AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.

Subject : Yoruba

 

Class : Jss 2

 

Term : Third  Term

 

Week : Week 8

 

Topic :

 

 

 

EDE    Ami Ohun Oro Onisilebu Meji.

ASA    Awon  Eya Yoruba ati ibi ti won tedo si.

LIT     Kikai we Apileko ti Ijoba yan.

 

 

 

 

OSE KEJO

 

EDE

ATUNYEWO AWON AWE GBOLOHUN

Awe gbolohun ni apakan odindi gbolohun. Awe gbolohun pin si orisi meji. Awon naa ni awe gbolohun afrahe ati olori awe gbolohun.

Olori Awe Gbolohun: Olori awe gbolohun ni abala apakan odindi gbolohun ti o le da duro pelu itumo.Fun apeere.

  • Mo ti lo ki ore mi de
  • Gbogbo ilu gbo pe oba waja
  • Akekoo naa mura ki o le gbebun

Awe Gbolohun Afarahe: Awe gbolohun afarahe je awe gbolohun ti ko le da duro pelu itumo. Omaa n fara he olori awe gbolohun ni. Fun apeere.

  • Ore mi ti o lo si Eko ti de.
  • Mo ti lo ki ore mi to de.
  • Mo we nigba ti mo setan
  • Awon eniyan mo pe ounje won.

 

IGBELEWON

1 Toka si olori awe gbolohun nihin-in

  • Maa jeun bi mo ba se tan
  • Tolu a ti lo ki o to de
  • Ounje yii dun bi I pe ki n je tan
  • Bade ri mi nigba ti mo de
  • A tete lo ki a le tete de

2 Tokasi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi

  • Oluko ri Dada ni oko oloko
  • Mo we nigba ti mo ti oko de
  • Bola mura sise ki o le yege

IWE AKATILEWA

1 Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S 2 ) oju iwe 29-32 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba

 

ASA

ASA ISINKU NI ILE YORUBA

Awon Yoruba gbagbo pe gbogbo wa ni a da agbada iku,won a ni ‘ma forum yo mi gbogbo wa la jo n lo.’atomode atagba ko si eni ti ko ni ku,gbogbo wa la je gbese iku.Ki Olorun ko fi iku rere pa ni.

Awon Yoruba gbagbo pe bi eniyan ba ku yoo lo si orun, yala rere tabi orun apaadi.

AWON ONA TI A N GBA SIN ORISIIRISII OKU.

Ki Edumare ki o fi iku ire pa gbogbo wa bi a ti n sin oku kookan da lori eni ti o je ati iru iku ti o pa eni bee. Die ninu iru re niwonyii.

Eni ti sango pa.                     Awon mogba nii se etutu  sisin re.

Eni ti sanponna pa               inu igbo ni won maa n sin-in si awon adahunse ni

Si n se etutu sisin re.

Eni ti o ku sinu odo              eti odo ti o ku si ni won maa n sin–in si, awon

alawo ni si n se etutu re.

Eni ti o ku  toyuntoyun       awon oloro nii se etutu sisin re.

Adete                                      awon ogbontarigi adahunse ni i se etutu sisin re, inu

Igbo ni won a sin-in si, won a si sun gbogbo nnkan                                                                               Ini re.

Eni ti o pokunso                   Awon onimole ni i sin in,idi igi ti o pokunso si naa

ni won o sin in si.

Abuke                                                Awon babalawo ati adahunse ni i se etutu sinsin re,

Inu igbo ni won sin in si, ninu ikoko,won a si sin

Gbogbo nnkan ini re mo pelu.

Babalawo                               awon agba awo ni i se etutu sisin oku babalawo

pelu eye ti o ga ti won yoo fi se etutu lati yose re

kuro ninu egbe awo.

Ode                                         awon ode nii se ayeye oku ode sisin,oro Pataki ti

Won ni lati se fun un ni sisipa ode ti a mo si ‘ ikopa ode’ eyi ni etutu ti won maa  n se ki awon eran ti ode naa ti pa nigba aye re ma baa hun un,ki o sile je ki awon ode to ku laye maa ri eranko.

Onilu                                      awon onilu nii se etutu onilu lati yowo elegbe won

ti o ti ku kuro ninu egbe ki awon to ku le maa ri se.

Alagbede                               Awon alagbede nii se oro igbeyin fun oku alagbede

lati yowo re kuro ninu egbe.Inu ile aro ti alagbede

naa ti n sise ki o to ku ni a ti maa n saba se etutu

Ikeyin yii.

Yato si gbogbo awon wonyii,awon Yoruba a maa ro oku paapaa eyi ti o ba je oku oroju ti

won gba pe iku re kii se lasan,awon agba adahunse tabi oloogun ni o maa n ro oku, ki

won to gbe e si koto, riro yii lo maa je ki o se iku pa eni ti o pa a.   .

 

IGBELEWON : –

  1. salaye ona ti a n gba sin awon oku wonyii; – i. eni toku somi,ii. Eni ti sango pa. iii. Adete, iv. Eni ti o pokunso.

 

IWE ITOKASI

Adewoyin S.Y (2006) Imo,Ede, Asa ati Litireso Ile Eko Sekondiri Agba. (S.S.S.3) Oju iwe 1-35 Corpromutt (Publishers) Nigeria Ltd.

 

APAPO IGBELEWON

1 Toka si olori awe gbolohun nihin-in

  • Maa jeun bi mo ba se tan
  • Tolu a ti lo ki o to de
  • Ounje yii dun bi I pe ki n je tan
  • Bade ri mi nigba ti mo de
  • A tete lo ki a le tete de

2 Tokasi awe gbolohun afarahe ninu awon gbolohun wonyi

  • Oluko ri Dada ni oko oloko
  • Mo we nigba ti mo ti oko de
  • Bola mura sise ki o le yege

LITIRESO

IGBELEWON

  1. Ko ise abinibi mewaa sile.
  2. Slaye okna ninu ise abinibi ti o ko.

 

KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN.

IWE AKATILEWA

1 Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) oju iwe 10- 15 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.

 

ISE ASETILEWA

  • Ewo lo kun ju lati gbe ero okan eni kale? (a) oro (b) awe gbolohun (d) gbolohun.
  • Ewo ni ki I se orisii gbolohun Yoruba (a) olopo oro ise (b) alakanpo (d) alatunto
  • Awe gbolohun wo lo le da duro bi odidi gbolohun (a) olori (b) afarahe (d) asaponle.
  • Ewi alohun ajemayeye ni (a) ijala (b) dadakuada (d) Oku pipe.
  • Eni ti won maa n sin pelu eru/gbogbo awon nnkan ti o ni ni? (a) adete (b) abuke (d) alawo

APA KEJI

  1. Iyato wo lo wa laarin awe gbolohun afarahe a ti olori awe gbolohun? Fun ni apeere meta
  2. Salaye bi won se n sin orisii oku marun-un.

 

 

Spread the word if you find this helpful! Click on any social media icon to share