Ọ̀RỌ̀ ÀGBÀ SỌ (INDIRECT SPEECH)

Subject : Yoruba

Class: SS 3

TERM: FIRST TERM

WEEK: WEEK 5

OSE KARUN – UN

ORO – AGBASO

Akoonu

Oro agbaso naa ni a mo si afo agbaran.

Oro agbaso:- je siso oro ti a gbo lenu oloro fun elomiran. Iru oro tabi iroyin bee gbodo je eyi to ti koja. Oro agbaso le je ohun ti enikan so nipa wa tabi elomiran. O si le je iroyin ohun to sele nibi kan. Awon wunren atoka oro agbaso ni so, wi, ni, ki, pase, wi pe, salaye, so fun  abbl

Tunde ni oun ko ni wa si ipade

Sola beere boya a ti jeun

 

Bi a ba n se agbaso, ayipada maa n de ba oro aropo oruko tabi oro aropo afarajoruko, ti eni to n soro ba lo oro aropo-oruko tabi oro aropo-afarajoruko enikinni ninu oro re – oro aropo –oruko tabi afarajoruko eniketa ni eni to n se agbaso yoo lo. Apeere:

Mo ri owo he.

Agbaso-           O ni oun ri owo he.

A  ko mo won ri

Won ni awon ko mo won ri

Mo fo aso

O ni oun fo aso

Atunse maa n sele si oro-oruko

ap

Afo asafo: Eyi  ni ki o ra.

O pase pe iyen  ni ki o ra

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i

 

ASA

EKO ILE

(Eko imototo, itoju ara, ikini, oro, siso, ounje sise, awo fifo)

Akoonu

 

Eko Ile:- Je ilana eko abinibi ti awon obi fi n ko awon omo won lati kekere. Yoruba ni kekere ni musulumi  ti n ko omo re laso. Awon Yoruba ka eko-ile si pupo, won a si maa du u ni gbogbo ona lati ko omo won, ki won si rii  pe omo naa gbeko, nitori won gbagbo pe omo ti a o ba ko ni yoo gbe ile ti a ko ta.

Omo ti a ko ti ko gba ni akoogba. Won gba pe ajoto ni omo kii se ajoke .

 

Eko–ile: ki i se ojuse obi nikan, ojuse gbogbo ebi ni lati ko omo. Ni ile Yoruba, ni kete ti a ba ti bi omo si aye ni eko ti n bere titi yoo fi dagba bee ni eko ile ko ni opin, eko omobinrin bere lati kekere titi ti yoo fi wo ile-oko.

 

Imototo: Lati kekere ni awon Yoruba ti n ko omo won ni imototo, won a ti we fun won laaaro, won a fo enu fun won, iwa yii naa ni awon omo maa tele ti a si mo won lara dagba.

Ikini:- Je asa ti o se pataki  laarin awon Yoruba , ojuse gbogbo obi  si ni lati fi ko omo, won a ti ko won lati kekere pe bi a ba ti ji laaaro kutukutu omode gbodo koko ki awon obi re pe obinrin a kunle, okunrin a si dobale.

E ku ikale ni a n ki eni to wa ni ijoko.

‘E  ku ewu’ – omo ni a n ki eni to bimo .

‘mo kota, mo kope ni a n ki awon tin ta ayo.

Gbogbo ikini wonyi ni awon Yoruba fi n ko omo won lati kekere.

 

Oro siso:- lati kekere ni awon Yoruba ti maa n to awon omo won sona nipa oro siso, pe kii se gbogbo oro tabi ohun ti a ri ni a n so; bakan naa won a to won sona nipa bi a se le ba agbalagba soro laini fi enu ko tabi ri agba fin nitori pe eko ile ni atona fun iwa rere.

Lati kekere naa ni awon Yoruba pataki julo awon iya yoo ti maa ko awon omobinrin bi a ti n toju ounje ati bi a se n se ise ile laaaro, ile gbigba ati abo fifo.

 

Litireso:- Kika iiran karun-un, kefa ati ikeje ninu iwe Adakedajo.

 

IGBELEWON

  1. Kin ni oro-agbaso?
  2. Se agbaso oro ti Alaga ijoba ibile agbegbe re so ninu ibewo re si ile eko re.

Mo ki gbogbo eyin oluko ati akeko, E ku ojo meta o. Inu mi dun pupo lati rii pe gbogbo ayika ile –eko yin lo mo tonitoni. Ise ribiribi ni e n se nile iwe tiyin. Gbogbo ohun ti e n fe ni oga ile-iwe yin ti fi to mi leti. Awa naa yoo gbiyanju lati ran yin lowo.

 

APAPPO IGBELEWON

  1. Kin ni oro-agbaso?
  2. Ki ni eko ile?
  3. Ko apeere afihan eko ile meje sile.

Ko apeere awon merin ti won maa n ko pa ninu eko ile.

 

ISE SISE

Seda oro oruko merin pelu: lilo afomo ati apetunpe

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers S.S.S.1 o.i

 

IWE AKATILEWA

Imo, Ede, asa ati litireso SS 2

Adewoyin S.Y. O.i 156 – 158

Eko Ede Yoruba Titun. Oyebanji  SS.2 o.i 123 – 124

Adakedajo – iran kejo & ikesan

 

ISE ASETILEWA

  1. Iwonyi ni oluko eko-ile fun omo ayafi (a) obi (b) ebi (d) Tisa
  2. Mo kota, mo kope ni an ki awon ti n (a) ta yo (b) ko ebe (d) di irun
  3. Ona pataki ti a fi n mo omluabi ni (a) ewa nini (b) ikini pelu oyaya (d) iran wiwo
  4. ‘Emi kii se ole eniyan’ oro agbaso re ni (a) oluko so pe emi kii se ole (b) Oluko so pe oun kii se ole (d) Oluko so pea won akekoo kii se ole
  5. Kanni ati Alade tun sa __________ jo ni eleekeji (a) Egberun mewaa (b) Egberun meedogun (d) Egberun lona ogun

 

APA KEJI

  1. a. Kin ni oro-agbaso?
  2. Salaye awon iyipada ti o maa n ba isori oro kookan pelu apeere
  3. Kin ni eko ile?

Ona wo ni awon Yoruba n gba  lati ko awon omo won ni iwa imototo, Ikini ati oro siso ni aye atijo.