SS 2 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA

ILAANA ISE NI SAA KINNI FUN SS2
YORUBA LANGUAGE
OSE
AKORI EKO
1
EDE – Atunyewo lori Aroko ajemo isipaya:
Ilana ero aroko ajemo isipaya
Akole, Ifaara, koko oro, agbalo gbdo
Alaye kikun lori eto ipin afo
Kiko aroko lori akole bii Omi, Iyan,Oja ati bee lo
ASA – Atunyewo lori eko ile:
Ibowofagba, ikini, bi o se ye ni gbogbo igba, suuru, otito sise, iforiti, igboran ati bee bee lo
LITIRESO – Itupale asayan iwe ti ajo WAEC/NECO yan ti rgbe Akomolede fi owo si.
2
EDE – Atunyewo lori silebu ede Yoruba:
Oriki silebu
Silebu oni faweli kan (F)
Silebu alakanpo konsonanti ati faweli
Pipin oro si silebu
ASA – Atunyewo ise abinibi:
Ise agbe, gege bi ise abinibi gbogbo wa. Awon ohun elo ise agbe: Oko, Ada, ati bee bee lo
Ise agbede, ise alapata, ise akope ati ise gbenagbena ati bee bee lo
LITIRESO – Itesiwaju lori atupale awon iwe Litireso:
Awon eda itan
Ibudo itan
3
EDE – Atunyewo aroko onisorongbesi:
Alaye lori oro onisorongbesi
Kiko aroko onisorongbesi to dale isele awujo
ASA – Ona ibanisoro:
Lilo awon eya ara fun ibanisoro bii sise ni ni eekanna, ori gbongbon, oju sise, ara mimi, titenimole, imu yinyin ati iparoko.
LITIRESO – Itupale iwe litireso:
Ahunpo itan ati awon asa Yoruba to seyo ninu itan naa
4
EDE – Atunyewo ihun oro
Siseda oro rouko
Alaye lori awon oro oruko ti a ko seda sugbon ti won dabi eyi ti aseda bi ile, oba, omo, iay ati bee bee lo
ASA – Itesiwaju eko lori ona ibanisoro:
Ibanisoro ni aye ode oni bi iwe iroyin, telifonu, redio, foonu, foonu alagbekaa 1 meeli ati fasi (fax)
LITIRESO – Sise atupale asayan iwe litireso:
Awon ilo ede/Akanlo ede
Sise orinkinniwin won
5
EDE – Onka Yoruba:
Lati egbaa de oke meedogbon on (2,000 – 500,000)
ASA – Awon orisa ile Yoruba:
Ogun, Obatala, Esu
Awon ohun ti a fi n bo eon ati oriki okookan won
LITIRESO – Kika iwe asayan ti ijoba yan
6
EDE – Onka Yoruba:
Lati oke meedogbon on de Aadota (500,000 – 1,000,000)
ASA – Awon orisa ile Yoruba ati bi a se n bo won:
Orunmila, Sango
Awon ohun ti a fi n bo won ati oriki okookan won
LITIRESO – Kika sayan iwe litereso Yoruba ti ajo WAEC/NECO yan
7
EDE – Atunyewo awon eya ara ifo:
Lilo awon eya ara ifo
Alaye lori afipe asunsi ati afipe akanmole
ASA – Awon orisa ati bi a se n bo won:
Awon orisa miiran ni agbegbe awon akeeko
Ipo orisa ni ile Yourba
Pataki orisa lawujo Yoruba
LITIRESO – Kika iwe litireso Yoruba ti ijoba yan
8
EDE – Atunyewo awon iro ninu ede Yoruba:
Iro faweli, iro konsonanti ati iro ohun
ASA – Ero ati igbagbo awon Yoruba lori Oso ati Aje:
Ise ti awon aje n se ninu isegun ati iwosan
LITIRESO – Kika iwe litireso ti ijoba yan
9.
EDE – Atunyewo apejuwe iro konsonanti ati iro faweli:
Yiya ate faweli ati konsonanti
Sise apejuwe awon iro konsonanti ati faweli leyo kookan
ASA – Ero ati igbagbo Yoruba lori akudaaya ati abami eda:
Akudaaya ati abami eda bii Egbere, Iwin, Alujonu, Ebora ati bee bee lo
LITIRESO – Kikai we litireso ti ijoba yan
10
EDE – Atunyewo eko lori ami ohun:
Kiko ami ohun Yoruba meteeta
Alaye lori ise ti ami ohun n se ninu ede Yoruba
ASA – Igbagbo Yoruba nipa ori tabi eleeda:
LITIRESO – Kika iwe litireso Yoruba ti ijoba yan fun saa yi
11 & 12
Atunyewo lori gbogbo ise saa yii ati idanwo ipari saa keta lori Ede, Asa ati Litireso ede Yoruba

 

 

 

 

OSE KINNI
AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA
Aroko ajomo-sispaya je aroko ti a fi n se isipaya awon ori oro to je mo ohun ayika eni. Aroko yii fi ara jo aroko asapejuwe sugbon o jinle ju u lo. Bi aroko asapejuwe se le fe ki o sapajuwe ‘Ile-iwe re’, aroko ajemo isipaya yoo fe ki a so nipa idagbasoke to de ba gbogbo nnkan ile iwe naa titi de ori eto isakoso. Aroko ajemo isipaya maa n tu isu de idi ikoko ijinle itumo, anfaani ati aleebu ori oro.
Eyi tumo sip e aoko ajemo isipaya pe fun imo to gbooro nipa sisafihan bi nnkan won se ri tabi sise. Ki akekoo to le yege ninu aroko ajemo isipaya, o gbodo nifee si ise iwadii nipa nnkan ayika, ki o si ma aka orisirisii iwe, jona ati iwe-iroyin, ti yoo fun un ni imo kikun nipa nnkan ayika.
Aroko ajemo isipaya le je eleyo-oro tabi apola ti won ni itumo to jinle. Apeere aroko ajemo isipaya ni:
Omi
Iwe iroyin
Ise Tisa
Oge-Sise
Imototo
Aso ebi
Aroko ajomo-isipaya tun le je ori-oro bii:
So awon nnkan ti iwo o se ti won bay an o ni alamojuto eto iwosan ni agbegbe re
Se ekunrere alaye bi iwo yoo se seto ayeye odun ibile laarin awon akekoo ile-iwe re.
E je ki a ka aroko ajemo isipaya yii wo, bi apeere:
OWO EYIN
Orisirisi iwa ibaje lo maa n fa Orile-Ede seyin. Okan ninu iru awon iwa ibaje bee ni gbigba ati fifuuni ni owo eyin. Iwa yiiti gbile ni Orile-Ede wa. Bi o tile je pe opo awon eniyan nla lo wa ni idi iwa yii, sibe eyi ko so di nnkan to dara. Ani ohun ti ko dara ko ni oruko meji, ko dara ni. Orisirisi oruko ni awon eniyan fun owo-eyin. Awon kan n pe e ni ‘Owo-abetele’. Awon kan n pe e ni ‘sowo kuduru’. Awon miiran si n pe e ni ‘riba’. ‘Owo ibole’ ni awon kan mo on si. Oun kan naa ni won n pen i ‘owo pabe’ tabi ‘owo ijule’. A ri awon ti n pe e ni ‘egbo’. Ko si oruko ti a pe ata ti a le mu tita ata kuro. Ani ko si oriki ti a le fun iwa-ibaje yii ti o le so di nnkan rere.
Ki i se owo nikan ni awon eniyan n lo gege bi abetele. Awon miiran n ra nnkan gege bi ebun, won o si fi se riba. Bee ni a si ri awon obinrin ti won n fi ara won dipo owo abetele. Ohun ti o daju ni pe ni gbogbo kolofin awujo wa ni iwa yii ti gbile bi owara ojo. Ko si si eni ti o le gba riba ti yoo se eto. Bi adajo ba gba a, too gbe ejo are fun elebi.
Olopaa ti o gba a ko ni le mu odaran. Wolewole to ba gba a yoo maa gba iwa idoti laaye laarin awon eniyan. Oluko to gba a ko ni salaida esi idanwo ru.
Asa awon kan ni pe ko si ibi ti won ki i ti fun ni lebun. Won ni ko si ibi ti iwa yii ko si, won lo tile wan i ilu awon oyinbo Geesi. Iro patapata gbaa ni eyi. Bi o ba tile wa nibe, eyi ko so di iwa daradara. Ohun ti won n se ni ohun ni fifi emi imoore han. Bi a ba se enikan lore, yoo si fun wa ni nnkan ami ope re. Ki i se pe owo la o beere fun nnkan naa. Bee ni ko pon dandan ki o fun wa. Awa naa maa n se iru eyi ti o wopo loke-okun ni Orile-Ede yii. Gege bi apeere, bi enikan ba ran wa ni eru, a oo wa nnkan fun un. Bee si ni a maa n fi imoore han fun eni toju wa ni ile ounje.
Ko si ona ti a gba wo owo ibole ti o so di nnkan rere. O ye ki gbogbo eniyan yera fun iwa abetele ki Orile-Ede wa le niilosiwaju. Bi a ba yera fun iwa abetele, onikaluku yoo le gba eto re. A o si fi ogun asa rere titun sile fun awon omo ti yoo ropo wa ni eyin-ola.

ALAYE: Aroko yii ko gun, sugbon o je apeere ajemo isipaya. Bii abuda, ori-oro yii jinle. O gba ki akeeko ni imo kikun nipa owo eyin. E je ki a woe to aroko yii:
ETO
Ifaara: o sipaya orisii itumo ti ‘Owo eyin’ ni ipin-afo kin-in-ni ati ikeji. Oun yii dara pupo.
Koko-Oro: Gbolohun ipari ipin afo keji ati iketa ni ni alaroko ti n so ewu owo eyin bi o se le dena eto eni si idajo ododo.
Ikadii: Ikadii aroko yii fi han pe yiyera fun iwa yii lo le mu ilosiwaju ati eto idajo ododo wa ni awujo
E je ki a tun wo apeere aroko ajemo isipaya yii wo.
OWO
Koseemanii ni owo je fun eda. Owo ni ohun ti a n na tabi fi ra nnkan. Ire meta ni eda n wa ni ile aye, bi Ifa, elerii-ipin se la a sile. O ni “Ninu gbogbo ire ile aye pata poo, meta l’o se pataki ju. Awon ire meta naa ni ire owo, ire omo, ire aiku (tabi alaafia) pari iwa.” O ni:
Ire meta l’awa n wa
Awa n wowo o,
Awa n womo,
Awa n wa atunbotan aye.
Ifa ni ‘Eni ti o ba ti ni awon ire meteeta wonyi ti ni iyoku. Eni ti o ba lowo yoo niyawo, yoo kole, yoo si ni aso. Idi niyi ti owo fi je egbon fun gbogbo ire yooku.’
Owo yii ni awon Yoruba pen i ‘aje, Ogungun-niso’. ‘Owo, apekanuko’. Awon Hausa pe e ni ‘Kudi, eya ibo pe e ni ‘Ego’.
Ni orile ede Naijiria, owo Naira ati Kobo ni a n na. Awon ilu okeere bi ilu Oba n na owo Dola, orile ede Amerika n na ‘Poun’, bee ni awon orile de agbaye miiran si n na ‘Euro’. Owo ibaa je dola, poun tabi naira, ‘nina lowo’. Ojuse pataki kan ti a mo on mo niyi. Won eni to ba n nawo ni a n pe ni ‘nawo-nawo’, alowo-lowo maa lee owo da. O le kole alaruru, o le ra obokun-oloye, o le fe iyawo. Owo ni a fi n se ohun gbogbo. Awon ayan a maa lulu pe “Olowo sehun gbogbo tan, iya ni o je omo talika”. Gbajumo olorin kan tile tusu de idi ape ninu orin re yii:
“Ohun gbogbo t’Oluwa o se fun wa,
Ma j’owo o gbehin rara
Tori oro t’owo ba se ti
Ile lo n gbe
E wa wohun t’owo se o
Nile aye ta wa yii
Owo ni n se nnkan ‘re
Owo ni n se nnkan gidi
Edumare fun mi ni ‘Moni’ o
Ki n r’owo fi jaye.”
Bi owo se se pataki to, tolori telemu ni n wa a kiri. Kaakiri agbaye ni awon eniyan ti n sare owo. Won ni “Ohun ta o sonu ti gbogbo wa n wa kiri”. Ona kan gboogi to mo ti a fi le ri owo ni ki a tepa mose nitori ‘Oju boro ko ni a fi n gbomo lowo ekuro’.
Orisiirisii owo lo wa. Owo tutu ati owo gbigbona. Owo ti a fi oogun oju eni ko jo ni a mo si owo tutu. Owoo-gbona ni owo won fi ona eru ko jo. Ohun ni won tun n pen i owo eje, owo okuta ati bee bee lo.
Okan-o-jokan ipede awon Yoruba fi pataki owo han. Won ni: ‘Owo ko si, eniyan ko suwon’, ‘owo ni ti oun ko ba si nile ki enikeni ma dabaa Kankan leyin oun.’ ‘Owo ni so omode di agba, oun naa ni so agba di ewe.
Owo a maa fun eniyan ni iyi. Ojuse owo kan niyi. Awon Yoruba a maa fi owo ra iyi. Won ni ‘A n wa owo lo, a pade iyi lona, ti a ba ri owo oun tan, iyi naa ni a o fi ra.
Owo ni a fi n pinle owo, ola ati ola. Opomulero ni owo je fun owo. Won ni “Owo la fi i peena owo, bi egbaa ba so soke egbaa la a fi ja a sile.’ Ipede wonyi fi han pe owo se koko ninu owo-sise. Won tile ni ‘Olowo lo lowo.’ Sugbon igbagbo w ape eni ti o ba n se eru nidii okowo, owo bee ko ni mo on lowo. Won ni ‘eni to ba taja erupe yoo gbowo okuta’. Owo okuta tumo si owo ti ki i duro lowo.
Oye owo ti a bar a oja n so bi a o se karamaasiki nnkan naa si. Bi a ko ba fi owo ra nnkan, a ki i mo iyi iru nnkan bee. Eredi ti won fi ni ‘Oogun ta a ba fowo se. eyin aaro ni i gbe.’ ‘Bia bas i fi owo ra ooyi, dandan ni ki o ko ni loju’. Oro agba niyi.
Bi owo se niyi to yii, awon Yoruba ni ‘Owo ni gbongbo ese.’ Gbongbo ni emi igi. Ti a ba si wa ni ‘owo ni gbongbo ese, eyi tumo si wi pe owo n fa ihuwasi ti o lodi si ilana ofin yala ti ofin Olorun, ti ijoba tabi ti awujo. Orisiirisii ona ni eda fi wa owo. Won n lu omolakeji ni jibiti, ti a mo si ‘gbajue’, bee ni won fi eniyan soogun owo! Ese si ni gbogbo iwonyi lodo Olorun. Bee ni “Elese kan ko ni lo laijiya” ni iwo Mimo so.
Ailowo lowo, won pe e ni ‘baba ijaya’. Okorin kan tile ko lorin, bee naa ni o tun so wipe owo tun n sokunfa igberaga, bee ni ‘igberaga ni saaju iparun’. O ko o pe:
“Oro gbogbo lori owo
Yesi, otito ni
Aini owo baba ijaya
Yesi, otito ni
Alowo lowo, baba afojudi
Yesi, otito ni……..
Koseemani ni owo je. Ko si ohun tie da le se lai si ‘Kudi’?
Kirakita eda nitori aje ni. Owo, ohun ta a sonu, taa n wa kiri! Owo, apekanuko.

ALAYE: Aroko yii gun. Bi aoko ajemo-sispaya, a ri oniruuru oruko ti a n pe owo, oriki, iwulo, anfaani ati alebu re. tun aroko yii ka, ki o sit un n ko niwonba.

AMUTILEWA
1. Ko igbese leta aigbagbefe mefa ti o mo sile leseese.
2. Ko aroko ajemo isipaya lori awon ori oro wonyi:
(i) Iku (ii) Iyan (iii) Ohunosin

 

 

AKORI EKO: ATUNYEWO EKO – ILE
Ni ile Yoruba, awon eko ti awon obi maa n ko omo lati kekere ni a n pe ni eko – ile. Yoruba ni “Ile ni a ti n ko eso rode.” Awon eko bee ni ikini, imototo, isora, iwa to to si obi, agbalagba, alejo, ati elegbe-eni. Omo ti won ko, to si gba, to si n mu eko naa lo nigba gbogbo ni a n pe ni omoluabi. “Omo-Olu-iwa-bi”. Olu-iwa ni eni ti o je orisun gbogbo iwa rere aye. Bi enikeni ba si je omo re, oluwa re ko ni sai ni ekun iwa rere; eni ti o ko gbogbo iwa rere po, ti gbogbo elegbe ati olugba ka si ojulowo eniyan. Owe Yoruba ni “iwa rere ni eso eniyan”.
Abuda omoluabi po jantirere. Ara re ni owo, iteriba fun agba, osise, oninuure, onisuuru, eni ti ko je huwa abosi tabi ireje si enikeji. Awon ona ti omode le gba huwa omoluabi niwonyi:
(i) Ibowo fun Agba: Awon obi a maa ko awon omo bi won se gbodo maa bowo fun agba. Won ni “Omode to bam o owo we yoo ba agba jeun”. Eyi ni pe, omode to ba ni iwa pele ati iwa rere yoo ma aba awon agba rin. Oniruuru iwa rere ni omode le hu si agba.
Ekini ninu won ni ibowo fun agba. Owe Yoruba ni “Aibowo fun agba ni ki i je ki aye gun.” Omode ki i yaju si agba. Omokomo ti o ba daa an wo, iya ni iru won n je.
Ona keji ni pe, bi agbalagba ba n soro, omode ko gbodo pariwo tabi se ayonuso si oro ti agba ba n so. Ni ile Yoruba, omode to gbeko ki i da si oro ti won ko pe e si. Bee ni omode ki i da nnkan se laisi ase agbalagba nibe. Won a maa ko ni orin:
B’agbalagba ba n soro,
K’omode kekere a woye;
Kekere ko l’Erin fi ju Ekun lo
Oro gbogbo l’owe.”
Bakan naa, bi agba ba n sise ile, omode ko gbodo maa wo o niran. Ti omode ni lati bo si ibe ki o pin ninu ise naa se ni ona ti yoo fi fuye fun agba. Bakan naa, bi agba ba ru eru nibi ti omode wa, tabi n ru eru bo lati okeere, omode ni lati gba a lori re.
EKO ILE
Ni apeje, bi agbalagba ba pe leyin, ti ijokoo ko si fun un, eto omode ti o ba wa nibe ni lati dide fun un lati jokoo si aare re. Bi o ba si je wi pe won jo de si asiko kan naa, agba ni lati ko jokoo saaju omode. Ni oju agbo tabi ipade yoowu, bi won ba n pin nnkan, ti agba ni a o ko yan.
Omode, ko gbodo pe agba loruko. A maa n fi oruko omo pe agba ti a ko le la oruko mo ni ori. Bi apeere, ‘Iya Wale’, tabi ‘Baba Kudi’, tabi ki a kuku pe won ni baba, iya, tabi egbon eni. A ki i lo ‘iwo’ fun agbalagba. “E” to fi owo han ni a n lo. “E kaaro”, “E kuuse o”, ati bee bee lo. Okan pataki ni ikini je ninu asa ibowo fun agba.
Omode ko gbodo maa ki agbalagba ki o nawo si i lati bo won lowo, bee ni iwa afojudi ni ki a ma aba agbalagba soro pelu pako ni enu laaro.
“Iwa rere ni eso eniyan”. Omode ti o ba huwa rere si agba yoo ri oore gba, ojo re yoo si pe ni aye. Awon omode to n bo leyin re yoo si bowo fun un, nitori “Aseele ni abo-aba.”
(ii) Kiki eniyan bi o se ye ni gbogbo igba: Kekere ni awon obi ti n ko omo ni orisirisi ikini. Bi omodekunrin ba ji laaaro, eto ni ki o ki awon obi re ninu ile towo-towo. “E kaaaro o, Momo” tabi “Ejiire Momo mi”. Omode ni lati fi ara re han bi omo ti o gbekoo nipa didobale bi o ba je okunrin tabi kikunle, bi o ba je obinrin. Omode ki i duro gbagidi ki agbalagba. Abiiko ni won n pe iru omo to ba huwa omugo bee. Aaro nikan ko ni a n ki ni. Omode gbodo mo bi a se n ki eniyan ni osan, irole, ale ati nigba gbogbo. Bi omode ba n ki agbalagba, yoo lo oro eni pupo fun eyo agba kan soso: ‘Mo n ki yin ni o!’ ‘Mo ba won nile’, ‘Eyin ni mo n ki, sa! Ati bee bee lo.
“E kuule” n la a ki araale, ‘E ku ona’. n la a ki ero ona. ‘Omo olokun, abaja-lorun, maa wo ‘le’ o!’ n la a ki omolooku, bee ni ‘iyawo a bi ako a bi abo o’ tabi ‘eyin iyawo ko ni mo eni o’, ni a n ki eni to sese se igbeyawo osingin. Gbogbo ikini wonyi ni omo Yoruba gbodo mo lati ewe. Eyi le le die fun omode, sugbon ‘Tita riro la a kola, bi o ba jina tan, oge ni i da’. Mimo eniyan an ki ni akoko to ye ati ona to to n iyi fun ni.
(iii) Ninu iwa Rere ati Suure: Gege bi itan isenbaye, bi awon Yoruba se gba ORI gbo naa ni won gba IWA gbo. Won gba pe bi eniyan yan ori rere, bi ko ban i iwa rere, aye ati orun re ko le dara.
Iwa ti a n wi yii, obinrin ni ati wi pe aya Orunmila ni. Orunmila ko iyawo re Iwa sile nitori o ni obun pupo, Iwa si ko lo si ile Olodumare. Se omo Olodumare ni Iwa nitori pe oun ni i se akobii Suuru, to je aremo Olodumare. Nitori eyi ni a fi maa n so pe “Suuru ni baba iwa”. Igba ti Orunmila ko iwa sile tan, ni aye re ko ba dara mo. Ko ri se mo, ko ri je, ko ri mu, bee ni gbogbo eeyan lo n ri i ho. Nigba ti aye Orunmila waa dorikodo nitori pe iwa nu-un, lo ba mura lati wa obinrin re lo. Nitori “Bi iwa ba nu eeyan, aye re lo nu un….” Bayii ni Orunmila se bo sinu eku Eegun, o bere si i wa Obinrin re kaakiri. O wa a de’le Alara, eji osa, omo amurin kan dogbon agogo. O wa a de’le Ajero, omo ogboju koro ija jale. O wa a de’le Owarangun aga, amota ede, oniguru, agun f’owo laba owo teteete. O wa de gbogbo ilea won oloja mereerindinlogun, sugbon ko ri i. L’o bag bona orun lo. Nibe l’o ti war i Iwa. O bere si i be e pe ki o ba oun kalo si ile, sugbon Iwa ni oun ko lo. O wa ki Orunmila ni ilo pe ki o maa fi owo re tun iwa ara re se laye. Lati ojo naa l’o ti di wi pe owo onikuluku l’o fi tun iwa ara re se. eyi ko ni wi pe iwa ati suuru se pataki. Ara abuda eko ile ni.
Yoruba n ko omo pe bi a se n toju obinrin eni ni a se n toju iwa eni. Bi eeyan ba w alai ni iwa, egbe ati otubante ni. Won ni:
B’a a lowo
B’aa niwa
Owo olowo ni
Iwa, iwa l’a n wa o,
Iwa……
Ara awon iwa rere ti omo n ko ni ki a ma so otito, ki a si maa ni suuru. O ni:
Ibinu ko da nnkan kan fun ni
Suuru baba iwa
Agba t’o ni suuru
Ohun gbogbo l’o ko ja….”
Omode ki i wo agba loju, bee ni won ko gbodo su agba lohun bi won ba n ba won wi. Igbesi aye re gbodo maa je apeere suuru ati irele okan, ti yoo je awokose fun awon eniyan.
(iv) Ninu Iforiti: Iforiti se koko ni aye eda. Bi isoro ba de, a gbodo ko omode bi won se n fi ori ti i, ti won ko fi ni bohun tabi kaaare. Yoruba ni “Iforitu lo ni ohun gbogbo”. Iforiti ni a fi n segun isoro yoowu ti i baa doju ko ni. Pelu iforiti, omo yoo le se ohun ti won ro wi pe o koja ogbon ori re.
(v) Otito ati Oro Rere Siso: Otito siso je okan gboogi ninu ohun ti obi n ko omo lati kekere. Won ni ki a soro ki a baa bee ni iyi omo eniyan. Lati pinnisin ni a ti n ko omo pe iro pipa ko dara. “Oro rere ni n yo obi ni apo, oro buburu ni yo ofa l’apo.” Omo ni lati maa ni ohun rere lenu nitori oro enu eniyan lo n fi bi okan ati inu eni ti ri han. Omode ki i soro buburu lenu. Kaka bee o dara ki o maa woye. Omode gbodo mo igba to ye ki o soro ati igba ti o ye ki o dake. Gbogbo awon eko wonyi ni won sodo sinu eko ile.
(vi) Igboran: Igboran se pataki fun omode. Omode n ko bi a se n gboran si obi ati ebi lenu. Igboran ki i je ki omode sise. Awon agba ni “Aguntan ti o b aba ajar in dandan ni ki o je igbe”. Bee ni “A ki i pe ni lole ki a maa gbe omo ewure sere”. Imoran ni awon owe wonyi lati enu awon agba. Owe je ara ona ti awon Yoruba fi n ko omo ni eko ile. Omo ti o ba mu imoran agbo lo ni a n pe ni ologbon omo. “Omo ti a n ba wi to warunki, yoo parun ni ogan.” Oro agba ni.
(vii) Oninu-didun Olore: Bi omoluabi ni ohunkohun, inu re a maa dun lati fun elomiran ninu re. ohun to dara ni ki a maa se itore fun awon alaini ati arugbo.
Bi a se n ba eniyan gbe po ni irepo
Ifarada: A ni lati ni ifarada ki a to le gbe ni irepo pelu awon eniyan ni awujo. A gbodo year fun ohun to je mo ikanra ati iwa igberaga.
Imowa fun oniwa: Bi a ba n ba eniyan gbe po, a ni lati mo wi pe iwa wa ko le sokan. Tayewo ati Keyinde, ti won gbe inu kan naa fun osu mesan-an ko mu iwa kan naa waye. Lati wa ni irepo, a ni lati mo iwa fun oniwa.
Suuru nini ni akoko wahala: A ko gbodo je ki wahala tan wan i suuru. ‘Suuru lere’ ni awon agba wi. Ti a ba le ni suuru, ipepo wa ni awujo ko ni soro.
Yiyan ore to daralati ba rin: “Fi ore re han mi, ki n so iru eeyan ti o je. Ni awujo, a gbodo mo iru eni ti a o ba kegbe. Won ni “Agubtan to ba aja rin, a je igbe.” Egbe rere lo pe. Iru won ko ni si wahala, bee ni a o maa wan i irepo ninu ile ati ni ode.
Ife: Won ni “Ife ni akoja ofin”. Ki a feran omolakeji ni ofin ti Olorun fun wa ni. Ti ife ba wa ninu ile, ikoriira, aso tenbelekun yoo di ohun afin-seyin ti eegun n fi aso.
Ninu iberu Olorun: “Iberu Olorun ni ipinlese ogbon”. Bi a ba sun mo Olorun, ti a n ka oro re, ti oro re si n gbe inu eni, gbede bi o se n ro koko lehinkunle ni ibagbe wa pelu awon eniyan yoo ri. Bi a ba wa ninu Oluwa, ti Oluwa si n gbe inu wa, ko sewu loko, afi giiri aparo.
Awon ona bi a se n year fun iwa aito ni awujo
Nipa titele imoran awon obi eni
Mimo iru ore ti a oo bar in tabi lilodi si egbe buburu: aguntan to b aba ajar in yoo je igbe.
Ki a maa tele ofin Orile-ede
Nipa fifun ara eni ni ijanu nipa oro siso
Nipa rerun ni ona to to nigbogbo igba
Nipa titele ofin Olorun ti a gbo ninu iwaasu ati titeti si oro Olorun
Rinrin ni awujo awon olododo.

Ise Amutilewa
1. So ona marun-un ti a le gba huwa omoluabi
2. So ona marun-un ti a fi le year fun iwa aito lawujo

 

 

 

 

 

OSE KEJI
AKORI EKO: ATUNYEWO LORI SILEBU EDE YORUBA
Ninu oro ‘baba’ ege meji ni a ni: ‘ba-ba’. Ege kookan ni o ni iro faweli ati ami ohun. Ege kookan yii ni a n pe ni silebu.
ABUDA SILEBU
(i) Silebu le je iro faweli kan tabi iro konsonanti ati faweli. Apeere:
i – ya
ba – ba
ko – bo
e – gbon
(ii) Iye ibi ti ohun ba ti je yo ninu oro kan ni yoo fi iye silebu ti oro naa ni han. Bi apeere:
Ife – Ibi meji ni ohun ti je yo (Silebu meji)
Omuti – Ibi meta ni ohun ti je yo (Silebu meta)
Ikadii – Ibi merin ni ohun ti je yo (Silebu merin)
IHUN SILEBU
Apa meji ni silebu pin si. Awon ni:
Odo silebu
Apaala silebu
(i) Odo Silebu: Odo silebu ni ipin ti a maa n gbo ketekete ti a ba pe ege silebu kan. Ori re ni ami ohun n wa. Iro faweli tabi konsonanti aranmu asesilebu ‘n’ ni won le je odo silebu. Odo silebu ni a fala si nidii wonyi:
i-wa
i-gba-la
o-ro-n-bo
(ii) Apaala Silebu: Awon iro ti a ki i gbo ketekete ti a ba pe oro sita. Konsonanti inu silebu ni o maa n duro bii apaala silebu. Apaala silebu ni a fala si nidii wonyi:
i-wa
o-san
du-n-du
EYA IHUN SILEBU
(i) Silebu Onifaweli Kan (F): Eyi le je eyo faweli kan soso. Apeere iro faweli bee ni a fala si nidii wonyi:
A ti lo
Mo ri o
Mo ka a
Gbogbo iro faweli wonyi le da duro bii silebu:
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
a, e, ҿ, i, o, ϙ, u,
(ii) Silebu Alahunpo Konsonanti ati Faweli (KF). Apeere iru silebu bee ni wonyi:
wa, ba, bϙ, bҿ, ri, ra, mo, kϙ
gbϙn, ran, tan, rin, kun, wϙn
(iii) Konsonanti aranmupe asesilebu (N). Apeere iru silebu bee niyi:
n lϙ
o-ro-n-bo
i-sa-n-sa
PINPIN ORO SI SILEBU
Awon oro kan wa ti won ni ju silebu kan lo ninu ihun. Awon oro bee ni a pe ni ‘oro olopo silebu’. Apeere:
(i) Oro Onisilebu Meji
Oro
Ipin
Ihun
Iye silebu
ҿgbon
ifҿ
iku
Bϙla
Ҿ-gbon
i-fҿ
i-ku
Bϙ-la
f-kf
f-kf
f-kf
kf-kf
meji
meji
meji
meji

(ii) Oro Onisilebu Meta
Oro
Ipin
Ihun
Iye silebu
Idoti
Agbado
Ijangbon
Kansu
Gbangba
Banjo
Gende
Gbolahan
I-do-ti
a-gba-do
i-jan=gbon
ka-n-su
gba-n-gba
Ba-n-jo
Ge-n-de
Gbo-la-han
f-kf-kf
f-kf-kf
f-kf-kf
kf-n-kf
kf-n-kf
kf-n-kf
kf-n-kf
kf-kf-kf
meta
meta
meta
meta
meta
meta
meta
meta

(iii) Oro Onisilebu Merin:
Oro
Ipin
Ihun
Iye silebu
Ekunrere
Alangba
Opolopo
Olatunji
Mofiimu
Ankoo
Laaro
e-kun-re-re
a-la-n-gba
o-po-lo-po
O-la-tun-ji
Mo-fi-i-mu
a-n-ko-o
la-a-a-ro
f-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf
kf-kf-f-kf
f-n-kf-f
kf-f-f-kf
merin
merin
merin
merin
merin
merin
merin

(iv) Oro Onisilebu Marun-un
Oro
Ipin
Ihun
Iye silebu
Alaafia
Ogunmodede
Ogedengbe
Alagbalugbu
Agbalajobi
Nigbakuugba
a-la-a-fi-a
o-gun-mo-de-de
o-ge-de-n-gbe
a-la-gba-lu-gbu
a-gba-la-jo-bi
ni-gba-ku-u-gba
f-kf-f-kf-f
f-kf-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf-n-kf
f-kf-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf-kf
kf-kf-kf-f-kf
marun-un
marun-un
marun-un
marun-un
marun-un
marun-un

(v) Oro Onisilebu Mefa
Oro
Ipin
Ihun
Iye silebu
Gbangbayikita
Orogodoganyin
Afarajoruko
Alapandede
Konsonanti
Bookubooku
Gba-n-gba-yi-ki-ta
o-ro-go-do-gan-yin
a-fa-ra-jo-ru-ko
a-la-pa-n-de-de
ko-n-so-na-n-ti
bo-o-ku-bo-o-ku
kf-n-kf-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf-kf-kf
f-kf-kf-kf-kf-kf
a-kf-kf-n-kf-kf
kf-n-kf-kf-f-kf
kf-f-kf-kf-f-kf
mefa
mefa
mefa
mefa
mefa
mefa

ISE AMUTILEWA
1. (a) Ki ni Silebu? (b) So abuda silebu meji ti o mo pelu apeere
2. Ko apeere oro marun-un ti o ni konsonanti aranmupe asesilebu. Pin won si iye silebu.
3. Pin awon oro wonyi si iye silebu won:
(i) Akalamagbo (ii) Olododo (iii) Aworerin-in (iv) Akikanju
(v) Osoosu (vi) egbeegberun (vii) ileladewa (viii) igbaradi
(ix) iyaloosa (x) Akerefinusogbon

 

 

AKORI EKO: ATUNYEWO ISE ABINIBI
Ise ni oogun ise
Eni ise n se ko ma b’Osun
Oran ko kan t’Osun
I baa b’Orisa
O di’jo to ba sise aje ko to jeun
“Owuro lojo, ise la a fi i se ni Otuu’Fe”. Kaakiri ile Yoruba, ise ni won n fi owuro se. won gbagbo wi pe ‘Ise loogun ise’. Eredi ti won fi mu ise abinibi won ni okunkundun. Se ‘eni mu ise je, ko sai ni mu ise je’. Iran Yoruba lodi si imele, won gbagbo wi pe ‘owo eni ki i tan ni je’. Bi onikaluku ba ti ji idi ise ni won n gba a lo nitori ‘idi ise eni ni aa ti mo ni lole.’ Ibi ti baba bat i n sise ni omo yoo ti maa wo owo re, ti yoo si tibe maa ko o. won ni “Atomode de ibi oro n wo finnifinni, atagba de ibi oro n wo ranran.’ Owe yii fi han wa pe ko si ohun ti a fi omode ko ti a si dagba sinu re ti a ko ni le se daadaa. Eyi ni ise abinibi.
PATAKI ISE ABINIBI
Oje ise to se fi le omo lowo bi ise asela tabi ona ola
O n dana airise se laaarin ebi. Ko fi aaye sile fun arinkiri awon ewe. Yoruba ni: “Owo to ba si dile, ni esu n ya lo”.
Ko si pe a n dajo akoko ti omo yoo lo lenu ekose. Lati kekere ni yoo ti bere; ko si to ya ise lodoo baba re, yoo ti di okunrin, okan re yoo si ti bale si ise naa ni sise. Opolopo ise to ba n se, baba re ni yoo maa se sin titi ti baba re yoo fi ya ise fun-un. Ninu iwe wa kin-in-ni, a pin ise abinibi si isori merin wonyi:
Ise Agbe, ise ode, ise ona ati ise owo. Awon ise abinibi ile Yoruba ti a o yewo siwaju sin i: Ise Agbe, Ise Ajorin, Ise Alapata, Ise Onisowo, Ise Akope ati Ise Gbenagbena.
1. ISE AGBE
Ise agbe ni ise ti o gbajumo julo ninu ise ti won n se ni ile Yoruba. Awon agbe ni won n sogbon ounje, ti won n pese ounje fun awa eniyan. Ounje ti a n je ni o n fun ara wan i okun ati agbara lati sise oojo. “Ona ofun, ona orun”. Bee ni ‘bi ebi bat i kuro ninu ise, ise buse’.
PATAKI ATI IWULO ISE AGBE
Ipese Ounje
Ipese ohun elo fun awon ile-ise
Ipese ohun amusoro aje
Ipese ise
Agbe pin si orisii meji wonyii:
(i) Agbe Alaroje: Iwonba oko ti won yoo fi bo enu ebi ni agbe alaroje n da. Won n gbin agbado, ege, ogede, ata ati ewedu. Eyi ti won ba je ku ni won n ta ni oja fun ara ilu.
(ii) Agbe Alada-Nla/Oloko-Nla: Awon agbe wonyii ni awon ti n fi ise agbe sise se, ti won n da oko nla, ti won si n kore repete. Bi won se n ta ni oja adugbo, ni won n ko won on koja si ilu miiran. Awon agbe yii maa n gba opolopo osise onise odun. Won le ra eru tabi ki won ya iwofa.
ORISII ILE TI AGBE N DA
Ile Igbo: Ile igbo/egan dara fun ogbin igi owo bii koko, obi, orogbo, ope, osan, kofi, roba, agbon.
Ile Odan: Ile odan tabi papa dara fun ogbin agbado, isu, ege, egunsi, eree, okaa-baba, owu, epa, anamo ati eso bii mangooro, opeyinbo ati bee bee lo.
Ile Akuro: Ile akuro dara fun ogbin agbado, ila, ata, efo lorisirisi, ireke, ati awon eso bii oronbp, mangooro ati bee bee lo.
ORISII OKO
Orisii oko meji to wa ni:
(i) Oko Egan: Oko egan ni oko titun ti enikan ko ti i da ri. Igbo kijikiji ni. O maa n jinna si ile. Won maa n ni ahere ti won le seun tabi maa gbe, ti won yoo si maa wale ni osoosu, tabi leekan lodun. Awon ni a n pen i ‘Ara-oko’ tabi ‘Agbe-Arokobodunde’.
(ii) Oko Etile: Oko etile ki fi bee jinna si ile. Awon ti n da oko etile ki saaba sun ni oko. Bi won ba lo ni aaro, won le pada si ile ni ale. Opo igba ni oorun tanmode-soko maa n mu won on di orun si oko.
OHUN ELO ISE AGBE: Oko, Ada, Akoko, Aake, Idoje ati Obe
Awon isoro to n doju koi se agbe
Airi ohun-elo idako igbalode lo: Ada, oko ni won si n lo. Won ko ni anfaani lilo ero katakata iroko, ikobe, oogun ifinko, ipako ati bee bee lo.
Ayipada Oju Ojo: Oda ojo ni akoko ti ko ye tabi ojo arooda maa n se akoba fun ikore agbe;
Awon Eranko: Awon eye, kokoro ati awon eranko bii oya maa n ko lu oko, ti won si le mu ki oko, ti won si le mu ki oko maa se daadaa.
Agbe ni Ode-Oni: Ni ode-oni, tabi-tijoye, tokunrin-tobinrin ni won n sise agbe nitori irorun to de ba ise naa.
Awon ero katakata, ero-irole, tabi ikobe wa kaakiri ti won le ya ni owo pooku. Bee ni oogun igbalode buu ajile, korikori, taritari wa fun awon agbe onikoko.
Awon onimo ijinle, egbe alajosepo, ile ifowopamo ati egbe alajaseku wa ti won n ran awon agbe ni owo fun itesiwaju ise won.
2. ISE AJORIN
Ise ajorin ni awon ti won n sise irin jijo, ti a mo si ‘Weda’ ni ode-oni. Bi a pe won ni alagbede, a ko jayo pa nitori igbe kan naa ni ode won n de. Ise yii lowo lori pupo.
IWULO ISE AJORIN
Bi ko si ajorin, awon agbe ko le sise. Awon ni won n jo ada, akoro, aake tabi obe to ba kan, tabi oko ti o bay a.
Ni ode-oni, awon ajorin igbalode ni won n jo irin geeti ati ferese ile.
Awon naa ni won n jo awon ibi ti o ba je ni ara oko oju omi, oju-irin ati ti ori-ile, tatapupu, omolanke ati bee bee lo.
OHUN ELO WON: Ni aye atijo irinse alagbede ko ju owu, omo owu, iponrin, ewiri, emu ati eesan lo. Awon ajorin ode-oni n lo ina gaasi ati kanbaadi, irin ati bee bee lo.
ILANA IKOSI: Niwo igba to je ise abinibi, kekere ni omo won yoo ti maa fi oju si ise yii. Igba ti o ba dagba ni yoo to da ise ya.
3. ISE ALAPATA
Ise alapata je ise abinibi awon iran kan ni ile Yoruba. Awon okunrin ni won po nidii ise yii, bi o tile je pea won obinrin naa ko gbeyin ninu owo eran tita. Ise alapata je mo ise eran pipa, eran tita. Maluu pipa ni a mo won mo teleteleeri. Sugbon ni ode-oni won ti n pa ewure ati agbo ta. Won tile ti n ni awon odo-eran ti won ti n pa awon eran wonyi.
PATAKI ISE ALAPATA
Nipase awon alapata ni eran se n wo ile Yoruba lati oke oya ni opo yanturu. Awon ni won n seto bi won se n ko Maluu, Agbo ati Ewure wole.
Eni to mo oju ogun ni pa obi ni ‘Re’. Awon alapata ni won mo ogbon mimu awon eran wonyi ti won ba ja ni oriso, bi a se n pa won ati kikun won.
Ise kekere ko ni eran-jije n se ni ago ara. O n fun ara wa lokun, mu ki ounje wu ni je.
AWON OHUN ELO ALAPATA
Obe: Obe to mu sarasara ni won fi n pa eran yoowu ti won ba fe pa. obe naa ni won fi n kun un si iwon esipon ti a fe.
Ada: Ibi to le ni ara eran ni won n fi ad age. Bi apeere, ese eran, ori ati beebee lo
Aake: Ise kan naa ni alapata n fi aake ati ada se. aake wulo lati fi sa egungun ti ada ko ran tabi to le ba enu ada je. Won le fi aake fo ori Maluu, ese tabi eyin re.
ILANA IKOSE: Awon omo alapata maa n koi se yii lati kekere. Bi omo bas i se n dagbe si ni yoo maa mo apadelude ise siwaju sii. Ise yii yoo gba omode ni odun marun-un si mefa ki o to le gba ominira.
4. ISE ONISOWO (OWO-SISE)
Okan ninu awon ise abinibi aye atijo ni owo-sise. Awon iran Ijesa ni a ko mob ii onisowo aso. Awon ni a n pen i ‘Osomaalo’ ni aye atijo. Awon onisowo ni won n ra, ti won si n ta oja fun awon eniyan. Awon obinrin ni won po ju lo nidii ise-owo.
Ise owo pin si orisiirisii. Alajapa ni a n pe awon ti won n ra tabi ya nnkan oko bii koko, ogede, isu, elubo, gaari, osan ati bee bee lo. Awon miiran n sowo ate. A n pe won ni ‘alate’. Awon miiran si wa ti won je onisowo aladaa-nla, ti won n ta aso-ofi, bata ati bee bee lo. Bee ni eran-osin bii ewure, agbo, maluu, eja, bee ni awon miiran n sowo re. ise owo ni owo lori pupo.
PATAKI ISE ONISOWO
Won n je ki oja da arowoto awon onraja ni asiko
O n pese ise asela fun ontaja
Ko mu pakanleke lowo, bi eniyan ba se karamasiki oja to ni a yoo se ta si.
OHUN ELO ISOWO
Owo-idokowo: Owo ni a fi n pinle owo. “Bi owo bas i ti mo ni oogun un mo”. Bi owo ti a fi bere wow ba se po to nioja eni yoo se tobi si.
Ibi Isowo: Ibi ti a o ti maa se owo se pataki. O le je inu oja, iwaju ile eni tabi ni irona. Ibe gbodo je ojutaye, ti oja wa yoo ti ta.
Ipolowo Oja: ‘Ipolowo oja ni agunmu owo’. Awon onisowo maa n kiri tabi pate oja won ki a le mo ohun ti won n ta, ki aje le bu igba je.
ONA IKOSE: Omo le koi se-owo ni owo obi bi ise abinibi tabi ki o lo ko o bi awose. Won ni ‘Bi a se n kose ni a ko iyara’. Ijafara se pataki nidii ekose owo.
5. ISE AKOPE
Ise ohunrin ni ise akope. Okan ninu awon ise ti a ba lowo awon baba-nla wa ni. Tokunrin-tobinrin ni won mo riri ise yii. Awon ni won n ko eyin ope ti a fi n se epo-pupa. Ise elege ni.
Ise yii gba suuru ati aya nini. Eniyan to ban i ooyi oju ko le sise akope. Igba miiran wa ti owo palaba akope le segi, ki igba ja, tabi ki ese ye ni ara igi ope tabi ki ejo nla san won ni ori ope. Gbogbo nnkan wonyi lo le fa ki akope jao. Koko bii irin sin i idi igi ope maa n le. Idi niyi ti o fi je wi pe opo eni ti o ba ja lati ori igi ope ki i fi i ye. Eegun eyin tabi ti ibadii le kan, tabi run yegeyege. Idi igi ope naa ni won n sin oku bee si.
PATAKI ISE AKOPE
Ipese epo isebe: Epo ni iroju obe. Bi ko si akope, obe efun ni a ba maa je.
Ipese Owo ati Apere: Imo ti akope ge lule lati ori igi open i a fi n fa owo ti a tun n fi ifon re hun apere. Bi owo ko si bi akitan ni ilr ati ayika i ba da. Bi agbon ko bas i ni ahere, owo ni a ba fi ko isu wale.
AWON OHUN ELO AKOPE
Igba: Igba ni okun agba ti won lo pot i akope fi n gun igi ope. Igba yii maa n gbopon, bee ni a maar o.
Aake: Aake ni akope n fi i re imo danu, ki o le ri aaye geo di eyin lule.
Ada: Akope le fi ad age imo ori ope, bakan naa ni o le fi sa odi eyin lule.s
EKOSE: Bi o tile je omode le maa fi oju si bi won se n gun ope, o gbodo di gende ki o le da ko ope. O le bere lati ori opekete. Eyi ni ope kekere ti owo lee to eyin ori re ni ile. Won ni “Opekete n dagbe, inu adamo n baje”.
6. ISE GBENAGBENA
Ise gbenagbena je okan pataki ninu ise ti a ba lowo awon baba-nla wa. Awon okunrin ni won n sise yii. Ise yii je ise ti toba-tijoye n karamasiki re. awon ni won n gbe igi opo-ile, ilekun, apoti ijokoo Oba. Won le fi igi gbe Ekun, Ologbo, Odidere, Erin ati orisirisii ere, apeere awonti a n ba pade ni aafin Oba tabi ilea won olola ati awon ijoye. Awon ni won n gbe opon-ayo, opon-ijeun, orisii ere fun ilo awon ara ilu ati awon ti a n ri ni iyara ikohun-isebaye-si bi eyi ti o wa ni Ile-Ife ati Binni. Gbenagbena naa ni won n se eeku ada, igi oko, igi aake ati bee bee lo fun ilo awon agbe. Owo tabuu ni won n pa.
PATAKI ISE GBENAGBENA
Ko je ki asa wa lo si okun igbagbe
O je ona ipawo wole si apo gbenegbena
O je ona ipawo wole fun Ijoba, ti wo ba fi awon ere wonyii sowo si oke okun
O pese ise fun awon odo
AWON OHUN ELO WON:
Aake: Aake ni gbenagbena fi n ge igi ti won fi n gbe ere lule, ti won yoo sig e si orisiirisi ike
Ada: Ada ni a n lo dipo aake lati ge igi ti a fe lo si ike-ike. Ohun naa ni a fi n bere ere gbigbe
Obe: Ti ise ba de ibi elege bii ki a fe se oju, imu, eti, enu, oyan-aya, obe ni a n lo. Oun ni won fi n gbe ara nnkan, ki o le dan daadaa. Bi won se ni obe nla ni wo ni kekere ti won fi n dan ara ere tabi opa itile.
Osese: Oseseni a fi n da iho sinu igi ti a fe fi gbe ere tabi ara nnkan miiran ti a fe gbe
Orisii Igi ti won n lo
Igi Iroko tabi Oganwo: Igi wonyi le pupo. Awon ni a fi n gbe odo, opa itile.
Igi Awun: Igi yii ko le koko bii igi iroko tabi oganwo. Oun ni a fi n gbe ere, opon-ayo.
ILANA IKOSE: Awon ti won ba je omo gbenagbena le bere lati kekere. Won yoo si lo to odun mewaa ki won to mo ise naa dunju. Awon ti won wa ko ise yii bi awose yoo lo bii odun marun-un si mefa ki o to gba ominira.
Ni ile Yoruba, ni ojo igbominira, ti o ba je ise awose, oga yoo fi oti ibile tabi oyinbo gba adura fun omo ekose. Awon obi omo-ekose naa yoo gbe ohun jije-mimu kale lati je ki won mu.

ISE AMUTILEWA
So pataki ise isenbaye
So iwulo ise abinibi meta
So orisii ise abinibi meta ki o si daruko ohun elo ise won
So pataki ise agbe marun-un

 

 

 

 

 

 

 

OSE KETA
AKORI EKO: AROKO ONI-SORO-N-GBESI
Aroko ti a ko to da lori itakuroso laaarin eniyan meji tabi ju bee lo ni a n pen i aroko oni-soro-n-gbesi.
Abuda Aroko Onisoro-n-gbesi
O maa n ni akopa bii ere ori itage
Oro enu akopa kookan maa n han ni iwaju oruko won
Iso bee ko gbodo gun ju, ko si se regi
Oro erin ati awada kii gbeyin, a si gbodo year fun awada ako
Isesi won ni a maa n fi sinu ami akamo olofo ( ).
E je ki a ka aroko oni-soro-n-gbesi yii wo, bi apeere:
(Won sese gbe oga titun kan de si ile-iwe re, ko iforo-jomi-tooro oro to waye laarin akekoo meji lori oga titun yii sile).
OGA TITUN
(Ranti ati Yemisi wa ni Kilaasi S.S.2. Won pade ni ikorita meta ni eba ile ounje. Yemisi fe lo kawe, Ranti fe lo pon omi)
Ranti: (o sunmo Yemisi) E ma si ku amojuba t’Oga titun
Yemisi: Baa se ki ni naa nu un. N o kuku tii ri won soju
Ranti: Ma je k’aye o gbo. Iya to wa si ipade apejopo akekooati oluko ni aaro ana
Yemisi: (o mo’ju tai) Se won ni mow a n’be ni? Mo pe de. Kilaasi ni mo gba lo taara
Ranti: Eyin isa-n-sa. Oju yin re e. ipade ohun ma larinrin
Yemisi: Ki lo sele? Won fun yin lo’oyin la? Gbee si mi leti, joo
Ranti: Oyin ko, ado ni. Won kan fi oga han wa ni. Oun alara si gba wan i iyanju pe ki a tepa mose.
Yemisi: Eyuun lo wa mu ipade dun? Osise ni wan i?
Ranti: Ki lo fe ki iya-oniyaa so? Oro iyanju ni akekoo n fe. Abi lo fe ko so. O kuku ti se’pade pelu awon oluko ati awon pirifeeti.
Yemisi: (O tewo pe e) Igba wow a ni ‘pade tiwa? Abi?
Ranti: Ipade wo ni o fe ki Alaaja tun ba wa se?
Yemisi: Wa na, se Musulumi ni?
Ranti: Musulumi ponbele ma ni. O kirun ju awo lo. Oro po. Iya naa le soro lataaro dale!
Yemisi: Awon akekoo Musulumi bo saye nu un. Logan ni yoo ko Mosalasi ti won ti ko pati lati bi odun merin.
Ranti: O ma ni oun ko boroesin wa. O ni bi esi idanwo asejade wa yoo se gbe peeli soke sii ni o je oun logun.
Yemisi: Too. Olorun a fun un se. Awon alale a tii leyin
Ranti: Ti awon alale ti se wa je ninu oro ile iwe?
Yemisi: Ki lo fe n so? Se bi, won ni ‘Isese lagba’?
Ranti: Ooto ma kuku ni. Obatala a ba a f’ase sii
Yemisi: Ase o
(won pinya)
ALAYE
Iwontunwonsi afo enikookan se regi. Ede won lo taara, bee ni awada ibe mo niwon. Akekoo
meji pere ni a lo. Ko dara ki akopa po repete.

ISE AMUTILEWA
Ko abuda aroko oni-soro-n-gbesi marun-un ti o mo
Ro o lokan ara re pe iwo (Femi) ati ore re (Bayo) lo woran are Boolu afesegba to waye laarin Super Eagles ati iko agbaboolu Argentina. Super Eagles feyin won bale ni amin ayo merin si ookan. Eyin mejeeji wa n foro jomi-tooro or obo wa si ile. Bi oro naa se lo re e:
AARE BOOLU
Femi: Boolu ale yii ko yoyo, o dun yato. Abi?
Bayo: Bee ni. Mo gbadun re gan an ni. Ki lo ri si ayo ti Kola gba wole ti Refiri fagi le un?
Femi: Mo rii. O dun mi wonu eegun. O dabi eni pe Refiri ti fon fere ki Kola to gba boolu naa s’awon.
Pari iforowero yii. Lo awon gbolohun ibeere ati ede iepri to je mo are boolu afesegba.

 

 

AKORI EKO: ONA IBANISORO
Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.
Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.
Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba. Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.
A. ONA IBANISORO NI AYE ATIJO
1. Lilo Eya Ara fun Ibanisoro: Eya ara ti a n lo fun Ibanisoro je awon eya ara ti a le gbe soke-sodo, ti eni ti a n fii ba soro le ri. Eni bee le wan i egbe eni tabi wa nibi ti ko jinna. Apeere awon eya ara naa niwonyi:
(i) Oju: Oju se pataki ninu eya ara ifo. Bi apeere, a le fi oju fa ‘ni mora’, kilo fun eniyan bee ni a le fi na eniyan lailo pasan. Eni ti o ba kuna lati mo eyi ni won n bun i alaimojumora. Bi apeere,
AMI
ITUMO/ALAYE
Ti a ba n soro, ti a wa se oju si eni naa
Ki o joo, gbe si mi leyin
Ki o dake, pe enikan n bo
Ti a bam o eniyan loju
N ko gba tire. Ami ija ni eyi
N ko fara mo oro ti o n so
Fe oju mo omode
A fi n deru ba a ni
Ti a ba fi odo oju tabi oju isale wo eniyan
Ami ife ni. Okunrin le fi oju isale wo obinrin.

(ii) Ori: Ipa pataki ni ori n ko bii ona Ibanisoro. Igba miiran, eniyan le so ori ko, won a ni oluware n ronu. Bi o ba n fi owo ja ori, to n fi ese jale, ajalu laabi kan ni o sele sii. Bi apeere:
AMI
ITUMO/ALAYE
Ti awon eniyan bag be ori so si nnkan ti a n se
O dara. Maa se lo
Ti won ba gbon ori
Ami ikaaanu ni naa tabi ilodi si nnkan to n se.
Ori gbigbon
Rara o. lati fi ilodi si han
Ti won ba bi wa leere oro, ti a mi ori
Tooto ni. Bee ni, tabi bee ko
Ti a ba mi ori si isale
A pe eniyan pe ki o wa
Ori mimi sotun-un, sosi
Rara o tabi bee ko

(iii) Imu: Yoruba kii dede yin imu ti ko bas i ija tabi ikunsinu. Bi apeere:
AMI
ITUMO/ALAYE
Ti a ba yinmu si eniyan
A n fi eni naa sefe ni, wi pe a ko ka oro ti eni naa n so si rara

(iv) Enu: A le lo enu lai ya a tabi sii raa. Bi apeere:
AMI
ITUMO/ALAYE
Ti a ba yo suti tabi yege enu si eniyan
A n fi eni naa se yeye ni tabi pe oro eni naa ko mu ogbon wa
A le fi enu sufee
Ko si oro ti a ko le fi so

(v) Ejika:
AMI
ITUMO/ALAYE
Bi a ba n ban ii soro ti a gbun tabi so ejika
Mo gba oro naa wole bii otito
Mo lodi si oro naa

(vi) Ese:
AMI
ITUMO/ALAYE
Bi a ba fi ese janle
Ami ilodi si nnkan kan ni eyi je
Tite eniyan lese mole
A n kilo fun un pe ki o ma se nnkan kan tabi ki o dake
A le fi pe akiyesi re si nnkan kan
Fi ese mole
A fi n han pe a ko nifee si ohun ti enikan n so.

(vii) Eekanna
AMI
ITUMO/ALAYE
Sise ni leekanna
Ikilo nip e ki o dake oro tabi fi pe akiyesi re si nnkan kan

(viii) Owo: Ilo owo bi ona ibanisoro po. A le ju owo si eniyan pe ki o wa, bee ni o le ya owo kan naa yii lati bun i.
AMI
ITUMO/ALAYE
Bi a ba sewo si eniyan
Ki o wa tabi ki o duro de wa
Ti a ba juwo si eniyan
A n kii ni
A n dagbere fun un pe ‘O digba o se’
A n le eni naa siwaju
Ti a bay a owo si eniyan
A n bu iya eni naa ni

(ix) Ete: Orisiirisii ona ni a le gba lo ete lati soro. Apeere.
AMI
ITUMO/ALAYE
A le yo suti ete
Lati fi saata tabi bun i
A le yo ete si enikan
Lati juwe tabi so ibi ti nnkan wa

IPAROKO
Aroko je ona kan ti an gba ba ara eni soro ni aye atijo. Bi awon agba ba fe soro asiri ti eni ti won fe so o fun ko si nitosi, tabi ti won ba fe ranse sile ni asiri, aroko ni won n lo. Aroko pipa ranse si ni ko gba sise alaye repete. Aroko ni yoo tumo ara re fun eni ti a ba ran an si.
Die ninu egbaagboje ona ti awon baba-nle wa n gba paroko ranse si eniyan ni wonyii:
(i) Ilu Lilu: Ni ile Yoruba, ilu n koi pa pataki ninu ona ibanisoro ni aye atijo. Ko si ohun ti won ko le fi wi. Ilu ni awon baba-nla wa fi maa n ranse si oju ogun. Bi ogun bag bona janjan, ilu ni won n ki awon asaaju.
(ii) Edan Ogboni: Edan je orisii opa Ogboni kan ti o maa n ni ere ni ori re. bi enikan ba je gbese, ti won wa fi edan Ogboni ranse sii, eni naa ko gbodo jafara bi o bat i rii gba. O ni lati wa owo na san kiakia. Eyi je asa larin awon Egba.
(iii) Opa Ase: Oba nikan ni o n fi opa ase paroko. Nitori pe kii se gbogbo ode ni Oba le e lo, opa ase yii ni Oba maa n gbe ranse lati fi han wi pe oun wa nibe. Bi Oba bas i fe ri enikan ni kiakia, opa ase ni yoo fi ranse sii.
(iv) Irukere: Oba, Baale, Ijoye ati agba-awo ni won n fi irukere paroko. Ti won bay o eyo irun irukere kan, ki won ta ni koko si inu aso pupa, ti won ba fi ranse si enikan, apeere ija tabi wiwa pipon onu eni tabi pe ija n bo niyi.
Awo Edun
Sigidi
Iye Adie
Ebiti ati Awo Ehoro
Owo-Eyo Meta
Aso Ibora
Igbale
Eepo igi ose ati aso pupa
Idaji agbe emu tabi ajadii agbe
Esun-isu
Igi sisa loge
Morinwo tabi Aso Pupa
Eni
Eeru
Awon aroko to je mo Onka: Iwonyi ni awon ami aroko to je mo onka Yoruba. Apeere:
AMI
ITUMO/ALAYE
Eeta
Ti a ba fi nnkan meta ranse si eniyan, o tumo si pe a ta onitohun danu.
Aarun-un
Awon onifa ni won n lo lati so fun eni naa ki o se kankan lori ohun ti o mu ni paroko naa ki ojo marun-un to pe
Eefa
Ami ife ni eyi n toka si. Okunrin le fi ranse si obinrin pe ki awon fi ara mora.
Eeje
Ojo ije egungun ati oro. O tun le tumo sip e ki eni ti a paroko ranse si ri ni ki ojo meje to pe
Eejo
Bi a ba fi nnkan mejo paroko ranse sin i, to ba je owo-eyo, o tumo si pe ko si ewu loro eni naa nitori ile jo
Eesan-an
Ami ki eniyan so ewe agbeje mowo niyi, paapaa si eni to n du oye. A fi so fun un pe “Ilesanmi dun ju oye lo”.
Eewaa
Ti a ba fi owo-eyo mewaa ranse si eeyan, o tumo sip e ki o wa. Won ni “Eewaa kii wa eni tire ti.”

Awon aroko to je mo awo
Awo
Ohun to duro fun
Funfun
Nnkan mimo/alaafia
Dudu
Nnkan buburu. Obinrin to n sofo maa n wo aso dudu
Pupa
Ohun to lewa. Pupo ni aso orisa Sango ati Esu

Awon aroko to je mo iro: Awon ohun elo ibanisoro ni a fi n gbe iro jade niwonyii:
Ohun-elo
Alaye ilo won
Fere
Fere le je eyi ti a fi irin, igi tabi iwo eran se. orisii fere to wa ni: Pakuta, Anbere, Tioko, Kakaki, Turumagbe, Talaka, Ekuku, Ti-an-ko, Iwo ati bee bee lo.
Awon ode n fon ekutu ati tioko laarin ara won
Won n lo fere lati pe ara won ni igbe ode
Won n fon kakaki lati fi ki Oba ni Aafin
Agogo
Orisii agogo lo wa:
Alagogo Oba maa n lu u lati fi pe eniyan jo lati jise Oba
Agogo orun aja ni lati mo ibi ti aja ode wa ninu igbo
Agogo ifa ati ilu aran tabi ipese ni awon awo n lo ki ohun didun le jade
Agogo ode asode ni lati kede pea won ti gbode

B. IBANISORO AYE ODE ONI
Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.
Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:
Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859. Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko” jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan. Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n waye.
Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta, gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:
Agogo ile isin lilu – lati pe eeyan wa josin ni soosi
Agogo omo ile wa – lati fi pea won akekoo wole
Agogo onisowo – lati fi fa onibara won mora.
ISE ASETILEWA
So marun-un lara ona ibanisoro ti o mo
So awon eya ara marun-un ti a fi n ba ara eni soro
Daruko marun-un ni ara ona ibanisoro ni aye ode oni
OSE KERIN-IN
AKORI EKO: ATUNYEWO IHUN ORO
Iro konsonanti ati iro faweli pelu ami ohun ni a n hun po di oro. Orisi oro meji ni o wa ninu ede Yoruba. Awon ni:
Oro ipinle; ati
Oro ti a seda
1. ORO IPINLE: Oro ipinle ni awon oro ti a ko le seda won. Apeere:
Adie, eedu, omi, ori, oju, imu, eti, apa, ese, owo, ile, oba, odo, ojo, agbara, omo, iya ati bee bee lo.
Abuda Oro Ipinle
Oro-ipinle maa n ni itumo kikun
A ko le seda won. Bi apeere:
Iya: a ko le so pe *i+ya lo di ‘iya’
Ori: a ko le so pe *o+ri lo di ‘ori’
Omo: a ko le so pe *o+mo lo di ‘omo’
Oba: a ko le so pe *o+ba lo di ‘oba’
Oro ti a seda ati oro-ipinle awon oke yii ko ni ijora itumo. Idi niyi ti a fi pe won ni oro ipinle ti a ko le seda rara.
2. ORO ASEDA: Eyi ni awon oro-oruko ti a seda nipa lilo afomo tabi oro miiran.
Abuda oro ti a seda
Oro aseda maa n ni oro ipinle ati afomo tabi oro miiran ti a fi kun un. Apeere:
Afomo ibeere Oro-Ipinle Oro ti a seda
a + de = ade
o + re = ore
(ii) Oro ipinle ati oro-oruko ti a seda gbodo ni ijora itumo. Apeere:
Oro-Ipinle Oro ti a seda
a + de = ade
o + re = ore
(‘de’ ati ‘ade’ ni itumo ti o jade. ‘de’ tumo si ki a fi nnkan bo nnkan ni ori; ‘ade’ ohun ti a de. ‘re’ ati ‘ore’ ni ijora itumo)

ORISII ONA TI A N GBA SEDA ORO-ORUKO
A le seda oro-oruko nipa awon ona wonyii:
Lilo Afomo
Akanpo Afomo Ibeere ati Oro Ipinle. Akanpo bee yoo di oro-oruko. Bi apeere:
Afomo Ibeere
Oro Ipinle/Oro-Ise
Oro-oruko ti a seda
A
a
o
o
ϙ
ϙ
ai
ai
on
on
ati
Yo
se
sise
ku
gbon
re
sun
gbagbo
te
kawe
je
ayo
ase
osise
oku
ogbon
ore
aisun
aigbagbo
onte
onkawe
atije

Akanpo afomo Ibeere ati ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarjoruko. Apeere:
Afomo Ibeere
Mofiimu Ipinle
Oro-oruko ti a seda
oni
oni
oni
ti
ti
Iranu
eja
aso
emi
eyin
oniranu
eleja
alaso
temi
teyin

Akanpo afomo ibeere ati oro ipinle to je oro-oruko tabi aropo afarajoruko. Apeere:
Afomo Ibeere
Oro-Ise
Oro-Ise
Oro-oruko ti a seda
A
i
i
Da
tan
gba
ko
je
la
adako
itanje
igbala

Lilo Afomo Aarin: ‘ki’, ‘de’, ‘ku’, ‘si’ ni aarin apetunpe oro ipinle to je oro-oruko. Apeere:
Mofiimu Ipinle
Afomo aarin
Mofiimu ipinle
Oro-oruko ti a seda
Ile
owo
iran
oro
iwa
eniyan
Si
de
de
ki
ki
ki
ile
owo
iran
oro
iwa
eniyan
ilesile
owodowo
irandiran
orokoro
iwakiwa
eniyankeniyan

(ii) Sise Apetunpe Kikun. Eyi le waye nipa:
Apetunpe Oro-Oruko
Oro-Oruko
Oro-Oruko
Oro-oruko ti a seda
iya
ose
odun
osu
ogorun-un
iya
ose
odun
osu
ogorun-un
Iyaaya
Osoose
Odoodun
Osoosu
Ogoogorun-un

Apetunpe Apola-Ise
Apola – Ise
Apola – Ise
Oro-oruko ti a seda
jaye
gbomo
wole
pana
jaye
gbomo
wole
pana
jayejaye
gbomogbomo
wolewole
panapana

(d) Apetunpe Elebe: Eyi n waye ti a ba fe dunrun mooro-ise. A o so oro-ise to je mofiimu ipinle di meji, ki a way o faweli ara oro-ise akoko sonu, a o wa fi faweli ‘i’ olohun oke ropo re. bi apeere:
Oro – Ise
Konsonanti to bere oro – ise
Mofiimu ‘i’
Oro-oruko ti a seda
Ra
ka
bi
we
R
k
b
w
i
i
i
i
rira
kika
bibi
wiwe

(iii) Sise Akanpo Oro – Oruko. eyi le waye nipa:
Akanpo oro-oruko meji inu eyi ti aranmo yoo ti han
Oro – oruko
Oro – oruko
Oro-oruko ti a seda
owo
ona
agbo
ewe
ile
ile
ile
obe
owoole
onaale
agboole
ewebe

Abranpo Oro-oruko meji inu eyi ti aranmoyoo ti han
Oro – oruko
Oro – oruko
Oro-oruko ti a seda
ara
enu
irun
Iwaju
ona
agbon
araawaju
enuuna
irungbon

(d) Akanpo Afomo Ibeere ati Apetunpe Oro-Oruko. Apeere:
Afomo Ibeere
Oro – Oruko
Oro – Oruko
Oro-oruko ti a seda
oni
oni
ojumo
osu
ojumo
osu
olojoojumo
olosoosu

 

(e) Akanpo Afomo Ibeere ‘oni’ mo oro-oruko meji. apeere
Afomo Ibeere
Oro – oruko
Oro – Oruko
Oro-oruko ti a seda
oni
oni
ori
aya
ire
oba
oloriire
alayaa

(iv) Sise asunki odidi gbolohun di oro-oruko. apeere
Gbolohun
Oro-oruko ti a seda
Oluwa to sin
A kuru yejo
Oluwatosin
Akuruyejo

(v) Siso oro-oruko onigbolohun po. Apeere:
Ifa ni eti – Faleti
Oye ba mi ji – Oyebamiji
Aje wo ile – Ajewole
(vi) Lilo ami asoropo oro onigbolohun. Apeere
a-duro-sigidi-koogun-o-je
a-losoo-gongo-je’su-eba-ona.

ISE AMUTILEWA
Se itupale akojopo oro-oruko eniyan ti a seda wonyii:
Faleti
Omolola
Ifeolu
Titilayo
Ilesanmi
Iluyomade
Adeoti
Olukoyejo
Adeyemi
Oladiran
Pin awon oro-oruko wonyi si eyi ti a seda ati eyi ti a ko seda
Igunpa
Imu
Aso
Oguntoye
Oko
Ese
Oju
Inufele
Erupe
Eti
AKORI EKO: ITESIWAJU EKO LORI ONA IBANISORO
Ibanisoro ni ona ti eniyan meji tabi ju bee lo n gba fi ero inu won han si ara lona ti o fi ye won yekeyeke. Ona yii ni a n pen i ede. Ede ni o n fun ohun ti a n so ni itumo. Bi eni meji ti won ko gbo ede ara ba n soro, bi ariwo lasan no ohun ti won n so.
Ni aye atijo, awon baba-nla wa kii fi gbogbo enu soro. Won gba wi pe ‘gbogbo aso ko la n sa loorun’. Awon ona kan wa ti won n gba ba eni to sun mo won, to wa nitosi tabi ona jijin soro lai lo enu. Se “Asoku oro ni je omo mi gb’ena”. Won a maa lo eya ara tabi fi nnkan miiran paroko ranse si won, ti itumo ohun ti won soyoo si ye won.
Ni ode-oni ewe, irufe ona ibanisoro yii wa, bi o tile je wi pe ona igbalode ni won n gbe e gba. Gbogbo nnkan wonyi ni a o yewo finnifinni.
IBANISORO AYE ODE ONI
Ni ode-oni, ede ni opomulero ona ibanisoro. Ede ni a fi n se amulo agbara lati ronu ti a o si so ero inu wa jade fun agboye: ti a fi n salaye ohunkohun. Ohn ni a fi n ba ni kedun, ti a n fi n ban i yo, ohun ni a fi n ko ni lekoo ni ile ati ile-iwe. Ede ni a fi n gbani ni iyanju, ti a tun fi n danilaraya. Pataki ede ni awujo ko kere.
Bi ko bas i ede, redio, iwe iroyin ko le wulo. Ede ni redio ati telifison fi n danilaraya, ti won fi n ko ni lekoo, ti won fi n royin. Olaju esin ati ti eko imo sayensi ti mu aye lu jara nipa imo ero. Awon ona ibanisoro ode oni niwonyi:
Iwe Iroyin: Ipa pataki ni iwe iroyin n ko bii ona ibanisoro. Henry Town send ni o koko te “Iwe Iroyin fun awon Egba ati Yoruba” jade ni ede Yoruba ni odun 1859. Eyi ni iwe iroyin akoko ni ede Yoruba. Leyin re ni “Iwe Irohin Eko” ti A.M. Thomas je olootu re jade ni odun 1888. Odun 1891 ni Eni-owo J. Vernal gbe “Iwe Eko” jade. Eyi fi han wipe ojo iwe iroyin tip e ni ile Yoruba.
Telifison: Ile Yoruba naa ni Telifison akoko ni ile eniyan dudu ti bere ni ilu Ibadan. Bi oruko re “Ero-Amohun-Maworan” ni a n pe o. anfaani gbigbo oro ati riri aworan awon eniyan inu re wo je iranlowo ti ko ni afirwe ninu gbigbe ede ati asa Yoruba laruge. Ona kaan naa niyi ti a fi gbe ero eni si ori eto, ti ibanisoro si n waye.
Redio: Ojo redie naa tip e ni ile Yoruba. Bii oruko re ‘ero-asoromagbesi’, oro lasan ni a n ti won n so ni ori eto okan-o-jokan won. Anfaani wa fun eniyan lati gbe ero won si ori afefe lati fi danilaraya, ko ni lekoo, ni lekoo ati fi laniloye.
Pako Alarimole lebaa Titi ati Ina Adari-Oko: Awon patako alarimole wa kaakiri oju popo ti won n juwe tabi dari eni si opopona laarin ilu-nla-nla. Bee ni ina adari-oko wan i ojuu Popo ti won n dari oko. Awon meta ni awon fi n paroko lilo ati diduro oko ni ikorita. Awo pupa duro fun ‘duro’, ewu wa lona; awo olomi osan ni ki a si ina oko ni imura sile lati lo, bee ni awo ewe ni ki oko maa lo.
Ero-Aye-Lu-Jara: (Intaneeti). Ero ayelujara je gbagede agbaye to si sile fun teru-tomo, ti a le lo, to si wan i arowoto gbogbo eniyan.
Leta Kiko: Leta kiko je aroko aye atijo ni orisiirisii ona. Gbigbe ni a n gbe leta, gbigbe naa ni a n gbe aroko ti a ba di ni gbinrin, titu ni a n tu apo-iwe lata, titu naa ni an tu gbinrin ti a di, kika la n ka leta, wiwo ni a n ami aroko. Igba ti won bat u u ni won yoo to mo ohun to wa nibe.
Foonu: Oro naa ni a n so si inu foonu ti eni to wan i odikeji ti a pe n gbo. Bi oun naa ba fesi awa ti a pe naa yoo gbo. Ona ibanisoro yii di ilumoka ni ile Yoruba. A le wan i Eko, ki a ma takuroso pelu eni to wan i ilu Oyinbo!
Agogo: Bi o tile je pe agogo je ohun-elo iparoko aye atijo, won si n lo won bi ona ibanisoro ni ode-oni. Bi apeere:
Agogo ile isin lilu – lati pe eeyan wa josin ni soosi
Agogo omo ile wa – lati fi pea won akekoo wole
Agogo onisowo – lati fi fa onibara won mora.

 

 

 

 

 

 

 

 

OSE KARUN-UN
AKORI EKO: ONKA YORUBA (EGBAA de AADOTA OKE)
Igba mewaa (200 x 10) ni a n pe ni egbaa. A le wa ka a bayii:
Onka Geesi
Onka Yoruba
Alaye ni Yoruba
Alaye ni Geesi
2,000
4,000
6,000
8,000
10,000
12,000
14,000
16,000
18,000
20,000
Egbaa
Egbaaji
Egbaata
Egbaarin
Egbaarun-un
Egbaafa
Egbaaje
Egbaajo
Egbaasan-an
Egbaawaa (oke kan)
Igba lona mewaa
Igba lona ogun
Igba lona ogbon
Igba lona ogoji
Igba lona aadota
Igba lona ogota
Igba lona aadoje
Igba lona ogoje
Igba lona aadorun-un
Igba lona ogorun-un
2,000 x 1
2,000 x 2
2,000 x 3
2,000 x 4
2,000 x 5
2,000 x 6
2,000 x 7
2,000 x 8
2,000 x 9
2,000 x 10

E je ki a lo egbaa lati se onka nipa fifi egbaa pin iye onka ti a ba fe ka, ji a to maa kaa loke loke.
Onka Geesi
Alaye ni Geesi
Onka Yoruba
Alaye ni Yoruba
30,000
32,000
34,000
36,000
38,000
42,000
44,000
46,000
48,000
52,000
54,000
56,000
58,000
2,000 x 15
2,000 x 16
2,000 x 17
2,000 x 18
2,000 x 19
2,000 x 21
2,000 x 22
2,000 x 23
2,000 x 24
2,000 x 26
2,000 x 27
2,000 x 28
2,000 x 29
Egbaa meedogun
Egbaa merindinlogun
Egbaa metafinlogun
Egbaa mejidinlogun
Egbaa mokandinlogun
Egbaa mokanlelogun
Egbaa mejilelogun
Egbaa metalelogun
Egbaa merinlelogun
Egbaa merindinlogbon
Egbaa metadinlogbon
Egbaa mejidinlogbon
Egbaa mokandinlogbon
Egbaa lona meedogun
Egbaa lona merindinlogun
Egbaa lona metadinlogun
Egbaa lona mejidinlogun
Egbaa lona mokandinlogun
Egbaa lona mokanlelogun
Egbaa lona mejilelogun
Egbaa lona metalelogun
Egbaa lona merinlelogun
Egbaa lona merindinlogbon
Egbaa lona metadinlogbon
Egbaa lona mejidinlogbon
Egbaa lona mokandinlogbon

‘o din’ tabi ‘o le’ ni a o maa lotiti de ori onkaye ta a n fe. Bi apeere: 30,400 je egbaa meedogun o la irinwo, 51,000 ni egberundilogbon; 57,991 je egbaa mokandinlogbon o din mesan-an; 58,008 je egbaa mokandinlogbon o le mejo. Lati ori 20,000, a le wa ma aka oke bayii:
Onka Geesi
Alaye ni Geesi
Onka Yoruba
Alaye ni Yoruba
40,000
60,000
80,000
100,000
120,000
140,000
160,000
180,000
200,000
220,000
240,000
260,000
280,000
300,000
400,000
500,000
600,000
800,000
1,000,000
20,000 x 2
20,000 x 3
20,000 x 4
20,000 x 5
20,000 x 6
20,000 x 7
20,000 x 8
20,000 x 9
20,000 x 10
20,000 x 11
20,000 x 12
20,000 x 13
20,000 x 14
20,000 x 15
20,000 x 20
20,000 x 25
20,000 x 30
20,000 x 40
20,000 x 50
Oke meji
Oke meta
Oke merin
Oke marun-un
Oke mefa
Oke meje
Oke mejo
Oke mesan-an
Oke mewaa
Oke mokanla
Oke mejila
Oke metala
Oke merinla
Oke meedogun
Ogun oke
Oke marundinlogbon
Ogbon oke
Ogoji oke
Aadota oke
Oke lona meji
Oke lona meta
Oke lona merin
Oke lona marun-un
Oke lona mefa
Oke lona meje
Oke lona mejo
Oke lona mesan-an
Oke lona mewaa
Oke lona mokanla
Oke lona mejila
Oke lona metala
Oke lona merinla
Oke lona meedogun
Oke lona ogun
Oke lona marundinlogbon
Oke lona ogbon
Oke lona ogoji
Oke lona aadata

Bi a se n lo ‘o din’ ni kika egbaalegbaa naa ni a n lo ‘o din’ ati ‘o le’ ti a ba n ka lokeelokee. Bi apeere:
Onka Geesi
Alaye ni Geesi
Onka Yoruba
Alaye ni Yoruba
20,080
40,008
40,060
43, 000
47,000
49,000
51,000
55,000
57,000
59,000
20,000+1 = 80
20,000+2 = 8
20,000×2 + 60
20,000×2 + 3,000
20,000×2 + 7,000
20,000×2 + 9,000
20,000×2 + 11,000
20,000×2 + 15,000
20,000×2 + 17,000
20,000×2 + 19,000
Orin le l’oke kan
Oke meji le mejo
Otalelokee meji
Oke meji le legbeedogun
Oke meji le leeedegbaarin
Oke meji le eedegbaarun-un
Oke meji o le eedegbaafa
Oke meji o le eegbaajo
Oke meji o le eedegbaasan-an
Oke meji le eedegbaawaa
Oke kan o le ogorin
Oke meji ati eeyo mejo
Oke meji o le ogota
Oke meji ati egbeedogun
Oke meji ati eedegbaarin
Oke meji ati egbaarun-un
Oke meji ati egbaafa o din egberun
Oke meji ati edegbaajo
Oke meji ati eedegbasan
Oke meji ati eedegbawa

ISE AMUTILEWA
Ko onka awon figo wonyi:
30,000
35,000
36,000
47,000
52,000
600,000
750,000
850,000
950,000
1,000,000
AKORI EKO: ORISA ILE YORUBA
OGUN
ITAN NIPA OGUN
Ogun je okan pataki ninu awon okanlenirinwo irunmole ti won ti ikole orun wa si ile aye. A gbo pe nigba ti awon orisa n bo wa si ile aye, won se alabaapade igbo didi kijikiji kan. Orisa-Nla ni a gbo pe o koko lo ada owo re lati la ona yii sugbon ada fadaka owo re se. Ogun ni a gbo wi pe o fi ada irin owo re la ona gberegede fun awon orisa yooku lati koja. Ise ribiribi ti ogun se yii ni awon orisa yii se fi jeoye Osin-Imole ni ile-Ife.
Itan fi han pe ode to ni okiki ni ogun. Tabutu ni oruko iya re. Baba re ni Ororinna. Won ni Ogun feran ise ode sise to bee to fi fi ilu sile lo si ori-oke kan ki o le ri aaye se ise ode. Igba ti ori-oke yii su un ni o pinnu lati pada si Ile-Ife. Igba ti ogun n bo, oju re le koko. Won ni:
‘Ojo Ogun n ti ori oke e bo,
Aso ina lo mu bo ‘ra,
Ewu eje lo wo sorun’.
Eyi ti Ogun iba fi duro ni Ile-Ife, ilu Ire ni a gbo pe Ogun lo. Won si gba a tayotayo. A gbo pe emu ni Ogun ko beere nigba ti o de Ire. Won fun un ni ounje ati emu mu. Idi niyi ti won fi n so pe: ‘Ire ki i se ile Ogun, o yak i won nibe menu ni’. Ori oke ninu igbo kan ni Ogun tun lo do sin i Ire. Bi o ba n bow a si aarin ilu, mariwo ni o maa n fi bora. Idi niyi ti won fi n ki i ni: ‘O-laso-nile fimokimo bora, Mariwo yegbeyegbe laso ogun’.
Orisirisi oruko ni won n pe Ogun. Ogun ni won tun n pen i Lakaaye; Osinmole, Awoo, Olumokin, Yankanbiogbe ati bee bee lo.
IGBAGBO YORUBA NIPA OGUN
Ogun ni orisa to ni irin. Gbogbo awon ti won n fi irin se je ti ogun.
Oun lo la ona fun awon orisa elegbe re
Orisa to feran ododo ati otito
Orisa ogun ni Ogun
Gbenagbena ni Ogun
ODUN OGUN
Kari ile Yoruba ni won ti n se odun Ogun, sugbon o gbayi ju lo ni awon ilue bii Ondo, Ilesa, Ile-Ife, Akure ati Ekiti. Akoko isu titun ninu osu keje si ikejo odun ni won n se odun Ogun.Ilu Agere, Katakoto ati bembe ni ile Ogun.
AWON OHUN TI WON FI N BO OGUN
Aja, Esun isu, epo, adiye, agbo, ewure, eyele, igbin, ewa eyan, iyan, obi abata, orogbo, ataare ati emu. Eekan soso ni apaja ogun gbodo be aja ni orun ti won ba n bo Ogun.
OJUBO OGUN
Awon ohun ti a n ri ni ojubo orisa yii ni omo owu, opa ogun, emu sekele, ada, ibon,obe, irin, olugbondoro, awon nnkan ija ogun.
BI WON SE N BO OGUN
Bi won se n bo Ogun ilu naa ni won n bo Ogun idile kookan. Okuta ribiti lo duro fun Ogun Agbede. Ori re ni awon alagbede ti n ro oko ati ada. Irin wewe ti a ko jo sinu ate Ogun lo duro fun ‘Ogun Ate’.
ORIKI OGUN
Ogun lakaye. Osin Imole
Ogun alada meji
O fi okan san’ko
O fi okan ye’na.
Ojo ogun n ti ori oke bo
Aso ina l’o mu bora
Ewu eje lo wo.
Ogun onile owo, olona ola
Ogun onile kangunkangun orun
O pon omi s’ile f’eje we
Ogun awon l’eyinju’
Egbe l’ehin omo kan,
Ogun meje l’ogun mi,
Ogun alara ni igba ‘ja,
Ogun Onire a gbagbo
Ogun ikola a gba’gbin
Ogun Elemona ni i gba esun’su
Ogun Aki’run a gba iwo agbo
Ogun Gbenagbena eran awun ni i je
Ogun Makinde ti d’Ogun l’ehin odi,
Bi ko ba gba Tapa, gb’Abooki,
Agba Uku-uku, agba Kemberi,
Nje nibo l’a ti pade Ogun?
A pade Ogun nibi ija,
A pade Ogun nibi ita;
A pade re nibi agbara eje n san,
Agbara eje ti i de ni lorun bi omi ago
Orisa t’o ni t’Ogun ko to nkan
A f’owo je’su re nigba aimoye…

 

OSE KEFA
AKORI EKO: ITESIWAJU ONKA YORUBA
Igba mewaa (200 x 10) ni a n pe ni egbaa. A le wa ka a bayii:
Onka Geesi
Onka Yoruba
Alaye ni Yoruba
Alaye ni Geesi
2,000
4,000
6,000
8,000
10,000
12,000
14,000
16,000
18,000
20,000
Egbaa
Egbaaji
Egbaata
Egbaarin
Egbaarun-un
Egbaafa
Egbaaje
Egbaajo
Egbaasan-an
Egbaawaa (oke kan)
Igba lona mewaa
Igba lona ogun
Igba lona ogbon
Igba lona ogoji
Igba lona aadota
Igba lona ogota
Igba lona aadoje
Igba lona ogoje
Igba lona aadorun-un
Igba lona ogorun-un
2,000 x 1
2,000 x 2
2,000 x 3
2,000 x 4
2,000 x 5
2,000 x 6
2,000 x 7
2,000 x 8
2,000 x 9
2,000 x 10

E je ki a lo egbaa lati se onka nipa fifi egbaa pin iye onka ti a ba fe ka, ji a to maa kaa loke loke.
Onka Geesi
Alaye ni Geesi
Onka Yoruba
Alaye ni Yoruba
30,000
32,000
34,000
36,000
38,000
42,000
44,000
46,000
48,000
52,000
54,000
56,000
58,000
2,000 x 15
2,000 x 16
2,000 x 17
2,000 x 18
2,000 x 19
2,000 x 21
2,000 x 22
2,000 x 23
2,000 x 24
2,000 x 26
2,000 x 27
2,000 x 28
2,000 x 29
Egbaa meedogun
Egbaa merindinlogun
Egbaa metafinlogun
Egbaa mejidinlogun
Egbaa mokandinlogun
Egbaa mokanlelogun
Egbaa mejilelogun
Egbaa metalelogun
Egbaa merinlelogun
Egbaa merindinlogbon
Egbaa metadinlogbon
Egbaa mejidinlogbon
Egbaa mokandinlogbon
Egbaa lona meedogun
Egbaa lona merindinlogun
Egbaa lona metadinlogun
Egbaa lona mejidinlogun
Egbaa lona mokandinlogun
Egbaa lona mokanlelogun
Egbaa lona mejilelogun
Egbaa lona metalelogun
Egbaa lona merinlelogun
Egbaa lona merindinlogbon
Egbaa lona metadinlogbon
Egbaa lona mejidinlogbon
Egbaa lona mokandinlogbon

‘o din’ tabi ‘o le’ ni a o maa lotiti de ori onkaye ta a n fe. Bi apeere: 30,400 je egbaa meedogun o la irinwo, 51,000 ni egberundilogbon; 57,991 je egbaa mokandinlogbon o din mesan-an; 58,008 je egbaa mokandinlogbon o le mejo. Lati ori 20,000, a le wa ma aka oke bayii:
Onka Geesi
Alaye ni Geesi
Onka Yoruba
Alaye ni Yoruba
40,000
60,000
80,000
100,000
120,000
140,000
160,000
180,000
200,000
220,000
240,000
260,000
280,000
300,000
400,000
500,000
600,000
800,000
1,000,000
20,000 x 2
20,000 x 3
20,000 x 4
20,000 x 5
20,000 x 6
20,000 x 7
20,000 x 8
20,000 x 9
20,000 x 10
20,000 x 11
20,000 x 12
20,000 x 13
20,000 x 14
20,000 x 15
20,000 x 20
20,000 x 25
20,000 x 30
20,000 x 40
20,000 x 50
Oke meji
Oke meta
Oke merin
Oke marun-un
Oke mefa
Oke meje
Oke mejo
Oke mesan-an
Oke mewaa
Oke mokanla
Oke mejila
Oke metala
Oke merinla
Oke meedogun
Ogun oke
Oke marundinlogbon
Ogbon oke
Ogoji oke
Aadota oke
Oke lona meji
Oke lona meta
Oke lona merin
Oke lona marun-un
Oke lona mefa
Oke lona meje
Oke lona mejo
Oke lona mesan-an
Oke lona mewaa
Oke lona mokanla
Oke lona mejila
Oke lona metala
Oke lona merinla
Oke lona meedogun
Oke lona ogun
Oke lona marundinlogbon
Oke lona ogbon
Oke lona ogoji
Oke lona aadata

Bi a se n lo ‘o din’ ni kika egbaalegbaa naa ni a n lo ‘o din’ ati ‘o le’ ti a ba n ka lokeelokee. Bi apeere:
Onka Geesi
Alaye ni Geesi
Onka Yoruba
Alaye ni Yoruba
20,080
40,008
40,060
43, 000
47,000
49,000
51,000
55,000
57,000
59,000
20,000+1 = 80
20,000+2 = 8
20,000×2 + 60
20,000×2 + 3,000
20,000×2 + 7,000
20,000×2 + 9,000
20,000×2 + 11,000
20,000×2 + 15,000
20,000×2 + 17,000
20,000×2 + 19,000
Orin le l’oke kan
Oke meji le mejo
Otalelokee meji
Oke meji le legbeedogun
Oke meji le leeedegbaarin
Oke meji le eedegbaarun-un
Oke meji o le eedegbaafa
Oke meji o le eegbaajo
Oke meji o le eedegbaasan-an
Oke meji le eedegbaawaa
Oke kan o le ogorin
Oke meji ati eeyo mejo
Oke meji o le ogota
Oke meji ati egbeedogun
Oke meji ati eedegbaarin
Oke meji ati egbaarun-un
Oke meji ati egbaafa o din egberun
Oke meji ati edegbaajo
Oke meji ati eedegbasan
Oke meji ati eedegbawa

ISE AMUTILEWA
Ko onka awon figo wonyi:
30,000
35,000
36,000
47,000
52,000
600,000
750,000
850,000
950,000
1,000,000
AKORI EKO: ITESIWAJU AWON ORISA ILE YORUBA
ORUNMILA
ITAN NIPA ORUNMILA
Okan pataki ni Orunmila je ninu awon okanlenirinwo Irunmole ti won ti ikole orun ro si Ofe Oodaye. Ni Oke Igbeti ni Orunmila koko de si ki o to lo si Oke Itase. Idi niyi ti won fi n ki i ni ‘Okunrin kukuru Oke Igbeti’.
Orunmila ni alakoso Ifa dida ati tite ile. Owo re ni akoso aye nipa ogbon ati imo ohun ti yoo sele lojo iwaju wa. Ko si oro kan ni abe orun tabi oro kan nipa isenbaye, ogbon ati igbagbo awon Yoruba ti Ifa ko so nipa re.
Gege bi Ojogbon ‘Wande Abimbola ti so ninu iwe “Awon Oju Odu Mereerindinlogun”, Orunmila lo opolopo odun ni Ife Oodaye, ki o to lo si Ado, ibi ti o ti pe ju lo ni ode aye. Idi niyi ti won fi n so pe ‘Ado n’ile Ifa’. Orunmila tun gbe ni Otu Ife.ibe ni o ti bi awon omo wonyi: Alara, Ajero, Owarangun-aga, Oloyemoyin, Ontagi-olele, Elejelu-mope ati Olowo. O tun gbe ni Ode Oyan, ibi to ti bi Amukanlode-Oyan. Bakan naa ni o gbe ni ode Onko, to ti bi Amosunlonkoegi.
Out-Ife ni itan so pe Orunmila ti pada si ode orun, ti ko si was i aye mo nitori iwa arifin ti Olowo, abikeyin omo re ni Otun Ife hu si i ni ojo ti Orunmila se odun. Orunmila ranse si awon omo re pe ki won w aba oun se odun. Bi won ti n de ni won n fori kanle ni okookan, ti won n so wi pe ‘aboruboye bo sise’. Igba ti Olowo de, o duro, o ni oun ko le wi ‘aboruboye bo sise’. Orunmila beere idi to fi se bee, Olowo ni:
“Iwo Orunmila sodun, o sodun ko;
Oun Olowo naa sodun, oun sodun ko
Iwo Orunmila f’osun ide lowo;
Oun Olowo naa f’osun ide lowo
Iwo bo salubata ide
Oun Olowo bo salubata ide…..
Iwo Orunmila dade
Oun Olowo naa dade,
Bee ni won sin i
Enikan ki i fori ade bale fenikan…..”
Oro yii lo mu Orunmila binu gba Osun Ide owo Olowo, o kori si idi Ope Agunka, ibe ni o gba lo si orun. Nigba ti Orunmila lo tan ni gbogbo nnkan daru, aye ko roju mo. Gbogbo aye lo be awon omo Orunmila ki won ba won be baba won. Igba ti won de idi ope agunka ti Orunmila do si, won be e titi, Orunmila da won lohun pe oun ko tun pada wale aye mo. O wa fun won ni ikin merindinlogun, ti o fi ropo ara re. O ni:
B’e e ba dele
B’e e f’owoo ni
Eni t’e e moo bi nu-un….
Lati igba naa ni ikin ti di ohun elo pataki ti awon babalawo fi n beere nnkan lowo Orunmila.
IGBAGBO YORUBA NIPA ORUNMILA
Orunmila alakoso Ogbon, Imo ati Oye
Opitan ni Orunmila
Okunrin Kukuru Dudu ni Orunmila
Orunmila ni alakoso Ifa dida ati tite ale
Orunmila ko ni egungun lara lati sise agbara
Agbaye-gborun ni Orunmila
BI WON SE N BO ORUNMILA
Ojo awo ni won bo Orunmila, bi o tile je wi pe ojoojumo ni awon babalawo n bo Ifa. Bi won se n difa oroorun naa ni won n se odun Ifa ni odoodun.
Ti won ba fe bo Ifa ni owuro, babalawo yoo mu obi si inu omi tutu, yoo maa fi iroke lu opon Ifa, yoo maa ki Orunmila ni mesan-an-mewa. Babalawo yoo pa obi naa, yoo se oju yii si inu omi. Omi naa ni yoo lo da fun Esu. Babalawo yoo wa da obi naa mo bi Ifa ba gba a. bi obi bay an tako tabo, iyen ti meji si oju, ti meji da oju de ile, Ifa ti gba obi nu un. Babalawo yoo pin obi fun awon to wa nibe lati je.
Bi o ba je Ifa odun, awon nnkan repete ni won yoo ka sile. Won yoo sip e mutumuwa fun ariya.
OHUN TI WON FIN N BO IFA
Eku meji, Eja meji, Igbin, Ewure, Adiye, Isu, Aguntan, Osuka omu ati obi.
AWON OHUN ELO IFA
Opele, Apo Ifa, Iroke Ifa, Opon Ifa.
Opon-Ifa ti a fin ona si lara, Iyerosun, Iroke, Ibo, Opele, Ikin merindinlogun, Awo-Ifa, Opa Osooro, Irukere.

SANGO: ITAN SANGO
Eniyan ni a gbo pe Sango je ki o to di orisa. Sango je orisa ti ise, irisi ati isoro re kun fun iberu. Sango je omo Oranmiyan. Awon iyawo re ni Oya, Osun ati Oba.
Itan so nipa Sango pe o je Oba l’ode Oyo-ile. Gege bi Oba alagbara, onigboya to tun loogun, o feran lati maa fi agbara re han awon eniyan. Bi Sango ba n soro ina a maa jade ni enu re. Ijoye tabi ara ilu to ba ni ti Sango bawo yoo je iyan re ni isu. A gbo pe Sango lo da ija sile laarin ijoye ilu meji, ti okan fi pa ekeji ku fininfinin.
Bayii ni Sango n da ilu ru, ti tomode-tagba ilu fi dite mo on. Igba ti ote yii kojaa siso, Sango ko eru re, o sa kuro l’ode Oyo. Awon iranse re, Osumare ati Oru pada leyin re. sugbon awon iyawi re meteeta n tele leyin lai mo ibi kan pato ti won n lo. Igba ti Sango rin die si Oyo, to ri pe oun ko leni lehin mo, afi Oya, ironu mu un, o way a si idi Igi Ayan, o si so ara re mo ibe, ti a n n pe ni Koso. Oya, iyawo re sa lo si apa ariwa, wole ni Ira, o si di odo Oya. Awon ero ti n koja ri Sango, won n yo suti ete si i pe ‘Oba so!, Oba so!’. Oro yii ko dun moa won eniyan Sango ninu, won si yo kelekele lo si ilu Ibariba lati gba oogun buburu ti won fi n baa won ota Sango ja. Igba miiran, won a yo kelekele fi in abo ile ni orun, won a ni Sango lo n binu. Ti ojo ba ro ti ara san, ti ‘edun ara’, ti o je okuta ba pa eniyan, won a ni Sango lo n binu. Idi niyi ti a se n pe Sango ni ‘Jakuta’. Igba ti wahala yii po ni awon ara Oyo bay i ohun pada, won n so pe ‘Sango Oba Koso’, ki won ma baa ri ibinu re. iberu yii ni won fi so Sango di orisa titi di oni.
Ilu Oyo ni odun Sango ti gbayi julo ni ile Yoruba. Won tun n se odun re ni Ibadan, Iseyin, Iwo, ede, Abeokuta, Ilesa, Ondo ati Ekiti. Awon aworo re ni a n pe ni Onisango tabi Adosun-Sango. Awon asaaju won ni a n pe ni Magba tabi Iya Magba. Adosun-Sango maa n di irun ori, won n wo aso osun ti Sango feran ju lo nigba aye re. Awon aworo re maa n mu Ose Sango lowo. Ilu bata ni ilu Sango Ounje ti Sango feran ni amala pelu obe eweedu, eran agba, orogbo ati obi. Idi niyi ti won fi n ki i ni: Sango oloju Orogbo, eleeke Obi.
IGBAGBO YORUBA NIPA SANGO
Orisa to ni agbara lori ara ati imonamona
Orisa afajo
O n fun won lomo
AWON OHUN ELO SANGO: Bata, ilu Sango, Ose Sango, Sere Sango, Laba Sango
OHUN TI WON FI N BO SANGO: Orogbo ni obi Sango. Won n fi oka, adiye ati aguntan bolojo bo. Ounje Sango ni oka.
ORIKI
Penpe bi asa, asode bi Ologbo
Sangiri-lagiri!
Olagiri kaka f’igba edun bo o!
Eefin ina l’a nda l’aiye
Ina mbe l’odo oko-mi orun
Sango Onibon orun
Ajalaji Oba Koso
Ewelere okoo mi
Aara-sowo-ija-lala!
Aara-o-fija-wole!…..

OSE KEJE
AKORI EKO: ATUNYEWO AWON EYA ARA IFO
“Eya ara ifo ni awon orisirisii eya ara ti a maa n lo fun pipe iro ede”.
Abuda kan pataki ti o ya awa eniyan soto si awon eda yooku ni ebun oro-siso. Bi apeere, ti a ba so wi pe ‘Bawo ni nnkan’, awon eya ara kan wa ninu ara wa lati ori de ikun ti won jumo sise papo lati gba gbolohun ibeere yii jade. Awon eya ara bee ni a n pe ni eya-ara ifo. Aworan eye-ara ifo naa niyi:

AWORAN EYA-ARA IFO

 

ISORI EYA-ARA IFO
A le pin awon eya-ara ifo si eya meji. Awon ni:
(i) AWON EYA-ARA IFO AFOJURI: Awon wonyi ni eya-ara ifo ti a le fi oju ri nipa lilo digi tabi nnkan miiran. Awon naa ni:
Afase, Olele, Iho imu Ita gogongo, Ete oke, Ete isale, Eyin oke, Eyin isale, Iwaju ahon, Aarin ahon, Eyin ahon, Erigi, Ajaa enu.
(ii) AWON EYA-ARA IFO AIFOJURI: Awon wonyi ni awon eya-ara ifo ti won wa lati inu ikun si inu ofun ti a ko le fi oju ri rara. Awon ni:
Kaa ofun, inu gogongo, Tan-an-na ofun, komookun, Eka komookun, Edo-foro.
S/N
EYA-ARA IFO
APEJUWE ILO WON
1.

 

2.
Komookun

 

Edo foro
Edo-foro: Inu edo-foro ni eemi ti a n lo fun opo iro ede ti n tu jade sita. Eyi ni a n pe ni eemi edo-foro. Eran ara edo-foro maa n fe lati pese eemi amisinu tabi amisode fun oro siso.

Komookun ati Eka komookun: inu eka komookun mejeeji ati komookun ni eemi edo-foro n gba koja si inu gogongo ati enu.
3.
Gogongo
Ori komookun tente ni gogongo dabuu le ni ofun. A le ri ita gogongo ni ofun wa.
4.
Tan-an-na ati Alafo Tan-an-na
Inu gogongo ni tan-an-na wa. Inu alafo tan-an-na yii ni eemi edo-foro n gba jade si ona ofun.
5.
Kaa Ofun, Kaa Enu ati Kaa Imu
Oke tan-an-na ni awon kaa meteeta wonyi wa. Ona ikoja ni won je fun eemi yala eemi amisinu tabi amisode
6.
Ahon
Ahon je eya ara lo n kopa julo pipe iro ifo nitori pe o se e gbe si orisiirisii ipo. A le pin ahon si apa meta wonyi:
Iwaju ahon
Aarin ahon
Eyin ahon
7.
Ete
A le paete po pekipeki; ete le fe seyin perese, tabi ki a su won po roboto. Idi niyi ti a fi n ni iro faweli perese tabi roboto.
8.
Afase
Ni enu, afasa le gbera soke tabi wale fun eemi lati ri aaye gba kaa imu tabi enu jade. Idi niyi ti a fi n ni iro aranmupe tabi iro airanmupe.
9.
Eyin oke, Erigi, Aja-enu
Afipe akanmole ni won. A n lo won po mo afipe asunsi lati pe iro. A n lo eyin-oke papo mo ete isale tabi iwaju ahon pelu arigi ati aja-enu.

AFIPE: Afipe ni eya ara yoowu ti o ba n kopa ninu iro pipe.
Afipe ni gbogbo awon eya ara-ifo ti won wa lati oke alafo tan-an-na ofun de enu ati imu. Aarin yii ni a n pe ni opona ajemohun.
A le pin awon eya-ara ifo ti eon je afipe si meji. Awon ni:
Afipe asunsi; ati
Afipe akanmole
AFIPE ASUNSI: Afipe asunsi ni awon eya ara isale enu ti won le gbera soke tabi sodo lati sun kan afipe akanmole ti a ba n pe iro. Awon ni: Olele, Ete isale, Iwaju ahon, Aarin ahon, Eyin ahon.
AFIPE AKANMOLE: Afipe akanmole ni awon eya ara oke enu ti won n duro gbari si oju kan ti a ba n pe iro. Awon ni: Ete oke, Ogiri ofun, Eyin oke, Afase, Aja-enu, Erigi, Kaa imu.
Awon eya-ara ifo miiran ti won wa ni opona ajemohun tun ni awon ise miiran ti won n se to yato si oro siso. Bi apeere, imu wa fun oorun gbigbo tabi mimi; eyin wa fun ounje wiwe, bee ni ahon wa fun tito nnkanwo. Opona ajemohun bere lati aarin oke alafo tan-an-na titi de enu ati imu.

AKORI EKO: AWON ORISA ATI BI A SE NBO WON
IPO OLODUMARE ATI ORISA
Awon Yoruba gba wi pe enikan wa ti o ni ogbon, agbara, to si ga ju gbogbo orisa ati eda aye lo. Eyi ni won n pe ni Olorun tabi ‘eni ti o ni orun’, ibi ti won gba gege bii ibugbe Re. Won mo, won si gba wi pe Olorun yii ni o tobi julo. Idi niyi ti won fi pe e ni Olodumare. Oniruru oruko ni won fun Olodumare lati fi igbagbo won han. Won ni “F’ija f’Olorun ja, f’owo leran”. Eyi fi Olodumare han bi onidajo ododo.
Alarina tabi alagbawi lasan ni awon orisa je laaarin Olodumare ati awon eda eniyan. Iranse Olodumare ni awon Yoruba ka won si. Olodumare ni o ran won wa si ile aye lati wa tun aye se. Idi niyi ti awon Yoruba se fi won si ipo pataki. Igbagbo Yoruba tun re e.
Awon orisa ni won le gbe ebe won de iwaju Olodumare. Won gbagbo pe nitori pe Olodumare ga ju fun awon lati maa sun mo nigba gbogbo. Bee ni awon orisa wonyi sun mo Olodumare niroti iranse re ni won. Bi a ba si fe gba nnkan lowo eniyan, eni ti o ba mo oju re ni a n toju ki o le je ise wa daadaa. Idi niyi ti awon Yoruba fi n toju awon oris, ti won fi n ko ile fun won.
Awon abami eda tabi emi buburu kan wa ti won le fi iku tabi aisan buburu je awon niya. Won n se ebo ati etutu lorisirisi lati petu fun abami eda ati lati wa oju rere won. Opolopo awon oke, odo, igi nla ati awon eni lile aye atijo, ti won ni eru lara ni won ti so di orisa akunlebo, bi apeere; Sango, Oya, Ogun ati bee bee lo. Igbagbo won ni pe awon emi buburu wonyi n gbe ori oke, abe apata, inu omi nlaati ara igi ti o ga pupo. Bee ni awon miiran n boa won abami eranko bii Onni, Ere tabi Ejo ati awonope ti o ba yo eka fun idi kan naa.

PATAKI ORISA LAWUJO YORUBA
Ti a ba n soro nipa orisa ile Yoruba, bi eni n soro nipa esin abalaye won ni. Awon orisa wonyi ti di ohun ti won n bo fun awon idi ti a ti menuba. Iwonyi ni pataki awon orisa yii ni awujo Yoruba.
Imuni mo orison eni: Awon agba ni “Odo to ba gbagbe orison gbigbe ni i gbe”. Awon orisa wonyi n je ki omo Yoruba mo esin idile won. Osagbemi, Efunkemi, Osuntokun, Abegunde je oruko idile oloosa. Olorisa Egungun ni won n so omo won ni Abegunde, awon Onifa ko je so omo won ni Osungbemi laelae. Awon orisa wonyi je ki a mo ona ti a to waye, eyi si n satona ihuwasi eni ni awujo.
Ipese aabo ati ipese ire gbogbo: Bi oro ba diju, ifa ni awon Yoruba maa n fi oro lo. O daju pe ko si nnkan ti a le fe dawole ni awujo Yoruba ti a ko ni bi Ifa. Bee naa ni a n bo egungun ni iranti awon ara orun fun idaabobo. Bee ni ko si ebo ti a le gbe leyin esu ki ebo naa fin.
Orisa gege bi amu eko iwa atata ati iwa-bi-Olorun: Awon orisa ile Yoruba ni eewo to n dari ihuwasi olusin. Obatala fe mimo mimo, ohun to funfun, ni iwa, ni ero ati ni ise. orisa Ogun ko fe iro. Idi niyi ti won fi n fi i buran i ile ejo. Orisa-Nla ko oro iwosi, ko ni ife si aso. O ko awon olusin re pe iyawo kan soso lo dara loode. O ni “A ko le gbe aarin oji eniyan k’a ma si wi”.
Orisa bi amu ilana akoso to to: Bi a ba wo itan iwase, bi Olodumare ti ni agbara to, to je pee da owo re ni gbogbo awon orisa, sibe o pin ise akoso fun olukuluku won. Orisa kookan lo n sakoso eka kookan ninu aye ti Olodumare da. Eyi je apeere rere fun awujo w ape ki a ma da wa gbogbo nnkan mo ori. Agbara pupo n seku pa ni. Oba nikan ko le da ilu se. awon ijoye ilu ni ojuse. Eto niyi yi a le mulo ninu eto iselu wa.
Ogun iyebiye: Ogun iyebiye ni an ri ko ni akoko odun awon orisa wonyi. Akoko naa maa n je asiko ajoyo, ijo ati orin kiko tabi ewi kike. Irufe orin yii ti di ogun iyebiye fun awon omo Yoruba. Awon orin bi Ijala are ode, Esa egungun, Sango pipe ti di ilumoka. Gege bi won n gbe awon ti Olodumare ba fi ke ni ile yii ati ni oke okun.
Amu imo fun awon onkowe: Awon onkowe n ri nnkan ko lori awon orisa fun ojo iwaju: awon onkowe itan tabi awon to n ko ewi n menuba oriki awon orisa ninu iwe won. Onkowe Yoruba ti ko bam o nipa awon orisa ile Yoruba ko le ko iwe to ye kooro ninu asa. Apeere iwe to samulo awon orisa ni Oba Koso ti Duro Ladipo ko, Obaluaye, ti Wale Ogunyemi ko. A ri i bi gbogbo awon orisa se dide pelu ija si ilu ti ko fi tiwon se. Iwe J.S. Sowande (Sobo Arobiodu) fi imo re to jinle ninu esin ati orisa Yoruba han ninu ewi yii fun awujo. O ni:
A ki i siwaju Olifa
A ki i siwaju Olorisa korisa
A ki i siwaju Olobatala reri ose;
A ki i siwaju Tisa liborin:
Bi a ba siwaju Tisa liborin
A ko maa gbo ki duuru kun.

ISE AMUTILEWA
So igbagbo Yoruba nipa orisa
Ko oriki awon orisa wonyi sile:
Sango
Orunmila
Ogun
So ipa pataki ti orisa ko laarin awon Yoruba
So ipo Olodumare ati orisa bi igbagbo awon Yoruba.

OSE KEEJO
AKORI EKO: ATUNYEWO AWON IRO NINU EDE YORUBA

 

 

OSE KESAN-AN
AKORI EKO: ATUNYEWO APEJUWE IRO KONSONANTI ATI IRO FAWELI
Iro konsonanti ni awon iro ti idiwo maa n wa fun eemi ti a fi n gbe won jade.
Idiwo le waye nipa ki ona eemi se patapata, ki iro jade pelu ariwo taki ki o se die ki iro jade ni irorun. Awon iro konsonanti ede Yoruba ni:
d, b, f, g, gb, h, j, k, l, m, n, p, r, s, ṣ, t, w, y.
ABUDA IRO KONSONANTI: Ti a ba fe se apejuwe iro konsonanti nipa abuda, a nilati wo awon ilana wonyi wo ni okookan:
Orison eemi ti a fi n pe iro
Irufe eemi ti a lo
Ipo alafo tan-an-na
Ipo afase
Irufe afipe ti a lo
Irufe idiwo ti o wa fun eemi
Orisun eemi ti a fi pe iro: A nilati so orison eemi ti a lo lati pe iro konsonanti, yala
Eemi edo-foro lati inu edo-foro ni tabi
Eemi amisinu ti a seda re wa ni enu
Eemi edo-foro ni a fi n gbe gbogbo konsonanti ayafi iro /kp/ ati /gb/ ti a n lo apapo eemi edo-foro ati eemi ti a seda re wa ni enu.
Irufe eemi ti a fi gbe iro jade: A nilati so iru eemi ti a fi gbe iro konsonanti jade: Yala
Eemi amisode;
Eemi amisinu; tabi
Apapo eemi mejeeji (bi o se ri ti a ba pe iro /kp/ ati /gb/)
Ipo alafo tan-an-na: A nilati so ipo tan-an-na ofun wa boya
Ipo imi (fun iro aikunyun) tabi
Ipo ikun (fun iro akunyun)
Ipo ti afase wa: A nilati so boya
Afase gbera soke di kaa imu ni tabi
Afase wale fun eemi lati gba kaa enu ati imu jade leekan naa.
Irufe afipe ti a lo: A nilati fi han boya
Afipe asunsi ni a n lo tabi
Afipe akanmole
Ipa ti afipe kookan ko nogba ti a ba pe iro konsonanti.
Irufe idiwo to wa fun eemi ti a lo: A gbodo so irufe idiwo ti o sele si eemi ni opona ajemohun, boya
Ona se patapata ni; tabi
Alafo die si sile fun eemi lati koja
A le wa se apejuwe abuda iro konsonanti ni okookan bayii. Bi apeere: iro /b/:
Orison eemi – eemi edo-foro ni a lo
Irufe eemi – eemi amisode
Ipo alafo tan-an-na – alafo tan-an-na wan i ipo ikun
Ipo afase – afase gbera soke di ona si imu
Irufe afipe – ete isale (asunsi) pade ete oke (akanmole)
Iru idiwo – ona eemi se patapata ni sakani ete mejeeji
ATE KONSONANTI
Ate yii fi gbogbo alaye wa lori owoo konsonanti han ni soki.
Ona Isenupe

[mediator_tech]
Afeji-ete-pe
Afeyin-fete-pe
Aferi-gipe
Afaja-fe-rigi-pe
Afajape
Afafasepe
Afitan-an-nape
Afafa-sefete-pe
Asenupe
Akunyun
Aikunyin
b

d
t

 

g
k

gb
p
Aseesetan
Akunyun

 

 

 

y

 

w
Asesi
Akunyun

 

 

j

 

 

 

Afunnupe
Aikunyun

f
s

 

h

Afegbe-enu-pe
Akunyun

 

l

 

 

 

 

Aranmupe
Akunyun
m

n

 

 

 

 

Arehon
Akunyun

 

r

 

 

 

 

 

DIDARUKO IRO KONSONANTI
A le se apejuwe iro konsonanti bayii:
[b] Konsonanti akunyun afeji-ete-pe asenupe
[d] konsonanti akunyun aferigipe asenupe
[g] Konsonanti akunyun afafasepe asenupe
[gb] Konsonanti akunyun afafasefetepe asenupe
[f] Konsoanti aikunyun afeyinfete afunnupe
[h] Konsonanti aikunyun afitan-an-nape afunnupe
[dz] Konsonanti akunyun afajaferigipe asesi
[k] Konsonanti aikunyun afafasepe asenupe
[l] Konsonanti akunyun aferigipe afegbe-enu-pe
[m] Konsonanti akunyun afeji-ete-pe aranmu
[n] Konsonanti akunyun aferigipe aranmu
[kp] Konsonanti aikunyun afafasefetepe asenupe
[r] Konsonanti akunyun aferigipe arehon
[s] Konsonanti aikunyun aferigipe afunnupe
[ʃ] Konsonanti aikunyun afajaferigipe afunnupe
[t] Konsonanti aikunyun aferigipe asenupe
[w] Konsonanti akunyun afafasefetepe aseesetan
[j] Konsonanti akunyun afajape aseesetan.

IRO FAWELI: Faweli ni awon iro ti a pe jade nigba ti ko si idiwo Kankan fun eemi to n ti inu edo-foro bo.
Iro faweli ede Yoruba pin si orisii meji. Awon ni:
Faweli airanmupe: a, e, ҿ, i, o, ϙ, u
Faweli aranmupe: an, ҿn, in, ϙn, un
Lati se apejuwe abuda iro faweli ede Yoruca, a nilati ye ipo ti awon eya ara ifo meta wonyi wa wo:
ahon
afase, ati
ete
Ipo ti ahon wa: A gbodo se akiyesi
apa kan ara ahon to gbe soke julo ninu enu (boya iwaju, aarin tabi eyin ahon)
bi apa kan to gbe soke naa se ga to ni enu. Bi apeere, bi a ba pe iro /i/:
iwaju ahon lo gbe soke jule ni enu
giga iwaju ahon feree de oke tente ni enu
ATE FAWELI: Ate isaje yii ni so ipo tabi irisi ahon ni enu ti a ba gbe iro faweli kookan jade.
Faweli airanmupe

 

 

Didaruko Faweli:
A le fun awon iro faweli kookan ni oruko bayii:
[a] faweli airanmupe ayanupe (odo) aarin perese
[e] faweli airanmupe ahanudiepe (ebake) iwaju perese
[ε] faweli airanmupe ayanudiepe (ebado) iwaju perese
[i] faweli airanmupe ahanupe (oke) iwaju perese
[o] faweli airanmupe ahanudiepe (ebake) eyin roboto
[ᴝ] faweli airanmupe ayanudiepe (ebado) eyin roboto
[u] faweli airanmupe ahanupe (oke) eyin roboto

FAWELI ARANMUPE

 

Didaruko Faweli: A le fun awon iro faweli kookan ni oruko bayii:
[ā] faweli aranmupe ayanupe aarin perese
[ε] faweli aranmupe ayanudiepe iwaju perese
[i] faweli aranmupe ahanupe iwaju perese
[ᴝ] faweli aranmupe ayanudiepe eyin roboto
[ṻ] faweli aranmupe ahanupe eyin roboto

AKORI EKO: ERO ATI IGBAGBO YORUBA LORI AKUDAAYA ATI ABAMI EDA
IGBAGBO AWON YORUBA NIPA ASEYINWAYE
Awon Yoruba ni igbagbo ti o jinle ninu aseyinwaye (iyen leyin iku) igbagbo ninu pipada wasiaye eni to ti ku yii wa ni aye atijo bee ni o si wa titi di oni.
Ni ona kinni, nibi isinku agba fi ese igbagbo yii mule. Ey ribee nigba ti agbalagba kan ninu idile ba ku (yala okunrin tabi obinrin) ti iyawo omo re ba wa ninu oyun ni akoko naa ti omobinrin naa ba ti mo okunrin tabi obinrin leyin iku baba tabi iya agba oruko ti won yoo so iru omo bee ni (ti o ba je okunrin) Babatunde, Babajide, abbl. Sugbon ti o ba je omobinrin, oruko ti won yoo ma pee ni Yetunde, Yeside, Iyabo, Yewande, Yejide abbl.
Ona keji ewe awon Yoruba tun gbagbo pe ti enikan ba ku nigba ti ojo re ni aye ko tii pe lati ku kii lo si orun taara, se ni won yoo wa ibikan tedo si tabi ki won maa rare kiri titi ojo re yoo fipe ni aye ki o to le pada lo si orun. Iru awon ti won ba fi ojo dajo lo bayii ni a n pen i akudaaya tabi akufon
Ona keta igbagbo awon Yoruba nipa abiku fi idi iye leyin iku mule. Abiku ni omo ti o ku, ti o tun pada wa si aye, o tun le ku, ki o si tun pada waye ni igba ti o ba wuu. Atigbo nipa abiku ti won ge ika owo re ti o si jepe igbati obinrin to bii ya pada bi omo, ika owo mesan-an ni omo tuntun ti o bi gbe waye. Eyi fihan pe omo akoko iru omo bee ni; Kokumo, Igbekoyi, Malomo, Bamitale, Durorike, Kosoko abbl.
Ona kerin, awon Yoruba tun gbagbo pe awon iwin ati egbere wa, atipe eniyan ni won tele ki won to di ebora. D.O. Faganwa fi igbagbo yii han ninu awon iwe itan aroso. Oro eda inu itan iwe re je oro tabi iwin. Inu igi bii igi iroko, igi agbalumo, inu igi ibepe, igi ahusa, agbo ogede ni won ngbe. Won asi maa yipada si eniyan nigba ti o ba wu won. Awon Yoruba tile gba pe won maa n na oja ale. Bakannaa ni awon ogboju ode maa n royin itu ti awon ebora maa n fi won pa ninu igbnigba ti won ba n sode ninu igbo.
Ona karun-un, awon Yoruba tun gbagbo pe awon elegbe omo wa. Awon omo elegbe bi eyi maa n yo obi won lenu. Aimoye won ni won maa n lo agbara won lati se obi won ni ibi. Ipese ni won maa n se fun won lati tu won loju. Won ti e maa n ka eewo fun awon obi won ti won ko gbodo lana lati se bii beeko, won yoo yo iya won lenu.
Won tun gbagbo wipe awon eyan to n wo aso egungun o se eniyan lasan pe awon alagbara eyan niwon tabi ole.

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

SS 3 FIRST TERM LESSON NOTE YORUBA

 

 

 

 

ILAANA ISE NI SAA KETA FUN JSS 3 THIRD TERM LESSON NOTES YORUBA

 

 

 

[mediator_tech]

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share