Yoruba d’un ká

Ipin Kiini: Iwekika Otito Bori 

1.) Ilu wo ni itan yii ti sele (a) Ayekooto (b) Ayedande
2.) Kini ise Mosun (a) agbe sise (b) oja tita
3.) Talo se ija mba fun Mosun? (a) Arugbo kan (b) omode kunrin kan
4.) Bawo ni won se ko ba Mosun?
(a) Won pariwo ole le Mosun (b) Won fi oja fayawo ranse si iso Mosun
5.) Talo jebi? (a) Alake (b) Ero Oja

Ipin Keji: Alo Apagbe: Ijapa ati Erin
1.) Ijapa ati _____ maa nse ore po (a) erin (b) elede
2.) Ni akoko yii, awon oba ilo maa nfi ______ bo ori won (a) eja nla (b) eranko nla
3.) Ijapa se ileri fun ______ pe, oun yoo mu erin wo lu fun-un (a) oba (b) ijoye
4.) Ijapa ologbon ewe fun Erin ni _____ aladun (a) robo (b) agbado
5.) ______ ni won fi din (a) ororo (b) oyin

Ipin Keta: Ikini
1.) Awon wo ni Yoruba nki bayii pe:- Olorun yoo wo, A a ni owo rere leyin o.
(a) aboyun (b) eni ti o sese bimo
2.) Awon wo ni Yoruba nki bayii pe, isokale anfaani o, afon a gbo, ko to wo
(a) aboyun (b) abiamo
3.) Awon wo ni Yoruba nki bayii pe, aje a wo igba o, ata jere o (a) onidiri (b) oni sowo
4.) Awon wo ni Yoruba nki bayii pe: Aboru boye o baba. (a) Babalawo (b) onisegun
5.) Awon wo ni oruba nki bayii pe:- igba a ro o, I emo se o (a) awako (b) akope

Ipin Kerin: Ipolowo Oja
1.) Oja wo ni a npolowo bayii: langbe jinna o, orokun ori ebe (a) agbado (b) iso
2.) Oja wo ni a npolowo bayii: gbeturuo, omi akerese, kii ndun lodo, to ba dele, a doyin
(a) eran (b) eja tutu
3.) Oja wo ni a npolowo bayii o gbona felifeli, o ntu muye, o ntu we e (a) isu (b) iresi
4.) Oja won ni a npolowo bayii: a rokun epo oyinbo (a) elepo pupa (b) oni karosini
5.) Oja wo ni a npolowo bayi:- __ elelo, __ elemi meje (a) dundun (b) moinmoin