DIDA ORO ORUKO TI A SEDA MO YATO SI EYI TI A KO SEDA

SUBJECT: YORUBA

CLASS: SS 3

TERM: FIRST TERM

OSE KETA

DIDA ORO ORUKO TI A SEDA MO YATO SI EYI TI A KO SEDA

Ori-oro-: Dida oro – oruko ti a seda mo ninu gbolohun Isunki ati aranmo ninu awon oro–oruko ti a seda

Akoonu

Bi a se le da oro – oruko ti a seda mo nipe, a gbodo le tu oro- oruko ti a seda pale, ki a si mo awon wunren to, bi Ini oro – oruko bee.

 

Apeere

I + jo = ijo

I – je afomo ibere

Jo – je oro – ise, eyi ti o fun wa ni ijo – a o rii pe itumo oro – ise yii gbe irumo oto – oruko ti o fun wa jade.

Isunki maa n waye leyin ti a ba ti so gblohun di oruko eyniyan. Apeere

Mo  ri  ohun mu bo yoo di

1         2         3         4         5         6

Bakan naa aranmo maa n waye laarin oro–oruko meji ti a seda ki won to di oro–oruko kansoso ti a seda. Apeere

Omo ile – Omoole

Oja Oba – Ojaaba.

 

IGBELEWON

Bawo ni a se le da oro-oruko ti a seda mo? Salaye.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo, Ede, asa ati Litireso Ede Yoruba Copromutt Publishers o.i

 

ASA

EGBE AWO

Akoonu

Egbe Awo je ohun ti a se ti a ko fi asiri re hani.

Egbe Awo:- ni egbe ti a da sile ti won n se ipade ti enikeni ko si mo ohun ti won nse nibi ipade naa. Iru egbe bee ti di egbe awo, ti awon omo egbe si fi ibura de ara won pe enikeni ko gbodo tu asiri ohun ti won n se.

 

Orisii egbe awo ti o wa nile Yoruba.

Orisiirisii egbe awo lo wa, opolopo nnkan ni won fi jora iyato diedie lo wa ni aarin won.

  1. Ogboni ibile
  2. Egbe ogboni ti a se atunse si (R. O. F)
  3. Awo Opa
  4. Awo to je mo esin ibile
  5. Awo oso ati aje
  6. Egbe Emere at Abiku

Ipa ti awon egbe wonyi n ko ninu eto iselu.

Ipa pataki ni awon ogboni n ko ninu eto iselu, awon lo maa n je oludamoran fun awon oba.

Awon ni alase ilu, owo won ni eto ifobaje wa. Oba gbodo je okan ninu omo egbe,

bi oba ba se awon ogboni ni ase lati da seria fun-un, bi ese re baju ijiya lo, won le yo kuro loye.

Owo won ni eto idajo wa nitori pe awon lo n se idajo fun awon arufin ati odaran.

Awon lo n fi oro gbe awon odaran ti ijiya ese won ba je mo iku.

Awon lon se eto isinku oba, olola ati ijoye laarin ilu.

 

ETO ORO AJE

Awon ogboni tun ni agbara nipa eto oro aje nitori pe awon ni parakoyi (onisowo pataki). Awon parakoyi lo maa n mojuto awon oja to wa laarin ilu.

Awon lo n ri si idagbasoke owo sise laye atijo.

Won maa n ran eni ti a je lowo lati ba a gba gbese pada.

 

ETUTU ILU

Awon ogboni lo maa n se etutu to le mu ilu tuba-tuse ni pataki julo ti ajakale arun ba wa.

Awon oye inu egbe awo bi eeyan ba darapo mo egbe awon ni pataki ogboni ipeyin tabi omode ni o maa koko wa, sugbon bi o ti n dagba si ninu egbe ni yoo ma ni igbega.

Iledi tabi ile ogboni ni a n pe ibi ti won maa n se ipade.

Oye mefa ni o ga ju nindu egbe ogboni, awon ni a mo si “iwarefa” awon naa ni:

Oluwo – ni olori patapata.

Lisa

Asalu

Aro

Apeena

Losi

Lemo

Nlado

Odofin abbl.

 

Imurawon

Ona ti awon ogboni n gba mura ni a fi maa n da won mo. Won maa n san aso mo idi, won yoo da bora, won yoo so saki tabi itagbe si ejika otun, leyin naa won yoo de akete fenfe, won yoo maa fi opa tele, won a si wa ileke sorun ati owo.

Awon omo egbe ogboni ka ara won si omo iya, won a si maa huwa omo iya meji si ara won. Idi niyi ti won fi maa n ran ara won lowo.

 

LITIRESO

Kika iwe ti ijoba yan . Iran kinni ati Ikeji.

 

IGBELEWON

  1. Pelu apeere salaye bi a se le da oro-oruko ti a seda mo.
  2. Se itupale fun oro-oruko eniyan (merin)

 

APAPO IGBELEWON

  1. Bawo ni a se le da oro-oruko ti a seda mo? Salaye.
  2. Pelu apeere salaye bi a se le da oro-oruko ti a seda mo.
  3. Se itupale fun oro-oruko eniyan (merin)

 

ISE SISE

  1. Se ipaje awon oro yii: ekuro, edidu, akara, daradara, eti ile, ewe oko, irun agbon, orisa, otito.
  2. Ko iwa omoluwabi mejo sile.
  3. Salaye lori ounje ibile Yoruba kan ti o mo.

 

IWE AKATILEWA

Eko Ede Yoruba Titun, iwe keji SS3

Oyebamiji Mustapha 0.1

 

ISE ASETILEWA

  1. Ewo ninu awon wonyi ni oro-oruko ti a seda lati inu gbolohun (a) Asona (b) Ogunniyi (d) Itiju
  2. A gbodo le ______ oro –oruko ti a ba seda (a) pe (b) tu pale (d) fi ami si
  3. ______ni awon ogboni ti maa n se ipade (a) ile egbe (b) Iledi (d) Ileipade
  4. ________ ni Olori patapata ninu awon oloye ogboni (a)apeena (b)Lisa (d) Oluwo
  5. Awon __________ lo n risi idagbasoke owo ni aye atijo. (a) Awon parakoyi (b) Awo opa (d) Doje

 

APAKEJI

Salaye pelu apeere ona meji ti a le gba lati da oro-oruko ti a seda mo.

  1. Kin in egbe awo?
  2. Salaye ipa merin ti awon ogboni n ko ninu eto iselu laye atijo.
  3. Salaye igi itanlowo fun awon omo Egbe Ogunniyi.
  4. Ogboni agbara ni eto egbuwa yii si ipeyin tabi ede Yoruba ti a mo to.
  5. Salaye lo maa n se etutu to le mu ilu tuba-tuse ni pataki julo ti ajakale Arun ba wa.
  6. Ogboni agba ipeyin tabi ede Yoruba ati omode lo n gba aso meji fun ise sise lemu aye.

 

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share
Use the search box to search for any topics or subjects that you want
Use the search box to search for any topics or subjects that you want