ALPHA TERM ILAANA ISE NI SAA KINNI FUN SS3
YORUBA LANGUAGE
OSE |
AKORI EKO |
1 |
EDE – Itesiwaju eko lori oro ise; Alaye lori orisii ati ilo re ninu gbolohun
ASA – Afiwe asa Isinku abinibi ati eto sinku ode oni. Ayipada to ti de ba Asa isinku abinibi tabi atohunrinwa
LITIRESO – Agbeyewo iwe ti Ajo WAEC/NECO yan. Onkowe, itan ni soki ati awon amuye miiran |
2 |
EDE – Itesiwaju eko lori isori gbolohun gege bi ihun won. Gbolohun eleyo oro ise, gbolohun olopo oro-ise, sise akojopo gbolohun eleyo oro-ise.
ASA – Eto ogunjije. Awon iran/orile ti o maa n jagun ni ile Yoruba laye atijo. Eto aabo ilu ati ipati awon obinrin n ko ninu eto ogun
LITIRESO – Itupale asayn iwe lati ajo WAEC/NECO yan |
3 |
EDE – Itesiwaju lori ihun oro
Dida oro oruko ti asede mo yato si eyi ti a ko seda
Itupale oro oruko eniyan, sise akojopo oro oruko
ASA – Itesiwaju eko lori Egbe Awo
Orisirisii egbe Awo ti o wa nile Yoruba
Alaye kiku lori ipa ti awon egbe wonyii n ko ninu eto oselu
LITIRESO – Itupale asayn iwe lati ajo WAEC/NECO yan |
4 |
EDE – Iba Isele (Aseranwo oro-ise)
- Orisii iba isele to wa Asetan, Aterere, Aisetan abbl
- Awon wunreni ti o toka iba isele ninu gbolohun
ASA – Itesiwaju eko nipa igbagbo ati ero Yoruba nipa oso ati aje. Ero ati igbagbo awon eya miiran ni orile ede Naijiiria ati orile ede miiran nipa oso ati aje
LITIRESO – Itupale asayn iwe lati ajo WAEC/NECO yan |
5 |
EDE – Itesiwaju lori Oro Agbaso
Yiyo oro enu oloro si oro agbaso, fifi eti si sise, kika ati jijabo iroyin ipade
Yiya afo agba oro si afo-asafo
ASA – Itesiwaju lori Eko ile ati imototo itoju ara, bi a se nkini, oro siso, onje jije ati awo fifo
LITIRESO – Itupale asayn iwe lati ajo WAEC/NECO yan |
6 |
EDE – Itesiwaju lori oro aroko oniroyin, ijiroro kikun lori awon ori oro to je mo aroko oniroyin. Kiko ilapa ero
ASA – Itesiwaju eko lori ojuse eni ni awujo pataki ojuse eni ninu ile, laarin ebi, egbe, adugbo, abbl
LITIRESO – Itupale asayn iwe lati ajo WAEC/NECO yan |
7 |
EDE – Iyato to wa laarin Oro Aponle ati Apola Aponle, alaye kikun. Oro Aponle ati Apola Aponle, titoka si ilo oro aponle ninu gbolohun, fifa oro aponle ati apola aponle yo ninu gbolohun tabi ipinro, sise alaye ise okookan won ninu gbolohun. Alopo mejeeji ninu gbolohun
ASA – Itesiwaju lori oran dida ati ijiya ti o to ipa ti awon agbefoba ati agbonfinro n ko ninu sise eto idajo fun arufin ati odaran, orisii eto idajo ati oan ti a o gba fi iya je odaran laye atijo ati ode oni
LITIRESO – Ayewo finifini lori awon Asayn itandowe. Itandowe siso, itandowe kookan ni oloro geere titoba si oew ati asa to suyo ninu itan kookan, isowolo ede ninu itan to di owe kookan. |
8 |
EDE – itesiwaju ninu aayan ogbufo. Ogbon ti a n ta fun aayan ogbufo lati ede geesi si ojulowo ede Yoruba. Fifoye itumo ayoka oloro geere to ta koko jut i ateyinwa lo lati inu ede geesi si ojulowo Yoruba ajumolo
ASA – Itesiwaju nipa igbagbo awon Yoruba si aseyin waye ati abami eda
LITIRESO – Itupale asayn iwe lati ajo WAEC/NECO yan |
9. |
EDE – Itesiwaju Akaye Ayoka (orisirisi, agbeyewo orisirisi, akaye bii oloro geere, ewi, ere onitan, ati orisii ayoka danra wo
ASA – Itesiwaju lori eewo. Awon eewo ti aisan mu wa akojopo aisan ati eewo ti alaisan kookan ko gbodo deja, anfaani awon eewo fun awon alaisan
LITIRESO – Itupale asayn iwe lati ajo WAEC/NECO yan |
10 |
EDE – Atunyewo awon isori oro-oruko, oro aropo oruko, oro ise, sise itupale gbolohun kekere si isori oro
ASA – Itesiwaju lori oruko ile Yoruba, oruko Amutorunwa, oruko abiso ati oriki inagije
LITIRESO – Itupale asayn iwe lati ajo WAEC/NECO yan |
11 |
Atunyewo eko lori ise saa yii ninu ede, asa ati litireso |
12 |
Akanse idanwo lori eko, ede, asa ati litireso |
OSE KINNI
AKORI EKO: ORO – ISE
Oro – ise ni oro tabi akojopo oro to n toka si isele tabi nkan ti oluwa se ninu gbolohun. Bi apeere:
Ade ra iwe ede Yoruba
Tuned gun igi osan
“ra” ati “gun” ni opomulero to je oro – ise ti a fi mo nkan ti oluwa se ninu iso oke wonyii:
Abuda oro – ise
- Oro – ise ni o maa n je yo leyin oluwa. Apeere:
Ade je moinmoin
Nike feran ese
- Oro ti o ba tele atoka iyisodi ko lo gbodo je oro –ise. Apeere:
Bola ko je iyan
Sunkanmi o wa
Eya/ orisii oro – ise
- ORO – ISE KIKUN: Oro – ise ti o le da duro ti o sin i itumo kikun lai sip e a fi oro – ise miiran kun un. Bi apeere:
Sade lo
Bisi sun
Kolade rerin-in
Oro – ise kikun le je
- Oro – ise agbabo
oro – ise agbabo ni awon oro – ise ti won ko le sai gbabo ninu gbolohun. Bi apeere:
mo de ikoko
bisi ra iyo
kikelomo je eja
OSE KEJI
AKORI EKO: ITESIWAJU LORI ISORI ORO EDE YORUBA
Apeere gbolohun lori oro – oruko ni ipo alo:
O mu emu
Ajadi fo agbe
Ekundayo ko ile alaja
Oro oruko ni ipo eyan
Okunrin oloro naa kun i afemojumo
Aja ode pa etu nla
Ewure Toorera ni won ji
Ile olowo naa rewa
ORISII ORO ORUKO
- Oruko eniyan – Bisi, Dele
- Oruko eranko – Kiniun, Obo
- Oruko bikan – Ibadan, Oyo
- Oruko ohunkan – Tabili, aso
- Oro Oruko afoyemo – Idunnu, Ayo
- Oro oruko aseeke – Owo, bata
- Oro oruko alaiseeka – Omi, iyepe
- Oro oruko asoye
- Oro oruko aridinnu – Ikoko, bata
ORO – AROPO ORUKO (PRONOUN): A maa n lo oro aropo oruko ninu gbolohun lati dekun awitu n wi a sa n ninu gbolohun ede Yoruba. Apeere: ȩ, ǫ, won, mo, a, wa ati bee bee lo.
Mo tele pa ile mo
A lo si ipade awon afobaje ranaa
Bukola ri won nibe
A le lo oro aropo oruko gege bi eya ati opo ni ipo eni kin-in-ni, eni keji ati ipo eni keta.
ORO – ISE (VERB): Isori oro yii ni o maa n tola ohun ti oluwa se tabi toka isele ninu gbolohun. Oro – ise ni opomulere gbolohun ede Yoruba, la i si oro-ise, irufe gbolohun bee yoo padanu itumo re. apeere
Bisi je iyan ni owuro
Akanbi gun igi rekoja ewe
Ogiri ile ti wo lule
ORO ASOPO TABI ASO OROPO (CONJUNCTION): eyi ni awon wu n ren la a n lo lati fi so oro tabi gbolohun po di eyo kan soso. Apeere: ati I pelu, sugbon, nitori, yola, tabi, afi abbl.
Kikelomo pelu Tijani ni won n pe
Yala Jumoke tabi Bisi ni yoo yege
Ile naa to bi sugbon yara re kere
ORO AROPO AFARAJORUKO (PRONOMINAL): Isede isori yii ran pe isori aropo oruko, ise kannaa ni won n jo n se ninu gbolohun ede Yoruba. Awon wunren aropo afarajoruko niwonyi. Oun, eni, emi, awon, eyin, awa, ati ibo. A maa n lo awon wunien yii dipo oro oruko ninu gbolohun. Apeere:
Emi ni won n ba wi
Awon egbe wa n yoo se ajodun lose yii
Iwo ati Kayode niyoo soju wa
ORO – APONLE: Awon oro ti o maa n pon oro – ise le ninu gbolohun ni a pen i oro aponle. Iru oro bee ni rakorako, fiofio, tonitoni. Apeere:
Aso re po n rakorako
Ile naa mo tonitoni
ORO APEJUWE: otun le je oro eyan o si ma n fi o le le ori oro-oruko ninu apola oruko ninu ede Yoruba. Eyin oro-oruko ti o n ya n ni oro-apejuwe maa n wa. Apeere:
Baba aburo ni mo fe mi
Iwe mi ni o faya
Aja dudu lode pa
[mediator_tech]
AFIWE ASA ISINKU ABINIBI ATI ETO ISINKU ABINIBI ATI ETO ISINKU ODE – ONI
Awon Yoruba gbagbe pe bi eniyan ba ku yoo lo si orun, yala orun rere tabi orun ti o ni iya ninu won gba pe bi eniyan ba ku, o tun le padawa ya lodo o mo re nipa bibi ige ge bi o mo.
Orisii oku meji ni o wa gege bi ojo ori eni ti o saisi bat i n, awon nii:
- OKU OFO: eyi ti o tumo sip e iku omode (iku aitojo). Eni tiko dagba, yala nipa ijamba tabi aisan. Eyi je iku ibanuje laa rin awon Yoruba.
- OKU EKO: iru iku bayii niti awon agbalagba ti o ti darugbo kujekuje ti won re iwale asa, awon eni ti won ti gbe ile – aye as ohunribiribi ki won to ku.
Afiwe asa isinke abinibi yato ge de rig be si eto isinku aye ode – oni nitori eto eru igba lode ti oti sun siwaju ju ti a te wala. Ni aye atijo iko si ona abayo si bi a ti se le toju oku ju ojo meta lo, sugbon ni aye ode oni. O seese ki a toju oku si inu iyara tabi ile igboku si ju osu mefa tabi ju bee lo lai dibaje.
Bakan naa, ilana itufo ti yaato sit i aye atijo. Orisirisi awonero igbalode ni o wa ti ale lo lati so eyi di mimo fun gbogbo agbaye.
IGBESE ISINKU
- Itufo
- Ile oku gbigb (awon ana oku ni o maa n sa ba se eyi)
- Oku wiwe (fifa irun oku, ri ree ekannaa)
- Oku tite (wiwo aso funfun fun oku pelu lilo lofinda oloo run didun)
- Oku sinsin
- Alejo sise
- Opo sise
- Opo sisu
OSE KETA
AKORI EKO – ETO OGUN JIJE LAYE ATIJO
Ogun jije se pataki pupo laarin awon Yoruba oun nii fi ilu alagbara han yato si ilu ti ko ni agba la. Orisii ogun meji ni o wa:
- Ogun ti a le pen i ogun adaja; ati
- Ogun ajadiju tabi ogun ajaku-akata: eyi le je ogun adugbo si adugbo, ileto si ileto tabi ilu si ilu
Die ninu awon ti I ma fa si sigun si ileto tabi ilu miiran nwonyi.
- Gbigbe sunmoni
- Ote
- Ilara
- Ija aala ile
- Ija ile
- Ija fun igi owo bi ope, orombo, obi abbl
- Siisiigun lati fi pa oloye ogun ilu miiran n lenu mo
- Siisiigun lati fi ko ilu tabi ileto keji logbo nii
- Siisiigun lati fi agbara han
- Sisigun lati fi wa owo bi oda owo ba fe da ni
Awon isise ti agbodo gbe ki a to segun
- Ifa dida
- Bibo ogun ati esu ati
- Pipolongo laarin ilu ki teruromo ilu lemo pe ogun ti ya
Awon ti won maa n jagun ni aye atijo
- Iran ologun, onikoyi ati aresa
- Awon ipanle tabi janduku
- Awon oloogun
- Awon ogboju ode ati
- Awon ti won maa nse koriya fun awon jagunjagun loju ogun bii onilu, onirara abbl.
Die ninu awon ete ogun
- Sise ota mole ki won maa le de ibi ti jaje ati mimu
- Dida oogun sinu omi ati ounje ota
- Riro gbogbo ona ti o wo ilu ota ki won to ji
- Wiwo ilu lojiji ati kiko ota ni papa mo ra
- Reran alami lati maa so ota ki won maa baa ko won ni papa mora
- Fifi ija ti o gbona girigiri le ota kuro lenu odi ilu.
Awon ohun ija ogun
- Oko
- Ida
- Ofa
- Kumo
- Ibonlori sirisi (ibon ilewo, sakabula, ilasa abbl)
Die ninu awon orisiirisii oogun ti won maa n lo loju ogun
- Okigbe
- Asakii ibon
- Afeta
- Afeeri
- Owo
- Abo
- Ayeta
- Isuju
- Kanako
Lara awon oloye ogun
- Aare ona kakanfo
- Basorun
- Balogun
- Jagunna
- Seriki
Anfaani Ogun
- A maa je ki awon eniyan di alagbara
- O maa n je ki ogun atayeba ye tun je yoo
- O maa fi ilu alagbara han
- O maa n so awon alagbara di olowo ojiji
Aleebu Ogun
- Biba nkan ini je
- Pipa emi nu
- Fifa ota ayeraye wa laari nilu kan si ekeji
- Mimu ki nkan jije won nitori aye ko si fun ise agbe
- O maa n je ki awon omo alaini baba po
- O maa n fa ki owo eru was aye (slave trade)
OSE KERIN
AKORI EKO: EGBE AWO LORISIRISII
Ohun to soro lati mo kulekule ohun ninu egbe awo nitori won kofi eni ti kii se omo egbe idi niyi ti o fi je omo egbe lo le so pelu idaniloju ohun ti o n sele ninu egbe won.
Orisirisii egbe awo ti o wa:
- Egbe ogboni (abalaye ati ti igbalode)
- Oro
- Egungun
- Agemo
- Imure
- Awo opa
Pataki ise opolopo awon egbe awo wonyi ni fun idagbasoke ati alaafia ilu ti okan si n gbe ekeji ni igbonwo. Bi apeere, egbe oro wa fun sise abo ati eto ti o ye lori ipinnu ti o bati odo egbe ogboni wa nipa eto ilu.
Tajateran ko nii se egbe ogboni, kaka bee o wa fun awon agba to ni ojo lori. Ko si fun odo obinrin afi awon ti o ti darugbo patapata ti Atari won to gbe eru awo. Bi apeere, Erelu okun. If ti o yii ni oso awon omo egba poi di niyi ti won fi n pe ara won ni omo iya.
Awon omo egbe ni ani ti won fi n la ara won mo lawujo. Ami egbe pataki ni edan. Ako edan wa fun nnkan ti ko ni ayo ninu ti abo si wa fun nkan ayo.
OSE KARUN
AKORI EKO: ORO AGBASO
Ohun ti o n bi oro agbaso nip e ko se e se fun eniyan lati wan i ibi gbogbo ti won ba n soro. Nigba ti eniyan ko basi tisi ni ibiti won bat i n soro kan o daju pe elomiran ti o wa nibe ni a n reti pe yoo wa so o fun eniyan.
O se e se pe iwo ni yoo tun lo so fun elomiran ti o baye wipe oun naa ko si nibe ti iwa si wa nibe. Oro agbaso ni ona ti a n gab se atunso oro ti agbo lenu elomiran. Oro bee ni a n pen i sagbaso re e je eyi ti an tunso fun elomiran ti ko se alore tabi oro ti a n tun so fun eni ti oro naa koye to bi o tile je pe oun gan-an feti ara re gbo lati enu oloro.
A le lo oro agbaso lati:
- Se iroyin ohun to se oju eni
- Se atunso iroyin ti agbo lori redio tabi telifisan
- Se alaye ohun ti agbo nibi idanileko
- Se atunso iwaasu
- Je ise ti ara n ni
- Jabo ise tabi ipaade
- Se iroyin ere ti a wo lori papa, ori itage tabi iran miiran.
Apeere awon oro to je atoka oro agbaso re:
- Leripe
- Pasepe
- So
- Wi
- Pe
- Wipe
- So fun
- Beere
- Salaye
- So pe
- Boya
- So fun wipe
- Ni
- Ki
- O si
- So wipe
Awon isori ti ayi pada maa n baa ninu oro agbaso ni
- Oro aropo oruko
- Oro aropo afarajoruko
- Oro – oruko
- Eyan
Bi apeere:
ORO ENU OLORO ORO AGBASO
Mo lo si Eko O ni ohun losi Eko
A lo si Epe O so pea won lo si Epe
Iyanda ri mi O salaye pe Iyanda ri oun
Eyi ni ki o mu O pase pe iyen ni ki o mu
Awon omo winyii maa jiya O le ripe awon omo wonyen maa jiya
Mo ti kaso wole O ni oun ti kaso wole
Ayo ni o O salaye pe ayo ni o
ISE ASETILEWA
Yii awon afo asafo si afo agbaran
- Se e ti jeun?
- Jowo bo sita ki aki o
- Oko ajagbe naa jona raurau
- Aba isu meloo ni aja baji?
- Sola: Bisi so ara re gidigidi.
OSE KEFA
AKORI EKO: IYATO TI O WA LARIN ORO APONLE ATI APOLA APONLE
Oro aponle je eyo oro kan ninu ihun gbolohun ti o maa n pon oro – ise. Ise re gan-an ni lati se afihan itumo fun apola ise ninu gbolohun. Bi apeere:
(i) Tunde rin: (ii) Tunde rin jaujau
Tunde rin kemokemo
Tunde rin pelepele
Gholohun (i) je oro ise alaigbagbo (rin) ko I oro aponle eyi ti yoo je ki a mo bi oluwa se rin. Sugbon awon iso/oro abo gbolohun (ii) ni oro aponle to se afikun itumo oro-ise “rin” ni ekunrere.
APOLA APONLE: Apola aponle je akojopo oro to n sise gege bi idi kan ti o si n pon oro-ise inu iso. Bi apeere: Ilu Osoosa maa n kun ni akoko odun agemo.
Orisirisi apola aponle
Apola aponle alasiko – eyi n fi igba tabi asiko isele han. Bi apeere:
Imole n mo nigba osan
Okunkun n su nigba oru
Ojo maa n po ni asiko ojo
Apola aponle orubii – eyi maa n toka si ibi kan pato nin afo gbolohun. Bi apeere:
Ile oduduwa wa ni Ile – Ife
O ti ile bere wahala
Oke giga wan i Efon
Apola aponle onidii: Eyi ni o maa n so idi nka pato. Bi apeere:
O kole nitori omo
A n sise nitori owo
O kekoo ko le di eniyan pataki
OSE KEJO
AKORI EKO: ORAN DIDA ATI IJIYA TI O TO
Laye atijo ko si ofin ti a ko sile gege bi ti ode – oni. Sugbon, a no awon asa, eewo, ilana ti awon agba fi n se eto agbo ile ati akoso ilu. Bi o tile je pe ako ni akosile ofin naa gege bi a ti nii ninu iwe ofin lode oni, ole jija, ipaniyan, alonilowogba, ifipa – jale, ati iwa buburu gbogbo ti a n tun ri lode oni, ko to bee po rara.
Eto idajo lori esun odaran lode oni ati ti aye atijo ko fi bee yato rara, gbogbo igbese bi ki agbo tie nu ti a fi esun kan a o si fun un laye lati pe eleri ti yoo ferii gbee leyin naa, a o se iwadi esun naa fin-ni-fin-ni. Ti o ba jare, a o daa sile ki o maa lo ni alaafia. Sugbon ti o ba jebi, a o fii ijayi ti o to jee. Bi ese bat i n pon to ni ijiya se nto.
Awon ohun ti eniyan le se ki a to so pe o daran pupo ni wonyii:
- Ipaniyan
- Fifi ipa ba obinrin lo
- Fifi dukia jona
- Agbere sise
- Idife si ilu eni tabi si ijoba
- Ole jija
- Ifipa jale
- Idigun jale
- Jiji omo gbe
- Sise afojudi si awon Oba, Ijoye ati awon alase ilu
- Biba nkan ajumolo je laini idi
- Ona dida
- Sise ogunika
- Lilo agbara aye lati se aidaa
- Fayawo ati kika oogun oloro wolu
OSE KESAN
AKORI EKO: ATUNYEWO AAYAN OGBUFO
Aayan ogbufo ni itumo ede lati ede kan si omiran, paapaa julo ede geesi si ede Yoruba.
Amuye for Ogbufo
- Gbigbo ede mejeeji: a gbodo gbo ede mejeeji daradara, eyi ni ede ti yoo tumo ati ede ti yoo tumo re si.
- Mimo ko ati mimo kaa: ogbufo gbodo le ka ede mejeeji daradara nitoripe akosile ede geesi ni won yoo gbe fun wa lati tumo.
Apeere ogbufo gbolohun die
Ede Geesi Itumo lede Yoruba
He was ashamed of his behaviour Oju tii nitori iwaa re
The headmaster permited the children to go home Oga ile eko na fun awon akeeko laye lati lo sile
The tortoise tricked the tiger and caged it at last Ijapa tan ekun naa je o sit i mo inu aago leyin – o – reyin
It rained cats and dogs in Lagos yesterday Ojo ro ofeere wu oku ole ni ilu Eko lana
Whoever beaks any of these golden rules Enikeeni ti o ba ru eyikeyi ninu awon ofin pataki wonyi yio dara re lebi
will have himself to blame
OSE KEEWA
AKORI EKO: MOFIIMU
Mofiimu ni ege tabi fonran ti o kere julo ti o si ni ise ti o n se (tabi ihimo kikun) ninu ihunoro. Apeere eya moffimu ni oju, omo, owo, alaafia, eemi, egbon ati, ai, a, i, on. A ko le se atunge awon ege mofiimu oke wonyi mo ti a ba ge e, won yoo so itumo won nu.
Eya Mofiimu
A le pon mofiimu si orisii meji. Awon ni:
- Mofiimu Ipile (adaduro)
- Mofiimu afarahe
MOFIIMU IPILE TABI ADADURO: eyi je ege ti o le da duro lai i ni afikun fonran (afomo) miiran pelu re.
Mofiimu ipile maa n da itumo ni
A ko le fo mofiimu ipile si wewe mo. Mofiimu ipile le je:
- ORO – ORUKO: oro oruko bayii kii gba afomo mora, bee ni a kole pinwon si meji tabi ki a seda won. Apeere: Adebisi, Igbokoda, Adaye, Omi, Ile, Ori abbl.
- ORO – AROPO AFARAJORUKO: awa, eyin, awon, emi, iwo.
- ORO – ISE: lo, gbe, wa, de abbl
- ORO – APEJUWE: pupa, dudu, funfun
- ORO APONLE: banku, roboto
A le lo mofiimu afarahen moa won isori (ii – iv) oke lati seda ororuko titun. Bi apeere
ti + eyin ==== teyin
Awon oro – oruko kan wa ti a le se apehinpe won seda oruko tuntun. Bi apeere
Irun + agbon ====== irungbon
Mofiimu Afarahe
Mofiimu afarahe tabi afomo je awon iro (leta) inu ede ti ko le duro bi oro kan lai je pe a kan mofiimu ipile mo won. A le pin mofiimu afarahe sei meji:
- Afomo afarahe ibere (iwaju) mofiimu ipile ni an fi afomo kun ni ibere lati seda oro-oruko miiran. Afomo ibere le je ……
- Eyo faweli airanmupe bii: a, e, ȩ, i, o, ǫ, u ki a wa fi kun mofiimu ‘ipile’. Apeere
I + fe
I + gbagbo
A + de
E + to
E + ko
O + sere
Ǫ + muti
- Akanpo iro onisilebu meji bii ai, on, oni, ati, sai, abbl. Apeere
ai + sun
on + te
oni + isu
ati + je
sai + gboran
- Afomo afarahe aarin. Afomo aarin maa n waye ni aarin oro-oruko mofiimu adaduro ti a se apetunpe re. wunren afomo aarin ni; de, ki, je, ku, ni, si, ri, abbl. Apeere
Oro Oruko Afomo aarin Oro Oruko Abajade
Ile ki ile
Iran de iran
Ije ku ije
Emi ri emi
Agba ni agba
Opo ni opo
Ebi si ebi
JSS 1 THIRD TERM LESSON NOTES YORUBA
JSS 2 THIRD TERM LESSON NOTE PLAN YORUBA
ILAANA ISE NI SAA KETA FUN JSS 3 THIRD TERM LESSON NOTES YORUBA
[mediator_tech]