ASA IRANRA – ENI LOWO (COMMUNAL ASSISTANCE)
Asa iranra – eni lowo je ona ti awon Yoruba fi maa n ran ara won lowo ni aye atijo. Asa yii maa n saba jeyo ninu ise oko riro, ile kiko, owo yiya tabi n kan miiran.
Asa iranra – eni lowo maa n mu ki ise ti o po ti o le gba eniyan ni akoko pupo di sise ni kiakia nipa pipapo se e. ilana jijumo se ise papo maa n mu ki okun ife nipon, o si maa n je ki wahala dinku laarin awon eniyan ti won wan i ayka kan naa.
Orisii ona iranra – eni lowo
- Owe
- Aaro
- Ajo
- Esusu
- Owo ele kiko (so ogundogoji)
- San – an – die – die
- Fifi omo/nnkan ini duro
- Aaro: awon odokunrin ti won je ore ti oko won si wan i itosi ara won ni won maa n be ara won ni aaro fun ise oko ti o bap o. olukuluku ni yoo si jumo se e ni ojo kan titi ti won yoo fi se kari ara won. Ounje tabi ohun mimu kii se dandan, sugbon ise naa gbodo yipo kari.
- Owe: A maa n be owe ni, opo eniyan bi ebi, ore tabi ojulumo ni a le be lowe lati ba ni sise. Won yoo da ojo owe kii sise dandan lati san owe pada, sugbon eni ti o be lowe gbodo pese ohun jije ati mimu.
- Esusu: eyi ni ona ti a maa n gba fi owo pamo lati fise n kan gidi ni ojo iwaju. Ko si ere ninu esusu, sugbon enikan n yoo je olori ti yoo dari won ti gbogbo akopa yoo si fenuko lori akoko ti won fe maa ko boya osose ni tabi osoosu.
- Ajo: Awon eniyan le maa dawo jo si owo enikan titi di ipari osu tabi akoko ti won ba fi adehun si. Eni ti o n gba ni yo maa se eto pinpin re, yoo si yo die lori owo eni kookan ni ibere owo ti won n da.
- Owo ele kiiko tabi sogundogoji: awon eniyan ti o ba koju isoro to le tabi ti o ba wo wahala, ni won maa n ko owo ele lati fi bo asiri ara won. Nigba miiran ele le je ilopo meji owo ti won ya.
- San – an – die – die: eniyan le ra oja awin pelu adehun lati maa san – an owo re pada die – die titi yoo fi san gbogbo oeo naa pada.
- Fifi omo tabi ohun ini duro: ti eniyan ba nilo owo, won maa n fi omo tabi nkan ini ti o niye lori duro lati ya owo. Igba ti eni naa ba san iru owo bee tan, ni yoo to gba n kan ti o fi duro pada.