ERE IDARAYA

Table of Contents

OSE KEFA

AKORI EKO: ERE IDARAYA

Ere idaraya ni awon ere t tewe – tagba maa n se lati mu ki ara won jipepe. Bi awon Yoruba se feran ise – sise to bee naa ni won ni akoko fun ere idaraya. Akoko ti ise ba dile tabi awon eniyan ba dari bo lati ibi ise oojo won ni won maa n fi aboo si ibi ere idaraya. Ere idaraya wa fun omode ati agbalagba.

A le pin ere idaraya ti o wopo laarin awon Yoruba si meji. Awon ni:

  1. Ere osupa ati
  2. Ere ojoojumo
  1. ERE OSUPA: ni awon omode maa n se ti ile bat i n sun i akoko osupa nitori aisi ina monamona ni oye ojoun (atijo)

Awon ere bee ni:

  1. Bojuboju
  2. Ekun meran
  3. Eye meloo tolongo waye
  4. Booko – booko
  5. Isa – n – saa – lu – bo 
  6. Kini newu
  7. Alo apamo ati alo apagbe 
  1. ERE OJOOJUMO: eyi ni ere ti tomode – tagba maa n se ni owo osan si irole. Iwonyi le je ere abe ile bii: (i) ayo tita (ii) moni – ni – moni – ni 
  2. ERE ITAGBANGBA: eyi le je:

(i) eke tabi ijakadi    (ii) okoto tita    (iii) Ere arin

ANFAANI ERE IDARAYA

  1. O n mu nii ronu jinle
  2. O n je ki a mo nipa oro ati itan atijo (atayebaye)
  3. Erin ati awada maa n waye
  4. O maa n ko ni bi a ti ri fi oju sun ohun okere (ninu ere arin)
  5. O n mu ki omode ni agbara ki o si ni aya lati le koju sioro (ija fun idaraya kii je ki omode saisan)
  6. O n mu ajosepo to danmoran wa laarin awon omode
  7. O n mu ki omode gbagbe wahala ise oojo.

ALEEBU ERE IDARAYA

  1. O maa n gba akoko eniyan
  2. Oro iwosi maa n waye ninu ere idaraya (ayo tita)
  3. Erupe le gbon si oju omode rabi ki emomiran kan ni orun ese nibi ti won ti n sare kiri
  4. Eniyan le ti ibi ijakadi di alaabo ara titi ojo aye onitohun.