ASA IGBEYAWO
Subject : Yoruba
Class : Jss 2
Term : Third Term
Week : Week 9
Previous Topics :
2 EDE Leta gbefe. Ohun ti leta gbefe je, awon ona ti a le gba ko leta gbefe
ASA Igbagbo awon Yoruba nipa Olodumare.
LIT Awon ewi ti a n fi oro inu won da won mo.
ASA Igbagbo ati ero Yoruba nipa orisa.
LIT Kika iwe apileko ti ijoba yan.
Topic :
EDE Atunyewo awon awe gbolohun ede Yoruba ( olori awe gbolohun ati
awe gbolohun afibo)
ASA Asa Isinku ni Ile Yoruba.
LIT Kika iwe apileko.
ASA Bi awon akoni eda se di orisa akunlebo (Sango, Ogun abbl)
LIT Kika iwe apileko ewi ti ijoba yan
5 EDE Iseda oro oruko ( lilo afomo ibere ati afomo aarin.
LIT Kika iwe apileko ti ijoba yan.
6 EDE Iseda oro oruko (lilo ilana apetunpe).
ASA Igbagbo awon Yoruba nipa iye leyin iku. Bo se suyo ninu asa Yoruba-
Isomoloruko, isinku, akudaaya (abbl).
LIT Awon ewi ti a fi oro inu won da won mo-ofo. Awon igbese-maye, ape
7 EDE Leta aigbefe (1) ohun ti leta aigbefe je (2) awon ilana ti a le gba ko le
ta aigbefe-adireesi, deeti,adireesi agbaleta,ikini ibere,koko leta, ipari.
ASA Awon ohun mimo ninu esin ibile- igba funfun,ileke funfun, awo funfun
OSE KESA-AN
EDE
APOLA APONLE
Oro aponle ni awon oro tabi akojopo oro to n sise aponle fun oro ise. Apeere oro aponle ni daradara, kiakia, foo. Orisiirisii oro aponle ti ani ninu ede Yoruba ni: apola aponle oniba, apola aponle alasiko, apola aponle onibi, apola aponle onidii, apola aponle alafiwe.
Apola Aponle Oniba: Apola aponle yii maa n toka si isesi, iba tabi bi a se n se nnkan ninu gbolohun. A le lo wuren ibeere *Bawo ni* fun irufe awon gbolohun wonnyi. Fun apeere:
Pupa foo
Tutu nini
Ga fiofio
Ara baba naa ya diedie
Igi agala naa ga fiofio.
Apola Aponle Alasiko: Gege bi oruko re se ri ni. Awon wonyi ni i se pelu asiko (time). Wuren ibeere ti o wulo fun eleyi julo ni * igba wo ni*. Fun apeere:
Teni n bo ni ola
Efo ki I po ni eerun
Wa bi o ba di ale
N o wa ri o bi mo ba setan
Dolapo yoo lo si Oke Oya bi o ba gba olude olojo gbooro.
Apola Aponle Onibi: Iru apola aponle yii ni o n toka si ibi (place). Wuren ti a le lo fun eleyi ni *ibo, ibo ni*. Fun apeere:
Oloselu naa wa ni ewon (lewon)
Awon akekoo wa ni kilaasi
Kola wa ni Ibadan.
A bi Olu ni Eko
Apola Aponle Alafiwe: Apola aponle alafiwe ni a maa n lo lati fi nnkan kan we ekeji re ninu gbolohun, (bi/bii) ni o maa n se atoka won. Fun apeere.
O n se bi omugo
Biola n soro bi ologbon
Awon eniyan po repete bi i yanrin
Omo ile-iwe n gbese kemokemo bi i oga ologun.
Apola Aponle Onidii: Eyi ni o maa n toka si idi ti isele inu gbolohun da le lori. Eleyi ni o maa n toka si idi ti nnkan kan se sele ninu gbolohun. Tori/nitorii ni o maa bere aponle oro aponle lopolopo igba inu gbolohun.
A n fe iyawo nitori omo
E huwa nitori ola
Sade n lo si yunifasiti tori imo
Mo fe jeun tori ebi.
Apola Aponle Onikani: Apola oro aponle yii maa n gbe oye ‘ ki a ni ‘ jade ninu gbolohun ni.
Oga yoo sebe bi o ba ri owo gba
A o ba dupe bi baalu ba fo
Agbe yoo jo igbo naa raurau.
IGBELEWON
A Fi oro-aponle to ba ye di alafo inu gbolohun wonyi:
- Ile iya agba mo……….
- Aja naa feju…………..
- Igi agbon ga ………….ninu igbo.
- Aja fo………… mo olowo re.
- wu ……. . bi i buredi olomi.
B Fa si idi apola aponle nihin-in:
- A a bi ile bas u
- Ile Akede wa ni Ibadan.
- Olu fe e nitori ewa
- Mo gba a tayotayo
- lo kiakia.
IWE AKATILEWA
Eko ede ati asa Yoruba iwe keji (J S S2 ) oju iwe 128-132 lati owo egbe akomolede ati asa Yoruba.
ASA
OWE
Owe ni awon oro ti itumo won jinle ninu asa. Won maa n jeyo ti a ba n so nipa asa Yoruba kan. Bi apeere:
ASA IGBEYAWO
Bi aya ba moju oko tan, alarina a yeba
Obe ti bale ile ki i je iyaale ile ki i se
Eni fun ni lobinrin pari ore.
ASA ISOMOLORUKO
Ile laawo ki a to somoloruko.
Agba ki I wa loja ki ori omo tuntun wo.
Oruko omo ni ijanu omo.
Ti oko ba mo oju aya tan alarina a yeba
IFOWOSOWOPO
Ajeji owo kan o gbe eru dori.
Owo omode ko to pepe, ti agbalagba kan ko wo keregbe.
Gba mi lojo, ki n gba o leerun.
IGBELEWON
- Pa owe meta ti a lo fun ifowosowopo.
- Pa owe meji ti a le ri nibi igbeyawo.
AKATILEWA
- New simplified Yoruba L1 iwe keta oju iwe 68-69 lati owo S.Y Adewoyin
APAPO IGBELEWON
A Fi oro-aponle to ba ye di alafo inu gbolohun wonyi:
- Ile iya agba mo……….
- Aja naa feju…………..
- Igi agbon ga ………….ninu igbo.
- Aja fo………… mo olowo re.
- wu ……. . bi i buredi olomi.
B Fa si idi apola aponle nihin-in:
- A a bi ile bas u
- Ile Akede wa ni Ibadan.
- Olu fe e nitori ewa
- Mo gba a tayotayo
- lo kiakia.
- Pa owe ti o je mo as igbeyawo, ifowosowopo, igbeyawo ati isomoloruko.
IGBELEWON
- Ko ona mejo ti a gba ran ara wa lowo.
- Salaye meta ninu awon asa iranra-eni-lowo.
AKATILEWA
Adewoyin S.Y (2004) New simplified Yoruba L1 iwe keta (J S S 3) oju iwe 44-50 Copromutt (publishers) Nigeria Limited.
ISE ASETILEWA
- Toka si atoka apola aponle ninu awon wonyi. (a) a (b) mo lo (d) nitori.
- Ewo ni ki i se wuren ibeere apola aponle nihin-in? (a) ewo (b) nibo/ibo (d) bi i.
- Fa ila si idi apola aponle ninu gbolohun yii: Biola n soro bi ologbon (a) Biola (b) soro bi (d) bi ologbon.
- Owo omode ko pepe ……. ? (a) ki o gun oke (b) ti agbalagba ko wo keregbe (d) ki agba gbe e.
- ‘Eyin iyawo ko ni mo eni’ oro yii maa n suyo ninu asa (a) igbeyawo (b) isomoloruko (d) ifowosowopo.
APA KEJI
- Fa ila si idi apola aponle ninu awon wonyi:
- Ole naa ko le soro paa lagoo olopaa
- Ojo ro pupo gan-an lale ana
- Ara re ya daadaa nile iwosan nigba ti a de.
- Owo Jide tutu nini bi omi yinyin
- O fe olomoge naa kiakia nitori ewa
8 EDE Ami Ohun Oro Onisilebu Meji.
ASA Awon Eya Yoruba ati ibi ti won tedo si.
LIT Kikai we Apileko ti Ijoba yan.