ÌYÀTÒ TI O WA LAARIN Ọ̀RỌ̀ APỌNLE ATI ÀPÓLÀ APỌNLE

Subject : Yoruba

Class: SS 3

TERM: FIRST TERM

WEEK: WEEK 7

 

OSE KEJE

IYATO TI O WA LAARIN ORO-APONLE ATI APOLA-APONLE

Isori oro ni oro-aponle sugbon apola aponle gbooro ju oro-aponle lo.

Apeere:

Ojo tete de

O de nigba ti Ojo wole

Isori oro-aponle nikan ni oro-aponle je mo sugbon apola aponle je mo alopo oro-atokun ati oro-oruko

Baba olu gbon pupo

Aso mi mo tonitoni

Apola – aponle

Apeere:

Ile nlanla po ni Eko

Aja kan ku si ita

Ninu oro-aponle a ko le gbe oro-aponle si iwaju gbolohun

Apeere:

O dun mi gan an

Gan-an ni o dun mi

Tete ni ojo de

Oro-aponle ko se e gbe siwaju fun itenumo sugbon apola-aponle se e gbe siwaju fun itenumo

Apeere:

O se pupo

Pupo ni o see

Baba agba rin pelepele

Pelepele ni baba agba rin.

 

IGBELEWON

Salaye pelu apeere iyato meji to wa laarin oro-aponle ati apola-aponle.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i 204-208

 

ASA

Oran dida ati ijiya ti o to,

Oran dida ati ijiya ti o to

  • Itumo
  • Ohun ti o faa
  • Orisii oran ti eeyan le da
  • Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je odaran
  • Orisirisi oran ti eeyan le da
  • Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je arufin

 

AKOONU

Se Yoruba bo won ni ‘ilu ti ko si ofin ese ko si, bakan naa awon Yoruba ni igbagbo ninu idajo ododo won ki i si i fi ejo se egbe.  Bakan naa, won ni elese kan ki yoo lo laijiya nitori idi eyi gbogbo oran lo ni ijiya. Oba, ijoye ati awon ologboni lo maa n se eto idajo ni aye atijo.

 

Oran Dida:  Ni ti tapa si ofin tabi rire ofin ilu kan koja ni pa sise ohun ti won ni won ko gbodo se tabi sise omonikeji ni ibi.  Ohun ti o n fa oran dida orisiirisii ni ohun ti o le fa oran dida, die ninu won niyi:-

  • Ojukokoro
  • Iwa imotara eni nikan
  • Aini itelorun
  • Etanu
  • Aigboran abbl.

Orisiirisii oran ti eeyan le da ati ijiya ti o to sii.  Eyi ni orisiirisii oran ti eeyan le da:

ipaniyan, ole jija, idigunjale, ifadiya, jibiti lilu, aje sise, biba iyawo oniyawo lopo, lilo oogun ika, gbomogbomo abbl.            Ipa ti oba ati ogboni n ko ninu fifi iya je odaran.

 

Ipa kekere ko ni oba ati awon ogboni n ko ninu fifi iya je odaran.  Gege bi a se mo pe oba ni olori ati alase ilu, ti o n ri si idagbasoke ati aabo ilu, ti odaran ba daran, ti o si ju eyi ti Baale tabi Baale le pari lo, aafin oba ni won yoo mu iru odaran bee lo, ti oba ati awon ijoye yoo si jiroro lori iru iya ti won yoo fi je iru odaran bee.  Bakan naa ni awon ogboni naa ko gbeyin ninu fifi iya je arufin.

 

IGBELEWON

Daruko oran marun-un ti eeyan le da.

 

Ori – Oro:- ITANDOWE

– Kin ni itandowe

– Siso itandowe kookan

– Tokasi owe ati Asayan to suyo ninu itan naa.

 

Akoonu

Itandowe: Je awon itan ohun kan ti o ti sele ni aye atijo ti awon baba-nla wa si so isele inu itan naa di owe.

Itandowe le je itan atenudenu bii itan ogun, itan isedale tabi itan aroso. Apeere itandowe.

Ogbon ti alabahun gbon, eyin ni yoo ma to igbin.

Inu itan aroso yii ni owe yii ti jade. Ni ojo kan alabahun, ti adape re n je ijapa Tiroko oko yanubo, ni oun fe ko gbogbo ogbon aye jo sinu akangbe kan. Loooto, o ko awon ogbon yii jo, o si dii pa mo inu akangbe. Ijapa wa fe lo toju akengbe yii si ori igi kan, ki o ma ba a si mi arowoto enikankan rara.

O so Okun mo akengbe yii ni orun, o gbe akengbe si ogangan aya, o fe gun igi naa lo.

Bi o ti n gun igi yii ni o n jabo nitori pe, akengbe to gbe ko aya ko je ki owo re ka igi to fegun daadaa. O n se idiwo fun-un igba die. Inu isoro yii ni o wa ti igbin fi de baa, ti o si koo pe ki o yi akengbe si eyin ki o le rorun fun-un. Ijapa se bee, o si ri igi naa gun.

Ijapa wa gba pe ogbon tun ku si ibikan, ati pe eni ti o si tun gbon ju oun lo wa.

O si fi ibinu fo akengbe ti o ko ogbon  jo si. Isele yii ni o faa ti awon eniyan fi maa n paa ni owe lati igba naa. E wo bi igbin se kere si ijapa.

 

Owe ati Asayan oro to suyo ninu itan naa.

Ninu itan ogbon ti alabahun gbon, eyin ni yoo maa to igbin’ a ri i pe ijapa ro pe oun ni oun gbon ju, ko tun si elomiran  mo, eyi ni o mu un hu iwa omugo ti o hu. Sugbon o mo nigba ti o ya pe igbin, bi o se kere to tun gbon ju ohun lo.

 

IGBELEWON

  1. a. Kin ni oran dida?
  2. Daruko orisii oran marun-un ti eeyan le da ati ijiya ti o to fun oran naa.
  3. Pelu apeere salaye iyato ti o wa laarin oro-aponle ati apola-aponle.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Salaye pelu apeere iyato meji to wa laarin oro-aponle ati apola-aponle.
  2. Kin ni oran dida?
  3. Daruko orisii oran marun-un ti eeyan le da ati ijiya ti o to fun oran naa.
  4. Pelu apeere salaye iyato ti o wa laarin oro-aponle ati apola-aponle.
  5. Ko owe meji ki o itan ti o je mo eyo kan.

 

ISE SISE

  1. Ki ni fonoloji? Pelu apeere.
  2. Ki ni aranmo? Pelu apeere
  3. Ki ni oro ayalo?
  4. Pelu apeere

 

IWE AKATILEWA

Eko Ede Yoruba titun – Oyebamiji Mustapha et al. o.i 71 – 75

Iwe igbaradi fun idanwo asekagba.

 

ISE ASETILEWA

  1. ________ ni oro – aponle maa n pon ninju gbolohun (a) or-oruko (b) atokun (d) oro – ise
  2. Oruko miiran fun alabahun ni (a) eni to ni aba (b) Okere (d) Ijapa
  3. Apola – aponle je ______ ti o n yan oro–ise ninu gbolohun. (a) eyo oro (b) akojopo oro (d) oro
  4. Laye atijo oran ti o ba ti mu eni o di dandan ki odaran naa (a) salo (b)fi ilu sile (d) ku
  5. ________ lo maa n se idajo awon odaran laye atijo (a) Awon oba ati ijoye (b) Awon okunrin (d) gbogbo eniyan

 

APA KEJI

  1. a. Kin ni oran dida?
  2. Daruko ohun meji ti o n fa oran dida.
  3. Pelu apeere salaye iyato to wa laarin oro-aponle ati apola – aponle.

 

 

 

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share