Second Term SSS 1 Yoruba

 

SECOND TERM E-NOTE

SUBJECT; YORUBA.                                                                     CLASS-; SS1

ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KEJI

Ose  kinni- Ede-Atunyewo awon isori oro

  • oro aropo oruko
  • oro aropo afarajoruko
  • oro atokun
  • oro asopo
  • oro-ise

Asa- Oge sise

Litireso-Itupale asayan iwe litireso

 

Ose keji  Ede- Awon isori gbolohun gege bi ihun won.

Asa-  Oge sise

Aso wiwo laarin okunrin ati obinrin

Awon ayipada ti o de ba aso wiwo aye atijo ati ode-oni.

Litireso- Itupale asayan iwe litireso.

Ose keta    Ede- Awon isori gbolohun gege bi ise won.

Asa-  Asa ila kiko

– pataki ati iwulo ila.

Litireso- Itupale asayan iwe litireso.

Ose kerin Ede- Aroko  Asapejuwe;ilana kiko aroko

– Awon ori-oro to je mo aroko asapejuwe.

Asa-   Asa Igbeyawo Ni Ile Yoruba.

  1. Awon igbese igbeyawo abinibi
  2. Awon ohun elo idana.

Litireso – Itupale asayan iwe litireso.

Ose karun-un  Ede- Aayan Ogbufo; ilana sise aayan ogbufo.

Asa – Orisii igbeyawo ti o wa

  1. igbeyawo nisu loka

gbigbe ese le iyawo

ana sise ni ile Yoruba.

Litireso- Itupale asayan iwe litireso.

Ose kefa Ede – Aayan Ogbufo; sise ogbufo ayoka ede Geesi si ede Yoruba.

Asa – Igbeyawo ode-oni-soosi, Yigi,Kootu.

  • iyato ati ijora ti o wa ninu igbeyawo ode-oni ati atijo.

Litireso- itan olorogeere gege bi orisun itan isedale ati asa Yoruba

-itan isedale Yoruba

– itan awon eya Yoruba

ose keje- Ede- Onka  Yoruba;onkaye lati ori  ookan titi de Egbaa (1- 2000)

Asa-  Oyun nini,itoju oyun,ibimo.

Igbagbo Yorubanipa agan,omo bibi ati abiku

Aajo lati tete ni oyun.

Eewo ati Oro idile.

Litireso –    Itan oloro geere gege bi orisun itan ati asa Yoruba; Asa bi Yoruba se n sin  oku sinu                                       ile.

Ose kejo- Ede- Atunyewo eko lori eka ede Yoruba; Ijesa, Ekiti,Oyo.abbl.

  • iwulo Yoruba Ajumolo

Fifi  eka ede we Yoruba ajumolo

Asa-    Isomoloruko Ni Ile Yoruba

  1. Pataki siso omo loruko
  2. Ohun elo ati isomoloruko.

Litireso-Itupale asayan iwe litireso.

Ose kesan-an

EDE-Aroko asotan/ oniroyin.

Orisii  ori-oro ti o je mo aroko oniroyin

Asa-  Orisii oruko ti a le so omo

  1. oruko amutorunwa
  2. abiso abbl

Litireso alohun oloro wuuru; Aalo orisirisi- apamo, apagbe,

iwulo aalo

awon ona ede ti o wa ninu aalo.

Ose  kewaa-  Ede- Isori oro-oruko

Oriki

Orisii

Ise ti oro-oruko n se ninu gbolohun.

Asa- Ipolowo oja; Iwulo ati pataki ipolowo oja.

Orisiirisii ona ipolowo oja ti abinibi-ikiri, ipate,ipolowo pelu ohun enu.

Litireso –  Ewi alohun gege bi orisun itan isedale ati asa Yoruba; oriki orile,ijala  abbl

Ose kokanla- Agbeyewo ise saa keji lapapo..

Ose kejila-  Idanwo saa keji.

 

 

 

OSE KINNI

ORI-ORO-;ATUNYEWO AWON ISORI ORO

-Oro-oruko

 

ORO AROPO ORUKO.

  • Oriki
  • Abuda oro aropo oruko
  • Ate oro aropo oruko
  • Irisi oro aropo oruko.

AKOONU

Oro aropo oruko ni a maa n lo dipo oro-oruko ninu apola oruko.apeere

‘Bolu je akara.

‘O je e.’

‘ewure je agbado Bola’

‘ewure je agbado re.

Abuda oro aropo oruko.

  1. Oro aropo oruko ni eto to n toka si iye bi eyo tabi opo.apeere

O lo [ eyo ni o ]

Won wa [ opo ni won]

  1. oro aropo oruko ni eto to n toka si eni.apeere.

enikinni /eyi ni eni ti o n soro.

Enikeji / eyi ni eni ti a n soro sii.

Eniketa / eyi ni eni tabi ohun ti a n soro re.

Mo ko leta.

O ko leta

O ko leta.

  1. Oro aropo oruko ni eto ipin si ipo.

 

IYE                             Eyo     opo

Enikin-in-ni                 mo       a

Enikeji                                     o          e

Eniketa                                    o          won.

 

  1. A ko le fi oro-asopo so oro aropo oruko meji papo.apeere

mo ati o

wa ati won.

 

  1. A ko le lo oro aropo oruko pelu da ati nko,ni,ko.apeere

mo n ko?

E da?

O ko?

  1. A ko le lo eyan pelu oro aropo oruko.apeere

mo naa

e gan-an

IRISI ORO AROPO – ORUKO.

Ona meta Pataki ni a le gba lo oro aropo oruko ninu gbolohun.

  • O le sise oluwa
  • Abo
  • Eyan ninu gbolohun.

Ipo oluwa; – oro aropo oruko maa n sise oluwa ninu gbolohun,

 

IYE                 EYO                OPO.

Enikin-ni         mo                   a

Enikeji             o                      e

Eniketa            o                      won

Apeere;- mo n jo

O n jo

Won n jo

E n jo

A n jo.

Ipo abo : – oro aropo oruko maa n sise abo bakan naa ninu gbolohun.

 

Iye                   Eyo                  Opo.

Enikin-in         mi                    wa

Enikeji             o/e                   yin

Eniketa            faweli              won

Oro-ise gun

 

Baba na mi.

Bolu n pe o/e

Oluko pe e.

Oba ri wa.

Ipo eyan : -oro aropo oruko maa n ni ipo eyan ninu gbolohun.

 

IYE                             EYO                OPO.

Enikin-ni                     mi                    wa

Enikeji                         re/e                  yin

Eniketa                        re/e                  won.

Apeere; –

Aja mi

Aja re

Aja re

Ile wa

Aso yin

Aja won.

IGBELEWON.

  1. Kin ni oro aropo oruko?
  2. salaye awon oro aropo oruko pelu apeere.

 

 

ORO AROPO AFARAJORUKO.

  • Oriki
  • Abuda oro aropo afarajoruko
  • Irisi oro aropo afarajoruko.
  • AKOONU : –

Oro aropo-afarajoruko ni isesi to farajo ti oro-oruko sugbon o mu eto iye ati eni lara abuda oro aropo oruko.Awon oro aropo afarajoruko ni wonyii; – emi,iwo,oun,awa,eyin,awon.fun apeere.

Emi ko ri Bola.

Ile awa dun.

Abuda oro aropo afarajoruko.

  1. Oro aropo afarajoruko ni eto iye ati eni.

Ate oro aropo afarajoruko.

 

IYE                 EYO                OPO.

Enikin-ni                     emi                  awa

Enikeji                         iwo                  eyin

Eniketa                        oun                  awon.

Fun apeere : – iwo ni won ran

Awa naa n bo.

  1. A le lo oro asopo lati so oro aropo afarajoruko meji papo.apeere.

emi ati iwo.

Awa ati eyin.

iii. Oro aropo afarajoruko le jeyo pelu awon wunren bii da,nko,ko.Fun apeere

iwo  n ko?

Oun da?

Eyin ko.

  1. Silebu meji ni oro aropo afarajoruko maa n ni.apeere.

emi – e /mi.

iwo – I /wo.

  1. Oro aropo afarajoruko le gba eyan.Apeere

emi naa wa.

Awon gan-an wa.

  1. A le gbe oro –aropo afarajoruko saaju wunren akiyesi alatenumo ‘ni’ fun apeere
    1. Eyin ni oga n pe.
    2. emi ni mo ra iwe naa.

IRISI ORO AROPO AFARAJORUKO.

Ise oluwa ni oro aropo afarajoruko maa n se ninu gbolohun.ap.

Emi naa mu osan.

Oun ni won n bawi.

LITIRESO.

Kika iwe litireso.

 

ORO APONLE

 

 

AKOONU

Oro-aponle je oro ti o maa n pon oro-ise ninu gbolohun, o ma n se afikun itumo fun apola-ise, ti yoo si je ki itumo re si tubo ye ni yekeyeke.

 

Tobi jeun die

Bolu n rin kanmokanmo bo

 

Ninu apola-ise ni oro-aponle ti maa n jeyo ninu gbolohun

Oro-ise ni oro-aponle maa n pon ninu gbolohun oro-aponle maa n se afikun ituom fun oro-ise.

 

Tade dide fuu

Igi naa ga fiofio

 

Irufe oro-aponle inu ede Yoruba orisii meji ni oro-aponle, awon naa ni:-

 

 

Awon oro-aponle aiseda

Awon oro-aponle aseda

Oro aponle aiseda ni oro-aponle ti a ko seda, iru oro yii kii ni ju silebu kan tabi meji lo. A won ni fio, kia, gan-an logan

 

O lo logan

Ile naa ga fio

 

  1. Oro-aponle aseda:- ni oro-aponle ti a seda lati ara oro-aponle, nipa sise apetunpe oro-aponle ponbele

 

Kia + Kia                     =          Kiakia

Wadu + Wadu  =          waduwadu

Pele + pele                   =          peleple

Jan + jan                      =          Janjan

Kele + kele                  =          kelekele

 

Tobi n laagun yoboyobo

 

 

 

 

 

 

Mo n laagun yobo

Aso naa funfun gboo

Obe naa ti tan yanyan

Osupa mole rokoso

 

ORO-ISE

 

  • Oriki
  • Iwulo oro ise
  • Ona ti a le gba lati da oro ise mo.
  • Isori oro ise.

AKOONU : –

Oro-ise ni oro ti o ba le duro bii koko fonran ninu gbolohunoro-ise ni oro ti o n toka si ohun ti oluwa se ninu gbolohun laisi oro ise ninu gbolohun ko le ni itunmo nitori ohun ni o je opomulero fun gbolohun.Ap.

Baba ra bata.

Olu fo aso.

Bi a ba yo oro-ise kuro ninu awon gbolohun wonyii ko le ni itunmo.

ONA TI A FI LE DA ORO-ISE MO.

  1. Oro-ise ni o maa n jeyo leyin oluwa.ap ‘mo je eba.’ ‘won gba owo’.
  2. oro ti o ba le tele erun oro-ise ‘n’ gbodo je oro-ise.ap ‘Ade n ko iwe’ ‘ mama n se obe.’
  3. oro ti o ba jeyo leyin yoo,maa,fi ati ti gbodo je oro-ise.Ap ‘Akekoo yoo se idanwo’ ‘oluko maa wa.’ ‘baba ti de’.
  4. oro ti o ba tele atoka iyisodi ‘ko/o gbodo je oro-ise.Ap ‘ Bayo ko ra aso.’ ‘ oluko ko je eba’.

ISORI ORO ISE.

Orisiirisii isori ni awon onimo girama pin oro ise si ninu ede Yoruba.

  1. Oro –ise Agbabo : – ni oro-ise ti a maa n lo abo pelu re ninu edeap ‘Tolu sun’ Tope kuru.’ ‘ ojo ro’.
  2. Oro ise asebeere : – meji naa ni o wa ninu ede Yoruba,awon naa ni da ati nko.fun apeere ‘ mama da’ ‘Bisi nko’.
  3. Oro ise asokunfa : – Eyi ni oro –ise ti o maa n se okunfa isele,awon oro-ise asokunfa ni;so,mu,se,ko,fi,da. Apeere Bola da erin pa mi. Bade fi iya je Sola. O se iku pa aja re.
  4. Oro-ise Elela: – Eyi ni oro-ise ti a le fi oro-oruko ti o duro fun abo bo laarin ninu gbolohun.apeere bawi,reje,pada,danu. ‘ mama ba omo wi’ ‘ Bola re mi je’ ‘ Baba da isu nu.
  5. Oro ise akanmoruko : – Eyi ni a seda lati ara apapo oro-ise ati oro-oruko.Apeere ‘Tope muti yo [mu oti] ‘mama gunyan je [gun iyan] ‘ Abiola lawo pupo [la owo].
  6. Oro-ise Asapejuwe : – ni oro-ise ti a maa n lo lati so irisi nnkan.Apeere ‘Bisi pupa foo’ ‘Eyin Tolu funfun’ ‘ Tope ga’.
  7. Oro ise Asoluwadabo : – ni oro-ise ti oluwa ati abo le gbapo ara won.Eyi nip e a le si oluwa ati abo ni ipo pada laisi iyato ninu gbolohun naa.Apeere- ‘ Ojo n se were,were n se Ojo’ ‘ mo ti ju’ ‘oju ti mi’ ‘ mo jaya,aya mi ja’.
  8. Oro-ise Alapepada: – ni oro ise ti a maa n se apetunpe fun ninu gbolohun.Apeere ‘ iwo ni o ku mi ku’ ‘ E row a ro ire’ ‘Aye ko feni foro’ ‘ ma da mi da wahala’.
  9. Oro-ise Asinpo : – ni oro-ise ti o maa n je meji tabi meta ninu gbolohun pelu oluwa kan.iye oro ise ti o wa ninu gbolohun yii ni iye gbolohun ti a le ri fayo.fun apeere, ‘Ola sun isu ta.-Ola sun isu. – Ola ta isu. ‘Tope ji eran je’. – Tope je eran. – Tope ji eran.

Bolu sare lo gbe aga wa.

  • Bolu sare
  • Bolu lo
  • Bolu gbe aga
  • Bolu wa.

 

 

Ori – oro:         Isori oro:          Oro-asopo

 

  1. Oriki
  2. Orisii wunren oro-asopo

iii.        Ise ti won n se ninu gbolohun

 

AKOONU

Oro-asopo ni awon wunren ti a n lo lati so awon oro tabi gbolohun bii meji tabi ju bee lo po di gbolohun kan.

 

Apeere

  • Ade feran iresi
  • Tomi feran iresi
  • Ade ati Tomi feran iresi
  • Ile re tobi
  • Iyara re kere

 

Ile re tobi sugbon iyara re kere.  Awon wunren oro-asopo inu ede Yoruba ni ati pelu, oun afi sugbon nigba ti, ayafi, abi, amo, bee ni, yala, tabi anbosi bosi abbl

 

Ise ti won n se ninu gbolohun ise oro-asopo ni fun siso oro tabi gbolohun papo.

 

  1. ‘ati’, pelu ati oun ni a fi n so

(a)        oro-oruko, meji po ninu oro

 

apeere:

Tolu ati Oye lo si ilu oba

Tunde Pelu Toyin lo si Ikorodu

Ola oun Bayo jo n kawe

 

(b)        A le fi so oro-aropo afarajoruko meji po ninu iso

apeeere

Iwo ati oun ni oloro

Awon pelu eyin kii se egbe

 

(d)        A le fi ‘ati’, pelu so oro-oruko ati oro aropo afarajoruko po

 

apeere:

Iwo ati Deinde ni mo ri

Emi pelu Rotimi n ka iwe iroyin

 

(e)   Sugbon, tabi, amo. A n lo awon oro wonyi lati so gbolohun meji po ti abayori re yoo je gbolohun olopo oro ise alakanpo.

 

Apeere:

Bola pe mi sugbon n ko dahun.

Mama ni owo amo won o ra aso.

 

Isori oro:-  Oro-atokun

Wunren oro-atokun

  • Ise ti won n se ninu gbolohun
  • Ibi ti won ti n jeyo

 

AKOONU

Oro – atokun ni oro ti a n lo lati so iha ti oro-oruko meji kosi ara won.  Awon wunren atokun inu ede Yoruba ni:  si, ti, ni.  Oro-atokun maa n jeyo saaju oro-oruko ninu gbolohun.

 

Apeere:

Ade ti Ikeja lo si Oyingbo ni  ana

Ise ti oro-atokun maa n se

 

Ninu ihun gbolohun, oro-atokun maa n toka

 

  1. Ibi ti eniyan tabi nnkan n lo. Oro atoka re ni – si

 

Apeere:

 

Mo lo si Ibadan

Oduduwa tedo si Ile Ife

 

 

II          O maa n fi ibi ti eeyan tabi nnkan ti n bo han.  ‘ti’ ni wunren re

 

Apeere:

 

Dele ti Akure de lanaa

Eru ti ori aja ja lule

 

III.       Oro_atokun maa n se afihan ibi ti eeyan tabi nnkan wa.  ‘ni’ ni atoka re.

 

Apeere:

Talabi wa ni Ikeja

Olu wa ni Eko

Mama wa ni ile Hausa

 

 

 

 

ORO   APEJUWE

Oro-apejuwe-; ni oro ti o maa n yan oro-oruko ninu gbolohun.A n lo oro-apejuwe lati se alaye yekeyeke ohun ti a n soro ba ninu iso.

Ap.

Omo pupa ni Bunmi.

Esin funfun ni baba ra.

Oti lile ko dara.

Iwa rere ni eso eniyan.

Iro konsonanti lo maa n bere oro apejuwe.

ap

Omo kekere ni mo je.

Inu apola oruko ni oro –apejuwe maa n wa.

ap

Irin rederede ko ye omoluabi.

 

Orisii oro-apejuwe

Oro-apejuwe ipile-;eyi ni awon oro bii rere,kekere,nla.

Oro-apejuwe iseda-; eyi ni  awon wunren oro-apejuwe ti a seda nipa sise apetunpe elebe.

Ap

Mu  -mimu

ro  -riro

bo  -bibo

oro apejuwe  ti a seda nipa apetunpe

ap

nla- ile nlanla ni won fun wa.

Igbelewon

Tokasi oro apejuwe ti o wa ninu gbolohun yii

Sile mefamefa ni oluko fun wa.

Omo giga ni Bola.

Oruko rere san ju wura oun fadaka lo.

Igbelewon

  1. Kin ni oge sise?
  2. Daruko awon ona ti a n gba se oge ni aye atijo.

kin ni oro-ise?

Salaye isori oro-oruko meta pelu apeere metameta fun ikookan.

IWE AKATILEWA

Imo, ede, asa ati litireso fun ile-eko sekondiri agba i.o. 163

–                       Eko ede Yoruba titun i. o.105

-ISE  ASETILEWA

 

  1. ___________oro-aponle maa n pon ninu gbolohun

(a)        Oro-Oruko                               (b)        Oro ise                         (d)        Eyan

 

  1. Inu ____________ni a ti maa n ba oro-aponle pade

(a)        Apola-aponle               (b)        apola-oruko                 (d)        Apola ise

 

  1. ‘lau je je apeere oro-aponle ______________

(a)        aseda                                       (b)        alaiseda                        (d)

  1. . Atoka oro asopo ti a le fi so gbolohun meta po di eyo kan ni

(a)        ati                                            (b)        yala…..tabi                  (d)        amo

 

  1. Iwo oun Deinde kii segbe.  Oro asopo inu iso yii ni

(a)        iwo                                          (b)        oun                                          (d)        segbe

 

Apa keji

  1. Salaye awon isori oro wonyi pelu apeere metameta fun ikookan
  1. oro-ise
  2. oro-atokun
  • oro-asopo

 

OSE KEJI

 

ORI-ORO-   AWON ISORI GBOLOHUN GEGE BI IHUN WON.

Gbolohun-; ni ipede ti o kun to si ni ise ti on je.

Won fun  gbolohun ede Yoruba  ni oruko gege bi ise ti o n se.

Eyi ni awon gbolohun gege bi ihun won;

Gbolohun eleyo oro-ise

Gbolohun olopo-oro-ise

Gbolohun alakanpo

Gbólóhùn eleyo oro-ise-: ni gbolohun ti o maa n ni eyo oro ise kan

Apola oro oruko ati apola oro ise  ni o maa n wa ninu gbolohun eleyo oro-lse

 

Apeere

 

Apola oro-oruko             Apola oro-ise

Olu                                   sun

Mo                                   ra eran

Tisa                                na titi

Baba                               te   eba.

 

Gbólóhùn olopo oro-ise-: eyi ni gbolohun ti o maa n ni ju oro-ise kan lo, o le je meji, meta  tabi ju bee lo. Iye oro-ise ti o ba wa ninu gbólóhùn yii ni iye gbolohun  ti a le ri fayo ninu re.

Apeere

– Omo naa gba ile baba mo tonitoni

– Omo naa gba ile baba

– Ile baba mo tonitoni

– Bolu sare lo ra aso

– Mama lo ra eran wa

Gbólóhùn -ase ni a maa n lo lati pase.

Gbolohun alakanpo-;eyi ni gbolohun ti a fi oro-asopo so awon gbolohun po mo ara won lati di eyo kan.okookan awon iso yii ni won le da duro.

ap

          Ola wa

      Ola ko ba mi

Ola wa sugbon ko ba mi.

Awon oro-asopo ni; ati, amo, sugbon,

  Titi ati Folake n gbafe ni ita.

  O ni aya sugbon ko lowo.

Igbelewon

  Salaye awon gbolohun wonyi pelu apeere mejimeji fun ikookan

             Gblolohun eleyo oro-ise

              Gbolohun olopo oro-ise

               Gbolohun alakanpo.

 

 

            ASA

ORI-ORO-;ASO WIWO LAARIN OKUNRIN ATI OBINRIN

  Aso wiwo-; je okan lara asa Yoruba ti o se pataki nitori pe ohun ni a fi n bo ihoho wa.

      Bakan naa, aso wiwo maa n je ki a dun un wo ki oju wa si gun rege.

Orisiirisii aso ni awon Yoruba ni,ti ohun ti a n lo ikookan won fun si yato si ara won.

       A pin awon aso Yoruba si

           Aso ise

           Aso iwole

           Aso imurode

  Iran Yoruba ki i wo aso idoti ,ohun ti won fi n pe won ni afinju niyi.Orisiirisii aso ni a ni ni ile Yoruba, aso obinrin yato si ti okunrin bee naa ni aso okunrin yato gedegbe si ti obinrin.Ni ile Yoruba obinrin ki I wo aso okunrin bee ni okunrin ko gbodo wo aso obinrin.

  Aso okunrin                                            Aso  obinrin   

    Buba                                                           buba

    Adiro                                                          iro

   Dandoogo                                                   gele

    Agbada                                                      iborun

     Dansiki                                                      ipele

     Sapara      

     Oyala

      Sulia

      Gbariye

       Kafutaani

       Kenbe

       sooro  

       Atu          

       Kamu

       Abeti aja

        Origi/ ikori

        Adiro

Ayipada ti o de baa so wiwo aye atijo

     Orisiirisii  ayipada ni o ti de baa so wiwo ni aye-ode oni,asa igbalode ti je ki imura ati iwoso yato si ti aye atijo.

      Aso lo n basiri ara ju sugbon ni aye ode-oni aso to n fi ihoho awon odo han ni won n wo.

    Ni aye atijo awon obinrin ki i wo sokoto.Oge odi sise ti so awon obinrin di eni ti on wo sokoto.

     Aso ti won n wo ni aye ode-ni ni

         Kootu

         Seeti

         Tai

         Sokoto

         Kaba

         Sikeeeti

      Igbelewon

  1.Kin ni oge sise?

  b.Daruko orisii ona ti a n gba soge laye atijo.

  1. Daruko orisii aso okunrin ati obinrin marun-unmarun-un.

   IWE AKATILEWA

       Simplified Yoruba Language Literature and  Culture bk 1 o.i 82-85,21-27.

ISE ASETILEWA

     1.Ibo lo ti n bo je

        (a) Gbolohun alaye  (b) Gbolohun ase  (d) Gbolohun ibeere.

  1. Gbogbo yin, e maa bo je

        (a) Gbolohun kani (b) gbolohun ibeere  (d) gbolohun ase

  1.   Dandoogo je apeere aso———-

       (a)  omode  (b)  okunrin  (d) obinrin

  1. ——— ni a n pea so ti awon ode maa n wo lo si igbe

       (a)  aso ode   (b)  gberi   (d) jerugbe                           

  1. Apeere aso ti a n wo laye ode-oni ni

       ­(a)  iro   (b) sikeeti     (d)  oyala

                             APA KEJI

 

    1. Salaye awon gbolohun yii pelu apeere mejimeji fun ikookan.

          Gbolohun alakanpo

           Gbolohun ase

           Gbolohun  ibeere.

2,Kin ni oge sise?

b.Daruko orisii ona ti a n gba soge ni aye atijo

  1. Daruko orisii aso marun-un fun okunrin ati obinrin.

 

 OSE KETA

ORI-ORO-;AWON ISORI GBOLOHUN EDE YORUBA GEGE BI ISE WON.

 

Ori-oro  Isori gbolohun gege bi ihun won

Ori – oro Isorí gbólóhùn gégé bíi ìse wọn

Oríkì

Ìsorí gbólóhùn pèlú àpẹẹrẹ

àkóónú

Gbólóhùn ni ìpèdè tí ó kún, tí o sí ní ìse tí ó ń jé.

Gbólóhùn jé ìsọ tí ó ní ìtumo kíkún.

A fún àwon gbólóhùn Yorùbá ní orúkọ gégé bí íse tí won ń se

 

Àpẹẹrẹ

Bólú je èbè

Bàbá kọ ebè

Èyà gbólóhùn

Orisiirisii ni awon eya gbolohun ti o wa ninu ede Yoruba.

Gbólóhùn        Ibeere

Gbólóhùn        Ase

Gbólóhùn        Alaye

Gbólóhùn        Akiyesi alatenumo

Gbólóhùn        Kani

Gbólóhùn        lyisodi

Gbólóhùn -ase ni a maa n lo lati pase

Apeere

Wa

Jade

Dake

Lo pon omi wa

Gbólóhùn lbeere-: ni a maa n lo lati se lbeere tabi wadii nnkan ni orisiirisii ona nipa lilo wunren lbeere bii kin ni elo, nibo, tani,  meloo, nigba wo.

Kin ni oruko re?

Nibo ni o n lo?

Elo ni o ra iwe yii?

Tola da ?

Se olu ti  wa?

Gbólóhùn kani-: ni a fi maa n so wulewule bi nnkan se ri ati idi ti o fi ri bee.

 

Apeere

Bi mo ba lowo, maa kole

Kaka ki n jale, maa seru

Bi bolu ba ro be yoo jeko

Gbólóhùn akiyesi alatenumo-: ni a fi n pe akiyesi si apa kan koko inu odidi gbólóhùn. ‘Ni’ atoka gbolohun yii . A le se atenumo fun oluwa ,abo tabi oro-ise .

 

Apeere

Mo ra iwe

Iwe ni mo ra (abo)

Rira ni mo iwe (oro-ise)

Emi ni mo ra iwe (oluwa)

Gbolohun iyisodi-: ni a fi n ko isele

 

Apeere

Bolu ko jeun

Baba ko yo

Se o maa lo?

N ko lo.

Bolu ti de?

Ko tii de

,

Igbelewon:

Kin ni gbolohun?

Salaye eya gbolohun marun-un pelu apeere kookan.

   I

 

ASA

ORI-ORO -;ILA KIKO

Ila kiko je okan lara ise abinibi ti a ni aye atijo,o je ise iran tabi ise idile,ise yii ni o je mo ila kiko.Tokunrin tobinrin, tomode tagba ni o maa n kola laye ayijo.

Awon  oloola ni o maa n ko ila laye atijo, o si je ise okunrin.Ohun ti won fi n ko ila ni abe sekele,osun,ose dudu,omi ogbin ewe feru.Aaro kutukutu ni won maa n ko ila

AKOON

Pataki ati iwulo ila

Ila kiko je okan lara awon ona ti a n gba sara loge laye atijo,awon Yoruba maa n

ko ila ni orisiirisii ona,bi a ti ri awon to n kola si ereke,iwaju ori ati agbon naa

ni a ri awon ti n ko ila si ara ,lati igbaya titi de isale ikun ati lati eyin de ibadi.

Pataki ila kiko

Idi Pataki ti a fi n ko ila oju ni ile Yoruba pin si ona m

  1. Ona akoko ni pe ila kiko maa n je ki a da ara wa mo ni aye atijo.
  2. O maa n bukun ewa wa ni aye atijo.

Ila oju yii pin si orisiirisii bee ni won yato lati agbegbe kan si ikeji,awon ila ti a ni naa ni-;

Pele

Baamu

Abaja

Keke

Ture

Gombo

Ila ondo

Pele-; ni ila meta ooro ti a fa si ereke,o wopo laarin awon Ijebu.

Gombo-; eyi ni ila gigun ti a fa lati ori,ti o si te woroko, o wopo laarin awon Oyo,Ogbomoso,Iwo,Ede ati Osogbo.

Ila ondo-; eyi ni ila kookan ti a  fa si ereke, eyi  wopo laarin awon Ondo.

Awon oloola lo maa n ko ila laye atijo,ohun-elo ti won maa n lo ni abe,omi igbin abbl.

Igbelewon

  1. kin ni oge sise?
  2. Daruko orisii ona ti a n gba sara loge laye atijo.
  3. Daruko orisii ila ti a ni ati idi meji ti a fi n ko ila laye atijo.

Iwe A katilewa.

Eko Ede Yoruba Titun,Oyebamiji Mustapha et al.203-215.

ISE ASETILEWA

1 Koko ise oloola ni——–

(a) ara finfin  (b) eyin pipa    (d)  ila

  1. ——– ni ila meta ti a ko ni ooro

(a) keke  (b) ila meta   (d) pele

  1. Igba wo ni won maa n ko ila ni aye atijo?

(a) aaro  (b) osan   (d) ale

  1. —— ni atoka fun gbolohun akiyesi alatenumo

(a)  ti  (b) ni    (d) si

5.Ade tobi sugbon ko ni agbara je gbolohun

(a)  akiyesi    (b)alakanpo  (d)  ase.

APA KEJI

  1. Salaye awon isori gbolohun yii pelu apeere mejimeji fun ikookan.

Gbolohun akiyesi alatenumo

Gbolohun iyisodi

Gbolohun kani.

2 Daruko orisii ila merin ti o mo.

b.Daruko ohun elo meta ti a n lo fun ila kiko.

 

 

OSE KERIN

ORI-ORO-;AROKO ALAPEJUWE

Aroko alapejuwe-; je aroko ti a fi n se apejuwe nnkan,nnkan yii le je ohun elemii tabi ohun alailemii.

Aroko alapejuwe ni a maa n lo lati yaworan nnkan ti o wa ni ookan aya eni sile ni ona ti eni ti ko si nibe yoo le fi oju inu wo o bi isele tabi nnkan naa se ri gan-an.

Eyi ni apeere awon ori-oro ti o je mo aroko alapejuwe

  • Aafin oba kan ti mo wo ri
  • Oja ale
  • Ija kan ti o soju mi
  • Omobinrin kan ti o wu mi lati fe.
  • Oja igbalode kan ti mo mo.

Igbelewon

Ko aroko lori

Ile-iwe re.

 

ASA

ORI-ORO-;ASA IGBEYAWO NI ILE YORUBA

Ni ile Yoruba paapaa laye atijo,awon Yoruba ko fi owo yepere mu igbeyawo rara,won ka a si nnkan pataki,gbogbo ohun to si ro mo igbeyawo naa ni o se pataki.

Gbogbo ohun ti o se pataki ninu igbeyawo yii ni won o ka si mo ni aye ode-oni,eyi si ni ko je ki igbeyawo pe mo ni ode-oni ko to daru. Igbeyawo je ibasepo laarin ebi meji ,o je igbeyawo laarin ebi oko ati ebi iyawo.

Igbeyawo je isopo okunrin ati obinrin lati maa gbe po gege bi oko ati aya.

Awon okunrin n gbe iyawo lati je oluranlowo fun won.

Bakan naa won fe ara won ki won ba a le ni aaro laye.

IGBESE IGBEYAWO

Eyi ni awon igbese igbese igbeyawo ti won maa n tele ni aye atijo

-Ifojusode

– Iwadii

– Alarina

–  Isihun/ Ijohen

–  Itoro

– Idana

– Igbeyawo

 

 

Ifojusode-;eyi ni igbese akoko ninu eto igbeyawo,bi odomokunrin ba ti balaga, yoo fi oju sode lati wa eni ti o wu u lati fe,bi o ba je aye atijo ni awon obi lo maa n foju sode lati wa iyawo fun omo won,ki i se ewa oju nikan ni won n fe bi ko se ati iwa.

Iwadii

Leyin igba ti odomokunrin ba ti ri iyawo to wu u lati fe,ohun ti yoo se ni pe yoo so fun awon obi re,awon obi re yoo si se iwadii iru iwa ti iya omo naa n hu nitori won gbagbo pe bi iwa iya ba ti ri bee ni ti omo re obinrin se maa ri.Won yoo se iwadii finnifinni bi arun buburu kan bi ete, warapa ati ikofee ba wa ninu ebi won,won yoo wadii boya ajigbese ni awon obi re abbl.

Paripari re won yoo wadii lodo Ifa bi igbeyawo won yoo ti ri, bi ifa ba fore  abusebuse.

Igbese keta ni alarina,alarina je iko ti o maa n gbokegbodo laarin odomokunrin ati odomobinrin ti won fe fe ara won.

Okan pataki ninu ise alarena yii ni lati se iwadi finifini nipa omobinrin naa ati idile re.  Eni to ba se e finu tan ni a maa n lo gege bii alarena nitori ise elege ni ise naa.  Oun ni yo mo gbogbo ogbon ati ete ti yoo lo lati ri pe omobinrin naa je hoo.  Ni kete ti awon mejeeji ba si ti pade ti won ti moju ara won ise alarena pari niyen.  Eyi ni won fi maa n powe pe bi oko ba moju aya tan alarena a yeba.

IJOHEN/ISIHUN

Orisirisi iwadi ni awon idile omobinrin naa maa n se lati mo iru idile ti omokunrin to fe fe omo won ti wa.  Boya won ni aisan kan to n ja won tabi idile onigbese ni won.  Ti ko ba ti si iwa abuku kankan ni idile naa, ti o si dun mo omobinrin lati fe okunrin naa ni omobinrin naa yoo to wa dahun pe oun gba.  Gbigba ti omobinrin yii gba lati fe omokunrin naa ni a n pe ni ijohen tabi isihun.Poun meji sile meji ni owo isihun ti oko yoo san fun iyawo afesona re.

ITORO

Gege bi asa Yoruba, ni kete ti omobinrin ba ti johen fun omokunrin oun ti o  kan ni ki awon obi omokunrin naa lo se itoro lodo awon obi omokunrin naa.  Ibi ni gbogbo eniyan yoo ti mo won gege bi afesona ti won yoo si da ojo idana

IDANA

Ojo idana ni ojo ti awon ebi omokunrin naa yoo wa san gbogbo ohun ti awon ebi iyawo ba fe gba patapata laiku eyokan.  Ariya ranpe lewaye ni iru ojo yii, igba yii ni won to sese ma mo awon mejeeji gege bi oko ati iyawo, won a si da ojo igbeyawo.

IGBEYAWO

Bi idile oko tabi idile iyawo ba se lowo to, bee naa ni ayeye igbeyawo won yoo se larinrin to, yato si pe to ba je won ko gbodo se igbeyawo alariwo gege bi iwadii ti won base.

Gege bi asa igbeyawo ni ile Yoruba owo irole ni iyawo maa n lo ile oko re nitori ero ni won ka asiko yii si. Ki o to di asiko yii ni yoo ma a kaakiri lati gba adura lenu awon obi ati ebi re ti won yoo si maa fun ni amoran lorisirisi.  Ni ale ojo keta, o di dandan ki oko sunmo iyawo re lati mo boya o ti mo okunrin ri tele.  Abuku gba a ni o maa n je fun iyawo ati awon ebi re to ba ti mo okunrin tele.  Sugbon ti ko ba ti i mo okunrin kan tele, orire n la ni fun won.

IGBELEWON

  1. Ki ni a n pe ni ifojusode ninu eto igbeyawo abinibi
  2. Se alaye ise alarena
  3. Kini ijohen tabi isihun tumo si
  4. Kini iyato laarin itoro ati idana

AKATILEWA

Imo,Ede,Asa Ati Litireso. Adewoyin S.Y. o .i 286-294.

ISE ASETILEWA

  1. Igbese akoko ninu igbeyawo ni

(a)  alarina    (b)  ifa iyawo   (d)  ifojusode

  1. Ara eru idana niyi, afi

(a)  aso  (b)  ate  (d)  owo.

  1. Bi oko ba moju aya tan,—- a yeba.

(a) iya oko  (b)  baba oko  (d)  alarina

4   ——-  ni a maa n san fun owo isihun

(a) poun kan sile kan  (b) poun meji sile meji   (d) poun meji sile kan.

  1. Ewi atenudenu ti a n lo fun ayeye igbeyawo ni

(a)  rara   (b) ekun iyawo (d)  orin iyawo

APA KEJI

  1. Kin ni igbeyawo
  2. Daruko awon igbese igbeyawo ti o wa.
  3. Ko aroko lori egbon re.

 

 

 

 

OSE  KARUN-UN

ORI-ORO-;Aayan  Ogbufo

 

 

AKOONU

Aayan ogbufo ni ise titumo ede kan si ede miiran

 

Ki ogbufo to le kogo ja ninu itumo ede, o gbodo mo tifun tedo ede Geesi , ki o si le tusu ede Yoruba naa de isale ikoko.

 

Kii se gbogbo oro inu ede kan naa le tumo si ode miiran.

 

A ko gbodo mu gbolohun ni okookan lati tumo, sise bee yoo so ewa ati itumo iru ayoka bee nii.

 

A ko gbodo mu oro ni eyo kookan lati tumo, ti a ba se been yoo so itumo oro ti a fe tu nu.

 

Akaye ati akatunka ayoka se Pataki ki o to le se ogbufo to peye.  Rii pe o lo akoto to muna doko eyi ni yoo je ki o see ka.

 

Lilo itumo erefee ko bojumu, eyi ko ni fun wa ni itumo ti o kun, itumo ijinle ni o ye ogbufo.

 

O san ki ogbufo lo oruko ti o wa ninu ayoka.

Eyi ni aayan ogbufo sise laarin awon akekoo ninu kilaasi.

 

Please bury the harchet

Jowo fiye denu

 

He who fight and run away, leaves to fight the other day

Agbo to feyinrin, agbara lo lo mu wa.

 

Time and tide wait for no man

Akoko ati igba ko duro de enikan.

 

Paddle your own canoe

Gbo tire       

 

They may have been drumming

Won ti le maa lu ilu

 

He came in reluctantly

O wole tikotiko

 

Tumo ayoka yii si ede Yoruba

 

Birds take a great deal of trouble to give their young a good start in life.  The female bird lays hard-shelled egg from which the young animal gradually develop with supplies of good good and air.  In most cases the eggs are laid in a carefully prepared nest which is hidden from enemies or out of their reach.

 

Awon eye a maa se opo wahala lati fun awon omo won ni ibere rere ni aye. Iya eye a maa ye eyin eleepo lile.

 

Ninu eyin yii ni awon omo eye yo ti maa ri ounje ati afefe ti yo mu won maa gbora diedie.  Ni opolopo igba inu ite ti won farablae ko ti o sa pamo fun ota ni won maa n ye won si.

 

ASA

ORISIIRISII IGBEYAWO TI O WA

 

Orisiirisii igbeyawo ni o wa ni ile Yoruba ni aye atijo, awon naa ni

Igbeyawo nisu loka

Jiji iyawo gbe

Pade mi ni diiko

Gbigbe ese le iyawo

Igbeyawo nisu loka-: eyi ni igbeyawo ti a se ni ona ti o to,ati eyi ti o ye.Eyi ni igbeyawo ti won tele gbogbo eto, ilana ati igbese igbeyawo ti o ye,ti idile mejeeji si fi owo sii.

Jiji  iyawo gbe-; eyi naa je orisii kan ti ko tona ,eyi ni jiji iyawo ti fe fe gbe ni ona oja,lona odo, won a si gbe e lo si ile, o di iyawo niyen.

Pade mi ni idiko-; eyi je ona ti omobinrin ti ko fi ara bale n gba lo si ile oko,eyi nip e adehun ti maa wa laarin omobinrin yii ati oko afesona re lati salo, won yoo si fi ipade si idi oko nibi ti won yoo gba salo

Gbigbe  ese le iyawo-; eyi ni nigba ti oba ba gbe  ese le iyawo asesegbe ti o sese n lo si ile oko,ti yoo si di iyawo oba lesekese ti oko iyawo o si gbodo so nnkankan,boya iyawo naa fe tabi o ko o di iyawo oba ni yen, ti ohunkohun ko si ni tie yin re wa.

IWE AKATILEWA

 

 

ISE ASETILEWA

1.———  ni  eni ti o n se ise ogbufo

(a) Aayan       (b)  Ologbifo     (d)  ogbufo.

  1. This is a societal problem.tumo si

(a)  Isoro egbe niyi   (b) isoro  awujo niyi   (d) isoro ilu niyi

3.________   nikan ni o le gbe ese le iyawo

(a) Oba     (b) Ijoye  (d) Ogboni.

  1. Igbeyawo ti o tele eto ati ilana igbeyawo ile Yoruba ni———

(a) igbeyawo nisu loka  (b) pade mi nidiiko (d) iyawo gbigbe ese le.

  1. Igbeyawo ——- nikan lo le duro gba ase lenu obi.

(a) pade mi nidiiko   (b)  Iyawo ti a gbese le   (d)  Igbeyawo nisu loka.

APA KEJI

1.Salaye awon igbeyawo wonyi

  1. igbeyawo nisu loka
  2. pade mi nidiiko

iii.  iyawo ti a gbese le.

  1. Salaye ohun merin ti a gbodo mo ki a to se aayan ogbufo.

OSE KEFA

ORI-ORO-;SISE AYOKA EDE GEESI SI EDE YORUBA

 

ASA

ORI-ORO-; IGBEYAWO ODE-ONI

  • IGBEYAWO SOOSI
  • IGBEYAWO MOSOLASI
  • IGBEYAWO KOOTU

Lode oni, aye ti di amulumala. Orisirisi ona ni a n gba gbe iyawo.  A n gbe iyawo ni ile Olorun, a n gbe e ni kootu, a si n gbe ni mosalasi.  Igbeyawo soosi yii fese mule laarin awon onigbagbo, igbeyawo mosalasi si mule laarin awon musulumi.

Igbeyawo soosi ni eyi to maa n waye laarin awon elesin Kristeni ninu ile ijosin won, sugbon ki eto igbeyawo yii to waye ni won yoo ti maa kede eni to ba ri idi ti won ko le fi so oko ati iyawo naa papo ko tete wa so bi bee ko  ko gbe enu re dake laelae.  Bi won ko ba tiri enikeni ko yoju ni won to le so awon mejeeji po.  Iru igbeyawo yii ko faye gba ju iyawo kan lo.

Igbeyawo mosolasi maa n waye laarin awon musulumi, eyi faye gba ju iyawo kan lo nitori won  ni “me” ni Olorun wi, ti agbara okunrin naa ba ti kaa.  Awon musulumi a maa fi omo se saara lae je pe onitohun fi okan sii tele eyi nipe ki won fun eniyan ni iyawo lairo tele.  Eyi ni won maa n pe ni iyawo saara.

Orisii igbeyawo yii fese mule daadaa nile Yoruba nitori esin igbagbo ati Isilamu to fese mule lode oni.  Gbogbo ilana lati ibi itoro titi de idana maa n saba je eyi ti a n tele.

Awon loko laya miiran a maa se igbeyawo alarede ti o je pe won a lo si olu ile-ise ijoba ibile tabi Kootu lati fowo si iwe ase ijoba, won a si fi bee gba oruka arede.  Eleyii naa ko faye gba ju iyawo kan ati oko kan lo, igbeyawo kootu ni a n pe e.

Ni aye ode oni ko si ohun to n je ekun iyawo mo, opolopo awon odo iwoyi ni won ti daju, gbogbo won ni oju n kan lati lo ile oko.  Ko tile sohun to fe pawon lekun nitori won ko ka ile oko si ohun babara.

IGBELEWON

  1. Salaye igbeyawo soosi
  2. Ki ni ohun ti o le so lori igbeyawo kootu
  3. Se afiwe igbeyawo abinibi pelu igbeyawo ode oni
  4. Awon ona wo ni awon musulumi n gba se igbeyawo

IWE AKATILEWA

  • Eko ede Yoruba titun (J S S ) iwe keji oju iwe 35-54 lati owo Oyebamiji Mustapha.
  • Eko ede ati asa Yoruba iwe keji oju iwe114-118 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

ISE ASETILEWA

  1. Awon………….. lo n se igbeyawo soosi

(a)        Musulumi        (b)        Igbagbo            (d)        Aborisa.

  1. Awon ________________lo n se igbeyawo Mosolasi

(a)        musulumi         (b)        Igbagbo            (d)        Aborisa.

  1. Awon _____________________lo maa fi omo se saara

(a)        Onigbagbo       (b)        Alarede            (d)        Musulumi

  1. kEJI

1 Salaye awon  igbeyawo wonyi

– igbeyawo soosi

– igbeyawo  mosalasi

– igbeyawo  kootu.

 

 

OSE  KEJE

ORI-ORO-;ONKA  YORUBA

OOKAN  DE EGBAA

 

ONA MEJI PATAKI NI ONKA YORUBA PIN SIN

ONKAYE        (ON – KA – IYE)

ONKAPO        (ON – KA – IPO)

‘m’ ni a fi n da pupo ninu awon onkaye Yoruba mo nigba ti a n fi (i) mo onkapo

 

Apeere

ONKAYE                                                        ONKAPO

Meni (mu eni)              =          1                      Ikini (iko eni)               =          1st

Meji (mu eji)                =          2                      Ikeji (iko eji)                =          2nd

Meta (mu eta)              =          3                      Iketa (iko eta)              =          3rd

Merin (mu erin)           =          4                      Ikerin (iko erin)           =          4th

Marun-un  (mu aarun   =          5                      Ikarun-un (iko arun)    =          5th

Mefa (mu efa)             =          6                      Ikefa (iko efa)             =          6th

Meje (mu eje)              =          7                      Ikeje (iko eje)              =          7th

Mejo (mu ejo)              =          8                      Ikejo (iko ejo)              =          8th

Mesan-an (mu esan)    =          9                      Ikesan (iko esan)         =          9th

Mewaa (mu ewa)         =          10                    Ikewaa (iko ewa)         =          10th

Mokanla (mu okan-le-ewa)      11                    Ikokanla (Iko-okan-le-ewa)     11th

Mejila (Mu-eji-le-ewa) 12                    Ikejila (iko-eji-le-ewa)=           12th

Metala (mu-eta-le-ewa)            13                    Iketala (iko-eta-le-ewa)            13th

Merinla (mu-erin-le-ewa)         14                    Ikerinla (iko-erin-le-ewa)         14th

Ki ato le mo itumo awon onka marun-un to tele merinla (14) a nilati wo iwaju ki a ri ogun (20) ki a tun woe yin ki a wo iye ti okookan awon onka wonyi (15-19) fi din si ogun bayii.

Meedogun (mu arun-din-ni-ogun)                    15

Ikeedogun (iko-arun-din-ni-ogun)                   15th

Merindinlogun (mu-erin-din-ni-ogun)              16

Ikerindinlogun (iko-erin-din-ni-ogun)              16th

Metadinlogun (mu-eta-din-ni-ogun)                 17

Iketadinlogun (iko-eta-din-ni-ogun)                 17th

Mejidinlogun (mu-eji-din-ni-ogun)                  18

Ikejidinlogun (iko-eji-din-ni-ogun)                  18th

Mokandinlogun (mu-okan-din-ni-ogun)                      19

Ikokandinlogun (iko-okan-din-ni-ogun)                      19th

Ogun (20) da duro funra re, ko si tumo si

eewa meji, o je akanda onka, oun naa ni a mo si okoo

mokanlelogun (mu-okan-le-ni-ogun)               21

Mejilelogun (mu-eji-le-ni-ogun)                                   22

Metalelogun (mu-eta-le-ni-ogun)                     23

Merinlelogun (mu-erin-le-ni-ogun)                  24

A o wo iwaju ri ogbon, ki atun woe yin wo iye ti okookan awon onka yii fi din.

Meedogbon (Mu-arun-din-ni-ogbon)               25

Merindinlogbon (mu-erin-din-ni-ogbon)          26

Metadinlogbon (mu-eta-din-ni-ogbon) 27

Mejidinlogbon (mu-eji-din-ni-ogbon)  28

Mokandinlogbon (mu-ookan-din-ni-ogbon)    29

Ogbon                                                              30

Bi a o se kaa niyi titi de ori

Ogoji (ogun eji =          20 x 2 =                      40

Ogota eta (ogun eta)     =          20 x 3  =          60

Ogorin (ogun erin)       =          20 x 4  =          80

Ogorun-un (ogun arun)            20 x 5  =                      100

Ogofa (ogun efa)         =          20 x 6  =          120

Ogoje (ogun eje)          =          20 x 7  =          140

Ogojo (ogun ejo)          =          20 x 8  =          160

Ogosan (ogun esan)     =          20 x 9  =          180

Ogowaa (ogun ewa)     =          20 x 10 =         200

Ogowaa yii tun ni akanda oruko kan Pataki ninu ede Yoruba

Ilo aadin-(ewa din)

Aadotan (ewa-din-ni-ota)         =          (20 x 3) – 10    =          50

Aadorin (ewa-din-ni-orin)        =          (20 x 4) -10     =          70

Aadorun-un  (ewa din ni orun)            (20 x 5) – 10    =          90

Aadofa (ewa-din-ni-ofa)          =          (20 x 6) – 10    =          110

Aadoje (ewa-din-ni-oje)           =          (20 x 7) – 10    =          130

Aadojo (ewa-din-ni-ojo)          =          (20 x 8) – 10    =          150

Aadosan (ewa-din-ni-osan)      =          (20 x 9) – 10    =          170

Aadowaa (ewa-din-ni-owa)     =          (20 x 10) – 10  =          190

Ogowaa (ogun mewaa)            =          (20 x 10)          =          200

Ti a ba lo isiro ilopo ogun, onka naa lo bayii

220      (200 + 20)                    =          Okoolenigba

230      (200 + 30)                    =          Ogbonlenigba

240      (200 + 40)                    =          Ojilenigba

260      (200 + 60)                    =          Otalenigba

280      (200 +  80)                   =          Orinlenigba

300      (200 + 100)                  =          Oodunrun

320      (300 + 20)                    =          Okoolelodunrun

340      (300 + 40)                    =          Ojileloodunrun

360      (300 + 60)                    =          Otaleloodunrun

380      (300 + 80)                    =          Orinleloodunrun

400      (300 + 100)                  =          Irinwo

420      (400 + 20)                    =          Okoolenirinwo

440      (400 + 40)                    =          Ojilenirinwo

460      (400 + 60)                    =          Otalenirinwo

500      (400 + 100)                  =          Eedegbeta (200 x 30) – 100

600      (400 + 200)                  =          Egbeta (200 x 3) = 600

700      (400 + 300)                  =          Eedegberin (200 x 4) – 100

800      (200 x 4)                      =          Egberin

900      (200 x 5) – 100            =          Eedegberun

1000    (200 x 5)                      =          Egberun

1200    (200 x 6) (Igba mefa)  =          Egbefa

1400    (200 x 7) (Igba meje    =          Egbeje

1600    (200 x 8 (igba mejo     =          Egbejo

1800    (200 x 9) (igba mesan-an)        egbesan

2000    (200 x 10) Igba mewaa)           Egbawa (egbaa)

ASA

ASA OYUN NINI

AKOONU

 

ITOJU OYUN  ATI  IBIMO

IGBAGBO YORUBA NIPA AGAN, OMOBIBI ATI ABIKU

  • ITOJU OYUN
  • IBIMO

Gbogbo wa la mo bi omo ti se pataki to laarin awa Yoruba.  Ko si bi owo, ola ati ola eniyan ti le po to ti ko ba bimo aye asan ni oluwa re wa.  Igbagbo yii fese mule laarin awon Yoruba to bee to fi je pe ko si ohun ti won ko le fi wa omo.  Nitori naa asa oyun nini ki i se nnkan ti won  n fi owo yepere mu rara, obinrin ti ko ba le loyun ni won  n pe ni agan nile Yoruba.  Ti okunrin ba gbe iyawo ti iyawo yii ko tete loyun tabi ti omo ba dagba lowo obinrin ti oyun ko ba tetede wonu de fun  okunrin naa niyen, ki a ni yoo ti to awon agba lo fun aajo ki iyawo le tete loyun.

Orisirisi itoju ni a maa n fun awon alaboyun ni ile Yoruba, lati igba ti iyawo ba ti so fun oko re pe oun kori nnkan osu oun mo ni yoo ti maa fi inu ro ona ti yoo gba, ti a o gbohun omo ti a o si tun gbo ti iya ti oyun na ko si ni baje.  Lara ona ti a n gba se itoju oyun ni Oyun dide  eyi saba maa n waye ti oyun ba n baje lara obinrin, ti iru obinrin yii ba loyun miran won maa n de e ki oyun naa ma ba tun baje.

Ohun miran to tun maa n je ki won de oyun ni pe laye atijo won ki i fe se oyun fun obinrin nitori ese ni won kaa si dipo bee se ni won  a de e ki oyun naa ma ba soke.  Looto ni won n lo orisirisi oogun, sugbon a kii saba lo oogun fun aboyun laarin osu kini si eketa, to ba pe osu meta orisirisi oogun ni won le lo.  Oogun ki omo le maa gbera daadaa ninu, ki ara obinrin le fuye, eyi ti yoo maa lo ti ese re ba n wu ati eyi ti yoo fi bi were (oogun abiwere).

Omiran ninu awon oogun wonyi yoo je nnkan bi agbo fun mimu tabi nnkan wiwe, omiran si le je lila.  Gbogbo agbo tabi ogun yii lo ni asiko ti a gbodo lo won.  Omiran ni osu keta, omiran ni osu karun-un tabi osu keje.

Ti oyun ba ti bere sii mu obinrin daadaa, won a ni ko kunle ko bere si ni gbin kikan-kikan.  Agba obinrin kan yoo duro leyin re.  ekeji niwaju lati maa so igba ti omo ba fe yo ori sita, ni kete ti won ba ti ri ami pe omo n bo ni won yoo ti te aso sile ti won yoo si fi owo pade re ti o

ba n bo.  Nigba miran isoro le wa sugbon gbogbo itu ti won ba mo ni won yoo pa tan.

                        OMO BIBI/ OJO IKUNLE

 

Ori ikunle ni obinrin ti maa n bimo.Bi o ba to asiko atibimo. Aboyun yoo ri eje ati omi die lara  omira re ami pe o to akoko lati bimo niyen. won a ni ki o maa gbin leralera. Agba obinrin yoo duro leyin re okan niwaju lati ma so igba ti omo maa yo ori sita ni igba miira isoro le wa sugbon gbogbo itu ti agbebi ba le pa ni yoo pa.

Eewo/Oro ile: Oro ile ni nnkan ti obinrin ti o bimo ko gbodo se fun anfaani ara re ati nitori omo to sese bi . Oro idile ibikan yato si omiiran. Fun apeere:

Ni idile olu oje, obinrin to bimo ko gbodo je iyan tabi amala titi ojo ikomojade. Isu ati ekuru ni yoo maa je. Ni idile onigbeeti, iya ikoko o gbodo je obe to ni iyo tabi ata titi di ojo ikomojade iru eyi ni won n pe ni obe ate. Won maa n gun iyan ati iru pelu epo pupa ni idile olokun esin iru ounje yii ni yoo maa je titi di ojo ikomo. Idile olofa ni won ti maa n je obe ate obe afun ni obinrin to sese bimo yoo maa fi je oka amala igbako kan soso lemeeta lojumo

                IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ABIKU

 

Abiku ni awon omo ti won maa n bi ju eekan  lo. Iru awon omo bayi maa n ku ti won ba ti n bi won. Igbagbo Yoruba nipe iru awon omo bayi ni egbe lorun. Inu le bi awon obi omo ki won ge ika ese tabi ti owo omo naa nigba ti o ba su won. Igbagbo won ni wi pe iru awon omo bee ko ni ya odo won mo ti o ba tun ile aye wa. Abuku ni iru eyi je fun won tori pe awon egbe re o ni gba mo. Orisirisi oruko ni o fi han pe abiku n be. Fun apeere kokumo, Fidimaye,Malomo, Kukoyi, Maku, Kosoko,Rotimi, Durosinmi Kosoko.

IGBELEWON

  1. Salaye orisii ona ti awon Yoruba n gba se itoju oyun ni aye atijo.

 

LITIRESO

ORI-ORO-;ITAN OLORO GEEREGEGE BI ORISUN ITAN  ATI ASA YORUBA;ASA BI YORUBA SE N SIN OKU SI INU ILE.

Litireso atenudenu-; je awon ewi ati itan ti a jogun ba lodo awon baba-nla wa, o je atenudenu nitori pe won ko si ni akosile nitori pea won baba-nla wa ko mo-on-ko bee ni won ko mo-on-ka.

Awon ewi atenudenu wonyi  lo je orison fun opolopo itan ati asa Yoruba, aria won itan atenudenu to n so isedale ati idi abajo asa ile wa lati inu odu ifa ,lati inu itan oniruuru ogunto ti ja koja ni ile Yoruba ati lati inu itan aroso adayeba.

Ni bayii, a fe wo idi ti awon Yoruba fi n sin oku

Ni aye atijo, awon Yoruba ki i.oku to ba ku.Won maa n gbe oku sonu sinu igbo ni to ba wa lebaa ilu ni. Bi oku ba ku ni ibikibi laarin ilu,inu igbo ni won ni won n ju u si tabi ki won so o sinu iho igi ninu igbo.

Nigba ti a n wi yii, okunrin kan wa ti oruko re n je Orunmila,oruko iyawo re ni Idi. Irepo    to dan moran ko si  laarin won,nitori naa, Idi fe ko oko re sile sugbon Orunmila ko fi aaye sile fun-un,nitori gbogbo ibi ti o n lo,oun pelu Idi ni. Bi ija ba sele laarin won ,iyawo yoo maa hale mo oko re pe oun maa ku si i lorun,oko re naa asi so fun-un pe ti o ba ku,oun maa gbe oku re so sinu igbo ni.

Se Idi ti n wa orisiirisii ona lati ko Orunmila sile,nigba ti o di ojo kan, ero kan wa si i lokan pe bi oun ba dibon pe oun ku,ti won si gbe oun sinu igbo,ki okunrin miiran ti oun fe few a gbe oun kuro nibe leyin ti awon ti to gbe sonu ba ti pada si aarin ilu,bayii ni o ba okunrin naa di     awo po.

Kop e ko jinna ni ija nla kan sele laarin Orunmila ati Idi. Were ,Idi ti subu lule to si se bi to ku. Leyin eyi ni awon ara ile ati ara adugbo gbiyanju lati ji i ,ti ko si se e se ,ni won bag be oku re sonu sinu igbo,okunrin ti o fe ti lo fi ara re pamo sinu igbo naa, ki oba le mo ogangan ibi ti won yoo ju oku re si.

Bi won ti gbe oku re sonu tan,ti awon togbe e wa pada si le ni okunrin ti Idi fe fe ba lo ba a nibi ti won ju oku re si,o tu gbogbo ohun ti won fi di i kuro lara re. awon mejeeji si  lo si Ejigbo lati maa gbe gege bi oko ati aya: Se won ko tun le pada wo ilu ti won n gbe tele nitori pe awon eeyan yoo tun maa ri i , bee ko si eni to tun le maa ba oku gbele .

Nigba ti won de Ejigbo,oko titun ti Idi fe  bere si ni da oko ila ati ikan.Iyawo re a si maa gbe e lo si oja Ejigbo lo ta. Ni gba ti o di ojo kan ,okunrin kan lati lati ilu Orunmila wa si oja Ejigbo lati ko ila, odo Idi taara ni o lo laimo pe oun ni, o bere si ni wo idi laimo pe oun ni,bi Idi ti n fi oju pamo bee ni okunrin naa tubo n ww o si I,nigba ti ara Idi ko gba a mo ,lo ba fi ibinu soro pe

Bo o kola, kola

Bo o gbeni, o gbeni

Ewo laboro woju oloja,loja Ejigbo

A i i wo o

Oju oku lo n wo

Nigba naa ni okunrin naa mo daju pe Idi ni oun ri, nigba ti o de ilu Orunmila o ro gbogbo ohun ti o ri fun Orunmila,Orunmila ranse lo si Ejigbo lati lo mu Idi wale; sugbon ki won to de ibe Idi ati oko re ti kuro nibe.Lati igba naa lo ti di asa pe ki awon eniyan maasin eni ti o ba ku dipo ki won maa gbe e sonu sinu igbo.

Idi abajo keji nipe ko si eni to ri oku to ti ku ni ojukoju

 

 

 

 

IGBELEWON

  1. Ona meloo ni onka Yoruba pin si
  2. Kin ni a fi n da okookan mo. Salaye re pelu apeere

ISE ASETILEWA

  1. Iro ______________________ni a fi n da pupo ninu awon onkaye mo

(a)        n                      (b)        m                     (d)        t

  1. Iro __________________________ni a fi n da onkapo mo

(a)        I                       (b)        m                     (d)        n

  1. Orinlenirinwo je ____________________________________

(a)        440                  (b)        480                  (d)        490

  1. Egbaa je ___________________________

(a)        2000                (b)        200                  (d)        20,000

 

  1. 14,000 je (a)        ogoje                (b)        egbaaje            (d)        irinwo

APA KEJI

  1. Ona meloo ni onka Yoruba pin si?
  2. Kin ni a fi n da won mo.
  3. Daruko orisii ona ti awon Yoruba n gba lati se itoju oyun laye atijo.
  4. salaye lekun-un-rere,idi ti awon Yoruba fi n sin oku.

 

 

 

 

OSE KESAN-AN

Ori-oro-; Aroko oniroyin

Akoonu:

Aroko oniroyin:- je mo iroyin sise tabi itan isle ti o ti koja seyin ti o si se oju eni ti a n royin re ni sise-n-tele ninu aroko oniroyin fun elomiran ti ko si nibe. A rii wi pe o fi ara pe aroko asapejuwe.

Ki a to le se iroyin yori, a gbodo je eni ti o ni ife si gbigbo tabi kika iwe itan kekere.

Eyi ni apeere ori-or, to je mo aroko oniroyin.

Iroyin ipade maje – o – baje kan ti mo lo.

Ayeye odun eyo ni ilu eko

Ojo buruku, esu gbomi mu.

Ipolongo eto idibo ti o koja

Bi mo se lo isinmi mi ti o koja

Isomoloruko kan ti won se ni odede wa laipe yii.

Igbelewon.

Ko aroko lori

Isomoloruko kan ti won se ni adugbo wa laipe yi.

ASA

ORI-ORO-;orisiirisii oruko ti a le so omo ni ile Yoruba

Akoonu

Oruko se Pataki ni ile Yoruba, awon Yoruba kii sii deede fun omo ni oruko, awon oruko Yoruba maa n ni itumo. Idi niyi ti awon agba fi maa n se akiyesi ipo ti omo ba gba waye, Ipo ti ebi wa, esin idile baba ki won to fun omo ni oruko, Yoruba ni ile laawo ki a to so omo ni oruko.

Eyi ni orisii oruko ti a ni ni ile Yoruba.

  1. Oruko amutorunwa
  2. Oruko abiku

iii. Oruko Inagije

  1. Oruko abiso

Oruko amutorunwa:- ni oruko ti a fun omo nipa sise akiyesi ona ara ti o gba wa si aye tabi isesi re nigba ti a bii.

Ap

Oruko amutorunwa:-

Ige                                           Omo ti o mu ese waye

Aina                                         Omobinrin ti o gbe ibi korun.

Ojo                                          Omokunrin ti o gbe ibi korun.

Oke                                          Omo ti o di ara re sinu apo ibi wa si aye epo tutu ni won maa

n ta si ara apo naa, ki o to le tu.

Oke                                          Omo ti o maa n daku ti won ba n fun ni ounje ni idubule.

Dada                                        Omo ti irun ori re ta koko.

Ilori                                          Omo ti iya re ko se nnkan osu ti o fi loyun

Oni                                          Omo ti won bi sile to n kigbe laisinmi

Babarinsa                                 Omo ti baba re ku ni kete ti won bii.

Abiona

Oruko abiku: Oruko ti a fun  omo ti o maa n ku, ti a sit un pada wa saye.

Won maa n fun won ni oruko bii ebe tabi epe ki won le duro.ap

Oruko                                      Itumo

Durojaye          –           Ki o duro ni ile aye je igbadun

Rotimi              –           Duro ti mi, ma se fi mi sile.

Malomo           –           Duro si aye, ma pada si orun mo

Kosoko            –           Ko si oko ti a o fi sin oku re mo

Kasimaawoo    –           Ki a si maa wo boya yoo tun ku tabi ye.

Bamitale          –           Duro ti mi di ojo ale

Aja                   –           Iwo ko ye ni eni ti a le fun ni oruko eniyan mo afi aja.

 

Oruko Inagije:- oruko atowoda ti a fi eniyan tabi ti eeyan fun ara re lati fi se aponle tabi apejuwe irisi tabi iwa re ap.

Eyinafe: Eni tie yin re funfun ti o si gbafe.

Ajisafe: Eni to feran afe ni owuro ti gbogbo eeyan ba n sise

Peleyeju: Eni to ko ila pele, ti ila oju naa si ye e gan-an.

Oginni: Eni ti o maa n roar n tele ginniginni.

 

Oruko abiso: eyi ni awon oruko ti o n tokasi ipo idile tabi obi omo saaju tabi asiko ti a bii.

Apeere oruko to n tokasi ipo tabi esin idile.

 

Ipo                                                                   Oruko abiso

Oba – A                                                           Adebisi, Adegorite, Adegoroye, Adesoji, Adegbite, Adeyefa.

 

Eleegun                                                            Ojewunmi, Ojeniyi, Eegunjo bi

 

Jagunjagun                                                       Akintola, Akinkunmi, Akindele

 

Onisona                                                           Onajide, Olonade

 

Elesin Ifa                                                         Fayemi, Faleye, Awobiyi, Awotunde

 

Onisango                                                         Sangobunmi, Sangodele

 

Orisa Oko/Idobatala                                         Efunjoke, Opakunle, Soyinka.

 

Orisa Ogun                                                      Ogunyemi, Ogunbiyi, Odetola.

 

Oruko to n tokasi ipo obi saaju tabi ni akoko ti won bii.

 

Oruko                                                              Itumo

Ekundayo                                                        Ibanuje ati ekun ti o wa ninu ebi di ayo.

 

Olabode                                                           Ola to ti lo ninu ebi tun ti pada de.

 

Tokunbo                                                          Omo ti won bi si Ilu oyinbo tabi ile okeere ti won gbe wa ile.

 

Igbelewon

  1. Kin ni Oruko?
  2. Daruko orisii oruko ti o wa.

IWE AKATILEWA

Imo,Ede ASA Ati Litireso.Adewoyin S.Y o.i 298-301.

ISE ASETILEWA

1.Ojo ——- ni won maa n fun omokunrin ni oruko laye atijo

2.Omo ti a bi ti o mu ese waye ni

(a)Amu-ese-wa  (b) Ige    (d)   Dada

3.——- ni o n bi iku ati arun danu

(a)   obi   (b) ata  (d) abikudanu/

  1. Efunyela je oruko ti o je mo orisa ———–

(a) Esu    (b) Orisa oko     (d)  Ogun

  1. Omo ti o maa n daku ti won ba n ro o ni ounje ni ibule ni ———

(a) Oke  (b)  Oke   (d)  Abiona.

APA KEJI

  1. Daruko orisii oruko marun-un,pelu apeere merinmerin fun ikookan.
  2. Ko aroko lori odun keresimesi ti o koja.

OSE KEWAA

ORI-ORO-;ISORI ORO-ORUKO

AKOONU

– oriki

– orisiirisii oro oruko.

– ise ti oro oruko n se ninu gbolohun.

– lilo oro oruko ninu gbolohun.

Oro –oruko ni awon oro ti won le da duro nipo oluwa,abo tabi eyan ninu gbolohun.AP.

Baba ko ebe.

Tolu fo aso.

Mama se isu ewura.

EYA ORO ORUKO.

  1. ORUKO ENIYAN : -Oro oruko le je oruko eniyan,eyi ni oruko ti o n toka si ohun ti o je eniyan.Ap

-Rotimi

– Dele

-Ahmed

– Dokita

– Iyalaje…abbl

  1. ORO-ORUKO ALAISEEYAN: -Eyi ni oruko to n toka si awon nnkan ti kii se eniyan AP.okuta,iwe, ewure,omi,iyanrin,bata abbl.
  2. Oro-oruko le je ohun elemi : – Eyi je oruko nnkan ti won ni emi bii eniyan tabi eranko.apaja,eniyan,esin,maalu,alangba,okunrin.abbl.
  3. Oro-oruko le je ohun alailemii: – Eyi ni awon nkan ti ko ni emi.ap iwe,ile,bata,ewe,igi,abbl.
  4. Oro-oruko le je ohun aridimu : – Eyi ni awon ohun ti a le fi oju ri tabi fi owo kan.apewa,eja,isu,tabili,sokoto,aga,ewedu,abbl.
  5. Oro-oruko le je oruko ibikan :- Eyi ni awon oro oruko ti a le fi ibo se ibeere won.Ap ibo lo n lo? Osodi,Meka,Soosi.
  6. Oro-oruko le je ohun afoyemo : – Eyi ni awon ohun ti a ko le fojuri sugbon ti a le mo nip aero opolo.Ap ogbon,ilera,ero,ife,alaafia,igbadun,wahala,imo.
  7. Oro-oruko le je aseeka : – Eyi ni o n toka si ohun ti a le ka Ap. Ile,ilu,eniyan,iwe,tatapupu.
  8. Oro-oruko le je alaiseeka : – Eyi ni o n tokasi awon ohun ti koseeka Ap Iyanrin,epo,omi,afefe,gaari,irun.
  9. Oro-oruko le je oruko igba : – Eyi ni oro ti a le lo lati toka si igba ti nnkan sele han.Ap Aaro,ana,odun,irole,oni,ola,ijeta.

ISE TI ORO-ORUKO N SE NINU GBOLOHUN.

Ona meta Pataki ni a le gba lo oro-oruko ninu gbolohun,o le sise:

i.Oluwa,

  1. abo

iii. eyan.

OLUWA;ni eni tabi ohun ti o se nnkan ninu gbolohun.ap Baba ko ebe.

Bola fo aso.

ABO;ni eni tabi ohun ti a se nnkan si,ap

Mama se obe

Bolu ko leta.

EYAN;ni o maa n se afikun itunmo fun oro-orukoap

Mama se obe eja yiyan.

 

 

 

Bola se isu ewura.

Ona miran ti a tun le gba da oro oruko mo ni pe

Oro-oruko maa n gba oro aropo bii eyan,ap

‘oro yin ni a sese so tan yii.’

‘ile re ni mo n lo.’

Oro-oruko le se e lo fun sise akiyesi alatenumo ti a ba gbe saaju wunren ‘ni’ap

‘iwe ni mo ra.’

Rira ni mo ra iwe yii.

 

ASA

IPOLOWO OJA

AKOONU

Ipolowo oja-;je ona ti a n gba lati ke gbajare oja ti a n ta si etigbo awon eniyan lati le ba won ra a.

Ona meji ni a n gba se ipolowo oja,awon naa ni

i.ipolowo oja abinibi

  1. ipolowo oja ode-oni.

Ipolowo oja abinibi-;je ona ti a n gba polowo oja ni aye atijo,awon naa ni;ipate,ikiri.

Ipolowo oja ode-oni-; je ona ti a n gba polowo oja ni ode-oni,lati le je ki oja ti a n ta ya,apeere ipolowo oja ti ode-oni ni; ipolowo lori telifisan,redio,iwe iroyin,fidio ati inu magasinni.

IWULO/PATAKI IPOLOWO OJA

Gege bi a se mo pe ipolowo ni agunmu owo,opolopo anfaani ni o wa ninu ipolowo oja ti anfaani re ko si se e fi owo ro seyin.

  1.         Ipolowo oja maa n je ki oja ta.
  2. O maa n je ki awon eeyan mo nipa oja titun to sese n jade.

iii.   O maa n je ki ohun ti a fe ra wa ni arowoto wa.

.iv.O maa n je ki awon eeyan mo ibi ti won ti le ri oja ti won fe ra.

ORISII  OJA TI A N POLOWO

ONA TI A N GBA SE IPOLOWO

O fere  je pe gbogbo oja ti a ni ni a maa n polowo,eyi ni die lara awon oja ti a maa n polowo.

OJA                                                           IPOLOWO

Efo                                                               E  refo e sebe.

Gaari                                                 gaari,olooyo,ayangbe gaari o

Ata                                                    E rata e sebe o

Iresi                                                  ofe niresi eran lowo

Epo                                                              E repo e sebe.

Iru                                                  E raru e sebe.

Orisii ogbon ni awon oloja maa n da lati polowo oja won,ki awon eeyan le ba won ra a,ara awon ogbon naa ni

  1. Itowo-;Eyi ni pe won a fun onibara ni die ninu oja ti won n ta pe ki o to o wo bi o se ri lenu ap gaari.
  • Isiwo-; Eyi ni pe won a ti ni kekere kan ninu oja yen ti won a maa fi han onibara lati wo o bi o se ri ap eko.
  1. Awin-; Awon oloja maa n ta oja awin fun awon onibarawon lati fi fa oju won mora.

Orisiirisii ede aponle ni awon oloja maa n lo lati fa oju awon onibara won mora,fun apeere “e woju obe e muyan.

Igbelewon

  1. Daruko awon oja ti a maa n polowo.
  2. se ipolowo merin ninu won.
  3. Daruko isori oro-oruko marun-un pelu apeere metameta fun ikookan..

Iwe Akatilewa

Iwe imodotun Yoruba fun olodun kin-in-ni o.i 93, 98.

ISE ASETILEWA

1.———-  ni agunmu owo

(a)  itowo  (b)  ipolowo    (d) ikiri

  1. ——- je okan lara ogbon ti awon oloja maa n lolati ta oja won.

(a) ipate    (b) itowo   (d)  eebu.

3.Okan lara ona ti a n gba se ipolowo oja lode oni ni

(a) ikiri (b) itowo (d)  redio

  1. Mama se eja tutu. Eyan ti o wa ninu gbolohun yii ni

(a)mama   (b)   eja    (d)  tutu.

  1. Orisii ise ——- ni oro-oruko maa n se ninu gbolohun.

(a) kan    (b)  meji     (d)   meta.

APA     KEJI

1,Kin ni ipolowo  oja?

b.Daruko orisii oja marun-un ti a maa n polowo,ki o si polowo won.

  1. Salaye ise ti oro-oruko n se ninu gbolohun,pelu apeere metameta fun ikookan.

 

 

 

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share