ATUNYEWO AWON EYA GBOLOHUN

OSE KẸFÀ 

AKORI EKO:

ATUNYEWO AWON EYA GBOLOHUN

Gbolohun ni oro tabi akojopo oro ti o ni itumo. Gbolohun le je ipede ti o ni itumo tabi ni ise ti o n se nibikibi ti o ba ti jeyo. Bakan naa a le pe gbolohun ni oro ti a le pin si spola oro-oruko ati apola ise.

ISORI GBOLOHUN EDE YORUBA

  1. Gbolohun eleyo oro-ise tabi gbolohun abode
  2. Gbolohun alakanpo
  3. Gbolohun ibeere
  4. Gbolohun olopo oro-ise
  5. Gbolohun alaye
  6. Gbolohun ase
  7. Gbolohun iyisodi
  8. Gbolohun iba tabi kani
  9. Gbolohun akiyesi alatenumo
  10. Gbolohun asodoruko
  1. Gbolohun eleyo oro-ise tabi gbolohun abode: eyi ni ipede tabi afo ti o ni oro-ise kan ninu. Irufe gbolohun yii ni a tun mo si gbolohun kukuru. Bi apeere:
    • Bisi sun
    • Dayo gun igi
    • Fadekemi we gele
  1. Gbolohun alakanpo: eyi ni ipede tabi gbolohun ti a lo oro asopo lati so gbolohun meji tabi ju bee lo po di eyo gbolohun kan soso. Bi apeere:

    Ile re tobi, iyara re kere = ile re tobi sugbon iyara re kere

    Temidayo lo si ibi ayeye naa

    Adeyemi lo si ibi ayeye naa

    = Temidayo ati Adeyemi lo si ibi ayeye naa

  1. Gbolohun ibeere: eyi ni awon gbolohun ti a fi n se ibeere. Awon wunren gbolohun ibeere ni, da, nko, tani, ati bee bee lo. Bi apeere:

    Adegoke da?

    Badejo nko?

    Ta ni o wa nibe?

  1. Gbolohun olopo oro-ise: gbolohun yii naa ni a mo si gbolohun onibo. Gbolohun yii maa n ju eyo oro-ise kan lo, oro-ise inu gbolohun yii le je meji tabi meta. Bi apeere:

    Mo jeun mo si yo

    Won n rin won n yan won si se oge

Ise asetilewa: Ko apeere meji lori orisii gbolhun ti o mo

ITESIWAJU ISE LORI ISORI GBOLOHUN

  1. Gbolohun alaye: eyi ni gbolhun ti a n lo lati so bi n kan se ri. Bi apeere:
  •     Won ti jewo bi oro ti se ri gan-an
  •     Iwe meweaa ni Bolude ka
  •     Ojo naa fere wu oku ole
  1. Gbolohun iba tabi kani: eyi ni gbolohun ti a fi n so bi nkan se ri ati idi ti o fi ri bee. Atoka re ni ‘bi’, ‘kaka’, ati ‘dipo’. Bi apeere:
  •     Bi mo ma lowo maa dara
  •     Kaka ki n jale, maa di eru
  •     Dipo ki n ra eran, maar a eba
  1. Gbolohun iyisodi: awon oro atoka gbolohun yii ni ‘ko’, ‘kii’, ‘ko’, ‘ma’. Bi apeere:
  •     Bisi ko wan i ana
  •     Femi o ri osere naa
  •     Akande kii wa si ipade dede
  •     Jegede kii je ewa
  1. Gbolohun akiyesi alatenumo: A maa n fi pe akiyesi si apa ibikan pato tabi koko kan ninu odidi gbolohun nipa lilo ‘ni’ ninu gbolohun abode ti a fe se atenumo. Bi apeere:
  •     Mo ra ile tuntun ni Abuja
  •     Rira ni mo ra ile
  •     Abuja ni mot i ra ile tuntun
  1. Gbolohun Ase: Eyi maa n waye nipo ipede ti o je kan-an nipa fun eniti a ba soro. A maa n lo o gege bi igba ti a fi n mu u je dandan fun eni naa. Bi apeere:
  •     Dake je!
  •     Dide duro ati bee bee lo

 

Ise asetilewa

Ko apeere kan-kan lori orisii gbolohun ti o se le ni ki o si ko meji lori gbolohun asodoruko.