ibe.
Aaga: aaga ni ami ti a ta mo ara igi meji ti a ri mole lati fi kilo fun eniyan lati sa fun ewu.
Itufu: ni awon nnkan ti o le mu ina wa, ti a gbe seyinkule eniyan lati fi kilo fun iru eni bee pe ki o jawo kuro ninu iwa ika. Bi bee ko won n bow a jo ile re.
Asewelewe: jija ewe tutu sile ni ikorita bi ami ni lati fi so fun awon ti won dijo n lo si ibi kan pea won ti koja siwaju.
AMI IPAROKO NI AYE ATIJO
AMI ITUMO
- Owo-eyo eni naa ti di eni itanu.
- Ikarahun igbin ife nini. Okan re n fa mi.
- Iye wa kiakia. Ija ti pari. O ti fo lo bi eye.
- Iye ayekooto sora lati so otito.
- Aidan wa san gbese re ni kiakia.
- Ajoku owu iku tabi ewu wa nitosi.
- Awo Ehoro sa jinna rere. Ewu wa nitosi.
- Awo oju ilu oro ti kuro ni asiri. Gbogbo aye ti mo.
- Awe Obi oro ti yanju.
- Esun Isu dawo ohun ti fe se yen duro.
- Esuru oro naa ko gbudo su o.
- Kain-kain, osun iyawo ti bi omo tuntun
- Obi gbo tie.
IGBELEWON
Ki ni itumo awon nnkan woyin ti a ba fi ranse si ni:
- ooya
- eja
- akan
- obi
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Copromutt Publishers 76-82.
LITIRESO
ZT%NY@W) IX!
- Ki ni oro aropo oruko eni kin-in-ni mesan-an sile.
- Ko apeere oro oruko eni keji sile.
- Ko apeere oro oruko eni keta mesan-an sile.
ISE ASETILEWA
- ‘’Yemi: mo ti yo bamubamu’’. Afo agbaran gbolohun yii ni o ti yo bamubamu B. mo ti yo bamubamu C. oun ti yo bambamu D. o ti yo bamubamu.
- ‘’ mo n lo’’ afo agbaran gbolohun yii je A. o n lo B. o ni mo lo C. o ni oun lo D. o ti n lo.
- Tinu so pe oun feran iresi pelu eja tutu. Ki ni afo asafo gbolohun yii? A. mo feran iresi eleja tutu B. o ni mo feran iresi ati eja tutu C. o ni oun feran iresi ati eja tutu D. o feran iresi pelu eja tutu.
- Yemi ni awon ti pon omi. Ki ni afo asafo gbolohun yii? A. e ti ponmi sile B. a ti ponmi sile C. emi ti ponmi sile D. Yemi ni a ti ponmi sile.
- Ti won ba fi obi ranse si eniyan itumo re ni A. ki iku o bi lori eniyan B. ki eniyan maa tete bo C. ife ti pari D. ki eniyan gbo tie.
APA KEJI
- Ki ni afo asafo?
- Ki ni afo agbaran?
- Se alaye: kain-kain, esuru, awo oju ilu.
OSE KEJO
ORO ATI GOLOHUN ONIPONNA
Gbolohun oniponna-; ni gbolohun ti o ni ju itumo kan lo.gbolohun oniponna le je eyo oro tabi apola kan ni o maa ni ponna.
Itupale eyo oro oniponna ninu gbolohun.
Ayo ko le da mi. o tumo si pe
. Ayo ko le da mi [ se eda mi ].
Ayo ko le segun mi.
Isu rira ni Badejo gbin.Tumo si-
isu ti o ti ra[baje] ni Badejo gbin.
Isu ti o ra ni oja ni o gbin.
Ogun ile ni Ariyibi gbonju ba.tumo si pe-;
ile ogun ni Ariyiibi gbonju ba[20],o tun le tumo si
ogun ile ti oloogbe fi sile ni Ariyibi gbonju ba.
Itupale apola oniponna ninu gbolohun.
Gbolohun Itumo
Ayo wu mi Mo feran Ayo
Mo fe idunnu
Omo Akin Omo ti Akin bi.
Akinkanju omo.
Omo-ise Akin.
Iya aje naa ti de Iya ti o bi iya aje.
Iya ti o je aje gan-an ti de.
Akanlo-Ede Oniponna
Mo buta Mo jeun
Ki a fi owo bu ata si inu nnkan
Oba waja Oba ilu ku.
Oba ilu wo inu orule ile lo.
Se itupale fun awon gbolohun isale yii
Eran afoju naa ti jade
- Owo sinkun tite omo ole ifo.
- Ode aperin da iyepe lu abami eda naa ni oju ese.
- Baba ru agbe emu merin lo si oja.
ORO ONIPONNA
Odi (i) eni ti ko le soro. (ii) ogiri ti a mo yi ilu ka. (ii) odidi padi eyin.
Tinu (i) oruko eniyan (ii) nnkan ti o wa ninu.
Nu (i) ki eniyan pa nnkan re (ii) fun ni ni ounje je (ii) ki nnkan sonu.
IGBELEWON
Ko itumo mejimeji fun awon gbolohun/oro yii:
- Iya aditi se ogede.
- Olu keran.
- Ayo ni yoo pa omo naa.
- A o ni polowo.
- Olu le omo afin lo.
IWE ITOKASI
Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Copromutt Publishers 226-229.
EEWO
Eewo je ohun ti a ko gbodo se rara, awon Yoruba si gbagbo pe ti a ba se awon nnkan wonyi tabi ti a ba dejaa nnkan buruku le sele.
Eewo ni ohun ti a agba ni ile Yoruba pe eniyan ko gbodo se, bi eniyan ba si dejaa yoo jiya re. A da eewo sile lati le ko awon omode ni iwa imototo, omoluwabi, ibowofagba ati igbe laruge asa wa.
A le pin eewo ile Yoruba si awon isori wonyi:-
- Eewo ikilo / ikonilogbon
- Eewo iderubani
- Eewo ti o je mo eri okan tabi ikora eni ni ijanu
- Eewo idile
- Eewo ilu
- Eewo esin
- Eewo fun ibagbepo eda
Eewo ikilo: Eyi ni eewo ti a gbe kale lati fi kilo tabi lati fi ko ni logbon. Apeere:
– Aboyun ko gbodo rin ni osan tabi ni oru ganjo
– A ko gbodo fi igi owo dana
– Omode ko gbodo fi owo gbe ojo
Eewo Iderubani: Ni a maa n lo tabi deruba omode. Apeere:
– Omode ko gbodo to si aarin aaro ki iya re ma baa ku
– Omode ko gbodo jokoo si eti odo
– Omode ko gbodo jokoo si enu ona nigba ti ojo ba n ro
– A ko gbodo soro nigba ti a ba n jeun.
Eewo ti o je mo eri okan
- Ode ko gbodo ba iyawo egbe re se nnkan papo
- Babalawo ko gbodo gba iyawo babalawo lati dekun iwa odale
Eewo esin
- Obatala ko gbodo mu emu ope
- Onisango ko gbodo mu siga, je sese
- A kii fi adi ko esu. Eni ti o ba dejaa yoo ri ija orisa re
Eewo Idile/orile: Eyi ni eewo ti o je mo idile kookan. Apeere
- Iran onikoyi ko gbodo je eran okete ati eran oore
Eewo Aisan
- Eni ti warapa ba n se ko gbodo duro si ibi ti ariwo ba tip o.
- Eni aromolegun ba n se ko gbodo fo egungun eran ki ara riro re ma baa po sii
Eewo fun Ibagbepo
A kii toju elese mesan-an kaa ki ija ma baa sele.
IGBELEWON
- Ki ni eewo :
Obatala
Sango
Esu
- Ki ni gbolohun oniponna? Fi apeere meta gbe e lese.
LITIRESO
Kika iwe apileko ti ijoba yan.
APAPO IGBELEWON
- Ko itumo mejimeji fun awon gbolohun/oro yii:
- Iya aditi se ogede.
- Olu keran.
- Ayo ni yoo pa omo naa.
- A o ni polowo.
- Olu le omo afin lo.
- KO idile merin sile ki o si ko eewo idile kookan.
- Ki ni gbolohun oniponna? Fi apeere meta gbe e lese.
ZT%NY@W) IX!
- Ni ilana tabili, ko iyato laarin oro-oruko ati oro aropo oruko mefa sile.
ISE ASETILEWA
- Oro ….. je oro ti o ba ni ju itumo kan lo. A. aranmo B. atokun C. ise D. oniponna
- ‘’ a o je isu lale’’ oro-pon-na inu iso yii ni A. a B. o C. jesu D. lale.
- ‘’Omo akin’’ gege bi iso pon-na ni itumo A. eyo kan B. meji C. meta D. merin.
- ‘’Olu jata’’ tumo sip e Olu …… A. jata B. jeun C. daran D. binu.
- Awon idile ti won ki i je eran okete ni A. Eso Ikoyi B. Aresa C. Iremogun D. Onigbeeti.
APA KEJI
- Ko itumo awon:
- Omo naa ko wulo
- Mo pa iro
- Eti mi ti kun
- Iya aje.
- Ko eewo imototo marun-un sile.
OSE KESAN-AN
EYA AWE GBOLOHUN
Gege bi a se so saaju pe awe gbolohun pin si meji: olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe.
1 OLORI AWE GBOLOHUN Olori awe gbolohun ni gbolohun to le da duro pelu itumo.Fun apeere.
Bola jeun ni ori tabili
Sade ra aso ti ko ni iho lara
Ojo gbodo jeun ki o to lo oogun re. Gbogbo awon ti a fala si nidi yii ni a pe ni olori awe gbolohun. Sade ra aso, Bola jeun, Ojo gbodo jeun; awon wonyi ni itumo ju ni ori tabili,ti ko ni iho lara,ki o to lo oogun.
- AWE GBOLOHUN AFARAHE
Eyi ni apa keji odidi gbolohun ti ko le da duro funra re,o fi ara he olori awe gbolohun ni Apeere: –
Ode wa mu oti yo ni oru ana
Gbogbo ilu gbo pe oba ti waja
Mo ti lo ki ore mi to de
IGBELEWON
- Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe?
- Fa ila si idi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi:
a Inu mi dun pe n ko subu
b Bade n korin bi eye
d Oga so pe ki a tete de
e Oga olopaa de ni oru ana
ORISII EYA AWE GBOLOHUN AFARAHE ASAPONLE
(a) Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Alafiwe: gbolohun yii maa n se afiwe nnkan meji wunren “bi” tabi “bi” ni atoka re
Ade nkorin bi eye se nkorin
Omo naa kigbe bi eni ti agbon ta
(b) Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Alasiko: eyi maa n toka asiko ti nnkan sele ninu gbolohun tabi igba. Apeere: –
Baba maa wa nigba ti o ba de
Mo ri tade ni ale ana
Bo se n bo lati ile lo ti raa dani
(d) Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Onibi:- A maa n fi eleyi toka ibi ti isele inu gbolohun ti waye. Apeere:
Mo ba ore mi nibi ti o ti n mu oti
Tomi pade oko re ni ile ijo ti o lo.
Oluko gba mi ni ori
(e) Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Onidii Abajo:- eyi ni a fi maa nsalaye okunfa isele kan ninu gbolohun. Apeere
Mo n jiya nitori ki n le joro
Baba tete jii ko le sin ore re de idiko
Akeko naa tera mose ko le gbebun
(e) Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Onikan: – eyi maa n so ohun ti iba sele bi nnkan miran ba sele saaju ninu gbolohun Apeere: –
Nba tele yin lo, kani mo tete ji
Kani mojisola wa ni, oju iba tii
N ba ra moto kani mo lowo
(f) Awe Gbolohun Afarahe Asaponle Oniba:– irufe gbolohun yii maa n so iru ona ti nnkan gba sele ninu gbolohun. Apeere:- Ojo naa ro bi eni pe ile yoo ru
Ounje yii dun bi eni pe ki n ma siwo
Oluko na akekoo naa ni ana daju bole
IGBELEWON
- KI ni a n pe ni awe gbolohun?
- Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe?
- Ona meloo ni ale pin gbolohun afarahe pin si, daruko won.
- Ona meloo ni awe gbolohun afarahe asaponle pin si, daruko won.
IWE AKATIELWA
- S.Y Adewonyi (2004) New Simplied Yoruba L1 Copromutt Publisher Book Three Oju Iwe 43 – 44
- Oyebanji Mustapha (2002) Eko Ede Yoruba Titun University Press Plc Iwe Keji Oju Iwe 11, 12
- Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2003) Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe Keta Oju Iwe 22- 23
IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ASEYIN WAYE ATI AWON ABANI EDA.
- Itumo aseyinwaye (iye leyin iku)
- Ohun to mu Yoruba gbagbo pe ajinde n be leyin iku
AKOONU
Awon Yoruba ni igbagbo ninu iye leyin iku, won gbagbo pe bi eni won ba fi owo rori ku, o le pada wa ya lodo omo re ki won si tun bi. Eyi ni o mu won maa so oruko bii Babawale, Babajide, Iyabode, Yejide. Bakan naa won gbagbo pe eni ti o ba ku ni rewerewe ko le lo si orun taara, kaka bee yoo maa rin kaakiri ni, o si tun le lo si ile ibomiran lati maa gbe, iru awon bee ni a mo si akudaaya. Bakan naa nitori igbagbo ti won ni ninu iye leyin iku ni won se maa n sin owo, ounje ati awon nnkan miiran mo oku laye atijo pe ti oba je ile ibomiran, a le ri owo ati ounje lo lohun-un.
Igbagbo awon baba-nla wa nipa abiku tun fi igbagbo ninu iye, leyin iku han, eyi ni o mu ki won maa so omo won loruko bii Malomo, Okoya, Kokumo, Kosoko abbl.
Igbagbo awon baba wa tun han nipa abobaku, ni aye atijo ti oba ba ku, ti won ba maa sin-in pelu Abobaku ni, awon wonyi logbodo ku pelu oba, won gbagbo pe ti oba ba ji si ile ibomiran, ko le ri awon eru ti a maa ran nise.
IKINI
Awon Yoruba ni igbagbo ninu iye leyin iku. Eyi si han ninu ikini won lakoko ti oku ba ku . Won a ni iya a ya o. Baba a somo o.
Igbelewon:
Pelu apeere salaye Igbagbo awon Yoruba ni pa aseyinwaye ati abani-eda.
EKA EDE
EDE YORUBA ATI AWON EKA RE
Ki ni ede Yoruba? Okan lara awon ede pataki ti a n so ni orile-ede Naijiria ni ede Yoruba. O je ede ti o gbajugbaja. Ti o si bi opolopo omo. Awon omo ti o bi yii ni eka ede ti o wa ni abe isori ede Yoruba. Ede yii ni a le ka kun ede ajumolo ni aarin awon Yoruba. Ohun ni ede ti a fi maa n se ipade, Ko omo ni ile iwe, ko iwe iroyin, polowo oja, ti a si tun n lo o lati yannanna ohun ti o ba ruju laarin ara wa. Idi niyi ti a fi ka kun ede ajumolo.
Ipinle mesan ni ede Yoruba je ede abinibi fun ni orile-ede Naijiria. Awon ipinle bii: Eko, Ogun, Oyo, Osun, Ondo, Ekiti, Kuwara, Kogi ati Edo. Nitori idi eyi koseese ki iyato diedie ma wa lati awujo kan de ekeji. Koda iyato yii le farahan de ibi pe a fere le ri eka ede wonyi gege bi ojulowo otooto. Die lara awon eka ede Yoruba ni Ife, Owo, Remo, Awori, Egba, Ijebu, Oyo, Onko, Igbomina, Akoko, Ekiti, Ijesa, Ketu, Gbede, Eko abbl.
Okookan awon eka ede wonyi ni o tun ni eka won. Fun awon apeere awon ilu ti o n so Ijebu ni Epe, Ikorodu, Ijebu Ode, Remo, Ikenne.
Awon ilu ti o n so Onko ni: Ayetoro ati Saki.
Awon ilu ti o n so Ibarapa ni: Lanlate, Eruwa, Igboora, Tapa, Igangan.
O soro lati so ni pato, iye eka ede to wa ninu ede Yoruba, nitori pe bi ilu se n paala laarin ara won, ni iyato die n ba eka ede won. Sugbon nitori pe agboye wa laarin awon ilu ti won jo paala, a ko ni tete fura si iyato awon eka ede ti won n so. Fun apeere, awon ara Saki gbo Iganna, Iganna gbo ti Iganna. Igboora gbo ti Igangan. Ayetoro gbo ede Igboora ni agboye Egba gbo ede Ayetoro. Remo gbo ede Egba. Ijebu gbo Remo bee ni awon Ijebu Waterside gbo ede awon Ilaje. Sugbon ti ara Saki ba n takuroso pelu ara Ilaje ese odo, o se e se ki agboye ma wa. Won tile lero pe ede otooto ni awon n so.
O ye ki a mo pe ko si eka ede to je erusin fun eka ede miiran, sugbon o se e se ki won gbajumo ju ara won lo. Ise kan naa ni gbogbo eka ede jo n so fun ibanisoro ati ibagbepo ojoojumo ni awujo kookan.
EDE YORUBA AJUMOLO
Yoruba ajumolo ni ede Yoruba ti a n so ti ki i se okan naa pelu eyikeyi awon eka ede ti a ti so saaju. Awon miiran a tie maa pe e ni ojulowo ede Yoruba sugbon a ko fee se eleyi. Bi a ba pe Yoruba ajumolo ni ojulowo ede Yoruba a je pe a gba pe gbaro-gudu ni eka ede Yoruba to ku. Eleyii ko dara to.
ORIKI FUN EDE ABINIBI
Ede abinibi ni ede ti a bi omo sinu re, ti omo naa dagba sinu re ti o si gbonju ba ni awujo ti o ba ara re. Ede abinibi ni ede ti omo maa n gbonju ba ni ayika re nigba ti o koko bere oro siso. Eyi maa n wa lowo agbegbe ti omo bee ba ara re. Omo ti obi re je Hausa ti won gbe ni ile Yoruba. Ede abinibi omo naa yoo je Yoruba.
ORISUN EDE YORUBA
Ede Yoruba je okan lara awon ede ti a n so ni orile ede Naijiria. Looto ni a ri ibi ti won ti n so ede Yoruba ni apa iwo oorun Afrika ati ni ile alawo funfun sugbon o soro lati so pato ibi ti oruko naa ti san wa. Opolopo ojogbon ni o ti so nnkan nipa re.
Awoniyi (1978) gbagbo wi pe oruko ti awon ajoji kan ronu lati fun awon eya ti o n so ede yii ni ‘aku’ awon miiran tun gbagbo pe awon Hausa ni o pile orukon ti awon eya yii n je loni nitori awon Hausa yii ni o koko n pe okunrin ti won ni ‘Yaribawa’‘ ti won si n pe obinrin ni ’Yarabanci’’. Atotonu miiran ni wi pe lara ede ti won n pe ni ‘’Kwa’’ ni ede Yoruba ti jade wa.
Awon ipinle meje ti o n so ede Yoruba yii julo ni orile ede Naijiria ni Eko, Ogun, Oyo, Osun, Ekiti, Ondo ati Kwara. Bakan naa ni awon apa ibi kan ni ipinle Kogi ati Edo. Ni apa iwo oorun Afrika ni ile olominira Benin, Togo, Ghana, Cote d’Ivore, ni won ti n so ede Yoruba. Ni apa iha Guusu Amerika bi (Cuba, Brazil) Haiti Trinidad ni a tun ri awon ti o n so ede yii bakan naa.
ORIKI FUN EKA EDE
Orisii oriki ni awon ojogbon ti fun eka ede. Eka ede ni ede ti awon eya kan tabi adugbo kan n so ni ile Yoruba. A tun le so wi pe eka ede ni ona ti iro tabi oro kan gba yato si ekeji ile Yoruba. A tun le so pe eka ede ni okan lara ede ajumolo ti awon eya kan ti okun ede Yoruba so papo.
Iro ki i se bakan naa ni gbogbo ede bee si ni iro ohun yato si omiran. Eyi tumo si wi pe ki oro ni itumo kan naa ki pipe won si yato si ara won.
Fun apeere: ninu ede ajumolo:
Inu mi dun nigba ti mo ri o.
Ijesa: Inu mii dun, nigbi mo ri o.
Ondo: I no mo don, nigi mo ri o.
Egba: Igba i mo ri o, inu mi dun.
Ijebu: Inu mii dun, Ki mi ri e.
Eka ede ni ona ibanisoro ti awon ara adugbo kan fowo si fun ibasepo owo, oro aje,esin,oselu, eto eko abbl. Ti o yato si ti awon ara adugbo miiran ni agbegbe kan naa. A tun le so pe eka ede ni ibanisoro ti awon owo tabi egbe kan n lo ti o yato si ti awon miiran.
IPINSOWOOWO AWON EKA EDE
Ipinle Eko:
Awori: awon ilu won n so niwon yii: Egan Oke, Egan Eyin, Osa, Oto, Ikanikin, Obadoore, Idoluwo, Iseri, Ikeja, Musin, Isagira, Etegun, Ojota.
EKA EDE IJEBU
Ikorodu ati agbegbe re, Epe, Ibeju, Imota, Odo Iragunse, Ilara, akodo abbl.
IPINLE OYO
Awon ilu ti won n so ede Oyo ni wonyi: Oyo, Ibadan, Fiditi, Jobele, Akinmoorin, Ajaawa, Ogbomoso, Ogbomoso abbl.
EKA EDE ONKO
Awon ilu ti n so ede Onko ni wonyi: Igbeti, Igboho, Saki, Ago Amodu, Aba, Iseyin, Sepenteri Kisi, Tede, Ago Awaye, Out, Okeho, Iganna, Igboora, Owo, Irawo ati Iwere abbl.
IPINLE OSUN
A ni awon eka ede yii ni ilu won:
EDE IJESA
Awon ilu ti won n so ede Ijesa ni: Ilesa, Ibokun, Osu, Ipetu Ijesa, Ikeji, Arakeji, Ijebu Ijesa, Idominasi, Imesi Ile, Erinmo, Erin, Iperindo.
EDE OSUN
Awon ti won n so ede Osun ni: Ede, Osogbo, Ogbaagba, Ifon, Ifon Osun, Erin Osin, Iragbiji, Erinpa, Ikirun, Otan abbl.
EKA EDE OYO
Awon eya ti won n so ede Oyo ni Osun ni Ila Orangun Oke Ila.
IPINLE OGUN
- EKA EDE EGBA: Abeokuta ati agbegbe re, Waasinmi, Owode, Papa abbl.
- EKA EDE YEWA: Ayetoro, Ilaro, Ajilete, Oke-Odan, Igbogila, Imeko, Ijofin, Ibooro, Saala, Ifonyin abbl.
- EKA EDE AWORI: Agbara, Igbesa, Ota, Atan, Ijoko.
- EKA EDE IJEBU: Ijebu Ode, Ijebu Igbo, Ago Iwoye, Ikene, Isara, Ososa, Ijesa, Ijebu, Ijebu Ife, Abigi, Jobore, Ijebu, Ilese, Ijebu-Musin abbl
- EKA EDE OHORI: Ijoun, Tata, Igan Alade, Igan-Okoto abbl.
EKA EDE ONDO
- AKURE: Iju, Ita-Igbolu, Ijare, Oba Ile, Igbatoro, Uso, Ilaramokin, Oda
- EDE OWO: Owo, Ipele, Iyere, Isuada Emure, Ipeme, Ikaro, Ifon, Okeluse, Imoru, Ute, abbl
- EDE ONDO: Ondo, Ile-Oluji, Idanre, Odigbo, Ore, Ondo Igbedo, Bagbe, Laje, Laamu, Erinla abbl.
- EDE IKALE: Iju-odo, Igbotako
- EKA EDE ILAJE: Igbokoda, Ugbonla, Ilu-titun, Ode-aye, Okitipupa, Ode Irele, Araromi abbl.
IGBELEWON
- ki ni ede ajumolo?
- Ki ni eka ede?
- Ko iyato merin laarin ede ajumolo ati eka ede.
APAPO IGBELEWON
- KI ni a n pe ni awe gbolohun?
- Iyato wo lo wa laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe?
- Ona meloo ni ale pin gbolohun afarahe pin si, daruko won.
- Ona meloo ni awe gbolohun afarahe asaponle pin si, daruko won.
- ki ni ede ajumolo?
- Ki ni eka ede?
- Ko iyato merin laarin ede ajumolo ati eka ede.
ZT%NY@W) IX!
- Ki ni oro ise?
- Ko abuda oro ise mefa sile pelu apeeremeji meji.
ISE ASETILEWA
- ‘’Mo ri e ni oru ana ni oru ana’’ je awe gbolohun afarahe ……… (a) asaponle(b) asapejuwe (d) asodoruko (e) alasiko
- Iwe ti mo ra ti faya ‘ti mo ra’ je awe gbolohun aafarahe …… (a) asaponle (b) asapejuwe (d) asodoruko (e) alasiko
- Apeere awe gbolohun afarahe asodoruko ni (a) yo bi ojo (b) nba wa ka ni e wi fun mi (d) pe mo de dun mo won (e) Ile ti mo ko ga
- Nba wa ka ni e wi fun mi ‘’ka ni e wi fun mi;; je apeere awe gbolohum afarahe… (a) asodoruko (b) onikani (d) asapejuwe (e) alasiko
- Olori awe gbolohun ni wonyi AYAFI (a) Ode pa etu (b) Ojo ro (d) ni abule oja (e) Bola ra aso.
APA KEJI
- ki ni eka ede?
- Ki ni ede ajumolo?
- Ko iyato meji laarin olori awe gbolohun ati awe gbolohun afarahe.
OSE KEWAA
APOLA
AKOONU: –
- Ki ni a n pe ni Apola.
- Ki ni Apola oro Oruko
- Ise ti Apola Oro Oruko n se ninu Gbolohun?
- Ki ni a n pe ni Apola ise?
- Ise ti Apola Ise n se ninu Gbolohun
Apola ni akojopo oro ti o n di apa kan gbolohun. Apola le je eyo oro kan, o si le je meji tabi ju bee lo. Orisiri apola lo maa n di apa kan tabi odidi gbolohun.
Apola oro oruko ni eyo oro oruko kan tabi meji tabi ju bee lo ti o di apa kan odindi. O si le je apapo oro oruko ati oro oruko eyan ninu gbolohun Yoruba. Apola oro oruko le je oro oruko, oro aropo oruko, tabi aropo afara joruko.
Apeere apola to je eyo oro oruko kan
Iwe
Moto
Aso
Ileke
Apola le je eyo oro oruko meji tabi ju bee lo
Oju titi
Omi ojo
Baba agbe
Igi oko
Awa omo baba olowo ilu yii niyi.
Oko ayokele oloye ni mo ra
Apola oro oruko ati eyan
Ewu tuntun meji ni mo ra
Ile tI mo ko ga fiofio
Ise yi ma le o
Iwo gan-an lo mu owo mi
ISE TI APOLA ORO ORUKO N SE
- Apola oruko maa n duro gege bii oluwa ninu gbolohun. Apeere:-
Mo je eba
Iwo ri olopaa
Ade pa aja
- Apola oro oruko tun le duro ni ipo abo ninu gbolohun. Ohun ni ohun ti oro ise maa n fi abo le lori ninu gbolohun. Apeere:-
Ife ra fila
Tisa na omo naa
Mo pe won
- Apola oro oruko le duro ni ipo eyan ninu gbolohun. Apeere:-
Ise akowe dara
Ounje Jumoke ni mo fe je
Ere ipa ko dara.
APOLA ISE
Oro ise ni opomulero ti o n toka si isele tabi koko inu gbolohun. Oro ise maan ko ipa Pataki ninu gbolohun ede Yoruba. Apeere Oro ise:-
Mo ta oja
Ade jeun
Omo naa n sunkun.
Apola oro ise le je eyo oro ise kan tabi oro ise meji tabi ju bee lo. Osi le je apapo oro ise pelu isori oro miiran ninu gbolohun Yoruba.
Apeere:- apola eyo oro ise kan.
Anike sun
Sangba fo
Ile jo
Oko danu
Apeere Apola Oro Ise Meji Tabi Ju bee Lo.
MO sare lo sun
Bola ti jise ti mo ran-an
Tade je isu ti ko jina
Apeere apola oro ise pelu isori oro miiran le je oro oruko, aponle, asapejuwe ati bee be lo.
Omo pupa kekere kan n wa iya re
Mo tete de si ipade lonii
O sun fonfon leyin ounje ale
ISE APOLA ORO ISE NINU GBOLOHUN
- Oro Ise Agbabo:- Awon oro ise kan wa ti won maa n ni oro oruko ti o tele won ninu gbolohun, iru awon oro ise bee ni a maa n pe ni oro ise agbabo. Iyen nipe won maa n ni abo ninu. Apeere:-
Tafa ta ofa
Jide ra keke kan
Mo ja ijakadi
- Oro Ise Alaigbabo:- Eyi ni awon oro ise ti kii ni oro oruko kankan ninu to duro gege bi abo ninu gbolohun. Apeere:-
Isu naa jina
Agbado hu
Tata n fo
Oro Ise Amugbalegbee:- Oun naa ni a mo si oro aponle. O maa n fun oro ise ni itumo kikun to si ja gaara. Apeere:-
Mo tete de
Ade sise gidi
Alejo mi sese de
IGBELEWON
- KI ni apola?
- Ki ni aplo oruko?
- Ki ni apola ise?
- Toka si apola oruko ni ipo oluwa nihihin
Ode pa eran
Sola ge igi
Baba wo oko ayokele
- Iru apola wo ni won fala si nidi yii
Tafa ta ofa
Agbado hu
IWE AKATILEWA
- Y Adewoyin (2004) NEW SIMPLIFIED YORUBA L1 J.S.3 Copromutt (publishers) Nigeria Limited Oju Iwe 15-16.
- Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe Keji Oju Iwe 8-10 Longman Nigeria Plc.
- Oyebamiji Mustapha Eko Ede Yoruba Titun Iwe Keji Oju Iwe 17-18 University Press.
- Egbe Akomolede ati Asa Yoruba Eko Ede ati Asa Yoruba Iwe Keji Oju Iwe 20-22 Longman Nigeria Plc.
- Oyebamiji Mustapha Eko Ede Yoruba Tunutun Iwe Keji Oju Iwe 102-103 University Press Plc.
IGBAGBO AWON YORUBA NIPA OLODUMARE
Akoonu: igbagbo awon Yoruba nipa Olodumare.
Orisiirisii oruko Olodumare
Ifihan ero Yoruba lori oruko Olodumare
Ohun ti opolopo awon eniyan lero ni wi pe awon Yoruba ko mo Olorun tele afi igba ti awon elesin Kristi ati awon islam to de. Iro patapata ni eyi. Awon Yoruba ti n sin Olorun ki awon elesin ajeji to de. Lara awon ohun ti o je ki a mo ni oniruuru oruko ti a n pe Olorun. Oun ni a n pe ni Olodumare tabi Eledumare,Olu orun,Olorun, Eledaa, Adedaa, Obanjigi, Oba ogo abbl.
Awon yoruba beru Olorun pupo bakan naa ni a si tun bowo fun. Idi niyi ti a ki I fi ku giri lo ba tabi ki a maa beere nnkan lowo re. Dipo bee a yan awon orisa kan gege bi asoju wa tabi alagbawi wa lodo re. Awon iru orisa bee ni Ogun, Sango, Orunmila, Obatala abbl. Awon wonyi ni awon Yoruba maa ran si Olorun nigba ti won ba fe gba nnkan lowo re.
Die lara awon oruko ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olorun ni:
- Olowogbooro
- Eleti gbaroye
- Atererekaye
- Awimayehun
- Olodumare
- Obanjigi
- Olorun
- Olu Orun
- Oba Ogo.
- Kabiyesi
- Jingbinikin
- Arogunmatidi
- Arabaribiti
IGBELEWON
Ko oruko Olodumare marun-un ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olodumare sile.
IWE AKATILEWA
1 Egbe Akomolede ati Asa Yoruba (2002) Eko Ede ati Asa Yoruba iwe keji (J.S.S.2) Longman Nig Plc.oju iwe 95-97
2 Oyebamiji Mustapha (2009) Eko Ede Yoruba Titun iwe keji (J.S.S.3) university Press Plc.oju iwe 181-18
APAPO IGBELEWON
- Ko oruko Olodumare marun-un ti o fi igbagbo awon Yoruba han nipa Olodumare sile.
ZT%NY@W) IX!
- Ki ni oro aropo afarajoruko?
- Ko apeere oro aropo afarajoruko sile.
- Ko iyato merin laarin oro aropo oruko ati oro aropo afarajoruko merin.
ISE ASETILEWA
- Apola oro oruko le wa ni ipo oluwa, abo ati _____(a) ise (b) eyan
(d) Apejuwe
- Oro wo ni o n sise oluwa ninu gbolohun yii “Ayo ba Tunde ja” (a) Tunde
(b) Ba (d) Ayo
- ______ ni opomulero gbolohun (a) Oro oruko (b) Oro ise (d) Oro aponle
- Isori oro wo ni a ko le ba pade ninu apola oro ise? (a) Ko si (b) Oro oruko (d) oro
aponle
- Oro ise alaigbabo ki i ni _______ ni ipo abo (a) ni oro ise (b) ni oro oruko
(d) Kii ni oro atokun.
APA KEJI
- ko oruko Olodumare mewaa sile.
- ki ni apola oruko?
- Ki ni apola ise?
- Ki apola apejuwe?