Third Term Examinations JSS 2 Yoruba

THIRD TERM

IJIYA FUN IJIWE DAKO NI LILE KURO NI ILE IWE MASE KOPA NINU RE .

JSS TWO – YORUBA LANGUAGE Wakati…….Wakati meji

IPIN A: Akiyesi : Ka ayoka yi daadaa ki o si dahun awon ibeere isale yii.

Eni a wi fun oba je o gbo “ori okere koko lawo” ni Orin ti o gbenu awon obi Ajantala ,ni gba ti ogoro eniyan wa ba won kedun iku ojiji ti o wole wa mu Omo won lo ni osan gangan ojo eti ninu Osu Keta odun ti o koja .

Akowe owo ni Ajantala n se ni ile ifowopamo nla kan ni ilu Oyo ni ipinle Oyo.iwe tasere

Ni o ka,sugbon ise takun takun ,iwa akinkanju pelu iwa oyaya re tete gbe de ipo oga.

Kin ni kan ba Ajao re je, ko si obinrin ti kii wu Ajantala Lati ba doree. Bi o ti n denu ko dudu ni o n fi owo fa oju pupa mora. Bi o ti n gba alejo olomoge ni o n yan abileko Loree.

Gbogbo arowa ati ikilo Saani baba re ati Omolara iya re,eyin Eti ni gbogbo won n gba lo, ko gboro si eni kankan won lenu.

Aseyinwa aseyinbo,Ajantàla ko aarun ti ko gboogun ,ise Bo Lowo re, o pada si Araromi lodo awon obi re,ori aisan yii ni o ku si.

.IBEERE:

Irufe ise wo ni Ajantala n se? (a) ise olode (b) Akekoo ni(d) ise asewo(e) ise akowe owo

Abileko tunmo si………. .. gege bi won se lo o ninu akaye naa (a) omidan(b) obinrin to ti loko (d) obinrin to ti dagba (e) obinrin to ti balaga

(3) Iwa ibaje ti o pa Ajantala ni (a) ole ija (b) Agbere sise (d) Igberaga sise (e) iwa ika

(4) Kin ni o Sele si Ajantala ni kete ti o ko aarun ti ko gboogun? (a) ise Bo Lowo re (b) o pada sori awon obi re(d) o n dore pelu awon abileko (e) o ko Eti ikun si awon obi re

(5) Akole ti o boju mu julo fun akaye yii ni…….. (a) Ale yiyan (b) Ere aigbonran (d) Ife obinrin(e) ori okere koko lawo

(6) Apejuwe isele pelu ohun – enu ni _______ (a) Aroso Asariyanjiyan (b) Aroso Oniroyin (d) Aroso Asapejuwe (e) Aroko

(7) _______ Ni o leto lati be owe (a) Omobinrin to ti ni oko (b) Odokunrin (d) Omokunrin ti o ba ti ni iyawo (e) Odo

(8) Iye ti eniyan ba da Ni yoo gba ninu ________ (a) Owe (b) Aaro (d) Ajo (e) Esusu

(9) “Oluko mi” je Ori oro _____ (a) Aroko Asalaye (b) Aroko Asapejuwe (d) Aroso oniroyin (e) Leta

(10) Asa riro oko kiri ni a n pe ni _______ (a) Iro-siro (b) A-ro-oko-de-oko (d) A-ti-ile-de-oko (d) A-ti-ile-de-oko (e) Etile

(11) Ninu ewo ni a ti le ko ilopo meji iye ti a ba da?_______ (a) egbe alafowo-sowopo (b) Esusu (d) owe (e) ajo

(12) Akoko odun ______ ni won maa n sun ijala (a) Oya (b) Egungun (d) Esu (e) Ogun

(13) Okan lara eewo oro ni ________ (a) Oro kii jeun (b) A korin tele oro (d) A kii je isu tutu saaju odun re (e) Obinrin ko gbodo ri oro

(14) Awon ________ ni olusin Ifa (a) Babalawo (b) Oloya (d) Musulumi (e) Alufa

(15) Akoko odun _______ ni won n sun iyere (a) Ifa (b) Osun (d) Egungun (e) Keresi

(16) ____ ni o n fi ilu alagbara han yato si Ilu ti ko ni agbara (a) Orin (b) Ere-Sise (d) Ogun Jija (e) Ijo Jijo

(17) Ta ni o da eto ati oye awon eso sile?____ (a) Orangun (b) Orunmila

( d) Oranmiyan (e) Olodumare

(18) Awon olusin Esu ni a n pe ni ______ (a) Eleesu (b) Elere (d) Elegbe (e)Elebe

(19) Awon olusin sango ni a n pe ni _____(a) Onilu (b)Adosun sango (d) Adeosun Onisango

(e) Agbonya

(20) Asa iranra-eni lowo ode oni_____ (a) Owe (b) Ajo (d) Ebese

(e) Egbe alafowosowopo

(21) Kika ayoka kan ti o ni itumo ni ona ti o le gbe yeni yekeyeke ni _______ (a) Aroko (b) Akaye (d) Akanlo (e) Ewi

(22) “Igba a ro” je ikini ________ (a) Onise Ode (b) Onise Agb (d) Onise Akope (e) Onise owo

(23) Ise ati iwa omoluabi bere lati inu ________ (a) Ile Iwe (b) Ile (d) Ile Ijosin (e) Ogba Ewon

(24) Orisi ayoka ninu akaye ni wonyi ayafi _______ (a) Akaye oni Isoro-n-gbesi (b) Akaye Alapejuwe (d) Akaye oloro-geere (e) Akaye Ewi

(25) Gbolohun ti o n Toka pe isele kan ko waye tabi Ri bee Ni ____ (a) Onibo(b) ayisodi(d) ibeere(e) Eyan

(26) Imototo lo le _______ aarun gbogbo (a) di (b) Segun (d) Mu (e) se

(27) Okan lara iwa omoluabi ni ________ (a) Oro Siso (b) Ounje Jije (d) Ere-Sise (e) Ise Sise

(28) Bi Omoluabi ba ri agbalagba ti o ru eru o gbodo ____ iru eni bee lowo (a) Ran (b) Bu (d) Je (e) Sa fun

(29) Abikeyin Okanbi ni _______ (a) Orunmila (b) Oduduwa (d) Alake (e) Oranmiyan

(30) “Ijamba oko kan ti o Soju mi’ je ori oro ________ (a) Aroko Alalaye

(b) Aroko Asariyanjiyan (d) Aroko Oniroyin (e) Aroko Onileta

Di awon alafo wonyi pelu Idahun ti o ye:

(31) Ona meloo Ni a pin ayoka inu akaye si…………..

(32). …….. ……..ni a fi n so nipa isele ti a fi oju wa Ri ati eyi ti a fi Eti wa gbo

(33) A maa n …………ijala

(34 ) A maa n ……….esa

(35) A maaa n ……..Orin arungbe

(36) Awon wo ni olusin ogun?

(37) “Awon obi mi” je ori oro aroko……….

(38). Eniyan le gba ju iye ti o da lo ninu…………

(39) ‘Aaro’ tunmo si……………

(40) Omo ti a bi,ti a ko sugbon ti ko gba eko ni………

IPIN KEJI: Dahun Ibeere akoko ati meji miiran

(1) (a) .Kin Ni Aroko asapejuwe?

(b) .Ko aroko ti ko din ni oodunrun oro lori okan lara awon ori oro wonyi:-

(i) Ile iwe mi, (ii) Ounje ti mo feran (iii) Iya mi (iv) Ilu mi

(2) (a) Ta ni Omoluabi?

(b) Salaye irufe Omo ti o wa ni ile yoruba

(d) Ko ojuse Omoluabi Marun-un ni awujo ki o si salaye okookan Ni kikun

(3) (a) Fun ogun jija ni oriki

(b) Salaye ohun marun-un ti o le fa ogun ni ilu kan lekun-un rere

(d) Se agbekale ona marun-un ti a le gba dena ogun jija ni ile Yoruba

(4) (a) Kin ni Gbolohun?

(b) Ko orisi gbolohun marun-un ki o si salaye pelu apeere

(d) Irufe gbolohun wo ni awon gbolohun isale wonyi:-

(i). Ise ojo oni ti pari , (ii) Wa ri mi, (iii) Kunle ati Bode je Isu

(iv) Adufe koi ti de

(v). Ta ni o mu owo naa?

(5) (a) Kin ni asa Iranra-eni lowo?

(b) salaye Ona Iranra-Eni Lowo Ile yoruba wonyi Ni kikun

(i) Ajo

(ii) Esusu

(iii) Owe

(iv) Aaro

(v). Arokodoko

(d) ko eko Marun un ti o ri ko ninu iwe litireso ti a ka ni saa Eto eko yii jade.

 

 

 

 

 

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share