ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KETA ISE-:EDE YORUBA                 S.S.S.2

Table of Contents

 

ISE-:EDE YORUBA                                                                             CLASS: S.S.S.2

ILANA ISE OSOOSE FUN SAA KETA

Ose:

  1. EDE: Aroko ti o je mo isipaya.

ASA:   EkoIle

LIT:     Itupale Asayan iwe litireso ti ijoba yan. WAEC/NECO.

  1. EDE: Silebu Ede Yoruba.

ASA:   Isse abinibi. Ise Agbe.

LIT: Itesiwaju lori  Asayan iwe litireso ti ijoba yan. Eda Itan. Ibudo Itan.

  1. EDE: Aroko Onisorogbesi

ASA:   Ona Ibaranisoro.

LIT:     Itupale Iwe Litireso.

  1. EDE: Ihun Oro. Iseda Oro Oruko.

ASA:   Itesiwaju eko lori ona Ibaranisoro.

LIT:     Sise atupale asayan iwwe ti Ijoba yan.

  1. EDE: Onka Yoruba.

ASA:   Awon orisa Ile Yoruba. Ogun, Obatala ati Esu.

LIT:     Kika awon iwe asayan ti ijoba yan.

  1. EDE: Onka Yoruba.

ASA:   Awon orisa ile yoruba ati bi a se n bo won. Orunmila ati Sango. Oriki won.

LIT:     Kika awon iwe asayan ti ijoba yan.

  1. EDE: Atunyewo awon eya ara ifo.

ASA:   Awon Orisa ati bi a ti n bo won. Awon orisa miiran ni agbegbe akekoo. Ipo

won orisa ni ile Yoruba.

LIT:     Kika awon iwe asayan ti ijoba yan.

  1. EDE: awon iro ninu ede Yoruba.

ASA:   Ero ati igbagbo awon Yoruba lori Oso ati Aje.

LIT:     Kika awon iwe asayan ti ijoba yan.

  1. EDE: Atunyewo iro Konsonanti ati iro faweli lo kookan.

ASA:   Ero ati igbagbo awon Yoruba akudaaya ati abami eda.

LIT:     Kika awon iwe asayan ti ijoba yan.

  1. EDE: Atunyewo eko lori ami ohun.

ASA:   Igbagbo awon yoruba nipa Ori ati eledaa.

LIT:     Kika awon iwe asayan ti ijoba yan.

  1. & 12 EDE: Idanwo ati ipari saa keta lori Ede, Asa ati Litireso.

IWE  ITOKASI

  1. Imo, Ede, Asa Ati Litireso. S.Y Adewoyin
  2. Eto Iro ati Girama fun Sekondiri Agba. Folarin Olatubosun.
  3. Akojopo Alo Apagbe: Amoo A. (WAEC).
  4. Oriki Orile Metadinlogbon: Babalola, A (WAEC).
  5. Iremoje Ere Isipa Ode: Ajuwon B. (WAEC).
  6. Igbeyin Lalayonta: Ajewole O. (WAEC).
  7. Iya Atata: Fadiya, O. (WAEC).
  8. Ore Mi: Aderibigbe, M. (WAEC).
  9. Egun Ori Ikunle: Lasunkanmi Tela. (NECO).
  10. Omo Ti A Fise Wo: Ojukorola Oluwadamilare. (NECO).
  11. Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).

 

 

OSE KIN-IN-NI

 

AROKO AJEMO ISIPAYA

Aroko ajemo isipaya je aroko ti o gba sise alaye kikun nipa nnkan ayika eni. Bi apeere aroko alaye ekunrere lori bi won se n se ounjeti a feran julo yato si pa ki a se apejuwe re. Apeere aroko ajemo-isipaya ni:

  1. Ise Tisa
  2. Oge Seise.
  • Aso Ebi
  1. Ise ti mo fe lojo iwaju.

Ki a to le ko akoyawo lori okookan ori-oro wonyi, a gbodo ni arojnle ohun ti won je, itumo ati itumo won miiran to farasin tabi ohun ti o ni abuda won. A nila ti wo anfaani ati aleebu ki a si fi arojinle ero gbe won kale.

 

IGBELEWON: ko aroko lori Oge sise tabi omi.

 

Iwe Akatilewa:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 155-156.

 

EKO ILE

Eko ile Yoruba, awon eko ti awon obi maa n ko omo lati kekere ni a n pe ni eko-ile. Yoruba ni ‘ni ile lati ko eso rode’. Awon eko bee ni ikini, imototo, isora, iwa ti o to si obi, agbalagba, alejo ati alagbe eni. Omo ti won ko to si gba, ti o sin mu eko naa lo nigba gbogbo ni a n pe ni omoluabi. ‘omo-olu-iwa-bi. Olu iwa ni eni ti o je orison gbogbo iwa rere. Abuda omoluabi ni =w=, iteriba, ise sise, oninuure, onisuuru, eni ti ko huwa abosi tabi ireje si eni keji. ABIIKO ati AKOOGBA.

IGBELEWON:

  1. Ta ni oluko eko ile.
  2. Ko abuda omoluabi marun-un miiran.
  3. Salaye abiiko ati akoogba.
  4. Pa owe merin ti o je mo eko ile.

 

Iwe Akatilewa::

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 129-135.

 

ATUPALE IWE ASAYAN

 

Atupale iwe asayan ti ijoba yan.

 

APAPO IGBELEWON:

  1. ko aroko lori Oge sise tabi omi.
  2. Ta ni oluko eko ile.
  3. Ko abuda omoluabi marun-un miiran.
  4. Salaye abiiko ati akoogba.
  5. Pa owe merin ti o je mo eko ile.

 

ISE ASETILEWA

  1. Aroko ti o je mo isipaya ni (a) ile iwe mi (b) baba mi (c) ilu Ibadan (d) eran osin.
  2. Ewo ni ki i se ara won? (a) ise tisa (b) ojo ti n ko le gbagbe (c) obe egusi (d) omi.
  3. Awon ti o koko maa n ko omo ni eko ile ni (a) egbon eni (b) iya (c) iya ati baba (d) ara adugbo.
  4. ‘owu ti iya gbon ni omo yoo ran’ owe yii tumo si wi pe (a) ise ti baba ba se ku ni omo maa se (b) ise ti iya ba se ku ni omo maa se (c) iwa omo maa n jo ti iya re (d) omo maa n ran aso iya re.
  5. Eda ita ni (a) awon onkorin (b) osere (c) awon ti won kopa ninu iwe ati ere (d) awon ti o ko itan.

 

APA KEJI

  1. Ko aroko lori iyan
  2. Ko iwa omoluabi merin sile
  3. Salaye akanlo-ede ayaworan merin.

 

OSE KEJI

ORI-ORO-;SILEBU EDE YORUBA

Oriki.

Ihun silebu.

AKOONU:- Silebu ni ege oro ti o kere julo ti eemi le gbe jade leekan soso

Iye ohun ti o ba wa ninu oro ni iya silebu ti oro naa yoo ni.

Fun Apeere

Wa-je oro onisilebu kan nitori pe ami ohun kan ni o wa lori re.

I / we = 2

Ba / ta = 2

Ihun silebu:-

Ona meta Pataki ni ihun silebu pin si awon naa ni:-

  1. Ihun faweli kansoso
  2. Ihun to je konsonanti ati faweeli.
  3. Ihun to je konsonanti aranmupe-asesilebu.

 

 

  1. IHUN FAWEELI KAN SOSO

Eyi ni ihun to je faweeli kan soso ‘f’ ni a maa n lo fun ihun yii..fun apeere

I / we

A /a / lo

 

  1. IHUN TO JE APAPO KONSONANTI ATI FAWEELI:-

Eyi ni ihun ti o je konsonanti ati faweeli,faweeli yii le je aranmupe tabi airanmupe. ‘KF’ni a n lo fun ihun yii.fun apeere

Je

Kf

 

Wa                   gbin

Kf                     kf

 

Ra                    sun

Kf                    kf

 

iii.IHUN TO JE KONSONANTI ARANMUPE ASESILEBU:-

Eyi ni ihun silebu ti konsonanti aranmupe ‘n’ ati ‘m’ maa n dun gege bi silebu.

‘N’ ni a maa n lo fun ihun yii.

Fun apeere

Gba /n /gba =3

Ke / n /gbe =3

A / la /  n / gba =4

Bi /m / bo.

Kf-N-kf

 

 

Oro olopo silebu-;eyi ni oro ti o ni ju silebu kan lo,o le je silebu meji,meta tabi ju bee lo.

ap

Oro                        ipin                         ihun                                  iye

Ade                       a-de                         f-kf                                  meji

Sugbon                  su-gbon                   kf-kf                                            meji

Nnkan                   n-n-kan                    f-f-kf                               meta

Opolopo                o-po-lo-po               f-kf-kf-kf                         merin

Ogunmodede         o-gun-mo-de-de      f-kf-kf-kf-kf                    marun-un

Alapandede           a-la-pa-n-de-de       f-kf-kf-N- kf-kf              mefa

 

IGBELEWON

  1. kin ni silebu?
  1. Daruko ihun silebu, ki o si salaye won pelu apeere.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 53-57

 

ISE ABINIBI

Eni ise ni oogun ise

Eni ise n se ko ma b’Osun

Oran ko kan t’Osun

I baa b’Orisa

O dijo to sise aje ko to jeun.

Owuro lojo, ise ni a fii se ni Otuu’Fe. Kaakiri ile Yoruba ni won ti n fi owuro sise. Won gbagbo wi pe ise loogun ise. Eredi ti won fi ise won ni okunkundun ni yii. Se eni mu ise je ko sai ni ise je. Eni ni ko feran ise ni won n pe ni ole. Won a maa ni ole afajo. Ojo odun de ni oro n dun ole tori gbogbo egbe re ni o raso sugbon oun ko le ra. Lara ise abinibi ile yoruba ni: ise agbe ‘eyi to wopo ju laarin ise abinibi’ ode, awako oju omi, babalawo ……..

 

ORISII ISE AGBE

Agbe olokonla

Agbe alaroje

 

ORISII OKO

Oko akuro

Oko etile

Oko egan

Oko odan

 

OHUN ELO ISE AGBE

Oko, Ada, apere, …………..

 

IGBELEWON

Salaye ogbin ati ikore agbado.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 136-150.

ATUPALE IWE ASAYAN

 

Atupale iwe asayan ti ijoba yan.

 

Salaye eda itan marun-un ninu iwe apileko

 

ISE ASETILEWA

  1. ohun ti o kere ju ti eemi le gbe jade leekan soso ni (A) akoto (B) oro (C) faweli (D) silebu.
  2. Silebu meloo ni o wa ninu ‘’olopaa’ (A) meji (B) meta (C) merin (D) mejo
  3. Ninu ‘iwe’ odo silebu ni (A) i (B) w (C) e (D) ko si odo silebu nibe.
  4. Ibi ti awon agbe maa n gbin nnkan si ni (A) oko (B) ile (C) oko (D) papa
  5. Awon agbe maa n lo ……. lati ka koko (A) oko (B) ibon (C) obe (D) ada.

APA KEJI

  1. Salaye odo silebu ati apaala silebu pelu apeere mejimeji.
  2. Fun awon wonyi ni apeere mejimeji: KFKF, KFKFKF, KFNKF, FKF, FKFKF
  3. Salaye lori ohun ogbin kan.

 

OSE KETA

 

AYOKA ONISOROGBESI

Ka ayoka isale yii,ki o si dahun ibeere ti o tele e

Ayo;               O da a,aanu re lo se mi

O mo on so, o dun lete re bi oyin

N o gba o si  egbe wa.

Baba Ramo     Haa! E seun o. Mo dupe o.

Ayo                 Sugbon owo iwegbe re n ko-

Poun  meedogun

Baba Ramo      Howu! Mo te patapata nu-un

Onini sagba mi lonii…….. sugbon mo be yin e gba mi.

Ayo                   Oro re ti e tu mi lara.

N o saanu re, a o gbowo fun o

Sugbon baa ba ti gbowo fun o.

Niwo naa o yara gbe nnkan fun wa

O domo egbe nu-un.

Baba Ramo       Ki le fe ki n gbe fun yin?

Ki le wi pe ki n gbe wa ti n ko nii gbe wa?

Ayo                   Apo marun-un la o gbe fun o.

Baba Ramo        Haaa ! kin ni n toju wa?

Ayo                    A o ni igbowo ohun fun o nisinsinyi

O digba too ba mu nnkan ta a wi wa.

Baba Ramo         Ko buru. Kin ni n toju wa?

Ayo                     Kii se nnkan pataki

Sugbon ,ohun ti o le won die ni

O o dolowo, o o tun tosi mo laelae

Bo o ba le fun wa ni wundia ti ko tii wole oko.

Baba Ramo         Ha !Eni to bimo nii romo gbe jo

Eniyan ti o bimo, ko le ri gbe pon

Bi o somo langidi?

N o bimo ! Tabi n o ti se e bayii?

Ayo                      Tulaasi ko

Ko sitiju; ko sowo

Bowo o ba te wundia ti o ti i rele oko.

Baba Ramo          Wundia? Haa  Hun-un

Gbogbo ara ile-yin nko?,nibo ni won lo?

Owo olowo,owo eni

Kedumare  o ma jee ka fe kan ku l’apo wa.

 

IGBELEWON

  1. Nnkan ninu ayoka yii n toka si?
  2. Kin ni baba Ramo wa de inu egbe yii?
  3. Kin ni idi ti baba Ramo fi so pe oun te?
  4. Kin ni yoo sele ti baba Ramo ba ri ohun ti won ni ko mu wa wa?
  5. Eelo ni Ayo seleri lati fun baba Ramo?
  6. Kin ni Ayo n reti lati odo baba Ramo?
  7. Nigba ti Ayo beere nnkan lodo baba Ramo kin ni o so?
  8. Salaye idi ope baba Ramo ninu ayoka yii.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 58-62.

 

ONA IBANISORO AYE ATIJO.

Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekyeke. Ona yii ni a n pe ni ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Awon ona ti a n gba ba ara eni soro ni

  1. Lilo Eya Ara fun Ibanisoro: oju, ori, imu, enu, ejika, ese, eekanna, owo, ete.
  2. Iparoko: (i) ilu lilu (ii) edan ogboni (iii) opa ase, (iv) owo eyo (v) awo edan (vi) irukere (vii) sigidi (viii)iye adie (ix) ebiti ati awo ehoro (x) owo-eyo meta (xi) aso ibora (xii) igbale (xiii) eepo igi ose ati aso pupa (xiv) idaji agbe emu tabi ajadi agbon.

 

IGBELEWON

Salaye ona mewaa ti awon Yoruba n gba ba ara won soro.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. O.I 58-62.

 

 

ATUPALE IWE ASAYAN

Atupale iwe asayan ti ijoba yan.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Salaye itumo aroko onisorogbesi
  2. Ko eya ara mefa ti a fi n ba eeyan soro marun-un pelu alaye.
  3. Se itupale ori keta ati ekerin ninu iwe ti o n ka.

 

ISE ASETILEWA

  1. Lara abuda aroko onisorogbesi ni (A) o maa n ni akopa bi ere inu itage (B) o maa n dun (C) ki i ni ipari (D) oro pupo maa n wa nibe.
  2. Itumo ki won fi aso ibora eni ranse si eniyan ni ki eni naa (A) wa sun nile (B) maa sun ita (C) maa sun eyin (D) maa gbe ni eyin, pe won ti ko o.
  3. Eni ti o maa n fi opa ase paroko ni (A) ijoye (B) olori ebi (C) oba (D) igba keji oba.
  4. Itumo ki won fi irukere ranse si eniyan ni wi pe (A) ki onitohun maa bo (B) oba n pe e (C) eni naa ni oye oba kan (D) won juba eni ti won fi irukere ranse si.
  5. Onka ‘eefa’ tumo si (A) ife (B) ifa (C) ki eni naa ma fa wahala (D) ifaseyin.

 

APA KEJI

  1. Salaye itumo aroko onisorogbesi.
  2. Ko ona ibanisoro marun-un pelu apeere.
  3. Salaye lori ori keta iwe apileko ti o ka. (A) (B) (C) (D)

 

OSE KERIN

ISEDA ORO-ORUKO

AKOONU

Oriki

Orisii Ona ti a n gba Seda Oro-Oruko

 

Iseda Oro-Oruko je siseda oro-oruko lati ara oro-oruko tabi oro-ise nipa afomo lilo. Bi  a ba fe seda oro oruko, eyi ni awon igbese ti a ni lati tele.

  1. Nipa lilo Afomo Ibere

Nipa lilo Afomo Aarin

Nipa sise Apetunpe kikun

Nipa sise Apetunpe Elebe

Nipa sise Akanpo Oro-Oruko

Nipa sise Isunki odidi Gbolohun.

 

  1. Lilo Afomo Ibere

A le lo afomo ibere pelu oro-ise lati seda oro-oruko.  Iru Oro-Oruko bayii gbodo ni ajose pelu oro ise ti a lo pelu afomo.  Awon afomo ibere naa ni: a, e, e, i o o u, alai, ai, o ni, oni abbl. Apeere

a          +          yo        =          ayo

a          +          lo         =          alo

a          +          to         =          ato

o          +          ku        =          oku

o          +          bi         =          obi

i           +          to         =          ito

i           +          fe         =          ife

e          +          gbe      =          egbe

e          +          to         =          eto

e          +          te         =          ete

e          +          ko        =          eko

o          +          le         =          ole

o          +          mu       =          omu

i           +          rin       =          irin

ai         +          sun      =          aisun

ai         +          ni         =          aini

ati        +          lo         =          atilo

ati        +          je         =          atije

on        +          te         =          onte

alai      +          gbon   =          alaigbon

alai      +          mo       =          alaimo

oni      +          igi        =          onigi

oni      +          omo    =          olomo

 

  1. A le lo afomo ibere pelu apola-ise eyi ni pe oro-ise ati oro-oruko

Apeere

 

a          +          ko        +          orin     =          akorin

a          +          ko        +          ope      =          akope

a          +          da        +          ejo       =          adajo

o          +          da        +          oran    =          odaran

ati        +          de        +          ade      =          atidade

o          +          se        +          ere       =          osere

o          +          da        +          oju      =          odaju

ai         +          gbon   +          oran    =          odaran.

alai      +          mo       =          alaimo

oni      +          igi        =          onigi

oni      +          omo    =          olomo

 

  1. A le lo afomo ibere pelu apola-ise eyi ni pe oro-ise ati oro-oruko

Apeere

 

a          +          ko        +          orin     =          akorin

a          +          ko        +          ope      =          akope

a          +          da        +          ejo       =          adajo

o          +          da        +          oran    =          odaran

ati        +          de        +          ade      =          atidade

o          +          se        +          ere       =          osere

o          +          da        +          oju      =          odaju

o          +          bi         =          obi

i           +          to         =          ito

i           +          fe         =          ife

e          +          gbe      =          egbe

e          +          to         =          eto

e          +          te         =          ete

e          +          ko        =          eko

o          +          le         =          ole

o          +          mu       =          omu

i           +          rin       =          irin

ai         +          sun      =          aisun

ai         +          ni         =          aini

ati        +          lo         =          atilo

ati        +          je         =          atije

on        +          te         =          onte

alai      +          gbon   =          alaigbon

alai      +          mo       =          alaimo

oni      +          igi        =          onigi

oni      +          omo    =          olomo

 

  1. A le lo afomo ibere pelu apola-ise eyi ni pe oro-ise ati oro-oruko

Apeere

 

a          +          ko        +          orin     =          akorin

a          +          ko        +          ope      =          akope

a          +          da        +          ejo       =          adajo

o          +          da        +          oran    =          odaran

ati        +          de        +          ade      =          atidade

o          +          se        +          ere       =          osere

o          +          da        +          oju      =          odaju

 

 

 

 

ORO-ORUKO NI ILANA APETUNPE

 

AKOONU

A le seda oro-oruko nipa sise apetunpe. Apetunpe yii pin si ona meji: eyi ni apetunpe kikun ati elebe.  A le se Apetunpe Kikun fun Oro-Oruko

Apeere:

Kobo  +          kobo   =          kobokobo

Odun  +          odun   =          odoodun

Ale      +          ale       =          alaale

Osu     +          osu      =          osoosu

Osan   +          osan    =          osoosan

Egbe   +          egbe    =          egbeegbe

 

A le se Apetunpe Kikun fun Oro-Ise alakopo mo oro-oruko

Apeere:

Wole               +          wole                =          wolewole

Gbomo           +          gbomo            =          gbomogbomo

Jedo                +          jedo                =          jedojedo

Dana               +          dana                =          danadana

 

Apetunpe Elebe

Nipa sise apetunpe elebe fun oro ise pelu oro-oruko.  A o se apetunpe fun konsonanti oro-ise ki a to fi faweli kun un. Apeere

Je                    =          jije

Lo                   =          lilo

Ra                   =          rira

Ko orin           =          kikorin

Se eda             =          S + i + se eda

So ooto           =          s + i + sooto

Sugbon bi konsonanti aranmu m/n ba pari oro-ise naa, faweli aranmu ‘in’ olohun oke ni o a fi kun apetunpe

Mo   –  m + in + mo  =          mimo

Mu   – m + in + mu   =          mimu

Ni –  n + i + ni                       =          nini

Na  = n + I + na         =          nina

Na omo = n + in + omo       ninamo

 

Apetunpe onka

Meta + meta              =          metameta

Nipa sise akanpo oro-oruko

 

IGBELEWON

  1. Daruko awon ona ti a n gba seda seda oro-oruko pelu apeere marun-unmarun-un.
  2. Ge awon oro wonyi si mofiimu: omokomo, iyaale, ijekuje, isekuse, Durotimi, Olorun, Iyeegbe, Ileese, Kabiyesi, agbalagba, Opolopo.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba J.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd.

 

ONA IBANISORO ODE ONI

Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye ti a fi n salaye ohunkohun. Ohun ni a fi n ba ni kedun. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:

  1. Iwe Iroyin: IweIroyin fun awon Egba 1859, Iwe iroyin Eko A.M Thomas 1888, Iwe Eko Vernal J. 1891.
  2. Telifisan: eyi awon Yoruba n pe ni Ero-Amohun-Maworan. Anfaani gbigbo oro ati wiwo aworan maa n wa nibe.
  3. Redio: Yoruba a ma ape e ni Ero-Asromagbesi sugbon ni aye ode oni o ti n gba esi.
  4. Pako alarimole ni Egbe Titi tabi Adari Ina Oko: eyi ni won maa n ko apejuwe ona ibi kan si. Adari ina oko ni o maa n dari oko ni popo ati titi ijoba.
  5. EroAye-Lu-Jara: ohun ni oloyinbo n pe ni ‘internet’ intaneeti eyi ni o gbode fun gbogbo eniyan lati ba eniyan soro ni kiakia.
  6. Leta Kiko: eyi je aroko ti a n ko si eniyan: orisii leta kiko meji ni o wa awon naa ni Leta gbefe ati leta aigbefe.
  7. Foonu: ohun ni ero alagbeka ti a fi n ba eniyan soro. Ohun ni o yara ju lati ba eniyan soro ni ibikibi.
  8. Agogo: aye atijo nikan ko ni won ti n lo agogo gege bi nnkan ibanisoro. Won n lo agogo ni ile isin, ni ile iwe ati ni oja ni odo awon ti o n ta oja.

 

IGBELEWON

  1. Ko orisii iwe iroyin marun-un ti o gbode ka ni ode oni.
  2. Iyato meji wo ni o wa laarin Redio ati Telifisan.
  3. Ko awon ona miiran meta ti a n gba ba ara soro lode oni.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 160-163.

 

ATUPALE IWE ASAYAN

 

Atupale awon ilo-ede/akanlo-ede. Sise orinkinniwin won.

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ko orisii iwe iroyin marun-un ti o gbode ka ni ode oni.
  2. Iyato meji wo ni o wa laarin Redio ati Telifisan.
  3. Ge awon oro wonyi si mofiimu: omokomo, iyaale, ijekuje, isekuse, Durotimi, Olorun, Iyeegbe, Ileese, Kabiyesi, agbalagba, Opolopo.
  4. Fa awon ona ede ogun (20) ti o ti jeyo ninu iwe apileko ti o n ka lowo.

 

ISE ASETILEWA

  1. Awon ona ti a le gba seda oro-oruko je (A) meji (B) meta (C) merin (D) mejo
  2. Ewo ni ki i sa ara won? (A) elo (B) imo (C) igbagbo (D) ilekile.
  3. Toka si eyi ti a ko seda ninu awon oro-oruko yii (A) owo ati aso (B) ijekuje ati omokomo (C) eto ati igbagbo (D) imo ati ije.
  4. Ge oro yii si mofiimu ‘opolopo’ (A) opo-lo-po (B) opo-n—opo (C) opo opo (D) opo ati opo.
  5. Ona ibanisoro ti ko ni anfaani aworan ni (A) redio (B) telifisan (C) intaneeti (D) faasi

APA KEJI

  1. Ko ona marun-un ti a n gba ba eniyan soro laye atijo pelu alaye.
  2. Ko ona meta miiran ti a ngba ba eniyan soro lode oni.
  3. Seda oro oruko meji nipase: apetunpe, akanmoruko, afomo ibere ati afomo aarin.

 

OSE KARUN-UN

 

ONKA (2,000-50,000).

Onka Geesi Onka Yoruba Alaye ni Yoruba Alaye ni Geesi
2,000 Egbaa Igba l-nz mewaa 2,000 x 1
4,000 Egbaaji Igba l-nz ogun 2,000 x 2
6,000 Egbaata Igba l-nz ogbon 2,000 x 3
8,000 Egbaarin Igba l-nz ogoji 2,000 x 4
10,000 Egbaarun-un Igba l-nz aadota 2,000 x 5
12,000 Egbaafa Igba l-nz ogota 2,000 x 6
14,000 Egbaaje Igba l-nz aadoje 2,000 x 7
16,000 Egbaajo Igba l-nz ogoje 2,000 x 8
18,000 Egbaasan Igba l-nz aadorun-un 2,000 x 9
20,000 Egbaawaa (=k1 kan) Igba l-nz ogorun-un 2,000 x 10

 

IGBELEWON

  1. Ko onka awon figo yii; 30,000, 35,000, 36,000, 47,000, 52,000.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 69-72.

 

 

 

AWON ORISA ILE YORUBA

Ona meji pataki ni a le pin awon orisa ile Yoruba si.  Awon orisa kan wa to je pe won ro wa lati orun,  orisa ni Olorun da won, won ki i se eniyan nigba kan kan ri. Awon orisa ipin keji ni awon eniyan ti a so di orisa nitori ise  ribiribi owo won nigba ti won wa laye.  Awon wonyi ki i se orisa lati orun wa.  Apeere awon orisa ti won ro wa lati orun ni Obatala, Orumila, Ogun, Esu. Awon ti a so di orisa akunlebo ni yemoja, sango, oya, osun, oba, meremi, orisa oko ati bee bee lo.

 

OGUN( god of iron):  Ode ni Ogun ni aye atijo. Tabutu ni oruko iya ogun.Oririnna si ni baba re O je oye Osinmole ni ile Ife, ki o to lo si ilu ire Ekiti. Mariwo ni aso Ogun, eje lo si maa n mu. Gbogbo ohun to je mo irin je ti ogun Ogun korira ki won gbe koronfo agbe emu duro. O tun korira iwa eke, iro pipa, ole jija

A gbo nigba ti awon orisa n ti ikole orun bow a si ile aye, won se alabapade igbo didi kijikiji kan. Orisa-Nla ni a gbo pe o koko lo ada owo re lati la ona yii sugbon ada fadaka owo re se. Ogun ni a gbo wi pe o fi ada irin  owo re la ona gberegede fun awon orisa yooku lati koja. Ise ribiribi ti ogun se yii ni awon orisa yii se fi je oye Osin-Imole ni Ile Ife. Itan yii fi han pe ode ti o ni okiki ni ogun.

 

IGBAGBO YORUBA NIPA OGUN

  1. Ogun ni orisa ti o ni irin.
  2. Oun ni o la ona fun awon orisa elegbe re.
  3. O je orisa ti o feran ododo ati otito.
  4. Orisa ogun ni Ogun
  5. Gbenagbena ni Ogun.

 

AWON OHUN TI WON FI N BO OGUN

Aja, esun isu, epo, adiye, agbo, ewure, eyele, igbin, ewa, eyan, iyan, obi abata, orogbo, ataare ati emu. Eekan soso ni apaja ogun gbodo be aja ogun ni orun ti won ba n boo gun.

 

BI WON SE N BO OGUN

Bi won se n bo Ogun ilu naa ni won n bo Ogun idile kookan. okuta ribiti lo duro fun ogun agbede. Ori re ni awon alagbede ti n ro oko ati ada.

 

ORIKI OGUN

Ogun lakaaye Osin Imole

Ogun alada meji

O fi okan san’ko

O fi okan ye’na

Ojo ogun n ti ori oke bo

Aso ina lo mu bora

Ewu eje lo wo

Ogun onile owo

Ogun onile owo, olona ola

Ogun onile kangunkangun orun

O pon omi sile f’eje we

Ogun meje logun mi

Ogun alara ni gb’aja

Ogun Onire a gb’agbo

Ogun Ikola a gba’gbin ……

 

ORISA-NLA/OBATALA

Orisa-Nla ni asaaju gbogbo awon orisa. Oun ni won gbagbo pe o je igbakeji Olodumare, nitori oun ni Eledaa koko da. Oun naa ni a tun n ni Obatala, iyen ‘Oba ti ala’

 

IGBAGBO YORUBA NIPA ORISA-NLA

  1. Alamo ti o mo ori.
  2. Orisa funfun ni
  3. Asaaju awon Orisa to ku ni.

 

OUNJE TI WON FI N BO ORISA-NLA

  1. Iyan ati obe eran igbin t won fi ori se.
  2. Omi idaji ni o maa n mu.

 

ORIKI

Alase, O so enikan soso di igba eniyan

Somi di’run, somi di’gbea

Somi d’otale-legbee eniyan

Orisa eti eni ola

O fi ojo gbogbo t’obi

O t’obi lai-segbe

Banta banta ninu olao sun ninu ala

O ji ninu ala

O ti inuala dide

Baba nla, oko Yemowo!

 

ESU

Esu je orisa pataki nile Yoruba. Oun ni o je olopaa si Olodumare. Oun ni o si eto lati fi iya je eni ti o ba rufin. Esu korira omi gbigbona ati adi. O je orisa ti o maa n se ire ti o si maaa n se ibi. Babalawo ki i fi oro se ere.

 

BI WON SE N BO ESU.

Won maa n fi epo, eje aja tabi ti ewure bo esu. Ti won ba fe ki o se ibi ni won maa n fi omi gbigbna ati adi bo o.

 

IGBELEWON.

  1. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa ogun?
  2. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa Obatala?
  3. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa esu?
  4. Ki oriki ogun

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 176-182.

 

KIKA IWE LITIRESO APILEKO

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ko onka awon figo yii; 30,000, 35,000, 36,000, 47,000, 52,000.
  2. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa ogun?
  3. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa Obatala?
  4. Ki ni igbagbo Yoruba nipa orisa esu?
  5. Ki oriki ogun.

 

ISE ASETILEWA

  1. 20,000 ni (A) oke kan (B) oke meji (C) oke ogun (D) egberungun.
  2. 40,000 ni (A) oke meji (B) oke meta (C) okemerin (D) egberunji.
  3. …. ni orisa ti o ni agbara lori irin. (A) esu (B) ogun (C) obatala (D) orisa-nla.
  4. Esin ti o korira omi gbigbona ati adi ni (A) ogun (B) sango (C) obatala (D) esu.
  5. Orisa ti o maa nfi mariwo bora bi aso ni (A) ogun (B) sango (C) obatala (D) esu.

APA KEJI

  1. Ko onka yii: 30,000, 70,000, 500,000
  2. Ki oriki esu
  3. Ki orikii ogun
  4. Ki oriki obatala.

 

 

OSE KEFA

 

 

 

ORUNMILA

Orunmila ni alakoso ifa. O si je okan pataki ninu awon orisa ile Yoruba. Oke Igeti ni Orunmila koko duro si ki o lo si oke *tas2. O lo opolopo odun ni Ife Ondaye ki o to lo si Ado. Ibi ti o tip e julo ni ode aye. Idi niyi ti won fi n so pe ‘Ado n’ile Ifa’ Orunmila tun gbe ni Otu Ife. Ibe ni o ti bi awon omo wonyi: Alara, Ajero, Owarangun-aga, Oloyemoyin, Ontagi-Olele, Elejelu-mope ati Olowo. O tun gbe ni Ode Oyan. Ibi ti o ti bi Amukanlode-Oyan. Bakan naa ni o gbe ni ode Onko ti o ti bi Amosunlonkoegi.

 

IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ORUNMILA

  1. Orunmila alakoso, ogbo, Imo ati Oye.
  2. Opitan ni Orunnmila.
  3. Okunrin kukuru dudu ni Orunmila
  4. Orunmila ni alakoso Ifa dida ati ale
  5. Orunmila ko ni egungun lara lati sise agbara.
  6. Agbaye-gborun ni Orunmila.

 

BI WON SE N BO ORUNMILA

Ojo awo ni won n bo Orunmila bi o tile je wi pe ojoojumo ni awon babalawo no Ifa. Bi won se n difa oroorun naa ni won n se odun Ifa ni odoodun.

Ti won ba fe bo ifa ni owuro, babalawo yoo mu obi sinu omi tutu, yoo maa fi iroke lu opon ifa, yoo maa ki Orunmilani mesan-an-mewaa. Babalawo yoo pa obi naa, yoo se oju obi si inu omi. Omi naa ni yoo lo da fun esu. Babalawo yoo lo da obi naa lati mo bi ifa ba gba a. bi obi bay an tako-tabo, iyen ti oju meji si oju, ti meji da oju deile. Ifa ti gba obi nu un. Babala yoo pin obi naa fun awon to wa niba lati je.

Bi o ba je ifa odun, awon nnkan repete ni won yoo ka sile. won yoo sip e mutumuwa fun ariya.

 

IGBELEWON

Salaye igbagbo awon yoruba lori Orunmila

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 164-166.

 

SANGO

Eniyan ni a gbo pe Sango je ki o to di orisa. Sango je orisa ti ise, irisi ati isoro re kun fun iberu. Sango je omo Oranmiyan. Awon iyawo re ni Oya, Osun ati Oba. Itan so fun  w a pe o je oba ni ilu Oyo. O ni agbara o si ni oogun. Ti inu ba n bi Sango, ina maa n yo ni enu re. Ninu itan kan, Sango si agbara lo o si pokunso lori igi aayan. Bayi ni awon iyawon re meteeta se parade di alagbalugbu omi. Oya wole ni Ira. Titi di oni ni won n boa won meteeta.

 

IGBAGBO YORUBA NIPA SANGO

  1. Orisa ti o ni agbara lori ara ati monamona ni.
  2. O je orisa afajo.
  3. O n fun won lomo.

 

OHUN TI WON FI N BO SANGO

Orogbo ni obi Sango. Won n fi oka, adiye ati aguntan bolojo bo o. Ounje Sango ni oka.

 

ORIKI SANGO

Penpe bi asa, asode bi ologbo

Sangiri-lagiri

Olagiri kaka f’gba edun bo o!

Eefin ina la n da laye

Ina n be lodo oko mi orun.

Sango onibon orun

Ajalaji Oba koso

 

IGBELEWON

Salaye lori esin Sango.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.2 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 173-175.

 

APAPO IGBELEWON

  1. K o onka yii: 70,000, 90,000.
  2. Salaye lori esin Orunmila.
  3. Ki ni igbagbo Yoruba lori Sango.

 

LITIRESO

Ewi Igbalode: Taiwo Olunlade. (NECO).

 

ISE ASETILEWA

  1. Esin ti o ni agbara lori ina ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu. (A) (B) (C) (D)
  2. Esin ti o ni agbara lori ara ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu.
  3. Esin ti awon Yoruba gbagbo pe o asaaju awon orisa yoku ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu.
  4. Esin ti o maa n lo iroke ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu.
  5. Orisa ti o mo ori ni (A) ogun (B) sango (C) orunmila (D) esu.

 

APA KEJI

  1. Ki oriki Orunmila
  2. Ki oriki Sango.

 

OSE KEJE

 

EYA ARA IFO

Eya ara ifo ni awon eya ara ti a fi maa n pe iro jade ni enu. Apeere ni: iho imu, kaa enu, aja enu, tan-an-na, gogongo, komookun, edo fooro, ete oke, ete isale, eyin oke, eyin isale, erigi oke erigi isale, eyin ahon, iwaju ahon, eyin ahon.

 

EYA ARA IFO

  • EYA ARA IFO TI A LE FOJU RI: awon eya ara wonyi ni a le fi oju ri. Apeere: iho imu, kaa imu, aja enu, tan-an-na, gogongo, komookun, edo-fooro, ete oke, ete isale, eyin oke, eyin isale, erigi oke, erigi isale iwaju ahon, aarin ahon ati eyin ahon, afase, olele, aja enu, ita gogongo, kaa imu.
  • EYA ARA IFO TI A KO LE FI OJU RI: eya ara ifo ti won wa lati inu ikun si inu ofun ti a ko le fi oju ri. Awon ni: kaa ofun, inu gogongo, tan-an-na, komookun, eka komookun, edo-foro, eran edo-fooro, efonha.

 

AFIPE

Afipe ni awon eya ara-ifo ti won wa ni opona ajemohun. Awon ni won n kopa ninu pipe-iro ede jade. Opona ajemohun bere lati oke alafo tan-an-na de iho enu ati imu. Afipe pin si meji: (i) Afipe Asunsi ati (ii) Afipe Akanmole.

  • Afipe Asunsi: awon afipe wonyi ni won maa n sun nigba ti a ba n pe iro. Apeere: ete isale, eyin isale, erigi isale, ahon, gogongo, olele.
  • Afipe Akanmole: awon afipe yii ki i sun lo si ibi kan ti a ba n pe iro. Apeere: eyin oke, ete oke, erigi oke, aja enu, kaa imu afase.

 

IGBELEWON

  1. Ko afipe asunsi marun-un sile.
  2. Ko afipe akanmole marun-un sile.
  3. Ko eya ara-ifo marun-un afojuri marun-un sile.
  4. Ko eya ara-ifo marun-un sile.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 5-8.

 

EGUNGUN

Egungun je okan pataki lara esin ibile Yoruba. Orisa egungun je orisa ti awon Yoruba fi maa n se iranti awon baba nla won. Ologbojo ni olori egungun. Eku ni won maa n dab o ori won. Igbale ni won maa n gbe eku egunngun pamo si. Irisi won jo tie sin gelede. Orisiirisii aso ni o maa n wa lara eku egungun. Awon elesin egungun ni won maa n je ‘oje’ Ojewale. Ojetunde, Ojegbenro ….

 

IGBAGBO YORUBA NIPA EGUNGUN

  1. Yoruba gbagbo wi pee sin egunfun je esin aseynwwaye
  2. Yoruba gbagbo wi pe o je esin lati orun.
  3. Awon yoruba gbagbo wi pe egungun je baba nla awon.

 

IGBELEWON

Salaye lori esin egungun.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd.

 

 

APAPO IGBELEWON

  1. Salaye lori esin egungun.
  2. Ko afipe asunsi marun-un sile.
  3. Ko afipe akanmole marun-un sile.
  4. Ko eya ara-ifo marun-un afojuri marun-un sile.
  5. Ko eya ara-ifo marun-un sile.

ISE ASETILEWA

  1. Eya ara-ifo ti a le fi oju ri ni (A) oju (B) ori (C) ete (D) edo foro
  2. Eya ara-ifo ti a ko le fi oju ri ni (A) edoforo (B) ete (C) eyin (D) eti.
  3. Ewo ninu awon wonyi ni o maa n sun ti ba n pe iro? (A) agbon (B) ete isale (C) ete oke (D) eyin oke.
  4. Ki ni aso egungun? (A) sapara (B) kenbe (C) eku (D) adiro
  5. Esin wo ni o fi igbagbo Yoruba han nipa iye leyin iku? (A) kokumo (B) oro (C) Obatala (D) egungun.

APA KEJI

  1. Se iyato laarin afipe akanmole ati asunsi pelu apeere.
  2. Ki ni igbagbo Yoruba nipa esin egungun?

 

OSE KEJO

 

IRO FAWELI

Iro-Ede -; ni ege ti  o kere julo ti a le fi eti gbo ninu ede, ti a ba n ba eniyan soro ,iro ifo ni ohun ti eni naa yoo maa gbo.

A le ko iro –ede sile nipa lilo leta tabi ami.Iro-ede ti a ni pin si ona meta;

Iro faweli

Iro konsonanti

Iro ohun.

Iro Faweli:- ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.

Ona meji ni iro faweli pin si

Faweli Airanmupe.

Faweli Aranmupe.

Faweli Airanmupe je meje. Awon naa ni a, e, e, i, o, o, u.

Faweli aranmupe je marun-un. Awon naa ni: an, en, en, in, un.

 

ADAKO IRO FAWELI

Ilana Akoto                         Ilana  Fonetiiki

a                                  [ a ]

e                                  [ e ]

e                                  [ Ɛ ]

I                                   [ i ]

o                                  [ o ]

o                                  [ Ɔ ]

u                                  [ u ]

an                                [ a ]

en                                [ Ɛ ]

in                                 [ i ]

on                                [ Ɔ ]

un                                [ u ]

 

ABUDA FUN ISAPEJUWE IRO FAWELI: Eyi ni abuda ti a n lo fun isapejuwe iro faweli.

  1. Ipo ti Ahon wa.
  2. Ipo ti Ete wa.
  3. Ipo ti Afase wa.
  4. Ipo ti Apa to gbe soke ga de ninu enu.

IPO TI AHON WA-; bi a ba tele abuda yii,ona meta ni a le pin iro faweli si,nitori pe ona meta ni ahon wa pin si,ipo ahon kookan lo si ni iro faweli ti a fi n pe.

Faweli iwaju

Faweli aarin.

Faweli   eyin

Faweli Iwaju– eyi ni faweli ti a fi iwaju ahon pe,ap I,e,e

Faweli Aarin– eyi ni faweli ti a fi aarin ahon pe.ap “a”

Faweli Eyin– eyi ni faweli ti a fi eyin ahon pe .ap o,u ,o.

 

IPO TI ETE WA-; bi a ba tele abuda yii, ona meji ni a le pin iro faweli si

Faweli roboto.

Faweli perese.

Faweli Roboto– eyi ni iro ti a pe nigba ti ete se roboto.ap u,o,o

Faweli Perese– eyi ni iro ti a pe nigba ti ete wa se perese.ap i,e,

 

IPO TI AFASE WA-; bi a ba tele abuda yii,ona meji ni a le pin iro faweli si

Faweli airanmupe

Faweli aranmupe

Faweli Airanmupe-; ni iro faweli ti a pe nigba ti afase gbe soke lati di kaa imu ,ti eemi si gba kaa enu jade. Ap: a, e, e, i, o, o, u.

Faweli Aranmupe-; eyi ni iro faweli ti a pe nigba ti afase wa sile lati di kaa enu ti eemi si gba kaa imu jade.Ap:  an, en in, un.

 

IPO TI APA TO  GBE SOKE JULO GA DE NINU ENU-; bi a ba tele abuda yii, ona merin ni a le pin iro faweli si:

Faweli ahanupe

Faweli ahanudiepe

Faweli ayanudiepe

Faweli ayanupe

 

Faweli Ahanupe (oke)-: ni faweli ti a pe nigba ti apa kan lara ahon ba gbe soke ti o si fere ga de aja-enu. Ap / I /, / u /, / in /, / un /.

Faweli Ahanudiepe (ebake)-: ni faweli ti a pe nigba ti apa kan to gbe soke ni ara ahon de ebake ,ti a ha enu die pee. Ap / e /, / o /.

Faweli ayanudiepe (ebado)-: ni faweli ti a pe nigba ti apa kan gbe soke to de ebado. Ap / Ɛ /,  / Ɔ /,  / Ɔ /, / Ɛ /.

Faweli  ayanupe (odo)-;ni faweli ti a penigba ti apa kan gbe soke ni ara ahon wa ni odo. Ap / a /, / a /

 

 

ATE    FAWELI AIRANMUPE

Ate yii ni o n so ipo tabi irisi ahon ni enu ti a ba n gbe iro faweli jade.

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

ATE  FAWELI  ARANMUPE

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

ISAPEJUWE  IRO  FAWELI

AIRANMUPE

[a]-      aarin, airanmupe,  ayanupe, perese.

[e]-      iwaju, airanmupe, ahanudiepe, perese

[Ɛ ]-    iwaju, airanmupe, ayanudiepe, perese.

[i ]-     iwaju, airanmupe, ahanupe, perese.

[o]-     eyin, airanmupe, ahanudiepe, roboto.

[ Ɔ ]-  eyin, airanmupe,  ayanudiepe, roboto.

[u]-     eyin, airanmupe, ahanupe, roboto.

 

ARANMUPE

[ a ]-    aarin,  aranmupe,   ayanupe, perese.

[ Ɛ ]-   iwaju, aranmupe, ayanudiepe, perese.

[ i ]-    iwaju, aranmupe, ahanupe, perese.

[ Ɔ ]-   eyin, aranmupe, ayanudiepe, roboto.

[ u ]-   eyin, aranmupe, ahanupe, roboto.

 

Akiyesi pataki:  ki a ranti pe gbogbo iro faweli (aranmupe ati airanmupe) ni won je iro akunyun.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 14-17.

 

IGBELEWON

  1. Se apejuwe iro faweli airanmupe pelu ate.
  2. Se apejuwe iro faweli aranmupe pelu ate.

 

IGBAGBO ATI ERO YORUBA NIPA OSO ATI AJE

Akoonu

Awon  Yoruba gba pe oso ati aje wa, won  tile ni igbagbo yii to bee ti o fi je pe o soro lati ri eni ti o ku, yagan tabi ti wahala sele si ti won ko ni so o mo oso ati aje.

Bakan naa awon Yoruba gbagbo pe oso ati aje ni agbara oogun ti won le fi pa eni ti won ba fe. Ewe won gbagbo pe inu ipade aje ni won ti maa n duna- an- dura bi won yoo se pa eni ti won ba fe pa. Won gbagbo pe ona meji ni okunrin fi n gba oso

-ajogunba

-wiwo egbe oso

bee naa ni ti aje o le je nipa ajogunba

Iyato laarin oso ati aye. Iyato to wa laarin oso ati aje ni pe awon okunrin lo maa n je oso ni gba ti awon aje je obinrin.

 

IGBELEWON

  1. Salaye lori igbagbo awon Yoruba nipa oso ati aje.
  2. Ko iyato kan ti o wa laaarin oso ati aje

 

LITIRESO

KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN ( EWI IGBALODE) ‘Taiwo Olunlade. NECO

 

APAPO IGBELEWON

  1. Se apejuwe iro faweli airanmupe pelu ate.
  2. Se apejuwe iro faweli aranmupe pelu ate.
  3. Salaye lori igbagbo awon Yoruba nipa oso ati aje.
  4. Ko iyato kan ti o wa laaarin oso ati aje

 

 

  1. ISE SETILEWA
  2. Iro iwaju ni (A) a (B) e (C) u (D) o
  3. Iro airanmupe ni iro (A) a (B) an (C) o (D) u.
  4. Faweli ahanupe iwaju ni (A) a (B) e (C) c (D) i.
  5. Faweli roboto ni (A) i (B) e (C) a (D) o.
  6. Ewo ni ko si lara ise ti awon aje maa n se? (A) iwosan (B) itusile (C) ounje fifun ni (D) pipani

APA KEJI

  1. Ya ate faweli airanmupe pelu alaye.
  2. Ya ate faweli aranmupe pelu alaye.

 

OSE KESAN-AN

 

IRO KONSONANTI

IRO KONSONANTI

Iro konsonanti-; ni iro ti a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o n ti inu edofooro bo.iro konsonanti mejidinlogun lo wa ninu ede Yoruba. Awon naa ni; b,d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, s, t, w, y.

APEJUWE IRO KONSONANTI

AKOONU

Iro Konsonanti: ni iro ti a pe nigba ti idiwo wa fun eemi ti o ti inu edofooro bo. Iro konsonanti mejidinlogun lo wa ninu ede Yoruba awon naa ni: b, d, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, S, t, w, y.

 

ABUDA FUN ISAPEJUWE IRO KONSONANTI

Eyi ni awon abuda ti a maa tele ti a ba fe sapejuwe iro konsonanti:

Ipo ti alafo tan-an-na wa.

Ipo ti afase wa.

Ibi isenupe.

Ona isenupe.

 

IPO TI ALAFO TAN-AN-NA WA

Bi a ba tele abuda yii, ona meji ni a le pin iro konsonanti si

Konsonanti aikunyun.

Konsonanti akunyun.

Konsonanti Aikunyun-: ni iro ti a pe nigba ti alafo tan-an-na fi aye ti o to sile fun eemi ti o n ti inu edofooro bo,eyi ni pe  ko si idiwo. Apeere konsonanti aikunyun ni t, k, p, f, s, s, h.

Konsonanti Akunyun-: ni a pe nigba ti alafo tan-an-na sunmo ara won pekipeki,ti idiwo si wa fun eemi  ti n ti inu edofooro bo. Ap /b/, /d/, /g/, /l/ abbl

 

 

 

IPO TI AFASE WA

Bi a ba tele abuda yii, ona meji ni a le pin iro faweli si,awon naa ni

Konsonanti airanmupe

Konsonanti aranmupe

 

Konsonanti Airanmupe-: ni iro ti a pe nigba ti afase gbe soke lati kaa imu, ti eemi si gba kaa- enu jade. ap/b/, /d/, /f//, /k/, /l/.

 

Konsonanti Aranmupe-: ni iro konsonanti ti a pe nigba ti afase wa sile lati di kaa-enu ti eemi si gba kaa-imu jade. ap /m/,/n/.

IBI ISENUPE

Ibi isenupe-: eyi ni o n tokasi afipe asunsi ati akanmole ti a lo lati gbe iro konsonanti jade.

Ibi isenupe pin si ona mejo

Afeji-ete-pe

Afeyin-fetepe

Aferigipe

Afaja-ferigipe

Afajape

Afafasepe

Afafase-fetepe

Afitan-an na-pe

 

ONA ISENUPE

Ona Isenupe-: ni o n tokasi iru idiwo ti o wa fun eemi ni gbigbe awon iro konsonanti jade. Ona meje ni ona isenupe pin si, awon naa ni

Asenupe

Afunnupe

Aranmu

Arehon

Afegbe-enu-pe

Aseesetan.

Asesi.

IGBELEWON

Kin ni iro konsonanti?

Daruko awon abuda fun isapejuwe iro konsonanti.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 14-17.

 

Bi a ti n sin oku oba yato patapata si bi a ti n sin oku eniyan lasan.Awon oba alade po ni ile Yoruba,bi a si ti n sinku oba ni ilu kan yato si ti ikeji, ati pe ipo oba kan yato si ara won. Isinku Alaafin ni a o fi se apeere.

Ilu ati ibon yiyin ni  a fi n tufo oba ati arugbo,won ki i tete tufo oku oba, ki awon omo to fi to awon oloye leti ni won yoo to palemo gbogbo ohun ti o ba je ohun ini ti oba ni won yoo ti palemo.

Leyin eyi ni awon omo oba yoo lo so fun awon ijoye pe ara baba awon ko ya, nitori pe won ko ni ase lati so fun won pe oba waja.Nigba ti awon ijoye ba de aafin ni won yoo to mo pe oba ti gbe emi mi, a ki i so pe oba ku, nitori pe oba ki i ku,oba wo aja-ile.A tun le so pe erin wo,opo ye tabi ile baje.

Gbara ti oba ba ku,ni awon ijoye ati awon agbaagba ti ise tabi ipo oye won ba je mo isinku oba, yoo ti bere etutu ati oro –isinku oba nitori pe aki i sinku oba gege bi a ti i sinku eniyan lasan.Oku gbogbo ilu ni oku oba,ni Oyo ilu koso ati fere Okinkin ti a fi eyin gbe.

Ni Bara ni won maa n sin oku Alaafin si ni aye atijo,lale si ni won maa n se eto oku naa,opolopo etutu ni won o ti se.

Ona-Onse Awo ni oloye ti ipo oye re jemo isinku oba Alaafin.Oloye yii ni yoo ge ori oba to waja,inu yara kan to wa laafin, ti a n pe ni ile ori ni yoo gbe ori oba si fun ilo oba ti yoo tun je tele e.

Bi won ba fe lo sin oku oba to ku ni Bara, won a fon fere Okinkin,a o si lu ilu koso lati so fun awon ara ilu  pe oba n re ile igbeyin lati lo sun.

Ibi mokanla ni awon oloye to gbe oba yoo ti duro ki won to de Bara nitori pe ibe jinna die si aarin ilu.Nibi kookan ti won ba ti duro si ni won yoo ti fi eeyan kan ati agbo kan rubo.

Koto ti a o sin oku Alaafin si maa n fe pupo,yoo gun daadaa,bee ni yoo si jin gidi nitori opolopo nnkan ti a o sin pelu re,aso dudu ati aso funfun ni a fi n sinku oba Alaafin.

Bi won se n sinku oba ni pe won a te oku oba si aarin koto ti a gbe,leyin eyi won a pa obinrin mejo,won a te merin si igberi re ati merin si igbase re .won a tun pa awon giripa okunrin merin,won o te meji si egbe re otun ati osi,leyin eyi ni won yoo wa ko oku awon mokanla ti a fi rubo loju ona,ki a to de Bara sinu koto nla naa.

Awon metalelogun ti a sin pelu oba ni won gbagbo pe yoo maa se iranse fun oba lona orun ati ni orun nibi ti o n lo.

Igbagbo won ni pe ipo ti oba wa laye ni yoo wa ni orun,nitori naa oba  ni lati ni opolopo obinrin  ati iranse.leyin gbogbo re ni won yoo pa eni ti o gbe ina lowo ti a fi se gbogbo eto isinku yii,won yoo gbe oku re pelu awon iranse ti o wa ninu koto.

Awon iyawo,omo,ore,ati ebi yoo wa bere si ko ebun,ounje ti won ko way ii ni won lero pe yoo wulo fun oba lona irin-ajo ti o n lo.leyin gbogbo eyi ni won yoo wa ro eepe bo gbogbo ohun ti o wa ninu koto.

Ayipada ti de ba bi a ti n sin oku oba laye ode-oni,won ko fi eniyan se etutu mo ni ilu oyo esin ati maluu ni won n lo bayii.

 

Akudaaya ni awon ti won ku ti won tun wa fi ara han ni ibomiran. Igbagbo Yoruba ni wi pe iru awon eniyan bayi ko i lo iye odun ti won ye ki won lo laye ki won to ku. Iku won le je sababi nnkan kan. Awon eda bee yoo lo si ilu miiran lati lo lo odun ti o ku nibe. Akudaaya le ni ni iyawo tabi ni oko ni ilu miiran ti o lo.

 

IGBELEWON

  1. Ki ni igbagbo awon Yoruba nipa akudaaya?
  2. Ko apeere abami eda marun-un sile.

 

LITIRESO

KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN ( EWI IGBALODE) ‘Taiwo Olunlade. NECO

 

APAPO IGBELEWON

  1. Kin ni iro konsonanti?
  2. Daruko awon abuda fun isapejuwe iro konsonanti
  3. Ki ni igbagbo awon Yoruba nipa akudaaya?
  4. Ko apeere abami eda marun-un sile.

 

ISE ASETILEWA

  1. Iro ti idiwo wa fun eemi re ni iro (A) konsonanti (B) faweli (C) ami (D) iro.
  2. Ewo ni iro akunyun? (A) f (B) h (C) gb (D) t
  3. Ewo ninu iro konsonanti yii ni eemi se mo patapata? (A) f (B) s (C) h (D) x
  4. As1nup4 ni (A) l (B) d (C) g (D) m
  5. Zk5dzqyz ni cni t7 9 fi 8l5 kan s7l2 l[ s7 8l5 m87rzn lqtzr7 p3 9 ……… (A) ku (B) salo (C) je gbese (D) binu.

APA KEJI

  1. Salaye awon iro konsanati yii ni kikun: k, gb, r, y, w
  2. Awon wo ni a n pe ni abami eda? Salaye pelu apeere.

 

 

OSE KEWAA

 

AMI     OHUN                   

Ede Yoruba je ede ami ohun. Opolopo ni ede ti won maa n se amulo ohun ni orile-ede yii ati kaakiri agbaye. Ara won ni ede faranse. Faweli ni o maa n gba ami sori pelu konsonati aranmupe asesilebu ‘’m ati n’’ Ninu ede Yoruba, oro eyokan pelu sipeli kanna le ni opolopo itumo paapaa julo ni iwon igba ti oro yii ba ti ni ami otooto lori. Ami ori oro meta ni a o gbe yewo ninu iwe yii. Awon naa ni: Ami o oke, ami  isale ati ami aarin.

Ami ohun oke  ( /  ) mi.

Ami ohun isale ( \ ) do.

Ami ohun aarin( –  ) re.

 

AMI OHUN OKE (mi)

                                    ba                    fe                     ge                    gbe

 

ji                      ki                     ni                    ri

 

AMI OHUN ISALE (do)

ba                                fa                                 ge                                gba

je                                 ka                                na                                ra

                        se                                 si                                  so                                 sun

da                                de                                di                                 dun

ya                                ye                                yo                                yin

wa                               we                               wo                               wu

 

AMI  OHUN AARIN (re)

be                      fe                               ge                   gbe

je                        ki                              lo                      re

                                               

Gege bi a ti so saaju pe, ami ohun meta ni a o yewo ninu iwe yii. Ki a ranti pe faweli nikan ni a maa n fi ami si lori ati konsonanti aranmupe asesilebu (m/n). Awon wonyi nikan ni won maa n gba ami sori bakan naa ni awon konsonanti yii le da duro gege bi odindi silebu ninu ede Yoruba.

 

AMI OHUN ONISILEBU MEJI

AMI OKE                                 AMI ISALE                             AMI AARIN

sibi                                                  iji                                              ife

Kunle                                               igba                                          omo

Wale                                                ego                                            ire

 

Batani  kin-in-ni  re mi

awo                             ile                                ise                                ipon

ile                                itun                              aja                                apa

aje                                ede                              egbe                             ere

ewe                              ibi                                imi                               odo

ogbo                            oro                               oso                               ose

 

Batani    keji  re do

aba                               ajo                   ida                   imo

aje                                ila                    ola                   ife

ere                               iko                   ibe                   amo

are                               ile                    iwi                   ige

Batani keta  do mi

egbe                 ore                   opa                  ota

ila                    otun                 aba                   ada

ilu                    agba                 Aja                  ala

ana                   apa                   ara                   amo

 

Bata kerin do  do

ebe                               ese                                           eje                                            efe

ele                                ala                                            aja                                            apa

ija                                ila                                            ifa                                            ika

 

Batani karun-un do re

ida                               Dada                                       aga                                           obo

ajo                               ole                                           obe                                          oje

ope                              owe.

           

IGBELEWON

  1. Ami ohun meloo ni o wa ninu ede Yoruba? (a) meji (b) meta (d) merin (e) marun-un.
  2. Ami ti o ye lori ‘’ilu’ (ibi ti eniyan n gbe) (a) ilu (b) ilu (d) ilu (e) ilu.
  3. Ami ti o ye lori ‘’oko’’ (….. ti o je eni oluran lowo iyawo). (a) oko (b) oko (d) oko (e) oko
  4. ‘’Ogun’’ (a) ipinle (b) je orisa ile Yoruba (d) ohun ti eniyan n mu ti ara eniyan ko ba ya (e) aawo laarin ilu si ilu.
  5. ‘’obe’’ ni (a) ohun ti a fi je ounje (b) ohun ti a fi n ge nnkan (d) ohun ti o dun ti o larinrin (e) ko ye mi.

 

ORI ATI  ELEDAA

Igbagbo Yoruba ni wi pe Orisa-Nla ni Alamo ti o mo ori. Awon Yoruba gbagbo pe orisa yii ni Olodumare fi dida eniyan le lowo. Oun ni Alamo rere, eni ti o se oju, imu, enu, eti ati eya ara eniyan yooku ni ori. Leyin re ni Olodumare mi emi iye si amo ti Obatala ba mo. idi niyi ti won fi n ki i ni: ‘Ajala Alamo ti mo ori’ tabi ‘Alamo rere’. Ise owo re ni awon eni orisa bi: abuke, amukun-un, aro, afin, afoju ati awon abirun miiran.

 

IGBELEWON

Salaye lori ori ati eledaa.

 

IWE ITOKASI:

Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 177-178

 

LITIRESO

KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN ( EWI IGBALODE) ‘Taiwo Olunlade. NECO

 

APAPO IGBELEWON

  1. Ami ohun meloo ni o wa ninu ede Yoruba? (a) meji (b) meta (d) merin (e) marun-un.
  2. Ami ti o ye lori ‘’ilu’ (ibi ti eniyan n gbe) (a) ilu (b) ilu (d) ilu (e) ilu.
  3. Ami ti o ye lori ‘’oko’’ (….. ti o je eni oluran lowo iyawo). (a) oko (b) oko (d) oko (e) oko
  4. ‘Ogun’ (a) ipinle (b) je orisa ile Yoruba (d) ohun ti eniyan n mu ti ara eniyan ko ba ya (e) aawo laarin ilu si ilu.
  5. ‘obe’ ni (a) ohun ti a fi je ounje (b) ohun ti a fi n ge nnkan (d) ohun ti o dun ti o larinrin (e) ko ye mi.
  6. Salaye lori ori ati eledaa.

ISE ASETILEWA

  1. Iye ami ti o wa ninu ede Yoruba ni (A) meta (B) meri (C) meji (D) okan.
  2. Fi ami si ori awon oro yii ‘owo hand, Owo town, owo broom’ (A) [w- =w= [w[ (B) =w= =w= [w- (C) [w- [w= owo  (D) [w= [w= [w=.
  3. Ami ti a fa lati isale lo si oke ni ami (A) do (B) re (C) mi (D) faso.
  4. Orisa ti o mo ori ni (A) esu (B) obatala (C) orunmila (D) Olokun
  5. ‘Ajala Alamo ti n mo ori’ ni …. (A) Orisa-Nla (B) Esu (C) Olokun (D) Olodumare.

APA KEJI

  1. Fi ami ohun se iyato laarin awon oro yii: hand, respect, war, medicine, twenty, property, god of thunder ati State in Nigeria.
  2. Salaye lori Ori ati Eledaa.